Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Kò Sí Olùgbé Kankan Tí Yóò Sọ Pé: “Àìsàn Ń Ṣe Mí”’

‘Kò Sí Olùgbé Kankan Tí Yóò Sọ Pé: “Àìsàn Ń Ṣe Mí”’

Orí Kẹrìndínlọ́gbọ̀n

‘Kò Sí Olùgbé Kankan Tí Yóò Sọ Pé: “Àìsàn Ń Ṣe Mí”’

Aísáyà 33:1-24

1. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ Aísáyà 33:24 fi tuni nínú?

“GBOGBO ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ bẹ́ẹ̀. (Róòmù 8:22) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa oògùn ìlera, síbẹ̀ àìsàn àti ikú kò tíì yéé han ìran ènìyàn léèmọ̀. Nígbà náà, ìlérí tó jẹ́ paríparì ẹ̀ka yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mà kúkú dára o! Ẹ fojú inú wo ìgbà tí “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ìgbà wo ni ìlérí yìí yóò ṣẹ, báwo ni yóò sì ṣe ṣẹ?

2, 3. (a) Ọ̀nà wo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbà ṣàìsàn? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo Ásíríà gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá” ìfìyàjẹni?

2 Ìgbà tí Aísáyà ń kọ ìwé yìí jẹ́ àsìkò tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. (Aísáyà 1:5, 6) Wọ́n ti wá rì wọnú irà ìpẹ̀yìndà àti ìṣekúṣe tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí dẹndẹ ìyà fi tọ́ sí wọn látọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ásíríà ni Jèhófà wá lò gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá” láti fi nà wọ́n. (Aísáyà 7:17; 10:5, 15) Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, níhà àríwá, ló kọ́kọ́ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà lọ́dún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa. (2 Àwọn Ọba 17:1-18; 18:9-11) Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Senakéríbù ọba Ásíríà dojú àgbáàràgbá ogun kọ ìjọba Júdà tó wà níhà gúúsù. (2 Àwọn Ọba 18:13; Aísáyà 36:1) Bí Ásíríà erinlákátabú sì ṣe wá ń run ilẹ̀ Júdà lọ ràì, ó dá bíi pé kò sí bí ilẹ̀ náà ò ṣe ní pa rẹ́ ráúráú.

3 Àmọ́, Ásíríà wá ki àṣejù bọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an pé kó bá òun fìyà jẹ àwọn èèyàn òun, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lépa ète oníwọra tirẹ̀ fúnra rẹ̀, ó fẹ́ ṣẹ́gun gbogbo ayé. (Aísáyà 10:7-11) Ṣé Jèhófà máa wá gbà pé kí Ásíríà lọ láìjìyà fún ìwà òǹrorò tó hù sí àwọn èèyàn òun? Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè yẹn yóò rí ìwòsàn nínú àìsàn tẹ̀mí tó ń ṣe é? A rí ohun tí Jèhófà fi dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí kà nínú Aísáyà orí kẹtàlélọ́gbọ̀n.

Fífi Afiniṣèjẹ Ṣe Ìjẹ

4, 5. (a) Báwo ni nǹkan ṣe máa yí padà mọ́ Ásíríà lọ́wọ́? (b) Àdúrà wo ni Aísáyà gbà nítorí àwọn èèyàn Jèhófà?

4 Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ báyìí pé: “Ègbé ni fún ìwọ tí ń fini ṣe ìjẹ, láìjẹ́ pé a fi ìwọ alára ṣe ìjẹ, àti fún ìwọ tí ń ṣe àdàkàdekè, láìjẹ́ pé àwọn mìíràn ṣe àdàkàdekè sí ọ! Gbàrà tí o bá ṣe tán gẹ́gẹ́ bí afiniṣèjẹ, a ó fi ọ́ ṣe ìjẹ. Gbàrà tí o bá parí ṣíṣe àdàkàdekè, wọn yóò ṣe àdàkàdekè sí ọ.” (Aísáyà 33:1) Ṣe ni Aísáyà kúkú dojú ọ̀rọ̀ kọ Ásíríà afiniṣẹ̀jẹ. Lásìkò tí agbára orílẹ̀-èdè abìjàwàrà yìí rinlẹ̀ jù lọ, ó dà bíi pé kò sẹ́ni tó lè rẹ̀yìn rẹ̀. ‘Ó fini ṣe ìjẹ láìjẹ́ pé wọ́n fi òun ṣe ìjẹ,’ ó gbọn àwọn ìlú Júdà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, ó tún kó dúkìá inú ilè Jèhófà, àní ńṣe ló tiẹ̀ kó o bí ẹni pé kò sẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò! (2 Àwọn Ọba 18:14-16; 2 Kíróníkà 28:21) Àmọ́ ní báyìí, nǹkan máa yí padà bírí mọ́ ọn lọ́wọ́. Aísáyà fìgboyà kéde pé: “A ó fi ọ́ ṣe ìjẹ.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí mà tu àwọn olóòótọ́ nínú o!

