Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ìwà Àìṣòótọ́

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ìwà Àìṣòótọ́

Orí Kejìdínlógún

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ìwà Àìṣòótọ́

Aísáyà 22:1-25

1. Báwo ló ṣe lè rí láyé àtijọ́, tí èèyàn bá wà nínú ìlú ńlá kan tí wọ́n sàga tì?

FOJÚ inú wo bó ṣe máa ń rí láyé àtijọ́ tí èèyàn bá wà nínú ìlú tí wọ́n sàga tì. Ọ̀tá rèé lẹ́yìn odi ìlú, alágbára àti aláìláàánú èèyàn sì ni. O mọ̀ pé àwọn ìlú yòókù ti bọ́ sí i lọ́wọ́. Ó sì ti wá pinnu láti ṣẹ́gun ìlú yín báyìí, láti kó gbogbo ìlú yín lẹ́rù lọ, láti fipá bá àwọn èèyàn ibẹ̀ lò pọ̀ kó sì pa wọ́n. Àwọn ọmọ ogun ọ̀tá yìí sì wá lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tẹ́ ò fi lè gbógun kò wọ́n lójú; áà, kí odi ìlú yáa dí wọn mọ́ ọ̀hún ni o. Bóo ṣe wo ẹ̀yìn odi, o rí àwọn ilé gogoro tí àwọn ọ̀tá gbé wá láti fi sàga ti odi ìlú. Wọ́n tún ní àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò nígbà ìsàgatì, èyí tó lè máa sọ àwọn òkúta ràbàtà ràbàtà láti fi fọ́ àwọn ohun tẹ́ẹ fi ń dáàbò bo ara yín. O rí àwọn òpó gbìǹgbì tí wọ́n fi ń fọ́ odi àti àwọn àtẹ̀gùn fún gígun odi, o rí àwọn tafàtafà àti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, o sì rí ẹgbàágbèje àwọn ọmọ ogun wọn. Nǹkan yìí mà kó jìnnìjìnnì bá ni o!

2. Ìgbà wo ni ìsàgatì tí Aísáyà orí kejìlélógún ṣàpèjúwe ṣẹlẹ̀?

2 Nínú Aísáyà orí kejìlélógún, a kà nípa irú ìsàgatì bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni, ìgbà ìsàgatì Jerúsálẹ́mù. Nígbà wo nìyẹn wáyé? Ó ṣòro láti tọ́ka sí ìsàgatì kan pàtó, tí gbogbo àpèjúwe yẹn bá mu. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn, ohun tó ti dára jù ni pé ká lóye rẹ̀ sí pé ó jẹ́ àpapọ̀ àpèjúwe onírúurú ìsàgatì tó máa bá Jerúsálẹ́mù, pé ó jẹ́ àpapọ̀ ìkìlọ̀ nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

3. Kí làwọn ará Jerúsálẹ́mù ń ṣe nípa ìsàgatì tí Aísáyà ṣàpèjúwe?

3 Nígbà tí ìsàgatì tí Aísáyà ṣàpèjúwe ń lọ lọ́wọ́, kí làwọn ará Jerúsálẹ́mù ń ṣe? Bí wọ́n ṣe jẹ́ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, ṣé wọ́n wá ń ké pe Jèhófà pé kó gba àwọn ni? Rárá o, ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu rárá ni wọ́n ń hù, ìwà tó jọ irú èyí táwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run lónìí ń hù.

Ìlú Tí Wọ́n Sàga Tì

4. (a) Kí ni “àfonífojì ìran,” kí ló sì jẹ́ kó gborúkọ yìí? (b) Irú ipò wo làwọn ará Jerúsálẹ́mù wà nípa tẹ̀mí?

4 Nínú Aísáyà orí kọkànlélógún, gbólóhùn tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ìdájọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni “Ọ̀rọ̀ ìkéde.” (Aísáyà 21:1, 11, 13) Orí kejìlélógún bẹ̀rẹ̀ lọ́nà kan náà, pé: “Ọ̀rọ̀ ìkéde nípa àfonífojì ìran: Kí wá ni ó ṣe ọ́, tí o fi gòkè lọ pátápátá sórí àwọn òrùlé?” (Aísáyà 22:1) Jerúsálẹ́mù ni “àfonífojì ìran” ń tọ́ka sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ibi gíga ni ìlú yìí wà, wọ́n ṣì pè é ní àfonífojì nítorí pé àárín àwọn òkè ńláńlá tó ga jù ú lọ ló wà. Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran àti ìṣípayá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ń ti ibẹ̀ wá ló jẹ́ kí wọ́n pè é ní ibi “ìran.” Ìdí tó fi yẹ kí àwọn ará ìlú yìí kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jèhófà nìyẹn. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni wọ́n kẹ̀yìn sí i, wọ́n sì bá òrìṣà lọ. Ọlọ́run wá lo àwọn ọ̀tá tó sàga ti ìlú yìí láti fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ oníwàkiwà.—Diutarónómì 28:45, 49, 50, 52.

5. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí táwọn èèyàn yẹn fi gòkè lọ sórí òrùlé wọn?

5 Ṣàkíyèsí pé àwọn ará Jerúsálẹ́mù “gòkè lọ pátápátá sórí àwọn òrùlé” wọn. Láyé àtijọ́, òrùlé pẹrẹsẹ ni ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ní, gbogbo ìdílé sì sábà máa ń péjọ síbẹ̀. Aísáyà kò sọ ìdí tí wọ́n fi péjọ síbẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé kò fara mọ́ ọn. Nígbà náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n lọ ké pe àwọn òrìṣà wọn lórí òrùlé. Àṣà wọn nìyẹn ní àwọn ọdún tó ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Jeremáyà 19:13; Sefanáyà 1:5.

6. (a) Irú ipò wo ló gbòde kan nínú Jerúsálẹ́mù? (b) Èé ṣe táwọn kan fi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà, ṣùgbọ́n kí ní ń bẹ níwájú?

6 Aísáyà ń bọ́rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Ìwọ kún fún yánpọnyánrin, ìlú ńlá aláriwo líle, ìlú tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà. Àwọn ènìyàn rẹ tí a pa kì í ṣe àwọn tí a fi idà pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe àwọn tí ó kú nínú ìjà ogun.” (Aísáyà 22:2) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ti rọ́ kún ìlú yẹn, yánpọnyánrin sì wà ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń pariwo nígboro, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n. Àmọ́ o, àwọn kan ń yọ̀, bóyá wọ́n wò ó pé ààbò wà fáwọn, tàbí kí wọ́n gbà gbọ́ pé ewu yẹn ti ń lọ. * Ṣùgbọ́n, ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ fẹ́nikẹ́ni tó bá ń yọ̀ lásìkò yẹn. Ikú oró tí yóò pa ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìlú yẹn yóò burú ju tàwọn tí wọ́n fi idà pa. Oúnjẹ ò lè wọ ìlú tí wọ́n bá sàga tì rárá. Oúnjẹ tí wọ́n kó jọ sínú ìlú sì ń tán lọ. Àìróúnjẹ jẹ àti kíkún tí ìlú kún férò máa ń yọrí sí àjàkálẹ̀ àrùn. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní Jerúsálẹ́mù yóò ṣe tipa ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn kú nìyẹn. Èyí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa àti lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.—2 Àwọn Ọba 25:3; Ìdárò 4:9, 10. *

7. Kí làwọn alákòóso Jerúsálẹ́mù ṣe nígbà ìsàgatì yẹn, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí wọn?

7 Nínú hílàhílo yìí, kí làwọn alákòóso Jerúsálẹ́mù ń ṣe gẹ́gẹ́ bí aṣáájú? Aísáyà dáhùn pé: “Gbogbo àwọn apàṣẹwàá rẹ pàápàá ti sá lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Láìnílò ọrun, a ti mú wọn ní ẹlẹ́wọ̀n. Gbogbo àwọn tí a rí nínú rẹ ni a mú ní ẹlẹ́wọ̀n pa pọ̀. Wọ́n ti fẹsẹ̀ fẹ lọ sí ibi jíjìnnàréré.” (Aísáyà 22:3) Ńṣe làwọn alákòóso àti alágbára ń sá lọ tọ́wọ́ fi tẹ̀ wọ́n! Láìtilẹ̀ sí pé wọ́n yọ ọfà tì wọ́n, ṣìnkún ni wọ́n mú wọn, tí wọ́n sì kó wọn lọ lóǹdè. Ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa lèyí ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ya odi Jerúsálẹ́mù, ṣe ni Sedekáyà Ọba kó àwọn alágbára rẹ̀ lẹ́yìn, tó fẹsẹ̀ fẹ lóru. Bí àwọn ọ̀tá ṣe gbọ́, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì lé wọn bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò. Làwọn alágbára bá fọ́n ká. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rá Sedekáyà mú, wọ́n fọ́ ọ lójú, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, wọ́n sì fà á gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sí Bábílónì. (2 Àwọn Ọba 25:2-7) Ẹ wo àgbákò tí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ yọrí sí fún un!

