Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Gbé Ilé Jèhófà Lékè

A Gbé Ilé Jèhófà Lékè

Orí Kẹrin

A Gbé Ilé Jèhófà Lékè

Aísáyà 2:1-5

1, 2. Ọ̀rọ̀ wo ni wọ́n kọ sára ògiri ojúde ọ́fíìsì àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ibo ló sì ti wá?

“WỌN yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Ara ògiri kan lójúde ọ́fíìsì àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Ìlú New York ni wọ́n kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí. Wọn kò sọ ibi tí wọ́n ti fa àyọkà yẹn yọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bó sì ṣe jẹ́ ète àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti rí i pé àlàáfíà wà kárí ayé, ó rọrùn láti kàn gbà pé àwọn tó dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lọ́dún 1945 ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.

2 Àmọ́, lọ́dún 1975, wọ́n gbẹ́ orúkọ Aísáyà sára ògiri yẹn, ní ìsàlẹ̀ àyọkà yìí. Ìgbà yẹn ló tó wá hàn gbangba pé òde òní kọ́ lọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé. Ká sòótọ́, ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá ọdún sẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ sínú ibi tó wá di orí kejì nínú ìwé Aísáyà báyìí. Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣẹ́yìn làwọn olùfẹ́ àlàáfíà ti ń ṣàṣàrò nípa ọ̀nà tí ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ yóò gbà ṣẹlẹ̀ àti ìgbà tí yóò ṣẹlẹ̀. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ lá à ń ṣe kàyééfì mọ́. Kòrókòró là ń fojú rí i bí àsọtẹ́lẹ̀ àtọjọ́mọ́jọ́ yìí ṣe ń ṣẹ lọ́nà tó bùáyà.

3. Àwọn wo ni orílẹ̀-èdè tó fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀?

3 Àwọn wo ni àwọn orílẹ̀-èdè tó fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀? Ó dájú pé kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tó wà láyé òde òní. Di báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ṣì ń rọ idà, tàbí àwọn ohun ìjà láti fi jagun àti láti fi mú kí “àlàáfíà” wà tipátipá. Ká sòótọ́, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè mà tiẹ̀ ń fẹ́ máa fi ohun èlò ìtúlẹ̀ tiwọn rọ idà o! Àwọn aṣojú látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Jèhófà, “Ọlọ́run àlàáfíà” lọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ sí lára.—Fílípì 4:9.

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ń Wọ́ Tìrítìrí Lọ Síbi Ìjọsìn Mímọ́ Gaara

4, 5. Àsọtẹ́lẹ̀ kí ni àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Aísáyà orí kejì sọ, kí ló sì túbọ̀ mú un dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ náà ṣe é gbára lé?

4 Ọ̀rọ̀ Aísáyà orí kejì bẹ̀rẹ̀ báyìí pé: “Ohun tí Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì rí ní ìran nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù: Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.”—Aísáyà 2:1, 2.

5 Mọ̀ dájú pé ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ kì í ṣe àsọbádé lásán. Ńṣe ni Aísáyà rí ìtọ́ni gbà pé kó ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tí ‘yóò ṣẹlẹ̀’—láìní kùnà. Ohunkóhun tí Jèhófà bá ti pète “yóò . . . ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.” (Aísáyà 55:11) Ẹ̀rí fi hàn pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fẹ́ kó túbọ̀ dájú pé ìlérí yìí ṣe é gbára lé, ló ṣe mí sí wòlíì Míkà, tó ń gbé ní ìgbà Aísáyà, láti kọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yìí sínú ìwé tirẹ̀ bó ṣe wà nínú Aísáyà 2:2-4 gẹ́lẹ́.—Míkà 4:1-3.

6. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ?

6 Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà máa ní ìmúṣẹ? “Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” Bíbélì New International Version sọ pé: “Ní ìkẹyìn àwọn ọjọ́.” Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn àmì tí yóò jẹ́ kí a dá àkókò yìí mọ̀. Lára wọn ni ogun, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, àti “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” * (2 Tímótì 3:1-5; Lúùkù 21:10, 11) Ṣíṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn sì ń ṣẹ jẹ́ ẹ̀rí pé a ń gbé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ayé ìsinsìnyí. Nígbà náà, a jẹ́ pé ó yẹ kí a máa retí pé kí àwọn ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ lákòókò tiwa yìí nìyẹn o.

