Ìtùnú fún Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
Orí Kejìlá
Ìtùnú fún Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
1. Àjálù wo ní ń bọ̀ wá bá Jerúsálẹ́mù àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, síbẹ̀ ìrètí wo ni wọ́n ní?
ODINDI àádọ́rin ọdún, ìyẹn iye ọdún ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn, ni orílẹ̀-èdè Júdà yóò fi wà nígbèkùn ní Bábílónì. (Sáàmù 90:10; Jeremáyà 25:11; 29:10) Ìgbèkùn ní Bábílónì ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kó lọ yóò darúgbó sí tí wọn yóò sì kú sí. Ẹ wo bí ẹ̀sín àti ẹlẹ́yà tí àwọn ọ̀tá wọn yóò fi wọ́n ṣe yóò ṣe dùn wọ́n tó. Ẹ sì tún wo bí wọn yóò ṣe máa pẹ̀gàn Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, nígbà tí odindi ìlú tó forúkọ ara rẹ̀ pè bá fi wà láhoro pẹ́ tó bẹ́ẹ̀. (Nehemáyà 1:9; Sáàmù 132:13; 137:1-3) Tẹ́ńpìlì pàtàkì nì, tí ògo Ọlọ́run kún nígbà tí Sólómọ́nì yà á sí mímọ́, kò ní sí mọ́. (2 Kíróníkà 7:1-3) Áà, àjálù ńlá ń bẹ níwájú! Àmọ́ o, Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pé ilẹ̀ wọn yóò rí àtúnṣe. (Aísáyà 43:14; 44:26-28) Nínú orí kọkànléláàádọ́ta ìwé Aísáyà, a rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ síwájú sí i lórí kókó ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí.
2. (a) Ta ni Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú rẹ̀ yìí fún? (b) Báwo ni àwọn Júù olóòótọ́ ṣe “ń lépa òdodo”?
2 Jèhófà wá sọ fún àwọn tó fi ọkàn sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ará Júdà pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn tí ń lépa òdodo, ẹ̀yin tí ń wá ọ̀nà láti rí Jèhófà.” (Aísáyà 51:1a) Béèyàn bá “ń lépa òdodo,” ó fi hàn pé kò káwọ́ lẹ́rán. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá “ń lépa òdodo” kò ní fẹnu nìkan jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. Wọn yóò máa sapá tìtara-tìtara láti jẹ́ olódodo àti láti gbé ìgbé ayé tó bá ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ mu. (Sáàmù 34:15; Òwe 21:21) Jèhófà nìkan ni wọn yóò máa wò gẹ́gẹ́ bí Orísun òdodo, wọn yóò sì máa “wá ọ̀nà láti rí Jèhófà.” (Sáàmù 11:7; 145:17) Kì í ṣe pé wọn ò tíì ní mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, tàbí pé wọn ò tíì mọ bí wọn yóò ṣe gbàdúrà sí i. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni wọ́n á máa ṣakitiyan láti túbọ̀ sún mọ́ ọn, wọ́n á máa sìn ín, wọ́n á máa gbàdúrà sí i, wọ́n á sì máa fi ṣe atọ́nà wọn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.
3, 4. (a) Ta ni “àpáta” tí wọn ti gbẹ́ àwọn Júù jáde, ta sì ni “ihò kòtò” tí wọ́n ti wà wọ́n jáde? (b) Kí ni ìdí tí yóò fi jẹ́ ìtùnú fún àwọn Júù tí wọ́n bá rántí ìtàn ìwáṣẹ̀ wọn?
3 Ṣùgbọ́n o, iye àwọn tó ń lépa òdodo lóòótọ́ ní Júdà kéré gan-an, èyí sì lè mú kí àwọn yẹn máa ṣojo, kí wọ́n sì sọ̀rètí nù. Ìyẹn ni Jèhófà fi lo àpèjúwe ibi ìfọ́-òkúta láti fi fún wọn níṣìírí, ó ní: “Ẹ yíjú sí àpáta tí a ti gbẹ́ yín jáde, àti ihò kòtò tí a ti wà yín jáde. Ẹ yíjú sí Ábúráhámù baba yín àti Sárà tí ó fi ìrora ìbímọ bí yín ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nítorí pé ọ̀kan ṣoṣo ni òun nígbà tí mo pè é, mo sì tẹ̀ síwájú láti bù kún un, mo sì sọ ọ́ di púpọ̀.” (Aísáyà 51:1b, 2) Ábúráhámù, ẹni pàtàkì kan nínú ìtàn, ẹni tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi ń yangàn, ni “àpáta” tí wọ́n ti gbẹ́ àwọn Júù jáde. (Mátíù 3:9; Jòhánù 8:33, 39) Òun ni ìṣẹ̀run orílẹ̀-èdè yẹn, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá láyé ńbí. Sárà, ẹni tó bí Ísákì baba ńlá Ísírẹ́lì sì ni “ihò kòtò” yẹn.
