Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe

Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe

Orí Kejìlélógún

Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe

Aísáyà 28:1–29:24

1, 2. Èé ṣe tí kò fi sí ìfòyà fún Ísírẹ́lì àti Júdà?

ÌFÒYÀ ò sí fún Ísírẹ́lì àti Júdà fún ìgbà kúkúrú kan. Àwọn aṣáájú wọn ti lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi tó sì lágbára jù wọ́n lọ mulẹ̀ kí wọ́n bàa lè rí ààbò nínú ayé eléwu. Samáríà, olú ìlú Ísírẹ́lì yíjú sí Síríà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, nígbà tí Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Júdà, gbẹ́kẹ̀ lé Ásíríà aláìláàánú.

2 Àwọn kan ní ìjọba àríwá sì tún lè retí pé kí Jèhófà dáàbò bo àwọn, láfikún sí ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ mulẹ̀, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń lo ère ọmọ màlúù wúrà nínú ìjọsìn wọn. Bákan náà ló ṣe dá Júdà lójú pé kò sí bí Jèhófà ò ṣe ní dáàbò bo òun. Àbí Jerúsálẹ́mù, olú ìlú wọn, kọ́ ni tẹ́ńpìlì Jèhófà wà ni? Àmọ́ o, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ tí yóò jẹ́ ìyàlẹ́nu fún orílẹ̀-èdè méjèèjì. Jèhófà mí sí Aísáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí yóò dà bí ohun àjèjì gbáà lójú àwọn ènìyàn rẹ̀ oníwàkiwà. Àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì gidi fún gbogbo èèyàn lónìí sì wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

“Àwọn Ọ̀mùtípara Éfúráímù”

3, 4. Kí ni ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá fi ń yangàn?

3 Ọ̀rọ̀ tó ṣeni ní kàyéfì ni Aísáyà fi bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí, ó ní: “Ègbé ni fún adé ọlọ́lá ògo ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúráímù, àti ìtànná rírọ ti ìṣelóge ẹwà rẹ̀ tí ó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn! Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tí ó lágbára tí ó sì ní okun inú. Bí ìjì yìnyín tí ń sán ààrá, . . . ṣe ni òun yóò fi ipá ṣe jíjù sísàlẹ̀ sórí ilẹ̀. Ẹsẹ̀ ni a ó fi tẹ àwọn adé ọlọ́lá-ògo ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúráímù mọ́lẹ̀.”—Aísáyà 28:1-3.

4 Éfúráímù tó lókìkí jù lọ nínú ẹ̀yà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó wà níhà àríwá, ló wá dúró fún gbogbo ìjọba Ísírẹ́lì báyìí. Ibi tó dára tó sì yọ sókè gedegbe ní “orí àfonífojì ọlọ́ràá,” ni Samáríà olú ìlú rẹ̀ wà. Ṣe ni àwọn aṣáájú Éfúráímù ń fi “adé ọlọ́lá ògo” pé àwọn ti gbòmìnira kúrò lábẹ́ àwọn ọba tó ń jẹ láti ìlà Dáfídì ní Jerúsálẹ́mù yangàn. Ṣùgbọ́n, “ọ̀mùtípara” ni wọ́n, ńṣe ni lílẹ̀dí àpò tí àwọn àti Síríà jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ ní ìdojú ìjà kọ Júdà ń pa wọ́n bí ọtí nípa tẹ̀mí. Àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀ làwọn tó ń ṣígun bọ̀ wá bá wọn yóò fẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ láìpẹ́.—Fi wé Aísáyà 29:9.

5. Inú ewu wo ni Ísírẹ́lì wà, ṣùgbọ́n ìrètí wo ni Aísáyà sọ pé ó wà?

5 Éfúráímù kò mọ̀ pé inú ewu lòun wà. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Òdòdó rírọ ti ìṣelóge ẹwà rẹ̀ tí ó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá yóò sì dà bí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n ṣáájú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, èyí tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí ń wòran rí i, nígbà tí ó ṣì wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, òun a gbé e mì gbìnrín.” (Aísáyà 28:4) Bí òkèlè dídùn téèyàn ń gbé mì káló ni Éfúráímù yóò ṣe kó sọ́wọ́ Ásíríà. Ṣé pé ìrètí wọn ti pin nìyẹn? Tóò, bí Aísáyà ṣe ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìdájọ́ yìí náà ló ṣe ń fi ọ̀rọ̀ ìrètí kún un gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ àtẹ̀yìnwá. Bí orílẹ̀-èdè yẹn bá tilẹ̀ ṣubú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ olóòótọ́ yóò làájá. Ó ní: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò dà bí adé ìṣelóge àti bí òdòdó ẹ̀yẹ ti ẹwà fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó nínú ìdájọ́, àti bí agbára ńlá fún àwọn tí ń lé ìjà ogun padà ní ẹnubodè.”—Aísáyà 28:5, 6.

“Wọ́n Ti Ṣáko Lọ”

6. Ìgbà wo ni Ísírẹ́lì pa run, èé ṣe tí kò fi yẹ kí Júdà bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́?

6 Ọdún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa lọjọ́ ẹ̀san dé bá Samáríà, nígbà tí àwọn ará Ásíríà run ilẹ̀ náà, tí orílẹ̀-èdè tó dá dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba àríwá kò fi wá sí mọ́. Júdà wá ńkọ́? Ńṣe làwọn ará Ásíríà á gbógun ja ilẹ̀ rẹ̀, lẹ́yìn náà làwọn ará Bábílónì yóò wá pa olú ìlú rẹ̀ run. Àmọ́ ṣá o, tẹ́ńpìlì Júdà àti ipò àlùfáà yóò ṣì wà nígbà ayé Aísáyà, àwọn wòlíì rẹ̀ yóò ṣì máa sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú. Ṣé kí Júdà máa fi ìparun tó ń bọ̀ lórí èkejì rẹ̀ níhà àríwá yọ̀ ọ́ ni? Rárá o! Jèhófà ṣì ń bọ̀ wá mú kí Júdà àti àwọn aṣáájú rẹ̀ jẹ́jọ́ ìwà àìgbọràn àti àìnígbàgbọ́ wọn bákan náà.

7. Ọ̀nà wo làwọn aṣáájú Júdà gbà mutí yó, kí ló sì yọrí sí?

7 Aísáyà wá darí ọ̀rọ̀ sí Júdà bó ṣe ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Àti àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú—nítorí wáìnì, wọ́n ti ṣáko lọ àti nítorí ọtí tí ń pani, wọ́n ti rìn gbéregbère. Àlùfáà àti wòlíì—wọ́n ti ṣáko lọ nítorí ọtí tí ń pani, ìdàrúdàpọ̀ ti bá wọn nítorí wáìnì, wọ́n ti rìn gbéregbère nítorí ọtí tí ń pani; wọ́n ti ṣáko lọ nínú ìríran wọn, wọ́n ti ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ní ti ìpinnu. Nítorí pé gbogbo àwọn tábìlì pàápàá ti kún fún èébì ẹlẹ́gbin—kò sí ibi tí kò sí.” (Aísáyà 28:7, 8) Ó mà ríni lára o! Ohun tó burú jáì ni pàápàá, pé kéèyàn mutí para nínú ilé Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọtí ń pa àwọn wòlíì àti àlùfáà wọ̀nyí nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé, níní tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìmùlẹ̀ ènìyàn púpọ̀ jù ti ra wọn níyè. Èrò tí wọ́n fi tan ara wọn jẹ ni pé kò tún sọ́nà tó bọ́gbọ́n mu yàtọ̀ sí ìyẹn, bóyá wọ́n ń rò ó pé ńṣe làwọn dọ́gbọ́n ìyẹn kalẹ̀ ná, tó bá wá di pé ààbò Jèhófà ò tó, àwọn yóò tètè fi ìyẹn tì í lẹ́yìn. Bí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí ṣe ti yó bìnàkò nípa tẹ̀mí, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bi onírúurú ọ̀rọ̀ ìṣọ̀tẹ̀ aláìmọ́ jáde lẹ́nu, tó ń fi hàn pé wọn ò ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run rárá.

8. Ìhà wo ni wọ́n kọ sí ọ̀rọ̀ Aísáyà?

8 Ìhà wo làwọn aṣáájú Júdà kọ sí ìkìlọ̀ Jèhófà? Ńṣe ni wọ́n ń fi Aísáyà ṣẹlẹ́yà, tí wọ́n sì ń bínú pé ó ń sọ̀rọ̀ sí àwọn bíi pé ìkókó làwọn, wọ́n ní: “Ta ni ènìyàn yóò fún ní ìtọ́ni nínú ìmọ̀, ta sì ni ènìyàn yóò mú lóye ohun tí a ti gbọ́? Àwọn tí a já lẹ́nu wàrà ni bí, àwọn tí a gbà lẹ́nu ọmú ni bí? Nítorí pé ó jẹ́ ‘àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n, okùn ìdiwọ̀n lé okùn ìdiwọ̀n, díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.’” (Aísáyà 28:9, 10) Àsọtúnsọ tó ṣàjèjì gbáà lọ̀rọ̀ Aísáyà jẹ́ létí wọn! Ohun kan náà ló ń sọ ṣáá, ó ń sọ pé: ‘Èyí ni Jèhófà pa láṣẹ! Èyí ni Jèhófà pa láṣẹ! Èyí ni ìlànà Jèhófà! Èyí ni ìlànà Jèhófà!’ * Àmọ́ láìpẹ́, Jèhófà yóò dìde sáwọn èèyàn Júdà, yóò “bá” wọn “sọ̀rọ̀” lọ́nà tó kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì, ìyẹn àwọn ará ilẹ́ òkèèrè tó ń sọ èdè àjèjì pọ́nbélé, ni òun yóò rán sí wọn. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọ̀nyẹn ni yóò kúkú wá mú kí “àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ” tí Jèhófà pa ní ìmúṣẹ, Júdà yóò sì wá ṣubú.—Ka Aísáyà 28:11-13.

