Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
Orí Keje
Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
1, 2. Kí ni ‘olùfẹ́ ọ̀wọ́n’ gbìn, ṣùgbọ́n báwo nìyẹn ṣe já a kulẹ̀?
“NÍ TI ìlò ọ̀rọ̀ tó gbámúṣé àti fífi òye tó jọjú gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó yéni yékéyéké, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sẹ́lẹgbẹ́ àkàwé yìí.” Ohun tí alálàyé lórí Bíbélì kan sọ nìyẹn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Aísáyà orí karùn-ún. Àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà kọjá wíwulẹ̀ fi ẹwà èdè dárà, àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ló ń fi àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yìí gbé jáde. Bákan náà, ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn tún ń kì wá nílọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra.
2 Àkàwé Aísáyà bẹ̀rẹ̀ báyìí pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n kọrin fún olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, orin kan nípa ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Ọgbà àjàrà kan wà tí olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n ní sí ẹ̀gbẹ́ òkè kékeré eléso. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí walẹ̀ rẹ̀, ó sì kó àwọn òkúta rẹ̀ kúrò, ó sì gbin ààyò àjàrà pupa sínú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé gogoro sí àárín rẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó gbẹ́ ibi ìfúntí wáìnì sínú rẹ̀. Ó sì ń retí pé kí ó so èso àjàrà, ṣùgbọ́n ó so èso àjàrà ìgbẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.”—Aísáyà 5:1, 2; fi wé Máàkù 12:1.
Ìtọ́jú Ọgbà Àjàrà Náà
3, 4. Àbójútó onífẹ̀ẹ́ wo ló fún ọgbà àjàrà rẹ̀?
3 Bóyá ńṣe ni Aísáyà kọ àkàwé yìí lórin sétígbọ̀ọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni o tàbí kò kọ ọ́ lórin, ó dájú pé ó gbàfiyèsí wọn. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló mọ̀ nípa àjàrà gbígbìn,
àpèjúwe Aísáyà sì ṣe kedere, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an ló sọ. Gẹ́lẹ́ bí ìṣe àwọn tí ń gbin àjàrà lóde òní, ọlọ́gbà àjàrà yìí kò gbin kóró èso àjàrà, ńṣe lo lọ́ ègé igi tàbí èèhù láti ara àjàrà mìíràn, “ààyò” tàbí ojúlówó “àjàrà pupa.” Ibi tó yẹ wẹ́kú ló ṣe ọgbà àjàrà rẹ̀ sí, “ẹ̀gbẹ́ òkè kékeré eléso,” níbi tí ọgbà àjàrà yóò ti ṣe dáadáa.4 Iṣẹ́ àṣekára ló máa ń gbà kí ọgbà àjàrà tó lè méso jáde. Aísáyà sọ nípa bí ọlọ́gbà náà ṣe “walẹ̀ rẹ̀, tó sì kó àwọn òkúta rẹ̀ kúrò”—iṣẹ́ líle, tó gbomi mu! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn tó tóbi lára òkúta yẹn ló fi “kọ́ ilé gogoro.” Láyé àtijọ́, irú ilé gogoro bẹ́ẹ̀ làwọn olùṣọ́ máa ń jókòó sí láti ṣọ́ ọ̀gbìn ibẹ̀ nítorí àwọn olè tàbí àwọn ẹranko. * Bákan náà, ó fi òkúta mọ ọgbà ààbò sí ẹsẹ̀ àwọn ipele títẹ́jú tí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà ní. (Aísáyà 5:5) Wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí àgbàrá má bàa gbá ọ̀rá ilẹ̀ náà lọ.
5. Lọ́nà ẹ̀tọ́, kí ni ọlọ́gbà náà ń retí pé kó tinú ọgbà àjàrà òun wá, àmọ́ kí ló rí níbẹ̀?
5 Pẹ̀lú gbogbo bí ọlọ́gbà náà ṣe ṣiṣẹ́ kárakára láti dáàbò bo ọgbà àjàrà rẹ̀ yìí, ó tọ́ pé kó máa retí pé kó so èso. Ìyẹn ló fi gbẹ́ ibi ìfúntí sílẹ̀ dè é. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó rí irè oko tó ń retí? Rárá o, àjàrà ìgbẹ́ ni ọgbà àjàrà rẹ̀ so.
