Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Irú ẹni wo ni Ọlọ́run?

Ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí ní Ọlọ́run. Òun ló dá ọ̀run, ayé àti gbogbo ohun alààyè. Kò sẹ́ni tó dá Ọlọ́run, torí náà kò ní ìbẹ̀rẹ̀. (Sáàmù 90:2) Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn wá òun kí wọn sì mọ́ òtítọ́ nípa ẹni tí òun jẹ́.—Ka Ìṣe 17:24-27.

Ọlọ́run ní orúkọ, a sì lè mọ orúkọ yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, tí a bá fara balẹ̀ ronú nípa àwọn ìṣẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, ìyẹn lè jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ìwà rẹ̀. (Róòmù 1:20) Àmọ́, tá a bá fẹ́ mọ Ọlọ́run dáadáa, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì ló jẹ́ ká mọ àwọn ìwà onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní.—Ka Sáàmù 103:7-10.

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìwà ìrẹ́jẹ

Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Nígbà tó dá àwa èèyàn, àwòrán ara rẹ̀ ló dá wa. (Diutarónómì 25:16) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Ọlọ́run kọ́ ló ń fa ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Ó fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń ṣi òmìnira yẹn lò, tí wọ́n sì ń hùwà ìrẹ́jẹ. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń dun Ọlọ́run gan-an.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6; Diutarónómì 32:4, 5.

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní jẹ́ kí ìwà ìrẹ́jẹ máa báa lọ títí láé. (Sáàmù 37:28, 29) Bíbélì ṣèlérí pé, láìpẹ́ Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ.—Ka 2 Pétérù 3:7-9, 13.

Bíbélì ṣèlérí pé, láìpẹ́ Ọlọ́run á mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé