Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”

“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”

Orí Ọgbọ̀n

“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”

Aísáyà 40:1-31

1. Kí ni ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń tù wá nínú?

JÈHÓFÀ ni ‘Ọlọ́run tí ń pèsè ìtùnú.’ Ọ̀nà kan tó gbà ń tù wá nínú jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìlérí rẹ̀ tó ti mú kó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Róòmù 15:4, 5) Bí àpẹẹrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan tóo fẹ́ràn kú, kí ni ì bá tún tù ọ́ nínú ju pé kóo máa retí pé onítọ̀hún ń bọ̀ wá jíǹde sínú ayé tuntun Ọlọ́run? (Jòhánù 5:28, 29) Ìlérí tí Jèhófà sì tún ṣe ńkọ́, pé láìpẹ́ òun yóò mú kí ìwà burúkú dópin, tí òun yóò sì sọ ayé yìí di Párádísè? Ǹjẹ́ ìtùnú kọ́ ló ń jẹ́ fúnni, láti nírètí pé a lè là á já bọ́ sínú Párádísè tó ń bọ̀ yìí láìní kú mọ́ rárá?—Sáàmù 37:9-11, 29; Ìṣípayá 21:3-5.

2. Èé ṣe tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Ọlọ́run?

2 Ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè gbọ́kàn lé àwọn ìlérí Ọlọ́run ní tòótọ́? Dájúdájú, a lè gbọ́kàn lé e! Ẹni tó ṣe àwọn ìlérí yẹn ṣeé gbọ́kàn lé pátápátá. Ó lágbára láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó sì fẹ́ láti mú un ṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) Ohun tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ, pé òun yóò mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù, jẹ́ kí èyí túbọ̀ hàn gbangba gbàǹgbà. Ẹ jẹ́ ká gbé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yẹ̀ wò, bó ṣe wà nínú Aísáyà orí ogójì, nítorí àgbéyẹ̀wò yẹn lè mú kí ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Jèhófà, Ẹni tí ń mú àwọn ìlérí ṣẹ, túbọ̀ lágbára sí i.

Ìlérí Tó Ń Tuni Nínú

3, 4. (a) Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Aísáyà kọ sílẹ̀, tí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa nílò nígbà tó bá yá lọ́jọ́ iwájú? (b) Èé ṣe tí àwọn ará Júdà àti Jerúsálẹ́mù yóò fi dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì, báwo ni wọn yóò sì ṣe sìnrú pẹ́ tó?

3 Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí àwọn èèyàn Jèhófà yóò nílò tó bá di ọjọ́ iwájú. Kété lẹ́yìn tí Aísáyà sọ fún Hesekáyà Ọba nípa ìparun tí ń bọ̀ wá sórí Jerúsálẹ́mù àti bí àwọn èèyàn Júù ṣe máa dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì, ni Aísáyà gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó jẹ́ ìlérí nípa ìmúbọ̀sípò wọn, ó ní: “‘Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,’ ni Ọlọ́run yín wí. ‘Ẹ bá ọkàn-àyà Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ kí ẹ sì ké pè é pé iṣẹ́ ìsìn ológun rẹ̀ ti pé, pé a ti san ìṣìnà rẹ̀ tán pátá. Nítorí pé ó ti gba iye tí ó kún rẹ́rẹ́ fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Jèhófà.’”—Aísáyà 40:1, 2.

4 Ọ̀rọ̀ yẹn, ‘ìtùnú,’ tó bẹ̀rẹ̀ Aísáyà orí ogójì yìí ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí tó wà nínú ìyókù ìwé Aísáyà gan-an ni. Apẹ̀yìndà tí àwọn ará Júdà àti Jerúsálẹ́mù dà ni yóò jẹ́ kí wọ́n dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n àwọn Júù òǹdè wọ̀nyí kò ní sin àwọn ará Bábílónì títí ayé. Rárá o, nítorí gbàrà tí wọ́n bá ti “san” ìṣìnà wọn “tán pátá” ni ìsìnrú wọn yóò dópin. Báwo ni ìyẹn ṣe máa pẹ́ tó? Àádọ́rin ọdún ni, gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà wòlíì ṣe wí. (Jeremáyà 25:11, 12) Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà yóò wá ṣamọ̀nà àwọn Júù tó ronú pìwà dà padà sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì. Nígbà tí yóò fi di àádọ́rin ọdún tí Júdà ti wà láhoro, ìtùnú gidi mà ni yóò jẹ́ fún àwọn tó wà nígbèkùn o, láti wá mọ̀ pé àkókò ìdáǹdè táa ṣèlérí fún wọn ti kù sí dẹ̀dẹ̀!—Dáníẹ́lì 9:1, 2.

5, 6. (a) Èé ṣe tí jíjìn tí ọ̀nà jìn láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù kò fi ní ṣèdíwọ́ fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run? (b) Ipa wo ni ìmúbọ̀sípò àwọn Júù sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò ní lórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù?

5 Ìrìn ẹgbẹ̀rin sí ẹgbẹ̀jọ kìlómítà ni wọn yóò rìn láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù, ó sinmi lórí ọ̀nà tí wọ́n bá gbà. Ṣé jíjìn tí ọ̀nà yẹn jìn yóò wá ṣèdíwọ́ fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run? Àgbẹdọ̀! Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń ké ní aginjù: ‘Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe! Ẹ mú kí òpópó fún Ọlọ́run wa, èyí tí ó la pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ kọjá, jẹ́ títọ́. Gbogbo àfonífojì ni kí a gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké sì ni kí a sọ di rírẹlẹ̀. Ilẹ̀ págunpàgun sì gbọ́dọ̀ di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ, ilẹ̀ kángunkàngun sì gbọ́dọ̀ di pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì. Dájúdájú, a ó sì ṣí ògo Jèhófà payá, gbogbo ẹran ara yóò sì rí i pa pọ̀, nítorí pé ẹnu Jèhófà gan-an ni ó sọ ọ́.’”—Aísáyà 40:3-5.

6 Kí àwọn ọba ìhà Ìlà Oòrùn Ayé tó gbéra ìrìn àjò, wọ́n sábà máa ń rán àwọn èèyàn lọ tún ọ̀nà ṣe nípa kíkó àwọn òkúta ńláńlá kúrò, wọn a tilẹ̀ tẹ́ afárá, wọn a sì sọ àwọn òkè kéékèèké di ibi tó tẹ́jú. Ní ti àwọn Júù tó ń padà bọ̀ wálé yìí, ńṣe ni yóò rí bí ẹni pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣáájú wọn, tó ń kó gbogbo ohun ìdìgbòlù kúrò lọ́nà. Ó ṣe tán, Jèhófà ni wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́, ńṣe ni ìmúṣẹ ìlérí tó ṣe pé òun yóò mú wọn padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò mú kí ògo rẹ̀ hàn kedere sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Bí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn fẹ́ bí wọ́n kọ̀ o, wọn yóò rí i ní túláàsì pé Jèhófà ni Ẹni tí ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

7, 8. (a) Ìmúṣẹ wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 40:3 ní ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa? (b) Ìmúṣẹ tó gbòòrò wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní lọ́dún 1919?

7 Ìmúbọ̀sípò ti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa nìkan kọ́ ni ìmúṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní. Ó tún ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pẹ̀lú. Jòhánù Oníbatisí ni ohùn ẹnì kan tí “ń ké jáde ní aginjù,” ní ìmúṣẹ Aísáyà 40:3. (Lúùkù 3:1-6) Jòhánù sì lo ọ̀rọ̀ Aísáyà fún ara rẹ̀ nípa ìmísí. (Jòhánù 1:19-23) Ọdún 29 Sànmánì Tiwa ni Jòhánù ti bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù Kristi. * Ṣe ni kíkéde tí Jòhánù ti kéde ṣáájú mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wá Mèsáyà táa ti ṣèlérí náà, kí àwọn náà lè gbọ́rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì tẹ̀ lé e. (Lúùkù 1:13-17, 76) Jèhófà yóò wá lo Jésù láti ṣamọ̀nà àwọn tó ronú pìwà dà lọ sínú òmìnira tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 1:29; 8:32) Ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò sí i nígbà tí àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí rí ìdáǹdè gbà kúrò nínú Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, àti nígbà ìmúbọ̀sípò wọn sínú ìjọsìn tòótọ́.

8 Ṣùgbọ́n, àwọn tó ń retí láti jàǹfààní nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí ìlérí yìí ní wá ńkọ́, ìyẹn àwọn Júù tó jẹ́ ìgbèkùn ní Bábílónì? Ǹjẹ́ wọ́n lè gbọ́kàn lé ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun yóò mú wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ọ̀wọ́n ní tòótọ́? Dájúdájú, wọ́n lè gbọ́kàn lé e! Aísáyà wá lo àwọn gbólóhùn tó ń mú ọ̀rọ̀ yéni yékéyéké àti àwọn àpẹẹrẹ ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe láti ọjọ́ dé ọjọ́, láti fi sọ àwọn ìdí pàtàkì tí wọ́n fi lè ní ìgbọ́kànlé kíkún pé Jèhófà yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

Ọlọ́run Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Wà Títí Láé

9, 10. Báwo ni Aísáyà ṣe fi ìyàtọ̀ hàn láàárín kíkúrú tí ọjọ́ ayé ọmọ ènìyàn kúrú àti wíwà tí “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run wà títí gbére?

9 Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ọ̀rọ̀ Ẹni tó ṣèlérí ìmúbọ̀sípò yìí wà títí láé. Aísáyà kọ̀wé pé: “Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: ‘Ké jáde!’ Ẹnì kan sì sọ pé: ‘Kí ni kí n ké jáde?’ ‘Gbogbo ẹran ara jẹ́ koríko tútù, gbogbo inú rere wọn onífẹ̀ẹ́ sì dà bí ìtànná pápá. Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ, nítorí pé ẹ̀mí Jèhófà gan-an ti fẹ́ lù ú. Dájúdájú, koríko tútù ni àwọn ènìyàn. Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’”—Aísáyà 40:6-8.

10 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ dáadáa pé koríko kì í wà títí ayé. Lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀, ńṣe ni oòrùn tó mú janjan máa ń sọ koríko tútù di gbígbẹ háúháú. Ní àwọn ọ̀nà kan, bíi koríko lọjọ́ ayé ọmọ ènìyàn rí, ó kúrú jọjọ. (Sáàmù 103:15, 16; Jákọ́bù 1:10, 11) Aísáyà wá fi ìyàtọ̀ hàn láàárín kíkúrú tí ọjọ́ ayé ọmọ ènìyàn kúrú àti wíwà tí “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run, tàbí ète rẹ̀ tó sọ, wà títí gbére. Ní tòótọ́, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa” máa wà títí láé ni. Bí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀, kò sí ohunkóhun tó lè pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ rẹ́ tàbí tó lè dènà rẹ̀ kó má ṣẹ.—Jóṣúà 23:14.

11. Èé ṣe tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò mú àwọn ìlérí tó wà nínú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ?

11 Lóde òní, ìlàlẹ́sẹẹsẹ ète Jèhófà wà lákọọ́lẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni Bíbélì sì ti ń rí àtakò tó gbóná janjan, àwọn olùtumọ̀ onígboyà àtàwọn mìíràn pẹ̀lú sì ti fi ìwàláàyè wọn wewu láti lè pa á mọ́. Síbẹ̀ àwọn ìsapá tí wọ́n ṣe nìkan kọ́ ni kìkì ìdí tó fi wà títí dòní. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà, “Ọlọ́run alààyè, tí ó sì wà pẹ́ títí,” Ẹni tó pa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, ìyẹn ló fi wà títí dòní. (1 Pétérù 1:23-25) Rò ó wò ná: Níwọ̀n bí Jèhófà ti pa àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, ǹjẹ́ a kò lè gbẹ́kẹ̀ lé e pé yóò mú àwọn ìlérí tó wà nínú rẹ̀ ṣẹ?

Ọlọ́run Alágbára Tó Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Àgùntàn Rẹ̀

12, 13. (a) Èé ṣe tí ìlérí ìmúbọ̀sípò fi ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé? (b) Ìhìn rere wo ló wà fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn, ìdí wo ni wọ́n sì fi lè gbọ́kàn lé e?

12 Aísáyà sọ ìdí kejì tí wọ́n fi lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí ìmúbọ̀sípò náà. Ẹni tó ṣe ìlérí yìí jẹ́ Ọlọ́run alágbára tó ń ṣìkẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Bá ọ̀nà rẹ gòkè lọ, àní sórí òkè ńlá gíga, ìwọ obìnrin tí ń mú ìhìn rere wá fún Síónì. Gbé ohùn rẹ sókè, àní tagbára-tagbára, ìwọ obìnrin tí ń mú ìhìn rere wá fún Jerúsálẹ́mù. Gbé e sókè. Má fòyà. Sọ fún àwọn ìlú ńlá Júdà pé: ‘Ọlọ́run yín rèé.’ Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò wá, àní gẹ́gẹ́ bí alágbára [“àní tòun tagbára,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW], apá rẹ̀ yóò sì máa ṣàkóso fún un. Wò ó! Ẹ̀san rẹ̀ ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, owó ọ̀yà tí ó ń san sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí. Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.”—Aísáyà 40:9-11.

13 Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà pé kí àwọn obìnrin ṣayẹyẹ ìṣẹ́gun, wọ́n á máa fi ohùn rara tàbí orin kíkọ kéde ìhìn rere nípa ìjagunṣẹ́gun tàbí nípa ìtura tó máa tó bá wọn. (1 Sámúẹ́lì 18:6, 7; Sáàmù 68:11) Ṣe ni Aísáyà wá ń fi hàn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé ìhìn rere ń bẹ fáwọn Júù tó wà nígbèkùn, ìhìn téèyàn lè fi àìbẹ̀rù kéde lóhùn rara, àní láti orí àwọn òkè pàápàá ni, àní sẹ́ Jèhófà yóò ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ padà sí Jerúsálẹ́mù wọn ọ̀wọ́n! Wọ́n lè gbọ́kàn lé e, nítorí pé Jèhófà yóò wá “àní tòun tagbára.” Nítorí náà, kò sí ohun tó lè dènà rẹ̀ kó máà mú ète rẹ̀ ṣẹ.

14. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà yóò gbà ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi ọ̀nà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn gbà ń ṣìkẹ́ àwọn àgùntàn wọn hàn? (Wo àpótí ojú ewé 405.)

14 Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run alágbára yìí tún ní ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ o. Aísáyà fi ìdùnnú ṣàpèjúwe bí Jèhófà yóò ṣe ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ńṣe ni Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ tó kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn rẹ̀ jọ, tó sì kó wọn sí “oókan àyà” rẹ̀. Ó dájú pé ìṣẹ́po ẹ̀wù lápá òkè ni ọ̀rọ̀ náà “oókan àyà” ń tọ́ka sí níhìn-ín. Nígbà mìíràn, ibẹ̀ làwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń gbé àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn àṣẹ̀ṣẹ̀bí sí, tí kò bá lè kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú agbo. (2 Sámúẹ́lì 12:3) Láìsí àní-àní, irú ìran tó wúni lórí bẹ́ẹ̀, látinú ohun táwọn darandaran máa ń ṣe láti ọjọ́ dé ọjọ́, fi ọkàn àwọn èèyàn Jèhófà tó wà nígbèkùn balẹ̀ pé ó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ kọbi ara sí ọ̀ràn àwọn. Dájúdájú, irú Ọlọ́run alágbára tó tún jẹ́ oníkẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ mà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé o, pé yóò mú ohun tó ṣèlérí fún wọn ṣẹ!

15. (a) Ìgbà wo ni Jèhófà dé “àní tòun tagbára,” ta sì ni ‘apá tó ń ṣàkóso fún un’? (b) Ìhìn rere wo ni a ní láti polongo rẹ̀ láìbẹ̀rù?

15 Ọ̀rọ̀ Aísáyà kún fún ìtumọ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ tiwa. Lọ́dún 1914, Jèhófà dé “àní tòun tagbára,” ó sì gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀run. Jésù Kristi, Ọmọ Jèhófà, tí ó gbé gorí ìtẹ́ rẹ̀ lọ́run, ni ‘apá tí ń ṣàkóso fún un.’ Lọ́dún 1919, Jèhófà dá àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mímú kí ìsìn mímọ́ gaara ti Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ padà bọ̀ sípò pátápátá. Èyí jẹ́ ìhìn rere tí a ní láti fi àìbẹ̀rù polongo rẹ̀, bí ẹní ń fi ohùn rara ké látorí àwọn òkè, kí ìpolongo yẹn lè dún lọ réré. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká gbé ohùn wa sókè o, kí a sì fìgboyà jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ti mú ìsìn mímọ́ gaara rẹ̀ padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé yìí!

16. Irú ọwọ́ wo ni Jèhófà fi ń ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní, èyí sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn wo?

16 Ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 40:10, 11 tún wúlò síwájú sí i fún wa lóde òní. Ìtùnú ló jẹ́ fúnni láti ri bí Jèhófà ṣe ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀. Gẹ́lẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe mọ àìní àgùntàn kọ̀ọ̀kan, àní títí kan àwọn ọ̀dọ̀ àgùntàn lẹ̀jẹ́lẹ̀jẹ́ tí kò lè kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú ìyókù agbo, ni Jèhófà ṣe mọ ibi tí agbára olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ mọ. Ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn oníkẹ̀ẹ́ yìí jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn. Ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi mú agbo, kí wọ́n ṣàfarawé àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń fi hàn. Kí wọ́n máa fi bí ọ̀ràn ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú agbo ṣe rí lára Jèhófà sọ́kàn nígbà gbogbo, agbo “tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.”—Ìṣe 20:28.

Olódùmarè, Ọlọ́gbọ́n Gbogbo

17, 18. (a) Èé ṣe tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn fi lè gbọ́kàn lé ìlérí ìmúbọ̀sípò náà? (b) Àwọn gbankọgbì ìbéèrè wo ni Aísáyà béèrè?

17 Àwọn Júù tó wà nígbèkùn lè gbọ́kàn lé ìlérí ìmúbọ̀sípò tí Jèhófà ṣe nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ Olódùmarè àti ọlọ́gbọ́n gbogbo. Aísáyà sọ pé: “Ta ni ó ti díwọ̀n omi nínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ lásán, tí ó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ lásán wọn ọ̀run pàápàá, tí ó sì ti kó ekuru ilẹ̀ ayé jọ sínú òṣùwọ̀n, tàbí tí ó fi atọ́ka-ìwọ̀n wọn àwọn òkè ńláńlá, tí ó sì wọn àwọn òkè kéékèèké nínú òṣùwọ̀n? Ta ni ó ti wọn ẹ̀mí Jèhófà, ta sì ni, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ń gbà á nímọ̀ràn, tí ó lè mú kí ó mọ ohunkóhun? Ta ni òun bá fikùn lukùn, tí ẹnì kan fi lè mú kí ó lóye, tàbí kẹ̀, ta ni ó ń kọ́ ọ ní ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo, tàbí tí ó ń kọ́ ọ ní ìmọ̀, tàbí tí ó ń mú kí ó mọ àní ọ̀nà òye gidi?”—Aísáyà 40:12-14.

