Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣírí Ìwà Àgàbàgebè Tú O!

Àṣírí Ìwà Àgàbàgebè Tú O!

Orí Kọkàndínlógún

Àṣírí Ìwà Àgàbàgebè Tú O!

Aísáyà 58:1-14

1. Ojú wo ni Jésù àti Jèhófà fi ń wo àgàbàgebè, irú àgàbàgebè wo ni wọ́n sì ń ṣe nígbà ayé Aísáyà?

JÉSÙ sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin . . . ní tòótọ́, fara hàn lóde bí olódodo sí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ní inú, ẹ kún fún àgàbàgebè àti ìwà-àìlófin.” (Mátíù 23:28) Bí Jésù ṣe bẹnu àtẹ́ lu ìwà àgàbàgebè yìí gẹ́lẹ́ ni Bàbá rẹ̀ ọ̀run ṣe kórìíra ìwà àgàbàgebè pẹ̀lú. Ìwà àgàbàgebè tó gbilẹ̀ ní Júdà ni orí kejìdínlọ́gọ́ta àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà pàfiyèsí sí ní pàtàkì. Gbọ́nmisi-omi-ò-to, ìnilára, àti ìwà ipá gbòde kan, wọ́n sì sọ Sábáàtì pípa mọ́ dí ààtò ṣíṣe lásán. Iṣẹ́ ìsìn gbà-má-pòóò-rọ́wọ́-mi làwọn èèyàn yẹn ń ṣe fún Jèhófà, wọn á tìtorí ṣekárími máa gbààwẹ̀ tí kò dénú ọkàn láti fi hàn pé àwọn ní ìtara ìsìn. Abájọ tí Jèhófà fi tú wọn fó gbáà!

‘Sọ Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Èèyàn Yìí fún Wọn’

2. Ẹ̀mí wo ni Aísáyà fi ń polongo iṣẹ́ tí Jèhófà rán an, àwọn wo ló sì dà bíi tirẹ̀ lóde òní?

2 Lóòótọ́ ìwà Júdà kó Jèhófà nírìíra gidigidi, síbẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ń bá orílẹ̀-èdè yẹn sọ, ó ṣì rọ̀ wọ́n tọkàntọkàn pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Àmọ́, Jèhófà ń fẹ́ kí wọ́n mọ ìbáwí òun sí ìbáwí lóòótọ́. Ìyẹn ló fi pàṣẹ fún Aísáyà pé: “Fi gbogbo ọ̀fun ké; má fawọ́ sẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí ìwo, kí o sì sọ ìdìtẹ̀ àwọn ènìyàn mi fún wọn, kí o sì sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jékọ́bù fún un.” (Aísáyà 58:1) Àwọn èèyàn lè bínú sí Aísáyà bí ó ṣe ń fi ìgboyà polongo ọ̀rọ̀ Jèhófà o, ṣùgbọ́n kò torí ìyẹn fà sẹ́yìn. Ẹ̀mí iṣẹ́ ìsìn kan náà tí ó ní tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tó fi sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi,” ló ṣì ní. (Aísáyà 6:8) Àpẹẹrẹ àtàtà gbáà ni ìfaradà Aísáyà jẹ́ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní, àwa tí Ọlọ́run yan bákan náà pé kí a lọ wàásù Ọ̀rọ̀ Òun kí a sì túdìí àṣírí àgàbàgebè inú ìsìn!—Sáàmù 118:6; 2 Tímótì 4:1-5.

3, 4. (a) Ojú ayé wo làwọn èèyàn ìgbà ayé Aísáyà ń ṣe? (b) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Júdà ní ti gidi?

3 Ojú ayé làwọn èèyàn ìgbà Aísáyà ń ṣe bí wọ́n ṣe láwọn ń wá Jèhófà àti pé àwọn ń fi inú dídùn hàn sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀. A ka ọ̀rọ̀ Jèhófà pé: “Ní ọjọ́ dé ọjọ́, èmi ni wọ́n ń wá, ìmọ̀ àwọn ọ̀nà mi sì ni wọ́n fi inú dídùn hàn sí, bí orílẹ̀-èdè tí ń bá a lọ ní ṣíṣe òdodo, tí kò sì fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn sílẹ̀, ní ti pé wọ́n ń béèrè fún ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ mi, wọ́n ń sún mọ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní inú dídùn sí.” (Aísáyà 58:2) Ǹjẹ́ ojúlówó ìdùnnú ni èyí tí wọ́n ń sọ pé àwọn ní nínú àwọn ọ̀nà Jèhófà yìí bí? Rárá o. Òótọ́ ní pé wọ́n dà “bí orílẹ̀-èdè tí ń bá a lọ ní ṣíṣe òdodo,” àmọ́ wọ́n kàn jọ ọ́ ní ìrísí ni. Ní tòótọ́, orílẹ̀-èdè yìí ti “fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn sílẹ̀.”

