Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Fi Ìdùnnú Ké Jáde ní Ìsopọ̀ṣọ̀kan”!

“Ẹ Fi Ìdùnnú Ké Jáde ní Ìsopọ̀ṣọ̀kan”!

Orí Kẹtàlá

“Ẹ Fi Ìdùnnú Ké Jáde ní Ìsopọ̀ṣọ̀kan”!

Aísáyà 52:1-12

1. Kí ni ìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí kejìléláàádọ́ta fi jẹ́ orísun ìdùnnú, ọ̀nà méjì wo ni wọ́n sì gbà ṣẹ?

ÌDÁǸDÈ! Kí ni ì bá dùn mọ́ àwọn tó wà nígbèkùn láti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ju èyí lọ? Nígbà tí ìdáǹdè àti ìmúbọ̀sípò sì ti jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ pàtàkì kan nínú ìwé Aísáyà, kò yani lẹ́nu pé, yàtọ̀ sí ìwé Sáàmù kò tún sí ìwé mìíràn nínú Bíbélì tó lo onírúurú ọ̀rọ̀ ìdùnnú tó tirẹ̀. Aísáyà orí kejìléláàádọ́ta ní pàtàkì sọ ìdí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run fi ní láti máa yọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ orí yìí sì ṣẹ sára Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àmọ́ ìmúṣẹ rẹ̀ tó ga jù lọ ṣẹ sára “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ìyẹn ni ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, èyí tí a sábà máa ń ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìyá àti aya.—Gálátíà 4:26; Ìṣípayá 12:1.

“Gbé Okun Rẹ Wọ̀, Ìwọ Síónì!”

2. Ìgbà wo ni Síónì jí, báwo nìyẹn sí ṣe ṣẹlẹ̀?

2 Jèhófà gbẹnu Aísáyà ké sí Síónì, ìlú àyànfẹ́ Rẹ̀ pé: “Jí, jí, gbé okun rẹ wọ̀, ìwọ Síónì! Gbé ẹ̀wù rẹ ẹlẹ́wà wọ̀, ìwọ Jerúsálẹ́mù, ìlú ńlá mímọ́! Nítorí pé aláìdádọ̀dọ́ àti aláìmọ́ kì yóò tún wá sínú rẹ mọ́. Gbọn ekuru kúrò lára rẹ, dìde, mú ìjókòó, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Tú ọ̀já ọrùn rẹ fún ara rẹ, ìwọ òǹdè ọmọbìnrin Síónì.” (Aísáyà 52:1, 2) Nítorí pé àwọn ará Jerúsálẹ́mù mú Jèhófà bínú ni Jerúsálẹ́mù fi dahoro fún àádọ́rin ọdún. (2 Àwọn Ọba 24:4; 2 Kíróníkà 36:15-21; Jeremáyà 25:8-11; Dáníẹ́lì 9:2) Àmọ́, àsìkò wá tó wàyí fún ìlú yìí láti jí nínú ipò ìdákẹ́rọ́rọ́ tó wà, kí ó sì gbé ẹ̀wù ìdáǹdè wọ̀. Jèhófà ti darí ọkàn Kírúsì pé kí ó dá “òǹdè ọmọbìnrin Síónì” sílẹ̀, kí àwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù yìí àti irú ọmọ wọn lè kúrò ní Bábílónì kí wọ́n sì padà sí Jerúsálẹ́mù láti lọ mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Wọn kò gbọ́dọ̀ rí aláìdádọ̀dọ́ tàbí aláìmọ́ kankan ní Jerúsálẹ́mù.—Ẹ́sírà 1:1-4.

3. Èé ṣe tí a fi lè pe ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “ọmọbìnrin Síónì,” ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà gba ìdáǹdè?

3 Ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí tún ṣẹ sára ìjọ Kristẹni pẹ̀lú. A lè ṣàpèjúwe ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí “ọmọbìnrin Síónì” òde òní, nítorí pé “Jerúsálẹ́mù ti òkè” ni ìyá wọn. * Níwọ̀n bí Ọlọ́run sì ti dá àwọn ẹni àmì òróró nídè kúrò lábẹ́ ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà àti ti àwọn apẹ̀yìndà, dandan ni kí wọ́n máa wà ní ipò mímọ́ lójú Jèhófà, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n á lọ dádọ̀dọ́ nípa ti ara o, adọ̀dọ́ ọkàn-àyà wọn ni wọ́n máa dá. (Jeremáyà 31:33; Róòmù 2:25-29) Èyí kan wíwà ní mímọ́ lójú Jèhófà nípa tẹ̀mí, nínú èrò orí, àti ti ìwà híhù.—1 Kọ́ríńtì 7:19; Éfésù 2:3.

4. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Jerúsálẹ́mù ti òkè” kò ṣàìgbọràn sí Jèhófà rí, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn aṣojú rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, èyí tó rí gẹ́lẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará Jerúsálẹ́mù àtijọ́?

4 Lóòótọ́ o, “Jerúsálẹ́mù ti òkè” kò ṣàìgbọràn sí Jèhófà rí. Ṣùgbọ́n nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣèèṣì rú òfin Jèhófà nítorí pé wọn kò ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni wà láìdásí tọ̀tún tòsì. Ni Jèhófà bá bínú sí wọn, wọ́n wá dèrò ìgbèkùn nípa tẹ̀mí nínú “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 17:5) Ipò ìgbèkùn tí wọ́n wà dé ògógóró rẹ̀ ní June 1918 nígbà tí wọ́n kó òṣìṣẹ́ mẹ́jọ lára àwọn ọmọ àjọ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n lórí àwọn ẹ̀sùn èké, títí kan ẹ̀sùn pé wọ́n dìtẹ̀. Lásìkò tí à ń wí yìí, iṣẹ́ ìwàásù tí a fètò sí fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró. Àmọ́ lọ́dún 1919, ìpè ró gbọnmọ gbọnmọ pé kí kálukú wọn jí nípa tẹ̀mí o. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wá bẹ̀rẹ̀ sí yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ìwà àìmọ́ tara àti tẹ̀mí tí Bábílónì Ńlá ń hù. Báyìí ni wọ́n dìde nínú ekuru ìgbèkùn, tí “Jerúsálẹ́mù ti òkè” sì wá di èyí tó ń dán gbinrin bí “ìlú ńlá mímọ́” níbi tí kò ti sáyè fún àìmọ́ tẹ̀mí kankan.

5. Èé ṣe tí Jèhófà fi ní ẹ̀tọ́ pátápátá láti ra àwọn èèyàn rẹ̀ padà láìsí pé ó ń sanwó ìtanràn fún àwọn tó kó wọn nígbèkùn?

5 Jèhófà ní ẹ̀tọ́ pátápátá láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa àti lọ́dún 1919 Sànmánì Tiwa. Aísáyà ṣàlàyé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Lọ́fẹ̀ẹ́ ni a tà yín, láìsan owó sì ni a óò tún yín rà.’” (Aísáyà 52:3) Àti Bábílónì àtijọ́ o, àti Bábílónì Ńlá o, kò sí ìkankan lára wọn tó san ohunkóhun nígbà tí wọ́n sọ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú dẹrú. Níwọ̀n bí kò sì ti sí káràkátà nínú ọ̀ràn wọn, Jèhófà ṣì ni Olúwa lórí àwọn èèyàn rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kó lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni? Rárá o. Ọ̀nà méjèèjì ni Jèhófà ti lẹ́tọ̀ọ́ láti ra àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ padà láìsí pé ó ń sanwó ìtanràn fún àwọn tó kó wọn nígbèkùn.—Aísáyà 45:13.

6. Àwọn ẹ̀kọ́ wo látinú ìtàn ni àwọn ọ̀tá Jèhófà kò fi ṣàríkọ́gbọ́n?

6 Àwọn ọ̀tá Jèhófà kò fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ rí ṣàríkọ́gbọ́n rárá. A kà á pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: ‘Íjíbítì ni àwọn ènìyàn mi sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ìgbà àkọ́kọ́ láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀; láìnídìí, Ásíríà, ní tirẹ̀, sì ni wọ́n lára.’” (Aísáyà 52:4) Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, bẹ́ẹ̀ wọ́n sì pè wọ́n wá ilẹ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n wá gbé ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlejò àwọn ni o. Àmọ́, Jèhófà mú kí Fáráò àti agbo ọmọ ogun rẹ̀ kú sínú agbami Òkun Pupa. (Ẹ́kísódù 1:11-14; 14:27, 28) Nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà wá fòòró Jerúsálẹ́mù, áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] lára àwọn ọmọ ogun ọba yẹn. (Aísáyà 37:33-37) Bákan náà ni kò ṣe ní sí ìkankan nínú Bábílónì àti Bábílónì Ńlá tí yóò tẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ba gbé.

“Àwọn Ènìyàn Mi Yóò Mọ Orúkọ Mi”

7. Kí ló bá orúkọ Jèhófà nítorí wíwà tí àwọn èèyàn rẹ̀ wà nígbèkùn?

7 Wíwà tí àwọn èèyàn Jèhófà wà nígbèkùn ní ipa lórí orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe fi hàn, ó ní: “‘Wàyí o, kí ni mo nífẹ̀ẹ́ sí níhìn-ín?’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Nítorí pé lọ́fẹ̀ẹ́ ni a kó àwọn ènìyàn mi. Àwọn ẹni náà tí ń ṣàkóso lé wọn lórí ń hu ṣáá,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nígbà gbogbo, láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, sì ni a ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ mi. Fún ìdí yẹn, àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi, àní fún ìdí yẹn ní ọjọ́ yẹn, nítorí pé èmi ni Ẹni tí ń sọ̀rọ̀. Wò ó! Èmi ni.’” (Aísáyà 52:5, 6) Kí ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí nínú ọ̀ràn yẹn? Èwo ló kàn án nínú pé wọ́n sọ Ísírẹ́lì dẹrú ní Bábílónì? Jèhófà ní láti wá nǹkan ṣe sí i, nítorí pé àwọn èèyàn rẹ̀ ni Bábílónì kó nígbèkùn, tí wọ́n sì tún ń hó lé wọn lórí pé àwọn ṣẹ́gun. Yíyangàn tí Bábílónì ń yangàn yìí ló sún un débi híhùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 36:20, 21) Kò gbà pé inú ló bí Jèhófà sí àwọn èèyàn rẹ̀ tó fi jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù dahoro. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bábílónì gbà pé Ọlọ́run àwọn Júù kò lágbára ló jẹ́ kí òun lè kó wọn lẹ́rú. Àní Bẹliṣásárì tó ń bá baba rẹ̀ ṣàkóso pọ̀ tilẹ̀ gan Jèhófà nípa lílo àwọn ohun èlò inú tẹ́ńpìlì Rẹ̀ nígbà àsè tó fi ń bọlá fún àwọn òrìṣà Bábílónì.—Dáníẹ́lì 5:1-4.

8. Irú ọwọ́ wo ni wọ́n fi mú orúkọ Jèhófà láti ìgbà tí àwọn àpọ́sítélì ti kú tán?

8 Báwo ni gbogbo èyí ṣe kan “Jerúsálẹ́mù ti òkè” ná? Látìgbà tí ìpẹ̀yìndà ti fìdí múlẹ̀ láàárín àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn ni a ti lè sọ pé “orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí [wọn] láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 2:24; Ìṣe 20:29, 30) Àní sẹ́, nítorí gbígba èèwọ̀ asán gbọ́, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí yẹra fún lílo orúkọ Ọlọ́run. Kò pẹ́ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì tí àwọn apẹ̀yìndà Kristẹni fi gba àṣà yìí pẹ̀lú, wọ́n wá ṣíwọ́ lílo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́. Ìpẹ̀yìndà yìí ló yọrí sí ìdásílẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù, èyí tó jẹ́ apá pàtàkì nínú Bábílónì Ńlá. (2 Tẹsalóníkà 2:3, 7; Ìṣípayá 17:5) Ìṣekúṣe bí ajá àti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọ̀dájú Kirisẹ́ńdọ̀mù yìí ti tàbùkù sí orúkọ Jèhófà.—2 Pétérù 2:1, 2.

9, 10. Òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ wo ni àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú lóde òní wá ní nípa àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà àti orúkọ rẹ̀?

9 Nígbà tí Jésù Kristi, tó jẹ́ Kírúsì Ńlá náà, dá àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, òye ohun tí Jèhófà ń fẹ́ wá túbọ̀ yé wọn sí i. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n ti yọ púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù tó pilẹ̀ látinú ìbọ̀rìṣà tó ti wà ṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni kúrò nínú ìsìn wọn, irú bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti ìdálóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Wàyí o, wọ́n wá tún bẹ̀rẹ̀ sí yọ gbogbo nǹkan tó bá jẹ mọ́ ohun tó tinú Bábílónì wá kúrò nínú ìsìn wọn. Òye sì tún wá yé wọn nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n wà láìdásí tọ̀tún tòsì rárá nínú ọ̀ràn ìṣèlú ayé yìí. Àní wọ́n tilẹ̀ múra tán láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ nítorí bóyá òmíràn lára wọn ti lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.

10 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní tún wá ní òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ nípa bí orúkọ Jèhófà ti ṣe pàtàkì tó. Lọ́dún 1931, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ kéde fáyé gbọ́ pé alátìlẹyìn Jèhófà àti orúkọ rẹ̀ làwọn jẹ́. Ẹ̀wẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún lo Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n tẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1950, láti fi dá orúkọ Ọlọ́run padà sí ibi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì. Dájúdájú, wọ́n ti mọyì orúkọ Jèhófà, wọ́n sì ń sọ ọ́ di mímọ̀ jákèjádò ayé.

“Ẹni Tí Ń Mú Ìhìn Rere Wá”

11. Kí ni ìdí tí gbólóhùn tí wọ́n sọ lóhùn rara náà pé, “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!” fi bá a mu nítorí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?

11 Wàyí o, a wá dá àfiyèsí wa padà sí Síónì nígbà tó ṣì wà láhoro. Ońṣẹ́ kan ń mú ìhìn rere bọ̀, áà: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́, ẹni tí ń sọ fún Síónì pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti di ọba!’” (Aísáyà 52:7) Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, báwo la ṣe lè sọ pé Ọlọ́run Síónì ti di Ọba? Ìgbà wo ni Jèhófà ṣàìjẹ́ Ọba tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ná? Dájúdájú, òun mà ni “Ọba ayérayé” o! (Ìṣípayá 15:3) Àmọ́, gbólóhùn tí wọ́n sọ lóhùn rara yìí pé, “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!” bá a mu gan-an ni, nítorí pé ìṣubú Bábílónì àti ìkéde ọba tó sọ pé kí wọ́n lọ tún tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù kọ́, kí wọ́n sì dá ìsìn mímọ́ padà síbẹ̀ tún jẹ́ ọ̀nà tuntun kan tí Jèhófà gbà fi ipò ọba rẹ̀ hàn.—Sáàmù 97:1.

12. Ta ní mú ipò iwájú nínú ‘mímú ìhìn rere wá,’ ọ̀nà wo ló sì gbà mú un wá?

12 Nígbà ayé Aísáyà, kò sí ẹnì kan tàbí àwùjọ kan tí wọ́n dárúkọ ní pàtó pé òun ni “ẹni tí ń mú ìhìn rere wá.” Àmọ́ lóde òní, a mọ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá yìí. Jésù Kristi ni ońṣẹ́ àlàáfíà gíga jù lọ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wàásù ìhìn rere pé àwọn èèyàn á rí ìtúsílẹ̀ gbà kúrò nínú gbogbo nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ń fà bá wọn, títí kan àìsàn àti ikú. (Mátíù 9:35) Jésù fi àpẹẹrẹ onítara lélẹ̀ nípa kíkéde ìhìn rere ohun tí ó dára jù fáyé gbọ́, ó sì lo gbogbo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti fi kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 5:1, 2; Máàkù 6:34; Lúùkù 19:1-10; Jòhánù 4:5-26) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

13. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe mú ìtumọ̀ gbólóhùn yìí gbòòrò sí i, èyí tó sọ pé, “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o”? (b) Kí ni ìdí tí a fi lè sọ pé ẹsẹ̀ àwọn ońṣẹ́ yìí “dára rèǹtè-rente”?

13 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó lo ọ̀rọ̀ Aísáyà 52:7 láti fi tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ti ṣe pàtàkì tó. Ó béèrè ọ̀wọ́ àwọn ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, títí kan ‘Báwo làwọn èèyàn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?’ Ó wá ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!’” (Róòmù 10:14, 15) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe mú ìlò ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 52:7 gbòòrò sí i nìyẹn o, ó lo ọ̀rọ̀ náà, “àwọn,” tó fi hàn pé ẹni púpọ̀ ló ń bá wí, dípò ọ̀rọ̀ náà, “ẹni,” tí Aísáyà lò nínú ìwé rẹ̀, èyí tó tọ́ka sí ẹnì kan. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, gbogbo Kristẹni jẹ́ ońṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà. Ọ̀nà wo wá ni ẹsẹ̀ wọn gbà “dára rèǹtè-rente”? Aísáyà sọ̀rọ̀ bíi pé ńṣe ni ońṣẹ́ yìí ń gba ọ̀kan nínú àwọn òkè Júdà tó wà nítòsí bọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù. Èèyàn ò lè rí ẹsẹ̀ ońṣẹ́ yìí láti òkè réré. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ońṣẹ́ yìí gan-an ló gbàfiyèsí níhìn-ín, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dúró fún ońṣẹ́ náà fúnra rẹ̀. Gẹ́lẹ́ bí ó ṣe ń wu àwọn ọlọ́kàn tútù láti rí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó ń kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìhìn rere tó ń gbẹ̀mí là ṣe ń fẹ́ láti máa rí àwọn Ẹlẹ́rìí lóde òní.

14. Báwo ni Jèhófà ṣe di Ọba ní àsìkò òde òní, láti ìgbà wo ni a sì ti ń kéde èyí fáyé gbọ́?

14 Lóde òní, látìgbà wo la ti ń gbọ́ igbe pé, “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!”? Láti ọdún 1919 ni. Ní ìpàdé tó wáyé ní ìlú Cedar Point, Ohio, lọ́dún yẹn, J. F. Rutherford, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn fi ọ̀rọ̀ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àsọyé fún Àwọn Alájọṣiṣẹ́ Wa” ru àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sókè. Ó fi ọ̀rọ̀ tí ó gbé karí Aísáyà 52:7 àti Ìṣípayá 15:2 yìí rọ àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu. Bí àwọn ‘ẹsẹ̀ tó dára rèǹtè-rente’ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí hàn lórí “àwọn òkè ńlá” nìyẹn o. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló kọ́kọ́ ń fi ìtara jáde lọ láti wàásù ìhìn rere pé Jèhófà ti di Ọba, tí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” sì wá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn náà. (Jòhánù 10:16) Báwo wá ni Jèhófà ṣe di Ọba? Ó fi ipò ọba rẹ̀ hàn lákọ̀tun lọ́dún 1914 nígbà tó fi Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọ̀run. Jèhófà sì tún fi ipò ọba rẹ̀ hàn lọ́dún 1919 nígbà tó dá “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nídè kúrò nínú Bábílónì Ńlá.—Gálátíà 6:16; Sáàmù 47:8; Ìṣípayá 11:15, 17; 19:6.

“Àwọn Olùṣọ́ Rẹ Ti Gbé Ohùn Wọn Sókè”

15. Ta ni “àwọn olùṣọ́” tó gbé ohùn wọn sókè lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?

15 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kọbi ara sí ọ̀rọ̀ táa sọ lóhùn rara yìí pé, “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!” bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Aísáyà kọ ọ́ pé: “Fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ ti gbé ohùn wọn sókè. Ní ìsopọ̀ṣọ̀kan ni wọ́n ń fi ìdùnnú ké jáde; nítorí pé ojú ko ojú ni wọn yóò rí i nígbà tí Jèhófà bá kó Síónì jọ padà.” (Aísáyà 52:8) Kò sí olùṣọ́ kankan tí wọ́n yàn sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa pé kó máa kí àwọn ìgbèkùn tó kọ́kọ́ padà wálé káàbọ̀. Àádọ́rin ọdún ni ìlú náà fi wà láhoro. (Jeremáyà 25:11, 12) Nípa bẹ́ẹ̀, “àwọn olùṣọ́” tó gbé ohùn wọn sókè ní láti jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọ́kọ́ gbọ́ pé Síónì fẹ́ padà bọ̀ sípò, tí wọ́n sì wá ń tan ìhìn yẹn káàkiri ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Síónì yòókù. Nígbà tí àwọn olùṣọ́ yìí rí i bí Jèhófà ṣe fi Bábílónì lé Kírúsì lọ́wọ́ lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, kò sí iyèméjì rárá lọ́kàn wọn pé Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Àwọn olùṣọ́ yìí pa pọ̀ mọ́ àwọn tó kọbi ara sí ohun tí wọ́n wí wá ń fi ìdùnnú ké jáde ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n ń fi ìhìn rere yìí tó àwọn èèyàn yòókù létí.

16. Ta ni “àwọn olùṣọ́” yìí ń rí ní “ojú ko ojú,” lọ́nà wo sì ni?

16 Àárín àwọn olùṣọ́ tó wà lójúfò yìí àti Jèhófà dán mọ́rán gan-an ni, àfi bíi pé wọ́n ń rí i ní “ojú ko ojú” tàbí lójúkojú. (Númérì 14:14) Àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn àti Jèhófà àti èyí tí wọ́n ní láàárín ara wọn, ń fi ìṣọ̀kan wọn hàn àti bí ìhìn wọn ṣe jẹ́ onídùnnú tó.—1 Kọ́ríńtì 1:10.

17, 18. (a) Báwo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ ti òde òní ṣe gbé ohùn wọn sókè? (b) Ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí gbà ń fi ìṣọ̀kan ké jáde?

17 Nígbà tí ọrọ̀ yìí ṣẹ lóde òní, ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà, tí í ṣe “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kò ké jáde sí àwọn tó ti wà nínú ètò àjọ Ọlọ́run tí a lè fojú rí nìkan wọ́n tún ké sí àwọn tí kò sí nínú ètò àjọ yìí pẹ̀lú. (Mátíù 24:45-47) Lọ́dún 1919, ìpè kan jáde pé kí wọ́n kó àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró jọ, nígbà tó sì di ọdún 1922 ìpè yìí túbọ̀ ró gbọnmọ gbọnmọ ní àpéjọpọ̀ ti ìlú Cedar Point, Ohio, níbi tí wọ́n ti rọ̀ wọ́n pé, “ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Láti ọdún 1935 ni àfiyèsí sì ti yí sí kíkó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn ẹni bí àgùntàn jọ. (Ìṣípayá 7:9, 10) Lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, ìpolongo nípa ipò ọba Jèhófà ti ró gbọnmọ gbọnmọ sí i. Lọ́nà wo? Lọ́dún 2000, nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ọ̀kẹ́ ló ń sọ̀rọ̀ ipò ọba Jèhófà ní àwọn orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ. Síwájú sí i, Ilé Ìṣọ́, tó jẹ́ olórí ohun èlò tí ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí ń lò, ń gbé ìhìn ayọ̀ yìí jáde ní èdè tó ju àádóje lọ.

18 Ó gba ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni kéèyàn tó lè kópa nínú iṣẹ́ tí ń soni pọ̀ ṣọ̀kan yìí. Kí ìpè yìí sì tó lè múná dóko, gbogbo àwọn tó ń wàásù yìí ní láti máa wàásù ìhìn kan náà, kí wọ́n máa sọ nípa orúkọ Jèhófà, ìràpadà tó pèsè, ọgbọ́n rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀. Bí àwọn Kristẹni kárí ayé tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, àárín àwọn àti Jèhófà á túbọ̀ máa dán mọ́nrán sí i, wọn yóò sì lè máa fi ìṣọ̀kan kéde ìhìn ayọ̀ yìí.

19. (a) Báwo ni àwọn “ibi ìparundahoro Jerúsálẹ́mù” ṣe tújú ká? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn”?

19 Bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń fi ayọ̀ ké jáde, ńṣe ló dà bíi pé ibi tí wọ́n ń gbé pàápàá tújú ká. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tẹ̀ síwájú pé: “Ẹ tújú ká, ẹ fi ìdùnnú ké jáde ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ibi ìparundahoro Jerúsálẹ́mù, nítorí pé Jèhófà ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú; ó ti tún Jerúsálẹ́mù rà. Jèhófà ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.” (Aísáyà 52:9, 10) Bí àwọn àbọ̀dé Bábílónì ṣe ń dé, àwọn ibi àríbanújẹ́ nínú ahoro Jerúsálẹ́mù wá ń dùn-ún wò nítorí pé ìjọsìn mímọ́ Jèhófà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun wàyí. (Aísáyà 35:1, 2) Ó sì dájú pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀ràn yìí. Jèhófà “ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn,” àfi bíi pé ó ká ọwọ́ ẹ̀wù rẹ̀ sókè, kí ó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.—Ẹ́sírà 1:2, 3.

20. Kí ló ti jẹ yọ látinú fífi tí Jèhófà fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn láyé òde òní, kí ló sì ń bọ̀ wá jẹ yọ?

20 Ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, Jèhófà ti fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn láti lè mú àwọn ẹni àmì òróró, ‘àwọn ẹlẹ́rìí méjì’ tí ìwé Ìṣípayá wí sọ jí. (2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 11:3, 7-13) Láti ọdún 1919 ni wọ́n ti wọnú párádísè nípa tẹ̀mí, ìyẹn àgbègbè ìgbòkègbodò wọn nípa tẹ̀mí, èyí tí àwọn àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn ẹlẹgbẹ́ wọn jọ ń lò pa pọ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà yóò fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là ní “Ha-Mágẹ́dọ́nì.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Nígbà yẹn, “gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.”

Ohun Tó Di Dandan Láti Ṣe Kíákíá

21. (a) Kí ló di dandan pé kí àwọn tó “ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà” ṣe? (b) Kí nìdí tí àwọn Júù tó ń lọ kúrò ní Bábílónì kò fi ní láti bẹ̀rù?

21 Àwọn tó jáde kúrò ní Bábílónì láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù ní àwọn ohun tó di dandan láti ṣe. Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀, ẹ wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà. Nítorí pé ẹ kì yóò jáde lọ nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì, ẹ kì yóò sì lọ nínú fífẹsẹ̀fẹ. Nítorí pé Jèhófà yóò máa lọ àní níwájú yín, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn yín.” (Aísáyà 52:11, 12) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń lọ kúrò ní Bábílónì ní láti fi ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìsìn èké Bábílónì sílẹ̀ lọ́hùn-ún ni o. Àwọn nǹkan èlò Jèhófà tó tinú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù wá ni wọ́n gbé, nítorí náà kì í ṣe òde ara nìkan ni wọ́n ní láti wà ní mímọ́, ìyẹn lọ́nà ti ààtò ìsìn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, inú ọkàn-àyà wọn ní láti mọ́ pẹ̀lú. (2 Àwọn Ọba 24:11-13; Ẹ́sírà 1:7) Síwájú sí i, Jèhófà ló ń ṣáájú wọn lọ, nítorí náà, kò sídìí fún wọn láti bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni kò sí pé wọ́n ń sáré kìtàkìtà bíi pé àwọn elèṣù ẹ̀dá ń gbá tọ̀ wọ́n bọ̀ lẹ́yìn. Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn wọn.—Ẹ́sírà 8:21-23.

22. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ ṣíṣe tó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ́ tónítóní?

22 Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ nípa wíwà ní mímọ́ yìí ṣẹ sí irú ọmọ “Jerúsálẹ́mù ti òkè” lára ní pàtàkì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ ìṣítí fún àwọn Kristẹni ti Kọ́ríńtì pé kí wọ́n má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Aísáyà 52:11 pé: “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Gẹ́lẹ́ bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń darí lọ sílé láti Bábílónì náà ni àwọn Kristẹni ṣe ní láti yàgò pátápátá fún ìsìn èké Bábílónì pẹ̀lú.

23. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ti ń rí i dájú pé àwọn wà ní mímọ́?

23 Ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tí wọ́n sá kúrò ní Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919 ní pàtàkì. Ńṣe ni wọ́n já gbogbo ohun tó bá sáà ti jẹ mọ́ ti ìsìn èké dà nù pátá lọ́kọ̀ọ̀kan. (Aísáyà 8:19, 20; Róòmù 15:4) Òye sì túbọ̀ ń yé wọn sí i pẹ̀lú nípa bí híhùwà mímọ́ ti ṣe pàtàkì tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fìgbà kankan rí fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn híhùwà títọ́, Ile-Iṣọ Na gbé ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan jáde lọ́dún 1952, tó tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti bá àwọn tó ṣe ìṣekúṣe wí kí ìjọ lè wà ní mímọ́. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ sì tún ń ran ẹni tó hùwà àìtọ́ lọ́wọ́ láti rí ìdí tó fi yẹ kí òun ronú pìwà dà látọkàn wá.—1 Kọ́ríńtì 5:6, 7, 9-13; 2 Kọ́ríńtì 7:8-10; 2 Jòhánù 10, 11.

24. (a) Kí ni “àwọn nǹkan èlò Jèhófà” lóde òní? (b) Èé ṣe tí àwọn Kristẹni òde òní fi ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò máa ṣáájú wọn nìṣó tí yóò sì máa bá a lọ láti jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn wọn?

24 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pa pọ̀ mọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn ti pinnu láti má ṣe fọwọ́ kan ohunkóhun tó jẹ́ àìmọ́ nípa tẹ̀mí. Sísọ tí a ti sọ wọ́n di mímọ́ tónítóní mú kí wọ́n tóótun láti di ẹni tí ń gbé “àwọn nǹkan èlò Jèhófà,” ìyẹn àwọn ìpèsè oníyebíye tí Ọlọ́run pèsè fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́, èyí tí a ń lò fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ilé dé ilé àti fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni yòókù. Bí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní bá ti ń bá a lọ láti wà ní mímọ́, kí ó dá wọn lójú pé Jèhófà yóò máa ṣáájú wọn nìṣó, yóò sì máa bá a lọ láti jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn wọn. Bí wọ́n sì ṣe jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, wọ́n mà ní ìdí púpọ̀ rẹpẹtẹ láti máa “fi ìdùnnú ké jáde ní ìsopọ̀ṣọ̀kan” o!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 3 Wo Orí kẹẹ̀ẹ́dógún ìwé yìí fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò nípa àjọṣe tó wà láàárín “Jerúsálẹ́mù ti òkè” àti àwọn ọmọ rẹ̀ ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 183]

Síónì yóò rí ìdáǹdè gbà kúrò nígbèkùn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 186]

Láti ọdún 1919 ni àwọn ‘ẹsẹ̀ tó dára rèǹtè-rente’ tún ti ń hàn ní orí “àwọn òkè ńlá”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 189]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ ní ìsopọ̀ṣọ̀kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 192]

Àwọn tó “ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà” ní láti mọ́ nínú ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí