Bó O Ṣe Lè Dàgbà Lọ́nà Tó Ń Yẹni
KÍ LÓ máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá wo ara rẹ, tó o sì rí i pé àgbà ti ń dé? Àyà àwọn kan máa ń já, ìrònú máa ń dorí àwọn míì kodò, kódà ìdààmú tó máa ń fà fún ọ̀pọ̀ kì í ṣe kèrémí. Ohun tó sì fà á ni àwọn ìṣòro tó máa ń dé bá àwọn arúgbó. Irú bí ara tó ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, gbígbàgbé nǹkan àti àìsàn tí kò lọ bọ̀rọ̀.
Ká sòótọ́, bí ọjọ́ ogbó ṣe máa ń bá oníkálukú yàtọ̀ síra. Àwọn kan máa ń ní ìlera tó dáa, ara wọn sì máa ń dá ṣáṣá, wọn kì í sábà ní ìṣòro táwọn arúgbó máa ń ní. Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn ti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ojútùú sí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó ń ṣe wọ́n tàbí kí wọ́n lo àwọn oògùn tó lè dẹwọ́ rẹ̀. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn oògùn yìí ti mú kí ẹ̀mí àwọn kan gùn sí i, ìlera wọn sì tún dára sí i.
Bó ti wù kó rí, yálà ẹnì kan ní àwọn ìṣòro táwọn àgbàlagbà máa ń ní tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sẹ́ni tí kò fẹ́ kí ọjọ́ ogbó yẹ òun. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ńṣe ló yẹ kéèyàn ní ẹ̀mí tó dáa, kó sì ṣe tán láti mú ara rẹ̀ bá ipò náà mu. Lórí kókó yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìlànà Bíbélì tó rọrùn, tó sì ṣeé múlò wọ̀nyí yẹ̀ wò.
MỌ̀WỌ̀N ARA RẸ: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí, “amẹ̀tọ́mọ̀wà” ń tọ́ka sí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn, tí wọ́n sì gbà pé ó níbi tí agbára àwọn mọ́ tó bá kan àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Charles ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] ní irú èrò yìí, ó sọ pé: “Kò sí bí èèyàn ṣe máa dàgbà títí, tí kò ní darúgbó. Ohun tí kò ṣe é yẹ̀ sílẹ̀ ni.”
Ti pé èèyàn mẹ̀tọ́ mọ̀wà tàbí mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kò sọ pé kéèyàn máa ro ara rẹ̀ pin, bíi kó máa ronú pé, “Mo ṣáà ti darúgbó, kí ló tún kù fún mi.” Ńṣe ni irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Ìwé Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Ẹni tó bá mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ máa ń ro ohun tó dáa, á sì sapá láti ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ̀ bá gbé.
Corrado, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Ó dàbí ìgbà téèyàn ń wa ọkọ̀ lórí òkè ni, bó o ṣe ń pọ́nkè lọ, ó ní láti fi ọkọ̀ náà sí jíà míì, kí ọkọ̀ náà má bàa bà jẹ́.” Lọ́nà kan náà, bí èèyàn ṣe ń dàgbà sí i ló ṣe yẹ kó máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, kó sì máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. Corrado àti ìyàwó rẹ̀ fọgbọ́n ṣètò ara wọn lọ́nà tí àwọn iṣẹ́ ilé á fi rọ̀ wọ́n lọ́rùn tí kò sì ní rẹ̀ wọ́n tí wọ́n bá máa fi ṣe tán. Marian, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin [81], tó ń gbé ní Brazil mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ bó ṣe ń dàgbà. Ó sọ pé: “Mo ti rí ìdí tí kò fi yẹ kí n ṣe ju ara mi
lọ. Tí mo bá parí iṣẹ́ kan, mo máa ń fún ara mi ní ìsinmi kí n tó bẹ̀rẹ̀ àwọn míì. Nígbà míì mo máa ń kàwé lórí ìjókòó tàbí kí n dùbúlẹ̀ tí mo bá ń gbọ́ orin. Mo gbà pé agbára mi ò lè gbé gbogbo nǹkan tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́.”WÀ NÍWỌ̀NTÚNWỌ̀NSÌ: “Kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” (1 Tímótì 2:9) Ọ̀rọ̀ náà “aṣọ tí ó wà létòletò” ni pé kéèyàn wọ aṣọ tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó sì bójú mu. Barbara, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74] tó ń gbé orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Mo máa ń wọ aṣọ tó mọ́ tónítóní, ìmúra mi sì máa ń gún régé. Mi ò torí pé mo ti dàgbà kí n wá rí ‘wúruwùru,’ mi ò sì ń ṣe iṣé pé ohun tó bá wu ẹlẹ́nu ló lè fẹnu ẹ̀ sọ.” Fern, ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń ra aṣọ tuntun kí ìmúra mi lè bóde mu.” Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ọkùnrin ńkọ́? Antonio, ọmọ ilẹ̀ Brazil tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73] sọ pé: “Mo máa ń múra lọ́nà tó wuyì, mo máa ń lọ aṣọ mi, ó sì máa ń mọ́.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń ṣe ìmọ́tótó ara rẹ̀, ó fi kún-un pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń wẹ̀, tí mo sì máa ń fá irùngbọ̀n mi.”
