Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Sọ Ìyangàn Tírè Di Ẹ̀tẹ́

Jèhófà Sọ Ìyangàn Tírè Di Ẹ̀tẹ́

Orí Kọkàndínlógún

Jèhófà Sọ Ìyangàn Tírè Di Ẹ̀tẹ́

Aísáyà 23:1-18

1, 2. (a) Irú ìlú wo ni Tírè àtijọ́ jẹ́? (b) Kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Tírè?

“ẸWÀ rẹ̀ pé,” bẹ́ẹ̀ ni “onírúurú dúkìá gbogbo” sì kún ibẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 27:4, 12, An American Translation) Ọ̀nà jíjìn réré ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun rẹpẹtẹ tó ní máa ń ná. Ó di “ológo gidigidi ní àárín òkun gbalasa,” ó sì ti fi “àwọn nǹkan rẹ tí ó níye lórí” “sọ àwọn ọba ilẹ̀ ayé di ọlọ́rọ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 27:25, 33) Ipò tí ìlú Tírè, tí ń bẹ nílẹ̀ Foníṣíà ní ìkángun ìlà oòrùn Mẹditaréníà, wà nìyẹn ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa.

2 Síbẹ̀, ìparun rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Tírè. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí Ìsíkíẹ́lì tó ṣàpèjúwe ìlú tó jẹ́ odi agbára Foníṣíà yìí ni wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú rẹ̀ àti ìbànújẹ́ tí yóò kó bá àwọn tó gbára lé e. Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ Ọlọ́run yóò yí àfiyèsí sí ìlú yìí, yóò sì jẹ́ kó tún padà láásìkí. Báwo lọ̀rọ̀ wòlíì yìí ṣe ṣẹ? Kí la sì lè rí kọ́ látinú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tírè? Táa bá lóye àjálù tó bá a yékéyéké, táa sì lóye ìdí tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ṣẹlẹ̀, yóò fún ìgbàgbọ́ táa ní nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ lókun.

“Ẹ Hu, Ẹ̀yin Ọkọ̀ Òkun Táṣíṣì!”

3, 4. (a) Ibo ni Táṣíṣì wà, báwo sì ni Tírè àti Táṣíṣì ṣe jẹ́ síra wọn? (b) Kí ni ìdí tí àwọn atukọ̀ òkun tó ń ṣòwò ní Táṣíṣì yóò fi “hu”?

3 Aísáyà fi “Ọ̀rọ̀ ìkéde nípa Tírè” ṣe àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wá kéde pé: “Ẹ hu, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì! nítorí a ti fi í ṣe ìjẹ kúrò nínú jíjẹ́ èbúté ọkọ̀, kúrò nínú jíjẹ́ ibi wíwọ̀.” (Aísáyà 23:1a) Wọ́n ka Táṣíṣì sí ara ilẹ̀ Sípéènì, níbi tó jìnnà réré sí Tírè níhà ìlà oòrùn Mẹditaréníà. * Àmọ́, àwọn ará Foníṣíà mọwọ́ ọkọ̀ òkun dọ́ba, ọkọ̀ òkun wọn gbòòrò, ara rẹ̀ sì gba ìyà lójú òkun. Àwọn òpìtàn kan gbà gbọ́ pé àwọn ará Foníṣíà ló kọ́kọ́ ṣàkíyèsí ìsopọ̀ tó wà láàárín òṣùpá àti ìrusókè omi òkun, pé àwọn ló sì kọ́kọ́ ń lo ìmọ̀ nípa ìlànà ojú ọ̀run láti fi rìnrìn àjò. Nítorí náà, ọ̀nà jíjìn tó wà láàárín Tírè àti Táṣíṣì kò jẹ́ ohunkóhun lójú wọn rárá.

4 Nígbà ayé Aísáyà, ibi ìṣòwò pàtàkì ni Táṣíṣì tó jìnnà yìí jẹ́ fún Tírè, ó jọ pé ibẹ̀ gan-an ló jẹ́ kí Tírè di ọlọ́là láàárín àkókò kan nínú ìtàn rẹ̀. Ilẹ̀ Sípéènì ní àwọn ibi ìwakùsà tí wọ́n ti ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fàdákà, irin, tánganran àti irú àwọn irin mìíràn. (Fi wé Jeremáyà 10:9; Ìsíkíẹ́lì 27:12.) Ìdí nìyẹn tí àwọn “ọkọ̀ òkun Táṣíṣì,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọkọ̀ òkun láti Tírè tí wọ́n fi ń ṣòwò ní Táṣíṣì, yóò fi “hu,” ìyẹn ni pé wọ́n á kédàárò nítorí ìparun tó dé bá ibùdókọ̀ òkun tó wà ní ìlú wọn.

5. Ibo làwọn atukọ̀ tó ń bọ̀ láti Táṣíṣì yóò ti gbọ́ nípa ìṣubú Tírè?

5 Báwo làwọn atukọ̀ tó wà lójú òkun yóò ṣe gbọ́ nípa ìṣubú Tírè? Aísáyà dáhùn pé: “Láti ilẹ̀ Kítímù ni a ti ṣí i payá fún wọn.” (Aísáyà 23:1b) Ó jọ pé “ilẹ̀ Kítímù” tọ́ka sí erékùṣù Kípírọ́sì, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà síhà ìwọ̀ oòrùn etíkun Foníṣíà. Ibi ìkẹyìn tí àwọn ọkọ̀ òkun tó ń lọ síhà ìlà oòrùn láti Táṣíṣì ti máa ń dúró nìyẹn kí wọ́n tó dé Tírè. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbà tí àwọn atukọ̀ bá dúró díẹ̀ ní Kípírọ́sì ni wọ́n máa gbọ́ ìròyìn pé èbúté ìlú wọn àtàtà ti parẹ́. Yóò mà bá wọn lójijì o! Ìbànújẹ́ yóò bò wọ́n, wọn yóò sì máa “hu” nínú ìdààmú ọkàn.

6. Ṣàpèjúwe bí Tírè àti Sídónì ṣe jẹ́ síra.

6 Ìdààmú ọkàn yóò bá àwọn èèyàn etíkun Foníṣíà pẹ̀lú. Wòlíì yìí sọ pé: “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ etí òkun. Àwọn olówò láti Sídónì, àwọn tí ń sọdá òkun—wọ́n ti kún inú rẹ. Orí omi púpọ̀ sì ni irúgbìn Ṣíhórì wà, ìkórè Náílì, owó àpawọlé rẹ̀; ó sì wá jẹ́ èrè àwọn orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 23:2, 3) Àwọn “olùgbé ilẹ̀ etí òkun,” ìyẹn àwọn tó wà láyìíká Tírè, yóò dákẹ́ rọ́rọ́ nítorí pé kàyéfì gbáà ló jẹ́ fún wọn bí Tírè ṣe ṣubú yakata. Àwọn wo ni “olówò láti Sídónì” tó “kún inú” àgbègbè wọ̀nyí, tó sì sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀? Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, àwọn ará Sídónì, tí í ṣe ìlú èbúté tó wà ní kìlómítà márùndínlógójì péré síhà àríwá Tírè, ló lọ dá dó sí Tírè. Sídónì tiẹ̀ kọ ọ́ sára owó ẹyọ rẹ̀ pé òun ni ìyá Tírè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ti Tírè padà wá ju ti Sídónì lọ, “ọmọbìnrin Sídónì” ṣì ni, àti pé ará Sídónì làwọn tí ń gbé ibẹ̀ ṣì ń pe ara wọn. (Aísáyà 23:12) Nítorí náà, ó jọ pé àwọn oníṣòwò tó ń gbé ní Tírè lọ̀rọ̀ náà “àwọn olówò láti Sídónì” ń tọ́ka sí.

7. Báwo làwọn oníṣòwò ará Sídónì ṣe tan ọrọ̀ kálẹ̀?

7 Òwò ṣíṣe máa ń gbé àwọn oníṣòwò tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní Sídónì sọdá Òkun Mẹditaréníà. Wọ́n máa ń gbé èso, tàbí ọkà, láti Ṣíhórì, ìyẹn ẹ̀ka tó sún mọ́ ìhà ìlà oòrùn jù lọ lára ibi tí Odò Náílì ti pẹ̀ka wọnú òkun lágbègbè Íjíbítì. (Fi wé Jeremáyà 2:18.) Àwọn nǹkan yòókù tó ń wá láti Íjíbítì pẹ̀lú jẹ́ ara “ìkórè Náílì.” Ṣíṣe òwò tàbí pàṣípààrọ̀ irú àwọn ẹrù ọjà bẹ́ẹ̀ ń mérè wá gan-an ni fáwọn oníṣòwò ojú òkun wọ̀nyí àtàwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jọ ń ṣòwò. Ńṣe ni owó tí Tírè ń rí pa wálé látọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò ará Sídónì kún inú Tírè. Áà, wọ́n á mà kẹ́dùn o nítorí ìsọdahoro rẹ̀!

8. Ipa wo ni ìparun Tírè yóò ní lórí Sídónì?

8 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Sídónì pé: “Kí ojú tì ọ́, ìwọ Sídónì; nítorí pé òkun, ìwọ ibi odi agbára òkun, ti sọ pé: ‘Èmi kò ní ìrora ìbímọ rí, èmi kò sì bímọ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rí, èmi kò sì tọ́jú àwọn wúńdíá dàgbà.’” (Aísáyà 23:4) Lẹ́yìn ìparun Tírè, ṣe ni etíkun níbi tí ìlú yẹn wà tẹ́lẹ̀ yóò dà bí ibi tó jẹ́ aṣálẹ̀ àti ahoro. Yóò wá dà bí pé òkun ń ké tẹ̀dùntẹ̀dùn, bí ìyá tó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀, tí àdánù yẹn sì dà á lórí rú dépò tó fi kúkú sọ pé òun kọ́ lòun bí wọn. Ìtìjú yóò bá Sídónì látàrí ohun tó bá ọmọbìnrin rẹ̀.

9. Ẹ̀dùn ọkàn tó bá àwọn èèyàn lẹ́yìn ìṣubú Tírè yóò jọ ìpayà tó wáyé nígbà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn wo?

9 Bẹ́ẹ̀ ni, ìròyìn ìparun Tírè yóò fa ìbànújẹ́ káàkiri ibi púpọ̀. Aísáyà sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó jẹ mọ́ Íjíbítì, bákan náà ni àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora mímúná nítorí ìròyìn nípa Tírè.” (Aísáyà 23:5) Ìrora àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ yóò jọ ìrora tí àwọn èèyàn ní nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn nípa Íjíbítì. Ìròyìn wo ni wòlíì yẹn ní lọ́kàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti ìmúṣẹ “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Íjíbítì,” èyí tó ti sọ ṣáájú. * (Aísáyà 19:1-25) Tàbí bóyá ìròyìn nípa ìparun ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò nígbà ayé Mósè, èyí tó kó ìpáyà bá àwọn èèyàn káàkiri, ni wòlíì yìí ní lọ́kàn. (Ẹ́kísódù 15:4, 5, 14-16; Jóṣúà 2:9-11) Bó ti wù kó rí, ìrora mímúná yóò bá àwọn tó bá gbọ́ ìròyìn nípa ìparun Tírè. Ó ní kí wọ́n sá lọ forí pa mọ́ sí Táṣíṣì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ké igbe ẹ̀dùn wọn sókè, ó ní: “Ẹ sọdá sí Táṣíṣì; ẹ hu, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ etí òkun.”—Aísáyà 23:6.

Ó Kún fún Ayọ̀ Ńláǹlà “Láti Àwọn Àkókò Ìjímìjí Rẹ̀”

10-12. Ṣàlàyé nípa ọrọ̀ Tírè, ìgbà tí Tírè ti wà, àti bí òkìkí rẹ̀ ṣe kàn tó.

10 Ìlú àtayébáyé ni Tírè jẹ́, àní bí Aísáyà ṣe rán wa létí nígbà tó béèrè pé: “Ṣé èyí ni ìlú ńlá yín tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, láti àwọn àkókò ìjímìjí rẹ̀?” (Aísáyà 23:7a) Ó kéré tán, láti ìgbà ayé Jóṣúà lọ́hùn-ún ló ti wà nínú ìtàn pé Tírè láásìkí. (Jóṣúà 19:29) Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, Tírè dolókìkí nídìí fífi irin rọ onírúurú nǹkan, ṣíṣe àwọn ohun èlò onígíláàsì, àti ṣíṣe aró aláwọ̀ àlùkò. Ẹ̀wù aláwọ̀ àlùkò tí wọ́n ń ṣe ní Tírè gbówó lórí gan-an ni, àwọn ọ̀tọ̀kùlú a sì máa du àwọn aṣọ olówó ńlá tó ń wá láti Tírè rà. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 27:7, 24.) Tírè tún jẹ́ ojúkò ìṣòwò fáwọn arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀, ó sì tún jẹ́ ibi pàtàkì tí wọ́n ń já àwọn ẹrù tó ń wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè àti èyí tó ń lọ sílẹ̀ òkèèrè sí pẹ̀lú.

11 Ẹ̀wẹ̀, ìlú yẹn tún lágbára ogun jíjà. L. Sprague de Camp kọ̀wé pé: “Lóòótọ́, àwọn ará Fonísíà kì í ṣe ológun, nítorí sójà kọ́ ni wọ́n, iṣẹ́ káràkátà niṣẹ́ wọn, àmọ́ tó bá ti dọ̀ràn dídáàbò bo ìlú wọn, tìgboyàtìgboyà ni wọ́n yóò fi jà, àjààgbulà sì ni. Ànímọ́ wọ̀nyí àti bí wọ́n ṣe jáfáfá tó lójú omi ló jẹ́ kí àwọn ará Tírè lè dènà ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà, tó lágbára jù lọ lásìkò yẹn.”

12 Ní tòótọ́, Tírè kò kẹ̀rẹ̀ rárá lágbègbè Mẹditaréníà ayé ìgbà yẹn. “Tẹ́lẹ̀ rí, ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ń gbé e lọ sí ibi jíjìnnàréré láti ṣe àtìpó.” (Aísáyà 23:7b) Àwọn ará Foníṣíà máa ń rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìnréré, wọn a máa dá ibùdó ìṣòwò àti èbúté sílẹ̀ káàkiri, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn wọn a sì kúkú sọ ibẹ̀ di ìlú àdádó tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Tírè ló lọ dá dó sí ìlú Carthage ní etíkun ìhà àríwá Áfíríkà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ibẹ̀ wá lókìkí ju Tírè lọ, àní Róòmù nìkan ló lẹ́nu ọ̀rọ̀ ju ìlú yìí ní gbogbo ẹkùn Mẹditaréníà.

Ìyangàn Rẹ̀ Yóò Di Ẹ̀tẹ́

13. Èé ṣe tí wọ́n fi ń béèrè pé ta ló tó dá Tírè lẹ́jọ́?

13 Látàrí wíwà tí Tírè ti wà látayébáyé àti ọrọ̀ tó ní, ó tọ́ bí wọ́n ṣe béèrè ìbéèrè yìí pé: “Ta ni ó ti ṣe ìpinnu yìí lòdì sí Tírè, tí í ṣe adéniládé, tí àwọn olówò rẹ̀ jẹ́ ọmọ aládé, tí àwọn oníṣòwò rẹ̀ jẹ́ ọlọ́lá ilẹ̀ ayé?” (Aísáyà 23:8) Ta ló tó sọ̀rọ̀ sí ìlú tó jẹ́ pé òun ló ń yan ẹni tó máa wà láwọn ipò ńláńlá ní àwọn ilẹ̀ àdádó rẹ̀ àti àwọn ibòmíràn, tó fi tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ “adéniládé”? Ta ló tó sọ̀rọ̀ sí olú ìlú táwọn olówò rẹ̀ jẹ́ ọmọ aládé, táwọn oníṣòwò rẹ̀ sì jẹ́ ọlọ́lá ayé? Maurice Chehab, alábòójútó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tẹ́lẹ̀ ní Ilé Iṣẹ́ Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ní ìlú Beirut, lórílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì, sọ pé: “Irú ipò pàtàkì tí ìlú London wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún gẹ́lẹ́ ni Tírè wà láàárín ọ̀rúndún kẹsàn-án títí dé ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa.” Nítorí náà, ta ló tó sọ̀rọ̀ sí ìlú yìí ná?

14. Ta ní dá Tírè lẹ́jọ́, kí ló sì fà á?

14 Ọ̀rọ̀ onímìísí tó dáhùn èyí yóò ṣe àwọn ará Tírè ní kàyéfì. Aísáyà sọ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti ṣe ìpinnu yìí, láti sọ ìyangàn gbogbo ẹwà di aláìmọ́, láti fojú tín-ín-rín gbogbo ọlọ́lá ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 23:9) Èé ṣe tí Jèhófà fi dá ìlú àtayébáyé, ìlú ọlọ́rọ̀ yìí, lẹ́jọ́? Ṣé torí pé àwọn aráàlú yìí ń bọ òrìṣà Báálì ni? Ṣé nítorí pé Tírè tan mọ́ Jésíbẹ́lì ni, ìyẹn ọmọbìnrin Étíbáálì ọba Sídónì àti ti Tírè, ẹni tó fẹ́ Áhábù ọba Ísírẹ́lì tó sì pa àwọn wòlíì Jèhófà? (1 Àwọn Ọba 16:29, 31; 18:4, 13, 19) Rárá ni ìdáhùn ìbéèrè méjèèjì yìí. Yíyangàn tí Tírè ń yangàn ló jẹ́ kó gba ìdájọ́, ó tún jẹ́ apanilẹ́kún-jayé, tó ń fá àwọn èèyàn lórí, títí kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ Jóẹ́lì sọ fún Tírè àtàwọn ìlú yòókù pé: “Àwọn ọmọ Júdà àti àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù ni ẹ sì ti tà fún àwọn ọmọ Gíríìkì, fún ète mímú wọn jìnnà réré kúrò ní ìpínlẹ̀ wọn.” (Jóẹ́lì 3:6) Ṣé kí Ọlọ́run wá gbójú fo bí Tírè ṣe pàtẹ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú bí ẹní pàtẹ wóróbo ni?

15. Kí ni yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà Tírè nígbà tí Jerúsálẹ́mù bá ṣubú sọ́wọ́ Nebukadinésárì?

15 Àní lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún pàápàá, kàkà kéwé àgbọn Tírè ó rọ̀, líle ni yóò máa le sí i. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Nebukadinésárì ọba Bábílónì bá pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ṣe ni Tírè yóò máa yọ̀ ṣìnkìn pé: “Àháà! A ti ṣẹ́ ẹ [Jerúsálẹ́mù], ilẹ̀kùn àwọn ènìyàn! Dájúdájú, ọ̀dọ̀ mi ni a ó tẹ̀ sí. A óò kún inú mi—a ti pa á run di ahoro.” (Ìsíkíẹ́lì 26:2) Tírè yóò yọ̀ bó ṣe ń retí pé ìparun Jerúsálẹ́mù yóò ṣe òun láǹfààní. Á máa retí pé nísinsìnyí tí olú ìlú Júdà tí wọ́n jọ ń du ọjà mọ́ra wọn lọ́wọ́ kò sí mọ́, kájé máa ya wọgbá òun wìtìwìtì ló kù. Ṣe ni Jèhófà yóò ṣe àwọn “ọlọ́lá” rẹ̀ ṣúkaṣùka, àwọn tó ń fi ìyangàn kín ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn.

16, 17. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará Tírè nígbà tí ìlú yẹn bá ṣubú? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

16 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ lórí bí Jèhófà ṣe dá Tírè lẹ́jọ́, ó ní: “Sọdá ilẹ̀ rẹ bí Odò Náílì, ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì. Kò tún sí ọgbà tí a ti ń kan ọkọ̀ òkun mọ́. Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun; ó ti kó ṣìbáṣìbo bá àwọn ìjọba. Jèhófà tìkára rẹ̀ ti pa àṣẹ lòdì sí Foníṣíà, láti pa àwọn ibi odi agbára rẹ̀ rẹ́ ráúráú. Ó sì wí pé: ‘Má yọ ayọ̀ ńláǹlà mọ́ láé, ìwọ ẹni tí a ni lára, wúńdíá ọmọbìnrin Sídónì. Dìde, sọdá sí Kítímù alára. Níbẹ̀ pàápàá, ìwọ kì yóò rí ìsinmi.’”—Aísáyà 23:10-12.

17 Èé ṣe tí wọ́n fi pe Tírè ní “ọmọbìnrin Táṣíṣì”? Bóyá nítorí pé Táṣíṣì ni yóò lágbára jù nínú àwọn méjèèjì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣẹ́gun Tírè. * Ńṣe ni wọ́n máa fọ́n àwọn aráàlú Tírè tó ti dahoro káàkiri bí odò tó kún àkúnya, tó sì ya kọjá bèbè rẹ̀, tómi rẹ̀ sì ń ṣàn káàkiri gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àyíká rẹ̀. Ohun tí Aísáyà ń sọ fún “ọmọbìnrin Táṣíṣì” túbọ̀ jẹ́ ká rí bí àjálù tí ń bọ̀ wá sórí Tírè yóò ṣe kira tó. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló na ọwọ́ rẹ̀ tó sì pàṣẹ yìí. Kò sẹ́nikẹ́ni tó lè yí ìmúṣẹ rẹ̀ padà.

18. Èé ṣe tí wọ́n fi pe Tírè ní “wúńdíá ọmọbìnrin Sídónì,” báwo sì ni àyípadà yóò ṣe bá a?

18 Aísáyà tún pe Tírè ní “wúńdíá ọmọbìnrin Sídónì,” tó fi hàn pé àwọn ajagunṣẹ́gun láti ilẹ̀ òkèèrè kò tíì ṣẹ́gun ìlú yẹn kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù lọ rí, ìlú tí wọn kò tẹ̀ lórí ba rí ni. (Fi wé 2 Àwọn Ọba 19:21; Aísáyà 47:1; Jeremáyà 46:11.) Àmọ́, ní báyìí, ṣe ni wọ́n máa pa á rẹ́, tí àwọn kan lára àwọn ará ibẹ̀ yóò sì sá lọ forí pa mọ́ sí Kítímù, ọ̀kan lára ìlú táwọn ará Fonísíà dá dó sí. Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìsinmi fún wọn lọ́hùn-ún nítorí pé ọrọ̀ ajé wọn ti fọ́.

Àwọn Ará Kálídíà Yóò Fi Í Ṣe Ìjẹ

19, 20. Ta ni àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò ṣẹ́gun Tírè, báwo sì ni ìyẹn ṣe ṣẹ?

19 Ìjọba wo ni yóò mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lórí Tírè? Aísáyà kéde pé: “Wò ó! Ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà. Èyí ni àwọn ènìyàn náà—kì í ṣe Ásíríà ni ẹni náà—wọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún àwọn olùgbé aṣálẹ̀. Wọ́n ti gbé àwọn ilé gogoro wọn ti ìsàgatì nà ró; wọ́n ti tú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sí borokoto; ẹnì kan ti ṣe é ní ìrúnwómúwómú. Ẹ hu, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì, nítorí pé a ti fi ibi odi agbára yín ṣe ìjẹ.” (Aísáyà 23:13, 14) Àwọn ará Ásíríà kọ́ ló máa ṣẹ́gun Tírè, àwọn ará Kálídíà ni. Wọn yóò gbé àwọn ilé gogoro ìsàgatì nà ró, wọ́n yóò wó àwọn ibùgbé Tírè palẹ̀ bẹẹrẹ, wọn yóò sì sọ odi agbára àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì yẹn di òkìtì àlàpà.

20 Bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ lóòótọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn ìṣubú Jerúsálẹ́mù tí Tírè fi ṣọ̀tẹ̀ sí Bábílónì, ni Nebukadinésárì bá wá sàga ti ìlú náà. Tírè gbà pé mìmì kan ò lè mi òun, nítorí náà kò juwọ́ sílẹ̀. Iṣẹ́ ìsàgatì yẹn ló mórí àwọn ọmọ ogun Bábílónì “pá” bí àṣíborí wọn ṣe ń yán irun orí wọn, tí èjìká wọn sì “di èyí tí a mú bó” látàrí ẹrù ohun èlò ìsàgatì tí wọ́n ń rù ṣáá. (Ìsíkíẹ́lì 29:18) Ohun kékeré kọ́ ni ìsàgatì yẹn ná Nebukadinésárì. Ó pa ìlú Tírè tó wà létíkun run lóòótọ́, àmọ́ kò rí ìkógun kankan kó níbẹ̀. Wọ́n ti kó ojúlówó ìṣúra Tírè sọdá lọ sí erékùṣù kékeré kan tó dín díẹ̀ ní kìlómítà kan sí orí ilẹ̀. Níwọ̀n bí Ọba àwọn ará Kálídíà yìí kò sì ti ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ ojú omi, kò ṣeé ṣe fún un láti gba erékùṣù yẹn. Ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn náà ni Tírè túúbá, àmọ́, ó ṣì wà lẹ́yìn náà, tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn fi wá ṣẹ sí i lára.

“Yóò sì Padà Sídìí Ọ̀yà Rẹ̀”

21. Ọ̀nà wo ni Tírè fi di ‘ìgbàgbé,’ títí di ìgbà wo sì ni?

21 Aísáyà wá sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Tírè ni a ó gbàgbé fún àádọ́rin ọdún, lọ́nà kan náà bí àwọn ọjọ́ ọba kan.” (Aísáyà 23:15a) Lẹ́yìn tí àwọn ará Bábílónì bá ti pa ìlú Tírè tó wà létíkun run, ìlú Tírè tó jẹ́ erékùṣù “ni a ó gbàgbé.” Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ, ọrọ̀ ajé ìlú Tírè tó jẹ́ erékùṣù yóò dẹnu kọlẹ̀, ní àsìkò tí “ọba kan,” ìyẹn Ilẹ̀ Ọba Bábílónì, yóò fi ṣàkóso. Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ ọ́ pé Tírè wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tóun ti yàn láti fún ní wáìnì ìbínú Òun mu. Ó ní: “Orílẹ̀-èdè wọ̀nyí yóò sì ní láti sin ọba Bábílónì fún àádọ́rin ọdún.” (Jeremáyà 25:8-17, 22, 27) Lóòótọ́, ìlú Tírè tó jẹ́ erékùṣù kò sin Bábílónì pé àádọ́rin ọdún, nítorí pé ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ilẹ̀ Ọba Bábílónì ṣubú. Ó hàn pé àádọ́rin ọdún yẹn dúró fún sáà tí ìṣàkóso Bábílónì múlẹ̀ jù lọ, ìyẹn ni àsìkò tí ìdílé tó ń jọba Bábílónì fi fọ́nnu pé òun gbé ìtẹ́ òun ga ré kọjá “àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run” pàápàá. (Aísáyà 14:13) Wọ́n jẹgàba lórí onírúurú orílẹ̀-èdè lónírúurú àsìkò. Àmọ́, lópin àádọ́rin ọdún, ìjẹgàba yẹn yóò dópin. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí Tírè?

22, 23. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè nígbà tó bá kúrò lábẹ́ àkóso Bábílónì?

22 Aísáyà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní òpin àádọ́rin ọdún, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin kárùwà kan ti wí pé: ‘Mú háàpù, lọ yí ká ìlú ńlá, ìwọ kárùwà tí a ti gbàgbé. Sa gbogbo ipá rẹ ní títa àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín; sọ orin rẹ di púpọ̀, kí a lè rántí rẹ.’ Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní òpin àádọ́rin ọdún náà pé Jèhófà yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí Tírè, yóò sì padà sídìí ọ̀yà rẹ̀, yóò sì máa bá gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí ó wà ní ojú ilẹ̀ ṣe kárùwà.”—Aísáyà 23:15b-17.

23 Lẹ́yìn ìṣubú Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Foníṣíà di ara ìgbèríko Ilẹ̀ Ọba Mídíà òun Páṣíà. Kírúsì Ńlá ọba Páṣíà jẹ́ ẹni tí kì í fi nǹkan nini lára. Lábẹ́ ìṣàkóso tuntun yìí ni Tírè yóò ti padà bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀, yóò sì sapá gidi láti tún bọ́ sójú ọpọ́n padà gẹ́gẹ́ bí ojúkò ìṣòwò lágbàáyé, àní gẹ́gẹ́ bíi kárùwà tí a ti gbàgbé, tí àwọn oníbàárà rẹ̀ sì ti lọ, ṣe máa ń wá oníbàárà tuntun nípa lílọ káàkiri ìlú, tí yóò máa ta háàpù rẹ̀ tí yóò sì máa kọrin. Ṣé Tírè yóò ṣàṣeyọrí? Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò jẹ́ kó ṣàṣeyọrí. Bí àkókò ti ń lọ, ìlú erékùṣù náà yóò láásìkí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wòlíì Sekaráyà yóò fi lè sọ, lápá ìparí ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, pé: “Tírè sì tẹ̀ síwájú láti mọ ohun àfiṣe-odi fún ara rẹ̀, àti láti to fàdákà jọ pelemọ bí ekuru àti wúrà bí ẹrẹ̀ ojú pópó.”—Sekaráyà 9:3.

‘Èrè Rẹ̀ Yóò Sì Di Ohun Mímọ́’

24, 25. (a) Báwo ni èrè Tírè ṣe di ohun mímọ́ lójú Jèhófà? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tírè ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run, àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà mí sí wòlíì rẹ̀ láti sọ sí i?

24 Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí mà kúkú gbàfiyèsí o! Ó ní: “Èrè rẹ̀ àti ọ̀yà rẹ̀ yóò sì di ohun mímọ́ lójú Jèhófà. A kì yóò tò ó jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tọ́jú rẹ̀ pa mọ́, nítorí pé ọ̀yà rẹ̀ yóò wá jẹ́ ti àwọn tí ń gbé níwájú Jèhófà, fún jíjẹ àjẹyó àti fún ìbora agbógoyọ.” (Aísáyà 23:18) Báwo ni àwọn ohun ìní tí Tírè jèrè ṣe di ohun mímọ́? Ńṣe ni Jèhófà mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó mú kí wọ́n lò ó gẹ́gẹ́ bó ṣe fẹ́, ìyẹn ni pé, àwọn èèyàn rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lájẹgbádùn, wọ́n sì lò ó fún aṣọ wọn. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì ti ìgbèkùn Bábílónì dé. Àwọn ará Tírè ṣèrànwọ́ fún wọn nípa pípèsè àwọn pátákó kédárì fún wọn láti fi tún tẹ́ńpìlì kọ́. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìlú Jerúsálẹ́mù ṣòwò pẹ̀lú.—Ẹ́sírà 3:7; Nehemáyà 13:16.

25 Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ṣì mú kí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn sí Tírè. Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú erékùṣù tó ti wá dọlọ́rọ̀ nísinsìnyí pé: “Wò ó! Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò lé e kúrò, inú òkun ni òun yóò sì ṣá ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ balẹ̀ sí; inú iná ni a ó sì ti jẹ òun fúnra rẹ̀ run.” (Sekaráyà 9:4) Èyí ṣẹ ní July 332 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá wó ìyálóde àárín òkun tó jẹ́ agbéraga yìí palẹ̀.

Yàgò fún Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì àti Ìgbéraga

26. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi bẹnu àtẹ́ lu Tírè?

26 Jèhófà bẹnu àtẹ́ lu Tírè nítorí ìgbéraga rẹ̀, torí pé Ọlọ́run kórìíra ìwà yẹn. Nínú ohun méje tí Jèhófà kórìíra, “ojú gíga fíofío” ni Bíbélì kọ́kọ́ mẹ́nu kàn. (Òwe 6:16-19) Pọ́ọ̀lù ka ìgbéraga sí ìwà Sátánì Èṣù, àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì sì fi ṣàpèjúwe Tírè agbéraga wà lára àwọn nǹkan tó jẹ́ àpèjúwe Sátánì alára. (Ìsíkíẹ́lì 28:13-15; 1 Tímótì 3:6) Kí ló fa ìgbéraga Tírè ná? Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa Tírè, ó ní: “Ọkàn-àyà rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìrera nítorí ọlà rẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 28:5) Gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ nílùú yẹn kò ju pé kí wọ́n máa ṣòwò, kí wọ́n máa sáré owó kiri ṣáá. Àṣeyọrí tí Tírè sì ṣe nídìí èyí ló jẹ́ kí ìrera wá wọ̀ ọ́ lẹ́wù. Jèhófà gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ fún “aṣáájú Tírè” pé: “Ọkàn-àyà rẹ di onírera, ìwọ sì ń wí ṣáá pé, ‘Èmi jẹ́ ọlọ́run kan. Ìjókòó ọlọ́run ni mo jókòó sí, ní àárín òkun gbalasa.’”—Ìsíkíẹ́lì 28:2.

27, 28. Ọ̀fìn wo làwọn èèyàn lè jìn sí, báwo sì ni Jésù ṣe ṣàkàwé èyí?

27 Ìgbéraga lè wọ odindi orílẹ̀-èdè lẹ́wù, kí wọ́n sì gbé ọrọ̀ lé ọkàn jù, ìyẹn náà sì lè ṣẹlẹ̀ sí olúkúlùkù èèyàn pẹ̀lú. Jésù sọ àkàwé kan tó fi hàn bó ṣe rọrùn tó pé kéèyàn jìn sínú ọ̀fìn yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí oko rẹ̀ so wọ̀ǹtìwọnti. Inú ọkùnrin yìí dùn gan-an ni, ló bá pète láti kọ́ àwọn àká ńláńlá tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pé òun á jayé yìí pẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ò rí bó ṣe rò. Ọlọ́run sọ fún un pé: “Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni o, ọkùnrin yìí kú, ọrọ̀ rẹ̀ kò sì ṣe é láǹfààní kankan.—Lúùkù 12:16-20.

28 Jésù wá parí àkàwé yìí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Kò sí nǹkan kan tó burú nínú ká lọ́rọ̀, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú kéèyàn kórè oko wálé wọ̀ǹtìwọnti. Ibi tí ọkùnrin yìí ti ṣisẹ̀ gbé ni pé ó sọ nǹkan wọ̀nyí di ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ ní ìgbésí ayé. Ọrọ̀ rẹ̀ ló gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé. Bó ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú, kò tiẹ̀ ronú rárá nípa Jèhófà Ọlọ́run.

29, 30. Báwo ni Jákọ́bù ṣe kìlọ̀ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé ara ẹni?

29 Kókó kan náà ni Jákọ́bù tẹnu mọ́ gbọnmọ-gbọnmọ. Ó ní: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la a ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí, a ó sì lo ọdún kan níbẹ̀, a ó sì kó wọnú iṣẹ́ òwò, a ó sì jèrè,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ sọ pé: ‘Bí Jèhófà bá fẹ́, àwa yóò wà láàyè, a ó sì ṣe èyí tàbí èyíinì pẹ̀lú.’” (Jákọ́bù 4:13-15) Lẹ́yìn náà, Jákọ́bù wá fi ìsopọ̀ tó wà láàárín ọrọ̀ àti ìgbéraga hàn nígbà tó ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ẹ ń yangàn nínú ìfọ́nnu ìjọra-ẹni-lójú yín. Irú gbogbo ìyangàn bẹ́ẹ̀ burú.”—Jákọ́bù 4:16.

30 Lẹ́ẹ̀kan sí i, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú òwò ṣíṣe. Ohun tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ níbẹ̀ ni ẹ̀mí ìgbéraga, ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú, ẹ̀mí àwa-la-wà-ńbẹ̀ tó máa ń bá ọrọ̀ níní rìn. Òdodo ọ̀rọ̀ ni òwe àtijọ́ kan sọ tó wí pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀.” Òṣì lè kó ìpọ́njú báni gidigidi. Ṣùgbọ́n, ọrọ̀ lè tini débi ‘sísẹ́ Ọlọ́run wí pé: “Ta ni Jèhófà?”’—Òwe 30:8, 9.

31. Àwọn ìbéèrè wo ló tọ́ kí Kristẹni kan bi ara rẹ̀ léèrè?

31 Ayé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti gbé ẹ̀wù ìwọra àti ìmọtara ẹni nìkan wọ̀ là ń gbé. Nítorí ọ̀rọ̀ owó tó gba àwọn èèyàn lọ́kàn, ṣe làwọn èèyàn ń lépa ọrọ̀ lójú méjèèjì. Nítorí náà, ó tọ́ kí Kristẹni kan yẹ ara rẹ̀ wò láti rí i dájú pé òun ò jìn sínú ọ̀fìn kan náà tí Tírè, ìlú ìṣòwò yẹn, jìn sí. Kìràkìtà rẹ̀ nítorí ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti àkókò tó fi ń lépa rẹ̀ ha pọ̀ débi pé ó ti sọ ara rẹ̀ di ẹrú ọrọ̀ bí? (Mátíù 6:24) Ṣé ó ń ṣe ìlara àwọn tó bá ní dúkìá jù ú lọ tàbí tí dúkìá tiwọn dára ju tirẹ̀ lọ bí? (Gálátíà 5:26) Bí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, ǹjẹ́ ìgbéraga ń mú kó rò pé ó yẹ kí wọ́n máa fóun ní àkànṣe àyẹ́sí tàbí àǹfààní ju àwọn ẹlòmíràn? (Fi wé Jákọ́bù 2:1-9.) Bí kò bá sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, ṣé ó ti “pinnu láti di ọlọ́rọ̀” lọ́nàkọnà? (1 Tímótì 6:9) Ọ̀ràn iṣẹ́ ha dí i lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé agbára káká ló fi ń ráyè gbọ́ ti Ọlọ́run? (2 Tímótì 2:4) Ṣé lílépa ọrọ̀ gbà á lọ́kàn débi pé ó máa ń pa àwọn ìlànà Kristẹni tì nídìí iṣẹ́ rẹ̀?—1 Tímótì 6:10.

32. Ìkìlọ̀ wo ni Jòhánù ṣe, báwo la sì ṣe lè lò ó?

32 Ipò tó wù kí ọ̀ràn àtijẹ-àtimu wa wà, ipò kìíní ló yẹ kí Ìjọba Ọlọ́run wà nígbà gbogbo nínú ìgbésí ayé wa. Ó ṣe pàtàkì pé ká má gbàgbé ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù láé, tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:15) Lóòótọ́, ìṣètò táyé ṣe nípa ọrọ̀ ajé la ń lò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. (2 Tẹsalóníkà 3:10) Nípa bẹ́ẹ̀, a “ń lo ayé”—ṣùgbọ́n a kò lò ó “dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:31) Báa bá ti fẹ́ràn ohun ìní ti ara, ìyẹn àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé, láfẹ̀ẹ́jù, a ò fẹ́ràn Jèhófà mọ́ nìyẹn. Ìlépa “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” kò bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mu rárá. * Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló ń sinni lọ sí ìyè ayérayé.—1 Jòhánù 2:16, 17.

33. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè yẹra fún ọ̀fìn tí Tírè jìn sí?

33 Ọ̀fìn fífi ìlépa àwọn nǹkan ti ara ṣáájú ohunkóhun ni Tírè jìn sí. Ó rí towó ṣe, ó di agbéraga, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà fún ìgbéraga rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn orílẹ̀-èdè àti olúkúlùkù èèyàn lóde òní. Ó mà kúkú dára o, pé ká ṣe bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gbà wá nímọ̀ràn! Ó rọ àwọn Kristẹni “láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ibi tí Táṣíṣì wà ni wọ́n ń pè ní Sadíníà báyìí, tó jẹ́ erékùṣù kan níhà ìwọ̀ oòrùn Mẹditaréníà. Sadíníà pẹ̀lú jìnnà sí Tírè.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo Orí 15, lójú ewé 200 sí 207, nínú ìwé yìí.

^ ìpínrọ̀ 17 Lọ́nà mìíràn, ó lè jẹ́ àwọn ará Táṣíṣì ni “ọmọbìnrin Táṣíṣì” tọ́ka sí. Ìwé kan sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Odò Náílì ṣe lè ṣàn káàkiri fàlàlà làwọn ará Táṣíṣì ṣe lè rìnrìn àjò kiri, kí wọ́n sì ṣòwò fàlàlà wàyí.” Síbẹ̀ náà, ohun tó máa tẹ̀yìn ìṣubú Tírè yọ ló ń tẹnu mọ́.

^ ìpínrọ̀ 32 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími” ni a·la·zo·niʹa, tí wọ́n ṣàlàyé pé ó jẹ́ “ìṣefọ́nńté asán, aláìtọ́, tó máa ń jẹ́ kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé àwọn nǹkan ti ayé, bí ẹni pé ayé tọ́ lọ bí ọ̀pá ìbọn.”—The New Thayer’s Greek-English Lexicon.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 256]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

YÚRÓÒPÙ

SÍPÉÈNÌ (Ibi tó jọ pé TÁṢÍṢÌ wà)

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

SADÍNÍÀ

KÍPÍRỌ́SÌ

ÉṢÍÀ

SÍDÓNÌ

TÍRÈ

ÁFÍRÍKÀ

ÍJÍBÍTÌ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 250]

Bábílónì ni Tírè yóò túúbá fún, kì í ṣe Ásíríà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 256]

Owó ẹyọ tí wọ́n ya Melkart, olórí òrìṣà àwọn ará Tírè sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 256]

Àwòrán kékeré nípa bí ọkọ̀ òkun àwọn ará Foníṣíà ṣe rí