Àwọn Ọ̀mùtípara Nípa Tẹ̀mí Lóde Òní

9, 10. Ìgbà wo lọ̀rọ̀ Aísáyà ní ìtumọ̀ fún àwọn ìran ẹ̀yìn ìgbà tirẹ̀, báwo ló sì ṣe nítumọ̀ fún wọn?

9 Ṣé orí Ísírẹ́lì àti Júdà àtijọ́ nìkan ni ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mọ sí ni? Rárá o! Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, wọ́n sì lò ó fún orílẹ̀-èdè tó wà nígbà ayé tiwọn. (Aísáyà 29:10, 13; Mátíù 15:8, 9; Róòmù 11:8) Lóde òní, bákan náà, ohun kan ti wáyé, tó dà bíi ti ìgbà ayé Aísáyà.

10 Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ló ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òṣèlú. Wọ́n wá ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kiri bíi tàwọn ọ̀mùtípara ní Ísírẹ́lì àti Júdà, wọ́n ń dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, tí inú wọ́n sì ń dùn ṣìnkìn pé àwọn tí ayé yìí kà sẹ́ni ńláńlá ń kàn sí àwọn. Èyí tí wọn ì bá sì fi máa sọ ojúlówó òtítọ́ látinú Bíbélì, ohun àìmọ̀ ni wọ́n ń sọ lẹ́nu. Bàìbàì ni wọ́n ń ríran nípa tẹ̀mí, kò sì sí bí wọn ó ṣe ṣamọ̀nà aráyé láìní kó wọn sí yọ́yọ́.—Mátíù 15:14.

11. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

11 Kí ló máa ń jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá pe àfiyèsí wọn sí Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìrètí tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà fún aráyé? Òye rẹ̀ kì í yé wọn o. Lójú tiwọn, atata-n-toto bíi tàwọn ìkókó làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ṣáá. Ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí ń fojú tín-ín-rín àwọn ońṣẹ́ wọ̀nyí, tí wọ́n sì ń ṣáátá wọn. Bíi tàwọn Júù ìgbà ayé Jésù làwọn náà ṣe rí, wọn kò fẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọn ò sì fẹ́ káwọn ọmọ ìjọ wọ́n gbọ́ nípa ẹ̀. (Mátíù 23:13) Ìdí nìyẹn táa fi ń sọ fún wọn pé kéku ilé ó gbọ́ kó sọ fún toko o, Jèhófà ò kàn ní fọ̀ràn mọ sí kìkì bó ṣe ń gbẹnu àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ tí kò lè ṣèpalára kankan sọ̀rọ̀ o. Ọjọ́ kan á jọ́kan tí gbogbo àwọn tí kò jọ̀wọ́ ara wọn fún Ìjọba Ọlọ́run yóò dẹni ‘tí a ṣẹ́, tí a dẹkùn sílẹ̀ dè, tí a sì mú,’ àní tí a pa rẹ́ ráúráú pàápàá.

Àwa Bá Ikú Dá Májẹ̀mú’

12. Kí ni májẹ̀mú tí Júdà lóun “bá Ikú dá”?

12 Aísáyà ń bá ìkéde rẹ̀ lọ pé: “Ẹ sọ pé: ‘Àwa ti bá Ikú dá májẹ̀mú; a sì ti fìdí ìran kan múlẹ̀ pẹ̀lú Ṣìọ́ọ̀lù; ìkún omi ayaluni lójijì tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé yóò kọjá, kì yóò dé ọ̀dọ̀ wa, nítorí pé a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, inú èké sì ni a fi ara wa pa mọ́ sí.’” (Aísáyà 28:14, 15) Ńṣe làwọn aṣáájú Júdà ń fọ́nnu pé mímulẹ̀ táwọn bá àwọn orílẹ̀-èdè mulẹ̀ kò ní jẹ́ kẹ́nikẹ́ni lè rí àwọn ṣẹ́gun. Èrò wọn ni pé àwọn ti “bá Ikú dá májẹ̀mú” pé kó má ṣe yọ àwọn lẹ́nu rárá. Ṣùgbọ́n ibi ìsádi ẹ̀tàn wọn kò ní dáàbò bò wọ́n. Ìmùlẹ̀ irọ́ ni ìmùlẹ̀ wọn, irọ́ gbuu. Bákan náà ni lóde òní, wọlé-wọ̀de Kirisẹ́ńdọ̀mù pẹ̀lú àwọn aṣáájú ayé kò ní dáàbò bò ó nígbà tó bá tákòókò tí Jèhófà yóò pè é wá jẹ́jọ́. Kódà, ìyẹn gan-an ni yóò ṣekú pa á.—Ìṣípayá 17:16, 17.

