Jèhófà Ọlọ́run Ṣàánú Àṣẹ́kù Kan
Orí Kẹfà
Jèhófà Ọlọ́run Ṣàánú Àṣẹ́kù Kan
1, 2. Kí ni wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù?
ÌJÌ líle kan rọ́ lu àgbègbè kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń gbé. Ńṣe ni ẹ̀fúùfù líle, òjò ńlá, àti omíyalé tó ń ya gbùúgbùú balẹ̀ jẹ́ lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ, tí ilé, oko, àti ẹ̀mí sì ṣègbé lọ jàra. Àmọ́ ìjì náà kò pẹ́ tó fi jà tán, tí ibi gbogbo sì wá dákẹ́ minimini. Àwọn tó là á já wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àtúnkọ́ àti ìmúbọ̀sípò.
2 Ohun tó jọ èyí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Ìjì ìdájọ́ Ọlọ́run ti dé tán—ó sì yẹ kó jà lóòótọ́! Ẹ̀ṣẹ̀ orílẹ̀-èdè náà pọ̀ jọjọ. Àìṣèdájọ́ òdodo àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni àwọn alákòóso àti aráàlú fi kún gbogbo ilẹ̀ náà. Jèhófà wá tipasẹ̀ Aísáyà fi ẹ̀bi Júdà hàn, ó sì kìlọ̀ pé ìdájọ́ Òun yóò dé bá orílẹ̀-èdè oníwàkiwà yẹn. (Aísáyà 3:25) Ahoro pátápátá ni ilẹ̀ Júdà máa dà lẹ́yìn tí ìjì yẹn bá jà kọjá. Ìrònú èyí ti ní láti ba Aísáyà lọ́kàn jẹ́.
3. Ìhìn rere wo ló wà nínú ìsọfúnni onímìísí tó wà nínú Aísáyà 4:2-6?
3 Ṣùgbọ́n o, ìròyìn ayọ̀ ń bẹ! Ìjì ìdájọ́ òdodo Jèhófà yóò kọjá lọ, àwọn àṣẹ́kù yóò sì là á já. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà yóò ṣàánú nígbà ìdájọ́ Júdà! Ọ̀rọ̀ ọjọ́ iwájú alárinrin yìí ni Aísáyà ń sọ nínú ìsọfúnni rẹ̀ onímìísí tó wà nínú àkọsílẹ̀ Aísáyà 4:2-6. Àfi bí ẹni pé oòrùn là wàà lẹ́yìn tí ìjì yẹn jà tán; ohun tí Aísáyà ń sọ wá ṣí kúrò lórí rírí àti gbígbọ́ nípa ọ̀ràn ìdájọ́ tí Aísáyà 2:6–4:1 ń ṣàpèjúwe rẹ̀, ó wá bọ́ sórí ọ̀ràn ilẹ̀ àtàwọn èèyàn tí àmúdọ̀tun ti bá ringindin.
4. Èé ṣe tó fi yẹ ká jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ nípa ìmúbọ̀sípò tí yóò dé bá àṣẹ́kù?
Aísáyà 2:2-4) Ẹ jẹ́ ká jíròrò lórí ìhìn tó bọ́ sákòókò yìí, nítorí yàtọ̀ sí pé ó jẹ mọ́ ọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀, ó tún kọ́ wa nípa àánú Jèhófà àti bí ẹni kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè rí i gbà.
4 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ìmúbọ̀sípò àwọn àṣẹ́kù àti ààbò tó wà lẹ́yìn náà ní ìmúṣẹ lọ́jọ́ tiwa pẹ̀lú—“ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (‘Èéhù Jèhófà’
5, 6. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àkókò àlàáfíà tó tẹ̀ lé ìjì líle tí ń bọ̀? (b) Kí ni ìtúmọ̀ gbólóhùn náà, “èéhù,” kí ni èyí sì fi hàn nípa ilẹ̀ Júdà?
5 Ọ̀rọ̀ atura ni Aísáyà ń sọ wàyí bó ṣe ń wo àkókò àlàáfíà tí ń bọ̀ lẹ́yìn rúgúdù náà. Ó kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ohun tí Jèhófà mú kí ó rú jáde [“èéhù Jèhófà,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] yóò wá wà fún ìṣelóge àti fún ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ohun ìyangàn àti ohun ẹlẹ́wà fún àwọn tí ó sá àsálà lára Ísírẹ́lì.”—Aísáyà 4:2.