Ọgbà Àjàrà àti Ẹni Tó Ni Í
6, 7. (a) Ta ló ni ọgbà àjàrà náà, kí sì ni ọgbà àjàrà yẹn? (b) Ẹjọ́ wo ni ọlọ́gbà àjàrà náà ní kí wọ́n dá?
6 Ta ló ni ọgbà àjàrà yẹn, kí sì ni ọgbà àjàrà náà? Ọlọ́gbà àjàrà náà jẹ́ ká rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nígbà tóun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wàyí o, ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin ènìyàn Aísáyà 5:3-5.
Júdà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi. Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀? Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé mo ń retí pé kí ó so èso àjàrà, ṣùgbọ́n tí ó so èso àjàrà ìgbẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀? Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí èmi yóò ṣe sí ọgbà àjàrà mi di mímọ̀ fún yín: Ìmúkúrò ọgbà ààbò rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di sísun kanlẹ̀. Ìwólulẹ̀ ògiri òkúta rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀.”—7 Dájúdájú, Jèhófà ló ni ọgbà àjàrà náà, bíi pé ó gbé ọ̀ràn rẹ̀ wá sílé ẹjọ́ ni, pé kí wọ́n ṣèdájọ́ láàárín òun àti ọgbà àjàrà tó gbéṣẹ́ òun wọmi. Kí wá ni ọgbà àjàrà yìí? Ọlọ́gbà yìí ṣàlàyé pé: “Nítorí ọgbà àjàrà Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Aísáyà 5:7a.
ni ilé Ísírẹ́lì, àwọn ọkùnrin Júdà sì ni oko ọ̀gbìn tí òun ní ìfẹ́ni fún.”—8. Kí ni ìjẹ́pàtàkì pípè tí Aísáyà pe Jèhófà ní “ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́”?
8 Aísáyà pe Jèhófà tó ni ọgbà àjàrà náà ní “ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.” (Aísáyà 5:1) Àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Aísáyà àti Ọlọ́run ló fi lè lo ọ̀rọ̀ tó ṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ fún Un. (Fi wé Jóòbù 29:4; Sáàmù 25:14.) Àmọ́, ìfẹ́ tí wòlíì yìí fẹ́ Ọlọ́run kò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ “ọgbà àjàrà” rẹ̀—orílẹ̀-èdè tó “gbìn.”—Fi wé Ẹ́kísódù 15:17; Sáàmù 80:8, 9.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ̀, bí ọgbà àjàrà tó ṣeyebíye?
9 Jèhófà ‘gbin’ orílẹ̀-èdè rẹ̀ sí ilẹ̀ Kénáánì, ó sì fún wọn ní àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀, tó jẹ́ bí ògiri tó dáàbò bò wọ́n, kí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù má bàa kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Sáàmù 147:19, 20; Éfésù 2:14) Síwájú sí i, Jèhófà fún wọn ní àwọn onídàájọ́, àlùfáà, àti wòlíì tí yóò máa kọ́ wọn. (2 Àwọn Ọba 17:13; Málákì 2:7; Ìṣe 13:20) Nígbà tí ogun ń bá Ísírẹ́lì fínra, Jèhófà gbé àwọn olùdáǹdè dìde fún wọn. (Hébérù 11:32, 33) Ìyẹn ni Jèhófà fi béèrè pé: “Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?”
Dídá Ọgbà Àjàrà Ọlọ́run Mọ̀ Lónìí
10. Àkàwé wo ni Jésù sọ tó jẹ mọ́ ọgbà àjàrà?
