Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ Láú
Orí Kẹjọ
Ìsìn Èké—Ìran Fi Hàn Pé Yóò Lọ Láú
1, 2. (a) Lójú àwọn kan, kí ni ìdí tó fi dà bíi pé kò lè ṣẹlẹ̀ pé ìsìn ayé máa dojú dé pii láìpẹ́? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Aísáyà orí kẹtàdínláàádọ́ta máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú? (d) Kí ni ìdí tí pípe gbogbo ìsìn èké àgbáyé ní “Bábílónì Ńlá” fi bá a mu bẹ́ẹ̀?
“ÌSÌN Tún Ti Gbòde.” Ìkéde tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times Magazine gbé jáde nígbà kan nìyẹn. Àpilẹ̀kọ yẹn fi hàn pé ó jọ pé ìsìn ṣì gba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an ni. Ìyẹn ni kò fi ní tètè ṣeé gbà gbọ́ pé ìsìn máa tó dojú dé pii kárí ayé láìpẹ́. Àmọ́, Aísáyà orí kẹtàdínláàádọ́ta fi hàn pé ibi tí ọ̀rọ̀ ìsìn máa já sí nìyẹn.
2 Ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n, nínú ìwé Ìṣípayá, a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 47:8, pé ó ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Níbẹ̀, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ òpin ètò àjọ kan tó ń ṣe bí aṣẹ́wó, ó pè é ní “Bábílónì Ńlá,” èyí tí í ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 16:19) Pípe àwọn ìsìn èké ayé yìí ní “Bábílónì” bá a mu gan-an ni, nítorí pé ìlú Bábílónì àtijọ́ ni ìsìn èké ti pilẹ̀. Ibẹ̀ ló sì ti tàn lọ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìsìn ayé pátá, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù, ló ń fi àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó pilẹ̀ ní Bábílónì kọ́ni, àwọn bí àìleèkú ọkàn, iná ọ̀run àpáàdì, àti sísin ọlọ́run mẹ́talọ́kan. * Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá lani lóye nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ìsìn?
Wọ́n Bá Bábílónì Kanlẹ̀
3. Ṣàpèjúwe bí Agbára Ayé Bábílónì ṣe tóbi tó.
3 Gbọ́ bí ìkéde àtọ̀runwá yìí ṣe wí ná, ó ní: “Sọ̀ kalẹ̀, kí o sì jókòó sínú ekuru, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì. Jókòó sílẹ̀ níbi tí ìtẹ́ kò sí, ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà. Nítorí pé ìwọ kì yóò tún ní ìrírí kí àwọn ènìyàn máa pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti ajíṣefínní.” (Aísáyà 47:1) Ọ̀pọ̀ ọdún ni Bábílónì ti fi wà ní ipò agbára ayé tó ń ṣàkóso. “Ìṣelóge àwọn ìjọba” ló jẹ́ látìgbà pípẹ́ wá, ìyẹn ibi tí ìgbòkègbodò ìsìn, ti ìṣòwò, àti ti àwọn ológun ti ń lọ ní pẹrẹu. (Aísáyà 13:19) Lásìkò tí ilẹ̀ ọba Bábílónì gbòòrò jù lọ, ìhà gúúsù rẹ̀ nasẹ̀ dé iyànníyàn ààlà Íjíbítì. Bí ó sì ṣe ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run pàápàá ò tilẹ̀ lè dá ìṣẹ́gun tó ń ṣẹ́gun lọ dúró rárá ni! Ìyẹn ló fi wá ka ara rẹ̀ sí “wúńdíá ọmọbìnrin,” ẹni tí ará ilẹ̀ òkèèrè kankan kò ní gbógun ká mọ́lé láé. *
4. Kí ni yóò dé bá Bábílónì?
4 Àmọ́ o, wọ́n máa tó yẹ àga mọ́ “wúńdíá” onírera yìí nídìí nípò agbára ayé tí kò ní alátakò tó wà, yóò sì tẹ́ débi pé wọ́n á ní kó “jókòó sínú ekuru.” (Aísáyà 26:5) Wọn kò ní kà á sí “ẹlẹgẹ́ àti ajíṣefínní,” bí ọbabìnrin tí wọ́n ń kẹ́ mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ pé: “Mú ọlọ ọlọ́wọ́, kí o sì lọ ìyẹ̀fun. Ṣí ìbòjú rẹ. Bọ́ ibi títú yagba lára aṣọ kúrò. Káṣọ kúrò ní ẹsẹ̀. Sọdá àwọn odò.” (Aísáyà 47:2) Bábílónì fúnra rẹ̀, tó kó gbogbo orílẹ̀-èdè Júdà lẹ́rú tẹ́lẹ̀ rí, yóò wá dẹni tí wọ́n ń lò ní ìlò ẹrú wàyí! Àwọn ará Mídíà òun Páṣíà tó yẹ àga ipò agbára rẹ̀ mọ́ ọn nídìí yóò máa fi tipátipá mú un ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó.