6 Ọ̀rọ̀ ìmúbọ̀sípò ni Aísáyà ń sọ níhìn-ín. Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ orúkọ tí a túmọ̀ sí “èéhù” tọ́ka sí ‘ohun tó rú, ọ̀mùnú, tàbí ẹ̀ka.’ Ọ̀ràn tó jẹ mọ́ aásìkí, ìbísí, àti ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni wọ́n máa ń lò ó fún. Àpèjúwe pé ìrètí wà ni Aísáyà ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe, ìyẹn ni pé, ìsọdahoro tí ń bọ̀ kò ní wà bẹ́ẹ̀ títí láé. Lọ́lá ìbùkún Jèhófà, ilẹ̀ Júdà, tó ti láásìkí tẹ́lẹ̀ rí yóò tún méso jáde wọ̀ǹtì-wọnti. *—Léfítíkù 26:3-5.
7. Ọ̀nà wo ni èéhù Jèhófà “yóò fi . . . wà fún ìṣelóge àti fún ògo”?
Ìsíkíẹ́lì 20:6) Ọ̀rọ̀ Aísáyà wá tipa báyìí mú kó dá àwọn ènìyàn yẹn lójú pé ilẹ̀ Júdà yóò padà ní ògo àti ẹwà tó ní tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ní ti gidi, bí adé ọ̀ṣọ́ ni yóò jẹ́ fún ilẹ̀ ayé.
7 Àwọn gbólóhùn tó ń ṣàpèjúwe nǹkan kedere ni Aísáyà lò láti fi júwe bí àtúnṣe tí ń bọ̀ yóò ṣe kàmàmà tó. Ohun tí Jèhófà máa mú kó rú jáde yóò “wà fún ìṣelóge àti fún ògo.” Ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí, “ìṣelóge,” múni rántí ẹwà tí Ilẹ̀ Ìlérí ní nígbà tí Jèhófà fi í fún Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà yẹn. Ó lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi kà á sí “ìṣelóge [“ohun ọ̀ṣọ́,” New American Bible] ilẹ̀ gbogbo.” (8. Àwọn wo ni yóò wà níbẹ̀ láti gbádùn ẹwà ilẹ̀ náà tó ti padà bọ̀ sípò, báwo ni Aísáyà sì ṣe ṣàpèjúwe bọ́ràn náà ṣe rí lára wọn?
8 Àmọ́, àwọn wo ló máa wà níbẹ̀ láti máa gbádùn ẹwà ilẹ̀ tó ti padà bọ̀ sípò náà? Aísáyà kọ ọ́ pé “àwọn tí ó sá àsálà lára Ísírẹ́lì” ni. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn kan yóò la ìparun atẹ́nilógo tí Aísáyà 3:25, 26) Àṣẹ́kù àwọn olùlàájá yóò padà lọ sí Júdà láti kópa nínú ìmúbọ̀sípò rẹ̀. Lójú àwọn tó ti àjò dé yìí, ìyẹn “àwọn tí ó sá àsálà,” ńṣe ni èso wọ̀ǹtì-wọnti tó ń wá láti inú ilẹ̀ wọn tó padà sípò náà yóò di “ohun ìyangàn àti ohun ẹlẹ́wà.” (Aísáyà 4:2) Ìyangàn yóò wá dípò ẹ̀tẹ́ tí ìdahoro náà kó bá wọn.
