Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

Orí Kẹtàlá

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

Aísáyà 11:1–12:6

1. Ṣàpèjúwe ipò tí àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú wà nípa tẹ̀mí nígbà ayé Aísáyà.

NÍGBÀ ayé Aísáyà, ipò táwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú wà nípa tẹ̀mí burú. Kódà lábẹ́ àkóso àwọn ọba olóòótọ́, bíi Ùsáyà àti Jótámù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yẹn lọ ń jọ́sìn ní àwọn ibi gíga. (2 Àwọn Ọba 15:1-4, 34, 35; 2 Kíróníkà 26:1, 4) Nígbà tí Hesekáyà jọba, ńṣe ló ní láti mú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Báálì kúrò ní ilẹ̀ náà. (2 Kíróníkà 31:1) Abájọ tí Jèhófà fi rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun, tó sì kìlọ̀ pé àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìyà ń bọ̀ wá jẹ wọ́n!

2, 3. Ìṣírí wo ni Jèhófà fún àwọn tó fẹ́ láti sìn ín láìka gbígbilẹ̀ tí ìwà àìṣòótọ́ ń gbilẹ̀ sí?

2 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo wọn ló kúkú ya ọlọ̀tẹ̀ paraku o. Jèhófà ní àwọn wòlíì olùṣòtítọ́, ó sì jọ pé àwọn kan lára àwọn Júù fetí sí wọn. Jèhófà wá bá àwọn wọ̀nyẹn sọ̀rọ̀ ìtùnú. Lẹ́yìn tí wòlíì Aísáyà ti ṣàpèjúwe bí ogun tí Ásíríà ń gbé bọ̀ ṣe máa ba Júdà jẹ́ tó, Jèhófà mí sí i láti kọ ọ̀kan lára àwọn àyọkà tó fani mọ́ra jù lọ nínú gbogbo Bíbélì, ìyẹn ni, àpèjúwe àwọn ìbùkún tí àkóso Mèsáyà yóò mú wá. * Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lára ìbùkún wọ̀nyí ní ìmúṣẹ ráńpẹ́ nígbà tí àwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ yẹn lápapọ̀ ní ìmúṣẹ tó gbòòrò lóde òní. Lóòótọ́, àwọn ìbùkún wọ̀nyí kò ṣojú Aísáyà àti àwọn Júù mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n, wọ́n fi ìgbàgbọ́ retí wọn, wọn yóò sì rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Aísáyà lẹ́yìn àjíǹde.—Hébérù 11:35.

3 Àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní ń fẹ́ ìṣírí bákan náà. Ìwà ìbàjẹ́ tó túbọ̀ ń gbèèràn sí i láyé, àtakò lílekoko sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, àti ìkù-díẹ̀-káàtó toníkálukú ń bá gbogbo wọn fínra. Ọ̀rọ̀ àgbàyanu tí Aísáyà sọ nípa Mèsáyà àti ìṣàkóso rẹ̀ lè fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run lókun, kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ìpèníjà wọ̀nyí.

Mèsáyà—Aṣáájú Tó Kúnjú Òṣùwọ̀n

4, 5. Kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa dídé Mèsáyà, ọ̀nà wo ló sì jọ pé Mátíù gbà lo ọ̀rọ̀ Aísáyà?

4 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, àwọn Hébérù mìíràn tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì ti sọ ọ́ pé Mèsáyà, Aṣáájú tòótọ́ tí Jèhófà yóò rán sí Ísírẹ́lì, ń bọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10; Diutarónómì 18:18; Sáàmù 118:22, 26) Wàyí o, Jèhófà lo Aísáyà láti ṣe àlàyé síwájú sí i. Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ̀ka igi kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè; àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù kan yóò máa so èso.” (Aísáyà 11:1; fi wé Sáàmù 132:11.) “Ẹ̀ka igi” àti “èéhù” pa pọ̀ fi hàn pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Dáfídì, ẹni tí wọ́n fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 16:13; Jeremáyà 23:5; Ìṣípayá 22:16) Nígbà tí Mèsáyà tòótọ́ bá dé, ìyẹn “èéhù” láti ilé Dáfídì yìí, èso rere ni yóò so.

5 Jésù ni Mèsáyà táa ṣèlérí yẹn. Ọ̀rọ̀ Aísáyà 11:1 ni Mátíù òǹkọ̀wé ìhìn rere ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé pípè tí wọ́n ń pe Jésù ní “ará Násárétì” mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ṣẹ. Ìlú Násárétì ni wọ́n ti tọ́ Jésù dàgbà, ìyẹn ni wọ́n fi ń pè é ní ará Násárétì, ó sì jọ pé orúkọ yìí tan mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “èéhù” nínú Aísáyà 11:1. *Mátíù 2:23, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Lúùkù 2:39, 40.

6. Irú alákòóso wo ni àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé Mèsáyà yóò jẹ́?

6 Irú alákòóso wo ni Mèsáyà yóò jẹ́? Ṣé yóò ya òṣìkà, aṣetinú-ẹni bíi ará Ásíríà tó pa ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá run ni? Rárá o. Aísáyà sọ nípa Mèsáyà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:2, 3a) Òróró kọ́ ni wọ́n fi yan Mèsáyà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni. Èyí wáyé nígbà tí Jésù ṣe batisí, tí Jòhánù Olùbatisí rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà sórí Jésù. (Lúùkù 3:22) Ẹ̀mí Jèhófà “bà lé” Jésù, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nínú bó ṣe ń fi ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ràn, agbára ńlá, àti ìmọ̀ ṣe àwọn nǹkan. Àwọn àgbàyanu ànímọ́ tó yẹ alákòóso gan-an nìwọ̀nyí!

7. Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́?

7 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pẹ̀lú lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. Nínú ọ̀kan lára àwọn àsọyé tí Jésù sọ, ó sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Nípa bẹ́ẹ̀, kí á má ṣe lọ́ tìkọ̀ rárá láti bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kí á má sì jáwọ́ nínú fífi èso rẹ̀ tó gbámúṣé sílò, irú bíi “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Jèhófà ṣèlérí pé bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá béèrè fún “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” láti lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé, òun yóò fún wọn.—Jákọ́bù 1:5; 3:17.

8. Báwo ni Jésù ṣe rí ìgbádùn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà?

8 Kí ni ìbẹ̀rù Jèhófà tí Mèsáyà ní? Ó dájú pé Ọlọ́run kò da jìnnìjìnnì bo Jésù, kó wá di pé ẹ̀rù ìbáwí rẹ̀ ló ń bà á. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Mèsáyà fi bẹ̀rù Ọlọ́run, ó fi ìfẹ́ bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Olùbẹ̀rù Ọlọ́run a máa fẹ́ láti “ṣe ohun tí ó wù ú” ní gbogbo ìgbà, bí Jésù ti ṣe. (Jòhánù 8:29) Nínú ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe, Jésù kọ́ni pé kò sóhun tó ń múni láyọ̀ bíi pé kéèyàn máa fi ojúlówó ìbẹ̀rù Jèhófà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ojoojúmọ́.

Onídàájọ́ Òdodo àti Aláàánú

9. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún àwọn táa bá ní kí wọ́n bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ nínú ìjọ Kristẹni?

9 Aísáyà túbọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ànímọ́ Mèsáyà pé: “Kì yóò . . . ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.” (Aísáyà 11:3b) Ká ní o fẹ́ rojọ́ ní kóòtù, inú rẹ kò ha ní dùn tóo bá rí irú adájọ́ yìí? Bí Mèsáyà ṣe jẹ́ Onídàájọ́ gbogbo aráyé, rírojọ́ èké, lílo ọgbọ́n àyínìke ní kóòtù, àgbọ́sọ, tàbí àwọn ohun mìíràn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, bíi jíjẹ́ ọlọ́rọ̀, kò lè nípa lórí rẹ̀. Ó rí àṣírí gbogbo ẹ̀tàn, ó ń wò ré kọjá ìrí ojú lásán, ó sì ń fòye mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” “ọkùnrin tó fara sin.” (1 Pétérù 3:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àpẹẹrẹ títayọ tí Jésù fi lélẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe fún gbogbo àwọn táa bá ní kí wọ́n bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ nínú ìjọ Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 6:1-4.

10, 11. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́nà? (b) Irú ìdájọ́ wo ni Jésù yóò ṣe fáwọn ẹni burúkú?