5. (a) Báwo ni wọn yóò ṣe gba ‘ìbòjú àti aṣọ títú yagba’ lára Bábílónì? (b) Kí ni àṣẹ pé kí ó “sọdá àwọn odò” lè túmọ̀ sí?
5 Wọn yóò gba ‘ìbòjú àti aṣọ títú yagba’ Bábílónì lára rẹ̀, yóò pàdánù gbogbo ọláńlá àti iyì rẹ̀ àtẹ̀yìnwá pátá. Ni àwọn akóniṣiṣẹ́ tí wọ́n yàn lé e lórí yóò bá pàṣẹ fún un pé, “Sọdá àwọn odò.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n á máa kó àwọn kan lára àwọn ará Bábílónì ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kiri. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì tún lè túmọ̀ sí pé bíi fífà bíi wíwọ́ ní wọn yóò fi mú àwọn kan sọdá àwọn odò bí wọ́n ṣe ń kó wọn lọ sígbèkùn. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Bábílónì kò ní rin ìrìn àjò ẹ̀yẹ tí ọbabìnrin máa ń rìn, tí wọ́n á fi àga àgbéléjìká tàbí kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé sọdá odò, mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò dà bí ẹrúbìnrin tó jẹ́ pé ó ní láti pa ìtìjú obìnrin tì ni, kí ó sì ká aṣọ rẹ̀ sókè kúrò ní ẹsẹ̀ kí ó lè wọ́dò kọjá. Áà, ó mà kúkú tẹ́ o!
6. (a) Ọ̀nà wo ni ìhòòhò Bábílónì yóò gbà tú síta? (b) Báwo ni Ọlọ́run kò ṣe ní “ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Jèhófà tún gbẹ́nu lé ẹ̀sín tó ń fi í ṣe, ó ní: “Ó yẹ kí o tú ìhòòhò rẹ síta. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó yẹ kí a rí ẹ̀gàn rẹ. Èmi yóò gbẹ̀san, èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí.” (Aísáyà 47:3) * Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ yóò bá Bábílónì dandan ni. Àṣírí ìwà ibi àti ìwà ìkà tí ó ń hù sí àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò tú. Kò mà sí ọgbọ́n tí ọmọ aráyé lè ta kí ẹ̀san Ọlọ́run máà ké o!
7. (a) Báwo ni ìròyìn ìṣubú Bábílónì yóò ṣe rí lára àwọn Júù tó wà nígbèkùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà tún àwọn èèyàn rẹ̀ rà padà?
7 Inú àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò dùn gan-an ni nígbà tí Aísáyà 47:4) Lábẹ́ Òfin Mósè, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ta ara rẹ̀ sóko ẹrú láti fi lè san gbèsè tí ó jẹ, olùtúnnirà kan (tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀) lè rà á padà kúrò lóko ẹrú. (Léfítíkù 25:47-54) Nígbà tí àwọn Júù sì ti máa dẹni tí a tà sóko ẹrú Bábílónì, yóò gba pé kí ẹnì kan tún wọn rà tàbí kó tú wọn sílẹ̀. Bí ilẹ̀ kan bá ṣẹ́gun ilẹ̀ kejì, ìyẹn kò ṣe ẹrú lóore kankan, nítorí ó kàn mú kó ti abẹ́ ọ̀gá kan bọ́ sábẹ́ òmíràn ni. Àmọ́, Jèhófà yóò mú kí Kírúsì Ọba aṣẹ́gun dá àwọn Júù nídè kúrò lóko ẹrú. Jèhófà yóò wá fún Kírúsì ní Íjíbítì, Etiópíà, àti Sébà gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà” dípò àwọn Júù. (Aísáyà 43:3) Òun ló fi bá a mu gan-an bí wọ́n ṣe sọ pé “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” ni Olùtúnniràpadà Ísírẹ́lì. Agbo ọmọ ogun Bábílónì tó dà bíi pé ó lágbára gidigidi kò já mọ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògìdìgbó àwọn áńgẹ́lì Jèhófà tí a kò lè fojú rí.
Bábílónì alágbára bá fi máa ṣubú nítorí pé láti àádọ́rin ọdún sẹ́yìn ló ti mú wọn nígbèkùn. Wọn yóò ké rara pé: “Ẹnì kan wà tí ń tún wa rà. Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Ẹ̀san Ìwà Ìkà
8. Ọ̀nà wo ni Bábílónì yóò gbà “wá sínú òkùnkùn”?
