Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni wọ́n ṣe ń lo ọlọ ọlọ́wọ́ láyé àtijọ́?
Ọlọ ọlọ́wọ́ ni wọ́n fí ń lọ ọkà di ìyẹ̀fun tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì. Ojoojúmọ́ ni àwọn obìnrin ilé tàbí àwọn ìránṣẹ́ máa ń lo ọlọ yìí. Kò sí ọjọ́ kan kí wọ́n má gbọ́ ìró ọlọ láyé ìgbà yẹn.—Ẹ́kísódù 11:5; Jeremáyà 25:10.
Àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n rí nílẹ̀ Íjíbítì jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe ń lò ó. Wọ́n á da ohun tí wọ́n bá fẹ́ lọ sórí òkúta pẹrẹsẹ tí wọ́n gbẹ́, tí wọ́n máa ń pè ní ìyá ọlọ. Ẹni tó fẹ́ lọ nǹkan á wá kúnlẹ̀ ti ọlọ yìí nílẹ̀, á sì fi ọwọ́ méjèèjì mú òkúta tí wọ́n ń pè ní ọmọ ọlọ. Á rin ọmọ ọlọ náà mọ́lẹ̀, á wá máa tì í lọ síwá-sẹ́yìn láti fi lọ nǹkan tó fẹ́ lọ̀. Ìwádìí kan jẹ́ ká mọ̀ pé irú ọmọ ọlọ yìí máa ń wúwo tó nǹkan bíi kílógírámù méjì sí mẹ́rin. Tí wọ́n bá sọ ọ́ lu èèyàn, ẹni náà lè kú.—Àwọn Onídàájọ́ 9:50-54.
Lílọ ọkà ṣe pàtàkì fún ìdílé kọ̀ọ̀kan tí wọn kò bá fé jẹ́ kí ebi pa wọ́n. Ìdí nìyẹn tí òfin kan nínú Bíbélì fi sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ọlọ ẹlòmíì pamọ́ kó ba lè san gbèsè tó jẹ. Ìwé Diutarónómì 24:6 sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má fi ipá gba ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò, nítorí pé ọkàn ni ó ń fi ipá gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.”
Kí ló túmọ̀ sí láti wà ní “ipò oókan àyà?”
Bíbélì sọ pé Jésù wà ní “ipò oókan àyà lọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 1:
Nígbà ayé Jésù, àwọn Júù máa ń jókòó sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú tí wọ́n gbé yí tábìlì oúnjẹ ká. Wọ́n máa kọrí sí tábìlì, wọ́n á sì ná ẹsẹ̀ wọn, wọ́n á wá gbé ìgúnpá wọn òsì sórí tìmùtìmù kan. Èyí máa jẹ́ kẹ́ni náà lè lo ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Ìwádìí kan fi hàn pé, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ òsì ni àwọn tó fẹ́ jẹun máa ń fi ti tìmùtìmù, “orí ẹnì kan máa sún mọ́ àyà ẹnì kejì tó wà lẹ́yìn rẹ̀, nítorí náà, wọ́n máa ń sọ pé ‘ó sinmi lé oókan àyà’ ẹnì kejì.”
Àǹfààní ńlá ni àwọn èèyàn kà á sí bí ẹnì kan bá jókòó sí oókan àyà olórí ìdílé tàbí ti ẹni tó gbà wọ́n ní àlejò. Torí náà nígbà Ìrékọjá tí Jésù ṣe kẹ́yìn, “ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù ti máa ń nífẹ̀ẹ́,” ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù, ló wà ní oókan àyà Jésù. Jòhánù lè tipa bẹ́ẹ̀ ‘tẹ̀ sẹ́yìn lé igẹ̀ Jésù’ láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.