Ohun Tí Bíbélì Sọ
Báwo ni tọkọtaya ṣe lè láyọ̀?
Àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nípa bí tọkọtaya ṣe lè láyọ̀ wúlò gan-an torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó ṣètò ìgbéyàwó ló fún wa ni àwọn ìmọ̀ràn náà. Bíbélì kọ́ wa bí a ṣe lè ní àwọn ìwà tó máa mú kí ìdílé wa láyọ̀, ó sì kọ́ wa bí a ṣe lè yẹra fún àwọn ìwà tó lè da àárín tọkọtaya rú. Ó tún kọ́ wa bí tọkọtaya ṣe lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí àwọn méjèèjì á sì máa láyọ̀.—Ka Kólósè 3:8-10, 12-14.
Ó yẹ kí tọkọtaya máa bọlá fún ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Tí àwọn méjèèjì bá ń ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run yàn fún wọn, wọ́n á máa láyọ̀.—Ka Kólósè 3:18, 19.
Kí ló lè jẹ́ kí tọkọtaya máa bá ara wọn gbé títí lọ?
Tí tọkọtaya bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, àjọgbé wọn á dùn. Ọlọ́run kọ́ wa bí a ṣe lè ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Ọlọ́run àti Jésù jẹ́ tó bá kan ti ká yááfì nǹkan kan nítorí àwọn èèyàn torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.—Ka 1 Jòhánù 4:7, 8, 19.
Tọkọtaya tó mọyì ètò ìgbéyàwó kò ní jẹ́ kí nǹkan kan yà wọ́n. Ọlọ́run tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ kò fẹ́ kí ìdílé tú ká, ó fẹ́ kí ọkọ àti aya wà pa pọ̀ títí láé. Tọkọtaya lè bá ara wọn kalẹ́, torí pé Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n fi lè máa ran ara wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa gba ti ara wọn rò. Ó tún dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀, lọ́nà tí wọ́n fi lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:18, 24.