àsọtẹ́lẹ̀ sọ níṣàájú já. (9. (a) Ní ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà, kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn kan tí wọ́n bí nígbà ìgbèkùn wà lára “àwọn tí ó sá àsálà”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
9 Bí Aísáyà ṣe wí, ìjì ìdájọ́ dé lóòótọ́ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣègbé. Àwọn kan là á já, wọ́n sì kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, ṣùgbọ́n, kò sẹ́ni tí ì bá là á rárá ká ní Ọlọ́run ò ṣàánú wọn. (Nehemáyà 9:31) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Júdà dahoro pátápátá. (2 Kíróníkà 36:17-21) Nígbà tó wá di ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run aláàánú yọ̀ǹda kí “àwọn tí ó sá àsálà” padà sí Júdà láti dá ìjọsìn tòótọ́ padà. * (Ẹ́sírà 1:1-4; 2:1) Àkọsílẹ̀ nípa bí àwọn ìgbèkùn tó padà ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn wà nínú Sáàmù 137, tó jọ pé wọ́n kọ nígbà ìgbèkùn tàbí kété lẹ́yìn náà. Bí wọ́n ṣe padà dé Júdà, wọn bẹ̀rẹ̀ sí dá oko. Ẹ wo bí yóò ṣe rí lára wọn nígbà tí wọn rí i pé ìbùkún Ọlọ́run wà lórí ìsapá wọn, tí ọ̀gbìn ilẹ̀ náà fi wá ń rú gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́ bí “ọgbà Édẹ́nì” eléso!—Ìsíkíẹ́lì 36:34-36.
10, 11. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà wà nígbèkùn “Bábílónì Ńlá” lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún àṣẹ́kù àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
10 Irú ìmúbọ̀sípò kan náà ti wáyé lọ́jọ́ tiwa. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ìṣípayá 17:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti kọ púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké sílẹ̀, àbàwọ́n àwọn èrò àti àṣà Bábílónì kan ṣì wà lára wọn. Àtakò tí àwùjọ àlùfáà súnná sí mú kí àwọn kan lára wọn wẹ̀wọ̀n ní ti gidi. Bí ilẹ̀ wọn nípa tẹ̀mí, ìyẹn ipò ìgbòkègbodò wọn nínú ẹ̀sìn, tàbí ipò wọn nípa tẹ̀mí, ṣe dahoro nìyẹn.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún, dèrò ìgbèkùn nípa tẹ̀mí nínú “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (11 Àmọ́ o, nígbà ìrúwé ọdún 1919, Jèhófà ṣàánú àṣẹ́kù àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí wọ̀nyí. (Gálátíà 6:16) Ó rí i pé wọ́n ronú pìwà dà àti pé wọ́n ń fẹ́ láti fòótọ́ jọ́sìn òun, ìyẹn ló fi rí sí i pé wọ́n jáde lẹ́wọ̀n, àti ní pàtàkì, pé wọ́n kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí. A dá “àwọn tí ó sá àsálà” wọ̀nyí padà sí ipò tẹ̀mí tí Ọlọ́run fi wọ́n sí tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run sì mú kó rú pìtìmù. Ipò tẹ̀mí yìí wá wuni, ó sì fani mọ́ra gan-an, tó fi mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run mìíràn dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú ìjọsìn tòótọ́.
12. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe gbé àánú tí Jèhófà fi hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ga?
12 Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ níhìn-ín gbé àánú tí Ọlọ́run fi hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ yọ lọ́nà tó ga. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, kẹ̀yìn sí Jèhófà, ó fàánú hàn sí àwọn àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà. A lè rí ìtùnú gbà látinú mímọ̀ pé àwọn tó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá ṣì lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà láìsọ̀rètí nù. Kí àwọn tó bá ronú pìwà dà má rò pé Jèhófà ò lè ṣàánú àwọn mọ́, nítorí kì í kọ oníròbìnújẹ́ sílẹ̀. (Sáàmù 51:17) Bíbélì mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sáàmù 103:8, 13) Dájúdájú, Ọlọ́run aláàánú yìí ló yẹ ká máa fi gbogbo ìyìn wa fún!
Àṣẹ́kù Kan Jẹ́ Mímọ́ Lójú Jèhófà
13. Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ Aísáyà 4:3, báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àṣẹ́kù tí Jèhófà yóò ṣàánú fún?
13 A ti gbọ́ nípa àṣẹ́kù tí Jèhófà yóò ṣàánú fún tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ní báyìí, Aísáyà túbọ̀ wá ṣàpèjúwe wọn ní kíkún. Ó kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, àwọn tí ó ṣẹ́ kù ní Síónì àti àwọn tí a ṣẹ́ kù ní Jerúsálẹ́mù ni a ó sọ pé wọ́n jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀, olúkúlùkù ẹni tí a kọ sílẹ̀ fún ìwàláàyè ní Jerúsálẹ́mù.”—Aísáyà 4:3.
