Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún
Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1. Ìkéde ìdájọ́ wo ni Aísáyà kọ sílẹ̀ nípa Ásíríà?
JÈHÓFÀ lè lo àwọn orílẹ̀-èdè láti fi jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ níyà nítorí ìwà burúkú wọn. Síbẹ̀ náà, kò ní gbójú fo ìwà ìkà láìnídìí, ìgbéraga, àti ìwà kèéta táwọn orílẹ̀-èdè yẹn bá hù sí ìjọsìn tòótọ́. Ìyẹn ló fi mí sí Aísáyà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú pé kó kọ “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Bábílónì.” (Aísáyà 13:1) Àmọ́ o, ewu ọjọ́ iwájú ṣì ni Bábílónì jẹ́. Nígbà ayé Aísáyà, Ásíríà ló ń ni àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú lára. Ásíríà pa ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá run, ó sì sọ èyí tó pọ̀ jù nínú Júdà dahoro. Ṣùgbọ́n ayọ̀ ìṣẹ́gun Ásíríà kò tọ́jọ́ rárá. Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra, pé: ‘Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀ . . . kí n lè fọ́ ará Ásíríà náà ní ilẹ̀ mi àti pé kí n lè tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá mi; àti pé kí àjàgà rẹ̀ lè kúrò lọ́rùn wọn ní ti gidi àti pé kí ẹrù rẹ̀ gan-an lè kúrò ní èjìká wọn.’” (Aísáyà 14:24, 25) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Ásíríà kò jẹ́ ewu fún Júdà mọ́.
2, 3. (a) Ta ni Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí láyé àtijọ́? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà pé Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí “gbogbo orílẹ̀-èdè”?
2 Àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú wá ńkọ́? Dandan ni kí àwọn náà gba ìdájọ́ tiwọn. Aísáyà kéde pé: “Èyí ni ìpinnu tí a ṣe lòdì sí gbogbo ilẹ̀ ayé, èyí sì ni ọwọ́ tí a nà lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti pinnu, ta sì Aísáyà 14:26, 27) “Ìpinnu” Jèhófà ju ìmọ̀ràn lásán lọ. Ohun tó ti ṣe tán láti ṣe ní ti gidi ni, ìyẹn àṣẹ tó pa. (Jeremáyà 49:20, 30) Agbára tí Ọlọ́run lò ni “ọwọ́” rẹ̀. Nínú àwọn ẹsẹ tó gbẹ̀yìn Aísáyà orí kẹrìnlá ẹsẹ 29-32 àti ní orí kẹẹ̀ẹ́dógún sí ìkọkàndínlógún, Jèhófà pinnu láti dojú ìjà kọ Filísíà, Móábù, Damásíkù, Etiópíà àti Íjíbítì.
ni ó lè sọ ọ́ di asán? Ọwọ́ rẹ̀ sì ni èyí tí a nà, ta sì ni ó lè dá a padà?” (3 Àmọ́ ṣá, Aísáyà sọ pé “gbogbo orílẹ̀-èdè” ni Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wọ̀nyí kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ láyé àtijọ́, àwọn kókó inú rẹ̀ kan “àkókò òpin” yìí pẹ̀lú, nígbà tí Jèhófà na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí gbogbo àwọn ìjọba ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; 12:9; Róòmù 15:4; Ìṣípayá 19:11, 19-21) Tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè ti fi ìdánilójú sọ ìpinnu rẹ̀ jáde. Kò sẹ́ni tó lè dá ọwọ́ rẹ̀ tó nà jáde padà.—Sáàmù 33:11; Aísáyà 46:10.
“Ejò Oníná Tí Ń Fò” Kọlu Filísíà
4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú ìkéde Jèhófà lòdì sí Filísíà?
4 Àwọn Filísínì lọ̀rọ̀ kọ́kọ́ kàn. Ó ní: “Ní ọdún tí Áhásì Ọba kú, ọ̀rọ̀ ìkéde yìí wáyé: ‘Má ṣe yọ̀, ìwọ Filísíà, ẹnikẹ́ni nínú rẹ, kìkì nítorí pé ọ̀pá ẹni tí ń lù ọ́ ti ṣẹ́. Nítorí pé láti inú gbòǹgbò ejò ni ejò olóró yóò ti jáde wá, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ ejò oníná tí ń fò.’”—Aísáyà 14:28, 29.
5, 6. (a) Ọ̀nà wo ni Ùsáyà gbà dà bí ejò lójú àwọn Filísínì? (b) Kí ni Hesekáyà jẹ́ sí Filísíà?
5 Ùsáyà Ọba kápá ogun tí Filísíà ń gbé dìde. (2 Kíróníkà 26:6-8) Èèyàn bí ejò ló jẹ́ lójú wọn, ọ̀pá rẹ̀ sì ń lu àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá tó yí i ká. Lẹ́yìn ikú Ùsáyà, ìyẹn ìgbà tí ‘ọ̀pá rẹ̀ ṣẹ́,’ Jótámù olóòótọ́ ló jọba, ṣùgbọ́n “àwọn ènìyàn náà ṣì ń gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.” Lẹ́yìn náà, Áhásì jọba. Ni ipò nǹkan bá yí padà, àwọn Filísínì wá bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ja Júdà, wọ́n sì ń ṣẹ́gun. (2 Kíróníkà 27:2; 28:17, 18) Àmọ́, ní báyìí, nǹkan tún ti ń yí padà. Lọ́dún 746 ṣááju Sànmánì Tiwa, Áhásì Ọba kú, ọmọ rẹ̀ Hesekáyà wá gorí ìtẹ́. Bí àwọn Filísínì bá rò pé àwọn ó ṣì máa rọ́wọ́ mú, àṣìṣe gbáà ni wọ́n ṣe. Àgbákò ńlá ni Hesekáyà jẹ́ fún wọn. Àtọmọdọ́mọ Ùsáyà (“èso” látinú “gbòǹgbò” rẹ̀) ni Hesekáyà, ó sì dà bí “ejò oníná tí ń fò,” àní tó ń já ṣòòrò láti ṣánni ṣàràṣàrà, tó sì ń mú ọ̀tá rẹ̀ joró bíi pé ó ń pọ oró sí wọn lára.
6 Rẹ́gí làpèjúwe yìí bá ọba tuntun yìí mu. “[Hesekáyà] ni ó ṣá àwọn Filísínì balẹ̀ títí lọ dé Gásà àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.” (2 Àwọn Ọba 18:8) Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìtàn Senakéríbù ọba Ásíríà ṣe wí, àwọn Filísínì di ọmọ abẹ́ ìjọba Hesekáyà. “Àwọn òtòṣì,” ìyẹn ìjọba Júdà tó di aláìlágbára, wá di èyí tó wà láàbò tó sì láásìkí, ṣùgbọ́n ìyàn ń mú Filísíà.—Ka Aísáyà 14:30, 31.
7. Kí ni Hesekáyà ní láti sọ fún àwọn ikọ̀ tó wá sí Jerúsálẹ́mù láti lè fi ohun tó gbà gbọ́ hàn?
7 Ó jọ pé àwọn ikọ̀ kan wá sí Júdà—bóyá ṣe ni wọ́n ń wá àwọn tí wọn yóò bá lẹ̀dí àpò pọ̀ láti bá Ásíríà jagun. Èsì wo ló yẹ kí wọ́n gbà? “Kí . . . ni ẹnikẹ́ni yóò sọ láti fi dá àwọn ońṣẹ́ orílẹ̀-èdè lóhùn?” Ó ha yẹ kí Hesekáyà tìtorí ààbò lọ bá ilẹ̀ òkèèrè wọ àjọṣepọ̀ bí? Rárá o! Kí ó sọ fún àwọn ońṣẹ́ náà pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀, inú rẹ̀ sì ni àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lára àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ti rí ibi ìsádi.” (Aísáyà 14:32) Ọba yìí ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún. Gbọn-in gbọn-in ni ìpìlẹ̀ Síónì fìdí múlẹ̀. Ìlú yẹn yóò máa wà lọ ni gẹ́gẹ́ bí ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu àwọn ará Ásíríà.—Sáàmù 46:1-7.
8. (a) Báwo làwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí ṣe dà bí Filísíà? (b) Ìtìlẹyìn wo ni Jèhófà ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní gẹ́gẹ́ bó ti ṣe nígbà àtijọ́?
Sáàmù 94:21) Lóòótọ́, àwùjọ Kristẹni yìí lè dà bí “ẹni rírẹlẹ̀” àti “òtòṣì” lójú àwọn ọ̀tá wọn. Àmọ́, pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, ńṣe ni nǹkan ń rọ̀ ṣọ̀mù fún wọn nípa tẹ̀mí nígbà tí ìyàn ń mú àwọn ọ̀tá wọn. (Aísáyà 65:13, 14; Ámósì 8:11) Nígbà tí Jèhófà yóò bá gbọ́wọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn Filísínì òde òní, ibi ààbò làwọn “ẹni rírẹlẹ̀” wọ̀nyí yóò wà. Ibo ni ibi ààbò yẹn? Wọn yóò wà pẹ̀lú “agbo ilé Ọlọ́run,” èyí tí Jésù jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ igun rẹ̀. (Éfésù 2:19, 20) Wọn yóò sì wà lábẹ́ ààbò “Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run,” ìyẹn, Ìjọba Jèhófà ní ọ̀run, tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀.—Hébérù 12:22; Ìṣípayá 14:1.
8 Lóde òní pẹ̀lú, àwọn orílẹ̀-èdè kan ń ta ko àwọn olùjọsìn Ọlọ́run bí Filísíà ti ṣe. Wọ́n kó àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n àti sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n fòfin dè wọ́n. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni wọ́n pa. Àwọn alátakò ń bá a lọ láti “gbéjà ko ọkàn olódodo lọ́nà mímúná.” (Wọ́n Mú Kí Móábù Dákẹ́ Rọ́rọ́
9. Orí ta ni ìkéde tó tẹ̀ lé e dá lé, báwo sì ni àwọn èèyàn yẹn ṣe jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run?
9 Orílẹ̀-èdè mìíràn tó tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì ni Móábù, ó wà níhà ìlà oòrùn Òkun Òkú. Àwọn ọmọ Móábù tún yàtọ̀ sí àwọn Filísínì, wọ́n bá Ísírẹ́lì tan ní tiwọn, nítorí pé àtọmọdọ́mọ Jẹ́nẹ́sísì 19:37) Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe jẹ́ ìbátan yìí náà, ọ̀tá Ísírẹ́lì ni Móábù jẹ́ látọjọ́ pípẹ́ wá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Mósè lọ́hùn-ún, ńṣe ni ọba Móábù lọ bẹ Báláámù wòlíì lọ́wẹ̀, ó ń retí pé kó gbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣépè. Nígbà tí ìyẹn ò bọ́ sí i, Móábù lọ lo ìṣekúṣe àti ìjọsìn Báálì láti fi kẹ́dẹ mú Ísírẹ́lì. (Númérì 22:4-6; 25:1-5) Abájọ tí Jèhófà fi wá mí sí Aísáyà láti kọ“ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Móábù”!—Aísáyà 15:1a.
Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù ni wọ́n. (10, 11. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Móábù?
10 Onírúurú ìlú àti àgbègbè ní ilẹ̀ Móábù ni Aísáyà darí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sí, títí kan Árì, Kírì, (tàbí Kiri-hárésétì), àti Díbónì. (Aísáyà 15:1b, 2a) Àwọn ọmọ Móábù yóò ṣọ̀fọ̀ ìṣù èso àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì, bóyá ìyẹn ni pàtàkì ohun tó ń ti ìlú yẹn wá. (Aísáyà 16:6, 7) Síbúmà àti Jásérì, tó gbajúmọ̀ nítorí èso àjàrà tó ń tibẹ̀ wá, yóò rí ìyọnu. (Aísáyà 16:8-10) Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà, tó ṣeé ṣe kí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ọmọ Màlúù Ọlọ́dún Mẹ́ta,” yóò dà bí ẹgbọrọ màlúù alágbára tó ń kérora tàánútàánú. (Aísáyà 15:5) Koríko ilẹ̀ ibẹ̀ yóò gbẹ, ẹ̀jẹ̀ yóò sì kún inú “omi Dímónì” nítorí ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn ọmọ Móábù. “Omi Nímúrímù” yóò di “ahoro pátápátá,” ìbáà jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tàbí ní ti gidi—bóyá nítorí pé àwọn ọ̀tá lọ dí àwọn odò wọn.—Aísáyà 15:6-9.
11 Àwọn ọmọ Móábù yóò wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, ìyẹn aṣọ ọ̀fọ̀. Wọn yóò fárí kodoro gẹ́gẹ́ bí àmì ìtìjú àti ìdárò. Wọn yóò “gé” irùngbọ̀n “mọ́lẹ̀,” tó ń fi hàn pé ìbànújẹ́ àti ẹ̀tẹ́ bá wọn dé góńgó. (Aísáyà 15:2b-4) Inú Aísáyà alára bàjẹ́ nítorí ó dá a lójú pé ìdájọ́ wọ̀nyí kò ní ṣàìṣẹ. Àánú ṣe é débi tí inú rẹ̀ fi dà bí okùn háàpù tí ń gbọ̀n lele, nítorí ègbé tó kéde sórí Móábù.—Aísáyà 16:11, 12.
