Òdodo Rú Jáde ní Síónì
Orí Kejìlélógún
Òdodo Rú Jáde ní Síónì
1, 2. Àyípadà wo ló máa tó dé bá Ísírẹ́lì, ta ni yóò sì mú àyípadà yẹn wá?
Ẹ KÉDE òmìnira! Jèhófà ti pinnu láti sọ àwọn èèyàn rẹ̀ dòmìnira kí ó sì dá wọn padà wá sí ilẹ̀ baba ńlá wọn. Bí irúgbìn tó hù lẹ́yìn òjò tó rọ̀ wọlẹ̀ dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni ìsìn tòótọ́ yóò ṣe tún padà rú jáde. Nígbà tí ọjọ́ yẹn bá dé, ìbànújẹ́ yóò yí padà di ìhó ìyìn, orí tó kún fún eérú nítorí ìbànújẹ́ tẹ́lẹ̀ yóò di èyí tó dádé ojú rere Ọlọ́run.
2 Ta ni yóò mú kí àyípadà àgbàyanu yìí wáyé? Jèhófà nìkan ló lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 9:19, 20; Aísáyà 40:25) Wòlíì Sefanáyà fi àsọtẹ́lẹ̀ pàṣẹ pé: “Fi ìdùnnú ké jáde, ìwọ ọmọbìnrin Síónì! Bú jáde nínú ìmóríyá gágá, ìwọ Ísírẹ́lì! Máa yọ̀, kí o sì fi gbogbo ọkàn-àyà yọ ayọ̀ ńláǹlà, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù! Jèhófà ti mú ìdájọ́ wọnnì kúrò lórí rẹ.” (Sefanáyà 3:14, 15) Ayọ̀ ìgbà yẹn yóò pọ̀ gan-an ni! Nígbà tí Jèhófà yóò bá fi kó àwọn àṣẹ́kù tó padà bọ̀ láti Bábílónì jọ pọ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, bí ẹni tí ń lá àlá ni yóò ṣe rí lójú wọn.—Sáàmù 126:1.
3. Àwọn ìmúṣẹ wo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí kọkànlélọ́gọ́ta ní?
3 Aísáyà orí kọkànlélọ́gọ́ta ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò yìí. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ ní kedere lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó tún ṣẹ ní kíkún sí i lákòókò mìíràn lẹ́yìn náà. Ṣíṣẹ tó tún ṣẹ ní kíkún sí i yìí kan Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní àti àwọn èèyàn Jèhófà òde òní. Ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí yìí á mà kún fún ìtumọ̀ gan-an o!
“Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà”
4. Nígbà tí Aísáyà 61:1 kọ́kọ́ ṣẹ, ta ni Jèhófà yàn láti sọ ìhìn rere, ta ló sì yàn nígbà tó ṣẹ lẹ́ẹ̀kejì?
4 Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára mi, nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè àti ìlajúsílẹ̀ rekete àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.” (Aísáyà 61:1) Ta ni Jèhófà yàn pé kó sọ ìhìn rere? Ó ṣeé ṣe kí ẹni àkọ́kọ́ jẹ́ Aísáyà, ẹni tí Ọlọ́run mí sí láti sọ ìhìn rere fún àwọn òǹdè tó wà ní Bábílónì. Ṣùgbọ́n, Jésù fi ọ̀nà pàtàkì jù lọ tí ọ̀rọ̀ Aísáyà gbà ṣẹ hàn nígbà tí ó sọ pé ó ṣẹ sí òun lára. (Lúùkù 4:16-21) Lóòótọ́, ńṣe ni Ọlọ́run rán Jésù láti wá sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù, ìyẹn ló fi fẹ̀mí mímọ́ yàn án nígbà tó ṣe ìrìbọmi.—Mátíù 3:16, 17.
5. Àwọn wo ló ti ń wàásù ìhìn rere láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn?
5 Ẹ̀wẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ajíhìnrere ni kí wọ́n jẹ́. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọgọ́fà lára àwọn wọ̀nyí la fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, wọ́n sì di ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 2:1-4, 14-42; Róòmù 8:14-16) Ọlọ́run yan àwọn náà láti máa sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù àti oníròbìnújẹ́. Àwọn ọgọ́fà yìí ni àkọ́kọ́ lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì táa máa fẹ̀mí yàn lọ́nà báyìí. Àwọn tó ṣẹ́ kù lára ẹgbẹ́ yìí ṣì ń báṣẹ́ lọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù ti ń wàásù nípa “ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù” láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn.—Ìṣe 20:21.