10 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀rọ̀ inú Aísáyà ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ń ṣe àkàwé àwọn aroko tó jẹ́ apànìyàn, ó ní: “Ọkùnrin kan wà, baálé ilé kan, tí ó gbin ọgbà àjàrà kan, ó ṣe ọgbà yí i ká, ó sì gbẹ́ ibi ìfúntí wáìnì sínú rẹ̀, ó sì gbé ilé gogoro kan nà ró, ó sì gbé e fún àwọn aroko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀.” Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn aroko yẹn dalẹ̀ ọlọ́gbà yẹn, àní wọ́n tilẹ̀ pa á lọ́mọ. Jésù wá jẹ́ kó hàn pé àkàwé yìí kò pin sọ́dọ̀ Ísírẹ́lì ti ara nígbà tó sọ pé: “A ó Mátíù 21:33-41, 43.
gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín [Ísírẹ́lì ti ara], a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.”—11. Ọgbà àjàrà nípa tẹ̀mí wo ló wà ní ọ̀rúndún kìíní, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì?
11 “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn, orílẹ̀-èdè tẹ̀mí ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ni “orílẹ̀-èdè” tuntun yẹn. (Gálátíà 6:16; 1 Pétérù 2:9, 10; Ìṣípayá 7:3, 4) Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyí wé “ẹ̀ka” ara “àjàrà tòótọ́,” ìyẹn, òun fúnra rẹ̀. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, a retí pé kí àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí so èso. (Jòhánù 15:1-5) Wọ́n gbọ́dọ̀ ní irú àwọn ànímọ́ tí Kristi ní, kí wọ́n sì kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14; Gálátíà 5:22, 23) Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí àwọn àpọ́sítélì méjèèjìlá ti kú, ayédèrú ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ara ẹ̀ka “àjàrà tòótọ́” náà—dípò èso rere, àjàrà ìgbẹ́ ni wọ́n ń so kùlà.—Mátíù 13:24-30, 38, 39.
12. Báwo lọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe bẹnu àtẹ́ lu Kirisẹ́ńdọ̀mù, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́?
12 Nítorí náà, ohun tí Aísáyà fi bẹnu àtẹ́ lu Júdà kan Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí pẹ̀lú. Àyẹ̀wò ìtàn rẹ̀—àwọn ogun tó jà, bó ṣe jagun ìsìn, àwọn Ìwádìí Láti Gbógunti Àdámọ̀ tó ṣe—jẹ́ ká rí bí èso rẹ̀ ṣe kan bóbó tó! Àmọ́ ṣá o, dandan ni kí ọgbà àjàrà tòótọ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” alábàákẹ́gbẹ́ wọn, gbọ́rọ̀ sí Aísáyà lẹ́nu. (Ìṣípayá 7:9) Bí wọn yóò bá wu ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà, dandan ni kí wọ́n so èso tí yóò wù ú, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀.
“Àjàrà Ìgbẹ́”
13. Kí ni Jèhófà yóò ṣe sí ọgbà àjàrà rẹ̀ nítorí pé èso rẹ̀ kò dára?
13 Lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára tí Jèhófà ti ṣe nídìí títọ́jú àti ríro ọgbà àjàrà rẹ̀, ó tọ́ bó ṣe retí pé kó di “ọgbà àjàrà wáìnì Aísáyà 27:2) Ṣùgbọ́n, dípò síso èso tó wúlò, “àjàrà ìgbẹ́” ló ń so, ọ̀rọ̀ yìí, ní ṣáńgílítí, túmọ̀ sí “àwọn ohun tó ń rùn” tàbí “èso kíkẹ̀.” (Aísáyà 5:2; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Jeremáyà 2:21) Ìyẹn ni Jèhófà fi sọ pé òun yóò mú “ọgbà ààbò” òun tó yí orílẹ̀-èdè náà ká kúrò. Yóò sọ orílẹ̀-èdè yẹn “di ohun tí a pa run,” a óò pa á tì, ọ̀dá omi yóò sì dá a. (Ka Aísáyà 5:6.) Mósè ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé nǹkan tí yóò bá wọn nìyẹn bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Òfin Ọlọ́run.—Diutarónómì 11:17; 28:63, 64; 29:22, 23.
tí ń yọ ìfóófòó!” (14. Èso wo ni Jèhófà retí pé kí orílẹ̀-èdè rẹ̀ so, ṣùgbọ́n kí ló wá so?