18 Gbankọgbì ìbéèrè nìwọ̀nyí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn láti ronú lé lórí. Ǹjẹ́ ọmọ aráyé lè dá ìgbì àwọn òkun ńláǹlà dúró? Rárá o! Bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, ńṣe ni àwọn òkun tó bo ilẹ̀ ayé dà bí ẹ̀kán omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀. * Ǹjẹ́ ọmọ adáríhurun lè díwọ̀n ìsálú ọ̀run tó lọ salalu, tó kún fún ìràwọ̀, tàbí pé kí ó wọn àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké ayé lórí ìwọ̀n? Rárá o. Bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà díwọ̀n ìsálú ọ̀run tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn bí ìgbà téèyàn bá ń fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ wọ̀n ọ́n, ìyẹn àlàfo tó wà láàárín àtàǹpàkò àti ọmọńdinrín bí a bá ya àtẹ́lẹwọ́ tán. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lè wọn àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké lórí ìwọ̀n. Ǹjẹ́ àwọn tó tiẹ̀ gbọ́n jù lọ nínú ọmọ aráyé lè gba Ọlọ́run nímọ̀ràn nípa ohun tó lè ṣe sí ipò táyé wà lónìí, tàbí kí wọ́n sọ ohun tó yẹ kó ṣe lọ́jọ́ iwájú fún un? Ó dájú pé wọn ò lè ṣe bẹ́ẹ̀!

19, 20. Àwọn gbólóhùn alápèjúwe, tó ń mú nǹkan yéni yékéyéké wo ni Aísáyà lò láti fi tẹnu mọ́ bí ògo Jèhófà ṣe tóbi tó?

19 Àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá ilẹ̀ ayé wá ńkọ́, ṣé wọ́n lè dènà Ọlọ́run bó ṣe ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ti ṣèlérí ṣẹ? Aísáyà dáhùn nípa ṣíṣàpèjúwe àwọn orílẹ̀-èdè báyìí pé: “Wò ó! Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí. Wò ó! Ó ń gbé àwọn erékùṣù pàápàá sókè gẹ́gẹ́ bí ekuru lẹ́búlẹ́bú lásán. Lẹ́bánónì pàápàá kò tó fún mímú kí iná máa jó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ rẹ̀ kò sì tó fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gbogbo orílẹ̀-èdè dà bí ohun tí kò sí ní iwájú rẹ̀; bí aláìjámọ́ nǹkan kan àti òtúbáńtẹ́ ni ó kà wọ́n sí.”—Aísáyà 40:15-17.

20 Lójú Jèhófà, bí ẹ̀kán omi kan tó kán sílẹ̀ látinú korobá ni gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe rí. Wọn kò ju ekuru lẹ́búlẹ́bú tó kù sórí òṣùwọ̀n, tí kò lè tẹ̀wọ̀n rárá. * Ká ní ẹnì kan mọ pẹpẹ ńlá kan, kó wá fi gbogbo igi tó wà lórí òkè Lẹ́bánónì dáná sídìí pẹpẹ yẹn. Lẹ́yìn náà, ká ní ó wá fi gbogbo ẹranko tó ń jẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá wọ̀nyẹn rú ẹbọ rẹ̀. Àní irú ẹbọ yẹn pàápàá kò tíì ní kúnjú òṣùwọ̀n ohun tó yẹ Jèhófà. Bí ẹni pé àpẹẹrẹ tí Aísáyà ti ń mú wá yìí kò tíì tó síbẹ̀, ló bá tún lo gbólóhùn tó tiẹ̀ tún lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ni pé, gbogbo orílẹ̀-èdè dà bí “aláìjámọ́ nǹkan kan” lójú Jèhófà.—Aísáyà 40:17, New Revised Standard Version.

21, 22. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà kò láfiwé? (b) Èrò wo ni àwọn àpèjúwe tó ṣe kedere tí Aísáyà ṣe, gbìn sí wa lọ́kàn? (d) Gbólóhùn tó yè kooro, tó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu wo ni wòlíì Aísáyà kọ sílẹ̀? (Wo àpótí ojú ewé 412.)

21 Aísáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí fi bí àwọn tó ń sọ wúrà, fàdákà, tàbí igi di òrìṣà ṣe gọ̀ tó hàn láti fi túbọ̀ tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà kò láfiwé rárá. Ó mà kúkú jẹ́ ìwà òmùgọ̀ o láti ronú pé irú àwọn òrìṣà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ àwòrán tó dọ́gba pẹ̀lú “Ẹnì kan . . . tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé,” tó sì ń ṣàkóso lórí àwọn olùgbé inú rẹ̀!—Ka Aísáyà 40:18-24.

22 Ńṣe ni gbogbo àpèjúwe tó ṣe kedere yìí ń gbin èrò kan sí wa lọ́kàn, ìyẹn ni pé, kò sóhun tó lè dènà Jèhófà tó jẹ́ Olódùmarè, ọlọ́gbọ́n gbogbo, ẹni tí kò láfiwé, pé kó máà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ọ̀rọ̀ Aísáyà ti ní láti jẹ́ ìtùnú gidigidi fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì, tí wọ́n ń hára gàgà láti padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ó sì ti ní láti fún wọn lókun! Lóde òní, àwa náà lè ní ìgbọ́kànlé pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la wa yóò ṣẹ ní ti tòótọ́.

“Ta Ni Ó Dá Nǹkan Wọ̀nyí?”

23. Ìdí wo làwọn Júù tó wà nígbèkùn fi lè mọ́kàn le, kí sì ni Jèhófà wá túbọ̀ fi hàn nípa ara rẹ̀?