Òkè Ìjọsìn

7. Àpèjúwe wo ni Aísáyà lò láti fi sàsọtẹ́lẹ̀?

7 Gbólóhùn mélòó kan ni Aísáyà fi ṣàpèjúwe àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ́nà tó yéni kedere. A rí òkè gíga fíofío kan, òkè tí tẹ́ńpìlì Jèhófà, ilé ológo, jókòó rèǹtè-rente sí lórí. Òkè yìí ga fíofío ré kọjá àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké tó wà ní àgbègbè ibẹ̀. Síbẹ̀ kò dẹ́rù bani, bẹ́ẹ̀ ni kò jáni láyà; ṣe ló fani mọ́ra. Ńṣe làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń hára gàgà láti gun òkè ilé Jèhófà lọ; tìrítìrí ni wọ́n ń wọ́ lọ síbẹ̀. Kíá lèèyàn lè fojú inú rí i bó ṣe ń ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí?

8. (a) Kí ni àwọn èèyàn mọ àwọn òkè kéékèèké àti òkè ńlá mọ́ láyé Aísáyà? (b) Kí ni wíwọ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè ń wọ́ tìrítìrí lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà” dúró fún?

8 Láyé Aísáyà, ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn làwọn èèyàn sábà máa ń ka àwọn òkè kéékèèké àti òkè ńlá sí. Bí àpẹẹrẹ, ibẹ̀ làwọn abọ̀rìṣà ti ń jọ́sìn, ibẹ̀ ni wọ́n ń kọ́lé òrìṣà sí. (Diutarónómì 12:2; Jeremáyà 3:6) Àmọ́ o, ńṣe ni ilé tàbí tẹ́ńpìlì Jèhófà bu ẹwà kún orí Òkè Mòráyà ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olùṣòtítọ́ máa ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọn a sì gun Òkè Mòráyà lọ láti jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. (Diutarónómì 16:16) Nítorí náà, ohun tí wíwọ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè ń wọ́ tìrítìrí lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà” dúró fún ni kíkó tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń kóra jọ sínú ìsìn tòótọ́.

9. Kí ni “òkè ńlá ilé Jèhófà” dúró fún?

9 Àmọ́ ṣá o, lónìí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run kì í kóra jọ pọ̀ sórí òkè ńlá kankan tí a lè fojú rí, tó ní tẹ́ńpìlì olókùúta. Àwọn ọmọ ogun Róòmù ti pa tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Àti pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yéni kedere pé àwòkọ́ṣe ni tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù àti àgọ́ ìjọsìn tó wà ṣáájú rẹ̀ jẹ́. Wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi kan tó jẹ́ tẹ̀mí, tó tóbi ju ìwọ̀nyẹn lọ, ìyẹn, “àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.” (Hébérù 8:2) Àgọ́ tẹ̀mí yẹn jẹ́ ìṣètò fún títọ Jèhófà lọ fún ìjọsìn, nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Hébérù 9:2-10, 23) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, “òkè ńlá ilé Jèhófà” tí Aísáyà 2:2 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà, tí a gbé lékè ní àkókò tiwa yìí. Àwọn tí ń kópa nínú ìjọsìn mímọ́ gaara kì í lọ péjọ pọ̀ sójú ibi kan ní pàtó; ṣe ni wọ́n ń péjọ pọ̀ fún ìjọsìn oníṣọ̀kan.

Gbígbé Ìjọsìn Mímọ́ Gaara Lékè

10, 11. Ọ̀nà wo ni a gbà gbé ìjọsìn Jèhófà lékè lọ́jọ́ tiwa?