8 Jèhófà tún gbẹ́nu lé bí ó ṣe ń bẹnu àtẹ́ lu Bábílónì, ó ní: “Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kí o sì wá sínú òkùnkùn, ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà; nítorí pé ìwọ kì yóò tún ní ìrírí kí àwọn ènìyàn máa pè ọ́ ní Ìyálóde Àwọn Ìjọba.” (Aísáyà 47:5) Òkùnkùn àti ìpòkúdu nìkan ṣoṣo ló kù fún Bábílónì. Kò ní jẹ gàba gẹ́gẹ́ bí ìkà ọbabìnrin lé àwọn ìjọba yòókù mọ́.—Aísáyà 14:4.
9. Kí ni ìdí tí Jèhófà fi bínú sí àwọn Júù?
9 Kí ni ìdí rẹ̀ tí Ọlọ́run tilẹ̀ fi gbà kí Bábílónì pa àwọn èèyàn òun lára lákọ̀ọ́kọ́ ná? Jèhófà ṣàlàyé pé: “Ìkannú mi ru sí àwọn ènìyàn mi. Mo sọ ogún mi di aláìmọ́, mo sì tẹ̀ síwájú Aísáyà 47:6a) Ó tọ́ bí Jèhófà ṣe bínú sí àwọn Júù. Ó ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé bí wọ́n bá rú Òfin òun, òun yóò lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ yẹn o. (Diutarónómì 28:64) Nígbà tí wọ́n tọrùn bọ ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe, Jèhófà fi ìfẹ́ rán àwọn wòlíì láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti padà sínú ìsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n “wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Ni Ọlọ́run bá yọ̀ǹda kí Bábílónì sọ Júdà ogún rẹ̀ di aláìmọ́ nígbà tí Bábílónì gbógun ja ilẹ̀ yẹn tó sì sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ Rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.—Sáàmù 79:1; Ìsíkíẹ́lì 24:21.
láti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.” (10, 11. Kí ni ìdí tí Jèhófà fi bínú sí Bábílónì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà pé kí ó ṣẹ́gun àwọn èèyàn òun?
10 Nítorí náà, nígbà tí Bábílónì kó àwọn Júù nígbèkùn, ǹjẹ́ kì í ṣe pé ó kúkú ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni? Ó tì o, nítorí Ọlọ́run sọ pé: “Ìwọ kò fi àánú kankan hàn sí wọn. O mú kí àjàgà rẹ wúwo gidigidi lọ́rùn àgbàlagbà. Ìwọ sì ń wí pé: ‘Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò máa jẹ́ Ìyálóde, àní títí láé.’ Ìwọ kò fi nǹkan wọ̀nyí sínú ọkàn-àyà rẹ; ìwọ kò rántí paríparí òpin ọ̀ràn náà.” (Aísáyà 47:6b, 7) Ọlọ́run kò fún Bábílónì láṣẹ láti hùwà ìkà tó burú jáì kí ó má sì fi ojú rere hàn “àní fún àwọn arúgbó.” (Ìdárò 4:16; 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni kò ní kí wọ́n máa fi àwọn Júù ṣẹ̀sín láti lè fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.—Sáàmù 137:3.
11 Bábílónì kò fi í sọ́kàn rárá pé ìgbà díẹ̀ ni àkóso tóun ní lórí àwọn Júù yóò mọ. Ó kọ etí ikún sí àwọn ìkìlọ̀ tí Aísáyà ṣe pé, bó bá yá, Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ó ń fẹlá bíi pé títí gbére ni yóò máa ṣàkóso àwọn Júù lọ, pé títí láé ni yóò máa jẹ́ ìyálóde lọ lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó di ìgbèríko rẹ̀. Àní ó kọ etí dídi sí ohun tí wọ́n ti sọ pé “paríparí òpin” yóò dé bá àkóso aninilára rẹ̀!
Jèhófà Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣubú Bábílónì
12. Èé ṣe tí wọ́n fi pe Bábílónì ní “jayéjayé obìnrin”?
12 Jèhófà kéde pé: “Wàyí o, gbọ́ èyí, ìwọ jayéjayé obìnrin, tí ó jókòó nínú ààbò, tí ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn. Èmi kì yóò jókòó gẹ́gẹ́ bí opó, èmi kì yóò sì mọ àdánù àwọn ọmọ.’” (Aísáyà 47:8) Àwọn èèyàn mọ Bábílónì mọ́ ayé jíjẹ dáadáa. Hẹrodótù, òpìtàn ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, sọ nípa “àṣà tó tini lójú jù lọ” nínú àṣà àwọn ará Bábílónì, ìyẹn ni pé, dandan ni kí gbogbo obìnrin ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó láti fi júbà abo òrìṣà wọn, òrìṣà ìfẹ́. Kọ́tíọ́sì, òpìtàn ìgbàanì kan, tún sọ pé: “Kò sí ìwàkiwà tó burú jáì tó ti ìlú yẹn; kò sí ètò àfẹ̀sọ̀ṣe láti fi mọ̀ọ́mọ̀ kẹ́ èèyàn bà jẹ́ tó fani mọ́ra, tó sì lè tètè sọni di wọ̀bìà, tó ti ìlú yẹn.”