14 Èso tó dára ni Ọlọ́run ń retí látọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè yẹn. Míkà, tó gbé ayé nígbà Aísáyà, sọ pé: “Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” (Míkà 6:8; Sekaráyà 7:9) Àmọ́, etí ikún lorílẹ̀-èdè yẹn kọ sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Jèhófà. “[Ọlọ́run] ń retí láti rí ìdájọ́, ṣùgbọ́n, wò ó! rírú òfin ni ó rí; ó ń retí láti rí òdodo, ṣùgbọ́n, wò ó! igbe ẹkún ni ó rí.” (Aísáyà 5:7b) Mósè sọ tẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè aláìṣòótọ́ yìí yóò so èso àjàrà májèlé “láti inú àjàrà Sódómù.” (Diutarónómì 32:32) Nígbà náà, a jẹ́ pé ìṣekúṣe, títí kan ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, wà lára ìwà tó lòdì sí Òfin Ọlọ́run tí wọ́n ń hù. (Léfítíkù 18:22) Gbólóhùn náà “rírú òfin” tún ṣeé túmọ̀ sí “títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” Ó dájú pé ìwà ìkà yẹn ló fa “igbe ẹkún” tí àwọn tí wọ́n ń fojú wọn gbolẹ̀ ń ké—igbe ẹkún tó ti détí ìgbọ́ Olùgbin àjàrà yẹn.—Fi wé Jóòbù 34:28.
15, 16. Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lè yẹra fún síso irú àwọn èso burúkú tí Ísírẹ́lì so?
15 “Olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo” ni Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 33:5) Ó pàṣẹ fún àwọn Júù pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìdájọ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá. Ìdájọ́ òdodo ni kí o fi ṣe ìdájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ.” (Léfítíkù 19:15) Nítorí náà, a ní láti yàgò fún ojúsàájú pátápátá nínú àjọṣe wa pẹ̀lú ara wa, ká máà jẹ́ kí àwọn nǹkan bí ẹ̀yà, ọjọ́ orí, jíjẹ́ ọlọ́rọ̀, tàbí tálákà nípa lórí ojú tí a fi ń wo àwọn ẹlòmíràn. (Jákọ́bù 2:1-4) Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn tó wà nípò àbójútó ‘má fi ẹ̀mí ìgbèsápákan ṣe ohunkóhun,’ kí wọ́n má ṣe jẹ́ agbẹ́jọ́-ẹnìkan-dá láé.—1 Tímótì 5:21; Òwe 18:13.
16 Ẹ̀wẹ̀, kíá ni Kristẹni, tí ń gbé inú ayé oníwàkiwà, lè bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn ìlànà Ọlọ́run lójú tàbí kó kúkú gbéjà kò ó. Àmọ́, ńṣe ni kí àwọn Kristẹni tòótọ́ “múra tán láti ṣègbọràn” sí àwọn òfin Ọlọ́run. (Jákọ́bù 3:17) Láìka ìṣekúṣe àti ìwà ipá inú “ètò àwọn nǹkan burúkú ìsinsìnyí” sí, wọ́n ní láti ‘ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí àwọn ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.’ (Gálátíà 1:4; Éfésù 5:15) Kí wọ́n yàgò pátápátá fún gbogbo ìgbàkugbà táyé ń gbà lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀, bí èdè-àìyedè bá sì wáyé, kí wọ́n yanjú rẹ̀ láìsí “ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” (Éfésù 4:31) Bí Kristẹni tòótọ́ bá ń fòdodo ṣèwà hù ńṣe ló ń gbé Ọlọ́run ga, á sì mú kó rójú rere rẹ̀.
Ohun Tí Ìwọra Ń Yọrí Sí
17. Ìwà burúkú wo ni Aísáyà bẹnu àtẹ́ lù nínú ègbé kìíní tí ó ké?