10 Báwo ni àwọn ànímọ́ títayọ tí Mèsáyà ní yóò ṣe nípa lórí ẹjọ́ tó bá dá? Aísáyà ṣàlàyé pé: “Yóò . . . fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé. Yóò sì fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ilẹ̀ ayé; yóò sì fi ẹ̀mí ètè rẹ̀ fi ikú pa ẹni burúkú. Òdodo yóò sì jẹ́ ìgbànú ìgbáròkó rẹ̀, ìṣòtítọ́ ni yóò sì jẹ́ ìgbànú abẹ́nú rẹ̀.”—Aísáyà 11:4, 5.

11 Nígbà tí ìbáwí tọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó bá wọn wí lọ́nà tó gbà ṣàǹfààní fún wọn jù lọ, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ dáradára fáwọn alàgbà Kristẹni. Àmọ́, ìdájọ́ mímúná ní ń bẹ fáwọn aṣebi ní tiwọn. Nígbà tí Ọlọ́run yóò bá pe ètò àwọn nǹkan yìí wá jíhìn, ńṣe ni Mèsáyà máa fi ohùn ọlá àṣẹ rẹ̀ “lu ilẹ̀ ayé,” nípa pípàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ẹni burúkú run. (Sáàmù 2:9; fi wé Ìṣípayá 19:15.) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, kò ní ṣẹ́ ku ẹni burúkú kankan tí yóò tún máa dí àlàáfíà ayé lọ́wọ́ mọ́. (Sáàmù 37:10, 11) Jésù lágbára láti ṣe é láṣeyọrí nítorí pé òdodo àti ìṣòtítọ́ ló sán mọ́ ìgbáròkó àti abẹ́nú rẹ̀ bí ìgbànú.—Sáàmù 45:3-7.

Àyípadà Bá Ipò Nǹkan Lórí Ilẹ̀ Ayé

12. Àwọn nǹkan wo ló lè kó ìdààmú ọkàn bá Júù tó bá ń ronú àtipadà sí Ilẹ̀ Ìlérí láti Bábílónì?

12 Fojú inú wò ó pé o rí ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa àṣẹ Kírúsì pé kí àwọn Júù padà sí Jerúsálẹ́mù láti tún tẹ́ńpìlì kọ́. Ṣé yóò fẹ́ kúrò ní Bábílónì tí ààbò wà, kó wá tẹsẹ̀ bọ ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sílé? Láàárín àádọ́rin ọdún tí Ísírẹ́lì fi fi ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, oko wọ́n ti di ìgbòrò tó dí gan-an ni. Ńṣe ni ìkookò, àmọ̀tẹ́kùn, kìnnìún, àti béárì ń jẹ̀ kiri inú oko wọ̀nyẹn fàlàlà. Ejò ṣèbé ti sọ ibẹ̀ dilé pẹ̀lú. Ẹran ọ̀sìn ni àwọn Júù tó bá padà síbẹ̀ yóò gbára lé kí nǹkan tó lè lójú fún wọn, ìyẹn ni pé, agbo ẹran yóò máa pèsè wàrà, irun àgùntàn, àti ẹran jíjẹ, wọn yóò sì máa fi màlúù túlẹ̀. Ṣé àwọn ẹranko ò ní pa wọ́n jẹ? Ṣé ejò ò ní máa ṣán àwọn ọmọ kéékèèké? Tí àwọn èèyàn bá lọ ba dè wọ́n lọ́nà ilé ńkọ́?

13. (a) Àpèjúwe tó pinminrin wo ni Aísáyà ṣe? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé àlàáfíà tí Aísáyà ṣàpèjúwe kò mọ sórí ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà?

13 Aísáyà wá ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run yóò ṣe mú kí ipò nǹkan tó pinminrin wà ní ilẹ̀ yẹn. Ó ní: “Ìkookò yóò . . . máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. Abo màlúù àti béárì pàápàá yóò máa jẹun; àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pa pọ̀. Kìnnìún pàápàá yóò jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Dájúdájú, ọmọ ẹnu ọmú yóò máa ṣeré lórí ihò ṣèbé; ihò tí ó ní ìmọ́lẹ̀, tí í ṣe ti ejò olóró ni ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ní ti gidi. Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:6-9) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò múni lọ́kàn yọ̀? Ṣàkíyèsí pé ìmọ̀ Jèhófà ló fa àlàáfíà tí ibí yìí ṣàpèjúwe. Nítorí náà, ọ̀ràn náà kò mọ sórí ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà nìkan. Ìmọ̀ Jèhófà kò ní yí àwọn ẹranko padà, ṣùgbọ́n yóò yí àwọn ènìyàn padà. Kò ní sídìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti bẹ̀rù àwọn ẹranko ẹhànnà tàbí àwọn èèyàn oníwà bí ẹranko, yálà bí wọ́n ṣe ń lọ sílé tàbí ní ilẹ̀ wọn tó ti padà bọ̀ sípò.—Ẹ́sírà 8:21, 22; Aísáyà 35:8-10; 65:25.

14. Ìmúṣẹ gbígbòòrò wo ni Aísáyà 11:6-9 ní?

14 Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ tó gbòòrò ju ìyẹn lọ. Lọ́dún 1914, Jésù, Mèsáyà náà, gorí ìtẹ́ ní Òkè Síónì ti ọ̀run. Lọ́dún 1919, àwọn àṣẹ́kù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” rí ìtúsílẹ̀ gbà kúrò nígbèkùn Bábílónì, wọ́n sì kópa nínú ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́. (Gálátíà 6:16) Nípa báyìí, ọ̀nà là fún àsọtẹ́lẹ̀ Párádísè tí Aísáyà sọ láti ní ìmúṣẹ tòde òní. “Ìmọ̀ pípéye,” tí í ṣe, ìmọ̀ Jèhófà, yí ìwà àwọn èèyàn padà. (Kólósè 3:9, 10) Àwọn tó ti jẹ́ òǹrorò tẹ́lẹ̀ rí ń di ẹni àlàáfíà. (Róòmù 12:2; Éfésù 4:17-24) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti wá nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni tó ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, iye wọ́n sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. (Sáàmù 37:29; Aísáyà 60:22) Àwọn wọ̀nyí ti kọ́ nípa bí a ti ń dúró de àkókò tí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò padà di Párádísè ibi ààbò, alálàáfíà, bí Ọlọ́run ṣe pète rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.—Mátíù 6:9, 10; 2 Pétérù 3:13.

15. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ bó ṣe sọ ọ́ gan-an nínú ayé tuntun? Ṣàlàyé.

15 Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yóò ní ìmúṣẹ síwájú sí i nínú Párádísè táa mú bọ̀ sípò yẹn, bóyá ìmúṣẹ tó túbọ̀ jẹ́ bó ṣe sọ ọ́ gan-an? Ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti rò bẹ́ẹ̀. Ìfọ̀kànbalẹ̀ kan náà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó padà wálé náà ló ń fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà; kò ní sí pé kí àwọn àti ọmọ wọn máa bẹ̀rù ìpalára láti ibikíbi—ì báà jẹ́ látọ̀dọ̀ ènìyàn tàbí ẹranko. Lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà, ńṣe ni gbogbo olùgbé ayé yóò máa jẹ̀gbádùn ní kẹlẹlẹ bí Ádámù àti Éfà ṣe jẹ̀gbádùn ní Édẹ́nì. Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìgbésí ayé ṣe rí ní Édẹ́nì—tàbí bó ṣe máa rí ní Párádísè. Àmọ́, kò sí àní-àní pé bí Jésù Kristi Ọba bá ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ tí yóò fi ọgbọ́n àti ìfẹ́ ṣe, ńṣe ni gbogbo nǹkan yóò máa dùn yùngbà.

Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Padà Bọ̀ Sípò Nípasẹ̀ Mèsáyà

16. Kí ló dúró bí àmì fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?

16 Ìgbà tí Sátánì ṣàṣeyọrí láti sún Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà ní Édẹ́nì ni àtakò kọ́kọ́ dìde sí ìjọsìn tòótọ́. Títí dòní, Sátánì kò tíì jáwọ́ nínú ète rẹ̀ láti yí iye èèyàn tó bá lè ṣeé ṣe fún un padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Jèhófà kò ní gbà kí ìjọsìn tòótọ́ pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Orúkọ rẹ̀ rọ̀ mọ́ ọn, ọ̀ràn àwọn olùjọsìn rẹ̀ sì jẹ ẹ́ lógún pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lo Aísáyà láti ṣe ìlérí pàtàkì yìí pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé gbòǹgbò Jésè yóò wà tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá yóò yíjú sí láti ṣe ìwádìí, ibi ìsinmi rẹ̀ yóò sì di ológo.” (Aísáyà 11:10) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Dáfídì fi ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè yẹn, jẹ́ àmì tí ń pe àfiyèsí àwọn olóòótọ́ àṣẹ́kù lára àwọn Júù tó fọ́n ká pé kí wọ́n padà sílé láti tún tẹ́ńpìlì kọ́.

