Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni ìgbésí ayé àwọn ẹrú ṣe rí ní ìlú Róòmù?

Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin ti àwọn ará Róòmù

Àwọn ẹrú pọ̀ gan-an ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù àtijọ́ torí pé tí àwọn ọmọ ogun Róòmù bá ti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn, ńṣe ni wọ́n máa ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rú tàbí kí wọ́n jí àwọn míì gbé. Wọ́n á wá ta àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú yìí síbi tí wọn kò tí ní lè rí àwọn ẹbí, ara àti ọ̀rẹ́ wọn mọ́ láé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹrú ló máa ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó títí ẹ̀mí wọn á fi bọ́ níbi tí wọ́n ti ń wa kùsà. Àmọ́, nǹkan rọrùn díẹ̀ fún àwọn tí wọ́n kó lọ ṣiṣẹ́ lóko àti àwọn tó ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ nínú ilé. Wọ́n máa ń fi tipátipá wọ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin sí ọrùn àwọn ẹrú kan tó bá fẹ́ sá lọ, wọ́n á sì kọ iye owó kan sí ara ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin náà, èyí tí wọ́n máa fún ẹnikẹ́ni tó bá rí ẹrú ọ̀hún tó sì dá a pa dà sí ọ̀dọ̀ olówó rẹ̀. Tó bá wá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ẹrú kan ń wá bó ṣe máa sá lọ àmọ́ tí ọwọ́ máa ń bà á, ńṣe ni wọ́n máa fi irin tó gbóná kọ lẹ́tà F tó dúró fún fugitive, ìyẹn ìsáǹsá, sàmì sí iwájú orí rẹ̀.

Nínú Bíbélì, ìwé Fílémónì sọ nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe dá ẹrú kan tó ń jẹ́ Ónẹ́símù, tó sá kúrò nílé Fílémónì tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ pa dà fún un. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Fílémónì ní àṣẹ láti fi ìyà tó tọ́ jẹ Ónẹ́símù lábẹ́ òfin, Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì pé kó “fi inú rere gba [Ónẹ́símù]” nítorí ìfẹ́ àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín wọn.—Fílémónì 10, 11, 15-18.

Kí nìdí tí aró aláwọ̀ àlùkò fi sọ ìlú Fòníṣíà àtijọ́ di olókìkí?

Láyé àtijọ́, ìlú Fòníṣíà tá a wá mọ̀ sí ilẹ̀ Lẹ́bánónì lónìí, gbajúmọ̀ nítorí aró aláwọ̀ àlùkò ìlú Tírè tí wọ́n máa ń ṣe. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fi ‘aṣọ aláwọ̀ àlùkò’ tí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìlú Tírè ṣe, dárà sínú Tẹ́ńpìlì tó kọ́.—2 Kíróníkà 2:13, 14.

Àwọ̀ àlùkò ti ìlú Tírè ni aró tó ṣeyebíye jù nígbà yẹn lọ́hùn-ún, torí pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n máa ń ṣe láti rẹ aró yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn apẹja máa ń kó oríṣi ìṣáwùrú òkun kan  * tó pọ̀ gan-an jáde látinú òkun. Ìdí ni pé, ìṣáwùrú tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ni wọ́n máa ń lò láti fi rẹ aró tó máa tó pa aṣọ kan ṣoṣo láró. Ohun kejì ni pé, wọ́n á yọ àwọn ìṣáwùrú kúrò nínú ìkarawun kí wọ́n lè lo àwọn omi aró tó bá jáde láti inú rẹ̀. Àwọn aláró á wá po aró yìí mọ́ iyọ̀, wọ́n á sì sá a síta kí oòrùn lè pa á, kí atẹ́gùn sì fẹ́ sí i fún ọjọ́ mẹ́ta. Lẹ́yìn náà, wọ́n á da gbogbo rẹ̀ pa pọ̀ sínú àgbá ọlọ́mọrí tí wọ́n fi ń rẹ aró, wọ́n á wá fí omi òkun sè é lórí ààrò tó rọra ń jò díẹ̀díẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan.

Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni aró àwọn ará Fòníṣíà fi ń tà wàràwàrà torí pé àwọn ará Fòníṣíà mọ iṣẹ́ yìí ṣe dáadáa, wọ́n tún mọ ọrọ̀ ajé ṣe, wọ́n sì ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lábẹ́ àkóso wọn. Díẹ̀ lára àwọn ohun èèlò tí wọ́n fi ń ṣe aró nígbà àtijọ́ ni wọ́n ti ṣàwárí ní ìtòsí Òkun Mẹditaréníà àti títí dé ibí tí ó jìnnà ní apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Cádiz ní orílẹ̀-èdè Sípéènì.

^ ìpínrọ̀ 8 Àwọn ìkarawun wọ̀nyí kò gùn ju ìka ìlábẹ̀ lọ [5-8 cm].