Ìdààmú Ọkàn Nítorí Àjálù

8. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà Aísáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìjábá tí yóò bá Jerúsálẹ́mù? (b) Báwo ni nǹkan yóò ṣe rí nínú Jerúsálẹ́mù?

8 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ba Aísáyà lọ́kàn jẹ́ gan-an ni. Ó ní: “Yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi. Dájúdájú, èmi yóò fi ìkorò hàn nínú ẹkún sísun. Ẹ má tẹpẹlẹ mọ́ títù mí nínú nítorí fífi tí a fi ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi ṣe ìjẹ.” (Aísáyà 22:4) Ìbànújẹ́ bá Aísáyà nítorí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò dé bá Móábù àti Bábílónì. (Aísáyà 16:11; 21:3) Wàyí o, ìdààmú ọkàn àti ìdárò rẹ̀ wá pọ̀ jọjọ bó ṣe ń ronú lórí ìjábá tí yóò bá àwọn èèyàn tirẹ̀. Kò gbìpẹ̀. Èé ṣe? “Nítorí pé ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀ àti ìfẹsẹ̀tẹ̀mọ́lẹ̀ àti mímú ẹnu wọhò ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ti ṣètò ní àfonífojì ìran. Olùwó ògiri palẹ̀ ń bẹ, àti igbe sí òkè ńlá.” (Aísáyà 22:5) Ìdàrúdàpọ̀ tó ga ni yóò gba Jerúsálẹ́mù kan. Ńṣe làwọn èèyàn yóò máa sá kìjokìjo kiri, láìní ibi pàtó tí wọ́n forí lé. Bí àwọn ọ̀tá bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ya odi ìlú wọlé, làwọn èèyàn ó máa ké “igbe sí òkè ńlá.” Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn ará ìlú yẹn yóò máa wá ké pe Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ mímọ́ lórí Òkè Mòráyà ni? Bóyá bẹ́ẹ̀ ni yóò rí. Àmọ́ ṣá, lójú bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìṣòótọ́, ó jọ pé ìtumọ̀ rẹ̀ kò ju pé ńṣe ni ìró igbe tí wọ́n ń ké nítorí ìbẹ̀rù yóò máa dún lọ réré lórí àwọn òkè ńláńlá tó wà láyìíká ibẹ̀.

9. Ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó wá gbógun ti Jerúsálẹ́mù.

9 Irú ọ̀tá wo ló gbógun ti Jerúsálẹ́mù? Aísáyà sọ fún wa pé: “Élámù alára sì ti gbé apó, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ti ará ayé, tí ó ní àwọn ẹṣin ogun; Kírì alára sì ti ṣí apata sílẹ̀.” (Aísáyà 22:6) Ńṣe lọ̀tá wọn dìhámọ́ra gádígádí. Wọ́n ní àwọn tafàtafà tí apó wọn kún fún ọfà. Àwọn jagunjagun ń ṣètò apata wọn sílẹ̀ fún ìjà. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn ẹṣin tí wọ́n ti kọ́ lógun jíjà ń bẹ. Àwọn ọmọ ogun láti Élámù, tó wà ní àríwá ibi táa ń pè ní Persian Gulf báyìí, àti láti Kírì, bóyá nítòsí Élámù, wà lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun yẹn. Orúkọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dá wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ ọ̀nà jíjìn táwọn agbóguntini yẹn ti wá. Ó tún fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tafàtafà láti Élámù wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó wá gbógun ti Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Hesekáyà.

Wọ́n Gbìyànjú Láti Gba Ara Wọn Sílẹ̀

10. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló fi hàn pé ìlú yẹn fẹ́ wọ gàù?

10 Aísáyà ṣàpèjúwe bọ́ràn ṣe ń lọ, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ààyò jù lọ nínú àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ rẹ yóò kún fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun, àwọn ẹṣin ogun gan-an yóò sì to ara wọn sí ẹnubodè láìkùnà, ẹnì kan yóò sì mú àtabojú Júdà kúrò.” (Aísáyà 22:7, 8a) Ńṣe làwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹṣin ogun kún pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù fọ́fọ́, wọ́n dójú lé àwọn ẹnubodè ìlú láti dojú ìjà kọ wọ́n. Kí ni “àtabojú Júdà” tí wọ́n mú kúrò? Ó jọ pé ọ̀kan nínú ẹnubodè ìlú ni, tó jẹ́ pé tó bá bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá pẹ́nrẹ́n, àwọn tó ń jà fáàbò ìlú wọ gàù nìyẹn. * Nígbà tí wọ́n mú àtabojú tí wọ́n fi ń dáàbò bo ara wọn yìí kúrò, ńṣe lọ̀nà wá là fáwọn ọ̀tá láti wọ̀lú.