4 Ọ̀ràn wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ má yàtọ̀ rárá sí èyí tí Ọlọ́run ṣí payá fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì lẹ́yìn náà. Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé àwọn Júù ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà jáde.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kìlọ̀ fún Ìsíkíẹ́lì nípa ẹ̀tàn ọkàn wọn, ó ní: “Wọn yóò sì wọlé wá bá ọ, . . . wọn yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ dájúdájú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò ṣe wọ́n, nítorí ẹnu wọn ni wọ́n fi ń sọ ìfẹ́-ọkàn onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ jáde, èrè wọn aláìbá ìdájọ́ òdodo mu sì ni ọkàn-àyà wọn ń tọ̀ lẹ́yìn. Sì wò ó! lójú wọn, ìwọ dà bí orin ìfẹ́ tí ń ru ìmọ̀lára sókè, bí ẹni tí ó ní ohùn iyọ̀, tí ó sì ń ta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín dáadáa. Wọn yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ dájúdájú, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí yóò ṣe wọ́n.” (Ìsíkíẹ́lì 33:30-32) Àwọn tó wà láyé nígbà ayé Aísáyà pẹ̀lú sọ pé àwọn ń ṣàfẹ́rí Jèhófà nígbà gbogbo, àmọ́ wọn kò ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí.

Ààwẹ̀ Àgàbàgebè

5. Ọ̀nà wo làwọn Júù gbìyànjú láti fi rí ojú rere Ọlọ́run, kí sì ni Jèhófà sọ nípa rẹ̀?

5 Àwọn Júù lọ ń gbààwẹ̀ ojú ayé lásán nítorí pé wọ́n fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òdodo arúmọjẹ wọn kúkú sọ wọ́n dẹni tó jìnnà sí Jèhófà ni. Ó jọ pé ìdààmú tó bá wọn ló mú kí wọ́n wá béèrè pé: “Fún ìdí wo ni a fi ń gbààwẹ̀ tí ìwọ kò sì rí i, tí a sì ń ṣẹ́ ọkàn wa níṣẹ̀ẹ́ tí ìwọ kò sì fiyè sí i?” Ni Jèhófà bá la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ fún wọ́n pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀yin ń rí inú dídùn nínú ọjọ́ ààwẹ̀ gbígbà yín, nígbà tí gbogbo àwọn aṣelàálàá yín ń bẹ tí ẹ ń kó lọ ṣiṣẹ́ ṣáá. Ní tòótọ́, fún aáwọ̀ àti ìjàkadì ni ẹ ń gbààwẹ̀, àti fún fífi ìkúùkù ìwà burúkú gbáni. Ẹ̀yin kò ha ń gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ tí ẹ ń mú kí a gbọ́ ohùn yín ní ibi gíga? Ṣé ó yẹ kí ààwẹ̀ tí mo yàn dà báyìí, bí ọjọ́ tí ará ayé ń ṣẹ́ ọkàn rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́? Tí ó ń tẹ orí rẹ̀ ba bí koríko etídò, kí ó sì tẹ́ aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú lásán-làsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀? Ṣé èyí ni ẹ ń pè ní ààwẹ̀ àti ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Jèhófà?”—Aísáyà 58:3-5.

6. Ìṣesí àwọn Júù wo ló tú wọn fó pé ààwẹ̀ àgàbàgebè ni wọ́n ń gbà?

6 Bí àwọn Júù yìí ṣe ń gbààwẹ̀, tí wọ́n ń ṣe òdodo arúmọjẹ, àní tí wọ́n tún ń béèrè fún àwọn ìdájọ́ òdodo Jèhófà pàápàá, wọn ò yéé lépa fàájì àti òwò onímọtara ẹni nìkan káàkiri. Wọ́n ń ṣaáwọ̀, wọ́n ń nini lára, wọ́n sì ń hùwà ipá. Láti lè dọ́gbọ́n fara hàn bíi pé wọ́n jẹ́ olódodo, wọn a máa ṣe ọ̀fọ̀ lọ́nà ṣekárími, wọ́n a soríkọ́ bí eèsún, wọn a sì jókòó sínú eérú tàwọn tí aṣọ àpò ìdọ̀họ lára, ní gbígbìyànjú láti fi hàn pé àwọn ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn. Àmọ́ kí làǹfààní gbogbo ìyẹn bí wọ́n bá ṣì ń bá ìṣọ̀tẹ̀ wọn lọ? Wọn kò tilẹ̀ ní ìkankan nínú ẹ̀dùn ọkàn àti ìrònúpìwàdà lọ́nà ti Ọlọ́run tó máa ń wé mọ́ ààwẹ̀ àtọkànwá rárá. Lóòótọ́ wọ́n pariwo gan-an bí wọ́n ṣe ń pohùn réré ẹkún o, síbẹ̀ ariwo wọn ò dé ọ̀run rárá o.