Tá a bá tún wò ó lọ́nà míì, kò dáa kí ìrísí wa gbà wá lọ́kàn débi tí a ò fi ní lo “ìyèkooro èrò inú.” Bok-im, ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin [69] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Korea máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ìmúra rẹ̀, ó ní: “Mo mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu kí n máa wọ àwọn aṣọ tí mo wọ̀ nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́.”
NÍ ÈRÒ TÓ DÁA: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Bó o ṣe ń dàgbà sí i, wàá máa rántí bó o ṣe máa ń ta kébékébé nígbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́ àti àwọn nǹkan tó o lè ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí o kò lè ṣe mọ́, ó ṣeé ṣe kó o tiẹ̀ máa ní èrò òdì. Má bọkàn jẹ́. Sapá láti fa èrò òdì yìí tu lọ́kàn rẹ. Tó bá jẹ́ àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe nígbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́ lò ń rò ṣáá, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá ẹ, kò sì ní jẹ́ kó o láyọ̀. Èyí kò ní jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan míì tí agbára rẹ gbé báyìí. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó máa ń ní èrò tó dáa ni Joseph ọmọ ilẹ̀ Canada, tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79], ó ní: “Mo máa ń sapá láti ṣe àwọn nǹkan tí agbára mi gbé kí n sì gbádùn rẹ̀, mi ò kì í fi ìrònú ṣe ara mi léṣe lórí àwọn nǹkan tí mi ò lágbára láti ṣe mọ́.”
Bó o bá ń kàwé, tí o sì ń kẹ́kọ̀ọ́, ọpọlọ rẹ á jí pépé, èyí á sì jẹ́ kó o máa ní èrò tó dáa. Bó bá ṣeé ṣe fún ẹ, gbìyànjú láti máa kọ́ àwọn ohun tuntun. Bí àpẹẹrẹ, Ernesto ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines fẹ́ràn láti máa lọ sí ilé ìkówèésí, ó sì máa ń ka àwọn ìwé tó gbádùn mọ̀ ọ́n. Ó sọ pé: “Mo ṣì ń gbádùn bí mo ṣe máa ń kàwé gan-an torí ó máa ń ṣe mi bíi pé àwọn ìwé náà ń jẹ́ kí n rìnrìn àjò kúrò nínú ilé mi lọ sí ọ̀nà jíjìn.” Ẹlòmíì tún ni Lennart, ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] tó ń gbé ní Sweden, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un, ó kọ́ èdè tuntun.
JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.” (Lúùkù 6:38) Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn míì, kó o sì máa fi ìwọ̀nba ohun tó o bá ní ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, inú rẹ á sì máa dùn. Ohun tí Hosa, ọmọ ilẹ̀ Brazil tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85] máa ń ṣe nìyẹn láìka àìlera tó ń bá a fínra sí, ó ní: “Mo máa ń fóònù àwọn ọ̀rẹ́ mi tó bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tó ń ṣàìsàn, mo tún máa ń kọ lẹ́tà sí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí wọn. Mo tún máa ń se oúnjẹ tàbí ìpápánu fún wọn.”
