Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí Ayé

Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí Ayé

Orí Kọkànlélógún

Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí Ayé

Aísáyà 60:1-22

1. Ìsọfúnni tó wúni lórí wo ló wà nínú Aísáyà orí ọgọ́ta?

Ọ̀NÀ tí a gba kọ Aísáyà orí ọgọ́ta jẹ́ ti àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó ń tani jí. Ìran kan tó ṣeni láàánú ló kọ́kọ́ hàn síni nínú àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ léraléra tẹ̀ lé e, títí tó fi wá parí sí ibi tó wúni lórí. Orí yìí ṣe àpèjúwe tó ṣe kedere nípa bí ìsìn tòótọ́ ṣe tún padà bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Jerúsálẹ́mù ayé àtijọ́ àti bí ìsìn tòótọ́ ṣe gbilẹ̀ kárí ayé lóde òní. Ẹ̀wẹ̀, ó tọ́ka sí àwọn ìbùkún ayérayé tí ń bẹ níwájú fún gbogbo àwọn tó ń fi ìdúró ṣinṣin jọ́sìn Ọlọ́run. Olúkúlùkù wa ló lè kópa nínú ìmúṣẹ ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó fani mọ́ra yìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fẹ̀sọ̀ yẹ̀ ẹ́ wò.

Ìmọ́lẹ̀ Tàn Nínú Òkùnkùn

2. Àṣẹ wo ni Jèhófà pa fún obìnrin tó dùbúlẹ̀ sínú òkùnkùn, kí sì nìdí tó fi ní láti ṣe ohun tó wí kánkán?

2 Obìnrin kan tó wà nípò ìbànújẹ́ ni Jèhófà bá sọ̀rọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ orí ìwé Aísáyà yìí. Ẹ̀rí fi hàn pé ṣe ni obìnrin yìí nà gbalaja sórí ilẹ̀yílẹ̀ nínú òkùnkùn. Lójijì, ìmọ́lẹ̀ wá tàn yàà sínú òkùnkùn yẹn bí Jèhófà ṣe gbẹnu Aísáyà pàṣẹ pé: “Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde, nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.” (Aísáyà 60:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, kí “obìnrin” yìí gbéra nílẹ̀ kó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ògo Ọlọ́run yọ ni o! Èé ṣe tó fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ kánkán? Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá a lọ pé: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ.” (Aísáyà 60:2) “Obìnrin” yìí ní láti “tan ìmọ́lẹ̀ jáde” dandan ni, fún àǹfààní àwọn tó ṣì ń táràrà nínú òkùnkùn ní àyíká rẹ̀. Kí ni ìyẹn yóò wá yọrí sí? Ó ní: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò . . . lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.” (Aísáyà 60:3) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tó bẹ̀rẹ̀ orí yìí, jẹ́ ká mọ kókó ohun tí àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ń bọ̀ wá ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ìyẹn ni pé, ìsìn tòótọ́ ní láti gbilẹ̀ kárí ayé dandan ni!

3. (a) Ta ni “obìnrin” yìí? (b) Kí nìdí tí “obìnrin” yìí fi dùbúlẹ̀ nínú òkùnkùn?

3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jèhófà ń sọ, síbẹ̀ ó sọ fún “obìnrin” yẹn pé ‘ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ti dé.’ Èyí ń jẹ́ kó túbọ̀ dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣẹ. Síónì, tàbí Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà ni “obìnrin” tí ibí yìí ń sọ. (Aísáyà 52:1, 2; 60:14) Ìlú náà dúró fún gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi kọ́kọ́ ṣẹ, ìdùbúlẹ̀ ni “obìnrin” yìí wà, nínú òkùnkùn, níbi tó ti wà láti ìgbà tí wọ́n ti pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àmọ́, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àṣẹ́kù olóòótọ́ lára àwọn Júù tó wà nígbèkùn padà lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì mú kí ìsìn mímọ́ tún bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà mú kí ìmọ́lẹ̀ tàn sórí “obìnrin” rẹ̀, ó sì mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti padà wálé di orísun ìlàlóye láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ti wà nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí.

Ìmúṣẹ Ńlá

4. Lórí ilẹ̀ ayé lónìí, àwọn wo ló ń ṣojú fún “obìnrin” yìí, àwọn wo sì ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí kàn bí a bá nasẹ̀ rẹ̀ síwájú sí i?

4 Kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ lára nìkan ló wù wá, ohun tó wù wá nínú rẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lórí ilẹ̀ ayé lónìí, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ló ń ṣojú fún “obìnrin” Jèhófà tó wà lọ́run yìí. (Gálátíà 6:16) Iye àwọn tó wà nínú orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí láti ìgbà tó ti wà láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di báyìí, jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì èèyàn tí a fi ẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn “tí a ti rà láti ilẹ̀ ayé wá,” tó ń retí láti bá Kristi jọba ní ọ̀run. (Ìṣípayá 14:1, 3) Àwọn tó wà láàyè lásìkò “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” nínú àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí ni Aísáyà orí ọgọ́ta ṣẹ sí lára lóde òní. (2 Tímótì 3:1) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì tún kan “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pẹ̀lú.—Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:11, 16.

5. Ìgbà wo ni àwọn tó ṣẹ́ kù láyé lára àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run nà gbalaja sílẹ̀ nínú òkùnkùn, ìgbà wo sì ni ìmọ́lẹ̀ Jèhófà tàn sí wọn lórí?

5 Fún àkókò kúkúrú kan ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ńṣe ni àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run nà gbalaja sílẹ̀ nínú òkùnkùn, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní fi máa parí, ipò tí ìwé Ìṣípayá lo àmì láti fi ṣàpèjúwe rẹ̀ ni wọ́n wà, ìyẹn ni pé òkú wọn wà “ní ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá títóbi náà, èyí tí a ń pè lọ́nà ìtumọ̀ ti ẹ̀mí ní Sódómù àti Íjíbítì.” (Ìṣípayá 11:8) Ṣùgbọ́n, lọ́dún 1919, Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sórí wọn. Ni àwọn náà bá gbéra nílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tan ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìbẹ̀rù.—Mátíù 5:14-16; 24:14.

6. Ìhà wo ní ayé lápapọ̀ kọ sí ìkéde pé Jésù ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí ọba, ṣùgbọ́n àwọn wo ni ìmọ́lẹ̀ Jèhófà fà mọ́ra?

6 Aráyé lápapọ̀ ṣe bí Sátánì tó jẹ́ olórí “àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí” ṣe darí wọn láti ṣe, wọ́n kọ etí dídi sí ìkéde tó sọ pé Jésù Kristi, tó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ayé,” ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí ọba. (Éfésù 6:12; Jòhánù 8:12; 2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Àmọ́ ṣá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ Jèhófà ti fà mọ́ra, títí kan “àwọn ọba” (ìyẹn àwọn tó di ẹni àmì òróró, ajogún Ìjọba ọ̀run) àti “àwọn orílẹ̀-èdè” (ìyẹn àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn).

Gbígbilẹ̀ Tí Ìsìn Tòótọ́ Ń Gbilẹ̀ Ń Fa Ìdùnnú Tó Kọyọyọ

7. Nǹkan ayọ̀ wo ni “obìnrin” yẹn rí?

7 Bí Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ àlàyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó mẹ́nu kàn nínú Aísáyà 60:3, ó tún pàṣẹ fún “obìnrin” yẹn pé: “Gbé ojú rẹ sókè yí ká, kí o sì wò!” Wíwò tí “obìnrin” yẹn máa wò yí ká báyìí, nǹkan ayọ̀ ló ń rí, àní àwọn ọmọ rẹ̀ ń bọ̀ wálé! Ó ní: “A ti kó gbogbo wọn jọpọ̀; wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ. Ibi jíjìnnàréré ni àwọn ọmọkùnrin rẹ ti ń bọ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ tí a óò tọ́jú ní ìhà rẹ.” (Aísáyà 60:4) Pípolongo Ìjọba Ọlọ́run káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1919, mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” tó jẹ́ ẹni àmì òróró tún dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run síwájú sí i. Lọ́nà báyìí, Jèhófà rí sí i pé àwọn tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí yóò bá Kristi jọba pé pérépéré.—Ìṣípayá 5:9, 10.

8. Kí ló ti mú ìdùnnú bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run láti ọdún 1919?

8 Ìbísí yìí mú ìdùnnú wá. “Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò wò, ìwọ yóò sì wá tàn yinrin dájúdájú, ọkàn-àyà rẹ yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, yóò sì gbòòrò, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọlà òkun yóò darí sí; àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Aísáyà 60:5) Kíkórè àwọn ẹni àmì òróró wọlé láàárín ọdún 1920 sí 1939 mú ayọ̀ ńlá bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Síbẹ̀ wọ́n tún ní ìdí mìíràn láti máa yọ̀. Ní pàtàkì láti àárín ọdún 1930 sí 1939 ni àwọn èèyàn tí wọ́n ti fìgbà kan rí wà lára “òkun” ọmọ aráyé tó yapa sí Ọlọ́run ti ń jáde wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, wọ́n wá ń jọ́sìn pa pọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run. (Aísáyà 57:20; Hágáì 2:7) Kì í ṣe pé olúkúlùkù àwọn tí a ń wí yìí wá ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó wù wọ́n o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n tọ “obìnrin” Ọlọ́run wá, wọ́n sì di ara agbo Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan. Ló wá di pé gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run wá ń kópa nínú mímú kí ìsìn tòótọ́ gbilẹ̀ sí i.

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ń Rọ́ Wá sí Jerúsálẹ́mù

9, 10. Àwọn wo ló ń rọ́ wá sí Jerúsálẹ́mù, irú ojú wo ni Jèhófà sì fi wò wọ́n?