17. Báwo ni Jésù ṣe “dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè” ní ọ̀rúndún kìíní àti ní ọjọ́ tiwa?

17 Ṣùgbọ́n, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà tọ́ka sí ju ìyẹn lọ o. Bí a ṣe rí i tẹ́lẹ̀, ó tọ́ka sí ìṣàkóso Mèsáyà, Aṣáájú tòótọ́ kan ṣoṣo táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 11:10 yọ láti fi hàn pé, láyé ìgbà tirẹ̀ lọ́hùn-ún, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò láyè tiwọn nínú ìjọ Kristẹni. Nínú ìwé tó kọ, ó fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí yọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì Septuagint, pé: “Aísáyà . . . wí pé: ‘Gbòǹgbò Jésè yóò wà, ẹnì kan tí ń dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wà; òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbé ìrètí wọn kà.’” (Róòmù 15:12) Ẹ̀wẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yìí tilẹ̀ tún rìn jìnnà jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó dé ọjọ́ tiwa yìí, nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń fi ìfẹ́ wọn sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn àṣẹ́kù tó jẹ́ arákùnrin Mèsáyà.—Aísáyà 61:5-9; Mátíù 25:31-40.

18. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ibi ìkójọpọ̀ ní ọjọ́ tiwa?

18 Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà lóde òní, “ọjọ́ yẹn” tí Aísáyà ń tọ́ka sí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Mèsáyà gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:10; 2 Tímótì 3:1-5; Ìṣípayá 12:10) Láti ìgbà yẹn wá ni Jésù Kristi ti di àmì àfiyèsí tó hàn kedere, ibi ìkójọpọ̀, fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí àti àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo tó ń yán hànhàn fún ìjọba òdodo. Lábẹ́ ìdarí Mèsáyà yìí, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:14; Máàkù 13:10) Agbára ìhìn rere yìí sì kọ yọyọ. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” ló ń jọ̀wọ́ ara wọn fún Mèsáyà nípa dídarapọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. (Ìṣípayá 7:9) Bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ṣe túbọ̀ ń dara pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù nínú “ilé àdúrà” Jèhófà nípa tẹ̀mí, ṣe ni wọ́n ń fi kún ògo “ibi ìsinmi” Mèsáyà náà, tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Ọlọ́run.—Aísáyà 56:7; Hágáì 2:7.

Àwọn Ènìyàn Tó Fìmọ̀ṣọ̀kan Ń Jọ́sìn Jèhófà

19. Ìgbà méjì wo ni Jèhófà mú àṣẹ́kù àwọn ènìyàn rẹ̀ tó fọ́n káàkiri ilẹ̀ ayé padà bọ̀ sípò?

