‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
Orí Kẹrìndínlọ́gbọ̀n
‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
1. Ọ̀rọ̀ tó fini lọ́kàn balẹ̀ wo ni àpọ́sítélì Pétérù kọ, ìbéèrè wo ló sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ yọ?
ǸJẸ́ àìṣèdájọ́ òdodo àti ìyà tí ń jẹni tiẹ̀ lè dópin láé bí? Ní ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pétérù kọ ọ̀rọ̀ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Pétérù àti ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, ti ń wọ̀nà fún ọjọ́ ńlá náà tí ìwà ta-ni-yóò-mú-mi, ìninilára, àti ìwà ipá yóò dópin, tí òdodo yóò sì jọba. Ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè ní ìdánilójú pé ìlérí yìí yóò ṣẹ?
2. Wòlíì wo ló sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” àwọn ọ̀nà wo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ àtọdúnmọ́dún yẹn ti gbà ṣẹ?
2 Bẹ́ẹ̀ ni o! Nígbà tí Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” kì í ṣe pé ó ń sọ ohun tí ẹnì kan ò tíì sọ rí. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Jèhófà ti gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ìlérí tó ti wà tipẹ́tipẹ́ yìí ṣẹ lọ́nà kékeré lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn Júù gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn Bábílónì, èyí tó mú kí wọ́n lè padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ń ṣẹ lọ́nà tó bùáyà lóde òní, a sì ń retí ìgbà tí yóò tún ṣẹ lọ́nà tó tiẹ̀ túbọ̀ wúni lórí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí ń bọ̀. Ní tòótọ́, ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ dídùnmọ́ni tí Ọlọ́run
gbẹnu Aísáyà sọ jẹ́ ká rí fìrífìrí àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣètò sílẹ̀ de àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀.Jèhófà Bá “Àwọn Alágídí” Sọ̀rọ̀
3. Ìbéèrè wo ni Aísáyà orí karùndínláàádọ́rin dáhùn fún wa?
3 Rántí pé, nínú Aísáyà 63:15–64:12, Aísáyà gbàdúrà lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nítorí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Ọ̀rọ̀ Aísáyà mú un ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò sin Jèhófà tọkàntọkàn, àmọ́ ó fi hàn pé àwọn kan ronú pìwà dà wọ́n sì yí padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ Jèhófà á tìtorí àṣẹ́kù tó ní ìròbìnújẹ́ yìí mú kí orílẹ̀-èdè yẹn bọ̀ sípò? A rí ìdáhùn rẹ̀ nínú Aísáyà orí karùndínláàádọ́rin. Ṣùgbọ́n kí Jèhófà tó ṣe ìlérí ìdáǹdè yìí fún àwọn mélòó kan tó jẹ́ olóòótọ́, ó kọ́kọ́ ṣàpèjúwe ìdájọ́ tí ń bẹ níwájú fún ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn tí kò ní ìgbàgbọ́.
4. (a) Àwọn wo ló máa wá Jèhófà, tí wọn kò ní ṣe bíi tàwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn Jèhófà? (b) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ Aísáyà 65:1, 2?
4 Jèhófà fara da ṣíṣọ̀tẹ̀ tí àwọn èèyàn rẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ léraléra. Àmọ́, ìgbà ń bọ̀ tí yóò jọ̀wọ́ wọn fún àwọn ọ̀tá wọn, yóò sì wá ṣojú rere sí àwọn mìíràn. Ìyẹn ni Jèhófà fi gbẹnu Aísáyà sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò béèrè mi wá mi kiri. Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò wá mi rí mi. Mo ti wí pé, ‘Èmi rèé, èmi rèé!’ fún orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi.” (Aísáyà 65:1) Ó bani nínú jẹ́ láti gbọ́ pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò tọ Jèhófà wá, ṣùgbọ́n Júdà olóríkunkun, tó jẹ́ àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú, yóò kọ̀ láti tọ̀ ọ́ wá lápapọ̀. Aísáyà nìkan kọ́ ni wòlíì tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa padà wá yan àwọn èèyàn tí kò kà sí tẹ́lẹ̀ rí. (Hóséà 1:10; 2:23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 65:1, 2 yọ látinú Bíbélì Septuagint láti fi ti àlàyé rẹ̀ lẹ́yìn pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò gba “òdodo tí ń jẹyọ láti inú ìgbàgbọ́” bí àwọn Júù àbínibí tiẹ̀ kọ̀ láti gbà á.—Róòmù 9:30; 10:20, 21.
5, 6. (a) Kí ni Jèhófà fi hàn pé ó wu òun gidigidi pé kó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ìhà wo ni àwọn èèyàn rẹ̀ kọ sí i? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ látinú ìwà tí Jèhófà hù sí Júdà?
Aísáyà 65:2) Béèyàn bá tẹ́ ọwọ́, a jẹ́ pé ńṣe ló ń ké síni tàbí pé ó ń pàrọwà. Ìgbà kúkúrú kọ́ ni Jèhófà sì fi tẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ó tẹ́ ẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni. Ó wù ú gidigidi pé kí Júdà yí padà sọ́dọ̀ òun. Síbẹ̀, etí dídi làwọn alágídí yìí kọ sí i.
5 Jèhófà ṣàlàyé ìdí tí òun yóò fi gbà kí àjálù bá àwọn èèyàn òun, ó ní: “Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ sí àwọn alágídí, àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára, tọ ìrònú wọn lẹ́yìn.” (6 Ẹ̀kọ́ táa rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí mà dùn mọ́ni o! Ìyẹn ni pé, ó ń fẹ́ ká sún mọ́ òun nítorí òun jẹ́ Ọlọ́run tó ṣeé sún mọ́. (Jákọ́bù 4:8) Ọ̀rọ̀ yìí sì tún fi hàn wá pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà. (Sáàmù 113:5, 6) Àní bí ìwà agídí àwọn èèyàn rẹ̀ tiẹ̀ ṣe “mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́” yìí pàápàá, kò ká ọwọ́ tó tẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ mọ́ra rárá, ó ṣì ń rọ̀ wọ́n ni, pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun. (Sáàmù 78:40, 41) Ẹ̀yìn ìgbà tó ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún rọ̀ wọ́n ló tó jọ̀wọ́ wọn fún àwọn ọ̀tá wọn níkẹyìn. Síbẹ̀síbẹ̀, kò kẹ̀yìn sí àwọn tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ láàárín wọn.
7, 8. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alágídí tó jẹ́ èèyàn Jèhófà gbà ń mú inú bí i?
7 Léraléra làwọn Júù alágídí ń fi ìwà wọn tó tini lójú ṣe ohun tó ń bí Jèhófà nínú. Jèhófà ṣàpèjúwe àwọn ìṣe wọn tó ń bíni nínú, ó ní: “Àwọn ènìyàn tí ó para pọ̀ jẹ́ àwọn tí ń mú mi bínú ní ojú mi gan-an nígbà gbogbo, àwọn tí ń rúbọ nínú àwọn ọgbà, tí wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn bíríkì, àwọn tí ń jókòó sáàárín àwọn ibi ìsìnkú, àní tí wọ́n tún ń sun inú àwọn ahéré ìṣọ́ mọ́jú, tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, àní omitoro àwọn ohun tí a sọ di àìmọ́ wà nínú àwọn ohun èlò wọn; àwọn tí ń sọ pé, ‘Dá dúró gedegbe. Má ṣe sún mọ́ mi, nítorí pé èmi yóò mú ìjẹ́mímọ́ wá fún ọ dájúdájú.’ Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi, wọ́n jẹ́ iná tí ń jó Aísáyà 65:3-5) Ńṣe làwọn tó ń ṣe bíi pé wọ́n ní ìtara ìsìn yìí kúkú ń ṣe ohun tó ń mú Jèhófà bínú ‘ní ojú rẹ̀ gan-an,’ èyí tó ṣeé ṣe kó fi hàn pé wọ́n ń hùwà àfojúdi àti ọ̀yájú. Wọn ò kàn tiẹ̀ fi ìwà ìríra wọn bò rárá ni. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹni tó bá kúkú wá ń dẹ́ṣẹ̀ níṣojú Ẹni tó yẹ kó bọ̀wọ̀ fún kó sì gbọ́ràn sí lẹ́nu jẹ dẹndẹ ìyà?
láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (8 Ìtumọ̀ ohun tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn yìí ń sọ fún àwọn Júù yòókù ni pé: ‘Máà dé sàkáání mi o, nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.’ Áà, àgàbàgebè wọn mà pọ̀ o! Àwọn “onítara ìsìn” yìí ń rúbọ, wọ́n sì ń sun tùràrí sí àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, bẹ́ẹ̀, Òfin Ọlọ́run sì ka ìyẹn léèwọ̀ o. (Ẹ́kísódù 20:2-6) Wọ́n ń jókòó sáàárín àwọn ibi ìsìnkú, ìyẹn sì mú kí wọ́n di aláìmọ́ lójú ohun tí Òfin wí. (Númérì 19:14-16) Wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ tó jẹ́ oúnjẹ aláìmọ́. * (Léfítíkù 11:7) Síbẹ̀ ààtò ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ṣì mú kí wọ́n ka ara wọn sí ẹni tó mọ́ ju àwọn Júù yòókù lọ, tí wọn kò fi fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dé sàkáání wọn, kí wọ́n má bàa tipa fífara kan àwọn di ẹni mímọ́. Àmọ́, irú ojú tí Ọlọ́run tó ń béèrè “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe” fi ń wo ọ̀ràn wọn kọ́ nìyẹn o!—Diutarónómì 4:24.
9. Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn?
9 Dípò tí Jèhófà yóò fi ka àwọn tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn yìí sí ẹni mímọ́, ohun tó sọ ni pé: “Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi.” Lédè Hébérù, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń pe “imú” tàbí “ihò imú” láti fi ṣàpẹẹrẹ ìbínú. A sì sọ̀rọ̀ èéfín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Diutarónómì 29:20) Ńṣe ni ìbọ̀rìṣà ẹlẹ́gbin tí àwọn èèyàn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mú kí ìbínú Jèhófà ru lọ́nà tó gbóná.
10. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe san ẹ̀san fún àwọn ará Júdà nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn?
Aísáyà 65:6, 7) Bí àwọn Júù ṣe ń bọ̀rìṣà, ńṣe ni wọ́n gan Jèhófà. Wọ́n wá mú kó dà bí pé ìsìn Ọlọ́run tòótọ́ kò sàn ju tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Nítorí “àwọn ìṣìnà wọn,” títí kan ìbọ̀rìṣà àti ìbẹ́mìílò, ṣe ni Jèhófà yóò san ẹ̀san iṣẹ́ wọn “sí oókan àyà tiwọn.” Ó dájú pé gbólóhùn yìí, “oókan àyà,” ń tọ́ka sí ibi tí wọ́n máa ń ṣẹ́ po lápá òkè ẹ̀wù láti fi gba hóró ọkà tí òǹtajà bá wọ̀n. (Lúùkù 6:38) Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí fún àwọn Júù apẹ̀yìndà sì dájú, òun ni pé Jèhófà yóò wọn “ẹ̀san” tàbí ìyà fún wọn. Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo yóò san wọ́n lẹ́san. (Sáàmù 79:12; Jeremáyà 32:18) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Jèhófà kì í yí padà, kí ó dá wa lójú pé tí àkókò tirẹ̀ bá ti tó, yóò mú ẹ̀san wá sórí ètò àwọn nǹkan burúkú yìí bákan náà.—Málákì 3:6.
10 Nítorí pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, kò ní jẹ́ kí àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yìí lọ láìjìyà. Aísáyà kọ̀wé pé: “‘Wò ó! A kọ̀wé rẹ̀ síwájú mi. Èmi kì yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó dájú pé èmi yóò san ẹ̀san; àní èmi yóò san ẹ̀san náà sí oókan àyà tiwọn dájúdájú, fún àwọn ìṣìnà wọn àti fún àwọn ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn lẹ́ẹ̀kan náà,’ ni Jèhófà wí. ‘Nítorí pé wọ́n ti rú èéfín ẹbọ lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ti gàn mí lórí àwọn òkè kéékèèké, ṣe ni èmi yóò kọ́kọ́ díwọ̀n owó ọ̀yà wọn sí oókan àyà wọn.’” (“Nítorí Àwọn Ìránṣẹ́ Mi”
11. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun yóò gba àṣẹ́kù olóòótọ́ là?
11 Ǹjẹ́ Jèhófà á ṣàánú àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn èèyàn rẹ̀? Aísáyà ṣàlàyé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Lọ́nà kan náà tí a gbà ń rí wáìnì tuntun nínú òṣùṣù, tí ẹnì kan yóò sì wá sọ pé, “Má bà á jẹ́, nítorí pé ìbùkún wà nínú rẹ̀,” bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí àwọn ìránṣẹ́ mi, kí n má bàa run gbogbo wọn. Dájúdájú, èmi yóò sì mú ọmọ kan jáde wá láti Jékọ́bù àti láti Júdà olùni àwọn òkè ńlá mi gẹ́gẹ́ bí ohun ìní Aísáyà 65:8, 9) Jèhófà lo àpèjúwe tí yóò tètè yé àwọn èèyàn rẹ̀, ó fi wọ́n wé òṣùṣù èso àjàrà. Èso àjàrà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, ìbùkún sì ni wáìnì tí wọ́n bá fi èso àjàrà ṣe jẹ́ fún aráyé. (Sáàmù 104:15) Ó ṣeé ṣe kí òṣùṣù tí àpèjúwe yìí ń sọ jẹ́ òṣùṣù kan tí àwọn kan lára èso ara rẹ̀ dára tí àwọn kan kò sì dára. Ó sì ṣeé ṣe kí àpèjúwe tó ń sọ fi hàn pé òṣùṣù kan péré ló dára, nígbà tí àwọn òṣùṣù yòókù kò gbó tàbí pé wọ́n rà. Èyí ó wù kó jẹ́, olùtọ́jú ọgbà náà kò sáà ní run àwọn èso àjàrà tó dára. Jèhófà wá tipa bẹ́ẹ̀ mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé òun ò ní pa orílẹ̀-èdè wọn run ráúráú, bí kò ṣe pé òun yóò dá àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ sí. Ó ní àwọn àṣẹ́kù tí òun ṣojú rere sí wọ̀nyí yóò jogún “àwọn òkè ńlá” òun, ìyẹn Jerúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Júdà, ẹkùn olókè ńláńlá tí Jèhófà sọ pé ó jẹ́ tòun.
àjogúnbá; àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì gbà á, àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò sì máa gbé níbẹ̀.’” (12. Àwọn ìbùkún wo ló wà níwájú fún àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́?
12 Àwọn ìbùkún wo ní ń bẹ níwájú fún àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ yìí? Jèhófà ṣàlàyé pé: “Ṣárónì yóò sì di ilẹ̀ ìjẹko fún àwọn àgùntàn, pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Ákórì yóò sì di ibi ìsinmi fún àwọn màlúù, fún àwọn ènìyàn mi tí yóò ti wá mi.” (Aísáyà 65:10) Ipa pàtàkì ni agbo ẹran kó nínú ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn Júù, tí ilẹ̀ ìjẹko bá sì pọ̀ rẹpẹtẹ, ó máa ń mú kí wọ́n láásìkí ní àkókò àlàáfíà. Jèhófà tọ́ka ibi méjì tó jẹ́ ìpẹ̀kun kan sí ìkejì ní ilẹ̀ náà láti fi ṣe àpèjúwe àlàáfíà àti aásìkí. Ó tọ́ka sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì níhà ìlà oòrùn, èyí tó tẹ́ rẹrẹ ní Etíkun Mẹditaréníà, a sì mọ̀ ọ́n dáadáa pé ó jẹ́ ilẹ̀ ẹlẹ́wà àti ọlọ́ràá. Àfonífojì Ákórì jẹ́ ara ààlà ilẹ̀ náà ní apá àríwá ìlà oòrùn. (Jóṣúà 15:7) Nígbà ìgbèkùn wọn lọ́jọ́ iwájú, gbogbo ilẹ̀ àwọn ibi tí à ń wí yìí ni yóò dahoro pọ̀ mọ́ ìyókù ilẹ̀ Júdà. Àmọ́, Jèhófà ṣèlérí pé lẹ́yìn ìgbà ìgbèkùn, wọn yóò di ilẹ̀ ìjẹko tó tutù yọ̀yọ̀ fún àwọn àṣẹ́kù tó padà bọ̀ láti ìgbèkùn.—Aísáyà 35:2; Hóséà 2:15.
Wọ́n Gbẹ́kẹ̀ Lé “Ọlọ́run Oríire”
13, 14. Àwọn ìṣe wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ti kẹ̀yìn sí i, kí ni ìyẹn yóò sì fà bá wọn?
13 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá padà sórí ọ̀rọ̀ àwọn tó kọ Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì di abọ̀rìṣà paraku. Ó ní: “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ àwọn tí ń fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn tí ń gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire, àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.” (Aísáyà 65:11) Ìṣe àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ni àwọn Júù apẹ̀yìndà yìí tọrùn bọ̀ bí wọ́n ṣe tẹ́ tábìlì oúnjẹ àti ohun mímu síwájú “ọlọ́run Oríire” àti “ọlọ́run Ìpín” yìí. * Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá fi ìwàǹwára lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà wọ̀nyí?
