KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Ronú Nípa Rẹ?
“Ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò.” *
Ṣé ó burú tí Dáfídì bá sọ pé kí Ọlọ́run gba tòun rò? Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń ronú nípa rẹ? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà pé Ọlọ́run Olódùmarè rí tàwọn rò rárá. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀?
Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́rùn wà ní ipò tí ó ga fíofío ju tàwa èèyàn lọ. Tá a bá ní ká wo ipò tí Ọlọ́run wà sí tèèyàn lóòótọ́, Bíbélì sọ pé ńṣe ni gbogbo orílẹ̀-èdè “dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí.” (Aísáyà 40:15) Òǹkọ̀wé kan ṣàríwísí pé: “A kàn ń tanra wa lásán ni tá a bá rò pé Ọlọ́run wà níbi kan tó rí tiwa rò.”
Ohun táwọn míì tún rò ni pé ibi tí ìwà àwọn burú dé, àwọn ò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run lè ronú kàn. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jim sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n ní àmúmọ́ra, kí n sì jẹ́ èèyàn àlàáfíà, àmọ́ kì í pẹ́ tí nǹkan kékeré á tún fi múnú bí mi. Ni mo bá kúkú gba kámú pé bóyá ìwà mi ti burú débi pé mi ò lè rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà.”
Ṣé Ọlọ́run wá jìnnà sí wa débi pé kò tiẹ̀ ń kíyè sí wa rárá? Ǹjẹ́ àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀? Láì jẹ́ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, kò sí ẹ̀dá kankan tó lè sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí rèé. Inú wá sì dùn pé nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ó jẹ́ ká lóye pé òun kò jìnnà sí wa àti pé òun máa ń ronú nípa wa. Kódà, Bíbélì sọ pé “ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Nínú àwọn àkòrí mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, a máa gbé ohun tí Ọlọ́run sọ nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò àti bó ṣe fi hàn pé òun bìkítà fún àwọn èèyàn bíi tìrẹ.
^ ìpínrọ̀ 3 Sáàmù 40:17; Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.