5 Ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn olóòótọ́ olùsin Jèhófà yóò ní láti yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́ lásìkò tó báni lẹ́rù yẹn. Ìyẹn ni Aísáyà fi gbàdúrà pé: “Jèhófà, fi ojú rere hàn sí wa. Ọ̀dọ̀ rẹ ni a fi ìrètí wa sí. Di apá [agbára àti àtìlẹyìn] wa ní òròòwúrọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, di ìgbàlà wa ní àkókò wàhálà. Ní gbígbọ́ ìró yánpọnyánrin, àwọn ènìyàn sá lọ. Ní dídìde tí ìwọ dìde, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́n ká.” (Aísáyà 33:2, 3) Gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ, Aísáyà gbàdúrà sí Jèhófà pé kó gba àwọn èèyàn Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe gbà wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀ rí. (Sáàmù 44:3; 68:1) Bí Aísáyà sì ṣe ń gbàdúrà yìí tán gẹ́lẹ́ ló sì tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Jèhófà fi dáhùn rẹ̀!

6. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Ásíríà, kí ló sì jẹ́ kí ó yẹ bẹ́ẹ̀?

6 Ó ní: “Ohun ìfiṣèjẹ yín [àwọn ará Ásíríà] ni a ó sì kó jọ ní tòótọ́ bí aáyán nígbà tí wọ́n bá ń kóra jọpọ̀, bí ìrọ́gìrọ́gìrọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eéṣú tí ń rọ́ luni.” (Aísáyà 33:4) Ọ̀ràn pé kí tata ya bo ibì kan láti jẹ ẹ́ run kò ṣàjèjì nílẹ̀ Júdà. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí o, àwọn ọ̀tá Júdà ni wọ́n yóò jẹ run. Ọ̀nà ẹ̀tẹ́ ni ìṣẹ́gun máa gbà bá Ásíríà, tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò fi ṣíyán láìdúró gbọbẹ̀, wọn yóò sá fi ìkogun ńláǹlà sílẹ̀, tí àwọn ará Júdà yóò wá fi ṣèjẹ! Bó ṣe yẹ kó rí fún Ásíríà, táwọn èèyàn mọ̀ mọ ìwà ìkà nìyẹn, ó yẹ kí wọ́n fi òun náà ṣèjẹ ni o.—Aísáyà 37:36.

Ásíríà Òde Òní

7. (a) Lóde òní, ta ló dà bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ṣàìsàn nípa tẹ̀mí? (b) Ta ni Jèhófà yóò lò gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá” láti fi pa Kirisẹ́ńdọ̀mù run?

7 Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe kàn wá lóde òní? Kirisẹ́ńdọ̀mù aláìṣòótọ́ dà bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ṣàìsàn nípa tẹ̀mí. Gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe lo Ásíríà gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá” láti fi na Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lo “ọ̀pá” láti fi na Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti ìyókù “Bábílónì Ńlá” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé pàápàá. (Aísáyà 10:5; Ìṣípayá 18:2-8) Àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ara Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn àjọ tí Ìṣípayá ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, ni yóò jẹ́ “ọ̀pá” yẹn.—Ìṣípayá 17:3, 15-17.

8. (a) Ta ni a lè fi wé Senakéríbù lóde òní? (b) Ta ni Senakéríbù òde òní yóò gbójúgbóyà lọ kọlù, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀?

