Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní Mu
Orí Kìíní
Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní Mu
1, 2. (a) Ipò burúkú wo là ń rí nínú ayé lónìí? (b) Báwo ni aṣòfin àgbà kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lórí bí ayé ṣe túbọ̀ ń bàjẹ́ sí i?
LÓNÌÍ, ta ni kì í wọ́nà lójú méjèèjì láti bọ́ kúrò nínú àwọn ìṣòro tó dojú kọ aráyé? Àmọ́, ó mà ṣe o, àléèbá ló máa ń já sí lọ́pọ̀ ìgbà! Àlàáfíà là ń wá lójú méjèèjì, ṣùgbọ́n ogun ló ń jà wá. Kófin àti ètò wà láwùjọ la fẹ́, ṣùgbọ́n, a kò lè dá olè jíjà, ìfipábánilòpọ̀, àti ìpànìyàn tó ń ga sí i láwùjọ wa dúró. Ká fọkàn tán àwọn aládùúgbò wa la fẹ́, ṣùgbọ́n ó di dandan láti máa ti àwọn ilẹ̀kùn wa pa, fáàbò ara wa. A fẹ́ràn àwọn ọmọ wa, a sì ń gbìyànjú láti fi ìwà ọmọlúwàbí kọ́ wọn, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣojú wa ni ìwàkiwà àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn máa ń ràn wọ́n láìsí ohun táa lè ṣe sí i.
2 Ká kúkú gbà pẹ̀lú ohun tí Jóòbù sọ ni pé ìgbà kúkúrú téèyàn ń lò láyé “kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Àgàgà táyé ọ̀hún tún wá burú, tó tún bògìrì lóde òní. Aṣòfin àgbà kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Kò sí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ mọ́ báyìí, àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ṣe ni àyè kúkú wá gba ìwà kí ẹ̀yà, ìran, àti àwọn ẹ̀sìn máa fìwà ìkà gbẹ̀san lára ọmọnìkejì wọn. . . . A ti fàyè gba ìgbàkugbà débi pé púpọ̀ àwọn èwe wa ò mọ èwo nìwà tí kò yẹ láti hù mọ́, gbogbo nǹkan tojú sú wọn, ìṣòro tó sì ń bá wọn fínra kì í ṣe kékeré. Èyí ti wá yọrí sí pípa tí àwọn òbí ń pa ọmọ wọn tì, ìkọ̀sílẹ̀, híhùwà àìdáa sọ́mọdé, káwọn ọmọ máa gboyún, pípa ilé ẹ̀kọ́ tì, ìkóògùnjẹ, àti ìwà ipá tó kún àwọn ìgboro wa. Ńṣe ló dà bíi pé, lẹ́yìn tí ilé wa ti la ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan tí ń jẹ́ Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ já, ni ikán tún wá ṣùrù bò ó.”
3. Ìwé Bíbélì wo ló fúnni nírètí ọjọ́ ọ̀la lọ́nà àrà ọ̀tọ̀?
3 Àmọ́ ṣá, ìrètí ṣì wà. Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run mí sí ọkùnrin kan tí ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, láti sọ onírúurú àsọtẹ́lẹ̀ tó nítumọ̀ àkànṣe fún ọjọ́ wa. Àkọsílẹ̀ ìsọfúnni wọ̀nyí wà nínú ìwé Aísáyà, ìyẹn ìwé Bíbélì tí ń jórúkọ wòlíì náà. Ta ni Aísáyà, kí sì nìdí táa fi lè sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, tó wà lákọsílẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo aráyé lónìí?
Olódodo Lákòókò Rúkèrúdò
4. Ta ni Aísáyà, ìgbà wo ló sì jẹ́ wòlíì Jèhófà?
4 Aísáyà sọ nínú ẹsẹ àkọ́kọ́ ìwé rẹ̀ pé òun jẹ́ “ọmọkùnrin Émọ́sì,” * ó sì sọ fún wa pé òun ṣe iṣẹ́ wòlíì Ọlọ́run “ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà, Jótámù, Áhásì àti Hesekáyà, àwọn ọba Júdà.” (Aísáyà 1:1) Èyí túmọ̀ sí pé, ó kéré tán, ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni Aísáyà fi ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tí ń jíṣẹ́ Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Júdà, bóyá ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìparí ìjọba Ùsáyà—ní nǹkan bí ọdún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa.
5, 6. Báwo ló jọ pé ìdílé Aísáyà ṣe rí, kí ló sì fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀?
5 Ìba díẹ̀ la mọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé Aísáyà fúnra rẹ̀, táa bá ní ká fi wéra pẹ̀lú ohun táa mọ̀ nípa àwọn wòlíì mìíràn. A ṣáà mọ̀ pé ó láya, ó sì pe aya rẹ̀ ní “wòlíì obìnrin.” (Aísáyà 8:3) Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, tí McClintock àti Strong ṣe ti wí, ohun tó pe aya rẹ̀ yìí fi hàn pé “yàtọ̀ sí ti pé” bí ìdílé Aísáyà ṣe rí “bá iṣẹ́ tó ń ṣe mu, ó tún fi hàn pé ṣe ni méjèèjì wọnú ara wọn ṣinṣin.” Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ aya Aísáyà alára jẹ́ iṣẹ́ wòlíì, gẹ́gẹ́ bíi tàwọn obìnrin olùfọkànsìn kan ní Ísírẹ́lì àtijọ́.—Àwọn Onídàájọ́ 4:4; 2 Àwọn Ọba 22:14.