17 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni Aísáyà kọ ní ẹsẹ kẹjọ. Fúnra rẹ̀ ló kéde ègbé àkọ́kọ́ nínú ègbé mẹ́fà tó fi bẹnu àtẹ́ lu mélòó kan lára “èso àjàrà ìgbẹ́” tí Júdà so, ó sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń so ilé pọ̀ mọ́ ilé, àti àwọn tí ń fi pápá kún pápá títí kò fi sí àyè mọ́, a sì ti mú kí ẹ máa dá gbé ní àárín ilẹ̀ náà! Ní etí mi, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tilẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì dára, yóò di ohun ìyàlẹ́nu pátápátá, láìsí olùgbé. Nítorí pé, àní sarè mẹ́wàá ọgbà àjàrà yóò mú kìkì òṣùwọ̀n báàfù kan ṣoṣo jáde, àní irúgbìn tí ó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì kan yóò sì mú kìkì òṣùwọ̀n eéfà kan jáde.”—Aísáyà 5:8-10.
18, 19. Báwo ni àwọn tó gbé ayé nígbà Aísáyà ṣe ṣàìka àwọn òfin Jèhófà lórí ohun ìní sí, kí ni yóò sì yọrí sí fún wọn?
18 Ti Jèhófà ni gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ jẹ́ látilẹ̀wá. Gbogbo ìdílé ni Ọlọ́run fún lógún tirẹ̀, wọ́n sì lè fi háyà tàbí kí wọ́n yá tẹlòmíràn lò, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ tà á “fún àkókò títí lọ fáàbàdà.” (Léfítíkù 25:23) Òfin yìí ṣèdíwọ́ fún fífọwọ́ ọlá gbáni lójú, bíi pé kẹ́nì kan ràgà bo gbogbo ilẹ̀. Ó tún gba àwọn ìdílé lọ́wọ́ dídi òtòṣì paraku. Àmọ́, ńṣe làwọn kan ní Júdà ń fi ìwọra rú òfin tí Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀ràn dúkìá. Míkà kọ̀wé pé: “Ojú wọn sì ti wọ pápá, wọ́n sì ti já wọn gbà; àti àwọn ilé pẹ̀lú, wọ́n sì ti gbà wọ́n; wọ́n sì ti lu abarapá ọkùnrin àti agbo ilé rẹ̀ ní jìbìtì, ènìyàn àti ohun ìní àjogúnbá rẹ̀.” (Míkà 2:2) Ṣùgbọ́n Òwe 20:21 kìlọ̀ pé: “Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.”
19 Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò gba gbogbo ohun tí oníwọra wọ̀nyẹn ti fi bìrìbìrì kó jọ. Ilé tí wọ́n já gbà yóò wà “láìsí olùgbé.” Èso táṣẹ́rẹ́ ni ilẹ̀ tójú wọn wọ̀ yóò so. Kò sọ bí ègún yìí ṣe máa ṣẹ àti ìgbà tí yóò ṣẹ. Bóyá apákan rẹ̀, ó kéré tán, tọ́ka sí ohun tó máa bá wọn lọ́jọ́ iwájú, nígbà ìgbèkùn ní Bábílónì.—Aísáyà 27:10.
20. Báwo ni àwọn Kristẹni lónìí ṣe lè yàgò fún ṣíṣàfarawé ìwà ìwọra tí àwọn kan ní Ísírẹ́lì hù?
20 Àwọn Kristẹni tòní ní láti kórìíra ìwà ìwọra tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ní nígbà yẹn lọ́hùn-ún. (Òwe 27:20) Bí níní àwọn ohun àlùmọ́nì bá ti jẹni lógún jù, kò lè pẹ́ tónítọ̀hún yóò fi máa gbọ̀nà àbòsí gbogbo kó ṣáà fi lè rí towó ṣe. Kíá lonítọ̀hún lè tọrùn bọ òwò tó mú bìrìbìrì ṣíṣe lọ́wọ́ tàbí kó máa ṣe gbájú-ẹ̀ kiri. “Ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” (Òwe 28:20) Ó mà ṣe pàtàkì pé kóhun téèyàn ní tẹ́ ẹ lọ́rùn o!—1 Tímótì 6:8.
Ìdẹkùn Fàájì Téèyàn Lè Fura Sí
21. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Aísáyà bẹnu àtẹ́ lù nínú ègbé kejì tí ó ké?
21 Ọpọ́n sún kan ègbé kejì tí Aísáyà ké, ó sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná! Háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì àti fèrè, àti wáìnì sì ní láti wà níbi àsè wọn; ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì ni wọn kò rí.”—Aísáyà 5:11, 12.