14. Àwọn wo ni “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” àti “àwọn tí a ṣẹ́ kù,” èé sì ti ṣe tí Jèhófà yóò fi ṣàánú wọn?
14 Àwọn wo ni “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” àti “àwọn tí a ṣẹ́ kù”? Àwọn tí ẹsẹ tó ṣáájú èyí pè ní àwọn tí ó sá àsálà ni—àwọn Júù tó wà nígbèkùn tí a ó yọ̀ǹda fún láti padà sí Júdà. Aísáyà wá fi ìdí tí Jèhófà yóò fi ṣàánú wọn hàn wàyí—wọn yóò “jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀.” Jíjẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí “kí nǹkan mọ́ nigín-nigín tàbí kó dá ṣáká lọ́nà ti ìsìn; àìlábààwọ́n.” Láti jẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí kéèyàn mọ́ nigín, tàbí kó dá ṣáká, lọ́rọ̀ àti níṣe, láti máa ṣe ohun tí Jèhófà là kalẹ̀ pé ó tọ́, tó sì yẹ. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà yóò ṣàánú àwọn tó “jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀,” yóò yọ̀ǹda fún wọn láti padà sí Jerúsálẹ́mù “ìlú ńlá mímọ́.”—Nehemáyà 11:1.
15. (a) Àṣà àwọn Júù wo ni gbólóhùn náà “kọ sílẹ̀ fún ìwàláàyè ní Jerúsálẹ́mù” mú wa rántí? (b) Ìkìlọ̀ pàtàkì wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà wá jẹ́?
15 Ṣé àwọn àṣẹ́kù yìí yóò dúró sọ́hùn-ún ni? Ìlérí tí Aísáyà ṣe ni pé wọ́n máa ‘kọ wọ́n sílẹ̀ fún ìwàláàyè ní Jerúsálẹ́mù.’ Èyí mú wa rántí àṣà àwọn Júù, wọn a máa kọ orúkọ àwọn ìdílé àti ẹ̀yà Ísírẹ́lì sílẹ̀ fínnífínní. (Nehemáyà 7:5) Bí orúkọ ẹnì kan bá ti wà lákọsílẹ̀, onítọ̀hún wà láàyè nìyẹn, nítorí pé béèyàn bá ti kú, ṣe ni wọ́n á yọ orúkọ rẹ̀ kúrò. Nínú àwọn apá ibòmíràn nínú Bíbélì, a kà nípa àkọsílẹ̀, tàbí ìwé ìṣàpẹẹrẹ kan, tó ní orúkọ àwọn tí Jèhófà máa fi ìyè dá lọ́lá nínú. Àmọ́, wíwà tí orúkọ ẹni yóò máa wà nìṣó nínú ìwé yẹn sinmi lórí àwọn ipò kan, nítorí Jèhófà lè ‘pa orúkọ rẹ́ kúrò’ nínú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 32:32, 33; Sáàmù 69:28) A jẹ́ pé ìkìlọ̀ pàtàkì ni ọ̀rọ̀ Aísáyà jẹ́—àfi bí àwọn tó tìgbèkùn bọ̀ bá ń bá a lọ láti wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run ni wọn yóò fi máa báa nìṣó ní gbígbé lórí ilẹ̀ wọn tó ti padà bọ̀ sípò.
16. (a) Kí ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ àwọn tó yọ̀ǹda fún láti padà sí Júdà lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àánú tí Jèhófà fi hàn sí àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” kò já sí asán?
16 Ète rere làwọn àṣẹ́kù tó padà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ní lọ́kàn tí wọ́n fi padà, ìyẹn ni, láti mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Ẹnikẹ́ni tí àbààwọ́n àṣà ẹ̀sìn abọ̀rìṣà tàbí ìwà àìmọ́ tí Aísáyà ti kìlọ̀ gbọnmọ-gbọnmọ lé lórí bá wà lára rẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti padà sílé. (Aísáyà 1:15-17) Kìkì àwọn tí Jèhófà bá kà sí mímọ́ nìkan ló lè padà lọ sí Júdà. (Aísáyà 35:8) Bákan náà, gbogbo ipá ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ń sà láti rí i pé àwọn wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run láti ọdún 1919 tí wọ́n ti gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn”—àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé—sì ti wá dara pọ̀ mọ́ wọn. (Jòhánù 10:16) Wọ́n ti yọwọ́ pátápátá nínú gbogbo ẹ̀kọ́ àti ìṣe Bábílónì. Olúkúlùkù wọn ń sakun láti má yẹ̀ kúrò lórí ìlànà ìwà rere gíga tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. (1 Pétérù 1:14-16) Àánú tí Jèhófà fi hàn sí wọn kò já sí asán.
17. Orúkọ àwọn wo ni Jèhófà ń kọ sínú “ìwé ìyè” rẹ̀, kí ló sì yẹ kí a pinnu láti ṣe?
17 Rántí pé Jèhófà kíyè sí àwọn èèyàn tó jẹ́ mímọ́ ní Ísírẹ́lì, ó sì ‘kọ orúkọ wọn sílẹ̀ fún ìwàláàyè.’ Lónìí pẹ̀lú, Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá tí a ń ṣe láti jẹ́ mímọ́ tọkàntara, bí a ṣe ń ‘fi ara wa fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe Róòmù 12:1) Ọlọ́run sì ń kọ orúkọ gbogbo àwọn tí ń gbé irú ìgbésí ayé yẹn sínú “ìwé ìyè” rẹ̀, ìyẹn ni, ìwé ìṣàpẹẹrẹ kan tí orúkọ àwọn tí yóò rí ìyè ayérayé gbà wà nínú rẹ̀, ì báà jẹ́ ìyè ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé. (Fílípì 4:3; Málákì 3:16) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run, nítorí ìyẹn ni a fi lè mú kí orúkọ wa máa bá a lọ láti wà nínú “ìwé” tó ṣeyebíye yẹn.—Ìṣípayá 3:5.
ìtẹ́wọ́gbà.’ (Ó Ṣèlérí Àbójútó Onífẹ̀ẹ́
18, 19. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 4:4, 5 ṣe fi hàn, irú ìfọ̀mọ́ wo ni Jèhófà fẹ́ ṣe, ọ̀nà wo ni yóò sì gbà ṣe é?
18 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà wá fi hàn bí àwọn olùgbé ilẹ̀ tó padà bọ̀ sípò yẹn yóò ṣe di mímọ́ àti àwọn ìbùkún tí ń bẹ nílẹ̀ fún wọn. Ó sọ pé: “Nígbà tí Jèhófà bá ti fọ ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ọmọbìnrin Síónì nù, tí yóò sì ṣan ìtàjẹ̀sílẹ̀ Jerúsálẹ́mù pàápàá kúrò láàárín rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìdájọ́ àti nípasẹ̀ ẹ̀mí jíjó kanlẹ̀, dájúdájú, Jèhófà yóò dá àwọsánmà ní ọ̀sán àti èéfín, àti ìtànyòò iná tí ń jó fòfò ní òru sórí gbogbo ibi àfìdímúlẹ̀ tí ń bẹ ní Òkè Ńlá Síónì àti sórí ibi àpéjọpọ̀ rẹ̀; nítorí pé ibi ààbò yóò wà lórí gbogbo ògo.”—Aísáyà 4:4, 5.
19 Níṣàájú, ìbáwí kíkankíkan ni Aísáyà fún “àwọn ọmọbìnrin Síónì,” tó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àṣehàn wọn bo ìwà ìbàjẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Ó tún tú àṣírí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn náà lápapọ̀, ó wá rọ̀ wọ́n láti lọ wẹ̀. (Aísáyà 1:15, 16; 3:16-23) Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló ń wo ọjọ́ iwájú, nígbà tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò ti “fọ ìgbọ̀nsẹ̀,” tàbí ìwà ẹ̀gbin wọn, tí yóò sì ‘fọ àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn.’ (Aísáyà 4:4, New International Version) Báwo ni yóò ṣe fọ̀ ọ́? Yóò jẹ́ nípasẹ̀ “ẹ̀mí ìdájọ́” àti nípasẹ̀ “ẹ̀mí jíjó kanlẹ̀.” Ìparun tí yóò dé bá Jerúsálẹ́mù àti lílọ tí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì yóò jẹ́ mímú tí Ọlọ́run mú kí ìdájọ́ àti ìbínú rẹ̀ jíjófòfò rọ́ lu orílẹ̀-èdè aláìmọ́ yẹn. Àwọn àṣẹ́kù tó bá la àjálù wọ̀nyẹn já, tí wọ́n sì padà délé yóò ti dẹni ìrẹ̀lẹ̀, táa ti yọ́ mọ́. Ìdí nìyẹn tí wọn yóò fi jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà, tí yóò sì ṣàánú wọn.—Fi wé Málákì 3:2, 3.