14 Jèhófà kìlọ̀ fún wọn gbangba gbàǹgbà pé: “Ṣe ni èmi yóò yàn yín sọ́tọ̀ fún idà, gbogbo yín yóò sì tẹrí ba fún ìfikúpa; nítorí ìdí náà pé mo pè, ṣùgbọ́n ẹ kò dáhùn; mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀; ẹ sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn.” (Aísáyà 65:12) Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ńṣe ni Jèhófà ń fi orúkọ òrìṣà Ìpín ṣe yẹ̀yẹ́ bí ó ṣe sọ pé òun yóò “yan” àwọn tó ń bọ òrìṣà yìí “sọ́tọ̀ fún idà,” ìyẹn ni pé, wọ́n á pa run. Jèhófà gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ pe àwọn èèyàn yìí léraléra, pé kí wọ́n ronú pìwà dà, ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí dídi sí i, wọ́n sì ń fi agídí ṣe ohun tó burú ní ojú rẹ̀. Áà, wọ́n mà kúkú fojú tín-ínrín Ọlọ́run o! Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, àjálù ńlá bá orílẹ̀-èdè yẹn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ nínú ìkìlọ̀ rẹ̀, nítorí Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Lákòókò yẹn, “ọlọ́run Oríire” kò lè dáàbò bo àwọn tó ń bọ ọ́ ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.—2 Kíróníkà 36:17.
15. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní gbà ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Aísáyà 65:11, 12?
15 Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà ní Aísáyà 65:11, 12. Wọn kò gba “Oríire” gbọ́, nítorí kì í ṣe ohun alágbára àràmàǹdà kan tó lè ṣeni lóore. Wọn kò jẹ́ fi ohun ìní wọn ṣòfò ní gbígbìyànjú láti tu “ọlọ́run Oríire” lójú, ìyẹn ni wọ́n fi ń yàgò fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ tẹ́tẹ́ títa. Ó dá wọn lójú hán-únhán-ún pé ṣe làwọn tó ń bọ òrìṣà yìí yóò pàdánù ohun gbogbo lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nítorí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà sọ fún pé: “Èmi yóò yàn yín sọ́tọ̀ fún idà.”
“Wò Ó! Àwọn Ìránṣẹ́ Tèmi Yóò Yọ̀”
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ṣùgbọ́n kí ni yóò dé bá àwọn tó kẹ̀yìn sí i?
16 Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń bá àwọn tó kọ Jèhófà sílẹ̀ wí, ó ṣàpèjúwe ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ń bẹ níwájú fún àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àti àwọn tó ń fi àgàbàgebè sìn ín, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: ‘Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu, ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀, ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà, ẹ ó sì hu nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.’” (Aísáyà 65:13, 14) Jèhófà yóò bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Ayọ̀ yóò kún ọkàn wọn débi pé wọ́n yóò máa hó ìhó ayọ̀. Jíjẹ, mímu, àti ayọ̀ yíyọ̀ jẹ́ àwọn gbólóhùn tó ń fi hàn pé Jèhófà yóò tẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ lọ́rùn dọ́ba. Àmọ́, ọ̀ràn ti àwọn tó yàn láti kẹ̀yìn sí Jèhófà yàtọ̀, ebi àti òùngbẹ nípa tẹ̀mí ni yóò máa hàn wọ́n léèmọ̀ ní tiwọn. Ńṣe ni wọn yóò máa ráágó kiri. Wọn yóò kígbe ẹkún, wọn yóò sì hu nítorí làásìgbò àti ìpọ́njú tí yóò bá wọn.
17. Kí nìdí tó fi tọ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?
17 Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà yìí ṣe ṣàpèjúwe ipò tẹ̀mí àwọn tó kàn ń fẹnu sọ ọ́ lásán pé àwọn ń sin Ọlọ́run lóde òní, bá a mu gan-an ni. Nígbà tí ẹ̀dùn ọkàn ń bá ẹgbàágbèje àwọn èèyàn inú Kirisẹ́ńdọ̀mù fínra, ńṣe làwọn olùjọsìn Jèhófà ń hó ìhó ayọ̀ ní tiwọn. Èwo ni wọn ò wá ní yọ̀ sí. Wọ́n ń jẹun yó dáadáa nípa tẹ̀mí. Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí fún wọn nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì àti nípasẹ̀ àwọn ìpàdé Kristẹni. Ní tòdodo, òtítọ́ tó ń gbéni ró àti àwọn ìlérí tó ń tuni nínú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fún wa ní “ipò rere ọkàn-àyà” gan-an ni!
18. Kí ni yóò ṣẹ́ kù fún àwọn tó kẹ̀yìn sí Jèhófà, kí sì ni lílò tí a óò máa lo orúkọ wọn láti fi búra ṣeé ṣe kí ó túmọ̀ sí?
18 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ sáwọn tó kẹ̀yìn sí i lọ, ó ní: “Dájúdájú, ẹ ó sì to orúkọ yín jọ fún ìbúra nípasẹ̀ àwọn àyànfẹ́ mi, ṣe ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò sì fi ikú pa yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ ni yóò fi orúkọ mìíràn pè; tí yóò fi jẹ́ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń súre fún ara rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́ súre fún ara rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń sọ gbólóhùn ìbúra ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́ búra; nítorí pé àwọn wàhálà àtijọ́ ni a ó gbàgbé ní ti tòótọ́ àti nítorí pé a ó fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 65:15, 16) Orúkọ lásán ni yóò ṣẹ́ kù fún àwọn tó kẹ̀yìn sí Jèhófà, ìyẹn orúkọ láti kàn máa fi búra, tàbí láti máa fi gégùn-ún. Èyí lè túmọ̀ sí pé, ńṣe ni àwọn tó bá fẹ́ búra láti fi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ọmọnìkejì wọn yóò sọ pé: ‘Bí mi ò bá mú ẹ̀jẹ́ mi yìí ṣẹ kí ìyà tó jẹ àwọn apẹ̀yìndà yẹn jẹ mi.’ Ó tiẹ̀ lé túmọ̀ sí pé orúkọ wọn yóò di lílò lọ́nà àpèjúwe bíi ti Sódómù àti Gòmórà, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìyà àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run yóò fi jẹ àwọn olubi.
19. Báwo la ó ṣe fi orúkọ mìíràn pe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kí sì nìdí tí wọ́n ó fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ìṣòtítọ́? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé pẹ̀lú.)