11, 12. Kí láwọn ará Jerúsálẹ́mù ń ṣe láti fi dáàbò bo ara wọn?

11 Aísáyà wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ ìsapá táwọn èèyàn yẹn ń ṣe láti gba ara wọn sílẹ̀. Èrò tó kọ́kọ́ sọ sí wọn lọ́kàn ni, ohun ìjà! Ó ní: “Ìwọ yóò sì wo ìhà ìhámọ́ra ilé igbó ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú, ẹ ó sì rí, àní àwọn àlàfo Ìlú Ńlá Dáfídì, nítorí pé wọn yóò pọ̀ ní tòótọ́. Ẹ ó sì gbá omi odò adágún ìsàlẹ̀ jọ.” (Aísáyà 22:8b, 9) Inú ìhámọ́ra ilé igbó ni wọ́n ń kó ohun ìjà sí. Sólómọ́nì ló kọ́ ilé ìhámọ́ra yìí. Nítorí pé igi kédárì láti Lẹ́bánónì ni wọ́n fi kọ́ ọ ni wọ́n ṣe ń pè é ní “Ilé Igbó Lẹ́bánónì.” (1 Àwọn Ọba 7:2-5) Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ibi tó ya lulẹ̀ lára odi. Wọ́n pọn omi pa mọ́, nítorí ìyẹn ṣe pàtàkì fáàbò ìlú. Àwọn aráàlú nílò omi tí wọn ò bá ní kú. Láìsí omi, ìlú ò lè dúró. Ṣùgbọ́n, kíyè sí i pé, wọn ò mẹ́nu kan ohunkóhun nípa pé wọ́n yíjú sí Jèhófà fún ìdáǹdè. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára tiwọn ni wọ́n gbójú lé. Kí àwa má ṣe irú àṣìṣe yẹn láé!—Sáàmù 127:1.

12 Kí ni wọ́n lè ṣe nípa àwọn ibi tó ya lulẹ̀ lára odi? Ó ní: “Ẹ ó sì ka ilé Jerúsálẹ́mù ní tòótọ́. Ẹ ó sì bi àwọn ilé wó pẹ̀lú láti lè sọ ògiri di ibi tí kò ṣeé dé.” (Aísáyà 22:10) Wọ́n ń yẹ àwọn ilé wò láti wo èyí tí wọ́n lè wó palẹ̀ láti lọ fi dí àwọn ibi tó ya lulẹ̀ lára odi. Wọ́n ń ṣe gbogbo ìsapá yìí kí odi ìlú má bàa bọ́ sáwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

Aláìnígbàgbọ́ Ni Wọ́n

13. Báwo làwọn èèyàn yẹn ṣe gbìyànjú láti rí i pé omi wà fáwọn, àmọ́, ta ni wọ́n gbàgbé?

13 “Bàsíà agbomidúró yóò sì wà tí ẹ ó ṣe sáàárín ògiri méjì fún omi odò adágún àtijọ́. Dájúdájú, ẹ kì yóò sì wo Olùṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá, ṣe ni ẹ kì yóò rí ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” (Aísáyà 22:11) Sísapá tí wọ́n ń sapá láti pọn omi pa mọ́, tí ẹsẹ yìí àti ẹsẹ kẹsàn-án mẹ́nu kàn, mú wa rántí ohun tí Hesekáyà Ọba ṣe láti dáàbò bo ìlú kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà tó ṣígun wá. (2 Kíróníkà 32:2-5) Àmọ́, àláìnígbàgbọ́ gbáà làwọn èèyàn ìlú tí Aísáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ yìí. Wọn kò dà bí Hesekáyà, nítorí pé bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí ọ̀ràn ààbò ìlú, ọkàn wọn ò tiẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá rárá ni.

14. Pẹ̀lú bí Jèhófà ṣe rán iṣẹ́ ìkìlọ̀ sáwọn èèyàn yẹn, ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu wo ni wọ́n ṣì ń hù?