9 Jèhófà lo àpèjúwe tí àwọn tó wà nígbà ayé Aísáyà mọ̀ dáadáa láti fi ṣàpèjúwe bí yóò ṣe gbilẹ̀. Bí “obìnrin” yẹn ṣe wòde láti orí Òkè Síónì níbi tó ti lè rí ọ̀nà jíjìn, òkè réré níhà ìlà oòrùn ló kọ́kọ́ wò. Kí ló rí? Ó ní: “Ìrọ́-sókè-sódò àgbájọ ràkúnmí pàápàá yóò bò ọ́, àwọn ẹgbọrọ akọ ràkúnmí Mídíánì àti ti Eéfà. Gbogbo àwọn tí ó wá láti Ṣébà—wọn yóò wá. Wúrà àti oje igi tùràrí ni wọn yóò rù. Ìyìn Jèhófà sì ni wọn yóò máa kéde.” (Aísáyà 60:6) Ọ̀wọ́ àwọn ràkúnmí àwọn oníṣòwò arìnrìn-àjò láti onírúurú ẹ̀yà forí lé ọ̀nà Jerúsálẹ́mù. (Jẹ́nẹ́sísì 37:25, 28; Àwọn Onídàájọ́ 6:1, 5; 1 Àwọn Ọba 10:1, 2) Ni ràkúnmí bá bo ilẹ̀ lọ súà, àfi bíi pé omi kún bo ilẹ̀! Ọ̀wọ́ àwọn ràkúnmí yìí ru ẹrù onírúurú ẹ̀bùn iyebíye wá, tó fi hàn pé àlàáfíà làwọn oníṣòwò yìí bá wá. Jèhófà ni wọ́n fẹ́ wá sìn, wọ́n sì fẹ́ fi èyí tó dára jù lọ lára ọrọ̀ wọn rúbọ.

10 Àwọn oníṣòwò wọ̀nyí nìkan kọ́ ló ń bọ̀ wá síbẹ̀ o. Ó ní: “Gbogbo agbo ẹran Kídárì—a óò kó wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn àgbò Nébáótì—wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ẹ̀yà àwọn darandaran pẹ̀lú ń bọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù. Ohun ìní wọn tó ṣeyebíye jù lọ ni wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn, ìyẹn agbo àgùntàn, wọ́n sì tún yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìránṣẹ́. Irú ojú wo ni Jèhófà fi wò wọ́n? Ó ní: “Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà ni wọn yóò fi gòkè wá sórí pẹpẹ mi, èmi yóò sì bu ẹwà kún ilé ẹwà mi.” (Aísáyà 60:7) Jèhófà tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn wọn o, a ó sì lò ó fún ìsìn mímọ́.—Aísáyà 56:7; Jeremáyà 49:28, 29.

11, 12. (a) Kí ni “obìnrin” yìí rí bó ṣe bojú wo ìhà ìwọ̀ oòrùn? (b) Kí nìdí tí àwọn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ń kánjú lọ sí Jerúsálẹ́mù?

11 Jèhófà wá pàṣẹ fún “obìnrin” yìí pé kí ó wo òkè réré níhà ìwọ̀ oòrùn, ó sí béèrè pé: “Ta ni ìwọ̀nyí tí ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà, àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn?” Jèhófà fúnra rẹ̀ dáhùn, ó ní: “Èmi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa retí, àti àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, láti lè kó àwọn ọmọ rẹ láti ibi jíjìnnàréré wá, bí fàdákà wọn àti wúrà wọn ti ń bẹ pẹ̀lú wọn, fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti fún Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí pé yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.”—Aísáyà 60:8, 9.

12 Fojú inú wò ó pé ìwọ pẹ̀lú “obìnrin” yẹn ló jọ dúró, tí ẹ jọ ń wo ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọdá Òkun Ńlá. Kí lo rí? Lọ́ọ̀ọ́kán, o rí àwọn nǹkan funfun tó-tò-tó tí ó lọ súà, tí wọ́n ń fẹ́ lẹlẹ bọ̀ lójú omi. Lókèèrè wọ́n dà bí ẹyẹ, àmọ́ bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, o rí i pé àwọn ọkọ̀ òkun tó ta ìgbòkun ni. “Ibi jíjìnnàréré” ni wọ́n ti ń bọ̀. * (Aísáyà 49:12) Àwọn ọkọ̀ òkun tó ń sáré bọ̀ ní Síónì yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi dà bí agbo àwọn àdàbà tó ń fò bọ̀ wálé. Kí ló ń lé ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun yìí léré? Ńṣe ló tètè fẹ́ sọ àwọn olùjọsìn Jèhófà tí ó ń kó bọ̀ láti àwọn èbúté tó jìnnà réré kalẹ̀. Ní ti gidi, Jerúsálẹ́mù ni gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí ń kánjú bọ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àjèjì, ì báà jẹ́ láti ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn àti láti ilẹ̀ itòsí tàbí ti ọ̀nà jíjìn réré, wọ́n fẹ́ wá ya gbogbo ohun ìní wọn àtàwọn fúnra wọn sí mímọ́ fún orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run wọn.—Aísáyà 55:5.

13. Lóde òní, àwọn wo ni àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin,” àwọn wo sì ni “ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”?

13 Àpèjúwe tí Aísáyà 60:4-9 ṣe nípa bí ìsìn mímọ́ ṣe gbilẹ̀ kárí ayé láti ìgbà tí “obìnrin” Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí tan ìmọ́lẹ̀ láàárín òkùnkùn ayé yìí mà kúkú ṣe kedere o! Àwọn “ọmọkùnrin” àti “ọmọbìnrin” Síónì ti ọ̀run, tó di Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n kọ́kọ́ dé. Lọ́dún 1931, àwọn wọ̀nyí kéde fáyé gbọ́ pé àwọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwọsánmà àwọn ọlọ́kàn tútù, “àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” àti “ọlà òkun,” sáré wá dára pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù lára àwọn arákùnrin Kristi. * Lóde òní, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí, tí wọ́n wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti láti onírúurú ẹ̀ka ìgbésí ayé ló ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run láti yin Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, àti láti gbé orúkọ rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí orúkọ tó tóbi lọ́lá jù lọ láyé àti lọ́run.