13. Ta ni “òkúta tí a ti dán wò,” báwo sì ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀?

13 Ibo ló wá yẹ kí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí yíjú sí? Aísáyà wá ṣàkọsílẹ̀ ìlérí Jèhófà pé: “Kíyè sí i, èmi yóò fi òkúta kan lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ní Síónì, òkúta tí a ti dán wò, igun ilé ṣíṣeyebíye ti ìpìlẹ̀ dídájú. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lo ìgbàgbọ́ tí ẹ̀rù jìnnìjìnnì yóò bà. Dájúdájú, èmi yóò sì fi ìdájọ́ òdodo ṣe okùn ìdiwọ̀n, èmi yóò sì fi òdodo ṣe ohun èlò ìmú-nǹkan-tẹ́jú; yìnyín yóò sì gbá ibi ìsádi irọ́ lọ, àní omi yóò sì kún bo ibi ìlùmọ́ pàápàá.” (Aísáyà 28:16, 17) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Hesekáyà olóòótọ́ Ọba jọba ní Síónì, tó fi jẹ́ pé, dídá tí Jèhófà dá sí ọ̀ràn rẹ̀ ló gba ìjọba rẹ̀ sílẹ̀, tí kì í ṣe pé àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀ tí wọ́n jọ mulẹ̀ ló wá gbèjà rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe Hesekáyà ló mú ọ̀rọ̀ onímìísí yẹn ṣẹ. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí yọ, ó sọ pé Jésù Kristi, tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Hesekáyà, ni “òkúta tí a ti dán wò” yẹn, àti pé kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ láti bẹ̀rùkẹ́rù. (1 Pétérù 2:6) Ẹ wá wo bó ṣe bani lọ́kàn jẹ́ tó, pé àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù tó pe ara wọn ní Kristẹni lọ ń ṣe ohun tí Jésù kọ̀ láti ṣe! Òkìkí àti agbára ni wọ́n ń wá nínú ayé yìí dípò tí wọn ì bá fi dúró kí Jèhófà mú Ìjọba rẹ̀, tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀, dé.—Mátíù 4:8-10.

14. Ìgbà wo ni “májẹ̀mú” tí Júdà “bá Ikú dá” yóò di títúká?

14 Nígbà tí “ìkún omi ayaluni lójijì,” ìyẹn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì, bá kọjá ní ilẹ̀ náà, Jèhófà yóò wá mú kí àṣírí ààbò tí Júdà fọkàn sí lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tú, pé irọ́ gbuu ni. Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, májẹ̀mú tí ẹ bá Ikú dá ni a ó sì tú ká . . . Ìkún omi ayaluni lójijì tí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀, nígbà tí ó bá kọjá—ẹ ó sì di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún un pẹ̀lú. Nígbàkúùgbà tí ó bá ń kọjá, . . . kì yóò sì jẹ́ ohun mìíràn bí kò ṣe ìdí fún ìwárìrì láti mú kí àwọn mìíràn lóye ohun tí wọ́n ti gbọ́.” (Aísáyà 28:18, 19) Dájúdájú, ẹ̀kọ́ ńláǹlà la óò rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n tún lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé ìmùlẹ̀ tí wọ́n bá àwọn orílẹ̀-èdè ṣe.

15. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àìtó ààbò Júdà?

15 Ẹ wo ibi tí àwọn aṣáájú Júdà wọ̀nyí wá bá ara wọn wàyí. Ó ní: “Àga ìrọ̀gbọ̀kú ti kúrú jù fún nína ara ẹni lé, aṣọ híhun pàápàá sì tẹ́rẹ́ jù nígbà tí ènìyàn bá fi bora.” (Aísáyà 28:20) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fẹ́ dùbúlẹ̀ láti sinmi ṣùgbọ́n tí nǹkan ò rọgbọ. Ó wá di pé, yálà kí ẹsẹ̀ wọ́n yọ síta sínú òtútù, káṣọ ó má bò ó, tàbí kí wọ́n ká ẹsẹ̀ kò, kí aṣọ tún ti ṣe tẹ́ẹ́rẹ́ ju èyí tó lè bo gbogbo ara wọn tí ara wọn ó fi lè móoru. Bí nǹkan ò ṣe rọgbọ gẹ́lẹ́ láyé ìgbà Aísáyà nìyẹn. Bí nǹkan sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn fẹ́nikẹ́ni tó bá lọ gbẹ́kẹ̀ lé ààbò irọ́ lọ́dọ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ó mà kúkú kóni nírìíra o, pé àwọn kan nínú àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù tìtorí ìṣèlú lọ ń lọ́wọ́ nínú ìwà ìkà tó burú jáì, irú bíi kí ìran kan dìde sí ìran kejì láti run wọn ráúráú, tàbí kí ẹ̀yà kan gbéra láti pa ìkejì rẹ́ pátápátá!

‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe

16. Kí ni ‘ìṣe tó ṣàjèjì’ tí Jèhófà yóò ṣe, èé sì ti ṣe tí iṣẹ́ rẹ̀ yìí fi kàmàmà?

16 Òdìkejì gbáà lọ̀ràn máa bá yọ sí àwọn aṣáájú ìsìn Júdà. Ohun tó ṣàjèjì sí àwọn ọ̀mùtípara Júdà ni Jèhófà máa wá ṣe. Ó ní: “Jèhófà yóò dìde gẹ́gẹ́ bí ti Òkè Ńlá Pérásímù, a ó ru ú sókè gẹ́gẹ́ bí ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ tí ó wà nítòsí Gíbéónì, kí ó lè ṣe ìṣe rẹ̀—ìṣe rẹ̀ ṣàjèjì—kí ó sì lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀—iṣẹ́ rẹ̀ kàmàmà.” (Aísáyà 28:21) Nígbà ayé Dáfídì Ọba, Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn Filísínì lọ́nà kíkàmàmà ní Òkè Ńlá Pérásímù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó rẹlẹ̀ ní Gíbéónì. (1 Kíróníkà 14:10-16) Láyé Jóṣúà, ó tiẹ̀ mú kí oòrùn dúró sójú kan lórí ìlú Gíbéónì kí Ísírẹ́lì bàa lè ṣẹ́gun àwọn Ámórì porogodo. (Jóṣúà 10:8-14) Áà, ìyẹn tún ṣàjèjì gan-an o! Jèhófà tún wá fẹ́ jà báyìí o, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwọn tó láwọn jẹ́ èèyàn rẹ̀ ló fẹ́ bá jà. Kí ló tún wá fẹ́ ṣàjèjì tàbí tó tún fẹ́ kàmàmà tó ìyẹn ná? Kò sì ní ṣàì ṣàjèjì táa bá rántí pé Jerúsálẹ́mù ni ojúkò ìjọsìn Jèhófà àti ìlú ọba tí Jèhófà fòróró yàn. Títí dìgbà tí à ń wí yìí o, wọ́n ò tíì gbàjọba lọ́wọ́ ìlà ìdílé Dáfídì ní Jerúsálẹ́mù rí. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà á ṣe ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì’ yìí dandan ni.—Fi wé Hábákúkù 1:5-7.

17. Kí ni ipa tí ìfinirẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà yóò ní lórí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?

17 Nítorí náà, Aísáyà ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Wàyí o, ẹ má fi ara yín hàn ní afinirẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, kí ọ̀já yín má bàa lágbára, nítorí pé ìparun pátápátá ń bẹ, àní ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí, tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, fún gbogbo ilẹ̀ náà.” (Aísáyà 28:22) Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Aísáyà sọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú yẹn ń fini rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà. Ọ̀dọ̀ Jèhófà, tí àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn bá dá májẹ̀mú, ló ti gbọ́ ọ. Bákan náà làwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ń fini rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà lónìí tí wọ́n bá ti gbọ́ nípa ‘ìṣe tó ṣàjèjì’ tí Jèhófà yóò ṣe. Àní wọ́n a tiẹ̀ bínú, wọn a faraya. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òótọ́ ni iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ o. Ó kúkú wà nínú Bíbélì, ìwé yẹn sì làwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn sọ pé àwọn ń ṣojú fún.

18. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń báni wí ní ìwọ̀n tó yẹ gẹ́lẹ́?

18 Ní ti àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn, ohun tí Jèhófà máa ṣe ni pé yóò tọ́ wọn sọ́nà, yóò sì tún ṣojú rere sí wọn padà. (Ka Aísáyà 28:23-29.) Bí àgbẹ̀ ṣe máa ń fi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ pakà rẹ̀ nígbà ìpakà àwọn wórókà bíi kúmínì tó gbẹgẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fún olúkúlùkù ní ìbáwí tó tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ bá ṣe rí. Kì í kùgìrì báni wí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọba ìkà, bí kò ṣe pé ó máa ń ṣe àwọn ohun tó lè mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ ọ̀hún ronú kó sì pìwà dà. Dájúdájú, bí èèyàn bá kọbi ara sí ohun tí Jèhófà fi fà á létí, ìrètí ń bẹ fún un. Bákan náà ni lóde òní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó lè yẹ ìdájọ́ tí ń bọ̀ wá sórí Kirisẹ́ńdọ̀mù, olúkúlùkù ẹni tó bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún Ìjọba Jèhófà lè mórí bọ́ nínú ìdájọ́ tí ń bọ̀ yẹn.

Ègbé Ni fún Jerúsálẹ́mù!

19. Ọ̀nà wo ni Jerúsálẹ́mù yóò gbà dà bí “ibi ìdáná pẹpẹ,” ìgbà wo nìyẹn ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀?

