Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | ÈLÍJÀ

Ó Fara Da Ìwà Ìrẹ́jẹ

Ó Fara Da Ìwà Ìrẹ́jẹ

Ó tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí Èlíjà fi rìn gba ọ̀nà àríwá láti orí Òkè Hórébù wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àwọn ọ̀nà tóóró tó wà ní Àfonífojì Jọ́dánì ló gbà kọjá. Nígbà tó dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó ríi pé nǹkan ti yàtọ̀ gan-an ní ìlú tí wọ́n bí i sí yìí. Ọ̀gbẹlẹ̀ ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó wà níbẹ̀ ti ń kásẹ̀ nílẹ̀. Òjò tó máa ń rọ̀ lásìkò ìkórè ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ díẹ̀díẹ̀, àwọn àgbẹ̀ sì ti bọ́ sóko kí wọ́n lè kọ ebè. Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Èlíjà ríi yìí mú kí ara tù ú, inú rẹ̀ á sì dùn bó ṣe ri i pé nǹkan ti sunwọ̀n sí i nílẹ̀ náà. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ ẹ́ lógún jù. Ìdí ni pé, àwọn èèyàn náà kò jọ́sìn Ọlọ́run mọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ṣì ń jọ́sìn òrìṣà Báálì. Nítorí náà, iṣẹ́ pọ̀ fún Èlíjà láti ṣe. *

Èlíjà rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ ní pẹrẹu lórí ilẹ̀ kan tó fẹ̀ nítòsí ìlú kan tó ń jẹ́ Ebẹli-Méhólà. Ó rí àwọn màlúù mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n fi àjàgà sí lọ́rùn ní méjì-méjì. Wọ́n pín wọn sí méjìlá, kí wọ́n lè máa tulẹ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti ìkejì lápá òsì. Bí wọ́n ṣe n túlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọ ebè sórí ilẹ̀ náà. Ẹni tó ń darí màlúù méjì tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn ni Èlíjà ń wá. Èlíṣà lorúkọ rẹ̀, òun sì ni Jèhófà ti yàn láti rọ́pò wòlíì Èlíjà. Ó dájú pé ó wu Èlíjà láti pàdé ẹni yìí. Ìdí ni pé, ó ti pẹ́ díẹ̀ tí Èlíjà ti ń ronú pé kò sí ẹlòmíì tó ń sin Jèhófà àfi òun nìkan.—1 Àwọn Ọba 18:22; 19:14-19.

Ǹjẹ́ Èlíjà lọ́ tìkọ̀ nígbà tó mọ̀ pé Èlíṣà máa gba díẹ̀ lára ojúṣe òun ṣe àti pé òun ló máa gba ipò òun lọ́jọ́ iwájú? A kò mọ̀, ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí irú èrò yìí ti wá sí i lọ́kàn. Ó ṣe tán, “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” lòun náà. (Jákọ́bù 5:17) Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Èlíjà sọdá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ju ẹ̀wù oyè rẹ̀ sára rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 19:19) Aṣọ àwọ̀lékè ni ẹ̀wù oyè tí Èlíjà máa ń wọ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé awọ àgùntàn tàbí ti ewúrẹ́ ni wọ́n fi ṣe é. Ẹ̀wù oyè yìí jẹ́ àmì pé Jèhófà ti yàn án fún iṣẹ́ pàtàkì kan, torí náà bó ṣe wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè yẹn fún Èlíṣà ní ìtumọ̀ pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé, Èlíjà fínnúfíndọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà láti yan Èlíṣà pé kó rọ́pò òun. Ohun tí Èlíjà ṣe fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣègbọràn sí i.

Èlíjà yan Èlíṣà láti rọ́pò rẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíṣà ṣì kéré lọ́jọ́ orí, tó sì jẹ́ pé kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ ló máa rọ́pò Èlíjà, síbẹ̀, ó múra tán láti ran wòlíì àgbà náà lọ́wọ́. Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì tún ràn Èlíjà lọ́wọ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́fà tó fi bá ṣiṣẹ́. Nígbà tó yá, Bíbélì pè é ni “ẹni tí ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà.” (2 Àwọn Ọba 3:11) Ẹ wo bí inú Èlíjà ṣe máa dùn tó pé òun ní irú òjíṣẹ́ tó dáńgájíá, tó sì máa ń tẹra mọ́ṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Kò pẹ́ tí àwọn méjèèjì fi di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tó dájú ni pé, bí àwọn méjèèjì ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń fún ara wọn ní ìṣírí ti ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti fara da ìwà ìrẹ́jẹ tó kún ilẹ̀ náà, pàápàá ìwà ìkà Áhábù ọba, tó túbọ̀ ń burú sí i lójoojúmọ́.

Ǹjẹ́ wọ́n ti rẹ́ ẹ jẹ rí? Ká sòótọ́, ṣàṣà ni ẹni tí wọn kì í rẹ́ jẹ nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí. Àmọ́, tó o bá ní ọ̀rẹ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ. Bákan náà, o  tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Èlíjà nípa bó ṣe lo ìgbàgbọ́ nígbà tí o bá kojú ìwà ìrẹ́jẹ.

“DÌDE, SỌ̀ KALẸ̀ LỌ PÀDÉ ÁHÁBÙ”

Èlíjà àti Èlíṣà ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín. Ó dájú pé, àwọn méjèèjì ló kọ́ àwọn wòlíì míì lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n ti ṣètò ọ̀nà tí wọ́n fi ń kọ́ wọn. Nígbà tó yá, Jèhófà gbé iṣẹ́ míì fún Èlíjà, ó sọ fún un pé: “Dìde, sọ̀ kalẹ̀ lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì.” (1 Àwọn Ọba 21:18) Kí ni Áhábù ṣe?

Ọba yìí ti fi Jèhófà sílẹ̀ pátápátá, òun sì ni ìwà rẹ̀ burú jù nínú gbogbo àwọn ọba tó tíì jẹ ní Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Ó fẹ́ Jésíbẹ́lì, ìyàwó rẹ̀ yìí sì mú kí ìjọsìn Báálì gbilẹ̀ gan-an débi pé Áhábù ọba fúnra rẹ̀ ń jọ́sìn òrìṣà náà. (1 Àwọn Ọba 16:31-33) Bí wọ́n bá ń jọ́sìn òrìṣà Báálì, wọ́n máa ń ṣe àwọn ààtò ìbímọlémọ, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètùtù, wọ́n máa ń ní ìbálòpọ̀ lọ́nà tó burú jáì, wọ́n tiẹ̀ tún máa ń fi àwọn ọmọ kéékèèké rúbọ níbẹ̀. Ṣáájú ìgbà yẹn ni Jèhófà ti pàṣẹ pé kí Áhábù pa Ọba Síríà tó ń jẹ́ Bẹni-hádádì, àmọ́ kò pa Ọba burúkú yìí nítorí owó tó máa rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. (1 Àwọn Ọba, orí 20) Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé oníwọra, ìkà àti olójú kòkòrò ni Áhábù àti Jésíbẹ́lì.

Áhábù ní ààfin ńlá kan ní Samáríà, ààfin náà sì tóbi gan an. Ó tún ní ààfin míì ni Jésíréélì tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàdínlógójì (37) sí ti Samáríà. Ọgbà àjàrà kan wà nítòsí ààfin kejì yìí. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nábótì ló ni ọgbà náà, ṣùgbọ́n ojú Áhábù ti wọ ọgbà yẹn. Ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé kó ta ọgbà náà fún òun tàbí kí òun fun un ní ọgbà míì. Nábótì dáhùn pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n fi ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi fún ọ.” (1 Àwọn Ọba 21:3) Àwọn kan lè rò pé alágídí ni Nábótì, tàbí ó kàn ń fi ikú ṣeré. Àmọ́, ńṣe ni Nábótì ṣègbọràn sí òfin Jèhófà tó sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ tí wọ́n jogún fún àkókò tí ó lọ kánrin. (Léfítíkù 25:23-28) Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Nábótì ni bó ṣe máa pa òfin Jèhófà mọ́. Ó mọ̀ pé ó léwu fún òun láti ta ko Áhábù, síbẹ̀ ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó ní ìgboyà, ó sì ní ìgbàgbọ́.

Áhábù ní tiẹ̀ kò ronú rárá nípa òfin Jèhófà. Ńṣe ló lọ sílé, “ó wúgbọ, ó sì dorí kodò” nítorí kò rí ohun tó ń wá. Bíbélì sọ pé: “Ó wá dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀, ó sì yí ojú padà, kò sì jẹ oúnjẹ.” (1 Àwọn Ọba 21:4) Nígbà tí Jésíbẹ́lì rí ọkọ rẹ̀ tó ṣu ẹnu pọ̀ bí ọmọ kékeré tí inú ń bí, ó wá bó ṣe máa bá a gba ohun tó ń fẹ́ àmọ́, ohun tó ṣe ni pé ó pa ìdílé ọkùnrin olóòótọ́ yẹn run.

Kò sí ìgbà táa bá ka ìtàn nípa bí Jésíbẹ́lì ṣe pa Nábótì, tí kì í yà wá lẹ́nu nítorí ìwà ìkà tó burú jáì tó hù. Jésíbẹ́lì mọ̀ pé, nínú òfin Ọlọ́run, kí ẹ̀sùn kan tó lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó kéré tán èèyàn méjì gbọ́dọ̀ ṣe ẹlẹ́rìí. (Diutarónómì 19:15) Ó wá kọ lẹ́tà kan ní orúkọ Áhábù, ó sì fi ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó wà ní ìlú Jésíréélì pé, kí wọ́n wá àwọn ọkùnrin méjì tó máa parọ́ mọ́ Nábótì. Irọ́  tó ní kí wọ́n pa mọ́ ọn ni pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba torí ó mọ̀ pé ńṣe ni wọ́n máa pa ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ká má fa ọ̀rọ̀ gùn, “àwọn ọkùnrin [méjì] tí kò dára fún ohunkóhun” parọ́ mọ́ Nábótì, àwọn èèyàn náà sì sọ Nábótì lókùúta pa. Wọn ò fi mọ síbẹ̀ o, ńṣe ni wọ́n tún pa àwọn ọmọ rẹ̀! * (1 Àwọn Ọba 21:5-14; Léfítíkù 24:16; 2 Àwọn Ọba 9:26) Áhábù wá sọ ara rẹ̀ di ọkọ gbẹ̀wù dání, ó jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ máa ṣe bó ṣe wù ú, títí tó fi pa àwọn ẹni ẹlẹ́ni tí kò ṣẹ̀.

Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Èlíjà nígbà tí Ọlọ́run fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn hàn án. Ó máa ń dùn wá gan-an nígbà tá a bá rí i tí àwọn ẹni burúkú ń gbádùn tí àwọn aláìṣẹ̀ sì ń jìyà. (Sáàmù 73:3-5, 12, 13) Lónìí, a sábà máa ń rí àwọn èèyàn tó ń hùwà ìrẹ́jẹ tó burú jáì, kódà, àwọn tó pe ara wọn ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá máa ń fi ọwọ́ ọlá gbáni lójú. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ lè tù wá nínú. Nítorí ó jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Jèhófà, gbogbo rẹ̀ pátá ló ń rí. (Hébérù 4:13) Kí ni Ọlọ́run máa ń ṣe sí àwọn ìwà ìkà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí?

‘O TI WÁ MI KÀN, ÌWỌ Ọ̀TÁ MI!’

Jèhófà rán Èlíjà sí Áhábù. Ọlọ́run wá sọ ní tààràtà pé: “Òun nìyẹn níbi ọgbà àjàrà Nábótì.” (1 Àwọn Ọba 21:18) Nígbà tí Jésíbẹ́lì sọ fún Áhábù pé ọgbà àjàrà náà ti di tiẹ̀, kíá ló dìde lọ sínú ọgbà tí ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ yẹn. Ńṣe ni inú rẹ̀ ń dùn ṣìnkìn bó ṣe ń yan fanda nínú ọgbà náà, tó sì ń ronú nípa àrà tí òun á fi ọgbà náà dá. Kò tiẹ̀ rò ó pé Jèhófà ń wo òun. Àmọ́, lójijì Èlíjà yọ sí i! Bó ṣe rí Èlíjà, inú rẹ̀ ò dùn mọ́, orí rẹ̀ gbóná, inú sì bẹ̀rẹ̀ sí í bí i, ló bá fi ìkanra sọ pé: ‘O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!’—1 Àwọn Ọba 21:20.

‘O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!’

Ohun tí Áhábù sọ yìí jẹ́ ká mọ nǹkan méjì nípa rẹ̀. Àkọ́kọ́, bó ṣe sọ pè: ‘O ti wá mi kàn’ fi hàn pé ó ti jìnnà sí Jèhófà. Jèhófà ti rí i tẹ́lẹ̀. Ó ti rí i pé Áhábù mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa, kó lè gbádùn ọgbà tí Jésíbẹ́lì fipá gbà yẹn. Ọlọ́run tún ri ohun tó wà nínú ọkàn Áhábù pé, àánú, ìdájọ́ òdodo, àti ìyọ́nú kò ṣe pàtàkì sí i mọ, ohun ìní tó fẹ́ kó jọ ló jẹ ẹ́ lógún. Ìkejì ni pé, Áhábù fi hàn pé òun kórìíra Èlíjà tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nígbà tó sọ pé: “Ìwọ ọ̀tá mi.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Èlíjà ló lè ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà kúrò lọ́nà ìparun tó ń tọ̀ yẹn.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì la rí kọ́ látinú ìwà òmùgọ̀ tí Áhábù  hù. A gbọ́dọ̀ máa rántí pé kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Bàbá onífẹ̀ẹ́ yìí máa ń mọ ìgbà ti a bá ṣàṣìṣe, ó sì máa ń wù ú pé ká ṣàtúnṣe. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sí wa láti ràn wá lọ́wọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn bí Èlíjà náà ti ṣe. Àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ tá a bá sọ àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà di ọ̀tá wa.—Sáàmù 141:5.

Nígbà tí Èlíjà dá Áhábù lóhùn, ó sọ fún un pé: “Mo ti wá ọ kàn.” Èlíjà wá a kàn torí ó mọ̀ pé ó ti di apànìyàn, ó ti jalè, ó sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ọba burúkú yẹn mà ni Èlíjà ń bá wí yìí, ẹ ò rí pé ó ní ìgboyà gan-an! Kò fi mọ síbẹ̀, ó tún kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fún Áhábù. Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni Jèhófà kúkú rí, ó rí bí ìdílé Áhábù ṣe ń kó ìwà ìkà wọn ran àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. Èlíjà wá sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún Áhábù pé: “Èmi yóò sì gbá ọ kúrò tefétefé,” ìyẹn ni pé, gbogbo ìdílé Áhábù pátápátá ló máa pa run. Jésíbẹ́lì gan-an á sì jẹ iyán rẹ̀ níṣu.—1 Àwọn Ọba 21:20-26.

Èlíjà mọ̀ dáadáa pé èèyàn ò lè ṣe ohun burúkú kó sì mú un jẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn kò gbà bẹ́ẹ̀ lónìí. Síbẹ̀, ìtàn Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni Jèhófà ń ri, yóò sì ṣe ìdájọ́ òdodo ní àsìkò tó yẹ. Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé, láìpẹ́ Ọlọ́run á fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ títí láé! (Sáàmù 37:10, 11) O lè máa ṣe kàyéfì pé, ṣé ìdájọ́ Ọlọ́run kò ju kó kàn fìyà jẹ àwọn tó ba ṣẹ̀ lọ? Àbí ṣé ó tún máa ń fi àánú hàn tó bá ń ṣe ìdájọ́?

“ÌWỌ HA TI RÍ BÍ ÁHÁBÙ ṢE RẸ ARA RẸ̀ SÍLẸ̀?”

Ó ṣeé ṣe kó ya Èlíjà lẹ́nu nígbà tó rí ohun tí Áhábù ṣe lẹ́yìn tó gbọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Gbàrà tí Áhábù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọn àwọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀, ó sì ń dùbúlẹ̀ nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìsọ̀rètínù.” (1 Àwọn Ọba 21:27) Ǹjẹ́ Áhábù ronú pìwà dà?

Ohun tí a mọ̀ ni pé ó gbé ìgbésẹ̀ tó dáa. Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ ohun kan tó ṣòro fún ẹni tó jẹ́ agbéraga tó sì jọ ara rẹ̀ lójú láti ṣe. Àmọ́, ṣé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Ó dáa, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé ti ọba kan tó ń jẹ́ Mánásè tó ṣàkóso lẹ́yìn rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Mánásè tiẹ̀ tún ya ìkà ju Áhábù lọ, àmọ́ nígbà tó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Kò fi mọ síbẹ̀ o, gbogbo àwọn òrìṣà tó ń sìn ló kó dànù, ó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, ó sì sapá láti sin Jèhófà, ó tiẹ̀ tún rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà láti yí pa dà. (2 Kíróníkà 33:1-17) Àmọ́, Áhábù ní tiẹ̀ kò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Síbẹ̀, ǹjẹ́ Jèhófà kíyè sí bí Áhábù ṣe fí ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn ní gbangba? Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: “Ìwọ ha ti rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ní tìtorí mi? Nítorí ìdí náà pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi, èmi kì yóò mú ìyọnu àjálù náà wá ní àwọn ọjọ́ rẹ̀. Àwọn ọjọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ ni èmi yóò mú ìyọnu àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 21:29) Ṣé Jèhófà ti wá dárí ji Áhábù ni? Rárá o, kí ó tó lè rí irú àánú bẹ́ẹ̀ gbà, ó gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Ìsíkíẹ́lì 33:14-16) Àmọ́, Áhábù fi hàn pé òun kábàámọ̀ ohun tóun ṣe níwọ̀nba, Jèhófà náà wá fi àánú hàn sí i ní ìwọ̀n tó fi kábàámọ̀. Ohun tí Jèhófà ṣe ni pé, kò jẹ́ kí gbogbo ìlà ìdílé Áhábù pa run nígbà ayé rẹ̀.

Síbẹ̀, Jèhófà kò yí ìdájọ́ tó ṣe fún un pa dà. Nígbà tó yá, Jèhófà bá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó dáa jù láti tan Áhábù sínú ogun tó máa gbẹ̀mí rẹ̀. Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn ní ohun tí Jèhófà sọ ṣẹ. ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ó fara gbọgbẹ́ lójú ogun, ẹ̀jẹ̀ sì dà lára rẹ̀ títí tó fi kú sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà wá fi kún un pé, nígbà ti wọ́n ń fọ kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí Áhábù kú sí, àwọn ajá bẹ̀rẹ̀ sí í lá ẹ̀jẹ̀ ọba náà. Ní ìta gbangba ni ọ̀rọ̀ Jèhófà, tí Èlíjà sọ fún Áhábù ti ní ìmúṣẹ, ìyẹn ni pé: “Ibi tí àwọn ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá yóò ti lá ẹ̀jẹ̀ rẹ.”—1 Àwọn Ọba 21:19; 22:19-22, 34-38.

Fún Èlíjà, Èlíṣà àti àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Áhábù mú un dá wọn lójú pé Jèhófà kò gbàgbé ìgboyà àti ìgbàgbọ́ Nábótì. Ohun kan tó dájú ni pé, kò sí bó ṣe lè pẹ́ tó, onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run, kò ní ṣàì fìyà jẹ àwọn ẹni ibi, síbẹ̀ ó máa ń fi àánú hàn nínú ìdájọ́ rẹ̀ tó bá rí ìdí tó fi yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Númérì 14:18) Ẹ̀kọ́ ńlá nìyẹn jẹ́ fún Èlíjà torí pé, ó ti fara da ìṣàkóso ọba burúkú yẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún! Ṣé àwọn èèyàn ti rẹ́ ìwọ náà jẹ rí? Ṣé ó wù ẹ́ kí Ọlọ́run fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ? Á dáa kí o fara wé ìgbàgbọ́ Èlíjà. Òun àti Èlíṣà tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fara da ìwà ìrẹ́jẹ, wọn sì ń bá a lọ láti máa polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!

^ ìpínrọ̀ 3 Jèhófà kò rọ òjò fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀, káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ríi pé òrìṣà Báálì tí wọ́n gbà pé ó ń mú òjò àti ọmọ wá fún ilẹ̀ náà kò ní agbára kankan. (1 Àwọn Ọba, orí 18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Ilé Ìṣọ́ April 1, 2008.

^ ìpínrọ̀ 13 Jésíbẹ́lì mọ̀ pé, àwọn ọmọ Nábótì ló máa jogún ọgbà àjàrà yẹn tí bàbá wọn bá kú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí ẹ̀ ló ṣe pa wọ́n. Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé” nínú ìwé yìí.