19 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé Jèhófà ti dá wọn nídè rí nígbà tí ọ̀tá alágbára kan ń fojú orílẹ̀-èdè yẹn gbolẹ̀. Ńṣe làwọn Júù olóòótọ́ máa ń gbé ẹ̀ka ìtàn Ísírẹ́lì yẹn gẹ̀gẹ̀, ìyẹn ni, ìtàn bí Jèhófà ṣe dá orílẹ̀-èdè yẹn nídè kúrò nígbèkùn Íjíbítì. Aísáyà kọ̀wé pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò tún na ọwọ́ rẹ̀, ní ìgbà kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò ṣẹ́ kù láti Ásíríà àti láti Íjíbítì àti láti Pátírọ́sì àti láti Kúṣì àti láti Élámù àti láti Ṣínárì àti láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù òkun. Dájúdájú, òun yóò gbé àmì àfiyèsí kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ; àwọn tí a tú ká lára Júdà ni òun yóò sì kó jọpọ̀ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 11:11, 12) Bí ẹní fà wọ́n lọ́wọ́ ni Jèhófà ṣe máa kó àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ látinú Ísírẹ́lì àti Júdà jáde kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n ká sí, yóò sì kó wọn délé gbẹẹrẹgbẹ. Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́nà ráńpẹ́ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, ìmúṣẹ rẹ̀ lọ́nà gbígbòòrò tún wá ní ògo tó bùáyà! Lọ́dún 1914, Jèhófà gbé Jésù Kristi tó gorí ìtẹ́ nà ró gẹ́gẹ́ bí “àmì àfiyèsí . . . fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Láti ọdún 1919 ni àṣẹ́kù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ń kóra jọ síbi àmì àfiyèsí yìí, wọ́n sì ń hára gàgà láti kópa nínú ìjọsìn mímọ́ gaara lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. “Inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” ni orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ti jáde wá.—Ìṣípayá 5:9.

20. Ìṣọ̀kan wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ní nígbà tí wọ́n bá padà dé láti Bábílónì?

20 Aísáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàpèjúwe ìṣọ̀kan tí orílẹ̀-èdè tó padà bọ̀ sípò náà yóò ní. Ìjọba àríwá ló pè ní Éfúráímù, ó sì pe ìjọba gúúsù ní Júdà, ó sọ pé: “Owú Éfúráímù yóò sì kúrò, àní àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí Júdà ni a óò ké kúrò. Éfúráímù pàápàá kì yóò jowú Júdà, bẹ́ẹ̀ ni Júdà kì yóò fi ẹ̀tanú hàn sí Éfúráímù. Wọn yóò sì fò lórí èjìká àwọn Filísínì lọ sí ìwọ̀-oòrùn; wọn yóò jùmọ̀ piyẹ́ àwọn ọmọ Ìlà-Oòrùn. Édómù àti Móábù ni àwọn tí wọn yóò na ọwọ́ wọn lé lórí, àwọn ọmọ Ámónì yóò sì jẹ́ ọmọ-abẹ́ wọn.” (Aísáyà 11:13, 14) Àwọn Júù kò ní pín sí orílẹ̀-èdè méjì mọ́ bí wọ́n bá ti padà dé láti Bábílónì. Ńṣe làwọn èèyàn gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ padà sí ilẹ̀ wọn níṣọ̀kan. (Ẹ́sírà 6:17) Wọn kò ní kórìíra ara wọn kí wọ́n sì máa fi ẹ̀tanú hàn síra mọ́. Ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan ni wọn yóò kojú àwọn ọ̀tá wọn látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, wọn yóò sì borí.

21. Báwo ni ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí ṣe yàtọ̀ gedegbe lóòótọ́?

21 Àmọ́, ìṣọ̀kan “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tilẹ̀ tún bùyàrì. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún tí ẹ̀yà méjìlá ìṣàpẹẹrẹ ti Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti ń bá ìṣọ̀kan wọn bọ̀, ìṣọ̀kan tó tinú ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí wá. (Kólósè 3:14; Ìṣípayá 7:4-8) Lónìí, àwọn èèyàn Jèhófà, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí pa pọ̀ mọ́ àwọn tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, wà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan kárí ayé lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà, irú ohun tí kì í ṣẹlẹ̀ rárá nínú àwọn ìjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú dídojú ìjà tẹ̀mí kọ àwọn ìsapá tí Sátánì fẹ́ fi ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn wọn. Ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń kọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Mèsáyà káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè bí Jésù ṣe pa á láṣẹ.—Mátíù 28:19, 20.

Wọn Yóò Borí Ìdènà

22. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe “ké ahọ́n òkun Íjíbítì kúrò” tí yóò sì “mi ọwọ́ rẹ̀ sí Odò”?