19 Ọ̀rọ̀ kí ni Jèhófà wá sọ wàyí o? Ó ní: “Ègbé ni fún Áríélì, fún Áríélì, ìlú tí Dáfídì dó sí! Ẹ fi ọdún kún ọdún; ẹ jẹ́ kí àwọn àjọyọ̀ lọ yí ká. Ṣe ni èmi yóò sì mú kí nǹkan le dan-in dan-in fún Áríélì, ìṣọ̀fọ̀ àti ìdárò yóò sì wà, yóò sì dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.” (Aísáyà 29:1, 2) Ó jọ pé “Ibi Ìdáná Pẹpẹ Ọlọ́run” ni “Áríélì” túmọ̀ sí, ó sì dájú pé Jerúsálẹ́mù ló tọ́ka sí níhìn-ín. Ibẹ̀ ni tẹ́ńpìlì àti pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ wà. Àwọn Júù a máa lọ ṣe àjọyọ̀, wọn a sì máa lọ rúbọ déédéé níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà, ṣùgbọ́n inú Jèhófà kò dùn sí ìjọsìn wọn. (Hóséà 6:6) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ pé “ibi ìdáná pẹpẹ” irú mìíràn ni ìlú yẹn fúnra rẹ̀ máa dà. Ńṣe lẹ̀jẹ̀ àti iná á bo ibẹ̀ bó ṣe máa ń rí níbi pẹpẹ. Jèhófà tiẹ̀ kúkú ṣàpèjúwe bó ṣe máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Èmi yóò sì dó tì ọ́ ní ìhà gbogbo, èmi yóò sì fi igi ọgbà sàga tì ọ́, èmi yóò sì gbé àwọn agbàrà dìde tì ọ́. Ìwọ yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni ìwọ yóò ti máa sọ̀rọ̀, bí ẹni pé láti inú ekuru sì ni àsọjáde rẹ yóò ti máa dún lọ́nà rírẹlẹ̀.” (Aísáyà 29:3, 4) Ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn ṣẹ sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì sàga ti ìlú yẹn tí wọ́n sì pa á run, tí wọ́n sì jó tẹ́ńpìlì rẹ̀. Ṣe ni wọ́n wó Jerúsálẹ́mù palẹ̀ bẹẹrẹ bí ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ ọ lé.

20. Kí ni yóò jẹ́ àtúbọ̀tán àwọn ọ̀tá Ọlọ́run?

20 Kó tó di ọjọ́ àjálù yìí, àwọn tó ń pa Òfin Jèhófà mọ́ máa ń jọba ní Júdà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí ló sì máa ń ṣẹlẹ̀? Ìyẹn ń jẹ́ kí Jèhófà jà fáwọn èèyàn rẹ̀. Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn ọ̀tá bo ilẹ̀ náà, ṣe ni wọ́n ń rí bí “ekuru lẹ́búlẹ́bú” àti “ìyàngbò.” Bó bá ti tákòókò lójú Jèhófà, ńṣe ló máa ń tú wọn ká, yóò lo “ààrá àti pẹ̀lú ìmìtìtì àti pẹ̀lú ìró ńlá, ẹ̀fúùfù oníjì àti ìjì líle, àti ọwọ́ iná tí ń jẹni run.”—Aísáyà 29:5, 6.

21. Ṣàlàyé àpèjúwe tó wà nínú Aísáyà 29:7, 8.

21 Àwọn ọ̀tá lè máa fi ìháragàgà retí ìgbà táwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí kó Jerúsálẹ́mù lẹ́rù, táwọn ó máa kó ìkógun wọ̀ǹtìwọ̀ǹtì. Àmọ́, àṣìṣe gbáà ni wọ́n ṣe! Bí ìgbà tẹ́ni ebi ń pa ń lálàá ni, tó ń jẹnu wúyẹ́ bó ṣe ń jàsè àjẹranjú lójú àlá, tó sì tají padà sínú ebi, bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀tá Júdà kò ṣe ní rí àsè tí ọ̀fun wọn ń dá tòlótòló sí jẹ láé. (Ka Aísáyà 29:7, 8.) Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà lábẹ́ Senakéríbù, nígbà tó ń lérí tó ń léka sí Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Hesekáyà Ọba olóòótọ́. (Aísáyà orí kẹrìndínlógójì àti ikẹtàdínlógójì) Òru ọjọ́ kan ṣoṣo làwọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà, tó jẹ́ erìkìnà ẹ̀dá, ṣíyán láìdúró gbọbẹ̀, láìsì jẹ́ pé ọmọ aráyé kankan gbọ́wọ́ sókè sí wọn, tó tún jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára àwọn akọni rẹ̀ ló kú síbẹ̀! Bí ìrètí ìṣẹ́gun ṣe máa já sí pàbó nìyẹn fáwọn erìkìnà ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù nì, nígbà tí wọ́n bá fi máa dìde ìjà sí àwọn èèyàn Jèhófà láìpẹ́.—Ìsíkíẹ́lì 38:10-12; 39:6, 7.

22. Ipa wo ni àmupara tí Júdà mu nípa tẹ̀mí ní lórí rẹ̀?

22 Lákòókò tí Aísáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ apá yìí, àwọn aṣáájú Júdà kò ní irú ìgbàgbọ́ tí Hesekáyà ní. Wọ́n ti fi ìmùlẹ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè aláìmọ Ọlọ́run rọ ara wọn yó bìnàkò nípa tẹ̀mí. Ó ní: “Ẹ dúró pẹ́, kí kàyéfì sì ṣe yín; ẹ sọ ara yín di afọ́jú, kí ẹ sì fọ́jú. Wọ́n ti yó, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú wáìnì; wọ́n ń rìn tàgétàgé, ṣùgbọ́n kì í ṣe nítorí ọtí tí ń pani.” (Aísáyà 29:9) Òye ìran tí Jèhófà fi han wòlíì rẹ̀ tòótọ́ kò lè yé àwọn aṣáájú wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti mutí para nípa tẹ̀mí. Aísáyà sọ pé: “Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra lù yín; ó sì pa ojú yín dé, tí í ṣe àwọn wòlíì, ó sì ti bo orí yín pàápàá, tí í ṣe àwọn olùríran. Ìran ohun gbogbo sì dà bí ọ̀rọ̀ ìwé tí a ti fi èdìdì dì fún yín, èyí tí wọ́n fi fún ẹni tí ó mọ̀wé, pé: ‘Jọ̀wọ́, ka èyí sókè,’ yóò sì sọ pé: ‘Èmi kò lè kà á, nítorí pé a ti fi èdìdì dì í’; a ó sì fi ìwé náà fún ẹni tí kò mọ̀wé, ẹnì kan wí pé: ‘Jọ̀wọ́, ka èyí sókè,’ yóò sì sọ pé: ‘Èmi kò mọ̀wé rárá.’”—Aísáyà 29:10-12.

