ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Fi Àánú Hàn Sí Mi Ju Bí Mo Ṣe Rò Lọ
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], gbogbo ohun tó gbà mí lọ́kàn kò ju bí máa ṣe bẹ́gbẹ́ pé. Mo gbádùn kí n máa bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣeré, ká máa lúwẹ̀ẹ́, ká sì jọ máa gbá bọ́ọ̀lù. Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ìgbésí ayé mi yí pa dà pátápátá. Mo fi alùpùpù mi jáàmù, mo sì ṣèṣe gan-an débi pé apá àti ẹsẹ̀ mí rọ. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún tọ́rọ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀, àtìgbà náà sì ni mi ò ti lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì mọ́.
Ìlú Alicante, ní etíkun ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Sípéènì ni mo dàgbà sí. Ilé wa kò tòrò rárá, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n pẹ́ níta. Ṣọ́ọ̀bù fọganáísà kan wà nítòsí ilé wa. Ibẹ̀ lèmi àti José María tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ti mọra, tá a sì di ọ̀rẹ́. Àwọn mọ̀lẹ́bí mi kò ráyè tèmi rárá, àmọ́ ara José yá mọ́ọ̀yàn, ó sì máa ń wáyè gbọ́ tẹ̀mí. Nígbà tí mo bá ní ìṣòro, ńṣe ló máa ń dúró tì mí bíi pé òun ni ẹ̀gbọ́n mi. Ọ̀rẹ́ wa wọ̀ dáadáa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ogún [20] ọdún jù mí lọ.
José María ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo sì rí i pé ó fẹ́ràn Ìwé Mímọ́, torí ó máa ń sọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún mi. Mo máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n mi ò fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀rọ̀ náà sí. Ìdí ni pé, àwọn nǹkan míì ló gba èmi lọ́kàn. Àmọ́, ṣàdédé ni nǹkan yí pa dà.
JÀǸBÁ TÓ YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ
Mi ò kì í fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí mi yẹn. Ohun tí mo kàn lè sọ ni pé, ìwà òmùgọ̀ ni mo hù. Ọjọ́ kan ni ìgbésí ayé mi yí pa dà pátápátá. Èmi tí mo máa ń fò sókè sódò tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó bára ẹ̀ nílé ìwòsàn, tí mi ò lè gbápá tí mi ò lè gbẹ́sẹ̀. Ó ṣòro fún mi láti gbà pé mi ò ní lè rìn mọ́. Mo wá ń bi ara mi pé: ‘Kí ni mo tún ń dúró ṣe láyé?’
José María wá wò mí, ó sì ṣètò pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìjọ àdúgbò máa bẹ̀ mí wò nílé ìwòsàn. Bí wọ́n ṣe ń wá lemọ́lemọ́ yẹn wú mi lórí. Gbàrà tí mo sì kúrò ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n fi Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí àwa èèyàn fi ń jìyà tá a sì ń kú àti ìdí tí Ọlọ́run fi ń fàyè gba àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú àti bí ayé ṣe máa di Párádísè, tí ẹnikẹ́ni kò ni sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.” (Aísáyà 33:24) Ó jọ mí lójú gan-an láti mọ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.
Mi ò dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi dúró lẹ́yìn tí mo kúrò nílé ìwòsàn. Nígbà tó yá, wọ́n dìídì ṣe àga arọ kan fún mi, èyí sì mú kí n lè máa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó tún jẹ́ kí n lè lọ wàásù. Ní November 5, 1988, mo ṣe ìrìbọmi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ kan. Ọmọ ogún [20] ọdún ni mí nígbà yẹn. Inú mi sì dùn pé Jèhófà Ọlọ́run ti kí jẹ́ ìgbésí ayé nítumọ̀ sí mi. Àmọ́, kí ni màá fi san oore yìí?
BÍ MO TILẸ̀ JẸ́ ALÁÀBỌ̀ ARA MI Ò JÓKÒÓ GẸLẸTẸ
Ó wù mí kí n ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìka àìlera mi sí. (1 Tímótì 4:15) Kò kọ́kọ́ rọrùn fún mi torí pé àwọn mọ̀lẹ́bí mi ta kò mí. Àmọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kò fi mí sílẹ̀. Wọ́n máa ń rí i dájú pé mi ò pa ìpàdé jẹ àti pé mo máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé.
Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo rí i pé ó pọn dandan kí n máa gba ìtọ́jú àkànṣe ní gbogbo ìgbà. Lẹ́yìn tí mo ṣèwádìí káàkiri, mo rí ibì kan tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn aláàbọ̀ ara ní ìlú Valencia, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà sí àríwá ìlú Alicante tí mò ń gbé. Ibẹ̀ ni mo wà látìgbà náà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì, síbẹ̀ mi ò fọ̀rọ̀ ìwàásù ṣeré
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì, mo pinnu láti máa sin Jèhófà nìṣó. Mo wá fi owó àjẹmọ́nú tí ìjọba ń fún àwa aláàbọ̀ ara ra fóònù àti kọ̀ǹpútà kan, wọ́n sì bá mi gbé e sí ẹ̀gbẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi. Láràárọ̀, ẹnì tó ń tọ́jú mi máa ń bá mi tan kọ̀ǹpútà àti fóònù náà. Ẹ̀rọ kan tí wọ́n dè mọ́ àgbọ̀n mi ni mo fi ń tẹ kọ̀ǹpútà náà. Ọ̀pá kan tún wà tí mo máa ń fi sẹ́nu, òun ni mo máa ń fi tẹ fóònù. Ọ̀pá yìí máa ń jẹ́ kí n lè tẹ ọ̀rọ̀ lórí kọ̀ǹpútà mi àti lórí fóònù.
Àwọn ẹ̀rọ yìí wúlò fún mi gan-an. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ti jẹ́ kí n lè máa lọ sórí ìkànnì jw.org, mo sì tún lè lọ wo ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower. Mo sábà máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lójoojúmọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí n sì ṣe ìwádìí nínú àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, kí n lè túbọ̀ mọ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. Nígbà tí nǹkan bá tojú sú mi, mo máa ń rí ohun kan lórí ìkànnì náà tó máa ń gbé mi ró.
Kọ̀ǹpútà mi tún máa ń jẹ́ kí n lè gbọ́ ohun tó ń lọ nípàdé kí n sì kópa nínú rẹ̀. Mo máa ń dáhùn, mo máa ń gbàdúrà, mo máa ń sọ àsọyé, mo tiẹ̀ tún máa ń ka Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n bá yàn fún mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi kì í sí láàárín àwọn ará ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lásìkò ìpàdé, síbẹ̀ ó máa ń ṣe mí bíi pé mo wà pẹ̀lú wọn.
Fóònù àti kọ̀ǹpútà mi tún jẹ́ kí n lè máa wàásù. Òótọ́ ni pé mi ò lè máa lọ láti ilé dé ilé bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù. Àmọ́ mi ò jẹ́ kí ìyẹn kó ìrònú bá mi. Fóònù àti kọ̀ǹpútà ni irinṣẹ́ ìwàásù tèmi. Mo ti wá mọwọ́ béèyàn ṣe ń fi fóònù wàásù débi pé àwọn alàgbà ìjọ mi ní kí n ṣètò bí àwọn ará ṣe máa fi fóònù wàásù. Àwọn ará ìjọ tí àìlera kò jẹ́ kí wọ́n lè jáde nílé ti jàǹfààní nínú ìṣètò yìí, torí ó jẹ́ kí wọ́n lè kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Àmọ́, kì í ṣe àwọn ẹ̀rọ yìí nìkan ló ń jẹ́ kí n gbádùn ìgbésí ayé. Ojoojúmọ́ làwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń wá kí mi. Wọ́n máa ń mú àwọn mọ̀lẹ́bí
àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sọ́dọ̀ mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fẹ́ kí n bá wọn sọ̀rọ̀. Láwọn ìgbà míì, àwọn ìdílé máa ń wá ṣe ìjọsìn ìdílé wọn lọ́dọ̀ mi kí n lè kópa nínú rẹ̀. Inú mi máa ń dùn tí àwọn ọmọdé bá jókòó tì mí, tí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ràn Jèhófà fún mi.Mo mọrírì bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń wá kí mi. Àwọn ọ̀rẹ́ mi tó ń gbé lọ́nà jíjìn àtàwọn tó ń gbé nítòsí kì í wọ́n lọ́dọ̀ mi. Ìfẹ́ tí wọ́n ń fi hàn sí mi yìí máa ń ya àwọn tó ń tọ́jú mi lẹ́nu. Ojoojúmọ́ ni mò sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n wà lára ẹgbẹ́ ará tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.
MÒ Ń BÁ A YÍ
Bí ẹnì kan bá kí mi tó sì béèrè pé ‘báwo ni o?’ Mo sábà máa ń sọ pé, “Mo wà ń bẹ̀ o, mò ń bá a yí!” Àwọn ará ò dá mi dá ìṣòro náà. Òótọ́ kan ni pé gbogbo Kristẹni ló ń “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́,” láìka ipò yòówù kí wọ́n wà sí. (1 Tímótì 6:12) Kí ló jẹ́ kí n lè fara da ipò mi? Mo máa ń gbàdúrà lójoojúmọ́, mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀. Mo tún tẹra mọ́ ìwọ̀nba tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, mó sì ń fọkàn sí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.
Mo sábà máa ń ronú nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí, tí màá tún lè fẹsẹ̀ ara mi rìn? Nígbà míì, mo máa ń bá José María ọ̀rẹ́ mi tí òun náà ni àrùn polio dápàárá pé a jọ máa sáré nínú ayé tuntun. Màá wá bíi pé, ta ló máa gbapò kìíní? José máa ń sọ pé, “ẹni tó máa gbapò kìíní kọ́ ló jà jù. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká dénú Párádísè, ká lè jọ sáré náà.”
Kí n sòótọ́, ọ̀rọ̀ àìlera mi yìí kò bára dé rárá. Mo mọ̀ pé mo hùwà òmùgọ̀ nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo ṣì ń jìyà ẹ̀ báyìí. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé Jèhófà ò pa mí tì. Ó ti fún mi ní ohun tó pọ̀, lára ẹ̀ ni àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Mo tún ń láyọ̀ bí mo ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́, mo sì ní ìrètí láti gbé nínú ayé tuntun. Àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í jẹ́ kí n máa ro ara mi pin mọ́. Tí mo bá ní kí n sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára mi ní gbólóhùn kan, ohun tí màá sọ ni pé Jèhófà fi àánú hàn sí mi ju bí mo ṣe rò lọ.