14 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò sì pè ní ọjọ́ yẹn fún ẹkún àti fún ọ̀fọ̀ àti fún orí pípá àti fún sísán aṣọ àpò ìdọ̀họ. Ṣùgbọ́n, wò ó! ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, pípa màlúù àti pípa àgùntàn, jíjẹ ẹran àti mímu wáìnì, ‘Kí jíjẹ àti mímu ṣẹlẹ̀, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.’” (Aísáyà 22:12, 13) Àwọn ará Jerúsálẹ́mù kò kábàámọ̀ rárá lórí ìṣọ̀tẹ̀ wọn sí Jèhófà. Wọn kò sunkún, wọn ò gé irun wọn, tàbí kí wọ́n wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ láti fi hàn pé àwọn ronú pìwà dà. Ká ní ohun tí wọ́n ń ṣe nìyẹn ni, bóyá Jèhófà ì bá jẹ́ kí àrélù tí ń bọ̀ yẹ̀ lórí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ayé ìjẹkújẹ ni wọ́n ń jẹ kiri. Ìwà kan náà lọ̀pọ̀ àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ lóde òní ń hù. Nítorí pé wọn kò ní ìrètí kankan—ì báà jẹ́ ti àjíǹde nínú òkú tàbí ti ìwàláàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé—ayé jíjẹ ni wọ́n ń lé kiri ṣáá, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Áà, wọ́n mà kúkú ponú o! Ká ní wọ́n lè gbẹ́kẹ̀ wọn lé Jèhófà ni, wọn ì bá ní àgbẹ́kẹ̀lé tí kò lè dòfo!—Sáàmù 4:6-8; Òwe 1:33.

15. (a) Kí ni ẹjọ́ tí Jèhófà dá Jerúsálẹ́mù, ta ló sì mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ? (b) Èé ṣe tí Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò fi jẹ irú ìyà kan náà tí Jerúsálẹ́mù jẹ?

15 Kò sí ààbò kankan fáwọn ará Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sàga tì. Aísáyà sọ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ṣí ara rẹ̀ payá ní etí mi pé: ‘“A kì yóò ṣètùtù ìṣìnà yìí fún yín títí ẹ ó fi kú,” ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.’” (Aísáyà 22:14) Nítorí pé ọkàn àwọn èèyàn yẹn yigbì, a ò ní dárí jì wọ́n. Ikú máa pa wọ́n dandan ni. Ohun tó dájú ni. Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ló sọ ọ́. Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀, ẹ̀ẹ̀mejì ni àjálù dé bá Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì pa á run, kí tàwọn Róòmù tó tún wá pa á run. Bí ìjábá yóò ṣe dé bá Kirisẹ́ńdọ̀mù aláìṣòótọ́ náà nìyẹn, èyí táwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn. (Títù 1:16) Ẹ̀ṣẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù, pa pọ̀ mọ́ tàwọn ẹ̀sìn ayé yòókù tó tẹ àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọ́run lójú, ti “wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run.” Ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn náà ti ré kọjá èyí tó ṣeé ṣètùtù fún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà.—Ìṣípayá 18:5, 8, 21.

Ìríjú Onímọtara Ẹni Nìkan

16, 17. (a) Ta ni Jèhófà ní kí wọ́n kìlọ̀ fún báyìí, kí ló sì fà á? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà nítorí nǹkan kàǹkà-kàǹkà tó ń lépa?

16 Wòlíì yìí wá mẹ́nu kúrò lórí àwùjọ èèyàn aláìṣòótọ́, ó bọ́ sórí ẹnì kan pàtó tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Aísáyà kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, wí: ‘Lọ, wọlé tọ ìríjú yìí lọ, èyíinì ni Ṣébínà, ẹni tí ń ṣe àbójútó ilé, “Kí ni ó jẹ́ tìrẹ níhìn-ín, ta sì ni ó jẹ́ tìrẹ níhìn-ín, tí o fi gbẹ́ ibi ìsìnkú síhìn-ín fún ara rẹ?” Ibi gíga ni ó ń gbẹ́ ibi ìsìnkú rẹ̀ sí; inú àpáta gàǹgà ni ó ń gbẹ́ ibùgbé sí fún ara rẹ̀.’”—Aísáyà 22:15, 16.