13. Báwo ni ayé jíjẹ tó ti kó sí Bábílónì lórí yóò ṣe tètè fa ìṣubú rẹ̀?
13 Ayé jíjẹ tó ti kó sí Bábílónì lórí ni yóò tètè fa ìṣubú rẹ̀. Ní alẹ́ ìkẹyìn tí ìṣubú rẹ̀ yóò dé, àsè ni ọba àti àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn rẹ̀ yóò máa jẹ, wọn yóò sì mutí yó bìnàkò. Bí wọn ò ṣe ní kọbi ara sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà tó ṣígun wá bá ìlú wọn nìyẹn. (Dáníẹ́lì 5:1-4) Bábílónì “jókòó nínú ààbò,” ó ti rò ó pé odi àti yàrà òun tó dà bíi pé mìmì kan ò lè mì kò lè jẹ́ kí ogun ọ̀tá rí òun gbé ṣe. Ńṣe ló ń bá ara rẹ̀ sọ ọ́ pé ‘kò sí ẹlòmíràn’ tó lè gbapò àjùlọ tí òun wà mọ́ òun lọ́wọ́ láéláé. Kò rò ó tì rí pé òun lè di “opó,” ní ti pé kí ó pàdánù aláyélúwà ọba rẹ̀ àti “àwọn ọmọ” rẹ̀, ìyẹn àwọn aráàlú rẹ̀. Àmọ́ o, kò sí odi kankan tó lè dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ apá ẹ̀san Jèhófà Ọlọ́run! Jèhófà ṣì máa sọ báyìí pé: “Bí Bábílónì tilẹ̀ gòkè re ọ̀run, àní bí ó tilẹ̀ sọ ibi gíga okun rẹ̀ di aláìṣeédé, láti ọ̀dọ̀ mi ni àwọn afiniṣèjẹ yóò ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀.”—Jeremáyà 51:53.
14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Bábílónì yóò gbà rí “àdánù ọmọ àti ìgbà opó”?
Aísáyà 47:9) Dájúdájú, òjijì ni agbára àjùlọ Bábílónì, tó mú kó jẹ́ agbára ayé, yóò dópin. Ní ilẹ̀ ìhà Ìlà-Oòrùn ayé àtijọ́, àjálù tó burú jù lọ fún obìnrin ni pé kí ó di opó kí ó sì tún ṣòfò ọmọ. A ò mọ iye “ọmọ” tí Bábílónì pàdánù lálẹ́ ọjọ́ tó ṣubú. * Ṣùgbọ́n ìlú yẹn yóò sáà padà dá páropáro ni lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Jeremáyà 51:29) Yóò tún di opó ní ti pé wọn yóò yẹ àga mọ́ àwọn ọba rẹ̀ nídìí.
14 Ibo ni ọ̀ràn Bábílónì yóò wá yọrí sí? Jèhófà ń bọ́rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Ṣùgbọ́n nǹkan méjèèjì wọ̀nyí yóò dé bá ọ lójijì, ní ọjọ́ kan: àdánù àwọn ọmọ àti ìgbà opó. Ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n wọn ni wọn yóò dé bá ọ, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́ rẹ, nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá èèdì rẹ—lọ́nà tí ó peléke.” (15. Láfikún sí ìwà ìkà tí Bábílónì hù sí àwọn Júù, ìdí mìíràn wo tún ni Jèhófà fi bínú sí Bábílónì?
15 Ṣùgbọ́n o, tìtorí pé Bábílónì ṣe àwọn Júù ṣúkaṣùka nìkan kọ́ ló fa ìbínú Jèhófà. “Ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́” rẹ̀ tún bí i nínú pẹ̀lú. Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ka ìbẹ́mìílò léèwọ̀; ṣùgbọ́n ńṣe ni Bábílónì tara bọ ẹgbẹ́ adáhunṣe lójú méjèèjì. (Diutarónómì 18:10-12; Ìsíkíẹ́lì 21:21) Ìwé náà Social Life Among the Assyrians and Babylonians sọ pé ‘ìfòyà ẹgbàágbèje iwin tí àwọn ará Bábílónì gbà pé ó yí àwọn ká kì í tán lára wọn nígbàkigbà lọ́jọ́ ayé wọn.’
Gbígbẹ́kẹ̀lé Ìwà Búburú
16, 17. (a) Báwo ni Bábílónì ṣe ‘gbẹ́kẹ̀ lé ìwà búburú rẹ̀’? (b) Kí ni ìdí tí òpin Bábílónì kò fi ṣeé yẹ̀ sílẹ̀?
16 Ṣé àwọn woṣẹ́woṣẹ́ Bábílónì yóò lè kó o yọ? Jèhófà dáhùn pé: “Ìwọ sì ń bá a nìṣó ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìwà búburú rẹ. Aísáyà 47:10) Bábílónì rò pé ọgbọ́n ayé àti ti ìsìn tí òun ní, agbára ogun jíjà òun, àti ọgbọ́n ìkà tí òun gbọ́n kò ní jẹ́ kí ipò agbára ayé bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́ rárá. Ó gbà pé ẹnikẹ́ni ò lè “rí” òun, ìyẹn ni pé, ẹnikẹ́ni ò lè pe òun wá jẹ́jọ́ ìwà ìkà tí òun ń hù. Kò tilẹ̀ sí ẹni tí ó rò pé ó lè bá òun figẹ̀ wọngẹ̀ rárá ni. Ńṣe ló ń sọ fún ara rẹ̀ pé: “Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn.”
Ìwọ ti wí pé: ‘Kò sí ẹnì kankan tí ó rí mi.’ Ọgbọ́n rẹ àti ìmọ̀ rẹ—èyí ni ó ti mú ọ lọ; o sì ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ pé: ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn.’” (17 Àmọ́, Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ mìíràn kìlọ̀ pé: “Ẹnì kankan ha lè fi ara pa mọ́ sí ibi ìlùmọ́ kí èmi fúnra mi má sì rí i?” (Jeremáyà 23:24; Hébérù 4:13) Nípa bẹ́ẹ̀ Jèhófà sọ pé: “Ìyọnu àjálù yóò sì dé bá ọ; ìwọ kì yóò mọ ìtujú kankan sí i. Ìwọ yóò sì ko àgbákò; ìwọ kì yóò sì lè yẹ̀ ẹ́. Ìparun tí ìwọ kò mọ̀ rí yóò sì dé bá ọ lójijì.” (Aísáyà 47:11) Àti àwọn òrìṣà Bábílónì o, àti oògùn “ìtujú” àwọn adáhunṣe rẹ̀ o, kò sí èyí tí yóò lè mú kí àjálù tí ń bọ̀ yẹ̀ kúrò lórí rẹ̀, àní irú àjálù yẹn kò tilẹ̀ bá a rí pàápàá!
Àwọn Agbani-Nímọ̀ràn Bábílónì Kùnà
18, 19. Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí Bábílónì ní nínú àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ yóò ṣe já sí pàbó?
18 Jèhófà kúkú wá fi ṣe ògidì ẹ̀fẹ̀, ó pàṣẹ pé: “Dúró jẹ́ẹ́, nísinsìnyí, ti ìwọ ti èèdì rẹ àti ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́ rẹ, nínú èyí tí o ti ń ṣe làálàá láti ìgbà èwe rẹ wá; bóyá ìwọ yóò lè jàǹfààní, bóyá ìwọ yóò lè fi ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì kọlu àwọn ènìyàn.” (Aísáyà 47:12) Ó pàṣẹ pé kí Bábílónì “dúró jẹ́ẹ́,” tàbí pé oògùn tó gbẹ́kẹ̀ lé ni kó ṣáà máa ṣe nìṣó o. Láti ìgbà “èwe” rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè ló kúkú ti ń ṣe làálàá lórí ìdàgbàsókè onírúurú iṣẹ́ awo.
19 Àmọ́ Jèhófà wá fi í ṣẹlẹ́yà pé: “Àárẹ̀ ti mú ọ pẹ̀lú ògìdìgbó àwọn tí ń gbà ọ́ nímọ̀ràn. Kí wọ́n dìde dúró, nísinsìnyí, Aísáyà 47:13) * Ìjákulẹ̀ yóò bá Bábílónì bí àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ yóò ṣe kùnà pátápátá. Òótọ́ ni pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ìrírí lẹ́nu ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmà ni àwọn awòràwọ̀ Bábílónì yóò ti ní, tí wọ́n sì ń lò. Ṣùgbọ́n bí àwọn awòràwọ̀ rẹ̀ yóò ṣe kùnà pátápátá lálẹ́ ọjọ́ tí yóò ṣubú ni yóò táṣìírí iṣẹ́ wíwò pé asán ni.—Dáníẹ́lì 5:7, 8.
kí wọ́n sì gbà ọ́ là, àwọn tí ń jọ́sìn ọ̀run, àwọn tí ń wo ìràwọ̀, àwọn tí ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun nípa àwọn ohun tí yóò dé bá ọ.” (20. Kí ni yóò bá àwọn agbani-nímọ̀ràn Bábílónì?
20 Jèhófà parí apá àsọtẹ́lẹ̀ yìí báyìí pé: “Wò ó! Wọ́n wá dà Aísáyà 47:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni o, iná máa mọ́ àwọn èké agbani-nímọ̀ràn wọ̀nyí láìpẹ́. Kì í ṣe iná atura tí èèyàn lè yáná rẹ̀ o, àgbáàràgbá iná apanirun ni, tí yóò fi àwọn èké agbani-nímọ̀ràn wọ̀nyí hàn pé àgékù pòròpórò tí kò wúlò ni wọ́n. Abájọ tí àwọn agbani-nímọ̀ràn Bábílónì yóò ṣe sá kìjokìjo! Bí ohun ìkẹyìn tí Bábílónì gbójú lé bá ti pòórá, kò ní sí ẹni tí yóò gbà á mọ́. Ohun tí ì bá fojú Jerúsálẹ́mù rí gan-an ni yóò sì padà wá sórí òun fúnra rẹ̀.—Jeremáyà 11:12.
bí àgékù pòròpórò. Ṣe ni iná yóò sun wọ́n kanlẹ̀. Wọn kì yóò dá ọkàn ara wọn nídè lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná náà. Kì yóò sí ìpọ́nyòò èédú fún àwọn ènìyàn láti yáná, kì yóò sí ìmọ́lẹ̀ iná láti jókòó sí iwájú rẹ̀. Báyìí ni wọn yóò dà fún ọ dájúdájú, àwọn tí o ti bá ṣe làálàá gẹ́gẹ́ bí atujú rẹ láti ìgbà èwe rẹ wá. Wọn yóò rìn gbéregbère ní ti tòótọ́, olúkúlùkù sí ẹkùn ilẹ̀ tirẹ̀. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà ọ́ là.” (21. Báwo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ṣẹ lóòótọ́, ìgbà wo ló sì ṣẹ?
21 Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀rọ̀ onímìísí yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ. Kírúsì kó agbo ọmọ ogun àwọn ará Mídíà òun Páṣíà wá, wọ́n gba ìlú yẹn, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì Ọba tó fi ìlú yẹn ṣe ibùjókòó. (Dáníẹ́lì 5:1-4, 30) Òru ọjọ́ kan ni wọ́n yẹ àga ipò àkóso ayé mọ́ Bábílónì nídìí. Bí agbára àjùlọ ìran Sẹ́máítì tó ti ń bá a bọ̀ látọdúnmọ́dún ṣe dópin nìyẹn tí àkóso ayé wá bọ́ sọ́wọ́ ìran Aryan. Ìgbà yẹn ni Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ sí jó rẹ̀yìn títí di ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, ìlú yẹn ti di èkìdá “ìtòjọpelemọ òkúta.” (Jeremáyà 51:37) Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa rẹ̀ wá ṣẹ porogodo.
Bábílónì Òde Òní
22. Ẹ̀kọ́ wo ni ìṣubú Bábílónì kọ́ wa nípa ìgbéraga?
22 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní àwọn ohun púpọ̀ nínú tí a ní láti ronú jinlẹ̀ lé lórí gidigidi. Ní pàtàkì, ó tẹnu mọ́ ewu tí Òwe 16:18) Nígbà mìíràn, ìgbéraga máa ń darí ara wa aláìpé yìí, bẹ́ẹ̀, béèyàn bá ń “wú fùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,” ó lè múni “ṣubú sínú ẹ̀gàn àti ìdẹkùn Èṣù.” (1 Tímótì 3:6, 7) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí á kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jákọ́bù tó sọ pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà, yóò sì gbé yín ga.”—Jákọ́bù 4:10.
ń bẹ nínú ìgbéraga àti ìrera. Ìṣubú Bábílónì agbéraga jẹ́ àpèjúwe òwe inú Bíbélì náà pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (23. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mú ká ní?
23 Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tún mú ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà, ẹni tó lágbára ju gbogbo alátakò rẹ̀ lọ. (Sáàmù 24:8; 34:7; 50:15; 91:14, 15) Ìránnilétí tó ń tuni nínú lèyí sì jẹ́ lásìkò tí nǹkan ò fararọ yìí. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà máa ń jẹ́ ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa láti wà láìlẹ́bi lójú rẹ̀, nítorí a mọ̀ pé “ọjọ́ ọ̀la ẹni [tí kò lẹ́bi] yóò kún fún àlàáfíà.” (Sáàmù 37:37, 38) Jèhófà ló bọ́gbọ́n mu pé ká yíjú sí nígbà gbogbo bí Sátánì bá ti dojú “àwọn ètekéte” rẹ̀ kọ wá, kí á má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé mímọ̀ ọ́n ṣe ti ara wa rárá.—Éfésù 6:10-13.
