Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ gbogbo ìsìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?
Tó o bá ń gbọ́ ìròyìn déédéé, ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé láwọn ìgbà míì, ńṣe làwọn èèyàn ń fi ẹ̀sìn bojú láti ṣiṣẹ́ ibi. Èyí fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 7:15) Ká sóòótọ́, ìsìn ti ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà.—Ka 1 Jòhánù 5:19.
Síbẹ̀, Ọlọ́run ń kíyè sí àwọn tó ń fi ọkàn rere wá òtítọ́ tó sì ń sapá láti ṣe ohun tó dáa. (Jòhánù 4:23) Ọlọ́run sì ń fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ka 1 Tímótì 2:3-5.
Báwo lo ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
Lónìí, Jèhófà Ọlọ́run ń kó àwọn èèyàn láti onírúurú ìsìn jọ, ó sì ń ṣe èyí nípa kíkọ́ wọn ní òtítọ́ àti kíkọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Míkà 4:2, 3) Torí náà, àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, èyí sì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tó o fi lè dá wọn mọ̀.—Ka Jòhánù 13:35.
Jèhófà Ọlọ́run ń kó onírúurú àwọn èèyàn jọ nípasẹ̀ ìjọsìn tòótọ́.
Gbogbo ohun tí àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ gbà gbọ́ ló wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. (2 Tímótì 3:16) Wọ́n tún máa ń gbé orúkọ Ọlọ́run ga. (Sáàmù 83:18) Wọ́n sì tún máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé. (Dáníẹ́lì 2:44) Wọ́n ń farawé Jésù bí wọ́n ṣe ń hùwà tó dáa sí àwọn aládùúgbò wọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ‘ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn.’ (Mátíù 5:16) Nítorí náà, gbogbo ìgbà ni àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń lọ sọ ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní ilé wọn.—Ka Mátíù 24:14; Ìṣe 5:42; 20:20.