23 Ìdí mìíràn ṣì tún wà tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn fi lè mọ́kàn le. Ẹni tó ṣèlérí ìdáǹdè ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, òun sì ni Orísun gbogbo ibú agbára gíga. Jèhófà wá pe àfiyèsí sí agbára rẹ̀ tó fara hàn nínú ìṣẹ̀dá, láti túbọ̀ fi hàn pé atóbijù lòun jẹ́ sẹ́ẹ̀, ó ní: “‘Ta ni ẹ lè fi mí wé, tí a ó fi mú mi bá a dọ́gba?’ ni Ẹni Mímọ́ wí. ‘Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.’”—Aísáyà 40:25, 26.

24. Bí Jèhófà ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀, báwo ló ṣe fi hàn pé kò sẹ́nì kankan tó bá òun dọ́gba?

24 Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló fúnra rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀. Jèhófà pe àfiyèsí sí àwọn ìràwọ̀ ọ̀run láti lè fi hàn pé kò sẹ́nì kankan tó bá òun dọ́gba. Bí ọ̀gágun tó lè pàṣẹ pé kí agbo ọmọ ogun òun tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ni Jèhófà ṣe láṣẹ lórí àwọn ìràwọ̀. Bó bá fẹ́ pè wọ́n jọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ‘kò sí ìkankan nínú wọn tí yóò dàwáàrí.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ìràwọ̀ pọ̀ lọ salalu, orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló máa fi ń pè wọ́n, yálà orúkọ tí olúkúlùkù wọn ń jẹ́ tàbí ohun tó fi ń pè wọ́n. Bí àwọn sójà tó ń ṣègbọràn ni wọ́n rí, olúkúlùkù dúró sí àyè tirẹ̀, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà bó ṣe yẹ, nítorí Ọ̀gá wọn jẹ́ ẹni tó ní ọ̀pọ̀ yanturu ibú ‘agbára gíga,’ ó sì “ní okun inú nínú agbára.” Nítorí náà, ìdí wà fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn láti ní ìgbọ́kànlé. Ẹlẹ́dàá, tó ń pàṣẹ fáwọn ìràwọ̀, kúkú lágbára láti ṣètìlẹyìn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

25. Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí ìkésíni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó wà ní Aísáyà 40:26, ipa wo ló sì yẹ kó ní lórí wa?

25 Ta ní lè kọ̀ nínú wa láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ké sí wa láti ṣe, èyí tó wà nínú Aísáyà 40:26, pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò”? Àwárí àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà lóde òní ti fi hàn pé ìsálú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ tiẹ̀ tún jẹ́ ìyanu ńláǹlà ju bí wọ́n ṣe rò pé ó jẹ́ nígbà ayé Aísáyà. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà, tó máa ń fi awò-awọ̀nàjíjìn lílágbára tí wọ́n ní, wo ojú ọ̀run, fojú bù ú pé, àgbáálá ayé tó ṣeé fojú rí ní iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó pọ̀ tó áárùnlélọ́gọ́fà [125] bílíọ̀nù. Bẹ́ẹ̀, iye ìràwọ̀ tó wà nínú ọ̀kan ṣoṣo lára rẹ̀, ìyẹn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà, ni àwọn kan fojú bù pé ó jú ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù lọ! Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹ kó mú kí á túbọ̀ bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa látọkànwá, kí á sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ṣèlérí.

26, 27. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe bí ọ̀ràn ṣe rí lára àwọn ìgbèkùn tó wà ní Bábílónì, kí ni àwọn ohun tó sì yẹ kí wọ́n mọ̀?

26 Jèhófà mọ̀ pé bí ọdún bá ṣe ń gorí ọdún, tí àwọn Júù sì wà nígbèkùn, wọn yóò máa rẹ̀wẹ̀sì, ìyẹn ló ṣe mí sí Aísáyà láti kọ ọ̀rọ̀ afinilọ́kànbalẹ̀ yìí sílẹ̀ ṣáájú, ó ní: “Kí ni ìdí tí o fi ń sọ, ìwọ Jékọ́bù, tí o sì fi ń sọ̀rọ̀ jáde, ìwọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ọ̀nà mi pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà, àti pé ìdájọ́ òdodo sí mi ń yọ́ bọ́rọ́ mọ́ Ọlọ́run mi tìkára rẹ̀ lọ́wọ́’? Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Kò sí àwárí òye rẹ̀.”—Aísáyà 40:27, 28. *