10 Wòlíì náà sọ pé “òkè ńlá ilé Jèhófà,” tàbí ìjọsìn mímọ́ gaara, yóò di “èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá,” pé a óò sì “gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké.” Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà Aísáyà ni Dáfídì Ọba tí gbé àpótí májẹ̀mú wá sórí Òkè Síónì ní Jerúsálẹ́mù, òkè tó fi òjìdínlẹ́gbẹ̀rin mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ. Ibẹ̀ ni àpótí náà wà kí wọ́n tó gbé e wá sínú tẹ́ńpìlì orí Òkè Mòráyà nígbà tí wọ́n kọ́ ọ tán. (2 Sámúẹ́lì 5:7; 6:14-19; 2 Kíróníkà 3:1; 5:1-10) Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó fi máa dìgbà ayé Aísáyà, wọ́n ti gbé àpótí mímọ́ náà sókè ní ti gidi, wá sínú tẹ́ńpìlì, níbi tó ga ju àwọn òkè púpọ̀ tí wọ́n ń lò fún ìsìn èké láyìíká ibẹ̀.

11 Ó dájú ṣáká pé, nípa tẹ̀mí, kò sí ìgbà kankan tí ìjọsìn Jèhófà kò lékè gbogbo nǹkan táwọn abọ̀rìṣà ń ṣe nínú ìjọsìn wọn. Àmọ́, lọ́jọ́ tiwa yìí, Jèhófà ti gbé ìjọsìn rẹ̀ ga fíofío, ré kọjá onírúurú ìjọsìn àìmọ́ gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni o, ó ga fíofío tayọ “òkè kéékèèké” àti “orí òkè ńláńlá” gbogbo. Lọ́nà wo? Ní pàtàkì, ó jẹ́ nípa kíkóra jọ pọ̀ tí àwọn tó ń fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” ń kóra jọ pọ̀.—Jòhánù 4:23.

12. Àwọn wo ni “àwọn ọmọ ìjọba náà,” iṣẹ́ ìkórè wo ló sì ti wáyé?

12 Àkókò ìkórè ni Kristi Jésù pe “ìparí ètò àwọn nǹkan,” àkókò tí àwọn áńgẹ́lì yóò kórè “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn ni, àwọn tó ń retí àtibá Jésù jọba nínú ògo ti ọ̀run. (Mátíù 13:36-43) Láti ọdún 1919 ni Jèhófà ti fún “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” lára àwọn ọmọ yìí lágbára pé kí wọ́n máa bá àwọn áńgẹ́lì ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. (Ìṣípayá 12:17) Nítorí náà, “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù, ni wọ́n kọ́kọ́ kórè ná. Àwọn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìkórè tó tún kù.

13. Báwo ni Jèhófà ti ṣe bù kún àwọn ẹni àmì òróró?

13 Ní àkókò ìkórè yìí, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni Jèhófà ń ran àwọn ẹni àmì òróró lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣàlàyé rẹ̀. Ìyẹn náà sì ti fi kún ìgbélékè ìsìn mímọ́ gaara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘òkùnkùn pàápàá bo ilẹ̀ ayé, tí ìṣúdùdù nínípọn sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè,’ ńṣe làwọn ẹni àmì òróró “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀” láàárín aráyé, nítorí Jèhófà ti fọ̀ wọ́n, ó sì ti yọ́ wọn mọ́. (Aísáyà 60:2; Fílípì 2:15) Bí àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ṣe “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí,” ńṣe ni wọ́n ń “tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”—Kólósè 1:9; Mátíù 13:43.

14, 15. Láfikún sí kíkó “àwọn ọmọ ìjọba náà” jọ, iṣẹ́ ìkórè wo ló ń lọ lọ́wọ́, báwo sì ni Hágáì ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?

14 Ẹ̀wẹ̀, àwọn mìíràn tún ti wọ́ tìrítìrí lọ sí “òkè ńlá ilé Jèhófà.” Jésù pè wọ́n ní “àwọn àgùntàn mìíràn” tí òun ní, ìrètí tiwọn ni láti wà láàyè títí láé nínú párádísè ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 21:3, 4) Bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930, wọ́n kọ́kọ́ ń jáde wá ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún, lẹ́yìn náà, ó di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún, ó tún ti di àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí! Nínú ìran kan tí wọ́n fi han àpọ́sítélì Jòhánù, wọ́n ṣàpèjúwe wọn pé wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.”—Ìṣípayá 7:9.