7. Báwo ni àwọn Júù ìgbà ayé Jésù ṣe hùwà àgàbàgebè, báwo sì ni ọ̀pọ̀ lónìí ṣe ń hu irú ìwà kan náà?

7 Àwọn Júù ìgbà ayé Jésù pẹ̀lú ń gbààwẹ̀ lọ́nà àṣà, àwọn kan tilẹ̀ ń gbà á lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ pàápàá! (Mátíù 6:16-18; Lúùkù 18:11, 12) Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ló sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìran ìgbà ayé Aísáyà pẹ̀lú, wọ́n le koko mọ́ni, wọ́n sì ń tẹni lórí ba. Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù fi ìgboyà táṣìírí àwọn àgàbàgebè onísìn wọ̀nyẹn, ó sì sọ fún wọn pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn jẹ́ òtúbáńtẹ́. (Mátíù 15:7-9) Lónìí pẹ̀lú, ẹgbàágbèje èèyàn ló ń “polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn, nítorí tí wọ́n jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí àti aláìgbọràn, a kò sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n fún iṣẹ́ rere èyíkéyìí.” (Títù 1:16) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa retí pé àwọn yóò rí àánú Ọlọ́run gbà o, àmọ́ ìwà wọn ń tú wọn fó pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dénú ọkàn wọn rárá. Lọ́nà tó yàtọ̀ sí tiwọn, ojúlówó ìfọkànsin Ọlọ́run àti ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣèwà hù.—Jòhánù 13:35.

Ohun Tó Wé Mọ́ Ìrònúpìwàdà Tòótọ́

8, 9. Àwọn ìṣe àtàtà wo ló ní láti bá ìrònúpìwàdà àtọkànwá rìn?

8 Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe ju pé kí wọ́n sáà ti gbààwẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ; ńṣe ló ń fẹ́ kí wọ́n ronú pìwà dà. Ìyẹn ni wọ́n fi lè rí ojú rere rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 18:23, 32) Ó ṣàlàyé pé kí ààwẹ̀ èèyàn tó lè nítumọ̀, onítọ̀hún ní láti ṣàtúnṣe lórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtẹ̀yìnwá. Wo ìbéèrè tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn tí Jèhófà béèrè, ó ní: “Èyí ha kọ́ ni ààwẹ̀ tí mo yàn? Láti tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìwà burúkú, láti tú ọ̀já ọ̀pá àjàgà, àti láti rán àwọn tí a ni lára lọ lómìnira, àti pé kí ẹ fa gbogbo ọ̀pá àjàgà já sí méjì?”—Aísáyà 58:6.

9 Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àti ọ̀pá àjàgà jẹ́ ohun tí a fi ṣàpèjúwe oko òǹdè lọ́nà tó bá a mu gan-an. Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí àwọn èèyàn yẹn máa gbààwẹ̀ kí wọ́n sì máa bá a nìṣó ní títẹ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lórí ba lẹ́sẹ̀ kan náà, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí òfin tó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Ńṣe ló yẹ kí wọ́n tú gbogbo àwọn tí wọ́n ń ni lára àtàwọn tí wọ́n kó lẹ́rú láìtọ́ sílẹ̀. * Àwọn àṣehàn inú ìsìn, bí ààwẹ̀ gbígbà, kò lè rọ́pò ojúlówó ìfọkànsin Ọlọ́run àti àwọn ìwà tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìfẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀. Wòlíì Míkà tó gbé láyé nígbà ayé Aísáyà kọ̀wé pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—Míkà 6:8.

10, 11. (a) Kí ni yóò sàn kí àwọn Júù ṣe ju ààwẹ̀ gbígbà lọ? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni òde òní ṣe lè fi ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún àwọn Júù sílò?

