TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓSẸ́FÙ
“Itumo Ko Ha Je Ti Olorun?”
JÓSẸ́FÙ ṣì wà lẹ́wọ̀n, ó sì ti pẹ́ níbẹ̀ débi pé kò sí nǹkan tí kò mọ̀ nípa ẹ̀wọ̀n náà. Lọ́sàn-án gangan, inú ẹ̀wọ̀n náà máa ń gbóná riri nítorí oòrùn tó mú níta àti atẹ́gùn tí kò ráyè wọlé dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù máa làágùn yọ̀bọ̀ bó ṣe ń parí iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un tó sì ń pa dà sínú àhámọ́ yẹn. Lóòótọ́, ó ti di ẹni iyì nínú ẹ̀wọ̀n náà, àmọ́ ẹlẹ́wọ̀n ṣì ni.
Ó dájú pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan á máa rántí bí nǹkan ṣe rí fún un nígbà tó máa ń da ẹran bàbá rẹ̀ káàkiri gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn òkè Hébúrónì. Kò ju ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún lọ nígbà náà lọ́hùn-ún tí bàbá rẹ̀ ràn an níṣẹ́ lọ sí ọ̀nà jíjìn, àmọ́ kò sáyè ìyẹn mọ́ báyìí. Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù jowú rẹ̀ débi pé wọ́n fẹ́ pa á kí wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá pinnu láti tà á sóko ẹrú. Ọ̀dọ̀ ìjòyè kan tó ń jẹ́ Pọ́tífárì nílẹ̀ Íjíbítì ló ti kọ́kọ́ ṣẹrú. Pọ́tífárì finú tán Jósẹ́fù, àmọ́ nígbà tí aya Pọ́tífárì fẹ̀sùn kan Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá òun lò, Pọ́tífárì fìbínú gbé Jósẹ́fù sọ sẹ́wọ̀n. Ohun tó sìn ín débi tó dé nìyẹn. *—Jẹ́nẹ́sísì orí 37 àti 39.
Ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni Jósẹ́fù báyìí, èyí sì fi hàn pé ó ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá lóko ẹrú àti nínú ẹ̀wọ̀n. Kò sì jọ pé nǹkan máa rí bó ṣe fẹ́. Ó lè máa bi ara rẹ̀ pé ọjọ́ wo lòun fẹ́ bọ́ nínú gbogbo wàhálà yìí? Ǹjẹ́ òun tún lè rí bàbá òun àti Bẹ́ńjámínì àbúrò òun mọ́? Ìgbà wo lòun máa kúrò nínú ẹ̀wọ̀n yìí?
Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ronú bíi ti Jósẹ́fù rí, torí pé nǹkan lè máà rí bá a ṣe fẹ́. Àwọn ìṣòro kan lè dé bá wa tó máa mú wá lómi. Ó lè ṣòro láti fara dà tàbí kó tiẹ̀ dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Jósẹ́fù náà ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.
“JÈHÓFÀ Ń BÁ A LỌ LÁTI WÀ PẸ̀LÚ JÓSẸ́FÙ”
Jósẹ́fù nígbàgbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run tí òun ń sìn kò ní fi òun sílẹ̀, bó ṣe ń fi irú èrò yìí tu ara rẹ̀ nínú jẹ́ kó lè fara dà á délẹ̀délẹ̀. Jèhófà pàápàá ò sì já a kulẹ̀, ó bù kún Jósẹ́fù nínú ẹ̀wọ̀n tó wà. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá, ó sì ń yọ̀ǹda fún un láti rí ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:21-23) Jósẹ́fù náà jára mọ́ṣẹ́, ìyẹn sì mú kí Jèhófà bù kún rẹ̀. Ìtùnú ńlá ni àwọn ìbùkún yẹn jẹ́ fún Jósẹ́fù, ó sì tún jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀!
Àmọ́, ṣé Jèhófà ò ní yọ Jósẹ́fù kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ni àbí ibẹ̀ ni yóò máa wà lọ gbére? Jósẹ́fù kò mọ̀, síbẹ̀ òun náà kò dákẹ́ àdúrà lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí Ọlọ́run bá máa dá sí nǹkan, wẹ́rẹ́ ni. Ọ̀nà àrà tí ẹnikẹ́ni ò ronú rẹ̀ ni Jèhófà gbà dáhùn àdúrà Jósẹ́fù. Lọ́jọ́ kan, ariwo ta nínú tẹ̀wọ̀n nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì kan dé. Òṣìṣẹ́ ààfin Fáráò láwọn méjèèjì, ọ̀kan jẹ́ olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì, èkejì sì jẹ́ olórí àwọn agbọ́tí.—Jẹ́nẹ́sísì 40:1-3.