24, 25. (a) Kí ni ìdí tí ìwòràwọ̀ kò fi bọ́gbọ́n mu, síbẹ̀ kí ni ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wò ó? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí àwọn Kristẹni fi ń yàgò fún èèwọ̀ asán?
24 A ti gba ìkìlọ̀ ní pàtàkì pé ká má ṣe lọ́wọ́ nínú ìṣe ẹ̀mí òkùnkùn kankan, pàápàá ìràwọ̀ wíwò. (Gálátíà 5:20, 21) Nígbà tí Bábílónì ṣubú, àwọn èèyàn kò ṣíwọ́ ìràwọ̀ wíwò. Ẹ sì wá wò ó o, ìwé tó ń jẹ́ Great Cities of the Ancient World (Àwọn Ìlú Ńláńlá Ayé Àtijọ́), sọ pé àwọn àgbájọ ìràwọ̀ tí àwọn ará Bábílónì yàwòrán rẹ̀ kalẹ̀ ti “ṣípò padà” kúrò níbi tí wọ́n wà láyé àtijọ́, “ó sì ti sọ gbogbo ohun tó jẹ mọ́ [ìwòràwọ̀] di ohun àìníláárí pátápátá.” Síbẹ̀síbẹ̀, ìwòràwọ̀ ṣì ń bá a lọ, ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ló sì ní àwọn abala ojú ìwé tí wọ́n ti ń gbé ìràwọ̀ wíwò jáde fún àwọn òǹkàwé wọn láti kà láìsí pé wọ́n ń ṣe wàhálà kankan.
25 Kí ló tilẹ̀ ń mú kí àwọn èèyàn, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀làjú, lọ máa yẹ ìràwọ̀ wò tàbí kí wọ́n máa gba àwọn èèwọ̀ asán, tí kò sì bọ́gbọ́n mu gbọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ó jọ pé àwọn èèyàn kò ní yéé gba èèwọ̀ asán gbọ́ láyé yìí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣì ń bẹ̀rù ara wọn tí wọn ò sì mọ̀nà tí wọ́n lè gbé ọ̀rọ̀ ọjọ́ ọ̀la gbà.” Béèyàn bá ń bẹ̀rù tí kò sì mọ̀nà tó lè gbé ọ̀rọ̀ ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ gbà, ìyẹn lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sì gba èèwọ̀ asán gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni ní láti yàgò pátápátá fún àwọn èèwọ̀ asán. Wọn kì í bẹ̀rù èèyàn, ṣebí Jèhófà ni wọ́n sáà gbára lé. (Sáàmù 6:4-10) Wọn kò sì ṣaláìmọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbé ọ̀rọ̀ ọjọ́ ọ̀la gbà; wọ́n mọ àwọn ète tí Jèhófà ṣí payá, ó sì dá wọn lójú pé, “fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró.” (Sáàmù 33:11) Gbígbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìmọ̀ràn Jèhófà mu máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tó wà títí gbére jẹ́ tiwa.
26. Báwo ni “èrò àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn” ṣe já sí “ìmúlẹ̀mófo”?
26 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn kan gbìyànjú láti lo àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ jẹ́ ti “sáyẹ́ǹsì” láti fi mọ ọjọ́ ọ̀la. Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan tilẹ̀ wà tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, wọ́n ní ó jẹ́ “ẹ̀ka tó ń lo òye bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti fi mọ ohun tó ṣeé ṣe kí ó wáyé lọ́jọ́ ọ̀la.” Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1972 lọ́hùn-ún ni àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn oníṣòwò kan tí a mọ̀ sí Club of Rome sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá fi máa di ọdún 1992, gbogbo góòlù, mẹ́kúrì, irin zinc, àti epo rọ̀bì tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ayé yìí pátá la ó ti wà tán. Lóòótọ́ o, àwọn gbankọgbì ìṣòro ló ti ń bá ayé fínra láti ọdún 1972 wá, síbẹ̀, irọ́ pátápátá ni àsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí já sí. Góòlù, mẹ́kúrí, irin zinc, àti epo rọ̀bì ṣì wà rẹ́kẹrẹ̀kẹ lábẹ́ ilẹ̀ káàkiri. Ní tòdodo, aráyé ti ṣòpò gan-an ni nídìí akitiyan láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n ìgbà gbogbo ni àwọn ìméfò rẹ̀ kì í ṣeé gbára lé. Ní tòótọ́, “èrò àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn jẹ́ ìmúlẹ̀mófo”!—1 Kọ́ríńtì 3:20.
Òpin Bábílónì Ńlá Dé Tán
27. Ìgbà wo ni Bábílónì Ńlá ṣubú lọ́nà kan tó dà bíi ti Bábílónì ti ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀nà wo ló sì gbà ṣubú?
27 Àwọn ẹ̀sìn òde òní ló ń tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ Bábílónì àtijọ́ kálẹ̀. Ìyẹn ló fi bá a mu gẹ́ẹ́ pé wọ́n pe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ní Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá 17:5) Àgbájọ àwọn ẹ̀sìn àgbáyé yẹn ti ṣubú lọ́nà kan tó bá ṣíṣubú tí Bábílónì àtijọ́ ṣubú lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa dọ́gba. (Ìṣípayá 14:8; 18:2) Lọ́dún 1919, àwọn àṣẹ́kù àwọn arákùnrin Kristi kúrò ní ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, wọ́n sì já ara wọn gbà lọ́wọ́ ipa tí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù tó jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú Bábílónì Ńlá ń ní lórí wọn. Láti ìgbà yẹn wá ni Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ti fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó ti ń jẹ gàba lé lórí tẹ́lẹ̀ rí.
28. Báwo ni Bábílónì Ńlá ṣe fọ́nnu, ṣùgbọ́n kí ló ń dúró dè é?
28 Ṣùgbọ́n, kékeré ni ìṣubú yẹn ṣì jẹ́ sí ìparun tí yóò bá ìsìn èké nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ẹ sì wò o, ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìṣípayá sọ nípa ìparun Bábílónì Ńlá mú wa rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 47:8, 9. Bíi Bábílónì àtijọ́ ni Bábílónì Ńlá òde òní ṣe sọ̀rọ̀ tó ní: “Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í sì í ṣe opó, èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.” Ṣùgbọ́n ńṣe ni “àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò . . . dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, a ó sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.” Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà orí kẹtàdínláàádọ́ta jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn tó ṣì ń ní àjọṣe pẹ̀lú ìsìn èké. Bí wọn ò bá fẹ́ pín nínú ìparun rẹ̀, kí wọ́n kọbi ara sí àṣẹ tí Bíbélì pa ni o, pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀”!—Ìṣípayá 18:4, 7, 8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 2 Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa bí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké ṣe pilẹ̀ tó sì ń gbilẹ̀, wo ìwé Mankind’s Search for God, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
^ ìpínrọ̀ 3 Lédè Hébérù, àkànlò èdè ni “wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì” jẹ́, Bábílónì tàbí àwọn olùgbé Bábílónì ni wọ́n sì ń lò ó fún. “Wúńdíá” sì ni nítorí kò tíì sí aṣẹ́gun kankan tó fi í ṣèjẹ látìgbà tó ti di agbára ayé.
^ ìpínrọ̀ 6 Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí” jẹ́ “àpólà ọ̀rọ̀ tó ṣòroó” túmọ̀ “gan-an ni.” Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi ọ̀rọ̀ náà, “ṣojú àánú,” kún un láti fi lè jẹ́ kó hàn pé kò ní sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti ti ibòmíràn wá láti wá gba Bábílónì sílẹ̀. Ìtumọ̀ Bíbélì kan, tí àwọn àjọ Jewish Publication Society ṣe, túmọ̀ àpólà ọ̀rọ̀ yìí báyìí: “Èmi . . . kì yóò gbà kí ẹnikẹ́ni bá a bẹ̀bẹ̀.”
^ ìpínrọ̀ 14 Ìwé Nabonidus and Belshazzar, tí Raymond Philip Dougherty kọ, sọ pé lóòótọ́ Àkọsílẹ̀ Ìtàn Nábónídọ́sì sọ pé ńṣe làwọn tó ṣígun wá sí Bábílónì kàn wọ̀lú “láìsí ìjà,” àmọ́ ọmọ Gíríìkì òpìtàn náà, Sẹ́nófọ̀n, fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí iye ẹ̀mí tó ṣòfò máà kéré.
^ ìpínrọ̀ 19 Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “àwọn tí ń jọ́sìn ọ̀run” ni àwọn kan túmọ̀ sí “àwọn tó pín ọ̀run sí onírúurú ọ̀nà.” Àṣà pípín ọ̀run sí onírúurú ẹ̀ka láti fi wòràwọ̀ ni èyí ń sọ o.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111]
A óò bá Bábílónì jayéjayé kanlẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]
Àwọn awòràwọ̀ Bábílónì kò ní lè sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣubú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 116]
Kàlẹ́ńdà ìwòràwọ̀ ti àwọn ará Bábílónì, ní ẹgbẹ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa
[[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]
Láìpẹ́, Bábílónì òde òní kò ní sí mọ́