4 Ó ṣẹlẹ̀ pé Ábúráhámù àti Sárà ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ, bẹ́ẹ̀ wọn ò sì bímọ kankan. Síbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò bù kún Ábúráhámù, òun yóò sì “sọ ọ́ di púpọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1-6, 15-17) Bí Jèhófà ṣe wá mú kí agbára ìbímọ Ábúráhámù àti Sárà sọjí, ni wọ́n bá bí ọmọkùnrin kan nígbà ogbó wọn, ọ̀dọ̀ ọmọ yẹn sì ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú ti pilẹ̀. Báyìí ni Jèhófà sọ ọkùnrin kan ṣoṣo yẹn di baba orílẹ̀-èdè ńlá kan, èyí tó wá pọ̀ lọ súà bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí a kò lè kaye wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5; Ìṣe 7:5) Nítorí náà, bí Jèhófà bá lè mú Ábúráhámù láti ilẹ̀ òkèèrè wá, tí ó sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ó dájú pé ó lè mú ìlérí tí ó ṣe ṣẹ pé òun yóò dá àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì, pé òun yóò dá wọn padà wá sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, òun yóò sì mú kí wọ́n tún padà di orílẹ̀-èdè ńlá. Ṣe bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù kúkú ṣẹ; ìlérí tí ó ṣe fún àwọn Júù ìgbèkùn yóò ṣẹ pẹ̀lú.
5. (a) Ta ni Ábúráhámù àti Sárà dúró fún? Ṣàlàyé. (b) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá ṣẹ nígbà ìkẹyìn, àwọn wo ló ṣèwádìí tí wọ́n sì rí i pé inú “àpáta” yìí làwọn ti ṣẹ̀ wá?
5 Ó jọ pé fífọ́ òkúta lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tí Aísáyà 51:1, 2 sọ ní ìtumọ̀ síwájú sí i. Diutarónómì 32:18 pe Jèhófà ní “Àpáta” tí ó bí Ísírẹ́lì àti “Ẹni tí ó fi ìrora ìbímọ bí [Ísírẹ́lì].” Ní èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ ìṣe kan náà ni wọ́n lò fún gbólóhùn yìí, ‘ẹni tí ó fi ìrora ìbímọ bí Ísírẹ́lì’ àti gbólóhùn inú Aísáyà 51:2 nípa pé Sárà bí Ísírẹ́lì. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni Ábúráhámù ṣàpẹẹrẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, òun ni Ábúráhámù Gíga Jù Lọ. Sárà aya Ábúráhámù wá dúró fún ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní gbogbo gbòò, èyí tí Ìwé Mímọ́ máa ń pè ní aya tàbí obìnrin Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣípayá 12:1, 5) Nígbà tí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí wá ṣẹ nígbà ìkẹyìn, orílẹ̀-èdè tó tinú “àpáta” dìde yìí ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni tí a fẹ̀mí yàn, tó bẹ̀rẹ̀ nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò rẹ̀ ní àwọn orí ìṣáájú nínú ìwé yìí, orílẹ̀-èdè yẹn dèrò ìgbèkùn Bábílónì lọ́dún 1918 ṣùgbọ́n a mú un padà bọ̀ sípò lọ́dún 1919, tó fi bọ́ sínú ipò aásìkí nípa tẹ̀mí.—Gálátíà 3:26-29; 4:28; 6:16.
6. (a) Kí ní ń bẹ níwájú fún ilẹ̀ Júdà, ìmúbọ̀sípò wo ni yóò sì wáyé? (b) Ìmúbọ̀sípò òde òní wo ni Aísáyà 51:3 mú wa rántí?
