Ohun Tí Bíbélì Sọ
Báwo ni ọjọ́ ọlá àwa èèyàn ṣe máa rí?
Ó dájú pé àwọn èèyàn á ṣì máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Àmọ́, ṣé àwọn fúnra wọn lè ṣe ohun tó máa mú kí gbogbo èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú? Rárá o. Lóde òní, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra ló kún inú ayé. Àmọ́, ohun tó dára gan-an ni Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn.—Ka 2 Pétérù 3:13.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, lọ́jọ́ iwájú gbogbo èèyàn kárí ayé máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. A ó máa gbé nínú ààbò, ẹnì kankan ò sì ní kó ìpayà bá wa.—Ka Míkà 4:3, 4.
Báwo ni ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe máa dópin?
Ọlọ́run ò dá ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́ àwa èèyàn. Àmọ́, nítorí pé ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí mú kó di aláìpé. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ la sì ti jogún ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Jésù sọ aráyé di pípé pa dà.—Ka Róòmù 7:21, 24, 25.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, Jésù kú ikú ìrúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwa èèyàn bọ́ lọ́wọ́ ohun tí àìgbọràn ọkùnrin àkọ́kọ́ fà. (Róòmù 5:19) Torí náà, Jésù mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti ní ọjọ́ ọlá àgbàyanu, nígbà tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan kò ní mú káwọn èèyàn máa hùwà burúkú mọ́.—Ka Sáàmù 37:9-11.