22. Ìwà àìníjàánu wo ni wọ́n ń hù ní Ísírẹ́lì, kí ni yóò sì yọrí sí fún orílẹ̀-èdè yẹn?
22 “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà jẹ́, kì í sì í bínú pé àwọn ìránṣẹ́ òun ń ṣe fàájì tó bá ti bójú mu. (1 Tímótì 1:11) Àmọ́, àṣejù gbáà ni tàwọn jayéjayé wọ̀nyí! Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí wọ́n . . . ń mu àmupara sábà máa ń mu àmupara ní òru.” (1 Tẹsalóníkà 5:7) Ṣùgbọ́n ní tàwọn aṣàríyá aláriwo inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń jí kùtù mutí yó bí itùn, àmuṣúlẹ̀ ni wọ́n sì ń mu ún! Wọn a ṣe bíi pé Ọlọ́run kò sí rárá, ìwà ta ni yóò mú mi ni wọ́n sì ń hù. Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé àgbákò ń bẹ níwájú fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. “Àwọn ènìyàn mi yóò ní láti lọ sí ìgbèkùn nítorí àìní ìmọ̀; ògo wọn yóò sì jẹ́ àwọn ènìyàn tí ìyàn ti hàn léèmọ̀, ogunlọ́gọ̀ wọn yóò sì gbẹ hán-ún hán-ún lọ́wọ́ òùngbẹ.” (Aísáyà 5:13) Nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tòótọ́ ṣe wí, àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú—tèwe tàgbà—yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù.—Ka Aísáyà 5:14-17.
23, 24. Ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì wo ni a rọ àwọn Kristẹni láti ní?
Gálátíà 5:21; Byington; 2 Pétérù 2:13) Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé ìwà àwọn Kristẹni kan lóde òní máa ń kù díẹ̀ káàtó tí àpèjẹ bá wáyé. Àìlo ìkóra-ẹni-níjàánu nídìí ọtí mímu mú kí àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí hó gèè, tí wọ́n sì ń pariwo. (Òwe 20:1) Ọtí tilẹ̀ pa àwọn kan títí débi híhùwà ìbàjẹ́, tí àwọn kan sì jẹ́ kí àpèjẹ tiwọn fẹ́rẹ̀ẹ́ di àṣemọ́jú, tó fi ṣèdíwọ́ fún àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni lọ́jọ́ kejì.
23 “Àwọn àríyá aláriwo,” tàbí “àríyá tó ń ṣàn,” jẹ́ ìṣòro pẹ̀lú láàárín àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní. (24 Àmọ́, àwọn Kristẹni tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì a máa hùwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, wọn a kóra wọn níjàánu, wọn a sì ṣe fàájì níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọ́n ń ṣe bí àmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 13:13 ṣe sọ, pé: “Gẹ́gẹ́ bí ní ìgbà ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá.”
Kíkórìíra Ẹ̀ṣẹ̀ àti Fífẹ́ Òtítọ́
25, 26. Èrò burúkú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rò wo ni Aísáyà fi ègbé kẹta àti ìkẹrin táṣìírí rẹ̀?
25 Wàyí o, ẹ gbọ́ ègbé kẹta àti ìkẹrin tí Aísáyà ké, ó sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń fi àwọn ìjàrá àìsọ òtítọ́ fa ìṣìnà, tí wọ́n sì ń fi ohun tí a lè pè ní àwọn okùn kẹ̀kẹ́ fa ẹ̀ṣẹ̀; àwọn tí ń sọ pé: ‘Kí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe kánkán; kí ó wá kíákíá, kí a lè rí i; kí ìmọ̀ràn Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sún mọ́ tòsí, kí ó sì wá, kí a lè mọ̀ ọ́n!’ Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára, àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn, àwọn tí ń fi ohun kíkorò dípò dídùn àti ohun dídùn dípò kíkorò!”—Aísáyà 5:18-20.