6 Ìtùnú tí Jèhófà fún Síónì tàbí Jerúsálẹ́mù kò mọ sí ṣíṣe ìlérí pé òun yóò mú orílẹ̀-èdè tí àwọn èèyàn pọ̀ sí rẹpẹtẹ jáde. A kà á pé: “Ó dájú pé Jèhófà yóò tu Síónì nínú. Ó dájú pé òun yóò tu gbogbo ibi ìparundahoro rẹ̀ nínú, òun yóò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà Jèhófà. Ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ pàápàá ni a óò rí nínú rẹ̀, ìdúpẹ́ àti ohùn orin atunilára.” (Aísáyà 51:3) Lásìkò ìdahoro àádọ́rin ọdún yẹn, ṣe ni ilẹ̀ Júdà yóò padà di aginjù, ibi tí àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún, òṣùṣú àti ewéko lónírúurú kún bò. (Aísáyà 64:10; Jeremáyà 4:26; 9:10-12) Nítorí náà, láfikún sí dídá àwọn ará Júdà padà wá sí ilẹ̀ wọn, ìmúbọ̀sípò yẹn yóò ní láti kan títún ilẹ̀ yẹn ṣe, èyí tí wọn yóò sọ di ọgbà ẹlẹ́wà bíi ti Édẹ́nì, tí yóò ní àwọn oko àti ọgbà eléso tí ń so wọ̀ǹtì-wọnti. Yóò sì wá dà bíi pé ilẹ̀ ọ̀hún pàápàá ń yọ̀. Ilẹ̀ yẹn yóò dà bí ọgbà Párádísè ní ìfiwéra pẹ̀lú bó ṣe dahoro lásìkò tí wọ́n wà nígbèkùn. Irú ipò Párádísè yẹn gẹ́lẹ́ ni àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run bọ́ sí nípa tẹ̀mí lọ́dún 1919.—Aísáyà 11:6-9; 35:1-7.
Àwọn Ìdí Téèyàn fi Lè Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jèhófà
7, 8. (a) Kí ni títẹ́tí tí Jèhófà ní kí wọ́n tẹ́tí sí òun túmọ̀ sí? (b) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí Júdà gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu?
7 Jèhófà sọ pé kí wọ́n wá túbọ̀ fetí sílẹ̀ wàyí, ó ní: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; àti ìwọ àwùjọ orílẹ̀-èdè mi, fi etí sí mi. Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ mi, àní òfin kan yóò jáde lọ, ìpinnu ìdájọ́ mi ni èmi yóò sì mú kí ó fìdí kalẹ̀ àní gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Òdodo mi sún mọ́lé. Ìgbàlà mi yóò jáde lọ dájúdájú, apá mi yóò sì dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́. Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò fi ìrètí wọn sí, apá mi sì ni wọn yóò dúró dè.”—Aísáyà 51:4, 5.
8 Títẹ́tí tí Jèhófà sọ pé kí wọ́n tẹ́tí sí òun kì í ṣe ti pé kí wọ́n kàn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sétí lásán. Ó túmọ̀ sí pé kí wọ́n fetí sílẹ̀ láti lè fi ohun tí wọ́n bá gbọ́ sílò ni o. (Sáàmù 49:1; 78:1) Orílẹ̀-èdè yẹn gbọ́dọ̀ mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé Jèhófà ni Orísun ìtọ́ni, ìdájọ́ òdodo, àti ìgbàlà. Òun nìkan ni Orísun ìlàlóye nípa tẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 4:6) Òun ni Onídàájọ́ ìkẹyìn fún ọmọ aráyé. Àwọn òfin àti ìpinnu ìdájọ́ tó bá ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tó bá jẹ́ kí wọ́n ṣamọ̀nà òun.—Sáàmù 43:3; 119:105; Òwe 6:23.
9. Yàtọ̀ sí àwọn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, àwọn wo ni yóò tún jàǹfààní nínú iṣẹ́ ìgbàlà Jèhófà?
9 Kì í ṣe kìkì àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú ni èyí yóò ṣẹ sí lára, yóò kan àwọn olùfẹ́ òdodo níbi gbogbo pẹ̀lú, àní títí kan àwọn tó wà ní erékùṣù òkun jíjìnnà Aísáyà 40:10; Lúùkù 1:51, 52) Lónìí bákan náà, iṣẹ́ ìwàásù onítara tí àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì Ọlọ́run ń ṣe ti mú kí ẹgbàágbèje èèyàn yí padà sọ́dọ̀ Jèhófà kí wọ́n sì gbà á gbọ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wá látinú àwọn erékùṣù jíjìnnà réré.
réré pẹ̀lú. Ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run pé ó lágbára láti gbèjà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kí ó sì gbà wọ́n kò ní já sófo rárá. Agbára rẹ̀, èyí tó fi apá rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ, wà digbí; kò sì sẹ́ni tó lè dí i lọ́wọ́ rárá. (10. (a) Òdodo ọ̀rọ̀ wo ni Nebukadinésárì Ọba máa tó mọ̀ tipátipá? (b) “Ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” wo ni yóò dópin?
10 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà sọ òdodo ọ̀rọ̀ kan tí yóò di dandan kí Nebukadinésárì ọba Bábílónì mọ̀. Òun ni pé, kò sí ohunkóhun láyé àti lọ́run tó lè dá Jèhófà dúró láti máà mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Dáníẹ́lì 4:34, 35) A kà á pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè sí ọ̀run, kí ẹ sì wo ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Nítorí pé àní ọ̀run ni a óò fọ́n ká ní wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí èéfín, ilẹ̀ ayé yóò sì gbó bí ẹ̀wù, àwọn olùgbé rẹ̀ pàápàá yóò sì kú bí kòkòrò kantíkantí lásán-làsàn. Ṣùgbọ́n ní ti ìgbàlà mi, yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, a kì yóò sì fọ́ òdodo mi túútúú.” (Aísáyà 51:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọba Bábílónì kì í gbà láti tú àwọn òǹdè wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè padà lọ sílé, kò sí ohun tó lè ṣèdíwọ́ fún gbígbà tí Jèhófà fẹ́ gba àwọn èèyàn rẹ̀. (Aísáyà 14:16, 17) A ó fi ìṣẹ́gun fọ́ “ọ̀run” Bábílónì, ìyẹn àwọn alákòóso rẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, “ilẹ̀ ayé” Bábílónì, ìyẹn àwọn aráàlú tí àwọn alákòóso ibẹ̀ ń ṣàkóso, yóò wá dópin. Dájúdájú, àkóso tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn pàápàá kò lè dènà agbára Jèhófà, tàbí kí ó ṣèdíwọ́ fún àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀.
11. Kí ni ìdí tí ṣíṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé a óò mú “ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” Bábílónì wá sópin ṣẹ pátápátá fi jẹ́ ìṣírí fún àwọn Kristẹni lóde òní?
11 Ìṣírí ńlá mà ló jẹ́ fáwọn Kristẹni òde òní o, láti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ pátápátá! Kí ni ìdí rẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé àpọ́sítélì Pétérù lo irú gbólóhùn kan náà fún ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ kánkán, “nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́!” Ó wá ní: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:12, 13; Aísáyà 34:4; Ìṣípayá 6:12-14) Lóòótọ́ o, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára àti àwọn alákòóso wọn tó ga fíofío bí ìràwọ̀ lè máa ṣàyà gbàǹgbà sí Jèhófà o, àmọ́ bí àkókò bá ti tó lójú rẹ̀, yóò sọ wọ́n dí asán, ńṣe ni yóò tẹ̀ wọ́n fọ́ pẹ̀ẹ́ bí ẹni pa kòkòrò kantí-kantí lásán. (Sáàmù 2:1-9) Ìjọba òdodo ti Ọlọ́run nìkan ni yóò máa wá ṣàkóso títí ayé, lórí àwùjọ èèyàn olódodo.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:1-4.
12. Kí ni ìdí tí kò fi yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bẹ̀rù nígbà tí àwọn èèyàn tó takò wọ́n bá ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́?
12 Jèhófà wá kọjú ọ̀rọ̀ sí àwọn “ènìyàn tí ń lépa òdodo,” ó ní: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ó mọ òdodo, ẹ̀yin ènìyàn tí òfin mi wà ní ọkàn-àyà yín. Ẹ má fòyà ẹ̀gàn àwọn ẹni kíkú, ẹ má sì jẹ́ kí a kó ìpayà bá yín kìkì nítorí ọ̀rọ̀ èébú wọn. Nítorí pé òólá yóò jẹ wọ́n tán bí ẹni pé ẹ̀wù ni wọ́n, òólá aṣọ yóò sì jẹ wọ́n tán bí irun àgùntàn. Ṣùgbọ́n ní ti òdodo mi, yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti ìgbàlà Aísáyà 51:7, 8) Àwọn èèyàn yóò ba àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lórúkọ jẹ́, àní wọn yóò pẹ̀gàn wọn nítorí ọkàn akin tí wọ́n ní, ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe ohun à-ń-bẹ̀rù rárá. Ọmọ adáríhurun lásánlàsàn làwọn ẹlẹ́gàn yìí, àwọn tó jẹ́ pé bí ìgbà tí òólá bá jẹ aṣọ ni wọ́n yóò ṣe di ‘jíjẹ tán’ pátá. * Bí àwọn Júù olóòótọ́ láyé àtijọ́ kò ṣe ní láti bẹ̀rù náà ni kò ṣe sídìí fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní láti bẹ̀rù ẹni yòówù kó takò wọ́n. Jèhófà, Ọlọ́run ayérayé, ni ìgbàlà wọn. (Sáàmù 37:1, 2) Ṣe ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá Ọlọ́run tún jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ lára àwọn èèyàn Jèhófà.—Mátíù 5:11, 12; 10:24-31.
mi, fún àwọn ìran tí kò níye.” (13, 14. Kí ni gbólóhùn náà “Ráhábù” àti “ẹran ńlá abàmì inú òkun” dúró fún, báwo ló sì ṣe di èyí tí a ‘fọ́ sí wẹ́wẹ́’ tí a sì ‘gún ní àgúnyọ’?
13 Aísáyà wá sọ̀rọ̀ bíi pé ó ń sọ pé kí Jèhófà gbéra láti gbèjà àwọn èèyàn Rẹ̀ tó wà nígbèkùn, ó ní: “Jí, jí, gbé okun wọ̀, ìwọ apá Jèhófà! Jí gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà àwọn ìran tí ó ti kọjá sẹ́yìn tipẹ́tipẹ́. Ìwọ ha kọ́ ni ó fọ́ Ráhábù sí wẹ́wẹ́, tí ó gún ẹran ńlá abàmì inú òkun ní àgúnyọ? Ìwọ ha kọ́ ni ó mú òkun gbẹ, omi alagbalúgbú ibú? Ẹni tí ó sọ àwọn ibú òkun di ọ̀nà fún àwọn tí a tún rà láti gbà sọdá?”—Aísáyà 51:9, 10.
14 Àwọn àpẹẹrẹ inú ìtàn tí Aísáyà mẹ́nu kàn bá a mu gan-an ni. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ló mọ̀ nípa bí orílẹ̀-èdè yẹn ṣe rí ìdáǹdè gbà kúrò ní Íjíbítì àti bí wọ́n ṣe la Òkun Pupa kọjá. (Ẹ́kísódù 12:24-27; 14:26-31) Gbólóhùn náà, “Ráhábù” àti “ẹran ńlá abàmì inú òkun” tọ́ka sí Íjíbítì tí Fáráò ń ṣàkóso lé lórí, èyí tó fàáké kọ́rí pé Ísírẹ́lì ò ní kúrò ní Íjíbítì. (Sáàmù 74:13; 87:4; Aísáyà 30:7) Bí ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ ṣe rí jọ ejò ńlá abàmì lóòótọ́, ńṣe ló dà bíi pé ó gbórí sí ibi tí odò Náílì ti pẹ̀ka wọnú òkun, tí ara rẹ̀ sì gùn lọ rẹrẹẹrẹ tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ní Àfonífojì Odò Náílì ọlọ́ràá. (Ìsíkíẹ́lì 29:3) Ṣùgbọ́n ẹran ńlá abàmì yìí ké sí wẹ́wẹ́ nígbà tí Jèhófà da Ìyọnu Mẹ́wàá lé e lórí. A gún un, ó fara gbọgbẹ́ gidigidi, ó sì di aláìlágbára nígbà tó di pé àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa rẹ́ sínú alagbalúgbú omi Òkun Pupa. Dájúdájú, Jèhófà fi agbára apá rẹ̀ hàn nínú itú tó fi Íjíbítì pa. Nítorí náà, ṣe á wá dijú sí ọ̀ràn àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ni?
15. (a) Ìgbà wo ni ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn Síónì yóò fò lọ, báwo ni yóò sì ṣe fò lọ? (b) Ìgbà wo ni ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn Ísírẹ́lì Ọlọ́run fò lọ lóde òní?
15 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá gbẹ́nu lé ọ̀ràn ìdáǹdè Ísírẹ́lì kúrò ní Bábílónì èyí tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Nígbà náà ni àwọn tí Jèhófà tún rà padà yóò padà, tí wọn yóò sì wá sí Síónì ti àwọn ti igbe ìdùnnú, ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin yóò sì wà ní orí wọn. Ọwọ́ wọn yóò tẹ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀. Ṣe ni ẹ̀dùn-ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò fò lọ.” (Aísáyà 51:11) Bó ṣe wù kí ipò àwọn tó ń ṣàfẹ́rí òdodo Jèhófà burú tó ní Bábílónì, ìrètí ológo ń bẹ níwájú fún wọn. Ìgbà ń bọ̀ tí ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn kò ní sí mọ́. Igbe ìdùnnú, ayọ̀ yíyọ̀, ayọ̀ ńláǹlà, ni yóò máa ti ẹnu àwọn tí Jèhófà tún rà padà jáde. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ lóde òní, ńṣe ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run rí ìdáǹdè gbà kúrò nígbèkùn Bábílónì lọ́dún 1919. Wọ́n wá fi ayọ̀ ńláǹlà padà sẹ́nu ìgbòkègbodò wọn tẹ̀mí ní pẹrẹu, tí ayọ̀ yẹn sì ń bá a lọ dòní olónìí.
16. Kí ni Jèhófà san láti lè dá àwọn Júù nídè?
16 Kí ni Jèhófà yóò san lórí ìdáǹdè àwọn Júù? Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti ṣí i payá ṣáájú pé Jèhófà ti fi “Íjíbítì fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà rẹ, Etiópíà àti Sébà dípò rẹ.” (Aísáyà 43:1-4) Ìyẹn ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá yá. Lẹ́yìn tí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà bá ṣẹ́gun Bábílónì tó sì ti tú àwọn Júù sílẹ̀ kúrò nígbèkùn tán, yóò wá ṣẹ́gun Íjíbítì, Etiópíà àti Sébà. Àwọn yẹn ni Ọlọ́run yóò fún un dípò ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Òwe 21:18 mẹ́nu kàn pé: “Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo; ẹni tí ń ṣe àdàkàdekè a sì gba ipò àwọn adúróṣánṣán.”
Ó Sọ̀rọ̀ Ìfọ̀kànbalẹ̀ Síwájú Sí I
17. Èé ṣe tí kò fi sídìí fún àwọn Júù láti bẹ̀rù ìhónú Bábílónì?
17 Jèhófà túbọ̀ fọkàn àwọn èèyàn rẹ̀ balẹ̀, ó ní: “Èmi—èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú. Ta ni ọ́ tí ìwọ yóò fi máa fòyà ẹni kíkú tí yóò kú, àti ọmọ aráyé tí a ó sọ di koríko tútù lásán-làsàn? Tí ìwọ yóò sì fi gbàgbé Jèhófà Olùṣẹ̀dá rẹ, Ẹni tí ó na ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, tí ìwọ fi wà nínú ìbẹ̀rùbojo nígbà gbogbo láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní tìtorí ìhónú ẹni tí ó há ọ mọ́, bí ẹni pé ó ti múra tán pátápátá láti run ọ́? Ìhónú ẹni tí ó há ọ mọ́ dà?” (Aísáyà 51:12, 13) Ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni wọ́n yóò lò nígbèkùn lóòótọ́ o. Síbẹ̀, kò sídìí fún wọn láti bẹ̀rù ìbínú Bábílónì. Òótọ́ ni pé orílẹ̀-èdè yẹn, tó jẹ́ agbára ayé kẹta nínú ìtàn Bíbélì, yóò ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọn yóò sì wọ́nà láti ‘há wọn mọ́,’ tàbí kí wọ́n dí ọ̀nà àsálà mọ́ wọn, síbẹ̀ àwọn Júù olóòótọ́ mọ̀ pé Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Kírúsì ń bọ̀ wá bi Bábílónì ṣubú. (Aísáyà 44:8, 24-28) Bí koríko tútù ṣe ń rọ tí oòrùn tó mú janjan bá ta sí i nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, bẹ́ẹ̀ làwọn olùgbé Bábílónì yóò ṣe pa run, nítorí wọn kò dà bíi Jèhófà, Ẹlẹ́dàá, tó jẹ́ Ọlọ́run ayérayé. Kí wá ni gbogbo ìhàlẹ̀ àti ìhónú wọn já sí nígbà náà? Ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu gbáà ni láti bẹ̀rù èèyàn ká wá gbàgbé Jèhófà, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé!
18. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò jẹ́ òǹdè fúngbà díẹ̀, ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ni Jèhófà fún wọn?
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò jẹ́ òǹdè fúngbà Sáàmù 30:3; 88:3-5) Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Dájúdájú, ẹni tí ó tẹ̀ ba pẹ̀lú àwọn ẹ̀wọ̀n ni a ó fi ìyára kánkán tú, kí ó má bàa lọ nínú ikú sí kòtò, kí ó má sì ṣaláìní oúnjẹ.”—Aísáyà 51:14.
díẹ̀, tí wọn ń “tẹ̀ ba pẹ̀lú àwọn ẹ̀wọ̀n” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, òjijì ni wọn yóò rí ìdáǹdè gbà. Wọn kò ní pa rẹ́ sí Bábílónì tàbí kí ebi lù wọ́n pa gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, tí wọn yóò fi wá di òkú inú Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn kòtò. (19. Kí ni ìdí tí àwọn Júù olóòótọ́ fi lè gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jèhófà pátápátá?
19 Jèhófà ń bá a lọ láti tu Síónì nínú, ó ní: “Ṣùgbọ́n èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń ru òkun sókè kí ìgbì rẹ̀ lè di aláriwo líle. Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Èmi yóò sì fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò sì fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ dájúdájú, kí n lè gbin ọ̀run, kí n sì lè fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, kí n sì wí fún Síónì pé, ‘Ìwọ ni ènìyàn mi.’” (Aísáyà 51:15, 16) Léraléra ni Bíbélì ń mẹ́nu kan bí Ọlọ́run ṣe lágbára lórí òkun àti bó ṣe káwọ́ rẹ̀. (Jóòbù 26:12; Sáàmù 89:9; Jeremáyà 31:35) Ó káwọ́ iná, ìgbì, ẹ̀fúùfù, oòrùn, òjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ó sì fi èyí hàn nígbà tó dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò ní Íjíbítì. Ta ni a wá lè fi wé “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,” àní bó tiẹ̀ jẹ́ lọ́nà bíńtín pàápàá?—Sáàmù 24:10.
20. “Ọ̀run” àti “ayé” wo ni yóò wáyé nígbà tí Jèhófà bá mú Síónì padà bọ̀ sípò, ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Jèhófà yóò wá sọ?
20 Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú làwọn Júù ṣì jẹ́, Jèhófà sì mú un dá wọn lójú pé wọ́n máa padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, tí Òfin òun yóò sì tún máa darí ìgbésí ayé wọn. Wọn yóò wá tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì ibẹ̀ kọ́, wọn yóò sì padà máa ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú májẹ̀mú tí ó tipasẹ̀ Mósè bá wọn dá. Bó bá ti wá di pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó padà wálé àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ń bí sí i nínú ilẹ̀ yẹn, “ilẹ̀ ayé tuntun” dé nìyẹn. “Ọ̀run tuntun,” ìyẹn ètò ìṣàkóso tuntun, yóò wá bẹ̀rẹ̀ lórí wọn. (Aísáyà 65:17-19; Hágáì 1:1, 14) Jèhófà yóò sì tún padà sọ fún Síónì pé: “Ìwọ ni ènìyàn mi.”
Jèhófà Sọ Pé Kí Síónì Gbéra Nílẹ̀
21. Ìpè wo ni Jèhófà pè pé kí Síónì gbéra nílẹ̀?
21 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti fi Síónì lọ́kàn balẹ̀ tán, ló bá ní kó gbéra nílẹ̀. Jèhófà wá bá a sọ̀rọ̀ bíi pé ó ti jìyà rẹ̀ dópin, ó ní: “Ta jí, ta jí, dìde, ìwọ Jerúsálẹ́mù, ìwọ tí o ti mu ife ìhónú Jèhófà ní ọwọ́ rẹ̀. Gàásì náà, ife tí ń fa títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́, ni o ti mu, ni o ti fà gbẹ.” (Aísáyà 51:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, dandan ni kí Jerúsálẹ́mù gbọnra nù kúrò nínú ìjábá tó bá a, kí ó padà sí ipò rẹ̀ àti sínú ọlá rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀. Ìgbà ń bọ̀ tí yóò ti fa ife ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run fún un mu gbẹ. Kò ní ku ìbínú Ọlọ́run sílẹ̀ fún un láti fara gbà mọ́.
22, 23. Kí ni Jerúsálẹ́mù yóò fara gbà bó bá ti mu ife ìbínú Jèhófà?
22 Àmọ́, nígbà tí Jerúsálẹ́mù bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́, kò sí ìkankan nínú àwọn olùgbé rẹ̀, àwọn “ọmọ rẹ̀,” tí yóò lè Aísáyà 43:5-7; Jeremáyà 3:14) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé: “Kò sí ìkankan lára gbogbo ọmọ tí ó bí tí ó ń darí rẹ̀, kò sì sí ìkankan lára gbogbo ọmọ tí ó tọ́ dàgbà tí ó ń di ọwọ́ rẹ̀ mú.” (Aísáyà 51:18) Dẹndẹ ìyà làwọn ará Bábílónì á fi jẹ ẹ́! “Ohun méjì wọnnì ni ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Ta ni yóò bá ọ kẹ́dùn? Ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀, àti ebi àti idà! Ta ni yóò tù ọ́ nínú? Àwọn ọmọ rẹ ti dákú lọ gbári. Wọ́n ti dùbúlẹ̀ sí ìkòríta gbogbo ojú pópó bí àgùntàn ìgbẹ́ tí ó wà nínú àwọ̀n, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìhónú Jèhófà, ìbáwí mímúná Ọlọ́run rẹ.”—Aísáyà 51:19, 20.
kọ ìyà yẹn fún un. (23 Áà, ó mà ṣe fún Jerúsálẹ́mù o! “Ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀” pẹ̀lú “ebi àti idà” ni yóò fara gbà. Bí “àwọn ọmọ rẹ̀” kò ṣe ní lè darí rẹ̀, tí wọn ò sì ní lè bá a kọ ìyà rẹ̀, ńṣe ni wọn yóò máa wò ṣùn-ùn, nítorí wọ́n á ti rù hangogo, wọn kò sì ní tẹ́ni tó lè gbéjà ko àwọn ará Bábílónì tó wá gbógun jà wọ́n. A ó máa rí wọn káàkiri oríta àti kọ̀rọ̀ ìgboro níbi tí wọ́n dákú sí, tó ti rẹ̀ wọ́n, tí okun wọn sì ti tán Ìdárò 2:19; 4:1, 2) Wọn yóò ti mu ife ìhónú Ọlọ́run, wọn yóò sì máa wò duu bí ẹranko tó kó sínú àwọ̀n.
sí. (24, 25. (a) Kí ni kò ní tún ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù mọ́? (b) Lẹ́yìn Jerúsálẹ́mù, ta ló kàn tí yóò mú ife ìhónú Jèhófà?
24 Àmọ́ ipò tó bani lọ́kàn jẹ́ yìí máa dópin o. Aísáyà sọ̀rọ̀ ìtùnú pé: “Nítorí náà, jọ̀wọ́, fetí sí èyí, ìwọ obìnrin tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, tí ó sì ti mu àmupara, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe pẹ̀lú wáìnì. Èyí ni ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà, àní Ọlọ́run rẹ, tí ń báni fà á nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ wí: ‘Wò ó! Ṣe ni èmi yóò gba ife tí ń fa títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Gàásì náà, ife ìhónú mi—ìwọ kì yóò tún mu ún mọ́. Ṣe ni èmi yóò fi í sí ọwọ́ àwọn tí ń sún ọ bínú, àwọn tí ó sọ fún ọkàn rẹ pé, “Tẹ̀ ba kí a lè sọdá,” tí ó fi jẹ́ pé ṣe ni o máa ń ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀, àti bí ojú pópó fún àwọn tí ń sọdá.’” (Aísáyà 51:21-23) Lẹ́yìn tí Jèhófà ti bá Jerúsálẹ́mù wí, ó wá fẹ́ ṣàánú rẹ̀ wàyí, ó sì fẹ́ dárí jì í.
25 Jèhófà yóò wá ṣíwọ́ bíbínú sí Jerúsálẹ́mù, yóò wá dojú rẹ̀ kọ Bábílónì wàyí. Àmọ́ ṣá, Bábílónì yóò ti bá Jerúsálẹ́mù kanlẹ̀, yóò sì ti tẹ́ ẹ. (Sáàmù 137:7-9) Ṣùgbọ́n Jerúsálẹ́mù kì yóò tún mu nínú irú ife yìí mọ́ látọwọ́ Bábílónì àti àwọn alájọṣe rẹ̀. Dípò ìyẹn, ńṣe ni Jèhófà yóò gba ife yẹn kúrò lọ́wọ́ Jerúsálẹ́mù, yóò sì fún àwọn tó ń yọ̀ ọ́ torí pé wọ́n dójú tì í. (Ìdárò 4:21, 22) Àmuyó bìnàkò ni Bábílónì yóò mu, tí yóò fi ṣubú yakata. (Jeremáyà 51:6-8) Ṣùgbọ́n ní ti Síónì, ńṣe ni yóò gbéra sọ! Bábílónì tó da eérú leérú máa padà tọ̀! Dájúdájú, ìtùnú ni ìrètí yìí yóò jẹ́ fún Síónì. Ìyẹn mú un dá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé àwọn iṣẹ́ ìgbàlà Jèhófà yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 12 Ẹ̀rí fi hàn pé òólá tí ibí yìí ń sọ ni òólá tí ìdin rẹ̀ máa ń baṣọ jẹ́ gan-an.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 167]
Jèhófà tó jẹ́ Ábúráhámù Gíga Jù ni “àpáta” ti a ti “gbẹ́” àwọn èèyàn rẹ̀ “jáde”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 170]
Àwọn tí ń tako àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò pa rẹ́, bí aṣọ tí òólá ti jẹ tán
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 176, 177]
Jèhófà ti fi hàn pé òun lágbára lórí ààrá, ìgbì, ẹ̀fúùfù, oòrùn, òjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 178]
Ife tí Jerúsálẹ́mù ti mu yìí yóò kọjá sọ́dọ̀ Bábílónì àti àwọn alájọṣe rẹ̀