Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Wàásù?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Wàásù?

Ohun tí àwọn èèyàn fi ń dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ yàtọ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù wa. A máa ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí àti níbikíbi tá a bá ti pàdé àwọn èèyàn. Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù ká lè fi ògo fún Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀. (Hébérù 13:15) A tún ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù Kristi pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”Mátíù 28:19, 20.

Yàtọ̀ síyẹn, a tún nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mátíù 22:39) A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní ẹ̀sìn tiwọn àti pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́, ó dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ Bíbélì ló máa jẹ́ ká rí ìgbàlà. Ìdí nìyẹn tí a fi ń bá a lọ “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi,” bíi tàwọn Kristẹni ìgbà ìjímìjí.Ìṣe 5:41, 42.

Ọ̀gbẹ́ni Antonio Cova Maduro, sọ nípa “ìsapá àti akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń lo gbogbo okun wọn . . . , kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dé ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìwé ìròyìn El Universal, lórílẹ̀-èdè Venezuela

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka àwọn ìwé wa kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ní ẹ̀sìn tiwọn. Síbẹ̀, wọ́n mọyì bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wá sọ́dọ̀ wọn.

Òótọ́ ni pé o lè ní àwọn ìbéèrè míì nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà nípa ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

  • Lọ sórí ìkànnì wa, www.pr418.com/yo.

  • Lọ sí àwọn ìpàdé wa. Gbogbo èèyàn ló lè wá, a kì í sì gbégbá owó.