26 Èyí mà ṣàpèjúwe àwọn tó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lọ́nà tó ṣe Jeremáyà 6:15; 2 Pétérù 3:3-7.
kedere o! Dan-indan-in ni wọ́n so mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí a ṣe ń so kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tó ń fà á. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù dídé ọjọ́ ìdájọ́ kankan. Wọ́n ń ṣẹ̀fẹ̀ pé: “Kí [iṣẹ́ Ọlọ́run] wá kíákíá!” Èyí tí wọn ì bá fi gbọ́ ti Òfin Ọlọ́run, wọ́n ń lọ́ àwọn nǹkan po, tí wọ́n ń sọ pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.”—Fi wé27. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè yẹra fún irú ìwà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù?
27 Àwọn Kristẹni òde òní ní láti yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́nàkọnà. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò jẹ́ gba ojú ìwòye ayé nípa kíka àgbèrè àti ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ sí ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà. (Éfésù 4:18, 19) Lóòótọ́, Kristẹni kan lè “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tó fi lè yọrí sí dídá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. (Gálátíà 6:1) Àwọn alàgbà inú ìjọ ṣe tán láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ṣubú, tí wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. (Jákọ́bù 5:14, 15) Nípasẹ̀ àdúrà àti ìmọ̀ràn tí wọ́n gbé karí Bíbélì, ìmúbọ̀sípò tẹ̀mí ṣeé ṣe. Àìṣe bẹ́ẹ̀, onítọ̀hún lè tipa bẹ́ẹ̀ di “ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Jòhánù 8:34) Kàkà kí àwọn Kristẹni fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́yà, kí wọ́n sì ṣàìfọkàn sí ọjọ́ ìdájọ́ tí ń bọ̀, wọn a máa sapá láti rí i pé àwọn wà “ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n,” lójú Jèhófà.—2 Pétérù 3:14; Gálátíà 6:7, 8.
28. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Aísáyà bẹnu àtẹ́ lù nínú àwọn ègbé ìkẹyìn tí ó ké, báwo sì ni àwọn Kristẹni òde òní ṣe lè yẹra fún irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀?
28 Ó bá a mu gẹ́ẹ́ bí Aísáyà ṣe fi àwọn ègbé tó kẹ́yìn wọ̀nyí kún un pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n ní ojú ara wọn, tí wọ́n sì jẹ́ olóye àní ní iwájú àwọn fúnra wọn! Ègbé ni fún àwọn tí ó jẹ́ alágbára ńlá nínú mímu wáìnì, àti fún àwọn ènìyàn tí ó ní ìmí fún ṣíṣe àdàlù ọtí tí ń pani, àwọn tí ń pe ẹni burúkú ní olódodo ní tìtorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì gba àní òdodo olódodo kúrò lọ́wọ́ rẹ̀!” (Aísáyà 5:21-23) Ó dájú pé àwọn tó jẹ́ onídàájọ́ ilẹ̀ náà ni ó fi ọ̀rọ̀ yìí bá wí. Àwọn alàgbà ìjọ lónìí a máa yẹra fún ṣíṣe bí ẹní “gbọ́n ní ojú ara wọn.” Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n ń tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn a sì rọ̀ mọ́ ìtọ́ni ètò àjọ tímọ́tímọ́. (Òwe 1:5; 1 Kọ́ríńtì 14:33) Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ni wọ́n ń mu ọtí, wọn kò sì jẹ́ mutí lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ bójú tó ọ̀ràn ìjọ. (Hóséà 4:11) Àwọn alàgbà tilẹ̀ tún ń yẹra fún ṣíṣe ohun téèyàn lè fura sí pé ó jẹ́ ojúsàájú pàápàá. (Jákọ́bù 2:9) Wọ́n mà yàtọ̀ sí àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù gan-an o! Ṣe ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn àlùfáà yìí máa ń gbé àwọn ẹni sàràkí-sàràkí àti ọlọ́rọ̀ inú wọn tó ń dẹ́ṣẹ̀ gẹ̀gẹ̀, èyí sì lòdì pátápátá sí ìkìlọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú Róòmù 1:18, 26, 27; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; àti Éfésù 5:3-5.
29. Àgbákò wo ló ń dúró de Ísírẹ́lì, ọgbà àjàrà Jèhófà, níkẹyìn?