23. Èé ṣe tí Jèhófà yóò fi mú kí Júdà jẹ́jọ́, báwo ni yóò sì ṣe ṣe é?

23 Àwọn aṣáájú ìsìn Júdà sọ pe àwọ́n lóye nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀. Ìkọ́kúkọ̀ọ́ tiwọn fúnra wọn ni wọ́n fi ń kọ́ni, wọ́n wá ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ìwàkiwà wọn láre àti àìnígbàgbọ́ wọn àti mímú tí wọ́n mú kí àwọn èèyàn pàdánù ojú rere Ọlọ́run. “Ohun àgbàyanu,” ìyẹn ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,’ ni Jèhófà yóò lò láti fi pè wọ́n wá jẹ́jọ́ fún ìwà àgàbàgebè wọn. Ó ní: “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, tí wọ́n sì ti fi kìkì ètè wọn yìn mí lógo, tí wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn pàápàá lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fún mi sì ti di àṣẹ ènìyàn tí wọ́n fi ń kọ́ni, nítorí náà, èmi rèé, Ẹni tí yóò tún gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà àgbàyanu pẹ̀lú àwọn ènìyàn yìí, lọ́nà àgbàyanu àti pẹ̀lú ohun àgbàyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn yóò sì ṣègbé, àní òye àwọn olóye wọn yóò sì fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Aísáyà 29:13, 14) Ńṣe ni Jèhófà yóò mú kí ohun tí Júdà ń pè ní ọgbọ́n àti òye yìí pa run nígbà tó bá mú kí Agbára Ayé Bábílónì wá pa gbogbo ètò ẹ̀sìn apẹ̀yìndà rẹ̀ run pátá. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, lẹ́yìn tí àwọn tó pe ara wọn ní aṣáájú olóye fún orílẹ̀-èdè Júù kó orílẹ̀-èdè yẹn ṣìnà. Irú ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ́jọ́ tiwa yìí.—Mátíù 15:8, 9; Róòmù 11:8.

24. Báwo làwọn ará Jùdíà wọ̀nyí ṣe fi àìní ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn?

24 Àmọ́, ní báyìí, ńṣe làwọn aṣáájú Júdà rò pé àwọn mọ ọgbọ́n táwọn máa ta tí sísọ tí wọ́n ń sọ ìjọsìn tòótọ́ dìbàjẹ́ ò fi ní bu àwọn lọ́wọ́. Ṣé wọ́n gbọ́n lóòótọ́? Bí Aísáyà ṣe ṣí aṣọ lójú wọn làṣírí wọn bá tú pé wọn ò ní ojúlówó ìbẹ̀rù Ọlọ́run rárá, nípa bẹ́ẹ̀ wọn ò tiẹ̀ gbọ́n rárá ni, ó ní: “Ègbé ni fún àwọn tí ń lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀ nínú fífi ète pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà tìkára rẹ̀, àti àwọn tí iṣẹ́ wọn ti wáyé ní ibi tí ó ṣókùnkùn, nígbà tí wọ́n ń sọ pé: ‘Ta ní ń rí wa, ta sì ni ó mọ̀ nípa wa?’ Ẹ wo bí ìwà àyídáyidà yín ti pọ̀ tó! Ṣé ó yẹ kí a ka amọ̀kòkò sí ọ̀kan náà pẹ̀lú amọ̀? Nítorí pé, ṣé ó yẹ kí ohun tí a ṣe sọ nípa ẹni tí ó ṣe é pé: ‘Òun kọ́ ni ó ṣe mí’? Ṣé ohun náà tí a ṣẹ̀dá yóò sì sọ ní tòótọ́ nípa ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ pé: ‘Kò fi òye hàn’?” (Aísáyà 29:15, 16; fi wé Sáàmù 111:10.) Bó ti wù kí wọ́n rò pé àwọn fara sin tó, “ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu” ni wọ́n wà lójú Ọlọ́run.—Hébérù 4:13.

Àwọn Adití Yóò Gbọ́ Dájúdájú’

25. Ọ̀nà wo ni “àwọn adití” yóò fi gbọ́ ọ̀rọ̀?