17 Ṣébínà jẹ́ ‘ìríjú tó ń ṣe àbójútó ilé,’ bóyá ìyẹn ni, ilé Hesekáyà Ọba. Nítorí náà, ipò ńlá ló wà, ipò ọba nìkan ló ju tirẹ̀ lọ. Ojúṣe rẹ̀ pọ̀ gan-an ni. (1 Kọ́ríńtì 4:2) Síbẹ̀síbẹ̀, ògo tara rẹ̀ ni Ṣébínà ń lépa lásìkò tó yẹ kó gbájú mọ́ ọ̀ràn orílẹ̀-èdè náà lójú méjèèjì. Ibojì tó fakíki, tó rí bíi tàwọn ọba gẹ́lẹ́, ló ní kí wọ́n máa bá òun gbẹ́ sínú àpáta gàǹgà kan. Bí Jèhófà ṣe ṣàkíyèsí èyí, ó mí sí Aísáyà pé kó kìlọ̀ fún ìríjú aláìṣòótọ́ yẹn pé: “Wò ó! Ìfisọ̀kò lílenípá ni Jèhófà yóò fi fi ọ́ sọ̀kò sísàlẹ̀, ìwọ abarapá ọkùnrin, òun yóò sì fi ipá gbá ọ mú. Láìkùnà, òun yóò dì ọ́ le dan-in dan-in, bí bọ́ọ̀lù fún ilẹ̀ gbígbòòrò. Ibẹ̀ ni ìwọ yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ògo rẹ yóò ti jẹ́ àbùkù ilé ọ̀gá rẹ. Ṣe ni èmi yóò tì ọ́ kúrò ní ipò rẹ; ẹnì kan yóò sì ya ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ìdúró ipò àṣẹ rẹ.” (Aísáyà 22:17-19) Nítorí gbígbọ́ tí Ṣébínà ń gbọ́ tara rẹ̀ nìkan, kò tiẹ̀ ní ní ibojì kankan, bó ti wù kó kéré mọ, ní Jerúsálẹ́mù. Dípò bẹ́ẹ̀, bíi bọ́ọ̀lù ni wọ́n ṣe máa jù ú láti lọ kú sí ilẹ̀ òkèèrè. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn tí ọ̀pá àṣẹ ń bẹ lọ́wọ́ wọn nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí wọ́n bá ṣi agbára wọn lò pẹ́nrẹ́n, àṣẹ yẹn á bọ́ lọ́wọ́ wọn, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ lé wọn dà nù.

18. Ta ló máa rọ́pò Ṣébínà, kí sì ni gbígbà tẹ́ni yẹn máa gba aṣọ oyè Ṣébínà, àti kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì túmọ̀ sí?

18 Báwo wá ni wọ́n ṣe máa yọ Ṣébínà kúrò nípò rẹ̀? Jèhófà gbẹnu Aísáyà ṣàlàyé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé, ṣe ni èmi yóò pe ìránṣẹ́ mi, èyíinì ni, Élíákímù ọmọkùnrin Hilikáyà. Èmi yóò sì fi aṣọ oyè rẹ wọ̀ ọ́, èmi yóò sì fi ìgbàjá rẹ gbà á gírígírí, èmi yóò sì fi àgbègbè ìṣàkóso rẹ lé e lọ́wọ́; yóò sì di baba àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti ilé Júdà. Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì lé èjìká rẹ̀, yóò sì ṣí láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò tì, yóò sì tì láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò ṣí.” (Aísáyà 22:20-22) Élíákímù yóò rọ́pò Ṣébínà, wọ́n yóò gba aṣọ oyè Ṣébínà fún un pa pọ̀ mọ́ kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì. Bíbélì lo gbólóhùn náà “kọ́kọ́rọ́” láti fi ṣàpẹẹrẹ àṣẹ, ìjọba, tàbí agbára. (Fi wé Mátíù 16:19.) Láyé àtijọ́, olùdámọ̀ràn ọba, tí kọ́kọ́rọ́ wà níkàáwọ́ rẹ̀, lè di alábòójútó àwọn gbọ̀ngàn ààfin, ó tiẹ̀ lè pinnu ẹni tí wọ́n máa yàn sẹ́nu iṣẹ́ ọba. (Fi wé Ìṣípayá 3:7, 8.) Nípa bẹ́ẹ̀, ipò ìríjú ṣe pàtàkì gan-an, ojúṣe ẹni tó bá sì wà nípò yẹn pọ̀ jọjọ. (Lúùkù 12:48) Ó ṣeé ṣe kí Ṣébínà já fáfá, ṣùgbọ́n nítorí kò jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà yóò fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀.

Èèkàn Méjì Tó Jẹ́ Ìṣàpẹẹrẹ

19, 20. (a) Báwo ni Élíákímù yóò ṣe jẹ́ ìbùkún fáwọn èèyàn rẹ̀? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ṣì ń gbójú lé Ṣébínà?

