KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN ẸLẸ́ṢIN MẸ́RIN INÚ BÍBÉLÌ ṢE KÀN Ọ́
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
Ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí lè dà bí àdììtú tàbí nǹkan tó ń dẹ́rù bani, àmọ́ kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí Bíbélì sọ àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí jẹ́ ká mọ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹlẹ́ṣin náà dúró fún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjálù làwọn ẹlẹ́ṣin náà mú wá sórí ayé, síbẹ̀ ó lè jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún ìwọ àti ìdílé rẹ. Lọ́nà wo? Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kàn àwọn ẹlẹ́ṣin náà dúró fún.
ẸNI TÓ GUN ẸṢIN FUNFUN
Bí ìran náà ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyìí: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”
Ta ló gun ẹṣin funfun yìí? Inú ìwé Ìṣípayá náà la ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Lọ́wọ́ ìparí ìwé náà, ó pe ẹni tó ń gun ẹṣin náà lọ́run ní “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run..” (Ìṣípayá 19:11-13) Jésù Kristi ni Bíbélì máa ń pè ní Ọ̀rọ̀ náà, torí pé òun ni agbẹnusọ fún Ọlọ́run. (Jòhánù 1:1, 14) Láfikún sí i, Bíbélì tún pè é ní “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,” ó sì tún jẹ́ “Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́.” (Ìṣípayá 19:11, 16) Ó ṣe kedere pé, Jésù Kristi ní àṣẹ láti jẹ́ ọba ajagunṣẹgún, kì í sì í lo agbára rẹ̀ nílòkulò. Síbẹ̀, ó yẹ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè kan.
Ta ló fún Jésù láṣẹ láti jẹ́ ajagunṣẹ́gun? (Ìṣípayá 6:2) Nínú ìran kan tí wòlíì Dáníẹ́lì rí, wọ́n fi Mèsáyà wé “ọmọ ènìyàn.” Jèhófà Ọlọ́run * tó jẹ́ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” náà sì fún un ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Torí náà, Ọlọ́run Olódùmarè ló fún Jésù ní agbára àti àṣẹ láti ṣàkósò, kó sì ṣe ìdájọ́. Ẹṣin funfun náà ṣàpẹẹrẹ ogun tó tọ́ tí Ọmọ Ọlọ́run jà, torí pé nínú Ìwé Mímọ́ àwọ̀ funfun sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó jẹ́ òdodo.
Ìgbà wo làwọn ẹlẹ́ṣin náà bẹ̀rẹ̀ sí i gun ẹṣin wọn? Wàá kíyè sí i pé ìgbà tí Jésù tó jẹ́ ẹlẹ́ṣin àkọ́kọ́ gba adé ló bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin náà. (Ìṣípayá 6:2) Ìgbà wo ni Ọlọ́run fi Jésù jẹ ọba lọ́run? Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó pa dà sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde. Bíbélì sọ pé ó dúró fún àkókò díẹ̀ kó tó di ọba. (Hébérù 10:12, 13) Jésù sọ àmì táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á fi mọ ìgbà tí àkókò dídúró òun máa dópin, tí ìjọba rẹ̀ sì máa bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run. Ó sọ pé níbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso òun, nǹkan máa yí pa dà sí búburú nínú ayé. Ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀-àrùn máa gbòde kan. (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:10, 11) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914, ló ti hàn gbangba pé a ti wọ àkókò wàhálà tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
Àmọ́ kí nìdí tí nǹkan fi ń burú sí i látìgbà tí Jésù ti gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914, dípò kó máa dáa sí i? Ìdí ni pé ọ̀run ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, kì í ṣe ayé. Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run, Jésù tó jẹ́ Ọba tuntun náà, tí Bíbélì tún pè ní Máíkẹ́lì, sì lé Sátánù àtàwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù rẹ̀ sáyé. (Ìṣípayá 12:7-9, 12) Inú wá ń bí Sátánì burúkú-burúkú torí pé kò lè pa dà sọ́run mọ́, ó sì tún mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun. Kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run fi máa pa Sátánì run, tí ìfẹ́ rẹ̀ á sì ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:10) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́ta yòókù ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé àkókò wàhálà tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé. Àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́ta yìí ò dà bí ẹlẹ́ṣin àkọ́kọ́ tó ṣàpẹẹrẹ ẹnì kan pàtó, kàkà bẹ́ẹ̀ bí ipò nǹkan ṣe máa rí jákèjádò ayé ni wọ́n ṣàpẹẹrẹ.
ẸNI TÓ GUN ẸṢIN ALÁWỌ̀ INÁ
“Òmíràn sì jáde wá, ẹṣin aláwọ̀ iná; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a sì yọ̀ǹda fún láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè máa fikú pa ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì; a sì fún un ní idà ńlá kan.”
Ẹni tó gun ẹṣin yìí ṣàpẹẹrẹ ogun. Wàá rí i pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ló ti mú àlááfíà kúrò, bí kò ṣe ní gbogbo ayé. Ogun kan jà kárí ayé lọ́dún 1914, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tirú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Ogun àgbáyé kejì jà tẹ̀ lé e, ó sì gbóná ju tàkọ́kọ́ lọ. Àwọn kan fojú bù ú pé àwọn èèyàn tó ti bá ogun àti rògbòdìyàn lọ láti ọdún 1914 ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] mílíọ̀nù! Láfikún sí i, àwọn tó fara pa yánna-yànnà kò lóǹkà.