14. Báwo ló ṣe wáyé pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ń “gòkè wá sórí pẹpẹ” Ọlọ́run?

14 Àmọ́ o, kí wá ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yìí “gòkè wá sórí pẹpẹ” Ọlọ́run? Ẹbọ la máa ń gbé sórí pẹpẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹbọ rírú nígbà tó kọ̀wé pé: “Mo . . . pàrọwà fún yín . . . pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Àwọn ojúlówó Kristẹni ṣe tán láti sa gbogbo ipá wọn. (Lúùkù 9:23, 24) Wọ́n ń lo àsìkò, okun àti òye iṣẹ́ wọn láti fi gbé ìsìn mímọ́ ga. (Róòmù 6:13) Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí, ẹbọ ìyìn tó ṣètẹ́wọ́gbà ni wọ́n ń rú sí Ọlọ́run. (Hébérù 13:15) Ó mà dùn mọ́ni o pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùjọsìn Jèhófà lóde òní, lọ́mọdé lágbà, ló ti fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ ọkàn tàwọn fúnra wọn sí ipò kejì! Ojúlówó ẹ̀mí ìfara-ẹni rúbọ ni wọ́n ní.—Mátíù 6:33; 2 Kọ́ríńtì 5:15.

Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Ń Kópa Nínú Mímú Ìsìn Mímọ́ Gbilẹ̀

15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi àánú hàn nípa àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè láyé àtijọ́? (b) Lóde òní, báwo ni “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” ṣe ń kópa nínú gbígbé ìjọsìn tòótọ́ ró?

15 Àti ohun ìní àti ìsapá wọn làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí fi ń ṣètìlẹyìn fún “obìnrin” Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yóò sì mọ àwọn ògiri rẹ ní ti tòótọ́, àwọn ọba wọn yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ; nítorí pé nínú ìkannú mi ni èmi yóò ti kọlù ọ́, ṣùgbọ́n nínú ìfẹ́ rere mi ni èmi yóò ti ṣàánú fún ọ dájúdájú.” (Aísáyà 60:10) Jèhófà fi àánú hàn ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ tẹ́ńpìlì kíkọ́ ní Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 3:7; Nehemáyà 3:26) Nínú ìmúṣẹ ńlá ti òde òní, “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,” àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, ń ṣètìlẹyìn fún àwọn àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró láti gbé ìsìn tòótọ́ ró. Wọ́n ń gbin àwọn ànímọ́ Kristẹni sínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn, wọ́n wá ń tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìjọ Kristẹni ró, wọ́n sì ń mú kí “àwọn ògiri” ètò àjọ Jèhófà tó dà bí ìlú ńlá túbọ̀ lágbára sí i. (1 Kọ́ríńtì 3:10-15) Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé gidi bákan náà, wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àti àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì. Báyìí ni wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró nínú bíbójú tó àwọn ohun tí ètò àjọ Jèhófà tó ń gbilẹ̀ sí i nílò.—Aísáyà 61:5.

16, 17. (a) Kí ló ti mú kí “àwọn ẹnubodè” ètò àjọ Ọlọ́run wà ní ṣíṣí sílẹ̀? (b) Báwo ni “àwọn ọba” ṣe ti ṣèránṣẹ́ fún Síónì? (d) Kí ni yóò bá àwọn tó bá ń gbìyànjú láti ti “àwọn ẹnubodè” tí Jèhófà fẹ́ kó wà ní ṣíṣí sílẹ̀?

16 Lọ́dọọdún, ètò ìkọ́lé nípa tẹ̀mí ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” máa dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà, bẹ́ẹ̀, ọ̀nà sì ṣí sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn sí i láti wọlé. Jèhófà sọ pé: “Ní ti tòótọ́, a óò ṣí àwọn ẹnubodè rẹ sílẹ̀ nígbà gbogbo; a kì yóò tì wọ́n àní ní ọ̀sán tàbí ní òru, láti lè mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ, àwọn ọba wọn yóò sì mú ipò iwájú.” (Aísáyà 60:11) Àmọ́, àwọn wo tiẹ̀ ni àwọn “ọba” tó ń mú ipò iwájú nínú mímú àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sí Síónì? Láyé àtijọ́, Jèhófà mú kí ọkàn-àyà àwọn ọba kan sún wọn láti “ṣe ìránṣẹ́ fún” Síónì. Bí àpẹẹrẹ, Kírúsì lo ìdánúṣe tirẹ̀ láti fi dá àwọn Júù padà sí Jerúsálẹ́mù láti lọ tún tẹ́ńpìlì kọ́. Lẹ́yìn náà, Atasásítà kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ kalẹ̀, ó sì rán Nehemáyà lọ láti lọ tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́. (Ẹ́sírà 1:2, 3; Nehemáyà 2:1-8) Ní tòótọ́, ńṣe ni “ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà.” (Òwe 21:1) Ọlọ́run wa lè sún àwọn alákòóso tó lágbára pàápàá láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.

17 Láyé òde òní, ọ̀pọ̀ “ọba,” tàbí àwọn aláṣẹ nínú ìjọba, ló ti gbìyànjú láti ti “àwọn ẹnubodè” ètò àjọ Jèhófà. Àmọ́, àwọn mìíràn ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún Síónì nípa ṣíṣe àwọn ìpinnu tó jẹ́ kí “àwọn ẹnubodè” wọ̀nyẹn wà ní ṣíṣí sílẹ̀. (Róòmù 13:4) Lọ́dún 1919, àwọn aláṣẹ dá Joseph F. Rutherford àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wọ́n sí láìtọ́. (Ìṣípayá 11:13) Àwọn ìjọba èèyàn ló “gbé” ìkún omi inúnibíni náà “mì,” ìkún omi tí Sátánì ya lù wọ́n lẹ́yìn tó ṣubú kúrò lọ́run. (Ìṣípayá 12:16) Àwọn ìjọba kan ṣàtìlẹ́yìn fún fífi àyè gba àwọn ìsìn, nígbà mìíràn ó sì máa ń jẹ́ nítorí ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣíṣe tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà yìí ti mú kí ó rọrùn fún àwọn ọlọ́kàn tútù láti gba “àwọn ẹnubodè” tó ṣí sílẹ̀ wọnú ètò àjọ Jèhófà. Àwọn alátakò tó ń gbìyànjú láti ti “àwọn ẹnubodè” wọ̀nyẹn ńkọ́ o? Wọn ò ní ṣàṣeyọrí rárá. Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa wọn pé: “Orílẹ̀-èdè èyíkéyìí àti ìjọba èyíkéyìí tí kò bá sìn ọ́ yóò ṣègbé; àwọn orílẹ̀-èdè náà alára yóò sì wá sínú ìparundahoro dájúdájú.” (Aísáyà 60:12) Gbogbo àwọn tó bá ń bá “obìnrin” Ọlọ́run jà—wọn ì báà jẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn àjọ kan—yóò pa run nínú ogun Amágẹ́dọ́nì tó ń bọ̀, ó pẹ́ tán.—Ìṣípayá 16:14, 16.

18. (a) Kí ni ìtumọ̀ ìlérí náà pé àwọn igi yóò gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní Ísírẹ́lì? (b) Kí ni “àyè ẹsẹ̀” Jèhófà lóde òní?

18 Lẹ́yìn tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣèkìlọ̀ ìdájọ́ yìí tán, ó padà sórí ìlérí ìgbéga àti aásìkí. Jèhófà bá “obìnrin” yìí sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni ògo Lẹ́bánónì gan-an yóò wá, igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì lẹ́ẹ̀kan náà, láti lè ṣe ibùjọsìn mi lẹ́wà; èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.” (Aísáyà 60:13) Àwọn igi tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ṣàpẹẹrẹ ohun ẹlẹ́wà àti ohun eléso. (Aísáyà 41:19; 55:13) Gbólóhùn yìí, “ibùjọsìn” àti “àyè ẹsẹ̀ mi,” tó wà nínú ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (1 Kíróníkà 28:2; Sáàmù 99:5) Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí, ìyẹn, ìṣètò tó wà fún títọ Jèhófà wá láti wá jọ́sìn lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi. (Hébérù 8:1-5; 9:2-10, 23) Lóde òní Jèhófà ń ṣe “àyè ẹsẹ̀” rẹ̀ lógo, ìyẹn àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí yìí tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. Èyí sì ti wá fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń wá síbẹ̀ láti wá ṣe ìsìn tòótọ́.—Aísáyà 2:1-4; Hágáì 2:7.

19. Kí ni àwọn alátakò máa gbà ní túláàsì, ìgbà wo sì ni wọ́n máa gbà bẹ́ẹ̀, ó pẹ́ tán?

19 Wàyí o, Jèhófà wá yí àfiyèsí sí àwọn alátakò rẹ̀, ó ní: “Ọ̀dọ̀ rẹ sì ni àwọn ọmọ àwọn tí ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́ yóò wá, ní títẹríba; gbogbo àwọn tí ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọ yóò sì tẹ̀ ba síbi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ gan-an, dájúdájú, wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú ńlá Jèhófà, Síónì tí í ṣe ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Aísáyà 60:14) Dájúdájú, rírí tí àwọn alátakò kan rí ìbísí wọ̀ǹtìwọnti àti ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ tí Ọlọ́run fi jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀ yóò mú kí wọ́n tẹrí ba kí wọ́n sì pòkìkí “obìnrin” yìí. Ìyẹn ni pé, wọ́n á gbà ní túláàsì, ó pẹ́ tán ní Amágẹ́dọ́nì, pé òótọ́ ni pé àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àti alábàákẹ́gbẹ́ wọn jẹ́ aṣojú ètò àjọ Ọlọ́run ti ọ̀run, “ìlú ńlá Jèhófà, Síónì tí í ṣe ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”

Lílo Àwọn Ohun Èlò Tó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó

20. Ìyípadà ńláǹlà wo ló bá “obìnrin” yìí?

20 Ìyípadà tó bá “obìnrin” Jèhófà yìí mà kúkú ga o! Jèhófà sọ pé: “Dípò kí ìwọ já sí ẹni tí a fi sílẹ̀ pátápátá, tí a sì kórìíra, láìsí ẹnikẹ́ni tí ń gba inú rẹ kọjá, ṣe ni èmi yóò tilẹ̀ sọ ọ́ di ohun ìyangàn fún àkókò tí ó lọ kánrin, ayọ̀ ńláǹlà fún ìran dé ìran. Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu, ìwọ yóò sì mu ọmú àwọn ọba; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ni Olùgbàlà rẹ, Ẹni Alágbára Jékọ́bù sì ni Olùtúnnirà rẹ.”—Aísáyà 60:15, 16.

21. (a) Báwo ni Jerúsálẹ́mù àtijọ́ ṣe di “ohun ìyangàn”? (b) Àwọn ìbùkún wo ni àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ti rí gbà láti ọdún 1919, báwo sì ni wọ́n ti ṣe “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu”?

21 Àádọ́rin ọdún ni Jerúsálẹ́mù àtijọ́ fi pòórá ni ká wí, ‘láìsí ẹnikẹ́ni tí ń gba inú rẹ̀ kọjá.’ Ṣùgbọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà mú kí àwọn èèyàn tún padà máa gbé ìlú yẹn, tó fi di “ohun ìyangàn.” Bákan náà, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń parí lọ, Ísírẹ́lì Ọlọ́run dahoro fún àkókò kan, lójú wọn ńṣe ni wọ́n dà bí “ẹni tí a fi sílẹ̀ pátápátá.” Ṣùgbọ́n lọ́dún 1919, Jèhófà tún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró rà padà kúrò nígbèkùn, ó sì ń bù kún wọn láti ìgbà yẹn wá, ó mú kí wọ́n gbilẹ̀ kí wọ́n sì láásìkí nípa tẹ̀mí lọ́nà tó ju tìgbàkigbà rí lọ. Àwọn èèyàn rẹ̀ sì ti “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu” nípa lílo àwọn ohun ìní àwọn orílẹ̀-èdè fún ìtẹ̀síwájú ìsìn tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, lílo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu ti mú kó ṣeé ṣe láti túmọ̀ Bíbélì àti àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, àti láti tẹ̀ wọ́n jáde. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dọọdún, tí wọ́n sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Olùgbàlà àti Olùtúnnirà àwọn nípasẹ̀ Kristi.—Ìṣe 5:31; 1 Jòhánù 4:14.

Ìtẹ̀síwájú Nínú Ìṣètò Wa

22. Irú ìtẹ̀síwájú àkànṣe wo ni Jèhófà ṣèlérí rẹ̀?

22 Bí iye àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i ni ìtẹ̀síwájú ń bá ọ̀nà tí a gba ń ṣe àwọn ètò wa. Jèhófà sọ pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:17) Ìtẹ̀síwájú ló jẹ́ béèyàn bá fi wúrà dípò bàbà, bákan náà ló sì jẹ́ ní ti àwọn ohun èlò yòókù tí ibí yìí mẹ́nu kàn. Níbàámu pẹ̀lú èyí, ńṣe ni ìtẹ̀síwájú ń bá ọ̀nà tí àwọn èèyàn Jèhófà ń gbà ṣètò àwọn nǹkan ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

23, 24. Ìtẹ̀síwájú nínú ọ̀nà tí a gbà ń ṣètò wo ló ti ń wáyé láàárín àwọn èèyàn Jèhófà láti ọdún 1919?

23 Títí di ọdún 1919, ńṣe la ń dìbò yan àwọn alàgbà àti àwọn díákónì nínú ìjọ. Láti ọdún yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run láti fi yan ẹnì kan ṣe aláṣẹ iṣẹ́ ìsìn, láti máa bójú tó àwọn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn ìjọ, ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibì kan pé àwọn alàgbà kan tí ìjọ dìbò yàn ń tako aláṣẹ iṣẹ́ ìsìn. Lọ́dún 1932, àwọn nǹkan yí padà. A lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti fi sọ fún àwọn ìjọ pé kí wọ́n ṣíwọ́ dídìbò yan àwọn alàgbà àti àwọn díákónì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí ìjọ yan ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn kan tí yóò máa bá aláṣẹ iṣẹ́ ìsìn ṣiṣẹ́ pọ̀. Ìtẹ̀síwájú ńlá nìyẹn jẹ́.

24 Lọ́dún 1938, “wúrà” púpọ̀ sí i wọlé wá nígbà tí a fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ inú ìjọ ni a ní láti yàn sípò lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Àbójútó ìjọ wá wà níkàáwọ́ ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ (èyí táa pè ní ìránṣẹ́ ìjọ lẹ́yìn náà) àti onírúurú ìránṣẹ́ tó ń ràn án lọ́wọ́, gbogbo wọn ló sì jẹ́ pé abẹ́ àbójútó “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” la ti ń yàn wọ́n. * (Mátíù 24:45-47) Àmọ́ lọ́dún 1972, a rí i pé lílo àwọn alàgbà láti fi máa bójú tó ìjọ dípò lílo ẹnì kan ṣoṣo ni ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. (Fílípì 1:1) Àwọn àyípadà mìíràn wáyé nínú ìjọ àti nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Àpẹẹrẹ àyípadà tó wáyé nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ti ìkéde kan tó wáyé ní October 7, 2000, pé àwọn tó jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí wọ́n sì tún wà lára àwọn olùdarí àjọ Watch Tower Society of Pennsylvania àti àwọn àjọ yòókù tó rọ̀ mọ́ ọn, ti fínnú fíndọ̀ fi ipò olùdarí àjọ sílẹ̀. Nípa báyìí, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó ń ṣojú fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye yóò lè túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ abójútó tẹ̀mí lórí “ìjọ Ọlọ́run” àti àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Ìṣe 20:28) Gbogbo irú ìṣètò yẹn ló jẹ́ ìtẹ̀síwájú. Wọ́n mú kí ètò àjọ Jèhófà túbọ̀ lágbára, wọ́n sì já sí ìbùkún fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀.

25. Ta ló mú kí ìtẹ̀síwájú bá àwọn ọ̀nà tí àwọn èèyàn Jèhófà gbà ń ṣètò nǹkan, àǹfààní wo ni wọ́n sì ti jẹ?

25 Ta ní ń bẹ lẹ́yìn àwọn ìtẹ̀síwájú yìí? Ṣé nítorí orí pípé nídìí ètò ṣíṣe tàbí làákàyè àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn ọmọ aráyé kan ní ló fi ṣeé ṣe ni? Rárá o, nítorí Jèhófà ló sọ pé: “Èmi yóò mú wúrà wá.” Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ló mú kí gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí ṣeé ṣe. Bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń jọ̀wọ́ ara wọn fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣàtúnṣe ara wọn, ni wọ́n ń jàǹfààní rẹ̀. Àlàáfíà ń jọba láàárín wọn, fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn òdodo sì ń mú kí wọ́n máa sin Jèhófà.

26. Àmì tó ń fi àwọn Kristẹni hàn yàtọ̀ wo ni àwọn alátakò pàápàá kíyè sí?

26 Àlàáfíà tó ti ọ̀dọ́ Ọlọ́run wá máa ń mú àyípadà bá ìgbésí ayé ẹni. Jèhófà ṣèlérí pé: “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ. Dájúdájú, ìwọ yóò sì pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà àti àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn.” (Aísáyà 60:18) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ mà nìyẹn o! Kódà àwọn alátakò pàápàá gbà pé àlàáfíà jẹ́ ọ̀kan nínú ànímọ́ títayọ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ní. (Míkà 4:3) Wíwà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti láàárín ara wọn yìí ń mú kí ibi ìpàdé àwọn Kristẹni jẹ́ ibùdó ìtura láàárín ayé oníwà ipá yìí. (1 Pétérù 2:17) Ó jẹ́ ìtọ́wò ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà tí yóò wà nígbà tí gbogbo olùgbé ayé yóò jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”—Aísáyà 11:9; 54:13.

Ìmọ́lẹ̀ Ológo Tó Fi Hàn Pé Wọ́n Rí Ojú Rere Ọlọ́run

27. Ìmọ́lẹ̀ ìgbà gbogbo wo ló ń tàn sórí “obìnrin” Jèhófà?

27 Jèhófà ṣàpèjúwe bí ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn sórí Jerúsálẹ́mù ṣe mọ́lẹ̀ tó nígbà tó sọ pé: “Oòrùn kì yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán, òṣùpá pàápàá kì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ mọ́ fún ìtànyòò. Jèhófà yóò sì di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, Ọlọ́run rẹ yóò sì di ẹwà rẹ. Oòrùn rẹ kì yóò wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kì yóò wọ̀ọ̀kùn; nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóò sì parí dájúdájú.” (Aísáyà 60:19, 20) Ńṣe ni Jèhófà yóò máa bá a lọ láti jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” tí ń tàn sórí “obìnrin” rẹ̀. Kò ní “wọ̀” bí oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní “wọ̀ọ̀kùn” bí òṣùpá. * Ìgbà gbogbo ni ìmọ́lẹ̀ ojú rere rẹ̀ ń tàn sórí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn èèyàn tó jẹ́ aṣojú “obìnrin” Ọlọ́run. Ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí yìí pọ̀ gan-an lórí àwọn àti ogunlọ́gọ̀ ńlá débi pé, kò sí òkùnkùn kankan látinú ìṣèlú tàbí inú ètò ọ̀rọ̀ ajé ayé tó lè dín ìmọ́lẹ̀ yìí kù rárá. Ọkàn wọ́n sì balẹ̀ lórí ọjọ́ ọ̀la alárinrin tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn.—Róòmù 2:7; Ìṣípayá 21:3-5.

28. (a) Ìlérí wo ló wà fún àwọn ará Jerúsálẹ́mù tó ń padà bọ̀ wálé? (b) Kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi ṣe ìní lọ́dún 1919? (d) Báwo ni àwọn olódodo yóò ṣe jogún ilẹ̀ náà pẹ́ tó?

28 Jèhófà wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Jerúsálẹ́mù, pé: “Àti ní ti àwọn ènìyàn rẹ, gbogbo wọn yóò jẹ́ olódodo; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò fi ilẹ̀ náà ṣe ìní, èéhù tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí a lè ṣe mí lẹ́wà.” (Aísáyà 60:21) Nígbà tí Ísírẹ́lì nípa ti ara padà dé láti Bábílónì, wọ́n “fi ilẹ̀ náà ṣe ìní.” Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn tiwọn, “fún àkókò tí ó lọ kánrin” tí ibí yìí wí parí ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti orílẹ̀-èdè àwọn Júù run. Lọ́dún 1919, àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jáde kúrò nínú ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, wọ́n sì fi ilẹ̀ nípa tẹ̀mí ṣe ìní. (Aísáyà 66:8) Ilẹ̀, tàbí àgbègbè ìgbòkègbodò yìí, kún fún aásìkí jìngbìnnì nípa tẹ̀mí, èyí tí kò ní pa rẹ́ rárá. Ísírẹ́lì tẹ̀mí kò dà bí Ísírẹ́lì àtijọ́, wọn kò ní ya aláìṣòótọ́ ní tiwọn. Ẹ̀wẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yóò ṣẹ nípa ti ara nígbà tí ayé bá di Párádísè ní ti gidi, tí yóò sì kún fún “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Nígbà náà, àwọn olódodo tó ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò wá jogún ilẹ̀ náà títí láé.—Sáàmù 37:11, 29.

29, 30. Báwo ni “ẹni tí ó kéré” ṣe ti di “ẹgbẹ̀rún”?

29 A rí ìlérí pàtàkì kan tí Jèhófà fi orúkọ ara rẹ̀ jẹ́rìí sí ní ìparí Aísáyà orí ọgọ́ta. Ó ní: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Nígbà tí a dá àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n fọ́n ká padà sẹ́nu ìgbòkègbodò lọ́dún 1919, àwọn ni “ẹni tí ó kéré.” * Ṣùgbọ́n iye wọn wá di púpọ̀ sí i bí a ṣe ń kó ìyókù àwọn Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí wọlé wá. Ìbísí yẹn sì tún wá bùáyà bí kíkó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ ṣe bẹ̀rẹ̀.

30 Láìpẹ́ láìjìnnà, àlàáfíà àti òdodo tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́kàn mímọ́ mọ́ra débi pé “ẹni kékeré” wá di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè” ní ti gidi. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, iye wọ́n pọ̀ ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè ayé tó dá wà láyè ara wọn lọ. Dájúdájú, Jèhófà ń lo Jésù Kristi láti fi darí iṣẹ́ Ìjọba náà, ó sì ti mú kó yára kánkán. Ó mà wúni lórí o láti rí i bí ìsìn tòótọ́ ṣe ń gbilẹ̀, tí a sì tún ń kópa níbẹ̀! Dájúdájú, ayọ̀ ló jẹ́ fúnni láti mọ̀ pé ìbísí yìí ń ṣe Jèhófà, ẹni tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí tipẹ́tipẹ́, lógo.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 12 Ó jọ pé ibi táa mọ̀ sí Sípéènì nísinsìnyí ni Táṣíṣì wà láyé ìgbà yẹn. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé kan ṣe wí, wọ́n ní irú àwọn ọkọ̀ òkun kan, ìyẹn “àwọn ọkọ̀ onígbòkun ńlá tó ń rìn lójú agbami òkun,” tó jẹ́ pé irú wọn ló “kúnjú òṣùwọ̀n láti máa wá sí Táṣíṣì,” ni gbólóhùn náà, “ọkọ̀ òkun Táṣíṣì” ń tọ́ka sí, ìyẹn ni pé, ó tọ́ka sí àwọn ọkọ̀ òkun tó ṣeé lò fún ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí àwọn èbúté ti ilẹ̀ òkèèrè.—1 Àwọn Ọba 22:48.

^ ìpínrọ̀ 13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni onítara tó ń ṣe déédéé, tí wọ́n ń retí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ti ń dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣáájú ọdún 1930, ọdún 1930 síwájú ló hàn gbangba pé iye wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i.

^ ìpínrọ̀ 24 Láyé ìgbà yẹn, ẹgbẹ́ la máa ń pe àwọn ìjọ kọ̀ọ̀kan.

^ ìpínrọ̀ 27 Ọ̀rọ̀ tó dà bí èyí náà ni Jòhánù fi ṣàpèjúwe “Jerúsálẹ́mù tuntun,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bí wọ́n ṣe wà nínú ògo wọn ti ọ̀run. (Ìṣípayá 3:12; 21:10, 22-26) Èyí bá a mu, nítorí pé “Jerúsálẹ́mù tuntun” dúró fún àpapọ̀ àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run lẹ́yìn tí wọ́n ti gba èrè wọn ní ọ̀run, tí àwọn àti Jésù Kristi sì pa pọ̀ di apá pàtàkì lára “obìnrin” Ọlọ́run, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè.”—Gálátíà 4:26.

^ ìpínrọ̀ 29 Lọ́dún 1918, ìpíndọ́gba iye àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ọ̀rọ̀ náà lóṣooṣù kò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 305]

Jèhófà pàṣẹ fún “obìnrin” náà pé kó “dìde”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 312, 313]

“Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì” kó àwọn olùjọsìn Jèhófà