10 Ìdájọ́ òdodo, inú rere àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ń béèrè pé kéèyàn máa ṣe ọmọnìkejì rẹ̀ lóore, ìyẹn sì ni ète tí Òfin Jèhófà wà fún. (Mátíù 7:12) Bí wọ́n bá pín lára ọrọ̀ wọn fún àwọn aláìní, ìyẹn gan-an sàn ju ààwẹ̀ gbígbà lọ dáadáa. Jèhófà béèrè pé: [Ààwẹ̀ tí mo yàn] kì í ha ṣe pípín oúnjẹ rẹ fún ẹni tí ebi ń pa, àti pé kí o mú àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, àwọn aláìnílé, wá sínú ilé rẹ? Pé, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ rí ẹnì kan tí ó wà ní ìhòòhò, kí o bò ó, àti pé kí o má fi ara rẹ pa mọ́ fún ẹran ara tìrẹ?” (Aísáyà 58:7) Ní tòótọ́, kàkà tí àwọn tó rí já jẹ yóò fi máa gba ààwẹ̀ ṣekárími, ńṣe ló yẹ kí wọ́n fún àwọn ará Júdà ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ aláìní, ìyẹn ara àwọn fúnra wọn, ní oúnjẹ, aṣọ, tàbí ilé.

11 Àwọn Júù ìgbà ayé Aísáyà nìkan kọ́ ni àwọn ìlànà àtàtà tó dá lórí ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni àti ìyọ́nú tí Jèhófà fi hàn yìí kàn. Wọ́n jẹ́ atọ́nà fún àwọn Kristẹni pẹ̀lú. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ìjọ Kristẹni ní láti jẹ́ ibi tí ìfẹ́, àní ìfẹ́ ará ti jọba, pàápàá bó ṣe jẹ́ pé àkókò tí a ń gbé báyìí túbọ̀ ń le koko sí i ni.—2 Tímótì 3:1; Jákọ́bù 1:27.

Ìgbọràn Máa Ń Mú Ìbùkún Jìngbìnnì Wá

12. Kí ni Jèhófà yóò ṣe bí àwọn èèyàn rẹ̀ bá gbọ́ràn sí i lẹ́nu?

12 Áà, àwọn èèyàn Jèhófà ì bá jẹ́ lo làákàyè wọn kí wọ́n fi ìbáwí Jèhófà sílò! Jèhófà sọ pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò là gẹ́gẹ́ bí ọ̀yẹ̀; pẹ̀lú ìyára kánkán sì ni ìkọ́fẹ yóò rú jáde fún ọ. Iwájú rẹ sì ni òdodo rẹ yóò ti máa rìn dájúdájú; àní ògo Jèhófà ni yóò jẹ́ ẹ̀ṣọ́ rẹ níhà ẹ̀yìn. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò sì dáhùn; ìwọ yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, ‘Èmi rèé!’” (Aísáyà 58:8, 9a) Ọ̀rọ̀ yìí mà tuni lára, ó mà sì fani mọ́ra o! Jèhófà a máa bù kún àwọn tó fẹ́ràn inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òdodo, a sì máa dáàbò bò wọ́n. Bí àwọn èèyàn Jèhófà bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì jáwọ́ nínú líle tí wọ́n ń le koko mọ́ni àti ìwà àgàbàgebè wọn, tí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, nǹkan yóò bẹ̀rẹ̀ sí dáa sí i fún wọn. Jèhófà yóò mú kí orílẹ̀-èdè wọn ní “ìkọ́fẹ,” kí ara wọ́n padà mókun nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara. Yóò sì ṣọ́ wọn bó ṣe ṣọ́ àwọn baba ńlá wọn nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò ní Íjíbítì. Kíákíá ni yóò sì máa dáhùn sí igbe tí wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́.—Ẹ́kísódù 14:19, 20, 31.

13. Àwọn ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn Júù bí wọ́n bá kọbi ara sí ìyànjú tí Jèhófà ń gbà wọ́n?