22 Ìdènà púpọ̀ ní ń bẹ, ìdènà gidi àti ìdènà ìṣàpẹẹrẹ, tó lè ṣèdíwọ́ fún ìpadàbọ̀ Ísírẹ́lì láti ìgbèkùn. Báwo ni wọ́n ṣe máa borí wọn? Aísáyà sọ pé: “Jèhófà yóò sì ké ahọ́n òkun Íjíbítì kúrò dájúdájú, yóò sì mi ọwọ́ rẹ̀ sí Odò nínú ìrànyòò ẹ̀mí rẹ̀. Yóò sì kọlù ú ní ojú ọ̀gbàrá rẹ̀ méjèèje, yóò sì mú kí àwọn ènìyàn fi sálúbàtà wọn rìn ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 11:15) Jèhófà ni yóò kó gbogbo ìdìgbòlù kúrò lọ́nà fáwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè padà wálé. Àní ìdènà tó páni láyà irú ti ibi tí Òkun Pupa ti ya wọlẹ̀ (irú bíi Gulf of Suez) tàbí ìdènà ti omilẹgbẹ Odò Yúfírétì tí kò ṣeé gbà kọjá pàápàá, yóò gbẹ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, débi pé èèyàn yóò lè sọdá wọn láìtilẹ̀ bọ́ sálúbàtà lẹ́sẹ̀!

23. Ọ̀nà wo ni ‘òpópó kan yóò fi wá wà láti inú Ásíríà’?

23 Nígbà ayé Mósè, Jèhófà lànà fún Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ Íjíbítì kí wọ́n sì kọjá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ohun tó jọ ìyẹn náà ni yóò ṣe báyìí, ó sọ pé: “Òpópó kan yóò sì wá wà láti inú Ásíríà fún àṣẹ́kù àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò ṣẹ́ kù, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ti wá wà fún Ísírẹ́lì ní ọjọ́ tí ó ń gòkè bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì.” (Aísáyà 11:16) Ńṣe ni Jèhófà máa ṣamọ̀nà àwọn ìgbèkùn tí ń bọ̀ wálé bí ẹni pé wọ́n ń gba òpópónà bọ̀ láti ibi ìgbèkùn lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Àwọn alátakò yóò gbìyànjú láti dá wọn dúró o, ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò wà pẹ̀lú wọn. Lónìí pẹ̀lú, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń dojú kọ àtakò líle koko, síbẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ síwájú tìgboyàtìgboyà! Wọ́n ti jáde kúrò nínú Ásíríà tòde òní, ìyẹn ayé Sátánì, wọ́n sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jáde kúrò bákan náà. Wọ́n mọ̀ pé ìjọsìn mímọ́ gaara máa ṣàṣeyọrí, pé yóò sì gbilẹ̀. Iṣẹ́ Ọlọ́run kúkú ni, kì í ṣe tèèyàn.

Ayọ̀ Àìlópin Fáwọn Ọmọ Abẹ́ Ìjọba Mèsáyà!

24, 25. Àwọn gbólóhùn ìyìn àti ìmọrírì wo ni àwọn èèyàn Jèhófà ń fohùn rara sọ?

24 Aísáyà wá fi ọ̀rọ̀ ìdùnnú ṣàpèjúwe bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lórí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ó sọ pé: “Ó sì dájú pé ìwọ yóò sọ ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Èmi yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbínú rẹ ru sí mi, ìbínú rẹ yí padà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o sì bẹ̀rẹ̀ sí tù mí nínú.’” (Aísáyà 12:1) Ìyà ńlá ni Jèhófà fi jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ tó yàyàkuyà. Ṣùgbọ́n ó yọrí sí ohun tó ń fẹ́, ó tún àárín òun àti orílẹ̀-èdè náà ṣe, ó sì mú kí ìsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò. Jèhófà mú kó dá àwọn olùjọsìn rẹ̀ olóòótọ́ lójú pé òun yóò gbà wọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Abájọ tí wọ́n fi fìmọrírì hàn!

25 Ẹ̀rí pé Ísírẹ́lì tó padà bọ̀ sípò fọkàn tán Jèhófà wá hàn délẹ̀délẹ̀, wọ́n sì fohùn rara wí pé: “‘Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi. Èmi yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìbẹ̀rùbojo kankan kì yóò sì bá mi; nítorí pé Jáà Jèhófà ni okun mi àti agbára ńlá mi, òun sì wá ni ìgbàlà mi.’ Ó dájú pé ayọ̀ ńláǹlà ni ẹ ó fi fa omi láti inú àwọn ìsun ìgbàlà.” (Aísáyà 12:2, 3) Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “agbára ńlá” ní ẹsẹ kejì ni wọ́n túmọ̀ sí “ìyìn” nínú Bíbélì ti Septuagint. Àwọn olùjọsìn wá bú sí orin ìyìn nítorí ìgbàlà “Jáà Jèhófà.” “Jáà” jẹ́ ìkékúrú orúkọ náà Jèhófà, wọ́n sì ń lò ó nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti tún gbà fi ìyìn àti ìmọrírì tó ga gidigidi hàn. Ńṣe ni lílo gbólóhùn náà “Jáà Jèhófà”—pípe orúkọ Ọlọ́run lápètúnpè—túbọ̀ ń gbé ìyìn Ọlọ́run ga sí i.

26. Lónìí, àwọn wo ló ń mú kí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe di mímọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè?

26 Àwọn ojúlówó olùjọsìn Jèhófà kì í pa ayọ̀ wọn mọ́nú. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sọ ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga. Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó ta yọ ré kọjá. Èyí ni a sọ di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’” (Aísáyà 12:4, 5) Láti 1919 ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ‘ń polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè wọ́n jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀,’ “àwọn àgùntàn mìíràn” ẹlẹgbẹ́ wọn sì wá ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn náà. Wọ́n jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́, . . . orílẹ̀-èdè mímọ́” táa yà sọ́tọ̀ fún ète yẹn. (Jòhánù 10:16; 1 Pétérù 2:9) Àwọn ẹni àmì òróró kéde pé orúkọ mímọ́ Jèhófà ni a gbé ga, wọ́n sì ń kópa nínú mímú kó di mímọ̀ kárí ilẹ̀ ayé. Wọ́n ń ṣáájú gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà nínú yíyọ̀ nítorí ìpèsè rẹ̀ fún ìgbàlà wọn. Bí Aísáyà ṣe polongo gẹ́lẹ́ ló rí, pé: “Ké jáde lọ́nà híhan gan-an-ran, kí o sì ké fún ìdùnnú, ìwọ obìnrin olùgbé Síónì, nítorí pé títóbi ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì láàárín rẹ”! (Aísáyà 12:6) Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀ Nípa Ọjọ́ Iwájú!

27. Ìdánilójú wo ni àwọn Kristẹni ní bí wọ́n ṣe ń dúró de ìgbà tí ohun tí wọ́n ń retí yóò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́?

27 Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹni tó jẹ́ “àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi tó gorí ìtẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Inú wọ́n dùn láti jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba yẹn, ìwúrí ló sì jẹ́ fún wọn pé wọ́n mọ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Ìṣọ̀kan tí wọ́n ní lágbo Kristẹni wọn ń fún wọn láyọ̀, wọ́n sì ń sapá kíkankíkan láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba, èyí tó ń fi ojúlówó ìránṣẹ́ Jèhófà hàn. (Aísáyà 54:13) Bó ṣe dá wọn lójú pé Jáà Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ọkàn wọ́n balẹ̀ lórí ìrètí tí wọ́n ní, ìdùnnú ńláǹlà ló sì jẹ́ fún wọn láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ kí olúkúlùkù olùjọsìn Jèhófà máa bá a lọ láti fi gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọ́run àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Kí gbogbo èèyàn fi ọ̀rọ̀ Aísáyà sọ́kàn o, kí wọ́n sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà nípasẹ̀ Mèsáyà Jèhófà!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 2 Inú ọ̀rọ̀ náà ma·shiʹach lédè Hébérù ni “Mèsáyà” tó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró” ti wá. Ọ̀rọ̀ tó bá a dọ́gba lédè Gíríìkì ni Khri·stosʹ, tàbí “Kristi.”—Mátíù 2:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

^ ìpínrọ̀ 5 Lédè Hébérù, neʹtser ni wọ́n ń pe “èéhù,” Nots·riʹ ni wọ́n sì ń pe “ará Násárétì.”

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 158]

Mèsáyà jẹ́ “ẹ̀ka igi” tó yọ láti ara Jésè, nípasẹ̀ Dáfídì Ọba

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 162]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 170]

Aísáyà 12:4, 5, bó ṣe wà nínú àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú (Àwọn ibi tí orúkọ Ọlọ́run wà la jẹ́ kó túbọ̀ hàn kedere)