27 Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà, èyí tó ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ìgbèkùn tó wà ní Bábílónì, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Àwọn kan rò pé Ọlọ́run àwọn ò rí “ọ̀nà” àwọn, ìyẹn ìgbésí ayé kòókòó jàn-án jàn án táwọn ń gbé, tàbí pé kò tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá. Wọ́n rò pé Jèhófà ò kọbi ara sí gbogbo bí wọ́n ṣe ń rẹ́ àwọn jẹ. Ló bá rán wọn létí ohun tó yẹ kí wọ́n ti mọ̀, ì báà jẹ́ látinú ìrírí ayé tiwọn alára, tàbí ó kéré tán látinú ìsọfúnni tí wọ́n bá láyé. Jèhófà lágbára láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Òun ni Ọlọ́run ayérayé, òun sì ni Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé pátá. Nípa bẹ́ẹ̀, agbára tó lò nígbà ìṣẹ̀dá ṣì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ digbídigbí, tó fi jẹ́ pé Bábílónì alágbára pàápàá kò kúrò níkàáwọ́ rẹ̀. Àárẹ̀ kì í mú irú Ọlọ́run yẹn rárá ni, débi pé yóò torí ìyẹn já àwọn èèyàn rẹ̀ kulẹ̀. Kò yẹ kí wọ́n retí pé àwọn yóò lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe àwọn nǹkan, nítorí pé ìmòye rẹ̀, tàbí ìjìnlẹ̀ òye, ìfòyemọ̀ àti agbára ìlóye rẹ̀, ré kọjá ohun tí wọ́n lè lóye.

28, 29. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé òun yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti rẹ̀? (b) Àpèjúwe wo ni Jèhófà lò láti fi bí òun ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ òun lágbára hàn?

28 Jèhófà wá gbẹnu Aísáyà ń bá a lọ láti fún àwọn ìgbèkùn tọ́ràn ti sú pátápátá yìí ní ìṣírí, ó ní: “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò sì kọsẹ̀ dájúdájú, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísáyà 40:29-31.

29 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀ràn ìrìn àjò tó nira, tí àwọn ìgbèkùn yóò ní láti rìn láti padà sílé, ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa fífún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára. Jèhófà rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé ó jẹ́ àṣà òun láti ṣèrànwọ́ fáwọn ẹni tó ti rẹ̀ tó bá yíjú sí òun fún ìtìlẹyìn. Àní ó tiẹ̀ lè rẹ àwọn tó ń ta kébékébé nínú ọmọ ènìyàn, ìyẹn “àwọn ọmọdékùnrin” àti “àwọn ọ̀dọ́kùnrin,” kí ó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọsẹ̀ pàápàá. Síbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò pèsè agbára fún ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, ìyẹn agbára láti sáré àti láti rìn láìkáàárẹ̀. Fífò tí ìdí ń fò fẹẹ bíi pé kò tiẹ̀ ṣe ìsapá kankan, ìyẹn ẹyẹ alágbára tó lè máa rá bàbà fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdáwọ́dúró, ni Jèhófà lò láti fi ṣàpèjúwe bí òun ṣe máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ òun lágbára. * Níwọ̀n bí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ti ń retí àtirí irú ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kò sí ìdí fún wọn láti sọ̀rètí nù.

30. Báwo ní àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ṣe lè rí ìtùnú gbà látinú àwọn ẹsẹ tó parí Aísáyà orí ogójì?

30 Àwọn ẹsẹ tó parí Aísáyà orí ogójì yìí ní ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú fáwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan burúkú yìí. Bí pákáǹleke àti àwọn ìṣòro tó ń fẹ́ máa páni láyà ṣe pọ̀ gan-an yìí, ìfọ̀kànbalẹ̀ ló máa ń jẹ́ fúnni láti mọ̀ pé kò sí ìṣòro tí a ń forí tì tàbí ìwà ìyànjẹ tí wọ́n ń hù sí wa tí Ọlọ́run wa kò rí. Kí ó dá wa lójú pé Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, Ẹni tí “òye rẹ̀ ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ,” yóò mú gbogbo ìwà ìyànjẹ kúrò lákòókò tirẹ̀ àti lọ́nà tirẹ̀. (Sáàmù 147:5, 6) Àmọ́ kó tó di ìgbà náà, kì í ṣe agbára tiwa la óò máa lò láti máa fi forí tì í. Jèhófà, ẹni tí agbára rẹ̀ ò lè pin láéláé, lè pèsè agbára, àní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lásìkò àdánwò.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

31. Fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì, ìlérí ìmọ́lẹ̀ wo ní ń bẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, kí sì ni a lè gbọ́kàn lé pátápátá?

31 Ronú nípa àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Jerúsálẹ́mù wọn ọ̀wọ́n wà láhoro ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà lọ́hùn-ún, tẹ́ńpìlì rẹ̀ sì jẹ́ àlàpà. Ní tiwọn, ìlérí atuni-nínú tó kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí ní ń bẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ìyẹn ni pé, Jèhófà yóò mú wọn padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn! Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ lọ sílé, ó fi hàn pé òun ni Ẹni tí ń mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Àwa pẹ̀lú lè gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. Àwọn ìlérí Ìjọba rẹ̀, èyí tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ lọ́nà tó wúni lórí gidigidi, yóò ṣẹ lóòótọ́. Ìhìn rere gbáà ni, àní ìhìn ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo aráyé!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa pípalẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jèhófà. (Aísáyà 40:3) Ṣùgbọ́n àwọn ìwé Ìhìn Rere lo àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fún ohun tí Jòhánù Oníbatisí ṣe, bó ṣe ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù Kristi. Ohun tó jẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé onímìísí tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lò ó lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe ni Jésù ṣojú fún Bàbá rẹ̀, tó sì tún wá lórúkọ Bàbá rẹ̀.—Jòhánù 5:43; 8:29.