29 Aísáyà mú ìsọfúnni alásọtẹ́lẹ̀ yìí wá sópin nípa ṣíṣàpèjúwe àgbákò tí yóò bá àwọn tó “ti kọ òfin Jèhófà” tí Aísáyà 5:24, 25; Hóséà 9:16; Málákì 4:1) Ó polongo pé: “[Jèhófà] gbé àmì àfiyèsí sókè sí orílẹ̀-èdè ńlá kan tí ó jìnnà réré, ó sì ti súfèé sí i ní ìkángun ilẹ̀ ayé; sì wò ó! pẹ̀lú ìṣekánkán ni yóò wọlé wá pẹ̀lú ìyára.”—Aísáyà 5:26; Diutarónómì 28:49; Jeremáyà 5:15.
wọn kò sì so èso òdodo. (30. Ta ni yóò kó “orílẹ̀-èdè ńlá” jọ ní ìdojú ìjà kọ ènìyàn Jèhófà, kí sì ni yóò jẹ́ àbáyọrí rẹ̀?
30 Láyé àtijọ́, tí wọ́n bá ri òpó mọ́ ibi gíga, ó lè jẹ́ fún “àmì àfiyèsí” tàbí ibi ìkójọpọ̀ fáwọn ènìyàn tàbí ọmọ ogun. (Fi wé Aísáyà 18:3; Jeremáyà 51:27.) Wàyí o, Jèhófà yóò fúnra rẹ̀ kó “orílẹ̀-èdè ńlá,” tí kò dárúkọ yìí jọ, kí wọ́n lè mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. * Yóò ‘súfèé sí i,’ ìyẹn ni pé, yóò pàfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ oníwàkiwà pé wọ́n yẹ láti fi ṣèjẹ. Wòlíì yìí wá ṣàpèjúwe bí ìkọlù àwọn aṣẹ́gun tó dà bíi kìnnìún yìí yóò ṣe yára kánkán tí yóò sì bani lẹ́rù tó, bí wọn yóò ṣe “gbá ẹran ọdẹ mú,” ìyẹn, orílẹ̀-èdè Ọlọ́run, tí “wọn yóò sì gbé e lọ” sí ìgbèkùn “láìséwu.” (Ka Aísáyà 5:27-30a.) Ohun tó yọrí sí fún orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn Jèhófà mà burú o! “Ènìyàn yóò sì tẹjú mọ́ ilẹ̀ náà ní ti tòótọ́, sì wò ó! òkùnkùn tí ń kó wàhálà báni ni ó wà; ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti ṣókùnkùn nítorí àwọn ohun tí ń kán sí i lórí.”—Aísáyà 5:30b.
31. Báwo ni Kristẹni tòótọ́ ṣe lè yẹra fún irú ìyà tó jẹ Ísírẹ́lì, ọgbà àjàrà Jèhófà?
31 Bẹ́ẹ̀ ni, ọgbà àjàrà tí Ọlọ́run fi ìfẹ́ tó ga gidigidi gbìn ti yàgàn—ìparun nìkan ló tọ́ sí i. Ẹ̀kọ́ ńláǹlà mà ni ọ̀rọ̀ Aísáyà jẹ́ fáwọn tó bá ń sin Jèhófà lónìí o! Ǹjẹ́ kó jẹ́ kìkì èso òdodo ni wọ́n ń sapá láti so ní gbogbo ìgbà, fún ìyìn Jèhófà àti ìgbàlà tàwọn fúnra wọn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 4 Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan bí àtíbàbà tàbí ahéré, tí kì í pẹ́, tó sì rọrùn láti kọ́, ló wọ́pọ̀ ju ilé gogoro olókùúta lọ. (Aísáyà 1:8) Wíwà tí ilé gogoro wà níbẹ̀ fi hàn pé ọlọ́gbà àjàrà náà sa ipá àrà ọ̀tọ̀ lórí “ọgbà àjàrà” rẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 30 Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn, Aísáyà tọ́ka sí Bábílónì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí yóò mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lé Júdà lórí.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 83]
Dan-indan-in ni ẹlẹ́ṣẹ̀ ń so mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí a ṣe ń so kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tó ń fà á
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 85]