Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́?
NÍ ÀWỌN àkókò kan nígbèésí ayé àwa èèyàn, a máa ń ṣàníyàn, ó sì máa ń ṣe wá bíi pé ká rí ẹni yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́. Ohun tó ń fa àníyàn wa ló máa pinnu irú ẹni tí a máa fẹ́ sọ ìṣòro wa fún, ó sì dájú pé ọ̀rẹ́ tó máa lè bá wa kẹ́dùn, tó sì ní ìrírí nípa ìṣòro tí à ń dojú kọ ni a máa fẹ́ sọ fún. Tí ẹnì kan bá ní ìrírí tó sì tún jẹ́ olójú àánú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà.
Irú èrò yìí ni àwọn kan máa ń ní nípa àdúrà. Dípò kí wọ́n tọ Ọlọ́run lọ fúnra wọn, wọ́n ronú pé Ọlọ́run àgbàyanu ni, ó sì ga ju àwọn lọ ní gbogbo ọ̀nà. Torí náà, wọ́n gbà pé ó rọ àwọn lọ́rùn láti gbàdúrà sí ọ̀kan lára àwọn ẹni mímọ́. Èrò wọn ni pé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣòro àti àdánwò táwa èèyàn ń ní ló ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni mímọ́ yìí rí, torí náà wọ́n máa mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó sọ nǹkan pàtàkì nù lè sọ pé ó rọ àwọn lọ́rùn láti gbàdúrà sí “Ẹni Mímọ́” tó ń jẹ́ Anthony ti ìlú Padua tí wọ́n kà sí ẹni tí wọ́n lè bẹ̀ lọ́wẹ̀ kó bá wọn wá àwọn nǹkan tó sọ nù tàbí èyí tí wọ́n jí. Tí ẹranko wọn bá ń ṣàìsàn, wọ́n lè gbàdúrà sí “Ẹni Mímọ́” tí wọ́n máa ń pè ní Francis ti ìlú Assisi. Tó bá sì jẹ́ pé ohun kan ṣẹlẹ̀ sí wọn tó mú kí wọ́n sọ̀rètí nù, wọ́n lè gbàdúrà sí “Ẹni Mímọ́” tí wọ́n ń pè ní Jude Thaddeus.
Àmọ́, báwo ni a ṣe lè mọ̀ bóyá Bíbélì fọwọ́ sí i pé ká máa gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́, àbí kò fọwọ́ sí i? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀nà tí a gbà ń bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ni àdúrà jẹ́, ó dájú pé a máa fẹ́ mọ̀ bóyá ó ń gbọ́ àdúrà wa. Á sì tún dáa ká mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àdúrà tí àwọn èèyàn ń gbà sí àwọn ẹni mímọ́.
ǸJẸ́ BÍBÉLÌ FỌWỌ́ SÍ I PÉ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ ÀWỌN ẸNI MÍMỌ́?
Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé àwọn ẹni mímọ́ lè máa bá wọn bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, torí náà, wọ́n lè máa gbàdúrà sí wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia ṣe sọ, èrò wọn ni pé, “tí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ bá ti bẹ̀bẹ̀, á rí àánú gbà fún ẹni tó nílò rẹ̀.” Torí náà, èrò ẹni tó ń gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́ ni pé, níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run, tí òun bá ń gbàdúrà sí wọn, Ọlọ́run máa ṣe ojú rere sí òun lọ́nà àkànṣe.
Ǹjẹ́ Bíbélì fi irú ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni? Àwọn kan sọ pé inú àwọn ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ni àwọn ti rí i pé èèyàn lè gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹ̀mí, pé kí ẹ tiraka pẹ̀lú mi nínú àdúrà sí Ọlọ́run fún mi.” (Róòmù 15:30) Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ni pé kí wọ́n máa bá òun bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá. Torí tó bá jẹ́ ti ká bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni, àwọn ló yẹ kó sọ fún Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ àpọ́sítélì Kristi pé kó máa bá àwọn bẹ Ọlọ́run. Àmọ́, ohun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ni pé, ó tọ́ láti sọ fún ẹni tó jẹ́ Kristẹni bíi tiwa pé kó rántí wa nínú àdúrà rẹ̀. Àmọ́, èyí yàtọ̀ pátápátá sí ká máa gbàdúrà sí ẹnì kan tí a gbà pé ó wà lọ́run, kó lè máa bá wa tọrọ ohun tí à ń fẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Nínú ìwé Ìhìn Rere tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ, Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Jésù tún sọ pé: “Baba lè fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá beere ní orúkọ mi.” (Jòhánù 15:16, Ìròhìn Ayọ̀) Jésù kò sọ pé ká gbàdúrà sí òun kí òun lè bá wa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí nípasẹ̀ Jésù nìkan, kì í ṣe ẹnikẹ́ni mìíràn.