12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ nípa Móábù ṣe ṣẹ?
12 Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣẹ? Kò ní pẹ́. “Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Móábù tẹ́lẹ̀ rí. Wàyí o, Jèhófà ti sọ̀rọ̀, pé: Aísáyà 16:13, 14) Lóòótọ́, àwọn awalẹ̀pìtàn rí ẹ̀rí pé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, Móábù jìyà tó le koko, púpọ̀ nínú àwọn ìlú rẹ̀ sì tú. Tigilati-pílésà Kẹta sọ pé Salamánù ará Móábù wà lára àwọn alákòóso tó san owó òde fóun. Senakéríbù gba owó òde lọ́wọ́ Kamusunábì, ọba Móábù. Ọba Esari-hádónì àti Aṣọbánípà ti Ásíríà sọ pé Músúrì àti Kamaṣátù ọba Móábù jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba àwọn. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni àwọn ọmọ Móábù pa rẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ènìyàn kan. Wọ́n ti rí àlàpà àwọn ìlú ńlá kan tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ti Móábù, àmọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ ni ẹ̀rí gidi tí wọ́n tíì rí wà jáde nípa ọ̀tá alágbára yìí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nígbà kan rí.
‘Láàárín ọdún mẹ́ta, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọdún lébìrà tí a háyà, ògo Móábù ni a ó fi gbogbo onírúurú arukutu púpọ̀ dójú tì pẹ̀lú, àwọn tí yóò ṣẹ́ kù yóò sì jẹ́ díẹ̀ tí kò tó nǹkan, kì í ṣe alágbára ńlá.’” (“Móábù” Òde Òní Pa Run
13. Àjọ wo la lè fi wé Móábù lóde òní?
13 Lóde òní, àjọ àgbáyé kan wà tó dà bí Móábù àtijọ́. Kirisẹ́ńdọ̀mù ni, èyí tó jẹ́ apá pàtàkì nínú “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣípayá 17:5) Ọ̀dọ̀ Térà baba Ábúráhámù ni Ísírẹ́lì àti Móábù ti jọ ṣẹ̀ wá. Bákan náà, bí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní ṣe ń sọ náà ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ń sọ ọ́, pé ọ̀dọ̀ ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní lẹ̀sìn àwọn ti pilẹ̀ wá. (Gálátíà 6:16) Àmọ́ o, oníwà ìbàjẹ́ ni Kirisẹ́ńdọ̀mù—gẹ́gẹ́ bíi Móábù—ṣe ni wọ́n ń gbé ìwà ìbàjẹ́ nípa tẹ̀mí àti ìjọsìn àwọn ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, lárugẹ. (Jákọ́bù 4:4; 1 Jòhánù 5:21) Lápapọ̀, ńṣe làwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ń tako àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 24:9, 14.
14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pinnu láti kọjú ìjà sí “Móábù” òde òní, ìrètí wo lẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àjọ yẹn ní?
14 Ṣùgbọ́n, wọ́n mú kí Móábù dákẹ́ rọ́rọ́ níkẹyìn. Ohun Ìṣípayá 17:16, 17) Àmọ́ ṣá, ìrètí ń bẹ fún àwọn tó wà nínú “Móábù” tòde òní. Láàárín àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà ń sọ nípa Móábù ló ti sọ pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ni a ó fi fìdí ìtẹ́ kan múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in; ẹnì kan yóò sì jókòó sórí rẹ̀ nínú òótọ́ nínú àgọ́ Dáfídì, yóò máa ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́ òdodo, yóò sì máa ṣe kánmọ́kánmọ́ nínú òdodo.” (Aísáyà 16:5) Lọ́dún 1914, Jèhófà fìdí ìtẹ́ Jésù, tó jẹ́ Alákòóso láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba, múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Jèhófà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn nípa fífi Jésù jọba, ṣe ni yóò sì jọba títí láé ní ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì Ọba dá. (Sáàmù 72:2; 85:10, 11; 89:3, 4; Lúùkù 1:32) Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kàn tútù ló ti fi “Móábù” òde òní sílẹ̀, tí wọ́n sì ti jọ̀wọ́ ara wọn fún Jésù láti lè jèrè ìyè. (Ìṣípayá 18:4) Ìtùnú gbáà ló jẹ́ fáwọn wọ̀nyí láti mọ̀ pé Jésù ‘yóò mú ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè’!—Mátíù 12:18; Jeremáyà 33:15.
kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ṣe ni Jèhófà máa lo àwọn tó dà bí Ásíríà lóde òní láti fi sọ ọ́ dahoro. (Damásíkù Di Òkìtì Àlàpà Tí Ń Dómùkẹ̀
15, 16. (a) Ìgbésẹ̀ burúkú wo ni Damásíkù àti Ísírẹ́lì gbé sí Júdà, kí ló sì yọrí sí fún Damásíkù? (b) Ta ni ìkéde lórí Damásíkù tún kàn? (d) Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Kristẹni òde òní lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ ti Ísírẹ́lì?
15 Àkọsílẹ̀ tí Aísáyà kọ tẹ̀ lé e ni “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Damásíkù.” (Ka Aísáyà 17:1-6.) Damásíkù, tó wà níhà àríwá Ísírẹ́lì ni “orí Síríà.” (Aísáyà 7:8) Nígbà tí Áhásì Ọba ń ṣàkóso Júdà, Résínì ti Damásíkù lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Pékà ní Ísírẹ́lì, wọ́n sì ṣígun lọ bá Júdà. Àmọ́, Áhásì bẹ Tigilati-pílésà Kẹta lọ́wẹ̀, lòun náà bá ṣígun ti Damásíkù, ó ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì kó púpọ̀ lára àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn. Lẹ́yìn ìyẹn, Damásíkù kò tún jẹ́ ewu fún Júdà mọ́.—2 Àwọn Ọba 16:5-9; 2 Kíróníkà 28:5, 16.