Ẹlòmíì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jan, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Sweden sọ pé: “Tó o bá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ.” Àwọn èèyàn máa ń mọrírì ẹni tó lawọ́. Torí ẹni tó bá lawọ́ máa ń kóni mọ́ra, ó tún máa ń mọyì àwọn ẹlòmíì. Irú ẹ̀mí yìí kì í jẹ́ kí nǹkan wọ́n ọ̀làwọ́ èèyàn.
JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ SÚN MỌ́: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá wà láyè ara rẹ, àmọ́ má ṣe máa ya ara rẹ sọ́tọ̀. Innocent, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin [72] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà fẹ́ràn kó máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń gbádùn bí mo ṣe máa ń bá tọmọdé tàgbà ṣọ̀rẹ́. Ọmọ ilẹ̀ Sweden tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85] tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Börje, sọ pé: “Mo máa ń bá àwọn ọ̀dọ́ ṣọ̀rẹ́ tórí bí wọ́n ṣe máa ń ta pọ́ún-pọ́ún yẹn máa ń mú kí n máa ròó pé èmi náà ṣì lókun, pàápàá bí mo ṣe wà nítòsí wọn.” Lo ìdánúṣe láti máa pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ wá sílé rẹ lóòrèkóòrè. Ọmọ ilẹ̀ South Korea kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Han-sik, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin [72] sọ ní tiẹ̀ pé: “Èmi àti ìyàwó mi máa ń pe àwọn ọ̀rẹ́ wa wá sí àpèjẹ tàbí ká pè wọ́n kí wọ́n wá jẹun alẹ́ nílé wa, àtàgbà àtọmọdé la sì máa ń pè.”
Ẹní tí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn máa ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ń fetí sílẹ̀ bí àwọn míì bá ń sọ̀rọ̀. Jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi, kó o sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ ọ́ lọ́kàn. Helena, ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin [71] tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Mozambique sọ pé: “Ara mi máa ń yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn, mo sì máa ń fi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n. Mo máa ń fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ kí n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn àti ohun tí wọ́n fẹ́.” José, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73] tó ń gbé ní Brazil, sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wà lọ́dọ̀ ẹni tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ohun tí wọ́n bá fẹ́ sọ, tí ọ̀rọ̀ wọn máa jẹ ẹ́ lọ́kàn, tó máa ń gbóríyìn fún wọn bó ṣe yẹ, tó sì máa ń dá wọn lára yá.”
Tó o bá ń sọ èrò inú rẹ fún àwọn èèyàn, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ máa dùn bí “iyọ̀.” (Kólósè 4:6) Máa gba ti àwọn ẹlòmíì rò, kó o sì máa fún wọn níṣìírí.
MÁA DÚPẸ́ OORE: Ẹ “fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Máa dúpẹ́ oore táwọn èèyàn bá ṣe fún ẹ, torí ẹni bá dúpẹ́ oore àná, á rí òmíràn gbà. Tó o bá mọyì oore tí wọ́n ṣe fún ẹ, wàá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Marie-Paule tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ sí ilé tuntun ni. Púpọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ wa ló sì wá ràn wá lọ́wọ́. A mọrírì ohun tí wọ́n ṣe fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. A wá ṣe káàdì ìdúpẹ́, a sì fi ránṣẹ́ sí wọ́n. A tún pe díẹ̀ lára wọn láti wá jẹun nílé wa.” Ẹlòmíì tún ni Jae-won, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] tó ń gbé ní South Korea. Ó mọrírì bí àwọn ará ṣe máa ń fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé e lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sọ pé: “Mo mọrírì ìrànwọ́ tí wọ́n máa ń ṣe fún mi gan-an débi pé mo máa ń fún wọn lówó kí wọ́n lè fi ra epo sọ́kọ̀. Mo tiẹ̀ máa ń fi ẹ̀bùn tàbí káàdì ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sí wọn pàápàá.”
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa dúpẹ́ pé o wà láàyè. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.” (Oníwàásù 9:4) Nítorí náà, béèyàn bá ní ẹ̀mí tó dáa, tó sì ṣe tán láti mú ara rẹ̀ bá ipò náà mu, ìyẹn á jẹ́ kéèyàn dàgbà lọ́nà tó ń yẹni.