Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ . . .

Kí Nìdí Tí Bíbélì Fi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Kan Àmọ́ Tí Kò Dárúkọ Wọn?

Kí Nìdí Tí Bíbélì Fi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Kan Àmọ́ Tí Kò Dárúkọ Wọn?

Ìwé Rúùtù nínú Bíbélì sọ ìtàn ọkùnrin kan tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀ bí Òfin Mósè ṣe ní kí wọ́n máa ṣe, àmọ́ Bíbélì ò dárúkọ rẹ̀, ṣe ló kàn pè é ní Lágbájá. (Rúùtù 4:1-12) Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé gbogbo àwọn tí Bíbélì ò dárúkọ wọn ni kò jámọ́ nǹkan kan tàbí pé wọ́n jẹ́ èèyàn burúkú?

Rárá o. Wo àpẹẹrẹ kan tó yàtọ̀. Nígbà tí Jésù ń múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá tó máa ṣe kẹ́yìn, ó sọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “lọ sínú ìlú ńlá náà, sọ́dọ̀ Lágbájá [“ọkùnrin kan báyìí,” Bíbélì Mímọ́]” kí wọ́n sì ṣètò ilé rẹ̀ sílẹ̀. (Mátíù 26:18) Ǹjẹ́ ó yẹ ká ronú pé èèyàn burúkú ni ọkùnrin tí wọ́n pè ní “Lágbájá” nínú ẹsẹ yìí tàbí pé kì í ṣe ẹni pàtàkì kan tó yẹ kí wọ́n dárúkọ rẹ̀? Kò yẹ ká ronú bẹ́ẹ̀ rárá, torí ó dájú pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ẹni tí wọ́n pè ní “ọkùnrin kan báyìí” yẹn. Àmọ́ torí pe orúkọ rẹ̀ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìtàn náà, Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀.

Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn burúkú ni Bíbélì dárúkọ wọn, àìmọye àwọn olóòótọ́ míì sì wà tí kò tiẹ̀ mẹ́nu ba orúkọ wọn rárá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dárúkọ obìnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ìyẹn Éfà, àwọn èèyàn sì mọ̀ ọ́n dáadáa. Síbẹ̀, ìwà ìmọtara ẹni nìkan àti àìgbọ́ràn rẹ̀ wà lára ohun tó kó Ádámù sínú ẹ̀ṣẹ̀, èyí sì wá fa àkóbá ńláǹlà fún gbogbo wa. (Róòmù 5:12) Ní ìyàtọ̀ síyẹn, Bíbélì ò dárúkọ ìyàwó Nóà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la rí kọ́ lára rẹ̀ ní ti bó ṣe fi taratara ṣiṣẹ́, tó jẹ́ onígbọràn, tó sì ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run gbé fún un. Ó dájú pé bí Bíbélì ò ṣe dárúkọ rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé kò jámọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run tàbí pé inú Ọlọ́run kò dùn sí i.

Àwọn míì náà ṣì wà tí Bíbélì ò dárúkọ wọn tí wọ́n kó ipa pàtàkì, kódà tí wọ́n ṣe gudugudu méje láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. Ṣé o rántí ọmọbìnrin kékeré ará Ísírẹ́lì yẹn tó jẹ́ ẹrú Náámánì, olórí ogun ilẹ̀ Síríà? Ó fìgboyà bá ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa wòlíì Jèhófà kan tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ohun ìyanu sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀. (2 Àwọn Ọba 5:1-14) Onídàájọ́ kan wà ní Ísírẹ́lì tó ń jẹ́ Jẹ́fútà. Ọmọbìnrin rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó bá dọ̀rọ̀ ká lo ìgbàgbọ́. Ó gbà tinútinú láti má ṣe lọ́kọ tàbí bímọ láyé rẹ̀ torí kó lè mú ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. (Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40) Bákàn náà, kì í ṣe gbogbo àwọn ọkùnrin tó kọ Sáàmù ni Bíbélì dárúkọ, bẹ́ẹ̀ ó lé ní ogójì Sáàmù tí àwọn tí kò dárúkọ yìí kọ. Yàtọ̀ síyẹn, a ò mọ orúkọ àwọn wòlíì kan tí Bíbélì sọ pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì.—1 Àwọn Ọba 20:37-43.

Àpẹẹrẹ míì tó tún lágbára ni tàwọn áńgẹ́lì olóòótọ́. Ọ̀kẹ́ àìmọye ni àwọn áńgẹ́lì yìí, síbẹ̀ méjì péré nínú wọn ni Bíbélì dárúkọ, ìyẹn Gébúrẹ́lì àti Máíkẹ́lì. (Dáníẹ́lì 7:10; Lúùkù 1:19; Júúdà 9) Bíbélì ò dárúkọ gbogbo àwọn tó kù. Bí àpẹẹrẹ, Mánóà, bàbá Sámúsìnì béèrè lọ́wọ́ áńgẹ́lì kan pé: “Kí ni orúkọ rẹ, kí a lè bọlá fún ọ dájúdájú nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” Áńgẹ́lì náà dá a lóhùn pé, ‘Èé ṣe tí o fi ń béèrè orúkọ mi?’ Áńgẹ́lì yìí mọ̀ọ́mọ̀ má sọ orúkọ rẹ̀ torí kò fẹ́ gba ògo tó tọ́ sí Ọlọ́run.—Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18.

Bíbélì ò sọ ìdí tó fi dárúkọ àwọn kan àti ìdí tí kò fi sọ orúkọ àwọn míì. Àmọ́ a lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lára ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n sin Ọlọ́run láì retí pé kí wọ́n gbọ́ orúkọ àwọn nílé lóko.