6 Ó kéré tán, Aísáyà àti aya rẹ̀ ní ọmọ méjì, wọ́n sì sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lórúkọ tó bá ọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀ lọ. Èyí àkọ́bí, Ṣeari-jáṣúbù, bá Aísáyà lọ nígbà tó lọ jẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run fún Áhásì Ọba. (Aísáyà 7:3) Ó hàn gbangba pé kárí ilé ni Aísáyà àti aya rẹ̀ fọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run ṣe—àpẹẹrẹ rere lèyí mà jẹ́ fún gbogbo tọkọtaya Kristẹni lóde òní o!
7. Ṣàpèjúwe bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní Júdà lọ́jọ́ Aísáyà.
7 Ayé ìgbà Aísáyà àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ àkókò tí rúkèrúdò gbòde kan ní Júdà. Rògbòdìyàn òṣèlú gbilẹ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbà ti ba àwọn ilé ẹjọ́ jẹ́, àgàbàgebè ti sọ ẹ̀sìn dìdàkudà láwùjọ. Orí àwọn òkè kún fọ́fọ́ fún pẹpẹ àwọn ọlọ́run èké. Kódà òmíràn nínú àwọn ọba ń gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, yàtọ̀ sí pé Áhásì fàyè gba ìbọ̀rìṣà láàárín àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀, òun gan-an tún ń bọ̀rìṣà, ó ń mú ọmọ tirẹ̀ alára “la iná kọjá” nígbà ààtò ẹbọ rírú sí Mólékì ọlọ́run àwọn ará Kénáánì. * (2 Àwọn Ọba 16:3, 4; 2 Kíróníkà 28:3, 4) Áà, kí gbogbo èyí sì máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tí wọ́n ti bá Jèhófà dá májẹ̀mú!—Ẹ́kísódù 19:5-8.
8. (a) Irú àpẹẹrẹ wo ni Ùsáyà àti Jótámù Ọba fi lélẹ̀, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn? (b) Báwo ni Aísáyà ṣe fi ìgboyà hàn láàárín àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn?
8 Ó dùn mọ́ni pé àwọn kan lára àwọn tó wà láyé nígbà Aísáyà—títí kan àwọn alákòóso mélòó kan—ṣe dáadáa, wọ́n sapá láti gbé ìsìn mímọ́ lárugẹ. Lára wọn ni Ùsáyà Ọba, tó ṣe “ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà.” Síbẹ̀síbẹ̀, lákòókò ìṣàkóso rẹ̀ àwọn ènìyàn “ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga.” (2 Àwọn Ọba 15:3, 4) Jótámù Ọba pẹ̀lú “ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” Síbẹ̀, “àwọn ènìyàn náà ṣì ń gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun.” (2 Kíróníkà 27:2) Bẹ́ẹ̀ ni, ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo ìgbà tí Aísáyà fi ń sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, ipò tó bani nínú jẹ́ ni ìjọba Júdà wà nípa tẹ̀mí àti nínú ìwà híhù. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àwọn èèyàn kọ ẹ̀yìn sí ipá tí àwọn ọba wọn ń sà láti tọ́ wọn sọ́nà. Dájúdájú, jíjẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn olóríkunkun wọ̀nyí kì í ṣe ohun tí yóò rọrùn. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí Jèhófà béèrè pé, “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Aísáyà ò lọ́ra rárá. Kíá ló dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”—Aísáyà 6:8.
Ó Jíṣẹ́ Ìgbàlà
9. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ Aísáyà, báwo sì ni èyí ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwé rẹ̀?
9 Orúkọ Aísáyà túmọ̀ sí “Ìgbàlà Jèhófà,” a sì kúkú lè sọ pé èyí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ iṣẹ́ tí ó jẹ́. Lóòótọ́, mélòó kan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ ti ìdájọ́. Síbẹ̀ náà, gbọnmọ-gbọnmọ lẹṣin ọ̀rọ̀ ìgbàlà ń ró nínú gbogbo rẹ̀. Àṣetúnṣe ni Aísáyà ń ṣàlàyé lórí bí Jèhófà yóò ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú Bábílónì bó bá ti tó àkókò, tí àwọn àṣẹ́kù kan yóò fi lè padà sí Síónì láti lè tún ilẹ̀ náà ṣe padà sí ipò ẹlẹ́wà tó wà tẹ́lẹ̀ rí. Dájúdájú, ìdùnnú Aísáyà yóò pọ̀ gan-an pé ó láǹfààní láti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀, tí òun fúnra rẹ̀ tún kọ sílẹ̀, nípa ìmúbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù, ìlú rẹ̀ àtàtà!
10, 11. (a) Èé ṣe tí a fi nífẹ̀ẹ́ sí ìwé Aísáyà lónìí? (b) Báwo ni ìwé Aísáyà ṣe pe àfiyèsí sí Mèsáyà?
Dáníẹ́lì 9:25; Jòhánù 12:41) Dájúdájú, kì í ṣe èèṣì lorúkọ Jésù àti ti Aísáyà fi fẹ́rẹ̀ẹ́ máa sọ ohun kan náà, nítorí ìtumọ̀ orúkọ Jésù ni “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”
10 Ṣùgbọ́n kí ló wá kàn wá nínú ọ̀ràn iṣẹ́ ìdájọ́ àti ìgbàlà tí ó jẹ́ náà? Ó dùn mọ́ni pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà kì í ṣe fún kìkì àǹfààní ìjọba Júdà tó jẹ́ ẹ̀yà méjì. Rárá o, àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ ṣe pàtàkì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ fún ọjọ́ wa lónìí. Aísáyà ṣe àpèjúwe tó bùáyà nípa bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe mú àwọn ìbùkún tó kàmàmà bá ilẹ̀ ayé wa. Nípa èyí, apá tó pọ̀ gan-an nínú àkọsílẹ̀ Aísáyà dá lórí Mèsáyà tí àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́nu kàn, ẹni tí yóò jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (11 Lóòótọ́, ó tó ọ̀rúndún méje lẹ́yìn ọjọ́ Aísáyà kí wọ́n tó bí Jésù. Síbẹ̀, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú ìwé Aísáyà kún rẹ́rẹ́, ó sì ṣe wẹ́kú gan-an ni, àfi bí ẹni pé ìtàn ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé ṣojú ẹni tó kọ ọ́. Ẹnì kan sọ pé ìyẹn ló ń mú kí àwọn kan pe ìwé Aísáyà ní “Ìhìn Rere Karùn-ún” nígbà mìíràn. Abájọ tó fi jẹ́ pé Aísáyà ni ìwé Bíbélì tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ jù lọ tí wọ́n bá fẹ́ ṣàlàyé tó yéni yéké lórí ohun tí a fi lè dá Mèsáyà mọ̀.
12. Èé ṣe tó fi yẹ ká tara ṣàṣà kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Aísáyà?
12 Onírúurú ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tó gbámúṣé ni Aísáyà fi ṣàpèjúwe “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” níbi tí ‘ọba kan yóò ti jẹ fún òdodo’ tí àwọn ọmọ aládé yóò sì ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo. (Aísáyà 32:1, 2; 65:17, 18; 2 Pétérù 3:13) Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé Aísáyà sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìrètí amọ́kànyọ̀, tí yóò wáyé lábẹ́ Jésù Kristi, Mèsáyà, tó máa jẹ́ Ọba rẹ̀. Ìṣírí ńláǹlà mà lèyí fún wa o, pé lójoojúmọ́ kí a máa fi ayọ̀ retí “ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ [Jèhófà]”! (Aísáyà 25:9; 40:28-31) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká tara ṣàṣà gbé ìsọfúnni àtàtà tó wà nínú ìwé Aísáyà yẹ̀ wò. Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbọ́kànlé tí a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò túbọ̀ lágbára sí i. Bákan náà, yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìdánilójú wa túbọ̀ lágbára sí i pé Jèhófà ni Ọlọ́run ìgbàlà wa lóòótọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 4 Ká má ṣi Émọ́sì baba Aísáyà gbé fún Ámósì tó sàsọtẹ́lẹ̀ nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Ùsáyà, tó sì tún jẹ́ pé òun náà ló kọ ìwé Bíbélì tí ń jórúkọ rẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn kan sọ pé ‘líla iná kọjá’ lè túmọ̀ sí ṣíṣe ààtò ìwẹ̀nùmọ́. Àmọ́, ó jọ pé rírúbọ ní ti gidi ni gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí. Kò sí àní-àní ní ti pé àwọn ará Kénáánì àti Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà máa ń fọmọ rúbọ.—Diutarónómì 12:31; Sáàmù 106:37, 38.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ta Ni Aísáyà?
ÌTUMỌ̀ ORÚKỌ RẸ̀: “Ìgbàlà Jèhófà”
ÌDÍLÉ RẸ̀: Ó láya, ó kéré tán ó bí ọmọ méjì
IBÙGBÉ RẸ̀: Jerúsálẹ́mù
IYE ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN RẸ̀: Ó kéré tán ó jẹ́ ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta, láti nǹkan bí ọdún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa sí nǹkan bí ẹ̀yìn ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa
ÀWỌN ỌBA TÓ JẸ NÍ JÚDÀ LÁYÉ ÌGBÀ TIẸ̀: Ùsáyà, Jótámù, Áhásì, Hesekáyà
ÀWỌN WÒLÍÌ TÓ WÀ LÁYÉ ÌGBÀ TIẸ̀: Míkà, Hóséà, Ódédì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Kárí ilé ni Aísáyà àti aya rẹ̀ fọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run ṣe