Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ohun Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Fún Ẹ

Ohun Tí Ọlọ́run Ti Ṣe Fún Ẹ

‘Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.’—Jòhánù 3:16, Bíbélì Mímọ́.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, àkàtúnkà ni àwọn èèyàn sì máa ń kà á. Kódà, àwọn kan sọ pé: “Kò sí ẹsẹ Bíbélì míì tó dà bí ẹsẹ Bíbélì yìí, tó ṣàlàyé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí èèyàn àti bá a ṣe lè rí ìgbàlà.” Ìdí nìyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń kọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí tàbí kí wọ́n kọ “Jòhánù 3:16” sára mọ́tò wọn tàbí ibi tí àwọn èèyàn sábà máa ń pọ̀ sí ládùúgbò tàbí sára ògiri.

Ó dá àwọn tó máa ń kọ ọ̀rọ̀ yìí lójú pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló máa jẹ́ ká ní ìgbàlà lọ́jọ́ iwájú. Ìwọ náà ńkọ́? Báwo ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe rí lọ́kàn rẹ? Ọ̀nà wo lo rò pé Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ẹ?

‘ỌLỌRUN FẸ́ ARÁYÉ TÓ BẸ́Ẹ̀ GẸ́Ẹ́’

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń yin Ọlọ́run fún àwọn nǹkan àgbàyanu tó dá, irú bí oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀, ilẹ̀ ayé, títí kan àwa èèyàn àti àwọn ìṣẹ̀dá míì. Bó ṣé jẹ́ pé ẹni tó ṣẹ̀dá àwọn ohun abẹ̀mí dá wọn lọ́nà àrà fi hàn pé ó gbọ́n fíìfíì jù wá lọ. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́ fún bó ṣe dá ẹ̀mí wọn sí. Àwọn ohun tó pèsè fún wa jẹ́ kòṣeémáàní, irú bí afẹ́fẹ́, omi àti oúnjẹ. Ó tún dá ayé lọ́nà tí ìdọ̀tí kò fi tò jọ pelemọ sórí ilẹ̀ ayé. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń mú ká wà láàyè ká sì máa gbádùn àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wa.

Tí a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́ fún gbogbo nǹkan tó ṣe fún wa yìí, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa nìkan ni, òun náà tún ni Olùpèsè. (Sáàmù 104:10-28; 145:15, 16; Ìṣe 4:24) Tá a bá fara balẹ̀  ronú lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa àti bó ṣe ń dá ẹ̀mí wa sí, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tó ní sí wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “[Ọlọ́run] fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo. Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.”—Ìṣe 17:25, 28.

Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa kọjá bó ṣe ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. Ó tún yẹ́ wa sí, ó sì gbé wa ga ní ti pé ó dá wa lọ́nà tá a fi lè sún mọ́ ọn, èyí sì mú ká yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹranko. (Mátíù 5:3) Àǹfààní ni èyí jẹ́ fún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn láti di ara ìdílé Ọlọ́run, ìyẹn àwọn “ọmọ” rẹ̀, lọ́jọ́ iwájú.—Róòmù 8:19-21.

Ohun míì tí Jòhánù 3:16 sọ ni pé, Ọlọ́run fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa nípa bó ṣe rán Jésù wá sí ayé láti kọ́ wa nípa Òun, tó jẹ́ baba rẹ̀. Ìdí míì ni pé ó wá kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Jésù kú fún wa. Wọn ò tún mọ ikú Jésù ṣe fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ìdí tí Jésù fi kú àti àǹfààní tí ikú rẹ̀ ṣe fún wa.