Jósẹ́fù ni olórí ẹ̀ṣọ́ fa àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì náà lé * Àmọ́ lóru ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin méjì yìí lá àlá kan to bà wọ́n lẹ́rù tó sì rú wọn lójú gidigidi. Nígbà tílẹ̀ mọ́, Jósẹ́fù kíyè sí pé àwọn ọkùnrin yìí fajú ro, ló bá bi wọ́n pé: “Kí ni ìdí tí ojú yín fi dágùdẹ̀ lónìí?” (Jẹ́nẹ́sísì 40:3-7) Bí Jósẹ́fù ṣe ṣaájò àwọn ọkùnrin yìí mú kí ara tù wọ́n, èyí sì mú kí wọ́n sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn jáde, wọ́n tún rọ́ àlá wọn fún un. Jósẹ́fù ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àlá yìí ló máa pa dà wá yọ òun nínú ìgbèkùn tí òun wà. Ṣùgbọ́n ká ní Jósẹ́fù ò dá sí àwọn ọkùnrin náà, wọn ò ní sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn débi tí wọ́n á tiẹ̀ rọ́ àlá kankan fún un. Ohun tó ṣe yẹ kó mú wa ronú jinlẹ̀, ‘Ǹjẹ́ àwa máa ń ṣaájò àwọn èèyàn bá a bá kíyè sí pé wọ́n ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?’
lọ́wọ́ torí pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n.Àwọn ọkùnrin méjì náà sọ fún un pé àlá táwọn lá ba àwọn lẹ́rù, àwọn ò sì rẹ́ni túmọ̀ àlá náà fún àwọn. Ohun kan ni pé àwọn ará Íjíbítì gbà gbọ́ nínú àlá, wọ́n sì gbára lé àwọn tó lè túmọ̀ àlá gan-an. Àwọn ọkùnrin yìí ò mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run tí Jósẹ́fù ń sìn ló jẹ́ kí àwọn lá àlá náà. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù ti mọ̀. Torí náà, ó wí fún wọn pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run? Ẹ rọ́ [àlá náà] fún mi, ẹ jọ̀wọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Bí Jósẹ́fù ṣe sọ̀rọ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn tó ń fòótọ́ ọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí. Bó ṣe yẹ kí gbogbo àwa tá à ń sin Ọlọ́run jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nìyí, a ò gbọ́dọ̀ máa gbára lé òye ara wa, Ọlọ́run ló yẹ ká gbára lé láti lè mọ ìtúmọ̀ àwọn ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì.—1 Tẹsalóníkà 2:13; Jákọ́bù 4:6.
Olórí agbọ́tí ló kọ́kọ́ rọ́ àlá tiẹ̀ fún Jósẹ́fù. Ó sọ fún Jósẹ́fù pé òun lá àlá nípa àjàrà tí ó ní ẹ̀ka igi mẹ́ta. Nígbà tí àwọn èso àjàrà náà pọ́n, òun fún ọtí èso náà sínú ife, òun sì gbé e fún Fáráò. Bí Jósẹ́fù ṣe gbọ́ àlá yìí tán, Jèhófà fún un ní ìtumọ̀ rẹ̀. Jósẹ́fù sọ fún ọba pé ẹ̀ka igi mẹ́ta náà jẹ́ ọjọ́ mẹ́ta. Ìyẹn ni pé ní ọjọ́ mẹ́ta sí i, Fáráò yóò dá agbọ́tí náà pa dà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé ara tú agbọ́tí náà wá pẹ̀sẹ̀, ó sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́ ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí mi, kí o sì sọ nípa mi fún Fáráò.” Jósẹ́fù ṣàlàyé fún ọkùnrin náà pé wọ́n jí òun gbé kúrò ní ìlú òun ni, wọ́n sì tún sọ òun sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 40:9-15.