15 Wòlíì Hágáì sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí yóò yọjú. Ó kọ ọ́ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i—láìpẹ́—èmi yóò sì mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì. Dájúdájú, èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè [ìyẹn àwọn tó dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú ìjọsìn mímọ́ gaara] yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Hágáì 2:6, 7) Wíwàa àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí ń pọ̀ sí i yìí àti àwọn ẹni àmì òróró ẹlẹgbẹ́ wọn, ń gbé ìjọsìn mímọ́ ga nínú ilé Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń ṣe é lógo. Kò tíì sí lákọsílẹ̀ rí pé iye àwọn tó pọ̀ tó báyìí ń fi ìṣọ̀kan jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, èyí sì ń ṣe Jèhófà àti Jésù Kristi, Ọba rẹ̀ tó ti jẹ, lógo. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Inú ògìdìgbó àwọn ènìyàn ni ọ̀ṣọ́ ọba wà.”—Òwe 14:28.

Àwọn Ènìyàn Ń Gbé Ìjọsìn Lékè Nínú Ayé Wọn

16-18. Àwọn àyípadà wo ni àwọn kan ti ṣe láti lè jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà?

16 Jèhófà ni gbogbo ọpẹ́ yẹ fún ìgbélékè ìjọsìn mímọ́ gaara lákòókò tiwa. Síbẹ̀ náà, àwọn tó bá tọ̀ ọ́ wá láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ yìí. Bí òkè gígùn ṣe gba ìsapá náà ni kíkọ́ nípa ìlànà òdodo Ọlọ́run àti gbígbé ìgbésí ayé níbàámu pẹ̀lú rẹ̀ ṣe gba ìsapá. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòde òní tí kọ ìgbé ayé àti àwọn ìwà tí kò bá ìjọsìn tòótọ́ mú sílẹ̀ pátápátá, gẹ́lẹ́ bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti ṣe. Àwọn alágbèrè, abọ̀rìṣà, panṣágà, olè, oníwọra, ọ̀mùtípara, àtàwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti yíwà padà, tí wọ́n dẹni tí ‘a ti wẹ̀ mọ́’ lójú Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

17 Àpẹẹrẹ kan ni ti ìrírí obìnrin kan tó kọ̀wé pé: “Mo ti fìgbà kan rí ṣèranù lọ, láìní ìrètí kankan. Ìṣekúṣe wọ̀ mí lẹ́wù, ẹmu-lẹ̀wù sì ni mí. Mo kó àrùn abẹ́ lóríṣiríṣi. Mo tún ń ta oògùn olóró, ohunkóhun ò sì jọ mí lójú.” Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́yìn náà, ó yí padà gidi gan-an láti lè ṣe bí ìlànà Ọlọ́run ṣe fẹ́. Ó wá sọ nísinsìnyí pé: “Ọkàn mi balẹ̀, mo dẹni iyì, ìrètí ọjọ́ iwájú ń bẹ fún mi, mo ní ìdílé àtàtà, lékè gbogbo rẹ̀, àárín èmi àti Jèhófà, Baba wa tún dán mọ́rán.”

18 Àní lẹ́yìn rírí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà pàápàá, gbogbo wa ló ní láti máa bá a lọ láti gbé ìjọsìn mímọ́ gaara lékè nípa fífi í ṣáájú ohunkóhun nínú ìgbésí ayé wa. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti tipasẹ̀ Aísáyà sọ ọ́ pé òun ní ìdánilójú pé ògìdìgbó ènìyàn yóò wà lónìí, tí yóò máa hára gàgà láti fi ìjọsìn òun sípò tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Ṣé o wà lára wọn?

Àwọn Ènìyàn Táa Fọ̀nà Jèhófà Kọ́

19, 20. Ẹ̀kọ́ kí ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń kọ́, ibo sì ni wọ́n ti ń kọ́ ọ?

19 Aísáyà túbọ̀ sọ fún wa nípa àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìsìn mímọ́ gaara lónìí. Ó ní: “Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.”—Aísáyà 2:3.