Nígbà kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ bá a pé kó kọ́ àwọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. Ohun tí Jésù sọ fún wọn ni pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, ‘Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Lúùkù 11:2) Ó ṣe kedere pé, “nígbàkigbà,” tàbí ní gbogbo ìgbà tí a bá ń gbàdúrà, Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí ní tààràtà, kì í ṣe Jésù tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn. Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Jésù tí kò lọ́jú pọ̀ yìí, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti gbà pé, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló yẹ ká máa gbàdúrà sí nípasẹ̀ Jésù Kristi, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn alárinà tàbí “ẹni mímọ́” èyíkéyìí?
Apá pàtàkì lára ìjọsìn wa ni àdúrà jẹ́. Kò sì bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu pé ká máa jọ́sìn ẹnikẹ́ni mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run. (Jòhánù 4:23, 24; Ìṣípayá 19:9, 10) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ni a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí.
ǸJẸ́ Ó YẸ KÁ MÁA BẸ̀RÙ LÁTI GBÀDÚRÀ SÍ ỌLỌ́RUN?
Nígbà tí Jésù ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó fi ọmọ kan tó béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ ṣe àpèjúwe. Ṣé bàbá kan máa fún ọmọ rẹ̀ ní òkúta dípò búrẹ́dì? Tàbí kó fún un ní ejò olóró dípò ẹja? (Mátíù 7:9, 10) Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ kò ní ṣe irú nǹkan báyẹn láéláé!
Ronú nípa àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé o jẹ́ òbí, ọmọ rẹ sì ní ohun pàtàkì kan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn tó fẹ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ. Látìgbà tí o ti bí ọmọ yìí lo ti ń tọ́ ọ tìfẹ́tìfẹ́, gbogbo ìgbà lo sì máa ń jẹ́ kí ara tù ú láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Àmọ́, nítorí ìdí kan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ṣe ni ó rán ẹnì kan pé kó wá bá òun béèrè ohun tí ó ń fẹ́ lọ́wọ́ rẹ, dípò kó wá bá ẹ fúnra rẹ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Tó bá jẹ́ pé ọmọ náà ti wá sọ ọ́ di àṣà rẹ̀ kó máa rán ẹni yìí sí ẹ ní gbogbo ìgbà tó bá fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, tó sì dà bíi pé ọ̀nà tó fẹ́ máa gbà bá ẹ sọ̀rọ̀ báyìí nìyẹn ńkọ́? Ǹjẹ́ inú rẹ máa dùn sí ohun tó ń ṣe yìí? Ó dájú pé ó máa dùn ẹ́ gan-an ni! Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wá bá àwọn sọ̀rọ̀ fúnra wọn, wọ́n á sì fẹ́ káwọn ọmọ náà béèrè ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ ní fàlàlà lọ́wọ́ àwọn.
Nígbà tí Jésù máa fa ẹ̀kọ́ tó wà nínú àpèjúwe rẹ̀ yọ nípa ọmọ tó béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ bàbá rẹ̀, Jésù sọ fún àwọn èèyàn yẹn pé: “Nítorí náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” (Mátíù 7:11) Kò sí àní-àní pé, ìdùnnú òbí ló máa ń jẹ́ láti fún ọmọ rẹ̀ ní àwọn nǹkan rere. Àmọ́, ó dájú pé inú Baba wa ọ̀run máa ń dùn gan-an ju ti àwọn òbí lọ láti dáhùn àdúrà wa.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun ní tààràtà kódà bí àwọn àṣìṣe wa bá tiẹ̀ ń mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Kò yan ẹnì kankan pé òun ni kó máa gbọ́ àdúrà wa. Kódà Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Dípò tí a ó fi máa gbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́ tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn pé kí wọ́n bá wa ṣe alárinà láàárín àwa àti Ọlọ́run, ṣe ló yẹ kí àwa fúnra wa gbìyànjú láti mọ Jèhófà Ọlọ́run dáadáa.
Ọ̀rọ̀ gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Baba wa ọ̀run lógún. Ó fẹ́ bá wa yanjú àwọn ìṣòro wa, ìdí nìyẹn tó fi ń pè wá pé ká sún mọ́ òun. (Jákọ́bù 4:8) Inú wa mà dùn o, pé a ní àǹfààní láti bá Ọlọ́run wa àti Baba wa tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀”!—Sáàmù 65:2.