Báwo lọ̀rọ̀ ogun jíjà ṣe lágbára tó lásìkò yìí? Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn aráyé, àwọn èèyàn ti ṣe ohun ìjà tó lè gbẹ̀mí gbogbo èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Ọ̀pọ̀ àjọ ni wọ́n ti dá sílẹ̀ kí àlàáfíà lè jọba, irú bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, síbẹ̀ wọn ò lè dá ẹni tó gun ẹṣin aláwọ̀ iná yìí dúró.
ẸNI TÓ GUN ẸṢIN DÚDÚ
“Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Mo sì gbọ́ tí ohùn kan bí ẹni pé ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé: ‘Ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà fún owó dínárì kan, àti ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.’”
Ẹni tó gun ẹṣin yìí ṣàpẹẹrẹ ìyàn. Ìràn yìí ṣàpẹẹrẹ àìtó oúnjẹ tó lékenkà débi pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní owó dínárì kan, tó jẹ́ owó iṣẹ́ ọjọ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kó tó lè ra ìlàrin (kìlógíráàmù 0.7) òṣùwọ̀n àlìkámà! (Mátíù 20:2) Iye kan náà ni wọ́n máa fi ra ìlàrin (kìlógíráàmù 2.1) òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì, tí kò níye lórí tó àlìkámà. Ṣé ìyẹn máa yó bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ? Ẹlẹ́ṣin náà wá kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe fi oúnjẹ ṣòfò, ó dìídì dárúkọ òróró ólífì àti wáìnì tó jẹ́ òunjẹ pàtàkì lákòókò yẹn.
Látọdún 1914 ni ẹlẹ́ṣin dúdú yìí ti ń gun ẹṣin rẹ̀ lọ láìdúró. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láàárín ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn, nǹkan bí àádọ́rin [70] mílíọ̀nù èèyàn ni ebi pa kú. Nínú ìròyìn kan, wọ́n fojú bù ú pé: “Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé márùn-ún [805] mílíọ̀nù èèyàn, ìyẹn ìdá kan nínú mẹ́sàn-án èèyàn tó wà láyé ni kò roúńjẹ re jẹ kánú lọ́dún 2012 sí 2014.” Ìwádìí míì fi hàn pé: “Tá a bá ṣírò iye èèyàn tí àrùn AIDS, àrùn ibà àti ikọ́ ẹ̀gbẹ ń pa, wọn ò tó iye tí ebi nìkan ń pa kú lọ́dọọdún.” Pẹ̀lú gbogbo ìsapá láti bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ńṣe ni ẹni tó gun ẹṣin dúdú yìí kàn ń gun ẹṣin rẹ̀ lọ yàà.
ẸNI TÓ GUN ẸṢIN RÀNDÁNRÀNDÁN
“Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin ràndánràndán kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní orúkọ náà Ikú. Hédíìsì sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní ọlá àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé, láti máa fi idà gígùn pani àti àìtó oúnjẹ àti ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani àti àwọn ẹranko ẹhànnà ilẹ̀ ayé.”
Ẹni tó gun ẹṣin kẹrin yìí ń fa àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn jàǹbá míì tó ń ṣekú pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1914, àrùn gágá pa ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn. Ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mílíọ̀nù èèyàn tó kó àrùn yìí, ìyẹn nǹkan bí èèyàn kan nínú mẹ́ta àwọn tó ń gbáyé nígbà yẹn!
Àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni èyí jẹ́. Àwọn ọ̀jọ́gbọ́n fojú bù ú pé àwọn tí àrùn ìgbóná pa láàárín ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn jẹ́ ìlọ́po-ìlọ́po àwọn tí àrùn gágá pa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an, síbẹ̀ àwọn àrùn bíi AIDS, ikọ́ ẹ̀gbẹ àti àìsàn ibà ṣì ń dá ẹ̀mí ẹgbàágbèje èèyàn légbodò.
Àbájáde kan náà ni ogun, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn máa ń ní, ikú ló máa ń gbẹ̀yìn gbogbo rẹ̀. Ńṣe ni isà òkú kàn ń gbé àwọn èèyàn mì káló ṣáá láìsinmi.
ÌGBÀ Ọ̀TUN TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÉ!
Láìpẹ́ àkókò wàhálà yìí á dópin. Má gbàgbé pé: Ọdún 1914 ni Jésù “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun,” tó sì lé Sátánì wá sáyé, àmọ́ Jésù kò parí ìṣẹ́gun rẹ̀ nígbà yẹn. (Ìṣípayá 6:2; 12:9, 12) Kò ní pẹ́ mọ́ tí ogun Amágẹ́dónì á fi bẹ́ sílẹ̀, nígbà ogun yẹn Jésù máa fọ́ gbogbo iṣẹ́ Sátánì túútúú, á sì mú gbogbo àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ kúrò. (Ìṣípayá 20:1-3) Jésù máa dá àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́ta yòókù dúró, á sì ṣàtúnṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n ti bà jẹ́. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ.
Àlááfíà máa jọba dípò ogun. Jèhófà máa “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́.” (Sáàmù 46:9) Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àlááfíà “yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà dípò ìyàn. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”
Dípò àjàkálẹ̀ àrùn àti ikú, gbogbo èèyàn á ní ìlera tó dáa, wọ́n á sì wà láàyè títí láé. Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára ohun tó máa gbéṣe nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Ó ṣe ohun tó jẹ́ kí àlááfíà jọba, ó bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó tiẹ̀ tún jí àwọn tó kú díde.
Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti fi ohun tó o máa ṣe hàn ẹ́ látinú Bíbélì rẹ, kó o lè múra sílẹ̀ de ìgbà tí wàhálà tí àwọn ẹlẹ́ṣin yìí dá sílẹ̀ máa dópin. Ṣé ó wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i lọ́dọ̀ wa?
^ ìpínrọ̀ 7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.