13 Jèhófà wá fi kún ìyànjú tó ti ń gbà wọ́n bọ̀ látẹ̀yìnwá, ó ní: “Bí ìwọ yóò bá mú ọ̀pá àjàgà [ìmúnisìn lílekoko, tí kò tọ́], nína ìka [ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ fún ìṣáátá tàbí ẹ̀sùn èké], àti sísọ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ kúrò ní àárín rẹ; tí ìwọ yóò sì yọ̀ǹda ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn rẹ fún ẹni tí ebi ń pa, tí ìwọ yóò sì tẹ́ ọkàn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ lọ́rùn, ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú yóò kọ mànà àní nínú òkùnkùn, ìṣúdùdù rẹ yóò sì dà bí ọjọ́kanrí.” (Aísáyà 58:9b, 10) Ìwà ìmọtara ẹni nìkan àti lílekoko mọ́ni a máa kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́, a sì máa múni rí ìbínú Jèhófà. Àmọ́ inúure àti ìwà ọ̀làwọ́ a máa múni gba ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, pàápàá bó bá jẹ́ ẹni tí ebi ń pa àti ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ la ṣe é fún. Àwọn Júù ì bá jẹ́ fi òtítọ́ wọ̀nyí sọ́kàn! Ìtànyòò wọn àti aásìkí wọn nípa tẹ̀mí ì bá mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọjọ́kanrí, tí kò fi ní sí ìṣúdùdù kankan lọ́ràn wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọn yóò mú ọlá àti ìyìn wá fún Jèhófà, Orísun ògo àti ìbùkún wọn.—1 Àwọn Ọba 8:41-43.

Orílẹ̀-Èdè Tó Padà Bọ̀ Sípò

14. (a) Ìhà wo ni àwọn tó gbé ayé nígbà ayé Aísáyà kọ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Ọ̀rọ̀ kí ni Jèhófà ń bá a lọ láti sọ fún wọn?

14 Ó dunni pé orílẹ̀-èdè náà kọ etí ikún sí rírọ̀ tí Jèhófà rọ̀ wọ́n, àní wọ́n tilẹ̀ tún tara bọ ìwà ibi sí i pàápàá. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣe é débi pé kò tún sóhun tó kù fún Jèhófà láti ṣe ju pé kó sọ wọ́n dèrò ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kìlọ̀ fún wọn ṣáájú. (Diutarónómì 28:15, 36, 37, 64, 65) Síbẹ̀, Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ ìrètí nínú ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àṣẹ́kù kan tó ti kọ́gbọ́n, tó sì kẹ́dùn ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò fi ìdùnnú padà wá sí ilẹ̀ Júdà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ náà wà láhoro.

15. Ìmúbọ̀sípò aláyọ̀ wo ni Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?

15 Bí Jèhófà ṣe wá gbẹnu Aísáyà sọ̀rọ̀ nípa ìmúbọ̀sípò tí yóò dé bá àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó ní: “Ó dájú pé Jèhófà yóò máa ṣamọ̀nà rẹ nígbà gbogbo, yóò sì máa tẹ́ ọkàn rẹ lọ́rùn àní ní ilẹ̀ gbígbẹ, yóò sì fún egungun rẹ gan-an lókun; ìwọ yóò sì dà bí ọgbà tí a ń bomi rin dáadáa, àti bí orísun omi, omi tí kì í tanni jẹ [‘ìsun omi tí omi rẹ̀ kì í tán,’ Bíbélì Mímọ́].” (Aísáyà 58:11) Jèhófà yóò sọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó ti di gbígbẹ di ilẹ̀ eléso wọ̀ǹtìwọnti. Èyí tó tilẹ̀ jẹ́ ìyanu jù lọ ni pé, yóò bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti ronú pìwà dà, yóò fún ‘egungun wọn gan-an’ lókun, tí wọn yóò tinú ipò òkú nípa tẹ̀mí dẹni tó wá ń ta kébékébé. (Ìsíkíẹ́lì 37:1-14) Ńṣe ni àwọn èèyàn náà yóò dà bí “ọgbà tí a ń bomi rin dáadáa,” tí ń so èso wọ̀ǹtìwọnti nípa tẹ̀mí.

16. Báwo ni a ó ṣe mú ilẹ̀ náà padà bọ̀ sípò?

16 Ìmúbọ̀sípò yẹn yóò kan àtúnkọ́ àwọn ìlú tí àwọn ará Bábílónì tó gbógun wá jà wọ́n pa run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. “Nítorí rẹ, ó dájú pé àwọn ènìyàn yóò kọ́ àwọn ibi tí a ti pa run di ahoro tipẹ́tipẹ́; ìwọ yóò gbé ìpìlẹ̀ àwọn ìran tí ń bá a lọ dìde. Ní ti tòótọ́, a óò máa pè ọ́ ní ẹni tí ń ṣe àtúnṣe àwọn àlàfo, àti ẹni tí ń mú àwọn òpópónà tí a óò máa gbé ẹ̀gbẹ́ wọn padà bọ̀ sípò.” (Aísáyà 58:12) Gbólóhùn méjì tó jọra yìí, “àwọn ibi tí a ti pa run di ahoro tipẹ́tipẹ́” àti “ìpìlẹ̀ àwọn ìran tí ń bá a lọ” (tàbí, ìpìlẹ̀ tó wà láhoro láti ìrandíran), fi hàn pé àwọn àṣẹ́kù tí a dá padà wálé yóò tún àwọn ìlú Júdà tó ti di àlàpà kọ́, pàápàá Jerúsálẹ́mù. (Nehemáyà 2:5; 12:27; Aísáyà 44:28) Wọn yóò ṣe àtúnṣe “àwọn àlàfo,” èyí tó ń tọ́ka sí àwọn àlàfo tó wà lára odi Jerúsálẹ́mù, ó sì dájú pé ó kan àwọn ìlú yòókù pẹ̀lú.—Jeremáyà 31:38-40; Ámósì 9:14.