‘Ó FI ỌMỌ BÍBÍ RẸ̀ KAN ṢOṢO FÚNNI’

Òótọ́ ni pé, ìgbàkigbà làwa èèyàn lè kú. Àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú sì ń fí ojú wa rí màbo. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ sí wa nìyẹn. Ó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní ọ̀nà tí wọ́n fi máa wà láàyè títí láé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ohun tó ń retí lọ́dọ̀ wọn ni pé kí wọ́n ṣègbọràn sí òun. Ọlọ́run sọ pé tí wọ́n bá ṣàìgbọràn, wọ́n máa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ṣùgbọ́n, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì yọrí sí ikú fún àwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Àmọ́, “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo” ni Ọlọ́run (Sáàmù 37:28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ dá, síbẹ̀ kò ta gbogbo wa nù pé ká máa jìyà, ká sì máa kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà “ẹ̀mí fún ẹ̀mí” tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì ló fi yanjú ọ̀ràn náà, èyí ló mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe fún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn. (Ẹ́kísódù 21:23) Ìbéèrè náà wá ni pé, Báwo la ṣe lè pa dà ní ìwàláàyè pípé tí Ádámù pàdánù? Ìdáhùn ni pé: Ẹnì kan gbọ́dọ̀ fi ìwàláàyè pípé tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí Ádámù pàdánù ṣe ìràpadà fún wa.

Jésù fínnúfíndọ̀ wá sí ayé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú

Ohun tó dájú ni pé, kò sí àtọmọdọ́mọ Ádámù kankan tó kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ìràpadà náà, àyàfi Jésù. (Sáàmù 49:6-9) Ìdí ni pé ẹni pípé ni Jésù nígbà tí wọ́n bí i, kò sì ní àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan gẹ́gẹ́ bí Ádámù ṣe wà kó tó ṣàìgbọràn. Torí náà, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, ó sì rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún. Ohun tó ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù láti gbádùn ìwàláàyè pípé tí Ádámù pàdánù. (Róòmù 3:23, 24; 6:23) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè jàǹfààní nínú ìfẹ́ títayọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí?

 ‘ẸNIKẸ́NI TÍ Ó BÁ GBÀ Á GBỌ́’

Ìwé Jòhánù 3:16 tún gbé kókó míì jáde pé, kí ‘ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Jésù gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ Èyí fi hàn pé ká tó lè gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun, ohun kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. A ní láti gba Jésù gbọ́, ká sì ṣègbọràn sí i.

Àmọ́, o lè máa rò ó pé: ‘Kí nìdí tí ìgbọràn fi ṣe pàtàkì? Ṣebí ohun tí Jésù sọ ni pé “ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́” máa ní ìyè àìnípẹ̀kun?’ Ká sòótọ́, ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì, síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ka mọ̀ pé kí èèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù jú ká kàn gbà pé Jésù wà. Ìwé náà, Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ṣàlàyé pé, ọ̀rọ̀ tí Jòhánù lò nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn túmọ̀ sí “ká gbára lé nǹkan pátápátá, kì í ṣe ká kàn gbà pé nǹkan ọ̀hún wà.” Láti rí ojú rere Ọlọ́run ju kí èèyàn kàn gba Jésù ní olùgbàlà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tí Jésù sọ. Tí èèyàn bá jókòó gẹlẹtẹ tó ní òun nígbàgbọ́, ìgbàgbọ́ orí ahọ́n lásán ló ní. Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Ká sọ̀rọ̀ síbi tí ọ̀rọ̀ wà, ẹni náà gbọ́dọ̀ máa lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, ìyẹn ni pé, ó gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé lóòótọ́ ló fọkàn tán Jésù.

Pọ́ọ̀lù tún ṣàlàyé kókó yẹn lọ́nà míì nígbà tó sọ pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan [Jésù] kú fún gbogbo ènìyàn . . . Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Tí a bá moore ìràpadà tí Jésù ṣe fún wa yìí dénú, ìyẹn á mú ká gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Dípò ká máa lo ìgbésí ayé wa bó ṣe wù wá, ó yẹ ká ka ohun tí Jésù kọ́ wa sí pàtàkì, ká sì máa fi ṣe ìwà hù. Èyí sì gbọ́dọ̀ máa hàn nínú àwọn ìpinnu wa àti nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe. Èrè wo ni àwọn tó bá gba Jésù gbọ́ tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ máa rí?

‘KÓ MÁ BAÀ ṢÈGBÉ, ṢÙGBỌ́N KÍ Ó LÈ NÍ ÌYÈ ÀÌNÍPẸ̀KUN’

Apá tó gbẹ̀yìn nínú Jòhánù 3:16 sọ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run ní ìgbésí ayé wọn. Ọlọ́run kò fẹ́ kí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “ṣègbé, ṣùgbọ́n kí [wọ́n] lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Lọ́jọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ ìbùkún ló máa wà fún àwọn tí yóò jàǹfààní nínú ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn.

Lára àwọn ìbùkún yìí ni ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run, èyí tí Jésù ṣèlérí fún àwọn kan. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé òun máa pèsè ibì kan sílẹ̀ fún wọn kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú òun nínú ògo òun. (Jòhánù 14:2, 3; Fílípì 3:20, 21) Àwọn tó bá jíǹde sí ọ̀run máa “jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.”—Ìṣípayá 20:6.

Ìwọ̀nba ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó máa ní àǹfààní yìí. Kódà, Jésù sọ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) Báwo ni àwọn “agbo kékeré” yìí ṣe máa pọ̀ tó? Ìṣípayá 14:1, 4 sọ pé: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù tó ti jíǹde] dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. . . . Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Tá a bá fi iye yìí wé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tó ti gbé láyé, àá rí i pé “agbo kékeré” ni wọ́n lóòótọ́. Àmọ́, Bíbélì pe àwọn wọ̀nyí ní ọba, àwọn wo wá ni wọ́n fẹ́ jọba lé lórí?

Jésù tún sọ nípa àwùjọ àwọn olóòótọ́ míì tó máa gbádùn lábẹ́ ìjọba tó máa ṣàkóso láti ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jòhánù 10:16, Jésù sọ pé: “Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí; àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, wọn yóò sì fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” Àwọn “àgùntàn” yìí ń fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àǹfààní kan náà tí Ádámù àti Éfà pàdánù. Báwo la ṣe mọ̀ pé  orí ilẹ̀ ayé níbí ni wọ́n ti máa gbádùn ìrètí ọjọ́ ọ̀la yìí?

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí ayé yìí ṣe máa di Párádísè. Kí ohun tá a ń sọ yìí lè dá ẹ lójú, jọ̀wọ́, ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí nínú Bíbélì rẹ: Sáàmù 37:9-11; 46:8, 9; 72:7, 8, 16; Aísáyà 35:5, 6; 65:21-23; Mátíù 5:5; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:4. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ìgbà tí ogun, ìyàn, àìsàn àti ikú kò ní sí mọ́. Ó tún sọ nípa ìgbà tí àwọn èèyàn rere máa láyọ̀ láti kọ́ ilé tiwọn fúnra wọn, tí wọ́n á gbin irè oko sínú ilẹ̀ wọn, wọ́n á sì tún tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ní àgbègbè tí àlàáfíà wà. * Ṣé ó wù ẹ́ láti gbé nínú irú ayé báyìí? Má mikàn, torí ó dájú pé àwọn ìlérí yìí máa tó ṣẹ.

ỌLỌ́RUN TI ṢE OHUN TÓ PỌ̀ FÚN WA

Ṣebí ẹni bá mọ inú rò, á mọ ọpẹ́ dá, tí ìwọ náà bá fara balẹ̀ ka àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ àti fún gbogbo èèyàn pátá, wàá rí i pé ilẹ̀ á kún. Ọlọ́run dá wa sí, ó fún wa ní làákàyè àti ìlera dé ìwọ̀n àyè kan, ó sì ń pèsè àwọn nǹkan tí a nílò ká lè wà láàyè. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Ọlọ́run tún fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn ni ìràpadà tí Jésù ṣe nígbà tó kú fún wa. Ẹ ò rí i pé, àwọn ohun tó wà nínú ìwé Jòhánù 3:16 ti jẹ́ ká mọ̀ pé ìràpadà yìí máa jẹ́ ká gbádùn ìbùkún tó pọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Ohun tó dájú ni pé ayọ̀ wa á kún, àá sì gbádùn ìgbésí ayé wa níbi tó tura, tí àlàáfíà wà, tí kò sí àìsàn, ogun, ìyàn àti ikú. Tó o bá fẹ́ gbádùn àwọn ìbùkún yìí, ọwọ́ rẹ ló kù sí. Paríparí rẹ̀, ó yẹ kí oníkálukú bi ara rẹ̀ pé, kí ni èmi náà ń ṣe fún Ọlọ́run?

^ ìpínrọ̀ 24 Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.