^ ìpínrọ̀ 18 Wọ́n ti ṣírò rẹ̀ pé “ìwọ̀n àwọn agbami òkun jẹ́ nǹkan bí 1.35 quintillion (1.35 x 1018) tọ́ọ̀nù lórí ìwọ̀n, ìyẹn ni pé, ká sọ pé a pín ìwọ̀n gbogbo Ilẹ̀ Ayé sí nǹkan bí ọ̀nà egbèjìlélógún [4,400], agbami òkun yóò kó ìdá kan rẹ̀.”—Encarta 97 Encyclopedia.

^ ìpínrọ̀ 20 Ìwé The Expositor’s Bible Commentary sọ pé: “Nínú ètò káràkátà inú ọjà ní ìhà Ìlà Oòrùn Ayé, bí wọ́n bá fẹ́ wọn ẹran tàbí èso lórí òṣùwọ̀n, wọn kì í ka ẹ̀kán omi kíún tó bá wà nínú korobá òṣùwọ̀n tàbí ekuru díẹ̀ tó bá wà lórí òṣùwọ̀n sí nǹkan kan.”

^ ìpínrọ̀ 26 Nínú Aísáyà 40:28, gbólóhùn náà, “àkókò tí ó lọ kánrin” túmọ̀ sí “títí láé,” nítorí Jèhófà ni “Ọba ayérayé.”—1 Tímótì 1:17.

^ ìpínrọ̀ 29 Agbára tí ìdí ń lò láti fi máa rá bàbà kì í tó nǹkan. Àwọn afẹ́fẹ́ olóoru tó ń fẹ́ lọ sókè sójú sánmà ló máa ń fọgbọ́n lò láti fi fò.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 405]

Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́

Aísáyà fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ tó máa ń gbé àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn rẹ̀ sí oókan àyà rẹ̀. (Aísáyà 40:10, 11) Ó dájú pé ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń ṣe láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni Aísáyà lò nínú àpẹẹrẹ tó fani mọ́ra yìí. Alákìíyèsí kan láyé òde òní, tó kíyè sí bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Hámónì ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ṣe máa ń ṣe, ròyìn pé: “Ńṣe ni olùṣọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan máa ń ṣọ́ agbo tirẹ̀ lójú méjèèjì láti lè mọ bí wọ́n ti ń ṣe sí. Tó bá wá rí àṣẹ̀ṣẹ̀bí ọ̀dọ́ àgùntàn, inú ìṣẹ́po . . . ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ló máa ń gbé e sí, nítorí pé kò tíì lè lágbára tó láti lè tọ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn. Bó bá di pé oókan àyà rẹ̀ kún, a máa gbé ọ̀dọ́ àgùntàn sí èjìká, tí yóò dì wọ́n mú ní ẹsẹ̀, tàbí kó fi àpò tàbí apẹ̀rẹ̀ gbé wọn sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, títí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn lẹ̀jẹ́lẹ̀jẹ́ yẹn yóò fi lè kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú ìyá wọn.” Kò ha tuni nínú láti mọ̀ pé irú Ọlọ́run tó ń ṣìkẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ́ẹ̀ là ń sìn?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 412]

Báwo Layé Ṣe Rí?

Láyé àtijọ́, ohun tí àwọn èèyàn lápapọ̀ gbà gbọ́ ni pé pẹrẹsẹ layé rí. Àmọ́, láti ọ̀rúndún kẹfà lọ́hùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa ni onímọ̀ èrò orí ará ilẹ̀ Gíríìkì náà, Pythagoras ti gbé àbá jáde pé ilẹ̀ ayé ní láti jẹ́ òbìrí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣáájú kí Pythagoras tó gbé àbá tirẹ̀ kalẹ̀ ni wòlíì Aísáyà ti fi ìdánilójú sọ ọ́ kedere kèdèrè pé: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 40:22) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, chugh, táa túmọ̀ sí “òbìrìkìtì” níhìn-ín, tún ṣeé túmọ̀ sí “òbìrí.” Ẹ sì wá wò ó, kìkì ohun tó bá jẹ́ òbìrí ló ń ṣe bìrìkìtì ní ìhà yòówù kí a ti wò ó.* Nípa bẹ́ẹ̀, wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ gbólóhùn tó yè kooro, tó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu, tí kò ní kọ̀lọ̀kọ́lọ́ ìtàn àròsọ kankan nínú, tó sì lọ jìnnàjìnnà ré kọjá ìgbà ayé tirẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

Táa bá ní ká sọ bó ṣe jẹ́ gan-an, kẹrẹbutu ni ayé rí. Ṣe ló tẹ́ pẹrẹsẹ díẹ̀ lókè àti nísàlẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 403]

Jòhánù Oníbatisí ni ohùn ẹnì kan tí “ń ké jáde ní aginjù”