Nígbà tí olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì rí i pé ó ti túmọ̀ ohun tí ó dára fún agbọ́tí, òun náà bá rọ́ àlá tiẹ̀ náà fún Jósẹ́fù. Ó lóun rí apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì mẹ́ta lórí òun, àwọn ẹyẹ sì ń ṣá búrẹ́dì náà jẹ lórí òun. Ọlọ́run tún mú kí Jósẹ́fù lóye àlá yìí, kó sì túmọ̀ rẹ̀. Àmọ́ ìròyìn ìbànújẹ́ ni ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ fún olùṣe búrẹ́dì náà. Jósẹ́fù sọ fún ọkùnrin náà pé, èyí ni ìtumọ̀ rẹ̀: Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta náà jẹ́ ọjọ́ mẹ́ta. Ní ọjọ́ mẹ́ta òní, Fáráò yóò bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ọ kọ́ sórí Jẹ́nẹ́sísì 40:16-19) Jósẹ́fù nígboyà, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní lè sọ ìtumọ̀ àwọn àlá náà bí Ọlọ́run ṣe fi rán an. Àwa náà nílò ìgboyà láti sọ ìròyìn rere àti ìròyìn ìparun tó ń bọ̀ wá láìpẹ́.—Aísáyà 61:2.
òpó igi; àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ẹran ara rẹ kúrò lára rẹ. (Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù ṣẹ. Fáráò ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, ìyẹn àṣà kan táwọn èèyàn Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ sí. Lọ́jọ́ yẹn, Fáráò ṣèdájọ́ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjèèjì. Ó dájọ́ ikú fún olórí olùṣe búrẹ́dì gẹ́lẹ́ bí Jósẹ́fù ṣe sọ, ó sì dá olórí agbọ́tí pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀gbẹ́ni aláìmoore yìí gbàgbé Jósẹ́fù.—Jẹ́nẹ́sísì 40:20-23.
“ÈMI KÒ YẸ NÍ KÍKÀ SÍ!”
Ọdún méjì kọjá, Jósẹ́fù kò gbọ́ nǹkan kan. (Jẹ́nẹ́sísì 41:1) Ẹ ò rí i pé ayé á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sú u! Lọ́jọ́ náà lọ́hùn-ún tí Jèhófà lò ó láti túmọ̀ àlá tí agbọ́tí ọba àti olùṣe búrẹ́dì lá, ó lè ti máa rò pé bóyá nǹkan fẹ́ ṣẹnuure fún òun nìyẹn. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́ láràárọ̀ lá á máa fojú sọ́nà pé wọn ò ní pẹ́ dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n láìmọ̀ pé òun kàn dààmú ara òun lásán ni. Ọdún méjì tó tún ṣe lẹ́wọ̀n yẹn á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ èyí tó le jù fún un láti fara dà. Síbẹ̀, kò sọ̀rètí nù, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Dípò kó máa kárísọ, ńṣe ló pinnu láti fara dà á, èyí sì mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i.—Jákọ́bù 1:4.
Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, gbogbo wa la nílò ìfaradà. Ká lè kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń kó ìdààmú báni, a gbọ́dọ̀ mọ́kàn, ká ní sùúrù, ká sì máa tọrọ aláàfíà ọkàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run torí òun nìkan ló lè kó wa yọ. Bó ṣe dúró ti Jósẹ́fù, yóò dúró ti àwa náà ká le borí àwọn ìṣòro náà. Kò sì ní jẹ́ ká sọ̀rètí nù láé!—Róòmù 12:12; 15:13.
Olórí àwọn agbọ́tí náà lè gbàgbé Jósẹ́fù, àmọ́ Jèhófà kò gbàgbé rẹ̀. Lóru ọjọ́ kan, Ọlọ́run mú kí Fáráò lá àlá méjì tó dà á láàmú. Nínú àlá àkọ́kọ́, ó rí màlúù méje tí wọ́n sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti inú Odò Náílì. Ó tún rí màlúù méje míì tí wọ́n rù hangogo. Àwọn màlúù tó rù yìí bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn màlúù méje àkọ́kọ́ tí wọ́n sanra. Kò pẹ́ ni Fáráò bá tún lálàá rí ṣírí ọkà méje tó sanra tó sì dára tí wọ́n jáde láti ara pòròpórò kan. Ó tún rí ṣírí ọkà méje míì tí wọ́n tín-ín-rín, tí ẹ̀fúùfù ti jó gbẹ. Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ṣírí ọkà méje tí wọ́n sanra mì. Nígbà tílẹ̀ fi máa mọ́, ọkàn Fáráò ò balẹ̀ mọ́. Ó ránṣẹ́ pe àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àtàwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì láti túmọ̀ àlá náà, ṣùgbọ́n kò sẹ́nì kankan tó mọ ìtúmọ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 41:1-8) Bóyá àwọn pidánpidán náà ò rí ọ̀rọ̀ sọ tàbí kò jẹ́ pé kátikàti ni gbogbo wọ́n ń sọ, ohun tá ṣáà mọ̀ ni pé wọ́n já Fáráò kulẹ̀, inú sì bí i gan-an. Èyí mú kí Fáráò túbọ̀ tẹra mọ́ wíwá ìtumọ̀ àlá náà.