25 Àmọ́ ṣá, ìgbàlà ń bẹ fún olúkúlùkù ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́. (Ka Aísáyà 29:17-24; fi wé Lúùkù 7:22.) “Àwọn adití” yóò “gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé náà,” ìyẹn ìsọfúnni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kì í ṣe ìwòsàn etíyèétí tó di lèyí ṣá o. Ìwòsàn tẹ̀mí ni. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Aísáyà tún sọ nípa ìgbá ìgbékalẹ̀ Ìjọba Mèsáyà àti bí ìṣàkóso Mèsáyà yóò ṣe mú ìsìn tòótọ́ bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Èyí ti ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa, tó fi jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn ló ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ àwọn sọ́nà tí wọ́n sì ń kọ́ láti máa yìn ín lógo. Ìmúṣẹ yìí mà wúni lórí o! Paríparì rẹ̀ ni pé, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù, gbogbo eléèémí yóò máa yin Jèhófà, tí wọn yóò sì ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́.—Sáàmù 150:6.

26. Ìránnilétí tẹ̀mí wo ni “àwọn adití” ń gbọ́ lóde òní?

26 Ẹ̀kọ́ wo ni irú “àwọn adití” bẹ́ẹ̀, tó ń gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lónìí ń kọ́? Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé gbogbo Kristẹni, pàápàá àwọn tó jẹ́ ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìjọ, ló gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti yàgò fún dídi ẹni tó ‘ṣáko lọ nítorí ọtí tí ń pani.’ (Aísáyà 28:7) Ẹ̀wẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí gbígbọ́ àwọn ìránnilétí Ọlọ́run, tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú tẹ̀mí wo gbogbo nǹkan, sú wa láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni máa ń tẹrí ba lọ́nà ẹ̀tọ́ fún àwọn aláṣẹ tó ń ṣèjọba, tí wọ́n sì ń retí pé kí wọ́n pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn kan, síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run ló ń pèsè ìgbàlà, kò lè wá láti ọ̀dọ̀ aráyé rárá. Bákan náà, ká má ṣe gbàgbé rárá pé bí àjàbọ́ kò ṣe sí nígbà ìdájọ́ Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe ní sí àjàbọ́ nígbà tí Ọlọ́run bá ń ṣèdájọ́ ìran yìí. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, a lè máa bá ìkéde ìkìlọ̀ rẹ̀ nìṣó lójú inúnibíni, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti ṣe.—Aísáyà 28:14, 22; Mátíù 24:34; Róòmù 13:1-4.

27. Ẹ̀kọ́ wo ni àwa Kristẹni lè rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?

27 Àwọn alàgbà àti àwọn òbí lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń báni wí, ó máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ lọ́nà tí yóò lè mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà padà rí ojú rere Ọlọ́run, kì í ṣe láti kàn jẹ wọ́n níyà lásán. (Aísáyà 28:26-29; fi wé Jeremáyà 30:11.) Tàgbà tọmọdé wa ló sì ti gba ìránnilétí nípa bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà, ká má ṣe díbọ́n pé a jẹ́ Kristẹni láti lè tẹ́ ènìyàn lọ́rùn. (Aísáyà 29:13) A gbọ́dọ̀ fi hàn pé a kò dà bí àwọn ará Júdà aláìnígbàgbọ́, pé a bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó tọ́, pé a sì ń fún un ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀. (Aísáyà 29:16) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ní láti fi hàn pé à ń fẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà kó sì kọ́ wa.—Aísáyà 29:24.

28. Ojú wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń wo àwọn ìṣe ìgbàlà rẹ̀?

28 Ó mà ṣe pàtàkì o pé ká ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe àwọn nǹkan! (Fi wé Sáàmù 146:3.) Létí ọ̀pọ̀ jù lọ, iṣẹ́ ìkìlọ̀ tí a ń wàásù rẹ̀ yóò dà bí atata-n-toto tí ìkókó máa ń sọ. Ọ̀ràn pé ìparun máa tó dé bá odindi àjọ kan, ìyẹn Kirisẹ́ńdọ̀mù, tó sọ pé òun ń sin Ọlọ́run, jẹ́ èrò tó ṣàjèjì, tó sì kàmàmà. Àmọ́ ṣá o, àṣedélẹ̀ porogodo ni Jèhófà máa ṣe ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì.’ Kò sí àní-àní kan nípa ìyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọba tó yàn, làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbẹ́kẹ̀ lé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní gbogbo àkókò òpin ètò àwọn nǹkan yìí. Wọ́n mọ̀ pé àwọn ìṣe Jèhófà tí ń gbani là, ìyẹn àwọn ohun tí yóò ṣe pa pọ̀ mọ́ ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,’ yóò mú ìbùkún ayérayé wá fún gbogbo aráyé onígbọràn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 8 Nínú Hébérù ìjímìjí, ọ̀rọ̀ tó dún bára jọ gẹ́gẹ́ bí àkọ́sórí àwọn ọmọ jẹ́lé-ó-sinmi ni ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 28:10. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ Aísáyà dún létí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn bí àsọtúnsọ tó jọ atata-n-toto tí ìkókó máa ń sọ.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 289]

Ìmùlẹ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso ènìyàn ni Kirisẹ́ńdọ̀mù gbẹ́kẹ̀ lé dípò Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 290]

Jèhófà ṣe ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì’ nígbà tó yọ̀ǹda kí Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 298]

Àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ odi nípa tẹ̀mí lè “gbọ́” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run