6. Àwọn wo ló rí ìtura gbà nípa gbígbọ́ tí wọ́n gbọ́ ìwàásù ìhìn rere láyé àtijọ́, àwọn wo ló sì ń rí i gbà lóde òní?
Mátíù 15:3-6) Lóde òní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi ìṣe àwọn Kèfèrí àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó tàbùkù sí Ọlọ́run kó nígbèkùn “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú ètò ìsìn yẹn. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Àwọn tó ṣègbọràn sí ìhìn rere lára wọn ń gba ìdáǹdè kúrò nínú ipò tó ṣeni láàánú yẹn. (Mátíù 9:35-38) Ojú ìmòye wọn sì là rekete nígbà tí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:24.
6 Iṣẹ́ onímìísí tí Aísáyà jẹ́ mú ìtura bá àwọn tó ti ronú pìwà dà lára àwọn Júù tó wà ní Bábílónì. Nígbà ayé Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó tún mú ìtura bá àwọn Júù tí ìròbìnújẹ́ bá nítorí ìwà ibi tó wà ní Ísírẹ́lì, tó sì jẹ́ pé wọ́n ń ráre nínú ìgbèkùn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ẹ̀sìn àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìíní. (7, 8. (a) Ẹ̀ẹ̀mejì wo ni “ọdún ìtẹ́wọ́gbà” ti wáyé? (b) Àwọn “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà wo ló wà?
7 Ó ní ìwọ̀n àkókò tí a ó fi wàásù ìhìn rere. Jèhófà pàṣẹ fún Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa; láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:2) Ọdún kan gùn lóòótọ́, àmọ́ ó ní ìbẹ̀rẹ̀ ó sì lópin. “Ọdún ìtẹ́wọ́gbà” lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ àkókò tí ó fi fún àwọn ọlọ́kàn tútù láǹfààní láti ṣègbọràn sí ìkéde òmìnira rẹ̀.
8 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọdún ìtẹ́wọ́gbà ti orílẹ̀-èdè àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 4:17) Ọdún ìtẹ́wọ́gbà yẹn wà títí di ìgbà “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà, èyí tó dé ògógóró rẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jèhófà yọ̀ǹda kí agbo ọmọ ogun Róòmù wá pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. (Mátíù 24:3-22) Lóde òní, à ń gbé ní ọdún ìtẹ́wọ́gbà mìíràn, èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914. Ọjọ́ ẹ̀san mìíràn tó máa kan àwọn ibi tó gbòòrò ju tàtẹ̀yìnwá lọ ni yóò jẹ́ òpin ọdún ìtẹ́wọ́gbà yìí, ìyẹn ni Jèhófà yóò fi pa gbogbo ètò àwọn nǹkan ayé yìí run nígbà “ìpọ́njú ńlá.”—Mátíù 24:21.
9. Lóde òní, àwọn wo ló ń jàǹfààní nínú ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà?
9 Lóde òní, àwọn wo ló ń jàǹfààní látinú ọdún ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run? Àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìhìn yìí ni, tí wọ́n fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù, tí wọ́n sì ń fi ìtara ṣètìlẹyìn fún ìpolongo Ìjọba Ọlọ́run ní “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń rí i pé ìhìn rere ń mú ìtùnú gidi wá. Àmọ́, àwọn tó bá kọ ìhìn yìí, tí wọ́n sì kọ̀ láti lo àǹfààní ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, yóò gba ìyà ọjọ́ ẹ̀san rẹ̀ láìpẹ́.—2 Tẹsalóníkà 1:6-9.
Èso Tẹ̀mí Tó Ń Ṣe Ọlọ́run Lógo
10. Ipa wo ni ohun ńláǹlà tí Jèhófà ṣe fún àwọn Júù tó ń padà bọ̀ láti Bábílónì ní lórí wọn?
10 Àwọn Júù tó padà bọ̀ láti Bábílónì rí i pé Jèhófà ti ṣe ohun ńláǹlà fún àwọn. Ọ̀fọ̀ tó bá wọn nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn yí padà di ayọ̀ ńláǹlà àti ìyìn nítorí pé wọ́n dòmìnira nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Nípa báyìí, Aísáyà jẹ́ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà rán an, ìyẹn ni, “láti yàn fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ fún Síónì, láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú, òróró ayọ̀ ńláǹlà dípò ọ̀fọ̀, aṣọ àlàbora ìyìn dípò ẹ̀mí ìsoríkodò; a ó sì máa pè wọ́n ní igi ńlá òdodo, ọ̀gbìn Jèhófà, kí a lè ṣe é lẹ́wà.”—Aísáyà 61:3.
11. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn wo ni kò lè ṣàìyin Jèhófà fún ohun ńláǹlà tó ṣe?
11 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Júù tó tẹ́wọ́ gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn ìsìn èké yin Ọlọ́run lógo bákan náà fún ohun ńláǹlà tó ṣe fún wọn. “Aṣọ àlàbora ìyìn” dípò ẹ̀mí ìsoríkodò tó ti bá wọn tẹ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe gba ìdáǹdè kúrò ní orílẹ̀-èdè tó ti kú nípa tẹ̀mí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí ní ti pé ọ̀fọ̀ tó bá wọn nítorí ikú Jésù yí padà di ayọ̀ Ìṣe 2:41) Ó mà dùn mọ́ wọn o pé ìbùkún Jèhófà wà fún wọn dájúdájú! Dípò kí wọ́n máa wá “ṣọ̀fọ̀ fún Síónì,” ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n gbà, tí “òróró ayọ̀ ńláǹlà,” tó ṣàpẹẹrẹ ayọ̀ ńlá tó wà fún àwọn tí Jèhófà bù kún jìngbìnnì, sì tù wọ́n lára.—Hébérù 1:9.
nígbà tí Olúwa wọn tó jíǹde fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Láìpẹ́ sí ìgbà náà, irú àyípadà kan náà yìí bá ẹgbẹ̀ẹ́dógún èèyàn tó ṣègbọràn sí ìwàásù àwọn Kristẹni táa ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀mí yàn yìí, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. (12, 13. (a) Àwọn wo ni “igi ńlá òdodo” láàárín àwọn Júù tó padà wálé lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Àwọn wo ló ti jẹ́ “igi ńlá òdodo” láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
12 Jèhófà fi àwọn “igi ńlá òdodo” jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn wo ni àwọn igi ńlá yìí? Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n jẹ́ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ṣàṣàrò lé e lórí, tí wọ́n wá dẹni tó ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. (Sáàmù 1:1-3; Aísáyà 44:2-4; Jeremáyà 17:7, 8) Irú àwọn èèyàn bí Ẹ́sírà, Hágáì, Sekaráyà, àti Jóṣúà Àlùfáà Àgbà, di àwọn “igi ńlá” tó dàràbà, wọ́n jẹ́ akọgun fún òtítọ́, wọ́n sì gbéjà ko ìwà ìbàjẹ́ nípa tẹ̀mí ní orílẹ̀-èdè náà.
13 Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa síwájú ni Ọlọ́run ti gbin àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró onígboyà tó jẹ́ irú àwọn “igi ńlá òdodo” bẹ́ẹ̀, sínú ipò tẹ̀mí tí orílẹ̀-èdè rẹ̀ tuntun, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wà. (Gálátíà 6:16) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, láti ìgbà yẹn wá, àwọn “igi” yìí wá di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tó ń so èso òdodo, èyí tó ń bu ẹwà kún Jèhófà Ọlọ́run, tó sì ń ṣe é lógo. (Ìṣípayá 14:3) Àwọn tó kẹ́yìn lára àwọn “igi” ràbàtà yìí ti ń gbilẹ̀ sí i láti ọdún 1919 tí Jèhófà ti mú àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì Ọlọ́run sọ jí kúrò nínú ipò àìsí ìgbòkègbodò tí wọ́n wà fúngbà kúkúrú. Jèhófà wá bu ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ omi nípa tẹ̀mí sí wọn, ìyẹn sì mú kí wọ́n dà bí igbó igi òdodo tó ń so èso.—Aísáyà 27:6.
14, 15. Iṣẹ́ wo ni àwọn olùjọsìn Jèhófà tó gba ìdáǹdè dáwọ́ lé lọ́dún (a) 537 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) 33 Sànmánì Tiwa? (d) 1919?
Aísáyà 61:4) Àwọn Júù olóòótọ́ tó padà bọ̀ láti Bábílónì ṣe gẹ́gẹ́ bí Kírúsì ọba Páṣíà ṣe pàṣẹ, wọ́n tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tó ti wà láhoro látìgbà pípẹ́ kọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò wáyé lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Tiwa àti ọdún 1919.
14 Aísáyà wá tẹnu bọ àlàyé nípa iṣẹ́ àwọn “igi” yìí, ó ní: “Wọn yóò sì tún àwọn ibi ìparundahoro tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ kọ́; wọn yóò gbé àwọn ibi ahoro ti ìgbà àtijọ́ dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ìlú ńlá tí a ti pa run dahoro di àkọ̀tun, àwọn ibi tí ó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran.” (15 Lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, ìbànújẹ́ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gidigidi nígbà tí wọ́n mú un, tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì pa á. (Mátíù 26:31) Àmọ́, ìbànújẹ́ wọn dayọ̀ nígbà tó fara hàn wọ́n lẹ́yìn tó jíǹde. Gbàrà tí wọ́n sì ti gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ní pẹrẹu, “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí mú ìsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò nìyẹn. Lọ́nà kan náà, láti ọdún 1919 síwájú ni Jésù Kristi ti mú kí àṣẹ́kù àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí tún “àwọn ibi tí ó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran” kọ́. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni àwùjọ àlùfáà àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ti fi ìmọ̀ Jèhófà kọ́ni rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tàwọn èèyàn àti àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ni wọ́n fi ń kọ́ni. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fọ àwọn ìṣe tó ní àbààwọ́n ìsìn èké kúrò nínú ìjọ wọn kí ìmúbọ̀sípò ìsìn tòótọ́ lè tẹ̀ síwájú. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, èyí tó jẹ́ pé ó máa tayọ gbogbo ìwàásù àtẹ̀yìnwá láyé yìí.—Máàkù 13:10.
16. Àwọn wo ló ń ran àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò yìí, iṣẹ́ wo ni wọ́n sì ń ṣe?
16 Iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí jẹ́. Báwo ni àwọn kéréje tó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí yóò ṣe lè ṣe iṣẹ́ ńlá yìí láṣeparí? Aísáyà 61:5) Àwọn àjèjì àti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù. * (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:11, 16) Wọn kò gba ẹ̀mí mímọ́ lọ́nà ti pé kí wọ́n lọ gba ogún ní ọ̀run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń retí láti gba ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3, 4) Síbẹ̀, wọ́n fẹ́ràn Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, iṣẹ́ àgbẹ̀, àti olùrẹ́wọ́ àjàrà. Iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kọ́ niṣẹ́ wọ̀nyẹn rárá. Àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n ń ṣètọ́jú àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kórè wọn wọlé lábẹ́ àbójútó àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì Ọlọ́run.—Lúùkù 10:2; Ìṣe 20:28; 1 Pétérù 5:2; Ìṣípayá 14:15, 16.
Jèhófà mí sí Aísáyà pé kí ó kéde pé: “Àwọn àjèjì yóò sì dúró ní ti tòótọ́, wọn yóò sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn agbo ẹran yín, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè sì ni yóò jẹ́ àgbẹ̀ yín àti olùrẹ́wọ́ àjàrà yín.” (17. (a) Kí ni a óò máa pe àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run? (b) Ẹbọ kan ṣoṣo wo ni a nílò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀?
17 Ísírẹ́lì Ọlọ́run wá ńkọ́ o? Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ fún wọn pé: “Ní ti ẹ̀yin, àlùfáà Jèhófà ni a óò máa pè yín; òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa ni a ó sọ pé ẹ̀yin jẹ́. Ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni ẹ ó jẹ, inú ògo wọn sì ni ẹ ó ti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó kún fún ayọ̀ nípa ara yín.” (Aísáyà 61:6) Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà gbé ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì kalẹ̀ pé kí wọ́n máa bá àwọn àlùfáà fúnra wọn àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn rúbọ. Àmọ́, lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà ṣíwọ́ lílo ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì, ó sì fi ìṣètò tó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́lẹ̀. Ó tẹ́wọ́ gba ìwàláàyè pípé ti Jésù pé ìyẹn gan-an ni ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Látìgbà náà wá, a kò tún nílò ẹbọ mìíràn mọ́. Títí gbére ni ẹbọ Jésù yóò máa báṣẹ́ lọ.—Jòhánù 14:6; Kólósè 2:13, 14; Hébérù 9:11-14, 24.
18. Irú ẹgbẹ́ àlùfáà wo ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run para pọ̀ jẹ́, kí sì ni iṣẹ́ tí wọ́n gbà?
1 Pétérù 2:9) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà tó gba iṣẹ́ pàtó kan, ìyẹn ni pé: kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ògo Jèhófà fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni wọ́n ní láti jẹ́. (Aísáyà 43:10-12) Ní gbogbo àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, iṣẹ́ pàtàkì yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi àìyẹhùn gbájú mọ́ lójú méjèèjì. Ìyẹn sì mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn wá dara pọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu iṣẹ́ jíjẹ́rìí nípa Ìjọba Jèhófà yìí.
18 Báwo wá ni àwọn tí í ṣe Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣe jẹ́ “àlùfáà Jèhófà”? Nígbà tí Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (19. Iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò láǹfààní láti ṣe?
19 Síwájú sí i, àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ìrètí pé àwọn yóò ṣe iṣẹ́ àlùfáà ní ọ̀nà mìíràn. Bí wọ́n bá ti kú, a óò jí wọn dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Yàtọ̀ sí pé wọn yóò bá Jésù jọba nínú Ìjọba rẹ̀ níbẹ̀, wọn yóò tún jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run. (Ìṣípayá 5:10; 20:6) Nípa bẹ́ẹ̀, wọn yóò láǹfààní láti lo àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù fún àwọn ọmọ aráyé olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nínú ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, èyí tó wà nínú Ìṣípayá orí kejìlélógún, wọ́n tún ṣàpèjúwe wọn níbẹ̀ pé wọ́n jẹ́ “àwọn igi.” Gbogbo “àwọn igi” yìí, tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ni ó sì rí ní ọ̀run, tí wọ́n “ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde . . . tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” (Ìṣípayá 22:1, 2) Áà, iṣẹ́ àlùfáà tí wọn yóò ṣe yìí ga lọ́lá o!
Ìtìjú àti Ìtẹ́lógo, Lẹ́yìn Náà Ayọ̀ Yíyọ̀
20. Láìfi àtakò pè, ìbùkún wo ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé yìí ń retí?
20 Àtakò ṣáá ni àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ń ṣe sí ẹgbẹ́ Ìṣípayá 12:17) Síbẹ̀síbẹ̀, pàbó ni gbogbo ìsapá wọn láti fòpin sí ìpolongo ìhìn rere náà já sí. Aísáyà ti sàsọtẹ́lẹ̀ èyí, ó ní: “Dípò ìtìjú yín, ìpín ìlọ́po méjì ni yóò wà, àti pé dípò ìtẹ́lógo, wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde nítorí ìpín wọn. Nítorí náà, ní ilẹ̀ wọn, wọn yóò gba ìpín ìlọ́po méjì. Ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni yóò wá jẹ́ tiwọn.”—Aísáyà 61:7.
àlùfáà aládé yìí láti ọdún 1914 tí ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀. (21. Báwo ló ṣe di pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gba ìpín ìlọ́po méjì ìbùkún?
21 Lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, Kirisẹ́ńdọ̀mù onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kó ìtìjú bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n sì tẹ́ wọn lógo. Àwọn tó jẹ́ ara àwùjọ àlùfáà wà nínú àwọn tó fẹ̀sùn èké kan àwọn olóòótọ́ arákùnrin mẹ́jọ ní orílé iṣẹ́ ní Brooklyn, pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Oṣù mẹ́sàn-án ni àwọn arákùnrin wọ̀nyí fi wà lẹ́wọ̀n láìtọ́. Níkẹyìn, ní ìgbà ìrúwé ọdún 1919, wọ́n dá wọn sílẹ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Bí ètekéte tí ọ̀tá pa láti fi dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà dúró ṣe wọmi nìyẹn o. Kàkà tí Jèhófà á fi gbà kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ gba ìtìjú fún ìgbà pípẹ́, ńṣe ló dá wọn nídè, tó sì dá wọn padà sínú ipò wọn nípa tẹ̀mí, ìyẹn “ilẹ̀ wọn.” Wọ́n wá gba ìpín ìlọ́po méjì ìbùkún níbẹ̀. Ìbùkún Jèhófà tí wọ́n rí gbà wá dí gbogbo ìyà tó ti jẹ wọ́n pátá, ó tún ṣèènì sí i. Ní tòótọ́, èyí tó mú wọn bú sí ayọ̀ o jàre!
22, 23. Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, báwo ló sì ṣe san èrè fún wọn?
22 Ohun tí Jèhófà tún sọ tẹ̀ lé e yìí tún fún àwọn Kristẹni òde òní ní ìdí mìíràn láti yọ̀, ó ní: “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, mo kórìíra ìjanilólè pa pọ̀ pẹ̀lú àìṣòdodo. Dájúdájú, Aísáyà 61:8) Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwọn ẹni àmì òróró kọ́ ti kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, àti láti kórìíra ìwà burúkú. (Òwe 6:12-19; 11:20) Wọ́n kọ́ láti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,” wọ́n sì wà láìdásí tọ̀tún tòsì nínú àwọn ogun àti rúkèrúdò ìṣèlú aráyé. (Aísáyà 2:4) Wọ́n tún yàgò fún àwọn ìṣe tó tàbùkù sí Ọlọ́run, irú bí ìbanilórúkọjẹ́, àgbèrè, olè jíjà, àti ìmutípara.—Gálátíà 5:19-21.
èmi yóò sì fi owó ọ̀yà wọn fún wọn ní òótọ́, májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò sì bá wọn dá.” (23 Nítorí bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo bíi ti Ẹlẹ́dàá wọn, Jèhófà wá fi “owó ọ̀yà wọn fún wọn ní òótọ́.” Irú “owó ọ̀yà” bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, ìyẹn májẹ̀mú tuntun, èyí tí Jésù kéde fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn kó tó kú. Májẹ̀mú yìí ni ohun tó mú wọn di orílẹ̀-èdè nípa tẹ̀mí, àti èèyàn àkànṣe fún Ọlọ́run. (Jeremáyà 31:31-34; Lúùkù 22:20) Lábẹ́ májẹ̀mú yìí ni Jèhófà yóò ti mú kí àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù ṣiṣẹ́, títí kan ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn yòókù tó bá jẹ́ olóòótọ́ lára ọmọ aráyé.
Yíyọ̀ Ayọ̀ Ńláǹlà Nínú Àwọn Ìbùkún Jèhófà
24. Àwọn wo ni “àwọn ọmọ” tó tinú àwọn orílẹ̀-èdè wá, tí wọn sì dẹni ìbùkún, báwo ni wọ́n sì ṣe di “ọmọ”?
24 Àwọn kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè rí i pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni Jèhófà tipa ìlérí yìí sọ, ó ní: “Ní ti tòótọ́, a ó mọ àwọn ọmọ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá, àti àwọn ọmọ ìran wọn láàárín àwọn ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò dá wọn mọ̀, pé àwọn ni ọmọ tí Jèhófà bù kún.” (Aísáyà 61:9) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ní àkókò ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Lóde òní, àwọn tó kọbi ara sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí. Bí àwọn tó tinú àwọn orílẹ̀-èdè wá yìí sì ṣe ń bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́, wọ́n láǹfààní láti di àwọn “ọmọ tí Jèhófà bù kún.” Ipò aláyọ̀ tí wọ́n wà sì hàn gbangba gbàǹgbà sí aráyé.
25, 26. Ọ̀nà wo ni gbogbo Kristẹni gbà fara mọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 61:10?
25 Gbogbo Kristẹni, yálà ẹni àmì òróró ni o, tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, ló ń wọ̀nà fún ìgbà tí wọn yóò lè yin Jèhófà títí láé. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi gbà pẹ̀lú wòlíì Aísáyà, tí ó sọ̀rọ̀ lábẹ́ ìmísí pé: “Láìkùnà, èmi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà. Ọkàn mi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run mi. Nítorí pé ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí; ó ti fi aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó jẹ́ ti òdodo bò mí, bí ọkọ ìyàwó tí ó wé ìwérí, bí ti àlùfáà, àti bí ìyàwó tí ó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.”—Aísáyà 61:10.
26 Bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti wọ “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó jẹ́ ti òdodo,” wọ́n pinnu láti wà ní mímọ́, láìlábààwọ́n, lójú Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 11:1, 2) Bí Jèhófà sì ṣe polongo wọn ní olódodo pé kí wọ́n lọ jogún ìyè ti ọ̀run, wọn kò ní padà sínú ipò ahoro inú Bábílónì Ńlá tí Jèhófà ti dá wọn nídè mọ́ láé. (Róòmù 5:9; 8:30) Aṣọ ìgbàlà ṣe iyebíye lójú wọn gidigidi. Bákan náà ni àwọn àgùntàn mìíràn alábàákẹ́gbẹ́ wọn sì ṣe pinnu láti pa àwọn ìlànà gíga tí Jèhófà Ọlọ́run fi lélẹ̀ fún ṣíṣe ìjọsìn mímọ́ mọ́. Bí ó sì ṣe jẹ́ pé ‘wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,’ wọ́n dẹni táa polongo ní olódodo, tí wọn yóò sì la “ìpọ́njú ńlá náà” já. (Ìṣípayá 7:14; Jákọ́bù 2:23, 25) Kó tó dìgbà náà, wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ti àwọn ẹni àmì òróró alábàákẹ́gbẹ́ wọn nípa yíyàgò fún gbogbo àbààwọ́n Bábílónì Ńlá.
27. (a) Lákòókò Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún, “ìrújáde” wo ni yóò wáyé? (b) Báwo ni òdodo ṣe ń rú jáde láàárín aráyé báyìí?
27 Lóde òní, ó dùn mọ́ àwọn olùjọsìn Jèhófà pé àwọn wà Aísáyà orí kọkànlélọ́gọ́ta ṣàpèjúwe ní kedere pé: “Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ayé ti ń mú ìrújáde rẹ̀ wá, àti gẹ́gẹ́ bí ọgbà ti ń mú kí àwọn nǹkan tí a fúnrúgbìn sínú rẹ̀ rú jáde, ní irú ọ̀nà kan náà ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò mú kí òdodo àti ìyìn rú jáde ní iwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 61:11) Lákòókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ‘òdodo yóò rú jáde’ ní ayé. Aráyé yóò wá hó ìhó ìṣẹ́gun, òdodo yóò sì gbilẹ̀ kárí ayé. (Aísáyà 26:9) Àmọ́ ṣá o, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé a ń dúró de ọjọ́ ológo yẹn kí a tó lè máa yin Jèhófà níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè. Ní báyìí, òdodo ń rú jáde láàárín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run tí wọ́n sì ń kéde ìhìn rere nípa Ìjọba rẹ̀. Àní nísinsìnyí pàápàá, ìgbàgbọ́ wa àti ìrètí wa ń mú kí a rí ìdí tó fi yẹ kí á máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú àwọn ìbùkún Ọlọ́run wa.
nínú párádísè tẹ̀mí. Láìpẹ́ wọn yóò gbádùn Párádísè tí a lè fojú rí. A ń fi gbogbo ọkàn wa retí àkókò yẹn, èyí tí ọ̀rọ̀ tó parí[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 16 Ó ṣeé ṣe kí Aísáyà 61:5 ṣẹ láyé àtijọ́, nítorí àwọn tí kì í ṣe Júù àbínibí bá àwọn Júù àbínibí padà wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèrànwọ́ láti mú ilẹ̀ náà padà bọ̀ sípò. (Ẹ́sírà 2:43-58) Àmọ́, ó jọ pé kìkì àwọn Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni ẹsẹ kẹfà síwájú kàn.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 323]
Aísáyà ní ìhìn rere tó fẹ́ polongo fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 331]
Láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni Jèhófà ti ń gbin àwọn “igi ńlá òdodo” tó jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 334]
Òdodo yóò rú jáde ní ayé