8 Nígbà tí Ásíríà òde òní bá ń ṣọṣẹ́ kiri inú ẹ̀sìn èké, yóò dà bíi pé kò sẹ́ni lè ṣí i lọ́wọ́. Ni irú ẹ̀mí tó gun Senakéríbù yóò bá gun Sátánì Èṣù, débi pé kò ní fi ìkọlù rẹ̀ mọ sọ́dọ̀ àwọn àjọ tó jẹ́ apẹ̀yìndà, tí ìparun tọ́ sí, yóò gbójúgbóyà lọ kọlu àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú. Àmọ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tó ti jáde wá látinú ayé Sátánì, tí Bábílónì Ńlá wà lára rẹ̀, ni yóò dúró ti Ìjọba Jèhófà láìyẹhùn, ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, ọmọ Jèhófà nípa tẹ̀mí. Ìbínú pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kọ̀ láti júbà òun ni yóò wá jẹ́ kí Sátánì, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” fi tìpá-tìkúùkù kọlù wọ́n. (2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìsíkíẹ́lì 38:10-16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tó bani lẹ́rù ni yóò gbà kọlu àwọn èèyàn Jèhófà, kò ní sídìí fún wọn láti máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ kiri. (Aísáyà 10:24, 25) Ọlọ́run mú kó dá wọn lójú pé òun yóò ‘di ìgbàlà wọn ní àkókò wàhálà.’ Yóò dá sí ọ̀ràn wọn, yóò sì pa Sátánì àti agbo rẹ̀ run. (Ìsíkíẹ́lì 38:18-23) Gan-an bó ṣe rí láyé àtijọ́ mà ni yóò tún ṣe rí o, àwọn tó ń sapá láti fi àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣèjẹ ni yóò fúnra wọn di ẹni ìfiṣèjẹ! (Fi wé Òwe 13:22b.) Orúkọ Jèhófà yóò wá di yíyà sí mímọ́, àwọn tó là á já yóò sì wá gba èrè fún wíwá tí wọ́n wá “ọgbọ́n àti ìmọ̀ [àti ] ìbẹ̀rù Jèhófà.”—Ka Aísáyà 33:5, 6.

Ìkìlọ̀ Fáwọn Aláìnígbàgbọ́

9. (a) Kí ni “àwọn akọni” Júdà àti “àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà” yóò ṣe? (b) Ìhà wo ni ará Ásíríà yóò kọ sí wíwá tí Júdà ń wá àlàáfíà?

9 Ṣùgbọ́n, kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìnígbàgbọ́ tó wà ní Júdà? Aísáyà ṣe àpèjúwe tó bani lẹ́rù nípa bí wọn yóò ṣe kàgbákò lọ́wọ́ Ásíríà. (Ka Aísáyà 33:7.) Ogun tí Ásíríà ń gbé bọ̀ da ìbẹ̀rù bo “àwọn akọni” lára àwọn ọmọ ogun Júdà débi pé wọ́n ń ké. Ẹ̀sín àti ẹ̀tẹ́ ló bá “àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà,” ìyẹn àwọn ikọ̀ tí wọ́n rán lọ láti wá àlàáfíà lọ́dọ̀ àwọn ará Ásíríà arógunyọ̀. Wọn yóò sunkún kíkorò nítorí pé ìyẹn kò bọ́ sí i fún wọn. (Fi wé Jeremáyà 8:15.) Ará Ásíríà tó jẹ́ òkú òǹrorò kò ní ṣàánú wọn rárá ni. (Ka Aísáyà 33:8, 9.) Yóò fi àìláàánú pa àwọn májẹ̀mú tó bá àwọn ará Júdà dá tì. (2 Àwọn Ọba 18:14-16) Ará Ásíríà yóò wá ‘fojú pa àwọn ìlú ńlá Júdà rẹ́,’ yóò wò wọ́n tìkà tẹ̀gbin, láìka ẹ̀mí èèyàn sí rárá. Nǹkan yóò wá bàjẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé, ká kúkú sọ pé ilẹ̀ náà fúnra rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ ni. Lẹ́bánónì, Ṣárónì, Báṣánì, àti Kámẹ́lì pẹ̀lú yóò ṣọ̀fọ̀ nítorí ìdahoro yẹn.