Àwọn Ìbùkún Tí Ń Wá Látinú Fífi Ìṣòtítọ́ Pa Sábáàtì Mọ́

17. Báwo ni Jèhófà ṣe rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n pa àwọn òfin Sábáàtì mọ́?

17 Sábáàtì jẹ́ ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà fi hàn pé ire ti ara àti tẹ̀mí àwọn èèyàn òun jẹ òun lógún gidigidi. Jésù sọ pé: “Sábáàtì wáyé nítorí ènìyàn.” (Máàkù 2:27) Ọjọ́ tí Jèhófà yà sí mímọ́ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkànṣe àǹfààní láti fi hàn pé àwọn fẹ́ràn Ọlọ́run. Ó ṣeni láàánú pé, nígbà tó fi dìgbà ayé Aísáyà, wọ́n ti sọ ọ́ di ọjọ́ ààtò ṣíṣe lásán àti ọjọ́ títẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹni lọ́rùn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó tún di dandan pé kí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìbáwí lẹ́ẹ̀kan sí i. Bẹ́ẹ̀ ló sì tún gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ó ní: “Bí ó bá jẹ́ pé nítorí sábáàtì, ìwọ yóò yí ẹsẹ̀ rẹ padà ní ti ṣíṣe àwọn ohun tí ìwọ ní inú dídùn sí ní ọjọ́ mímọ́ mi, tí ìwọ, ní tòótọ́, yóò sì pe sábáàtì ní inú dídùn kíkọyọyọ, ọjọ́ mímọ́ Jèhófà, èyí tí a ń ṣe lógo, tí ìwọ yóò sì ṣe é lógo ní tòótọ́ dípò títẹ̀lé àwọn ọ̀nà tìrẹ, dípò wíwá ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ àti sísọ ọ̀rọ̀ kan; bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, dájúdájú, èmi yóò mú kí o gun àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé; èmi yóò sì mú kí o jẹ nínú ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù baba ńlá rẹ, nítorí pé ẹnu Jèhófà ti sọ ọ́.”—Aísáyà 58:13, 14.

18. Kí ni kíkùnà tí Júdà kùnà láti bọ̀wọ̀ fún Sábáàtì yóò yọrí sí?

18 Ọjọ́ tó wà fún ríronú nípa ohun tẹ̀mí, àdúrà gbígbà, àti ìjọsìn ìdílé ni ọjọ́ Sábáàtì jẹ́. Ńṣe ló yẹ kó ran àwọn Júù lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣe nítorí tiwọn, kí wọ́n sì ronú lórí ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ tó fi hàn nínú Òfin rẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ kí fífi tí wọ́n bá ń fi ìṣòtítọ́ pa ọjọ́ mímọ́ yìí mọ́ ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wọn ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń ba Sábáàtì jẹ́, ìyẹn sì lè sọ wọ́n dẹni tí ò lè rí ìbùkún Jèhófà gbà mọ́.—Léfítíkù 26:34; 2 Kíróníkà 36:21.

19. Àwọn ìbùkún jìngbìnnì wo làwọn èèyàn Ọlọ́run yóò rí gbà bí wọ́n bá padà bẹ̀rẹ̀ sí pa Sábáàtì mọ́?