20 Jèhófà ò jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa dà gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kiri bí àgùntàn tó sọ nù. Ó ń lo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì láti fi gbin “òfin” àti “ọ̀rọ̀” rẹ̀ sí wọn lọ́kàn kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀. Ìmọ̀ ọ̀hún ló ń mú kí wọ́n lè “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” Ìmọrírì tó kún ọkàn wọn, àti ìfẹ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni Ọlọ́run ṣe wí, wá ń sún wọn láti máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. Wọn a máa péjọ ní àwọn àpéjọpọ̀ ńláńlá àti ní àwùjọ kéékèèké—nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nínú ilé àdáni—láti gbọ́ àti láti kọ́ nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run. (Diutarónómì 31:12, 13) Wọ́n tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ìjímìjí, tó máa ń pàdé pọ̀ láti fúnra wọn níṣìírí àti láti ru ara wọn sókè kí ‘ìfẹ́ àti àwọn iṣẹ́ àtàtà’ wọn lè máa pọ̀ sí i.—Hébérù 10:24, 25.

21. Inú iṣẹ́ wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń kópa?

21 Wọ́n ń ké sí àwọn ẹlòmíràn láti “gòkè lọ” síbi ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run tí a ti gbé lékè. Ìyẹn mà bá àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kó tó gòkè re ọ̀run mu gan-an o! Ó sọ fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Bí Ọlọ́run ṣe ń ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn, wọ́n ń ṣègbọràn nípa jíjáde lọ kárí ayé, láti kọ́ àwọn èèyàn, láti sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ń batisí wọn.

Fífi Idà Rọ Abẹ Ohun Ìtúlẹ̀

22, 23. Kí ni Aísáyà 2:4 sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kí sì ni ọ̀gá kan nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ nípa ìyẹn?

22 Wàyí o, ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ló kàn, ara ẹsẹ yìí ni wọ́n ti kọ ohun tí wọ́n kọ sára ògiri ojúde ọ́fíìsì àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Aísáyà kọ̀wé pé: “Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

23 Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni yóò gbà kí èyí tó lè ṣeé ṣe. Federico Mayor, olùdarí àgbà fún Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ nígbà kan rí pé: “Kò jọ pé gbogbo bí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ṣe ń gbé gbogbo aburú tí ogun ń fà jáde fáyé rí lóde òní lè fòpin sí pípọ̀ sí i àwọn ẹ̀rọ ogun gìrìwò-gìrìwò tí wọ́n ti gbé kalẹ̀, tí wọ́n sì ń mójú tó láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú ìran ìsinsìnyí ni iṣẹ́ tí Bíbélì sọ, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè ṣeé ṣe, ìyẹn ni, “láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” kí wọ́n sì yí ìwà ìrógunyọ̀—tó ti mọ́ra látayébáyé wá—padà sí ti jíjẹ́ kí àlàáfíà jọba. Bọ́wọ́ wa bá lè tẹ èyí, a jẹ́ pé a ti ṣe ohun tó dára tó sì gbayì jù lọ tí ‘aráyé’ tíì gbé ṣe rí, yóò sì jẹ́ ogún tó dára jù lọ tí a fi lé àtọmọdọ́mọ wa lọ́wọ́.”

24, 25. Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ sí lára, lọ́nà wo sì ni?

24 Àwọn orílẹ̀-èdè lápapọ̀ kò lè gbé nǹkan ribiribi yìí ṣe láé. Agbára wọn ò tilẹ̀ gbé e rárá ni. Àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, tí wọ́n ṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ gaara, ló ń mú ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí ṣẹ. Jèhófà ti “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” láàárín wọn. Ó ti kọ́ àwọn ènìyàn tirẹ̀ láti jùmọ̀ máa gbé pọ̀ lálàáfíà. Ní tòótọ́, wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn” lọ́nà àpèjúwe, nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí aáwọ̀ sì kún fọ́fọ́ yìí. Lọ́nà wo?