10. (a) Báwo ni yóò ṣe jẹ́ pé “àwọn akọni” Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ní wúlò? (b) Ta ni yóò dáàbò bo àwọn ojúlówó Kristẹni ní ọjọ́ hílàhílo Kirisẹ́ńdọ̀mù?

10 Ó dájú pé irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ yóò ṣì wáyé láìpẹ́, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ẹ̀sìn. Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Hesekáyà, pàbó ni yóò já sí bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ gbógun dènà agbo ọmọ ogun aṣèparun yìí. “Àwọn akọni” inú Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìyẹn àwọn òṣèlú, olùdókòwò, àti àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn inú ibẹ̀, kò ní lè ṣèrànwọ́ kankan fún Kirisẹ́ńdọ̀mù. Wọn yóò da ‘àwọn májẹ̀mú’ tàbí àdéhùn òṣèlú àti ti okòwò táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn ohun tó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù. (Aísáyà 28:15-18) Gbogbo kìràkìtà láti fi ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ dènà ìparun yẹn yóò kùnà. Ìṣòwò yóò dáwọ́ dúró, nítorí, yálà kí wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn dúkìá àti ohun ìdókòwò Kirisẹ́ńdọ̀mù tàbí kí wọ́n ti pa wọ́n run. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣì fẹ́ràn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ní lè ṣe ju pé kó tàdí mẹ́yìn kó máa wá ṣọ̀fọ̀ ìparun rẹ̀. (Ìṣípayá 18:9-19) Ṣé Kristẹni tòótọ́ máa wá pa run pọ̀ mọ́ àwọn èké Kristẹni ni? Rárá o, nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ mú kó dani lójú pé: “‘Ṣe ni èmi yóò dìde wàyí,’ ni Jèhófà wí, ‘ṣe ni èmi yóò gbé ara mi ga wàyí; ṣe ni èmi yóò gbé ara mi sókè wàyí.’” (Aísáyà 33:10) Níkẹyìn, Jèhófà yóò dá sí ọ̀ràn yẹn nítorí àwọn olóòótọ́, bíi Hesekáyà, yóò sì dá ogun tí Ásíríà ń gbé bọ̀ dúró.—Sáàmù 12:5.

11, 12. (a) Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 33:11-14 ṣẹ, báwo ló sì ṣe ṣẹ? (b) Ìkìlọ̀ wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà fúnni lóde òní?

11 Àwọn aláìṣòótọ́ kò lè wá máa retí irú ààbò yẹn. Jèhófà sọ pé: “Ẹ lóyún koríko gbígbẹ; ẹ óò bí àgékù pòròpórò. Ẹ̀mí yín, gẹ́gẹ́ bí iná, yóò jẹ yín run. Àwọn ènìyàn yóò sì dà bí ìjóná ẹfun. Bí àwọn ẹ̀gún tí a gé kúrò, a ó ti iná bọ̀ wọ́n. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ wà ní ibi jíjìnnàréré, ohun tí èmi yóò ṣe! Kí ẹ sì mọ agbára ńlá mi, ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí. Ní Síónì, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ti wà nínú ìbẹ̀rùbojo; ìgbọ̀nrìrì ti gbá àwọn apẹ̀yìndà mú, pé: ‘Ta ni nínú wa tí ó lè bá iná tí ń jẹni run gbé fún ìgbà èyíkéyìí? Ta ni nínú wa tí ó lè bá àgbáàràgbá iná wíwà pẹ́ títí gbé fún ìgbà èyíkéyìí?’” (Aísáyà 33:11-14) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ìgbà tí Bábílónì, ọ̀tá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú, dojú ìjà kọ Júdà. Lẹ́yìn ikú Hesekáyà, Júdà tún padà sínú àwọn ìwà burúkú rẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nǹkan ti wá bàjẹ́ ní Júdà débi pé gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn pátá ló ní láti fara gba iná ìbínú Ọlọ́run.—Diutarónómì 32:22.

12 Àmọ́ gbogbo ètekéte àti ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí àwọn aláìgbọràn wá ń ta kí ìdájọ́ Ọlọ́run lè ré àwọn kọjá kò ní láárí ju àgékù pòròpórò lọ. Kódà, ẹ̀mí ìgbéraga àti ọlọ̀tẹ̀ tí orílẹ̀-èdè yìí ní yẹn gan-an ni yóò kúkú wá fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí ìparun rẹ̀. (Jeremáyà 52:3-11) Àwọn olubi yóò wá dà bí “ìjóná ẹfun,” àní sẹ́, ráúráú ni wọ́n máa pa run! Bí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ará Júdà ṣe ń ronú lórí àjálù tó ń bọ̀ yẹn, ìbẹ̀rùbojo ńlá bá wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Júdà aláìṣòótọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ ipò tí àwọn ọmọ ìjọ inú Kirisẹ́ńdọ̀mù wà lóde òní. Àgbákò ń bẹ níwájú fún wọn bí wọn ò bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run.

‘Rírìn Nínú Òdodo Tí Ń Bá A Lọ Títí’

13. Ìlérí wo ló wà fún ẹni tó bá “ń rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí,” báwo ló sì ṣe ṣẹ nípa ti Jeremáyà?

13 Láti jẹ́ kí òdì kejì èyí hàn, Jèhófà sọ̀rọ̀ síwájú sí i pé: “Ẹnì kan wà tí ń rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí, tí ó sì ń sọ ohun dídúróṣánṣán, tí ó ń kọ èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu, èyí tí ó wá láti inú jìbìtì, tí ó ń gbọn ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú dídi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ mú, tí ó ń di etí rẹ̀ sí fífetísí ìtàjẹ̀sílẹ̀, tí ó sì ń pa ojú rẹ̀ dé kí ó má bàa rí ohun tí ó burú. Òun ni ẹni tí yóò máa gbé àwọn ibi gíga pàápàá; ibi gíga ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ àwọn ibi àpáta gàǹgà tí ó ṣòro láti dé. A ó fi oúnjẹ rẹ̀ fún un; ìpèsè omi rẹ̀ yóò jẹ́ aláìkùnà.” (Aísáyà 33:15, 16) Ọ̀nà tí àpọ́sítélì Pétérù gbà sọ ọ́ lẹ́yìn náà ni pé, “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (2 Pétérù 2:9) Jeremáyà rí irú ìdáǹdè bẹ́ẹ̀ gbà. Lásìkò tí Bábílónì sàga tì wọ́n, ṣe làwọn aráàlú ní láti máa “jẹ oúnjẹ nípa ìwọ̀n àti nínú àníyàn ṣíṣe.” (Ìsíkíẹ́lì 4:16) Àní àwọn obìnrin kan tiẹ̀ jẹ ọmọ àwọn fúnra wọn. (Ìdárò 2:20) Síbẹ̀, Jèhófà rí sí i pé Jeremáyà wà láìséwu.

14. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè máa bá a lọ láti máa “rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí”?

14 Àwọn Kristẹni òde òní bákan náà ní láti máa “rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí,” kí wọ́n máa ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà Jèhófà ṣe wí lójoojúmọ́. (Sáàmù 15:1-5) Wọ́n ní láti máa “sọ ohun dídúróṣánṣán” kí wọ́n sì kọ irọ́ pípa àti àìṣòótọ́ sílẹ̀. (Òwe 3:32) Lóòótọ́, ìwà jìbìtì àti àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lè wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìríra gbáà ló jẹ́ lójú ẹni tí “ń rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí.” Dandan ni kí àwọn Kristẹni jẹ́ ẹni tó ní “ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí” nídìí òwò wọn, kí wọ́n máa sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn yàgò fún ìwà bìrìbìrì àti jìbìtì. (Hébérù 13:18; 1 Tímótì 6:9, 10) Ẹ̀wẹ̀, ẹni tó bá “ń di etí rẹ̀ sí fífetísí ìtàjẹ̀sílẹ̀, tí ó sì ń pa ojú rẹ̀ dé kí ó má bàa rí ohun tí ó burú” a máa ṣe àṣàyàn nínú irú orin tó máa ń gbọ́ àti eré ìnàjú tó máa ń ṣe. (Sáàmù 119:37) Nígbà ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà, yóò dáàbò bo àwọn olùjọsìn rẹ̀ tó bá ń tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀, yóò sì mẹ́sẹ̀ wọn dúró.—Sefanáyà 2:3.

Wọ́n Rí Ọba Wọn

15. Ìlérí wo ni yóò fún àwọn Júù olóòótọ́ tó wà ní ìgbèkùn lókun?

15 Aísáyà wá mẹ́nu ba ohun alárinrin yìí tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ó ní: “Ojú rẹ yóò rí ọba kan nínú ìrẹwà rẹ̀; wọn yóò rí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré. Ọkàn-àyà rẹ yóò sọ̀rọ̀ ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lórí ohun tí ń da jìnnìjìnnì boni pé: ‘Akọ̀wé dà? Ẹni tí ń san nǹkan fúnni dà? Ẹni tí ń ka àwọn ilé gogoro dà?’ Ìwọ kì yóò rí àwọn aláfojúdi ènìyàn kankan, àwọn ènìyàn tí èdè wọn jinlẹ̀ jù láti fetí sí, àwọn tí ahọ́n wọn ń kólòlò tí ìwọ kì yóò lóye wọn.” (Aísáyà 33:17-19) Ìlérí nípa Mèsáyà Ọba tí ń bọ̀ àti Ìjọba rẹ̀ yóò máa fún àwọn Júù olóòótọ́ lókun nígbà ọdún gbọọrọ tí wọ́n fi wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn lè máa wo Ìjọba yẹn lókèèrè réré. (Hébérù 11:13) Nígbà tí ìṣàkóso Mèsáyà yóò bá fi bẹ̀rẹ̀ ní ti gidi, gbogbo ìwà ìkà agbonimọ́lẹ̀ tí Bábílónì ń hù yóò ti di ohun àtijọ́. Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó bá la ogun tí Ásíríà gbé jà wọ́n já yóò fi béèrè pé: “Àwọn òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ọ̀gá, tó ń bu owó orí lé wa, tó sì ń gba owó òde lọ́wọ́ wa dà?”—Aísáyà 33:18, Moffatt.

16. Láti ìgbà wo ni o ti ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láti “rí” Mèsáyà Ọba, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀?

16 Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Aísáyà mú kó dájú pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn yóò padà bọ̀ wálé láti ìgbèkùn Bábílónì, ṣùgbọ́n, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò ní láti dúró dìgbà àjíǹde kí wọ́n tó lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmúṣẹ ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní wá ńkọ́? Láti ọdún 1914 ni ó ti ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn Jèhófà láti “rí,” tàbí láti fòye mọ Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba, tòun ti gbogbo ẹwà rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 45:2; 118:22-26) Nítorí náà, wọ́n rí ìdáǹdè gbà kúrò lábẹ́ ìtẹ̀lóríba àti ìdarí ètò àwọn nǹkan burúkú ti Sátánì yìí. Inú ààbò tòótọ́ nípa tẹ̀mí ni wọ́n wà lábẹ́ Síónì, ibùjókòó Ìjọba Ọlọ́run.

17. (a) Àwọn ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa Síónì? (b) Báwo ni àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa Síónì ṣe ṣẹ sórí Ìjọba Mèsáyà àti sórí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé?

17 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Wo Síónì, ìlú àwọn àkókò àjọyọ̀ wa! Ojú rẹ yóò rí Jerúsálẹ́mù tí í ṣe ibi gbígbé tí kò ní ìyọlẹ́nu, àgọ́ tí ẹnikẹ́ni kì yóò ká kúrò. A kì yóò fa àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀ tu láé, a kì yóò sì fa ìkankan lára àwọn ìjàrá rẹ̀ já sí méjì. Ṣùgbọ́n níbẹ̀, Jèhófà, Ọba Ọlọ́lá, yóò jẹ́ ibi àwọn odò fún wa, ibi àwọn ipa odò tí ó gbòòrò. Ọ̀wọ́ ọkọ̀ alájẹ̀ kankan kì yóò gba orí rẹ̀, ọkọ̀ òkun ọlọ́lá ńlá kankan kì yóò sì gba orí rẹ̀ kọjá.” (Aísáyà 33:20, 21) Aísáyà mú kó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè fa Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run tu tàbí tó lè pa á rẹ́. Ẹ̀wẹ̀, ó dájú pé irú ààbò bẹ́ẹ̀ nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn olóòótọ́ alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé lóde òní. Àní bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bá tiẹ̀ dojú kọ àdánwò tó le koko lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ìdánilójú wà fún wọn pé, gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìsapá yòówù kí ẹnikẹ́ni ṣe láti pa wọ́n rẹ́ kò lè láṣeyọrí. (Aísáyà 54:17) Gẹ́lẹ́ bí yàrà tàbí ipa odò ṣe máa ń dáàbò bo ìlú ni Jèhófà yóò ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Ọ̀tá kankan tó bá dìde sí wọn, kódà, kó lágbára bí “ọ̀wọ́ ọkọ̀ alájẹ̀” tàbí bí “ọkọ̀ òkun ọlọ́lá ńlá,” ráúráú ni yóò pa run!

18. Kí ni Jèhófà gbà gẹ́gẹ́ bí ojúṣe rẹ̀?

18 Àmọ́, kí ló mú kó dá àwọn olùfẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lójú hán-ún hán-ún tó bẹ́ẹ̀ pé ààbò Ọlọ́run ń bẹ fún àwọn? Aísáyà ṣàlàyé pé: “Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa; òun fúnra rẹ̀ yóò gbà wá là.” (Aísáyà 33:22) Jèhófà gbà pé ojúṣe òun ni láti dáàbò bo àwọn èèyàn òun tó mọyì ipò òun gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, àti láti darí wọn. Ńṣe ni àwọn wọ̀nyí sì fínnúfíndọ̀ fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ tó ń lo Mèsáyà Ọba láti ṣe, wọ́n gbà pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà láṣẹ láti ṣòfin, ó tún lè pàṣẹ fúnni láti tẹ̀ lé e. Àmọ́ ṣá, níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo, ìṣàkóso rẹ̀ tó ń lo Ọmọ rẹ̀ láti ṣe, kì í ṣe ẹrù ìnira fún àwọn olùjọsìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń ‘ṣe ara wọn láǹfààní’ látinú títẹríba tí wọ́n ń tẹrí ba fún àṣẹ rẹ̀. (Aísáyà 48:17) Kò ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀ láé.—Sáàmù 37:28.

19. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe bí ọ̀tá àwọn olóòótọ́ èèyàn Jèhófà yóò ṣe jẹ́ aláìlètapútú?

19 Aísáyà wá sọ fún ọ̀tá àwọn olóòótọ́ èèyàn Jèhófà pé: “Àwọn ìjàrá rẹ yóò rọ̀ dirodiro; wọn kì yóò di òpó ìgbòkun ọkọ̀ mú ní nínàró ṣánṣán; wọn kò ta ìgbòkun. Ní àkókò yẹn, àní ọ̀pọ̀ yanturu ohun ìfiṣèjẹ ni a óò pín; àwọn tí ó yarọ pàápàá yóò piyẹ́ ohun púpọ̀ ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 33:23) Ọ̀tá yòówù tó bá ń gbéjà bọ̀ wá bá Jèhófà kò ní lè ta pútú, ìsapá rẹ̀ yóò já sí asán, gẹ́lẹ́ bíi ọkọ̀ òkun ológun, tí okùn ìgbòkun rẹ̀ ti tú jọwọlọ, tí òpó ìgbòkun rẹ̀ sì ń gbò yèpéyèpé, tí kò sì ta ìgbòkun rárá. Ìparun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run yóò jẹ́ kí ohun ìfiṣèjẹ pọ̀ rẹpẹtẹ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé àní àwọn abirùn pàápàá yóò rí ohun piyẹ́. Nítorí náà, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò borí àwọn ọ̀tá rẹ̀ nínú “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ yìí, Jésù Kristi Ọba ni yóò sì lò.—Ìṣípayá 7:14.

Ìwòsàn

20. Irú ìwòsàn wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò rí gbà, nígbà wo sì ni?

20 Ìlérí amọ́kànyọ̀ kan ló parí ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí, ó ní: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” (Aísáyà 33:24) Ní ìpìlẹ̀, àìsàn tẹ̀mí ni Aísáyà ń sọ nípa rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ yẹn dá lórí ẹ̀ṣẹ̀, tàbí “ìṣìnà.” Ní ọ̀nà àkọ́kọ́ tí Jèhófà gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ṣe ló ṣèlérí pé lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè yẹn bá gba ìdáǹdè kúrò lóko ẹrú Bábílónì, òun yóò wò wọ́n sàn nípa tẹ̀mí. (Aísáyà 35:5, 6; Jeremáyà 33:6; fi wé Sáàmù 103:1-5.) Bó sì ṣe di pé àwọn Júù tó padà bọ̀ wálé rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá gbà, ohun tó kàn tí wọn yóò ṣe ni pé kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn mímọ́ gaara ní Jerúsálẹ́mù.

21. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn olùsin Jèhófà òde òní gbà ń rí ìwòsàn gbà nípa tẹ̀mí?

21 Àmọ́ ṣá o, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ tòde òní. Àwọn èèyàn Jèhófà lónìí pẹ̀lú rí ìwòsàn tẹ̀mí gbà bákan náà. Wọ́n ti rí ìdáǹdè gbà kúrò lábẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké bí àìleèkú ọkàn, Mẹ́talọ́kan, àti iná ọ̀run apáàdì. Wọ́n ń gba ìtọ́sọ́nà nípa ìwà ọmọlúwàbí, èyí tó ń mú kí wọ́n jìnnà sí ìwà ìṣekúṣe gbogbo, tó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára. Ẹ̀wẹ̀, ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló mú kí wọ́n lè wà ní ipò tó mọ́ lójú Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Kólósè 1:13, 14; 1 Pétérù 2:24; 1 Jòhánù 4:10) Ìwòsàn tẹ̀mí yìí ṣàǹfààní nípa ti ara. Bí àpẹẹrẹ, yíyàgò fún ìṣekúṣe àti yíyàgò fún àwọn ohun tí wọ́n bá fi tábà ṣe, kì í jẹ́ kí àwọn Kristẹni kó àwọn àrùn tó ń bá ìṣekúṣe rìn àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan.—1 Kọ́ríńtì 6:18; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

22, 23. (a) Ìmúṣẹ tó pẹtẹrí wo ni Aísáyà 33:24 yóò ní lọ́jọ́ iwájú? (b) Kí ló jẹ́ ìpinnu àwọn olùsìn tòótọ́ lóde òní?

22 Ní àfikún sí i, àwọn ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 33:24 yóò ṣẹ lọ́nà tó pẹtẹrí nínú ayé tuntun Ọlọ́run, lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. Nígbà tí Ìjọba Mèsáyà bá ń ṣàkóso, aráyé yóò gba ìwòsàn ńláǹlà nípa ti ara pa pọ̀ mọ́ ìwòsàn tẹ̀mí tí wọ́n ń gbà. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ó dájú pé, kété tí ètò àwọn nǹkan Sátánì bá ti pa run, irú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Afọ́jú yóò ríran, adití yóò gbọ́ràn, arọ yóò rìn! (Aísáyà 35:5, 6) Èyí ni yóò jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá já lè kópa nínú iṣẹ́ alárinrin ti sísọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.

23 Lẹ́yìn náà, bí àjíǹde bá ti bẹ̀rẹ̀, ó dájú pé ara dídá ṣáṣá làwọn tó bá jíǹde yóò bá jí. Àmọ́ o, bí àǹfààní ìtóye ẹbọ ìràpadà bá ṣe túbọ̀ ń wá sí i làwọn àǹfààní mìíràn nípa ti ara yóò ṣe máa yọjú, títí aráyé yóò fi dé ìjẹ́pípé. Ìgbà yẹn ni àwọn olódodo yóò “wá sí ìyè” ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ rẹ̀. (Ìṣípayá 20:5, 6) Ní ìgbà yẹn, “Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí,’” ì báà jẹ́ nípa tẹ̀mí tàbí nípa ti ara. Áà, ìlérí yìí mà wúni lórí o! Ǹjẹ́ kí gbogbo olùsìn tòótọ́ lónìí pinnu láti wà lára àwọn tí yóò rí ìmúṣẹ rẹ̀!

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 344]

Aísáyà fi ìdánilójú gbàdúrà sí Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 353]

Ẹbọ ìràpadà ló mú kí àwọn èèyàn Jèhófà wà ní ipò tó mọ́ lójú rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 354]

Nínú ayé tuntun, ìwòsàn ńláǹlà nípa ti ara yóò wáyé