19 Àmọ́ ṣá, bí àwọn Júù bá fi ìbáwí yẹn ṣàríkọ́gbọ́n tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀wọ̀ fún ìṣètò Sábáàtì, wọn yóò rí ìbùkún jìngbìnnì gbà. Ire tó máa tipa ṣíṣe ìjọsìn tòótọ́ àti bíbọ̀wọ̀ fún Sábáàtì ya lù wọ́n, yóò wá kún àkúnwọ́sílẹ̀, débi pé yóò kan ohun gbogbo nínú ìgbésí ayé wọn. (Diutarónómì 28:1-13; Sáàmù 19:7-11) Bí àpẹẹrẹ, ṣe ni Jèhófà yóò mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ “gun àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé.” Gbólóhùn yìí dúró fún ààbò àti ìṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ẹni. Ẹni tó bá ń ṣàkóso àwọn ibi gíga, ìyẹn àwọn òkè kéékèèké àti òkè ńlá, ló ni ilẹ̀ ibẹ̀ níkàáwọ́. (Diutarónómì 32:13; 33:29) Láyé ìgbà kan, Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí Jèhófà, ààbò Jèhófà sì wà lórí orílẹ̀-èdè yẹn, tó fi jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń bọ̀wọ̀ fún wọn ni, wọ́n sì tún bẹ̀rù wọn pàápàá. (Jóṣúà 2:9-11; 1 Àwọn Ọba 4:20, 21) Bí wọ́n bá tún padà yíjú sí Jèhófà wàyí nípa gbígbọ́ràn sí i lẹ́nu, wọn yóò rí díẹ̀ lára ògo wọn ìgbà yẹn gbà padà. Jèhófà á wá fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìpín fún àwọn èèyàn rẹ̀ nínú “ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù,” ìyẹn àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí nígbà tó bá àwọn baba ńlá wọn dá májẹ̀mú, pàápàá ìbùkún pé mìmì kan ò ní mì wọ́n kúrò ní Ilẹ̀ Ìlérí yìí.—Sáàmù 105:8-11.

20. Irú “ìsinmi ti sábáàtì” wo ló wà fún àwọn Kristẹni?

20 Ǹjẹ́ àwa Kristẹni lé rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí? Nígbà tí Jésù Kristi kú, Òfin Mósè di èyí tó kọjá lọ, títí kan Sábáàtì pípa mọ́. (Kólósè 2:16, 17) Àmọ́, ohun tó yẹ kí pípa Sábáàtì mọ́ sún àwọn ará Júdà láti máa ṣe, ìyẹn fífi ire tẹ̀mí sípò kìíní àti sísún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́, ṣì ṣe pàtàkì gidigidi fún àwọn olùjọsìn Jèhófà. (Mátíù 6:33; Jákọ́bù 4:8) Ẹ̀wẹ̀, nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Hébérù, ó ní: “Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” Àwọn Kristẹni a máa wọnú “ìsinmi ti sábáàtì” yìí nípa ṣíṣègbọràn sí Jèhófà àti nípa lílépa òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi tó ta sílẹ̀. (Hébérù 3:12, 18, 19; 4:6, 9-11, 14-16) Ọjọ́ kan péré lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kọ́ làwọn Kristẹni fi ń pa irú Sábáàtì yìí mọ́ o, ojoojúmọ́ ni.—Kólósè 3:23, 24.

Ísírẹ́lì Tẹ̀mí “Gun Àwọn Ibi Gíga Ilẹ̀ Ayé”

21, 22. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà mú kí Ísírẹ́lì Ọlọ́run “gun àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé”?

21 Látìgbà tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti gba ìdáǹdè kúró nígbèkùn Bábílónì lọ́dún 1919 ni wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ pa ohun tí Sábáàtì ṣàpẹẹrẹ mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà ti mú kí wọ́n “gun àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé.” Lọ́nà wo? Nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà bá àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù dá májẹ̀mú pé bí wọ́n bá gbọ́ràn, wọn yóò di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Ní gbogbo ogójì ọdún tí wọ́n lò nínú aginjù, ńṣe ni Jèhófà gbé wọn láìséwu, bí idì ṣe ń gbé àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀gúnyẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ìpèsè rẹpẹtẹ jíǹkí wọn. (Diutarónómì 32:10-12) Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè yẹn ṣàìní ìgbàgbọ́, níkẹyìn, wọ́n wá pàdánù àwọn àǹfààní tí wọn ì bá ní. Síbẹ̀ ṣá o, Jèhófà ṣì ní ìjọba àwọn àlùfáà lóde òní. Òun ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run.—Gálátíà 6:16; 1 Pétérù 2:9.