Aísáyà 65:16, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ yẹn yóò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, nítorí yóò ti mu àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ lóòótọ́. * Kò sì ní pẹ́ táwọn Júù yóò fi gbàgbé ìpọ́njú àtẹ̀yìnwá bí ìfọ̀kànbalẹ̀ bá ti wà fún wọn ní ìlú ìbílẹ̀ wọn.
19 Ọ̀ràn ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mà kúkú yàtọ̀ sí tiwọn o! Orúkọ mìíràn la ó fi pè wọ́n. Ìyẹn dúró fún ipò aásìkí àti iyì tí wọn yóò bọ́ sí ní ìlú ìbílẹ̀ wọn lọ́hùn-ún. Wọn kò ní tọ òrìṣà èyíkéyìí lọ láti tọrọ aásìkí, wọn kò sì ní fi ère aláìlẹ́mìí kankan búra. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá ń súre tàbí bí wọ́n bá ń búra, Ọlọ́run ìṣòtítọ́ ni wọn yóò fi búra. (“Èmi Yóò Dá Ọ̀run Tuntun àti Ilẹ̀ Ayé Tuntun”
20. Báwo ni ìlérí Jèhófà nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ṣe ṣẹ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?
20 Jèhófà wá túbọ̀ ṣàlàyé sí i nípa ìlérí rẹ̀ pé òun yóò mú àwọn àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà bọ̀ sípò tí wọ́n bá ti dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì. Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Ó dájú pé ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun yóò mú wọn bọ̀ sípò yóò ṣẹ, ìyẹn ló ṣe sọ̀rọ̀ ìmúbọ̀sípò ọjọ́ iwájú yẹn bíi pé ó ti ń ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìgbà tí àṣẹ́kù àwọn Júù padà wá ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ. Kí ló para pọ̀ jẹ́ “ọ̀run tuntun” ní àkókò yẹn? Ìyẹn ni jíjẹ tí Serubábélì jẹ gómìnà, tó sì fi Jerúsálẹ́mù ṣe ibùjókòó rẹ̀, tí Jóṣúà, Àlùfáà Àgbà, sì tì í lẹ́yìn gbágbáágbá. Àṣẹ́kù àwọn Júù tó padà bọ̀ wálé ló para pọ̀ jẹ́ “ilẹ̀ ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ èèyàn táa ti wẹ̀ mọ́, èyí tó fi ara rẹ̀ sábẹ́ ìṣàkóso Serubábélì, tó sì ṣèrànwọ́ láti mú kí ìsìn mímọ́ tún padà bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ náà. (Ẹ́sírà 5:1, 2) Ayọ̀ ìmúbọ̀sípò yẹn wá borí gbogbo ìyà wọn àtẹ̀yìnwá; àní ìpọ́njú tó bá wọn tẹ́lẹ̀ rí kò tiẹ̀ wá sí wọn lọ́kàn mọ́.—Sáàmù 126:1, 2.
21. Ọ̀run tuntun wo ló bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914?
21 Ṣùgbọ́n rántí pé Pétérù tún àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ, tó sì fi hàn pé ó ṣì máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Àpọ́sítélì Pétérù kọ ọ́ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Lọ́dún 1914, ọ̀run tuntun táa ti ń retí tipẹ́tipẹ́ dé. Ìjọba Mèsáyà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún yẹn wá ń ṣàkóso látọ̀runwá, Jèhófà sì fún un láṣẹ pé kó ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 2:6-8) Ìjọba tó ń ṣàkóso yìí, èyí tó wà ní ìkáwọ́ Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jọ ń ṣàkóso, ni ọ̀run tuntun yẹn.—Ìṣípayá 14:1.
22. Àwọn ta ni yóò para pọ̀ di ilẹ̀ ayé tuntun, báwo sì ni a ṣe ń múra àwọn èèyàn tí yóò di ìpìlẹ̀ ètò yẹn sílẹ̀ nísinsìnyí?
22 Kí wá ni ilẹ̀ ayé tuntun? Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ èyí tó ṣẹ láyé àtijọ́ ṣe fi hàn, àwọn èèyàn tó fi ìdùnnú fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso ti ìjọba tuntun tó wà ní ọ̀run ni ilẹ̀ ayé tuntun. Àní nísinsìnyí pàápàá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọlọ́kàn títọ́ ló ń fara wọn sábẹ́ ìjọba yìí, tí wọ́n sì ń ṣakitiyan láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, òfin tó jẹ́ pé ó wà nínú Bíbélì. Inú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti èdè ni àwọn wọ̀nyí ti wá, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti sin Jésù Kristi, Ọba tó ń ṣàkóso. (Míkà 4:1-4) Tí ètò àwọn nǹkan búburú yìí bá kọjá lọ tán, àwùjọ yìí ni yóò para pọ̀ di ìpìlẹ̀ fún ayé tuntun, yóò sì wá gbilẹ̀ kárí ayé gẹ́gẹ́ bí àwùjọ àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó jogún ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ara ilẹ̀ ọba Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 25:34.
23. Ìsọfúnni wo la rí nínú ìwé Ìṣípayá nípa “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan,” báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò sì ṣe ṣẹ?
23 Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa ọjọ́ Jèhófà tí ń bọ̀, nínú èyí tí a ó ti mú ètò àwọn nǹkan búburú yìí kúrò. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó sọ Sátánì sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìṣípayá 19:11–20:3) Lẹ́yìn tí Jòhánù ṣe àpèjúwe yẹn tán, ó tún ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ, ó kọ ọ́ pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan.” Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú ìran ológo yìí sọ nípa àkókò kan tó jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run yóò yí ipò inú ayé yìí padà sí rere pátápátá. (Ìṣípayá 21:1, 3-5) Dájúdájú, ìlérí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” tó wà nínú ìwé Aísáyà yóò ṣẹ lọ́nà àgbàyanu nínú ayé tuntun Ọlọ́run! Àwùjọ tó jẹ́ ilẹ̀ ayé tuntun yóò máa gbádùn Párádísè nípa ti ara àti tẹ̀mí lọ lábẹ́ ìṣàkóso tí í ṣe ọ̀run tuntun. Ìlérí yìí tuni nínú gan-an ni, ìyẹn ìlérí tó sọ pé “àwọn ohun àtijọ́ [àìsàn, ìyà àti ọ̀pọ̀ làásìgbò tó ń bá àwọn èèyàn fínra] ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” Ohun yòówù ká rántí lákòókò yẹn, kò ní dùn wá, kò sì ní fa ìrora ńlá tó máa ń di ẹ̀dùn ọkàn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láyé ìsinsìnyí.
24. Kí nìdí tí inú Jèhófà yóò fi dùn pé Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò, kí ni a kò sì tún ní gbọ́ mọ́ láàárín ìlú yẹn?
24 Aísáyà ń bá àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun tí ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà. Ó sì dájú pé èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Jerúsálẹ́mù, èmi yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú àwọn ènìyàn mi; a kì yóò sì gbọ́ ìró ẹkún tàbí ìró igbe arò mọ́ nínú rẹ̀.” (Aísáyà 65:18, 19) Yàtọ̀ sí pé àwọn Júù yóò yọ̀ pé Ọlọ́run mú wọn padà wá sí ilẹ̀ wọn, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò yọ̀ pẹ̀lú, nítorí yóò sọ Jerúsálẹ́mù di ibi tó lẹ́wà, àní yóò tún padà di ibi tí ìsìn mímọ́ fìdí kalẹ̀ sí lórí ilẹ̀ ayé. A ò ní gbọ́ ìró ẹkún nítorí àjálù, èyí tó gbòde kan nínú ìlú yẹn ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mọ́.
25, 26. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ṣe Jerúsálẹ́mù ní “ohun tí ń fa ìdùnnú” lóde òní? (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe lo Jerúsálẹ́mù Tuntun, kí sì nìdí tí a fi lè máa yọ ayọ̀ ńláǹlà lóde òní?
25 Lóde òní pẹ̀lú, Jèhófà ṣe Jerúsálẹ́mù ní “ohun tí ń fa ìdùnnú.” Lọ́nà wo? Bí a ti rí i níṣàájú, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó nípìn-ín nínú ìjọba ọ̀run yóò di ara ọ̀run tuntun tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 yẹn níkẹyìn. Àwọn ni àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “Jerúsálẹ́mù Tuntun.” (Ìṣípayá 21:2) Ọ̀rọ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí ni Ọlọ́run ń sọ nígbà tó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun tí ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà.” Ọlọ́run yóò lo Jerúsálẹ́mù Tuntun láti fi mú ìbùkún yàbùgà yabuga wá fún aráyé onígbọràn. A kì yóò gbúròó ẹkún tàbí igbe arò mọ́ níbẹ̀, nítorí pé Jèhófà yóò tẹ́ wa lọ́rùn ní ti “àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà [wa] wá.”—Sáàmù 37:3, 4.
26 Ní tòdodo, ó yẹ ká yọ ayọ̀ ńláǹlà lóde òní! Láìpẹ́, Jèhófà yóò sọ orúkọ ọlọ́lá ńlá rẹ̀ di mímọ́ nípa pípa gbogbo alátakò rẹ̀ run. (Sáàmù 83:17, 18) Ọ̀run tuntun yóò sì wá gba àkóso pátápátá. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìdí tó ga lọ́lá fún wa láti máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí á sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí Ọlọ́run yóò dá!
Ìlérí Ọjọ́ Ọ̀la Tó Fini Lọ́kàn Balẹ̀
27. Ọ̀nà wo ni Aísáyà gbà ṣàpèjúwe ìbàlẹ̀ ọkàn tí yóò wà fáwọn Júù tó padà wálé ní ìlú ìbílẹ̀ wọn?
27 Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò kọ́kọ́ ṣẹ, báwo ni ìgbésí ayé yóò ṣe rí fún àwọn Júù tó padà bọ̀ wálé lábẹ́ ọ̀run tuntun yẹn? Jèhófà sọ pé: “Kì yóò sí ọmọ ẹnu ọmú kan níbẹ̀ tí ọjọ́ rẹ̀ kéré níye, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí àgbàlagbà kan tí ọjọ́ rẹ̀ Aísáyà 65:20) Áà, àpèjúwe ìbàlẹ̀ ọkàn tí yóò wà fáwọn ìgbèkùn tó padà wálé yìí kọyọyọ! Ọmọ jòjòló tí ọjọ́ rẹ̀ ṣì kéré níye kò ní ṣẹ́kú rárá. Bẹ́ẹ̀ ni ikú kò ní dá ẹ̀mí àgbàlagbà légbodò. * Ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí mà fí àwọn Júù tí yóò padà sí Júdà lọ́kàn balẹ̀ gidi o! Kò ní sídìí fún wọn láti máa jáyà pé àwọn ọ̀tá yóò wá gbé àwọn lọ́mọ lọ tàbí pé àwọn ọ̀tá yóò pa àwọn èèyàn àwọn nítorí pé ààbò tó dájú yóò wà fún wọn ní ilẹ̀ wọn.
kò kún; nítorí pé ẹnì kan yóò kú ní ọmọdékùnrin lásán-làsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún; àti ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.” (28. Ẹ̀kọ́ wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà kọ́ wa nípa ìwàláàyè nínú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba rẹ̀?
28 Kí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà wá fi ń yé wa nípa ìgbésí ayé nínú ayé tuntun tí ń bọ̀? Òun ni pé, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù ọmọ yóò ní ìbàlẹ̀ ọkàn nípa ọjọ́ ọ̀la. Kò ní sí olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí yóò kú ní rèwerèwe. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni àwọn tó jẹ́ onígbọràn nínú aráyé yóò wà, tí wọn yóò fi lè gbádùn ayé wọn. Ẹnikẹ́ni tó bá wá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ńkọ́? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò pàdánù àǹfààní láti wà láàyè. Ì báà tiẹ̀ jẹ́ “ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún” ni ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn, yóò kú dandan ni. Bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, òun á jẹ́ “ọmọdékùnrin lásánlàsàn” ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tó yẹ kí ó jẹ́, ìyẹn ẹni tí yóò máa wà láàyè títí lọ gbére.
29. (a) Kí ni ohun ìdùnnú tí àwọn onígbọràn lára àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò rí gbà ní ilẹ̀ Júdà tó padà bọ̀ sípò? (b) Kí nìdí tí igi fi jẹ́ ohun tó bá a mu láti fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí gígùn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
29 Jèhófà ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ nípa bí nǹkan yóò ṣe rí ní ilẹ̀ Júdà tó padà bọ̀ sípò, ó ní: “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, Aísáyà 65:21, 22) Lẹ́yìn tí àwọn onígbọràn lára àwọn èèyàn Ọlọ́run bá padà dé ilẹ̀ Júdà tó dahoro, èyí tó dájú pé kò ní ní ilé àti ọgbà àjàrà nínú, yóò jẹ́ ìdùnnú fún wọn láti máa gbé nínú ilé tiwọn, kí wọ́n sì máa jẹ èso ọgbà àjàrà tiwọn. Ọlọ́run yóò bù kún iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ẹ̀mí wọn yóò sì gùn, àní bí ọjọ́ igi, tí wọ́n ó fi lè máa jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn nìṣó. *
wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (30. Ipò ìdùnnú wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wà lóde òní, kí ni wọn yóò sì gbádùn nínú ayé tuntun?
30 Láyé ìgbà tiwa yìí, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ṣẹ lọ́nà kan. Àwọn èèyàn Jèhófà jáde wá látinú ìgbèkùn tẹ̀mí lọ́dún 1919, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú “ilẹ̀” wọn, tàbí àgbègbè ìgbòkègbodò àti ìjọsìn wọn padà bọ̀ sípò. Wọ́n fi àwọn ìjọ lọ́lẹ̀, wọ́n sì dẹni tó ń so èso nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nísinsìnyí pàápàá, àwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn párádísè nípa tẹ̀mí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kí ó dá wa lójú pé irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a lọ ni títí wọnú Párádísè tí ó ṣeé fojú rí. Bí a bá tiẹ̀ ní ká fojú inú wo ohun tí Jèhófà yóò tipasẹ̀ ọwọ́ àti ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùyọ̀ǹda ara ẹni gbé ṣe nínú ayé tuntun, a kò lè róye rẹ̀ tán. Áà, ìdùnnú tó kọyọyọ ni yóò jẹ́ láti kọ́ ilé tìrẹ kí o sì máa wá gbé inú rẹ̀! Iṣẹ́ tó ń mú inú ẹni dùn yóò sì pọ̀ jaburata lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Èrè ńlá mà ni yóò jẹ o láti máa “rí ohun rere” nígbà gbogbo látinú iṣẹ́ àṣekára rẹ! (Oníwàásù 3:13) Ṣé àkókò á sì gùn tó fún wa láti fi lè gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? Yóò gùn tó dájúdájú! Ẹ̀mí gígùn kánrin táwọn èèyàn olóòótọ́ yóò ní yóò gùn “bí ọjọ́ igi,” àní yóò tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún yóò sì jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá!
31, 32. (a) Àwọn ìbùkún wo ni yóò tẹ àwọn ìgbèkùn tó padà wálé lọ́wọ́? (b) Nínú ayé tuntun, àǹfààní wo ni àwọn olóòótọ́ nínú aráyé yóò ní?
31 Jèhófà ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀ ìbùkún sí i tó wà níwájú fún àwọn ìgbèkùn tó padà bọ̀ wálé, ó ní: “Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu; nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà, àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn.” (Aísáyà 65:23) Jèhófà yóò bù kún àwọn Júù tó padà bọ̀ sípò yẹn tó fi jẹ́ pé wọn kò ní ṣiṣẹ́ àṣedànù. Òbí ò ní bímọ kí ọmọ rẹ̀ sì wá ṣẹ́kú. Àwọn tó ti ìgbèkùn wálé nìkan kọ́ ni yóò gba ìbùkún ìpadàbọ̀sípò yìí o; àwọn ọmọ wọn yóò jẹ níbẹ̀ pẹ̀lú. Ó wu Ọlọ́run láti tètè ṣe ohun tí àwọn èèyàn rẹ̀ ń fẹ́ fún wọn, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi ṣèlérí pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ti tòótọ́ pé, kí wọ́n tó pè, èmi fúnra mi yóò dáhùn; bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi fúnra mi yóò gbọ́.”—Aísáyà 65:24.
32 Báwo ni Jèhófà yóò ṣe mú àwọn ìlérí yìí ṣẹ nínú ayé tuntun tí ń bọ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣì ní sùúrù di ìgbà náà. Jèhófà kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ tán fún wa, ṣùgbọ́n kí ó dá wa lójú pé àwọn olóòótọ́ nínú aráyé kò tún ní “ṣe làálàá lásán” mọ́. Àwọn ogunlọ́gọ̀ tí yóò la Amágẹ́dọ́nì jà àti ọmọ tí wọ́n bá bí yóò lè ní ẹ̀mí gígún kánrin tó ń dùn mọ́ni, àní ìyè ayérayé! Àwọn tó bá jíǹde, tí wọ́n sì yàn láti gbé ìgbésí ayé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí Ọlọ́run là sílẹ̀, yóò rí ìdùnnú nínú ayé tuntun pẹ̀lú. Jèhófà yóò gbọ́ ohun tí wọ́n bá tọrọ yóò sì dá wọn lóhùn, àní yóò tiẹ̀ ti múra sílẹ̀ dè wọ́n kí wọ́n tó béèrè pàápàá. Ní tòótọ́, ńṣe ni Jèhófà yóò ṣí ọwọ́ rẹ̀ tí yóò sì “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn,” ìyẹn ìfẹ́ ọkàn tí ó tọ́.—Sáàmù 145:16.
33. Ọ̀nà wo ni àwọn ẹranko yóò gbà wà ni àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Júù nígbà tí wọ́n bá padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn?
Aísáyà 65:25) Nígbà tí àwọn Júù olóòótọ́ bá padà wá sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, abẹ́ àbójútó Jèhófà ni wọn yóò wà. Àní ńṣe ni kìnnìún yóò jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ní ti pé, kìnnìún kò ní pa àwọn Júù tàbí àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn lára rárá. Ìlérí yìí dájú, nítorí pé ọ̀rọ̀ náà, “ni Jèhófà wí,” ló parí rẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í sì í yẹ̀ rárá ni!—Aísáyà 55:10, 11.
33 Báwo ni àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ yìí yóò ṣe gbilẹ̀ tó? Jèhófà parí apá àsọtẹ́lẹ̀ yìí pé: “‘Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn pàápàá yóò máa jùmọ̀ jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù; àti ní ti ejò, oúnjẹ rẹ̀ yóò jẹ́ ekuru. Wọn kì yóò ṣe ìpalára kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi,’ ni Jèhófà wí.” (34. Ọ̀nà tó wúni lórí wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà gbà ń ṣẹ lóde òní, ọ̀nà wo ni yóò sì gbà ṣẹ nínú ayé tuntun?
34 Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti ń ṣẹ lọ́nà tó wúni lórí láàárín àwọn olùjọsìn rẹ̀ lóde òní. Láti ọdún 1919 ni Ọlọ́run ti bù kún ilẹ̀ tẹ̀mí tí àwọn èèyàn rẹ̀ wà, ó sì sọ ọ́ di párádísè tẹ̀mí. Àwọn tó ń wá sí párádísè tẹ̀mí yìí ti máa ń ṣe àyípadà tó bùáyà ní ìgbésí ayé wọn. (Éfésù 4:22-24) Àwọn kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ oníwà-bí-ẹranko, tó jẹ́ pé wọ́n jẹ́ afámọ-lórí fọ̀dà-kùn-ún, tàbí tí wọ́n ti máa ń fìtínà ọmọnìkejì wọn tẹ́lẹ̀ rí, ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti ràn lọ́wọ́ láti yí àwọn ìwàkiwà yẹn padà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n jùmọ̀ ń jọ́sìn ní àlàáfíà àti ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Ńṣe ni ìbùkún tí àwọn èèyàn Jèhófà ń rí gbà nínú párádísè tẹ̀mí wọn yìí yóò sì máa bá a lọ títí wọnú Párádísè tí a lè fojú rí, níbi tí àlàáfíà yóò ti wà láàárín àwọn ènìyàn àti ẹranko àní gẹ́lẹ́ bí àlàáfíà yóò ṣe jọba láàárín àwọn èèyàn. Kí ó dá wa lójú pé, tí ó bá ti tó àsìkò lójú Ọlọ́run, iṣẹ́ tó gbé lé ọmọ èèyàn lọ́wọ́ yóò di ṣíṣe, ìyẹn ni pé: ‘Ẹ ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.’—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
35. Kí nìdí tó fi yẹ kí á “kún fún ìdùnnú títí láé”?
35 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”! Ìlérí yẹn ṣẹ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì tún ń ṣẹ síwájú sí i lóde òní. Ìmúṣẹ méjèèjì yìí ń jẹ́ ka mọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la ológo ń bẹ níwájú fún àwọn onígbọràn nínú aráyé. Jèhófà ṣe wá lóore gan-an ni, ó tipa àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ ká lè bojú wo ohun tí ń bẹ lọ́jọ́ iwájú fún àwọn tó bá fẹ́ràn rẹ̀. Ní tòdodo, ìdí wà fún wa láti ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Jèhófà wí o, ó ní: “Ẹ . . . kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá”!—Aísáyà 65:18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 8 Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé nítorí àtilè bá òkú sọ̀rọ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí fi ń lọ sí àwọn ibi ìsìnkú. Ó lè jẹ́ ìbọ̀rìṣà ló sún wọn débi jíjẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 13 Nígbà tí Jerome, tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì (ẹni tí wọ́n bí ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa), ń ṣàlàyé nípa ẹsẹ yìí, ó sọ nípa ohun kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe látijọ́ ní ìparí oṣù tó kẹ́yìn nínú ọdún wọn. Ó kọ̀wé pé: “Wọ́n máa ń tẹ́ tábìlì tó kún fún onírúurú oúnjẹ àti ife ọtí tí wọ́n fi wáìnì dídùn lú, nítorí kí wọ́n lè ṣoríire nídìí ìbísí ti ọdún tó parí, tàbí kí ìbísí lè wà lọ́dún tuntun.”
^ ìpínrọ̀ 19 Nínú ìwé ti àwọn Másórẹ́tì tó jẹ́ èdè Hébérù, Aísáyà 65:16 sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tí í ṣe Àmín.” “Àmín” túmọ̀ sí “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “ó ti dájú,” ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé èèyàn fara mọ́ ohun tó gbọ́ tàbí pé ó dáni lójú pé ohun kan jẹ́ òótọ́ tàbí pé yóò ṣẹ dájúdájú. Bí Jèhófà sì ṣe mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ńṣe ló fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ òun.
^ ìpínrọ̀ 27 Bíbélì The Jerusalem Bible túmọ̀ Aísáyà 65:20 báyìí pé: “Kò ní sí pé ọmọ ọwọ́ ṣẹ́kú mọ́, tàbí pé àgbàlagbà kú láìjẹ́ pé ó gbó, pé ó tọ́.”
^ ìpínrọ̀ 29 Igi jẹ́ ohun tó bá a mu láti fi ṣàpèjúwe ẹ̀mí gígùn, nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun alààyè tí a mọ̀ pé ó máa ń pẹ́ jù lọ kí ó tó kú. Bí àpẹẹrẹ, igi ólífì lè máa so èso nìṣó fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, ó sì lè lò tó ẹgbẹ̀rún ọdún láìkú.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 389]
Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àkókò yóò gùn tó fún wa láti lè gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wa