19 Níkẹyìn, Jèhófà lo èdè àpèjúwe láti ṣàlàyé bí agbára yóò ṣe ti ọwọ́ Ṣébínà bọ́ sọ́wọ́ Élíákímù. Ó sọ pé: “‘Èmi yóò sì gbá a [Élíákímù] wọlé gẹ́gẹ́ bí èèkàn sí ibi wíwà pẹ́ títí, yóò sì dà bí ìtẹ́ ògo fún ilé baba rẹ̀. Wọn yóò sì gbé gbogbo ògo ilé baba rẹ̀ kọ́ sára rẹ̀, àwọn ọmọ ìran àti èéhù, gbogbo ohun èlò irú èyí tí ó kéré, àwọn ohun èlò irú èyí tí ó jẹ́ àwokòtò àti gbogbo ohun èlò tí ó jẹ́ àwọn ìṣà títóbi. Ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘èèkàn [Ṣébínà] tí a gbá wọ ibi wíwà pẹ́ títí ni a óò mú kúrò, a ó sì gbẹ́ ẹ kanlẹ̀, yóò sì ṣubú, ẹrù tí ó wà lára rẹ̀ sì ni a óò ké kúrò, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.’”—Aísáyà 22:23-25.

20 Élíákímù ni èèkàn àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ wọ̀nyí. Ńṣe ni yóò di “ìtẹ́ ògo” fún ilé Hilikáyà, baba rẹ̀. Kò ní ṣe bíi Ṣébínà, ní ti pé kò ní dójú ti ilé baba rẹ̀, kò sì ní borúkọ bàbá rẹ̀ jẹ́. Élíákímù yóò wá di èèkàn wíwà pẹ́ títí fáwọn ohun èlò ilé, ìyẹn àwọn yòókù tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ọba. (2 Tímótì 2:20, 21) Ní ìdàkejì, Ṣébínà ni èèkàn kejì ń tọ́ka sí. Ó lè jọ bíi pé mìmì kan ò lè mì í, àmọ́ yíyọ ni wọ́n máa yọ ọ́. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣì ń gbójú lé e yóò já bọ́.

21. Lóde òní, ta ni wọ́n fi ẹlòmíràn rọ́pò gẹ́gẹ́ bíi ti Ṣébínà, kí ló fà á, ta ló sì rọ́pò rẹ̀?

21 Ó yẹ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà rán wa létí pé kí àwọn tó bá láǹfààní iṣẹ́ ìsìn láàárín àwọn tó bá sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run lò ó láti fi ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn àti láti fi mú ìyìn wá fún Jèhófà. Kí wọ́n má ṣe ṣi ipò wọn lò, nípa fífi í sọ ara wọn dọlọ́rọ̀ tàbí láti fi gba òkìkí. Bí àpẹẹrẹ, ó pẹ́ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ti gbé ara rẹ̀ sípò ẹni tí wọ́n yàn ṣe ìríjú, tí wọ́n ń pe ara wọn ní aṣojú Jésù Kristi lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Ṣébínà ṣe ṣe ohun tó tàbùkù sí baba rẹ̀ nípa wíwá ògo ti ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ṣe ohun tó tàbùkù sí Ẹlẹ́dàá nípa sísọ ara wọn di ọlọ́rọ̀ àti alágbára ńláǹlà. Nípa báyìí, Jèhófà yọ Kirisẹ́ńdọ̀mù kúrò lọ́dún 1918, nígbà tó tákòókò tí ìdájọ́ “bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.” Ó pe ìríjú mìíràn, ìyẹn “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye,” ó sì yàn án ṣe olórí ilé Jésù lórí ilẹ̀ ayé. (1 Pétérù 4:17; Lúùkù 12:42-44) Ẹgbẹ́ yìí lápapọ̀ sì ti fi hàn pé òun tóótun láti gba “kọ́kọ́rọ́” ọba, èyí tó jẹ́ ti ilé Dáfídì, sọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí “èèkàn” tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, olúkúlùkù “ohun èlò,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ní onírúurú ẹrù iṣẹ́ rọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì gbára lé e fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí. Bákan náà làwọn “àgùntàn mìíràn,” tó dà bí ‘àtìpó ní ẹnubodè’ Jerúsálẹ́mù àtijọ́, ṣe gbára lé “èèkàn” yìí, ìyẹn Élíákímù òde òní.—Jòhánù 10:16; Diutarónómì 5:14.

22. (a) Èé ṣe tó fi jẹ́ pé àkókò tó bá a mu wẹ́kú ni wọ́n fi ìríjú mìíràn rọ́pò Ṣébínà? (b) Lóde òní, èé ṣe tó fi jẹ́ pé àkókò tó bá a mu wẹ́kú ni wọ́n yan “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye”?

22 Ìgbà tí Senakéríbù àtàwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Jerúsálẹ́mù ni wọ́n fi Élíákímù rọ́pò Ṣébínà. Lọ́nà kan náà, wọ́n yan “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye,” sẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò òpin, àkókò tí yóò parí nígbà tí Sátánì àti agbo ọmọ ogun rẹ̀ bá dìde ìkọlù ìkẹyìn sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” àti àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Gálátíà 6:16) Ìkọlù yẹn yóò wá yọrí sí ìparun àwọn ọ̀tá òdodo, gẹ́lẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Hesekáyà. Àwọn tó bá sì gbára lé “èèkàn tí a gbá wọ ibi wíwà pẹ́ títí,” ìyẹn ìríjú olóòótọ́, yóò yè bọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe yè bọ́ nígbà tí Ásíríà ṣígun lọ bá Júdà. Ó mà bọ́gbọ́n mu o, pé kéèyàn má rọ̀ mọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù, “èèkàn” tí ó ti di àpatì yẹn!

23. Kí ló padà wá ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà, ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa?

23 Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà? A kò ní àkọsílẹ̀ nípa bí ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ nínú Aísáyà 22:18, ṣe ní ìmúṣẹ. Nígbà tó gbé ara rẹ̀ ga, tí wọ́n sì wá dójú tì í, Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jọ, àmọ́, ó jọ pé ó fi ìbáwí yẹn kọ́gbọ́n. Ní ti ìyẹn, ó yàtọ̀ pátápátá sí Kirisẹ́ńdọ̀mù. Nígbà tí Rábúṣákè ará Ásíríà fi ń sọ pé kí Jerúsálẹ́mù túúbá, Élíákímù tó jẹ́ ìríjú tuntun fún Hesekáyà ló ṣáájú àwọn aṣojú tó lọ pàdé rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Ṣébínà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ọba. Ó dájú pé Ṣébínà ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ọba. (Aísáyà 36:2, 22) Ẹ̀kọ́ tó dára mà rèé o, fáwọn tí wọ́n bá gba ẹrù iṣẹ́ lọ́wọ́ wọn nínú ètò àjọ Ọlọ́run! Dípò kí ọkàn wọn gbọgbẹ́, kí wọ́n sì fárígá, ohun tó ti bọ́gbọ́n mu kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n máa sin Jèhófà nìṣó nínú ipòkípò tó bá fi wọ́n sí. (Hébérù 12:6) Ìyẹn ni wọ́n fi lè yẹra fún àgbákò tí yóò dé bá Kirisẹ́ńdọ̀mù. Wọn yóò sì rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run gbà títí ayé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 6 Lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló bú sáyọ̀ nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tó sàga ti Jerúsálẹ́mù padà sẹ́yìn.

^ ìpínrọ̀ 6 Gẹ́gẹ́ bíi Josephus, òpìtàn ọ̀rúndún kìíní ṣe wí, lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, ìyàn mú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní Jerúsálẹ́mù, táwọn èèyàn fi ń jẹ irú awọ bíi awọ bàtà, koríko, àti èérún koríko. Ìròyìn kan sọ pé ìyá kan sun ọmọ rẹ̀ jẹ.

^ ìpínrọ̀ 10 Ẹ̀wẹ̀, “àtabojú Júdà” lè tọ́ka sí ohun mìíràn tó jẹ́ ààbò ìlú yẹn, irú bí odi agbára tí wọ́n ń kó ohun ìjà sí, tó sì jẹ́ ibùgbé àwọn ọmọ ogun.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 231]

Nígbà tí Sedekáyà fẹsẹ̀ fẹ, ọwọ́ tẹ̀ ẹ́, wọ́n sì fọ́ ojú rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 232, 233]

Nǹkan korò fáwọn Júù tó há sí Jerúsálẹ́mù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]

Hesekáyà sọ Élíákímù di “èèkàn tí a gbá wọ ibi wíwà pẹ́ títí”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 241]

Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ní Kirisẹ́ńdọ̀mù dà bí Ṣébínà, wọ́n ṣe ohun tó tàbùkù sí Ẹlẹ́dàá nípa kíkó ọrọ̀ jọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 242]

Lóde òní, wọ́n ti yan ẹgbẹ́ ìríjú olóòótọ́ kan ṣe alábòójútó ilé Jésù