Níkẹyìn, agbọ́tí rántí Jósẹ́fù! Ó dùn ún pé òun gbàgbé Jósẹ́fù, ó lọ bá Fáráò ó sì sọ fún un nípa Jósẹ́fù. Ojú ẹsẹ̀ ni Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Jósẹ́fù wá nínú ẹ̀wọ̀n.—Jẹ́nẹ́sísì 41:9-13.
Ẹ wo bí inú Jósẹ́fù ṣe máa dùn tó nígbà táwọn ìránṣẹ́ ọba wá mú un jáde lẹ́wọ̀n. Jósẹ́fù pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì fá irun àgbọ̀n àti orí rẹ̀ kodoro torí báwọn ara Íjíbítì ṣe máa ń múra nìyẹn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó dájú pé ó gbàdúrà sí Jèhófà kó lè rí ojú rere lọ́dọ̀ ọba! Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, Jósẹ́fù ti bá ara rẹ̀ nínú ààfin ringindin ńlá kan. Bíbélì sọ pé nígbà tó dé iwájú ọba, “Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé: ‘Mo lá àlá kan, ṣùgbọ́n kò sí olùtumọ̀ rẹ̀. Wàyí o, èmi fúnra mi ti gbọ́ tí a sọ nípa rẹ pé o lè gbọ́ àlá kí o sì túmọ̀ rẹ̀.’” Jósẹ́fù fèsì pé: “Èmi kò yẹ ní kíkà sí! Ọlọ́run yóò kéde àlàáfíà fún Fáráò.” Ìdáhùn yìí fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 41:14-16.
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ tó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi fún Jósẹ́fù ní ìtumọ̀ àlá náà. Ko jẹ́ kójú tì í bíi tàwọn ọlọ́gbọ́n àtàwọn àlùfáà Íjíbítì. Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ àlàyé, ó ní ìtumọ̀ kan náà ni àlá Fáráò méjèèjì ní. Àwọn màlúù tó sanra àtàwọn ṣírí ọkà tó dára dúró fún ọdún méje tí oúnjẹ á fi pọ̀ nílùú, àmọ́ àwọn màlúù tó rù hangogo àtàwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín tí ẹ̀fúùfù ti jó gbẹ dúró fún ọdún méje ìyàn tí yóò dé lẹ́yìn àkókò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìyàn náà á le débi pé yóò jẹ gbogbo ìlú run. Bí Ọlọ́run ṣe fi àlá yìí han Fáráò lẹ́ẹ̀mejì túmọ̀ sí pé “nǹkan náà fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” ó sì dájú pé á ṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 41:25-32.
Ọkàn Fáráò wá balẹ̀ torí ìtumọ̀ tí Jósẹ́fù ṣe yé e Jẹ́nẹ́sísì 41:33-36) Jósẹ́fù ní ìrírí, ó sì kúnjú ìwọ̀n, síbẹ̀ kò dámọ̀ràn ara rẹ̀ láti ṣe kòkáárí iṣẹ́ yìí. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní kò jẹ́ kó fi wàdùwàdù wá ipò fún ara rẹ̀, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run ò jẹ́ kó tiẹ̀ ka ara rẹ̀ yẹ tàbí dámọ̀ràn ara rẹ̀. Bí àwa náà bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà lóòótọ́, à ò ní máa wá ipò tàbí ká máa dámọ̀ràn ara wa fún ipò kan. Ńṣe la máa fọ̀rọ̀ wa sọ́wọ́ Ọlọ́run, torí òun ló mọ ohun tó yẹ wá.
dáadáa. Àmọ́ kí ni ṣíṣe báyìí. Jósẹ́fù dábàá ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìyàn má bàa jẹ ilẹ̀ náà run. Ó ní kí Fáráò wá ọkùnrin kan tí ó jẹ́ “olóye, tí ó sì gbọ́n,” kí ó yàn án ṣe alábòójútó lórí ilẹ̀ náà, kí ẹni náà ṣètò láti tọ́jú ọ̀pọ̀ oúnjẹ sílùú lọ́dún méje àkọ́kọ́, kó lè pèsè rẹ̀ fáwọn èèyàn ní ọdún méje ìyàn tí yóò tẹ̀ lé e. (“ǸJẸ́ A LÈ RÍ ỌKÙNRIN MÌÍRÀN TÍ Ó DÀ BÍ ẸNI YÌÍ?”
Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fiyè sí gbogbo ohun tí Jósẹ́fù sọ, wọ́n sì rí i pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ni. Fáráò tún kan sárá sí Ọlọ́run tó ti Jósẹ́fù lẹ́yìn tó fi lè sọ̀rọ̀ ọgbọ́n jáde. Fáráò wá sọ fún gbogbo àwọn tó wà láàfin lọ́jọ́ náà pé: “Ǹjẹ́ a lè rí ọkùnrin mìíràn tí ó dà bí ẹni yìí, tí ẹ̀mí Ọlọ́run wà nínú rẹ̀?” Lẹ́yìn ìyẹn, Fáráò wí fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí, kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ olóye, tí ó sì gbọ́n tó ọ. Ìwọ fúnra rẹ ni yóò ṣolórí ilé mi, gbogbo àwọn ènìyàn mi yóò sì fi gbogbo ara ṣègbọràn sí ọ. Lórí ọ̀ràn ìtẹ́ nìkan ni èmi yóò ti pọ̀ jù ọ́ lọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 41:38-41.
Gbogbo ohun tí Fáráò sọ gẹ́lẹ́ ló ṣe. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti gbé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wọ Jósẹ́fù, Fáráò tún fún Jósẹ́fù ní òrùka àmì àṣẹ rẹ̀ àti ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí a fi wúrà ṣe. Wọ́n wá gbé e gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ọlọ́lá, Fáráò sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ilẹ̀ náà kó lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbá tó dá fún ọba! (Jẹ́nẹ́sísì 41:42-44) Láàárín ọjọ́ kan péré, Ọlọ́run yọ Jósẹ́fù lẹ́wọ̀n ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá láàfin. Ẹlẹ́wọ̀n lásánlàsàn ló wá di igbá kejì ọba yìí! Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ tí Jósẹ́fù ní nínú Ọlọ́run mú èrè wá! Jèhófà rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ti hù sí àyànfẹ́ rẹ̀ yìí. Nígbà tó sì tó àkókò lójú rẹ̀, ó dá sí i, ó sì mú ohun gbogbo tọ́. Àmọ́, ohun tí Jèhófà ṣe gbòòrò ju pé ó san Jósẹ́fù lẹ́san ire, ńṣe ló tún ṣí ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò fi ní pa run lọ́jọ́ iwájú sílẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú máa ṣàlàyé sí i lórí kókó yìí.
Bí ìwọ náà bá wà nínú ipò kan tó ń pọ́n ẹ lójú fún ọ̀pọ̀ ọdún, tó sì dàbí pé kò sọ́nà àbáyọ, má sọ̀rètí nù. Rántí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù. Má gbàgbé pé ó ní inúure, ó nírẹ̀lẹ̀, ó ní ìfaradà, ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Níkẹyìn Jèhófà san án lẹ́san!
^ ìpínrọ̀ 4 Wo àkòrí “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” míì tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1 àti November 1, 2014.
^ ìpínrọ̀ 10 Àwọn Fáráò ayé àtijọ́ máa ń jẹ tó àádọ́rùn [90] oríṣi búrẹ́dì àti kéèkì. Torí náà, èèyàn pàtàkì ni ẹni tí wọ́n bá yàn ṣe olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì. Ẹnì kejì tó jẹ́ olórí àwọn agbọ́tí ló máa ń mójú tó bí wọ́n ṣe ń ṣe wáìnì tàbí bíà tí Fáráò máa ń mu. Wáìnì náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ògidì, kò sì gbọ́dọ̀ ní májèlé nínú. Torí nígbà yẹn, wọ́n máa ń dìtẹ̀ ọba, wọ́n sì lè máa wá ọgbọ́n láti pa á. Ìdí nìyí tí agbọ́tí ọba fi sábà máa ń wà lára àwọn tí ọba fọkàn tán tó sì máa ń bá ọba dámọ̀ràn.