22 Ní “àkókò òpin,” orílẹ̀-èdè nípa tẹ̀mí yìí ṣe ohun tí Ísírẹ́lì àtijọ́ kùnà láti ṣe. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. (Dáníẹ́lì 8:17) Bí àwọn èèyàn inú rẹ̀ ṣe ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ojúlówó ìlànà àti àwọn ọ̀nà gíga lọ́lá ti Jèhófà, wọ́n dẹni tí Jèhófà gbé gòkè sí ibi gíga lọ́nà tẹ̀mí. (Òwe 4:4, 5, 8; Ìṣípayá 11:12) Bí wọ́n ṣe wà lábẹ́ ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà àìmọ́ tó yí wọn ká, wọ́n ń gbé ìgbé ayé ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, dípò tí wọ́n á fi máa wonkoko mọ́ rírìn ní àwọn ọ̀nà tiwọn, wọ́n ní “inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà” àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 37:4) Jèhófà dáàbò bò wọ́n nípa tẹ̀mí lójú àwọn àtakò lílekoko tí wọ́n ń gbé kò wọ́n lójú káàkiri ayé. Láti ọdún 1919, kò sí ẹnikẹ́ni tó tíì ya odi “ilẹ̀” wọn nípa tẹ̀mí. (Aísáyà 66:8) Wọ́n ń bá a lọ láti jẹ́ àwọn tí a ń fi orúkọ rẹ̀ gíga lọ́lá pè, wọ́n sì ń fi tayọ̀tayọ̀ polongo orúkọ yẹn káàkiri ayé. (Diutarónómì 32:3; Ìṣe 15:14) Ní àfikún sí i, àwọn ọlọ́kàn tútù tí iye wọ́n ń pọ̀ sí i, látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, wá ń bá wọn nípìn-ín nínú àǹfààní gíga lọ́lá yìí, ìyẹn àǹfààní dídi àwọn ẹni tí Jèhófà ń kọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tó sì ń ràn lọ́wọ́ láti rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.

23. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró “jẹ nínú ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù”?

23 Jèhófà ti mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró “jẹ nínú ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù.” Nígbà tí baba ńlá nì, Ísákì, ń súre fún Jékọ́bù dípò Ísọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìbùkún yóò wà fún gbogbo àwọn tí yóò bá lo ìgbàgbọ́ nínú Irú Ọmọ Ábúráhámù tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jẹ́nẹ́sísì 27:27-29; Gálátíà 3:16, 17) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn dà bíi Jékọ́bù, wọ́n “mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀,” pàápàá oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè lọ́pọ̀ yanturu, wọn kò dà bí Ísọ̀ rárá. (Hébérù 12:16, 17; Mátíù 4:4) Oúnjẹ tẹ̀mí yìí, tí ó kan ìmọ̀ nípa ohun tí Jèhófà ń gbé ṣe nípasẹ̀ Irú Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ Irú Ọmọ náà, máa ń fún wọn lókun, ó ń mú wọn jí pépé, ó sì ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè wọn nípa tẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. (Sáàmù 1:1-3) Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa péjọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nínú àwọn ìpàdé Kristẹni. Ó sì ṣe pàtàkì gidigidi pé kí wọ́n máa gbé àwọn ojúlówó ìlànà gíga tí ń bẹ nínú ìsìn mímọ́ lárugẹ bí wọ́n ṣe ń fi ìdùnnú ṣàjọpín oúnjẹ yẹn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

24. Irú ìwà wo làwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ń hù?

24 Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn ìlérí Jèhófà, ǹjẹ́ kí wọ́n máa bá a lọ láti yàgò fún gbogbo onírúurú àgàbàgebè. Bó ṣe jẹ́ pé “ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù,” ń fún wọn lókun, ǹjẹ́ kí wọ́n máa bá a lọ láti gbádùn ààbò nípa tẹ̀mí lórí “àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 9 Jèhófà ṣètò pé kí àwọn tó bá wọ gbèsè lára àwọn èèyàn rẹ̀ ta ara wọn sí oko ẹrú, ìyẹn ni pé kí wọ́n fi ara wọn háyà gẹ́gẹ́ bíi lébìrà, kí wọ́n fi lè san gbèsè wọn. (Léfítíkù 25:39-43) Àmọ́ Òfin náà sọ pé inúure ni kí wọ́n máa fi bá ẹrú lò. Èyí tí wọ́n bá ṣe ṣúkaṣùka nínú wọn ní láti dòmìnira.—Ẹ́kísódù 21:2, 3, 26, 27; Diutarónómì 15:12-15.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 278]

Àwọn Júù gbààwẹ̀ wọ́n sì tẹrí ba nínú ìrònúpìwàdà arúmọjẹ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn kò yí àwọn ìṣe wọn padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 283]

Kí àwọn tágbára wọn bá gbé e pèsè ilé, aṣọ, tàbí oúnjẹ fún àwọn aláìní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 286]

Bí Júdà bá ronú pìwà dà, yóò tún àwọn ìlú rẹ̀ tó ti pa run kọ́ padà