25 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n kì í dá sí ọ̀ràn ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Kété ṣáájú ikú Jésù, àwọn kan dìhámọ́ra wá láti mú un. Nígbà tí Pétérù yọ idà tì wọ́n láti dáàbò bo Jésù Ọ̀gá rẹ̀, Jésù sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Látìgbà yẹn wá ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, tí wọ́n sì ti yọwọ́ nínú gbígbé ohun ìjà sí ọmọnìkejì wọn láti pa wọ́n tàbí kí wọ́n ṣètìlẹyìn fún ọ̀ràn ogun lọ́nàkọnà. Ńṣe ni wọ́n ń “lépa” wíwà ní “àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Hébérù 12:14.

Lílépa Àwọn Ọ̀nà Àlàáfíà

26, 27. Báwo làwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe ń “wá àlàáfíà,” tí wọ́n sì “ń lépa rẹ̀”? Sọ àpẹẹrẹ kan.

26 Wíwà tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run wà lálàáfíà ré kọjá kíkọ̀ láti jagun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ tí wọ́n wà ju ọgbọ̀n-lénígba lọ, tí wọ́n sì tinú àìmọye èdè àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wá, àlàáfíà wà láàárín wọn. Àwọn ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣẹ sí lára lóde òní, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) “Onílàjà” làwọn Kristẹni lóde òní. (Mátíù 5:9, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Wọn a “máa wá àlàáfíà,” wọn a “sì máa lépa rẹ̀.” (1 Pétérù 3:11) Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà” ló sì ń fún wọn lókun.—Róòmù 15:33.

27 Àwọn àpẹẹrẹ tó bùáyà wà, ní ti àwọn tó ti kọ́ bí a ṣe ń jẹ́ onílàjà. Ọ̀gbẹ́ni kan kọ ìtàn ìgbà èwe rẹ̀ pé: “Ìyà ló mú kí n lọ kọ́ bí mo ṣe lè gba ara mi sílẹ̀. Ìyẹn ló sọ mi di erìkìnà, agara ìgbésí ayé sì ń dá mi. Ìjà ni mo ń jà ṣáá ní gbogbo ìgbà. Lójoojúmọ́, ọmọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ń bá jà ládùúgbò, bí mi ò lo ẹ̀ṣẹ́, màá lo òkúta tàbí ìgò. Òǹrorò ẹ̀dá ni mo sì yà bí mo ṣe ń dàgbà.” Àmọ́, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó jẹ́ ìpè náà pé kí ó wá sí “òkè ńlá ilé Jèhófà.” Ó kọ́ àwọn ọ̀nà Ọlọ́run, ó sì di ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó di onílàjà.

28. Kí làwọn Kristẹni lè ṣe láti lè lépa àlàáfíà?

28 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò gbé irú ìgbésí ayé òǹrorò bẹ́ẹ̀ rí. Síbẹ̀síbẹ̀, àní nínú àwọn ohun kéékèèké pàápàá—ìwà inúure, dídáríjini, àti ìgbatẹnirò—wọn a máà sapá láti jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwọn àti ẹlòmíràn. Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ìmọ̀ràn Bíbélì wí, pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”—Kólósè 3:13.

Ọjọ́ Ọ̀la Alálàáfíà

29, 30. Ìrètí wo ló wà fún ilẹ̀ ayé?

29 Jèhófà ti ṣe ohun ìyanu ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” tí a wà yìí. Ó kó àwọn ènìyàn tó ń fẹ́ láti sìn ín jọ pọ̀ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó fi rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà àlàáfíà, kọ́ wọn. Àwọn wọ̀nyí ni yóò la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ wá já, bọ́ sínú ayé tuntun alálàáfíà tí a ó ti fòpin sí ogun títí láé.—Ìṣípayá 7:14.

30 Kì yóò sí idà, ìyẹn, ohun ìjà ogun, mọ́. Onísáàmù náà kọ̀wé nípa àkókò náà pé: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.” (Sáàmù 46:8, 9) Bí a ti ṣe ń retí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, wẹ́kú lọ̀rọ̀ ìyànjú tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e tún bá a mu lónìí, gẹ́lẹ́ bó ṣe bá a mu nígbà tó kọ ọ́ pé: “Ẹ̀yin ará ilé Jékọ́bù, ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 2:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, ká jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ Jèhófà tàn sí ọ̀nà wa nísinsìnyí, a óò sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ títí ayé.—Míkà 4:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 6 Wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, orí 9, “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?” àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]