16 Bóyá torí pé Ísírẹ́lì ní àjọṣe pẹ̀lú Damásíkù ni Aísáyà 17:3-6) Ísírẹ́lì yóò dà bí pápá tí kò ní ju hóró ọkà mélòó kan nígbà ìkórè, tàbí bí igi ólífì tí èso ólífì rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbọ̀n dànù tán lórí ẹ̀ka rẹ̀. (Aísáyà 17:4-6) Àríkọ́gbọ́n gidi mà lèyí jẹ́ o, fáwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà! Ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe ló ń fẹ́, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó bá ti ọkàn wá nìkan ló sì ń tẹ́wọ́ gbà. Ó sì kórìíra àwọn tó bá ń kọjú ìjà sí àwọn arákùnrin wọn.—Ẹ́kísódù 20:5; Aísáyà 17:10, 11; Mátíù 24:48-50.
Jèhófà ṣe kúkú fi ọ̀rọ̀ ìdájọ́ lórí ìjọba àríwá aláìṣòótọ́ kún ìkéde rẹ̀ sórí Damásíkù. (Wọ́n Gbọ́kàn Lé Jèhófà Pátápátá
17, 18. (a) Kí làwọn kan ní Ísírẹ́lì ṣe nípa àwọn ìkéde Jèhófà, ṣùgbọ́n ìhà wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ kọ sí i? (b) Báwo ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ṣe dà bí ti ìgbà Hesekáyà?
17 Aísáyà wá sọ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ará ayé yóò gbé ojú sókè sí Olùṣẹ̀dá rẹ̀, ojú rẹ̀ yóò sì tẹ̀ mọ́ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì pàápàá. Kì yóò sì wo àwọn pẹpẹ, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀; kì yóò sì tẹjú mọ́ ohun tí ìka rẹ̀ ṣe, yálà àwọn òpó ọlọ́wọ̀ tàbí àwọn pẹpẹ tùràrí.” (Aísáyà 17:7, 8) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn kan ní Ísírẹ́lì kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Hesekáyà ránṣẹ́ lọ pe àwọn ará Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wá bá Júdà ṣe Ìrékọjá pọ̀, àwọn kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bó ti wí, wọ́n gbéra lọ síhà gúúsù láti dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. (2 Kíróníkà 30:1-12) Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ló ń fàwọn òjíṣẹ́ tó rán sí wọn ṣẹlẹ́yà. Ìpẹ̀yìndà ti di bárakú fún orílẹ̀-èdè yẹn. Nítorí náà, Jèhófà mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ lé e lórí. Ásíríà pa àwọn ìlú Ísírẹ́lì run, ilẹ̀ náà di aṣálẹ̀, pápá wọn kò sì méso jáde.—Ka Aísáyà 17:9-11.
18 Òde òní ńkọ́? Ísírẹ́lì jẹ́ orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà. Nípa bẹ́ẹ̀, bí Hesekáyà ṣe gbìyànjú láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú orílẹ̀-èdè yẹn lọ́wọ́ láti padà sínú ìjọsìn tòótọ́ mú wa rántí bí àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ṣe ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà. Láti 1919 ni àwọn ońṣẹ́ látọ̀dọ̀ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ń la inú Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ, wọ́n ń ké sí àwọn èèyàn láti wá nípìn-ín nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. (Gálátíà 6:16) Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló kọ̀. Ọ̀pọ̀ ń fi àwọn ońṣẹ́ wọ̀nyẹn ṣẹlẹ́yà. Àmọ́, àwọn kan jẹ́ ìpè wọn. Wọ́n ti wá di àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, ó sì wù wọ́n láti ‘tẹjú mọ́ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,’ bó ṣe ń kọ́ wọn. (Aísáyà 54:13) Wọ́n kọ ìjọsìn ṣíṣe nídìí àwọn pẹpẹ àìmọ́ sílẹ̀, ìyẹn ni, fífún àwọn ọlọ́run àtọwọ́dá ní ìfọkànsìn àti gbígbẹ́kẹ̀ lé wọn, wọ́n sì fìháragàgà yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà. (Sáàmù 146:3, 4) Olúkúlùkù wọ́n ń sọ bí Míkà, tó gbé ayé nígbà Aísáyà ṣe sọ, pé: “Ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.”—Míkà 7:7.
19. Ta ni Jèhófà yóò bá wí lọ́nà mímúná, kí ni èyí yóò sì túmọ̀ sí fún wọn?
19 Wọ́n mà kúkú yàtọ̀ sí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ wọn lé ènìyàn, ẹni kíkú o! Ìjì ìwà ipá àti rúkèrúdò ń han aráyé léèmọ̀ lemọ́lemọ́ lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí. Igbe ẹ̀hónú àti rògbòdìyàn ni “òkun” aráyé ọlọ̀tẹ̀ tó ń ru gùdù ń sọ sókè ṣáá. (Aísáyà 57:20; Ìṣípayá 8:8, 9; 13:1) Jèhófà yóò “bá” àwùjọ aláriwo yìí “wí lọ́nà mímúná.” Ìjọba rẹ̀ ọ̀run yóò pa gbogbo àjọ àti ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ oníjàngbọ̀n run, tí wọn yóò fi “sá lọ . . . gẹ́gẹ́ bí òṣùṣú tí ààjà ń gbé kiri níwájú ẹ̀fúùfù oníjì.”—Aísáyà 17:12, 13; Ìṣípayá 16:14, 16.
20. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè “ń piyẹ́” àwọn Kristẹni tòótọ́, kí lohun tó dá wọn lójú?
20 Kí ni àbájáde rẹ̀? Aísáyà sọ pé: “Ní àkókò ìrọ̀lẹ́, họ́wù, wò ó! ìpayà òjijì ń bẹ. Kí ó tó di òwúrọ̀—kò sí mọ́. Èyí ni ìpín àwọn tí ń kó wa ní ìkógun, àti ipa tí ó jẹ́ ti àwọn tí ń piyẹ́ wa.” (Aísáyà 17:14) Ọ̀pọ̀ ló ń piyẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n ń kanra mọ́ wọn tí wọ́n sì ń kàn wọ́n lábùkù. Nítorí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe apá kan àwọn ẹ̀sìn jàǹkàn jàǹkàn ayé yìí, ńṣe làwọn ẹlẹ́tanú tí ń ṣe lámèyítọ́ àtàwọn alátakò tí ara ń ta kà wọ́n sí ẹni táwọn kàn lè nawọ́ gán nígbàkigbà. Àmọ́, ó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú pé “òwúrọ̀,” nígbà tí ìpọ́njú wọn yóò dópin kù sí dẹ̀dẹ̀.—2 Tẹsalóníkà 1:6-9; 1 Pétérù 5:6-11.
Etiópíà Mú Ẹ̀bùn Wá fún Jèhófà
21, 22. Orílẹ̀-èdè wo ni Aísáyà tún kéde ìdájọ́ lé lórí, báwo sì ni ọ̀rọ̀ onímìísí tó sọ ṣe ṣẹ?
21 Ó kéré tán, ó tó ẹ̀ẹ̀mejì tí Etiópíà, tó wà níhà gúúsù ilẹ̀ Íjíbítì, dara pọ̀ mọ́ àwọn tó dìde ogun sí Júdà. (2 Kíróníkà 12:2, 3; 14:1, 9-15; 16:8) Aísáyà wá sọ tẹ́lẹ̀ pé ìdájọ́ ń bọ̀ wá sórí orílẹ̀-èdè yẹn, ó ní: “Háà, nítorí ilẹ̀ àwọn kòkòrò akùnrànyìn tí ó ní ìyẹ́ apá, èyí tí ń bẹ ní ẹkùn ilẹ̀ àwọn odò Etiópíà!” (Ka Aísáyà 18:1-6.) * Jèhófà pàṣẹ pé ńṣe ni wọ́n máa ‘ké Etiópíà kúrò, wọn yóò mú un kúrò, wọn yóò sì ké e dànù.’
22 Àwọn òpìtàn sọ fún wa pé Etiópíà ṣẹ́gun Íjíbítì, ó sì ṣàkóso rẹ̀ fún ọgọ́ta ọdún ní apá ìgbẹ̀yìn ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Olú Ọba Esari-hádónì àti Aṣọbánípà láti Ásíríà pẹ̀lú gbógun jà á. Pípa tí Aṣọbánípà pa ìlú Tíbésì run ni Ásíríà fi wá jẹ gàba lé Íjíbítì lórí, bó sì ṣe mú àkóso Etiópíà lórí Àfonífojì Náílì wá sópin nìyẹn. (Wo Aísáyà 20:3-6 pẹ̀lú.) Òde òní wá ńkọ́?
23. Kí ni ipa tí “Etiópíà” òde òní kó, èé sì ti ṣe tó fi pa run?
23 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì sọ nípa “àkókò òpin,” ó sọ pé àwọn ará Líbíà àti àwọn ará Etiópíà yóò “wà ní ìṣísẹ̀ [ọba àríwá]” oníjàgídíjàgan, ìyẹn ni pé, wọ́n ń gbọ́ tirẹ̀. (Dáníẹ́lì 11:40-43) Wọ́n sì tún dárúkọ Etiópíà mọ́ ara agbo ọmọ ogun “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” (Ìsíkíẹ́lì 38:2-5, 8) Agbo ọmọ ogun Gọ́ọ̀gù, títí kan ọba àríwá, pa run nígbà tí wọ́n gbógun ti orílẹ̀-èdè mímọ́ Jèhófà. Nípa báyìí, Jèhófà yóò nawọ́ rẹ̀ sára “Etiópíà” òde òní pẹ̀lú nítorí pé ó tako ipò ọba aláṣẹ Jèhófà.—Ìsíkíẹ́lì 38:21-23; Dáníẹ́lì 11:45.
24. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà gba “àwọn ẹ̀bùn” látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè?
24 Síbẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún sọ pé: “Ní àkókò yẹn, a óò mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga àti alára dídán, àní láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù níbi gbogbo . . . [a óò mú un wá] sí ibi orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Òkè Ńlá Síónì.” (Aísáyà 18:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè kò ka ipò ọba aláṣẹ Jèhófà sí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọn a ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn Jèhófà. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn aláṣẹ kan gbé àwọn òfin kan kalẹ̀, wọ́n sì dá àwọn ẹjọ́ kan nílé ẹjọ́, tó fún àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin. (Ìṣe 5:29; Ìṣípayá 12:15, 16) Àwọn ẹ̀bùn mìíràn sì tún wà pẹ̀lú. “Àwọn ọba yóò mú àwọn ẹ̀bùn wá fún ìwọ alára. . . . Àwọn ohun tí a fi àdàlù bàbà àti tánganran ṣe yóò wá láti Íjíbítì; Kúṣì [Etiópíà] alára yóò tètè nawọ́ àwọn ẹ̀bùn sí Ọlọ́run.” (Sáàmù 68:29-31) Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn ará Etiópíà” òde òní tó bẹ̀rù Jèhófà ló ń mú “ẹ̀bùn” wá, nípa ṣíṣe ìjọsìn. (Málákì 1:11) Wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ takuntakun ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà káàkiri ayé. (Mátíù 24:14; Ìṣípayá 14:6, 7) Ẹ̀bùn yẹn mà dára láti fún Jèhófà o!—Hébérù 13:15.
Ọkàn-Àyà Íjíbítì Domi
25. Ní ìmúṣẹ Aísáyà 19:1-11, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì àtijọ́?
25 Íjíbítì, tó ti fìgbà pípẹ́ jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Júdà níhà gúúsù. Aísáyà orí kọkàndínlógún mẹ́nu kan bí nǹkan ṣe dà rú ní Íjíbítì nígbà ayé Aísáyà. Ogun abẹ́lé wà ní Íjíbítì, tó fi jẹ́ pé “ìlú ńlá lòdì sí ìlú ńlá, ìjọba lòdì sí ìjọba.” (Aísáyà 19:2, 13, 14) Àwọn òpìtàn fi ẹ̀rí hàn pé onírúurú ìlà ìdílé ọba tó ń figẹ̀ wọngẹ̀ ń ṣàkóso ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú orílẹ̀-èdè yẹn lẹ́ẹ̀kan náà. Ọgbọ́n tí Íjíbítì fi ń yangàn, àti ‘àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí àti àwọn atujú rẹ̀,’ kò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ “ọ̀gá líle.” (Aísáyà 19:3, 4) Ásíríà, Bábílónì, Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù ṣẹ́gun Íjíbítì tẹ̀léra tẹ̀léra. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 19:1-11 ṣẹ.
26. Kí ni àwọn olùgbé inú “Íjíbítì” òde òní yóò ṣe nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá ní ìmúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò?
26 Àmọ́ o, nínú Bíbélì, Íjíbítì sábà máa ń dúró fún ayé Sátánì. (Ìsíkíẹ́lì 29:3; Jóẹ́lì 3:19; Ìṣípayá 11:8) Nítorí náà, ṣé “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Íjíbítì” tí Aísáyà sọ wá ní ìmúṣẹ tó túbọ̀ gbòòrò sí i ni? Bẹ́ẹ̀ ni o! Àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yẹ kó mú kí olúkúlùkù kíyè sára, ó sọ pé: “Wò ó! Jèhófà gun àwọsánmà yíyára, ó sì ń bọ̀ wá sí Íjíbítì. Ó dájú pé àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí ti Íjíbítì yóò gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí rẹ̀, ọkàn-àyà Íjíbítì gan-an yóò sì domi ní àárín rẹ̀.” (Aísáyà 19:1) Láìpẹ́, Jèhófà yóò dìde sí ètò àjọ Sátánì. Nígbà yẹn, yóò wá hàn pé ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí kò ní láárí. (Sáàmù 96:5; 97:7) “Ọkàn-àyà Íjíbítì gan-an yóò domi” nítorí ìbẹ̀rù. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè [yóò wà], láìmọ ọ̀nà àbájáde nítorí ìpariwo omi òkun àti ìrugùdù rẹ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Lúùkù 21:25, 26.
27. Ìyapa wo ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò wà láàárín “Íjíbítì,” báwo ni èyí sì ṣe ń ṣẹ lóde òní?
27 Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àkókò tí yóò wà ṣáájú ìdájọ́ yẹn ṣe máa rí, ó ní: “Ṣe ni èmi yóò gún àwọn ọmọ Íjíbítì ní kẹ́sẹ́ lòdì sí àwọn ọmọ Íjíbítì, olúkúlùkù wọn yóò sì bá arákùnrin rẹ̀ jagun dájúdájú, olúkúlùkù yóò sì bá alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jagun, ìlú ńlá lòdì sí ìlú ńlá, ìjọba lòdì sí ìjọba.” Aísáyà 19:2) Láti ìgbà ìgbékalẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, ńṣe ni orílẹ̀-èdè ń dìde sí orílẹ̀-èdè tí ìjọba sì ń dìde sí ìjọba, ìyẹn sì “jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín” Jésù. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀mí ló ti ṣòfò ní àkókò òpin yìí nítorí tí ẹ̀yà kan ń pa ìkejì nípakúpa, tí ẹ̀yà kan ń dìde láti run ẹ̀yà kejì, tí àwọn ìran kan sì ń gbógun láti run ìran mìíràn tí wọ́n kà sí ìrankíran láàárín wọn. Ńṣe ni irú “ìroragógó wàhálà” wọ̀nyẹn yóò sì máa pọ̀ sí i bí òpin ṣe ń sún mọ́lé.—Mátíù 24:3, 7, 8.
(28. Kí ni ìsìn èké yóò lè ṣe láti fi gba ètò àwọn nǹkan yìí lọ́jọ́ ìdájọ́?
28 “Ìdàrúdàpọ̀ yóò sì dé bá ẹ̀mí Íjíbítì ní àárín rẹ̀, èmi yóò sì da ìmọ̀ràn rẹ̀ rú. Ó sì dájú pé wọn yóò yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí àti sí àwọn atujú àti sí àwọn abẹ́mìílò àti sí àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀.” (Aísáyà 19:3) Nígbà tí Mósè tọ Fáráò lọ, ojú ti àwọn àlùfáà Íjíbítì, nítorí pé agbára wọn kò gbé ohun àrà tí Jèhófà ń ṣe. (Ẹ́kísódù 8:18, 19; Ìṣe 13:8; 2 Tímótì 3:8) Bẹ́ẹ̀ náà ni ìsìn èké kò ṣe ní gba ètò àwọn nǹkan tó díbàjẹ́ yìí lọ́jọ́ ìdájọ́. (Fi wé Aísáyà 47:1, 11-13.) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Íjíbítì bọ́ sọ́wọ́ “ọ̀gá líle,” ìyẹn Ásíríà. (Aísáyà 19:4) Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ àgbákò tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yóò kò lọ́jọ́ iwájú.
29. Kí làwọn òṣèlú máa rí ṣe bó bá di ọjọ́ Jèhófà?
29 Àwọn aṣáájú ìṣèlú ńkọ́? Ṣé wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ ṣe? “Àwọn ọmọ aládé Sóánì ya òmùgọ̀ ní tòótọ́. Ní ti àwọn ọlọ́gbọ́n lára àwọn agbani-nímọ̀ràn Fáráò, ìmọ̀ràn wọn jẹ́ ohun tí kò lọ́gbọ́n nínú.” (Ka Aísáyà 19:5-11.) Ó mà kúkú ṣàìbọ́gbọ́nmu o, pé kẹ́nì kan máa retí pé kí àwọn agbani-nímọ̀ràn rí ọgbọ́n ta lọ́jọ́ ìdájọ́! Àní bí wọ́n tilẹ̀ kó gbogbo ọgbọ́n ayé jọ, wọn kò ní ọgbọ́n Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 3:19) Wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì yíjú sí ohun tí wọ́n pè ní sáyẹ́ǹsì, ọgbọ́n èrò orí, owó, fàájì, àtàwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n sọ di ọlọ́run wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò mọ̀ nípa àwọn ète Ọlọ́run. Wọ́n dẹni ìtànjẹ, àìbalẹ̀ ara sì bá wọ́n. Asán ni àwọn iṣẹ́ wọ́n já sí. (Ka Aísáyà 19:12-15.) “Ojú ti àwọn ọlọ́gbọ́n. Àyà wọn já, a ó sì mú wọn. Wò ó! Àní wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?”—Jeremáyà 8:9.
Àmì àti Ẹ̀rí fún Jèhófà
30. Ọ̀nà wo ni ‘ilẹ̀ Júdà yóò fi di okùnfà fún títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ fún Íjíbítì’?
30 Àmọ́ o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú “Íjíbítì” jẹ́ aláìlágbára “bí obìnrin,” àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣì wà tó ń wá ọgbọ́n Ọlọ́run. Àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” Ọlọ́run. (Aísáyà 19:16; 1 Pétérù 2:9) Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ètò Sátánì. Ipò yìí ni Aísáyà ń wò lọ́jọ́ iwájú tó fi sọ pé: “Ilẹ̀ Júdà yóò sì di okùnfà fún títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ fún Íjíbítì. Gbogbo ẹni tí ènìyàn bá mẹ́nu kàn án fún ni ìbẹ̀rùbojo yóò mú nítorí ìpinnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, èyí tí ó ti pinnu lòdì sí i.” (Aísáyà 19:17) Àwọn tó jẹ́ ońṣẹ́ olóòótọ́ fún Jèhófà ń bá a lọ láti sọ òtítọ́ fáwọn èèyàn—títí kan ìkéde àwọn ìyọnu tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣípayá 8:7-12; 16:2-12) Èyí ń kó ìdààmú bá àwọn aṣáájú ìsìn ayé.
31. Báwo ló ṣe wá ṣẹ pé wọ́n ń sọ “èdè Kénáánì” ní àwọn ìlú ńlá Íjíbítì (a) nígbà àtijọ́? (b) lóde òní?
31 Àbáyọrí ìyanu wo ni iṣẹ́ ìkéde yìí wá ní? “Ní ọjọ́ yẹn, ìlú ńlá márùn-ún ni yóò wà ní ilẹ̀ Íjíbítì tí ń sọ èdè Kénáánì, tí ó sì ń búra fún Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ìlú Ńlá Ìyalulẹ̀ ni a óò máa pe ìlú ńlá kan.” (Aísáyà 19:18) Nígbà àtijọ́, ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí àwọn Júù tó sá lọ sí Íjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí sọ èdè Hébérù wọn nínú àwọn ìlú ńlá Íjíbítì. (Jeremáyà 24:1, 8-10; 41:1-3; 42:9–43:7; 44:1) Lónìí, àwọn èèyàn wà ní ilẹ̀ “Íjíbítì” òde òní tí wọ́n mọ bí a ti ń sọ “èdè mímọ́ gaara” ti òtítọ́ Bíbélì. (Sefanáyà 3:9) Orúkọ ọ̀kan nínú ìlú ìṣàpẹẹrẹ márùn-ún yẹn ni “Ìlú Ńlá Ìyalulẹ̀,” tó ń fi hàn pé apá kan lára èdè “mímọ́ gaara” jẹ mọ́ títú àṣírí ètò Sátánì àti ‘yíya á lulẹ̀.’
32. (a) Kí ni “pẹpẹ” tó wà láàárín ilẹ̀ Íjíbítì? (b) Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe dà bí “ọwọ̀n kan” lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Íjíbítì?
32 Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìkéde tí àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe, orúkọ ńlá Jèhófà yóò di mímọ̀ dájúdájú nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. “Ní ọjọ́ yẹn, pẹpẹ kan yóò wà fún Jèhófà ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì, àti ọwọ̀n kan fún Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà rẹ̀.” (Aísáyà 19:19) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń tọ́ka sí ipò tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, wà. (Sáàmù 50:5) Bí wọ́n ṣe jẹ́ “pẹpẹ,” wọn a máa rúbọ; bí wọ́n ṣe jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́,” wọ́n ń jẹ́rìí nípa Jèhófà. (1 Tímótì 3:15; Róòmù 12:1; Hébérù 13:15, 16) Wọ́n wà “ní àárín ilẹ̀ náà” ní ti pé àwọn—àti “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn—wà ní àwọn orílẹ̀-èdè àti erékùṣù òkun tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ. Síbẹ̀ wọn “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 10:16; 17:15, 16) Bí ẹni pé wọ́n dúró sáàárín ààlà ayé yìí àti Ìjọba Ọlọ́run ni, tí wọ́n ń múra láti sọdá ààlà yẹn kí wọ́n sì gba èrè wọn lọ́run.
33. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ẹni àmì òróró gbà jẹ́ “àmì” àti “ẹ̀rí” ní “Íjíbítì”?
33 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní ilẹ̀ Íjíbítì; nítorí pé wọn yóò ké jáde sí Jèhófà nítorí àwọn aninilára, òun yóò sì rán olùgbàlà kan sí wọn, àní ẹni títóbilọ́lá, ẹni tí yóò dá wọn nídè ní tòótọ́.” (Aísáyà 19:20) Gẹ́gẹ́ bí “àmì” àti “ẹ̀rí,” ńṣe làwọn ẹni àmì òróró mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti gbígbé orúkọ Jèhófà ga nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Aísáyà 8:18; Hébérù 2:13) Jákèjádò ayé la ti ń gbọ́ igbe àwọn ẹni tí wọ́n ń tẹ̀ lórí ba, àmọ́, ìjọba èèyàn kì í sábà lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Ṣùgbọ́n, Jèhófà yóò rán Jésù Kristi Ọba, Olùgbàlà Ńlá, láti wá dá gbogbo àwọn ọlọ́kàn tútù nídè. Tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bá wá dé ògógóró rẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, òun yóò mú ìtura àti àwọn ìbùkún ayérayé wá fún àwọn èèyàn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run.—Sáàmù 72:2, 4, 7, 12-14.
34. (a) Báwo ni “àwọn ará Íjíbítì” yóò ṣe di ẹni tó mọ Jèhófà, ẹbọ àti ẹ̀bùn wo sì ni wọn yóò mú wá fún un? (b) Ìgbà wo ni Jèhófà yóò fi ìyọnu àgbálù kọlu “Íjíbítì,” ìwòsàn wo ni yóò sì tẹ̀ lé e?
34 Ní báyìí ná, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí onírúurú èèyàn jèrè ìmọ̀ pípéye kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (1 Tímótì 2:4) Nítorí náà, Aísáyà kọ̀wé pé: “Dájúdájú, Jèhófà yóò sì di mímọ̀ fún àwọn ọmọ Íjíbítì; àwọn ọmọ Íjíbítì yóò sì mọ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò sì rú ẹbọ, wọn yóò sì mú ẹ̀bùn wá, wọn yóò sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà, wọn yóò sì san án. Ṣe ni Jèhófà yóò sì fi ìyọnu àgbálù kọlu Íjíbítì. Fífi ìyọnu àgbálù kọlù àti ìmúniláradá yóò sì ṣẹlẹ̀; wọn yóò sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, òun yóò sì jẹ́ kí wọ́n pàrọwà sí òun, yóò sì mú wọn lára dá.” (Aísáyà 19:21, 22) Àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé Sátánì, ìyẹn ẹnì kọ̀ọ̀kan lára “àwọn ọmọ Íjíbítì,” di ẹni tó wá mọ Jèhófà, wọ́n sì ń rúbọ sí i, ìyẹn ẹbọ “èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Wọ́n ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà nípa yíya ara wọn sí mímọ́ fún un, wọ́n sì ń san ẹ̀jẹ́ wọn nípa fífi ẹ̀mí ìdúróṣinṣin ṣe iṣẹ́ ìsìn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti “fi ìyọnu àgbálù” kọlu ètò àwọn nǹkan yìí ní Amágẹ́dọ́nì, yóò lo Ìjọba rẹ̀ láti fi wo aráyé sàn. Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Jésù, aráyé yóò dé ìjẹ́pípé nípa tẹ̀mí, èrò orí, ìwà híhù, àti ní ara ìyára—ìwòsàn dé lóòótọ́!—Ìṣípayá 22:1, 2.
“Ìbùkún Ni fún Àwọn Ènìyàn Mi”
35, 36. Ní ìmúṣẹ Aísáyà 19:23-25, kí ló pa Íjíbítì, Ásíríà, àti Ísírẹ́lì pọ̀ láyé àtijọ́?
35 Wòlíì náà wá rí ohun pàtàkì kan tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Ní ọjọ́ yẹn, òpópó kan yóò wá wà láti inú Íjíbítì sí Ásíríà, Ásíríà yóò sì wá sí Íjíbítì ní tòótọ́, àti Íjíbítì sí Ásíríà; dájúdájú, wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, Íjíbítì pẹ̀lú Ásíríà. Ní ọjọ́ yẹn, Ísírẹ́lì yóò wá jẹ́ ìkẹta pẹ̀lú Íjíbítì àti Ásíríà, èyíinì ni, ìbùkún ní àárín ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ti súre fún un, pé: ‘Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn mi, Íjíbítì, àti iṣẹ́ ọwọ́ mi, Ásíríà, àti ogún mi, Ísírẹ́lì.’” (Aísáyà 19:23-25) Bẹ́ẹ̀ ni o, lọ́jọ́ kan ṣáá, Íjíbítì àti Ásíríà yóò bára wọn ṣọ̀rẹ́. Báwo?
36 Nígbà tí Jèhófà gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè látijọ́, bí ẹni pé ó la òpópónà òmìnira fún wọn ni. (Aísáyà 11:16; 35:8-10; 49:11-13; Jeremáyà 31:21) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ ráńpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun Bábílónì, tí àwọn ìgbèkùn láti Ásíríà àti Íjíbítì àtàwọn ti Bábílónì sì di ẹni tó padà sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Aísáyà 11:11) Òde òní wá ńkọ́?
37. Báwo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lónìí ṣe ń gbé ìgbésí ayé bíi pé òpópónà wà láàárín “Ásíríà” àti “Íjíbítì”?
37 Lóde òní, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró Ísírẹ́lì tẹ̀mí jẹ́ Dáníẹ́lì 11:5, 8) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó dìhámọ́ra ogun àti látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó túbọ̀ mú nǹkan rọrùn wọ̀nyí ló ti ń tọ ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́. Bó ṣe di pé àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń fi ìṣọ̀kan ‘ṣe iṣẹ́ ìsìn’ pọ̀ nìyẹn. Wíwá tí wọ́n wá látinú orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kò fa ìpínyà láàárín wọn rárá. Wọ́n fẹ́ràn ara wọn, dépò táa fi lè sọ ní tòótọ́ pé ‘Ásíríà wá sí Íjíbítì, tí Íjíbítì sì wá sí Ásíríà.’ Àfi bíi pé òpópónà tinú ọ̀kan já sí ìkejì.—1 Pétérù 2:17.
“ìbùkún ní àárín ilẹ̀ ayé.” Wọ́n ń gbé ìsìn tòótọ́ lárugẹ, wọ́n sì ń kéde iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn kan lára orílẹ̀-èdè wọ̀nyí rí bí Ásíríà, wọ́n dìhámọ́ra ogun kùkùkaka. Bẹ́ẹ̀ làwọn orílẹ̀-èdè mìíràn sì túbọ̀ mú nǹkan rọrùn, bóyá bí Íjíbítì, tó fìgbà kan rí jẹ́ “ọba gúúsù” nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì. (38. (a) Báwo ni Ísírẹ́lì yóò ṣe “wá jẹ́ ìkẹta pẹ̀lú Íjíbítì àti Ásíríà”? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi sọ pé “Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn mi”?
38 Àmọ́, báwo ni Ísírẹ́lì ṣe “wá jẹ́ ìkẹta pẹ̀lú Íjíbítì àti Ásíríà”? Ní ìbẹ̀rẹ̀ “àkókò òpin,” ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń sin Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Dáníẹ́lì 12:9; Gálátíà 6:16) Láti àwọn ọdún 1930, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “àwọn àgùntàn mìíràn” wá ń yọjú. (Jòhánù 10:16a; Ìṣípayá 7:9) Bí wọ́n ṣe jáde wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè—tó ṣàpẹẹrẹ Íjíbítì àti Ásíríà—wọ́n ń wọ́ tìrítìrí lọ sínú ilé ìjọsìn Jèhófà, wọ́n sì ń ké sí àwọn mìíràn láti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn. (Aísáyà 2:2-4) Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù kan náà táwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń ṣe, wọ́n ń fara da irú àwọn ìdánwò kan náà, ìṣòtítọ́ àti ìwà títọ́ kan náà ni wọ́n ń fi hàn, wọ́n sì jùmọ̀ ń jẹun lórí tábìlì kan náà nípa tẹ̀mí. “Agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan” làwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” jẹ́ lóòótọ́. (Jòhánù 10:16b) Lójú ìtara àti ìfaradà wọn yìí, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè máa ṣiyèméjì pé inú Jèhófà dùn sí ìgbòkègbodò wọn? Abájọ tó fi súre fún wọn pé: “Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn mi”!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 21 Èrò tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ ni pé “ilẹ̀ àwọn kòkòrò akùnrànyìn tí ó ní ìyẹ́ apá” tọ́ka sí àwọn eéṣú tó máa ń ṣí kiri Etiópíà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn mìíràn sọ pé ohun tí wọ́n ń pe “akùnrànyìn” lédè Hébérù, ìyẹn tsela·tsalʹ, dún bíi tsaltsalya, tó jẹ́ orúkọ irù lọ́dọ̀ àwọn Galla, ìyẹn àwọn Hámítì tó ń gbé nílẹ̀ Etiópíà òde òní.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 191]
Àwọn jagunjagun Filísínì ń lépa àwọn ọ̀tá wọn (àwòrán tí wọ́n fín ní Íjíbítì ní ọ̀rúndún kejìlá ṣááju Sànmánì Tiwa)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 192]
Àwòrán jagunjagun tàbí ọlọ́run Móábù tí wọ́n gbẹ́ sára òkúta (láàárín ọ̀rúndún kọkànlá sí ìkẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 196]
Jagunjagun ará Síríà tó gun ràkúnmí (ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 198]
Igbe ẹ̀hónú àti rògbòdìyàn ni “òkun” aráyé ọlọ̀tẹ̀ tó ń ru gùdù ń sọ sókè ṣáá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 203]
Agbára àwọn àlùfáà Íjíbítì kò gbé ohun àrà tí Jèhófà ń ṣe