20. (a) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ bí “àwọsánmà,” “èéfín,” àti “iná tí ń jó fòfò” múni rántí? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn ìgbèkùn táa ti wẹ̀ mọ́ bẹ̀rù?
20 Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà ṣèlérí pé àbójútó onífẹ̀ẹ́ lòun yóò fún àwọn àṣẹ́kù táa ti wẹ̀ mọ́ yìí. Ńṣe ni gbólóhùn náà “àwọsánmà,” “èéfín,” àti “iná tí ń jó fòfò” múni rántí bí Jèhófà ṣe bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. “Ọwọ̀n iná àti àwọsánmà” ló dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tí ń lépa wọn bọ̀; ó tún ṣamọ̀nà wọn nínú aginjù. (Ẹ́kísódù 13:21, 22; 14:19, 20, 24) Nígbà tí Jèhófà fara hàn lórí Òkè Sínáì, òkè yẹn “rú èéfín káríkárí.” (Ẹ́kísódù 19:18) Nígbà náà, ìbẹ̀rù kankan kò ní sí fún àwọn ìgbèkùn táa ti wẹ̀ mọ́ yẹn. Jèhófà ni yóò jẹ́ Aláàbò wọn. Ì báà jẹ́ inú ilé wọn ni wọ́n kóra jọ sí tàbí wọ́n pé jọ sí àwọn àpéjọpọ̀ mímọ́, yóò wà pẹ̀lú wọn.
21, 22. (a) Ète wo ni wọ́n sábà máa ń pa àtíbàbà, tàbí ahéré fún? (b) Kí ni ìrètí tí ń bẹ níwájú fún àṣẹ́kù tó ti dẹni táa wẹ̀ mọ́?
21 Aísáyà wá fi ọ̀ràn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ parí àpèjúwe tó ń ṣe bọ̀ nípa ààbò Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Àtíbàbà kan yóò sì wà fún ibòji ní ọ̀sán kúrò lọ́wọ́ ooru gbígbẹ, àti fún ibi ìsádi àti fún ibi ìfarapamọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò àti kúrò lọ́wọ́ ìrọ̀sílẹ̀ òjò.” (Aísáyà 4:6) Ìdí táwọn èèyàn fi sábà máa ń pa àtíbàbà tàbí ahéré sínú ọgbà àjàrà tàbí sínú pápá ni láti ríbi forí pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ oòrùn ìgbà ẹ̀rùn tó máa ń mú janjan àti kúrò lọ́wọ́ òtútù àti ìjì ìgbà òjò.—Fi wé Jónà 4:5.
22 Nígbà tí ooru inúnibíni àti ìjì àtakò bá dé, Jèhófà ni Ẹni tí yóò jẹ́ ibi ààbò, ìpamọ́, àti ìsádi fáwọn àṣẹ́kù táa ti wẹ̀ mọ́ yìí. (Sáàmù 91:1, 2; 121:5) Nípa bẹ́ẹ̀, ìrètí àtàtà ní ń bẹ níwájú fún wọn, ìyẹn ni pé: Bí wọ́n bá kọ àwọn ìgbàgbọ́ àti ìṣe aláìmọ́ tó wà nínú Bábílónì sílẹ̀, tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún ìfọ̀mọ́ tí ìdájọ́ Jèhófà fẹ́ ṣe, tí wọ́n sì gbìyànjú láti jẹ́ mímọ́, wọn yóò máa wà láìséwu bíi pé wọ́n wà lábẹ́ “àtíbàbà” ààbò Ọlọ́run.
23. Èé ṣe tí Jèhófà fi bù kún àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn?
23 Ṣàkíyèsí pé ìfọ̀mọ́ ló kọ́kọ́ ṣáájú, kí àwọn ìbùkún tó dé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà tiwa. Lọ́dún 1919 lọ́hùn-ún, àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró fi ìrẹ̀lẹ̀ jọ̀wọ́ ara wọn fún ìyọ́mọ́, Jèhófà sì “fọ” àìmọ́ wọn “nù.” Láti ìgbà náà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ti jẹ́ kí Jèhófà wẹ àwọn mọ́. (Ìṣípayá 7:9) Bí àṣẹ́kù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe wá dẹni táa ti wẹ̀ mọ́, ìbùkún bá wọn—Jèhófà fi wọ́n sábẹ́ ààbò rẹ̀. Kò fi ọ̀nà ìyanu dènà ooru inúnibíni tàbí kí ìjì àtakò má ṣe rọ́ lù wọ́n. Ṣùgbọ́n ó dájú pé ó ń dáàbò bò wọ́n, bíi pé ó pa ‘àtíbàbà fún ibòji àti ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ìjì òjò’ fún wọn. Báwo?
24. Báwo ló ṣe hàn gbangba pé Jèhófà ti bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan?
24 Gbé èyí yẹ̀ wò ná: Àwọn kan lára àwọn ìjọba tí ìtàn fi hàn pé ó jẹ́ alágbára jù lọ ló ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe tàbí kí wọ́n ti gbìyànjú láti kúkú pa wọ́n rẹ́. Síbẹ̀, gbọn-in gbọn-in làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró, wọ́n ń bá ìwàásù wọn lọ láìdáwọ́dúró! Kí ni ìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ò fi lè fòpin sí ìgbòkègbodò àwùjọ ènìyàn yìí, tó kéré sí wọn, tó sì dà bí èyí tí kò lóhun ìjà kankan? Ìdí ni pé abẹ́ “àtíbàbà” ààbò tẹ́nikẹ́ni ò mà lè wó dànù ni Jèhófà kó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti wẹ̀ mọ́ sí o!
25. Kí ni ohun tí níní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Aláàbò wa túmọ̀ sí fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
25 Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Pé Jèhófà jẹ́ Aláàbò wa kò túmọ̀ sí pé ńṣe ni gbogbo nǹkan yóò máa rọ̀ ṣọ̀mù fún wa nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ni àjálù ńláńlá ń bá, àwọn nǹkan bí ipò òṣì, àwọn ìjábá, ogun, àìsàn, àti ikú. Bí irú àwọn ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ bá báni, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé Ọlọ́run wa wà pẹ̀lú wa. Ó ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, ní pípèsè ohun tí a nílò—kódà ó ń pèsè “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” pàápàá—tí yóò jẹ́ ká lè fi ìṣòtítọ́ fara da àdánwò. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Kò sídìí fún wa láti bẹ̀rù, nítorí iwájú rẹ̀ táa wà yìí, abẹ́ ààbò ni. Ó ṣe tán, báa bá ṣáà ti ń sa gbogbo ipá wa láti wà ní mímọ́ lójú rẹ̀, kò sóhun tí “yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:38, 39.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 6 Èrò tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbé jáde ni pé Mèsáyà, ẹni tó jẹ́ pé ó di ẹ̀yìn ìmúbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù kó tó dé, ni gbólóhùn náà ‘èéhù Jèhófà’ tọ́ka sí. Bíbélì Aramaic Targums tún gbólóhùn yìí sọ lọ́rọ̀ mìíràn, ó kà báyìí pé: “Mèsáyà [Kristi] Jèhófà.” Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ orúkọ yìí kan náà, (tseʹmach) lédè Hébérù, ni Jeremáyà tún lò lẹ́yìn náà nígbà tó pe Mèsáyà ní “èéhù kan tí ó jẹ́ olódodo” tí wọ́n gbé dìde fún Dáfídì.—Jeremáyà 23:5; 33:15.
^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n bí nígbèkùn wà lára “àwọn tí ó sá àsálà.” A lè sọ pé àwọn wọ̀nyí “sá àsálà” nítorí ká ní àwọn baba ńlá wọn ò la ìparun yẹn ni, wọn kì bá bí wọn rárá.—Ẹ́sírà 9:13-15; fi wé Hébérù 7:9, 10.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 63]
Ìjì ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀ wá sórí Júdà