Ọwọ́ Jèhófà Kò Kúrú
Orí Ogún
Ọwọ́ Jèhófà Kò Kúrú
1. Kí ni ipò nǹkan ti rí ní Júdà, kí sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀?
ORÍLẸ̀-ÈDÈ Júdà sọ pé àwọn àti Jèhófà jọ dá májẹ̀mú. Síbẹ̀, ńṣe ni ìjàngbọ̀n gbòde kan níbẹ̀. Ìdájọ́ òdodo ṣọ̀wọ́n, ìwà ọ̀daràn àti ìnilára sì gbilẹ̀, ìrètí pé àwọn nǹkan yóò sàn sí i já sófo. Ìyẹn fi hàn pé nǹkan kù díẹ̀ káàtó níbì kan. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rò ó pé bóyá ni Jèhófà máa tún nǹkan wọ̀nyẹn ṣe. Bí ipò nǹkan ṣe rí nígbà ayé Aísáyà nìyẹn o. Ṣùgbọ́n, ohun tí Aísáyà kọ pé ó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí à ń wí yìí kì í ṣe ìtàn ohun tó kàn ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ lásán. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àwọn ìkìlọ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú fún ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun ń sin Ọlọ́run síbẹ̀ tí kò ka àwọn òfin Rẹ̀ sí. Àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí yìí, tó wà nínú Aísáyà orí kọkàndínlọ́gọ́ta, pèsè ìṣírí tó dùn mọ́ni fún gbogbo àwọn tó bá ń ṣakitiyan láti sin Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé lákòókò ìnira àti eléwu.
Wọ́n Ta Kété sí Ọlọ́run Tòótọ́
2, 3. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi dáàbò bo Júdà mọ́?
2 Áà, ó ṣe, àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú ti di apẹ̀yìndà! Wọ́n kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kúrò lábẹ́ ọwọ́ ààbò rẹ̀. Ìyẹn ni ìpọ́njú fi bá wọn gidigidi. Àbí wọ́n tiẹ̀ sọ pé Jèhófà ló kó ìnira bá àwọn? Aísáyà sọ fún wọn pé: “Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò wúwo jù tí kò fi lè gbọ́. Rárá, ṣùgbọ́n àwọn ìṣìnà tiyín gan-an ti di ohun tí ń fa ìpínyà láàárín Aísáyà 59:1, 2.
ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti ṣokùnfà fífi tí ó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín kí ó má bàa máa gbọ́.”—3 Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni ó là mọ́lẹ̀ yẹn o. Jèhófà ṣì ni Ọlọ́run ìgbàlà. Òun ni “Olùgbọ́ àdúrà,” nípa bẹ́ẹ̀ ó ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (Sáàmù 65:2) Àmọ́ o, kì í bù kún àwọn aṣebi. Àwọn èèyàn yẹn ló fúnra wọn kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ìwà ibi wọn ló sì mú kó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn.
4. Àwọn ẹ̀sùn wo ni a kà sí Júdà lọ́rùn?
4 Ní tòdodo, Júdà ṣe ohun tó burú jáì. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mẹ́nu kan díẹ̀ lára ẹ̀sùn wọn, ó ní: “Ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí, ìṣìnà sì ti sọ ìka yín di eléèérí. Ètè yín ti sọ èké. Ahọ́n yín ń sọ kìkìdá àìṣòdodo lábẹ́lẹ̀.” (Aísáyà 59:3) Àwọn ará Júdà ń purọ́, wọ́n sì ń sọ àwọn ohun àìṣòdodo. Sísọ tó sọ pé, “ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí,” fi hàn pé àwọn kan tiẹ̀ ti ṣìkà pànìyàn. Èyí mà tàbùkù sí Ọlọ́run o, ẹni tó jẹ́ pé, yàtọ̀ sí pé Òfin rẹ̀ ka ìṣìkàpànìyàn léèwọ̀, ó tún sọ pé ó lòdì láti “kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ”! (Léfítíkù 19:17) Ó yẹ kí mímu tí àwọn ará Júdà ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹní mu omi, tí wọ́n fi tipa bẹ́ẹ̀ rugi oyin, rán olúkúlùkù wa lónìí létí pé dandan ni kí á kápá ìrònú àti ìmọ̀lára tí ń tini dẹ́ṣẹ̀. Láìṣe bẹ́ẹ̀, a lè dẹni tó ń hùwà burúkú tí yóò yà wá nípa sí Ọlọ́run.—Róòmù 12:9; Gálátíà 5:15; Jákọ́bù 1:14, 15.
5. Báwo ni ìwà ìbàjẹ́ Júdà ṣe rìn jìnnà tó?
5 Ẹ̀ṣẹ̀ dídá ti ran gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn látòkè délẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń ké jáde nínú òdodo, kò sì sí ẹnì kankan tí ó lọ sí kóòtù nínú ìṣòtítọ́. Gbígbẹ́kẹ̀lé òtúbáńtẹ́ ń ṣẹlẹ̀, àti sísọ ohun àìníláárí. Lílóyún ìjàngbọ̀n ń ṣẹlẹ̀, àti bíbí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.” (Aísáyà 59:4) Kò sí ẹnikẹ́ni tó ń sọ òdodo. Kódà, ó ṣọ̀wọ́n láti rí ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tàbí olùṣòtítọ́ ní kóòtù pàápàá. Júdà kẹ̀yìn sí Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé àjọṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè, kódà ó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí. Bẹ́ẹ̀, “òtúbáńtẹ́,” ohun tí kò wúlò rárá, ni gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́. (Aísáyà 40:17, 23; 41:29) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, àpérò tí wọ́n ń ṣe pọ̀ lóòótọ́, àmọ́, ohun àìníláárí ni gbogbo rẹ̀ ń já sí. Wọ́n ń ṣe àwọn ìwéwèé o, àmọ́, ìjàngbọ̀n àti ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ ló ń yọrí sí.
6. Báwo ni ìṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe dà bíi ti Júdà gẹ́lẹ́?
6 Àìṣòdodo àti ìwà ipá Kirisẹ́ńdọ̀mù bá ti Júdà dọ́gba gẹ́lẹ́. (Wo “Kirisẹ́ńdọ̀mù Bá Jerúsálẹ́mù Apẹ̀yìndà Dọ́gba,” lójú ewé 294.) Ogun àgbáyé méjì tó burú jáì ni ayé ti jà, àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n láwọn jẹ́ Kristẹni sì wà lára àwọn tó jà á. Títí dòní olónìí, irú ìsìn tí àwọn èèyàn inú Kirisẹ́ńdọ̀mù ń ṣe kò lágbára láti fòpin sí ìpẹ̀yàrun láàárín àwọn ọmọ ìjọ wọn àti pípa tí àwọn ẹ̀yà wọn ń para wọn ní ìpakúpa. (2 Tímótì 3:5) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ni kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, ńṣe ni àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù ń bá a lọ láti gbẹ́kẹ̀ lé àkójọ ohun ìjà ogun àti àjọṣe pẹ̀lú àwọn olóṣèlú. (Mátíù 6:10) Àní inú àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó jẹ́ òléwájú nínú àwọn tó ń pèsè ohun ìjà ogun wà! Ó dájú pé, bí Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ìsapá èèyàn àti àwọn àjọ tí èèyàn dá sílẹ̀, fún ààbò ọjọ́ ọ̀la, “òtúbáńtẹ́” lòun náà gbẹ́kẹ̀ lé yẹn.
Ọ̀rọ̀ Wọ́n Já sí Ìbànújẹ́
7. Kí nìdí tí ìpètepèrò Júdà fi ń yọrí sí kìkì ìpalára?
7 Àwùjọ tí ìbọ̀rìṣà àti àìṣòótọ́ bá wà kì í tòrò. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ìwọ̀nyẹn lohun tí àwọn Júù aláìṣòótọ́ yàn láti máa ṣe, wàhálà tí wọ́n fọwọ́ ara wọn fà wá ń bá wọn wàyí. A kà á pé: “Ẹyin ejò olóró ni wọ́n pa, wọ́n sì ń hun jàǹkárìwọ̀ aláǹtakùn lásán-làsàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹyin wọn yóò kú, ẹyin tí a bá sì tẹ̀ fọ́ yóò pa paramọ́lẹ̀.” (Aísáyà 59:5) Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìpètepèrò Júdà títí dìgbà tí wọ́n fi mú un ṣẹ, kò mú ohun tó ní láárí jáde rárá. Kìkì ìpalára ni ìròkírò wọn ń yọrí sí, gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé ejò olóró ni ẹyin ejò olóró yóò pa. Orílẹ̀-èdè yẹn sì jẹ dẹndẹ ìyà.
8. Kí ló fi ìrònú òdì tí Júdà ní hàn?
8 Lóòótọ́, àwọn ará Júdà kan lè yíjú sí ìwà ipá híhù láti lè dáàbò bo ara wọn, ṣùgbọ́n wọn yóò kùnà. Lílo ipá láti fi dáàbò bo ara wọn kò lè rọ́pò níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti ṣíṣe iṣẹ́ òdodo, àní bí èèyàn ò ṣe lè wọ jàǹkárìwọ̀ aláǹtakùn láti fi gba òtútù dípò ẹ̀wù. Aísáyà kéde pé: “Jàǹkárìwọ̀ wọn lásán-làsàn kì yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fi iṣẹ́ wọn bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ìgbòkègbodò ìwà ipá sì ń bẹ ní àtẹ́lẹwọ́ wọn. Ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí kìkì ìwà búburú, wọ́n sì ń ṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀. Ìrònú wọn jẹ́ ìrònú tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́; ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀ ń bẹ ní àwọn òpópó wọn.” (Aísáyà 59:6, 7) Ìrònú Júdà lòdì pátápátá o. Yíyí tó yíjú sí ìwà ipá láti fi yanjú àwọn ìṣòro rẹ̀, ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ló ń hù yẹn. Kò tilẹ̀ jẹ́ ohunkóhun lójú rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tí òun ti pa ló jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀, àti pé àwọn kan lára wọn jẹ́ ojúlówó ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
9. Èé ṣe tí ọwọ́ àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi lè tẹ àlàáfíà tòótọ́?
9 Ọ̀rọ̀ onímìísí yìí mú wa rántí ìtàn Kirisẹ́ńdọ̀mù tó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Dájúdájú, Jèhófà yóò mú kó jíhìn fún ẹ̀gàn tó kó bá ìsìn Kristẹni tó lóun ń ṣojú fún! Ohun tí àwọn Júù ìgbà ayé Aísáyà ṣe náà ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe, ìgbé ayé ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n ń gbé nítorí pé ìyẹn nìkan ni ìgbé ayé tí àwọn aṣáájú wọn gbà pé ó ṣeé gbé. Wọ́n á máa sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà, ṣùgbọ́n àìṣèdájọ́ òdodo ni wọ́n ń hù níwà. Áà, àgàbàgebè wọn pọ̀! Nígbà tí àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ò sì ti jáwọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ wọn ò lè tẹ àlàáfíà tòótọ́ láé. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ síwájú sí i náà lọ̀ràn wọ́n ṣe rí, ó ní: “Wọ́n ti Aísáyà 59:8.
fi ọ̀nà àlàáfíà dá àgunlá, kò sì sí ìdájọ́ òdodo ní àwọn òpó ọ̀nà wọn. Àwọn òpópónà wọn ni wọ́n ti ṣe ní wíwọ́ fún ara wọn. Kò sí ẹnì kankan tí ń rìn nínú wọn tí yóò mọ àlàáfíà ní ti gidi.”—Wọ́n Ń Táràrà Nínú Òkùnkùn Nípa Tẹ̀mí
10. Kí ni Aísáyà jẹ́wọ́ bó ṣe ń gbẹnu sọ fún orílẹ̀-èdè Júdà?
10 Jèhófà kò lè bù kún ìwà békebèke àti àwọn ọ̀nà ìparun tí Júdà ń tọ̀. (Sáàmù 11:5) Ìyẹn ni Aísáyà fi gbẹnu sọ fún gbogbo orílẹ̀-èdè Júdà, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn pé: “Ìdájọ́ òdodo . . . wá jìnnà réré sí wa, . . . òdodo kò sì bá wa. A ń retí ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! òkùnkùn; a ń retí ìtànyòò, ṣùgbọ́n inú ìṣúdùdù ìgbà gbogbo ni a ń rìn. A ń táràrà wá ògiri gẹ́gẹ́ bí àwọn afọ́jú, àti bí àwọn tí kò ní ojú ni àwa ń táràrà. A ti kọsẹ̀ ní ọ̀sán ganrínganrín gẹ́gẹ́ bí ẹni pé nínú òkùnkùn alẹ́; láàárín àwọn tí ó taagun, a kàn dà bí òkú. Àwa ń kérora ṣáá, gbogbo wa, gẹ́gẹ́ bí béárì; àti bí àdàbà, ṣe ni a ń ké kúùkúù tọ̀fọ̀-tọ̀fọ̀.” (Aísáyà 59:9-11a) Àwọn Júù kò fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fìtílà fún ẹsẹ̀ wọn àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wọn. (Sáàmù 119:105) Nípa báyìí, ńṣe làwọn nǹkan ṣókùnkùn. Àní lọ́sàn án ganrínganrín, ṣe ni wọ́n táràrà kiri bíi pé òru ni. Àfi bíi pé wọ́n ti kú. Bí wọ́n ṣe ń wọ̀nà fún ìtura, wọ́n ń kérora ńláǹlà bíi béárì tí ebi ń pa tàbí bí èyí tó ti fara gbọgbẹ́. Àwọn mìíràn ń ké kúùkúù lọ́nà tó ṣeni láàánú, àfi bí àdàbà tó nìkan wà.
11. Kí nìdí tí ìrètí Júdà láti rí ìdájọ́ òdodo àti ìgbàlà fi já sásán?
11 Aísáyà mọ̀ dájúdájú pé ṣíṣọ̀tẹ̀ tí Júdà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ló kó wọn sínú ìyọnu. Ó ní: “A ń retí ìdájọ́ òdodo ṣáá, ṣùgbọ́n kò sí ìkankan; a ń retí ìgbàlà, ṣùgbọ́n ó dúró ní ọ̀nà jíjìnréré sí wa. Nítorí pé ìdìtẹ̀ wa ti di púpọ̀ ní iwájú rẹ; àti ní ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀kọ̀ọ̀kan ti jẹ́rìí lòdì sí wa. Nítorí pé àwọn ìdìtẹ̀ wa ń bẹ pẹ̀lú wa; àti ní ti àwọn ìṣìnà wa, a mọ̀ wọ́n dáadáa. Ìrélànàkọjá àti sísẹ́ Jèhófà ti ṣẹlẹ̀; sísún sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, sísọ̀rọ̀ ìnilára àti ìdìtẹ̀, lílóyún èké àti sísọ ọ̀rọ̀ èké lábẹ́lẹ̀ láti inú ọkàn-àyà gan-an sì ti ṣẹlẹ̀.” (Aísáyà 59:11b-13) Níwọ̀n bí àwọn ará Júdà kò ti ronú pìwà dà, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣì ń bẹ lọ́rùn wọn síbẹ̀. Kò sí ìdájọ́ òdodo mọ́ ní ilẹ̀ náà nítorí pé àwọn ará ibẹ̀ ti fi Jèhófà sílẹ̀. Elékèé paraku ni wọ́n, àní wọ́n tún ń ni àwọn arákùnrin wọn lára. Kirisẹ́ńdọ̀mù òde òní kò mà yàtọ̀ sí wọn o! Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣàìka ìdájọ́ òdodo sí, wọ́n tún ń ṣe inúnibíni sí àwọn olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣakitiyan láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Jèhófà Dá Wọn Lẹ́jọ́
12. Ìwà wo ni àwọn tó ń bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ ní Júdà ń hù?
12 Ó jọ pé kò sí ìdájọ́ òdodo, kò sí òdodo tàbí òtítọ́ ní Júdà. Ó ní: “A . . . fipá sún ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn, òdodo pàápàá sì wulẹ̀ dúró sí ibi jíjìnnàréré. Nítorí pé òtítọ́ ti kọsẹ̀ àní ní ojúde ìlú, ohun tí ó tọ́ kò sì lè wọlé.” (Aísáyà 59:14) Wọ́n sábà máa ń ṣe ojúde ìlú sí ẹ̀yìn àwọn ẹnubodè ìlú ní Júdà, àwọn àgbààgbà a sì máa pàdé níbẹ̀ láti bójú tó ẹjọ́. (Rúùtù 4:1, 2, 11) Òdodo ló yẹ kí àwọn wọ̀nyẹn máa fi dájọ́, kí wọ́n sì máa wá ọ̀nà láti ṣe ìdájọ́ òdodo, kì í ṣe pé kí wọ́n máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Diutarónómì 16:18-20) Àmọ́, ọ̀nà tó bá èrò onímọtara ẹni nìkan tiwọn mu ni wọ́n gbà ń dájọ́. Èyí tó tiẹ̀ burú jù ni pé, wọ́n ka ẹnikẹ́ni tó bá ń gbìyànjú tinútinú láti ṣe rere sí ẹni tó dùn ún fá lórí. A kà á pé: “Òtítọ́ sì dàwáàrí, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń yí padà kúrò nínú ìwà búburú ni a ń fi ṣe ìjẹ.”—Aísáyà 59:15a.
13. Nígbà tí àwọn onídàájọ́ Júdà kò ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, kí ni Jèhófà yóò ṣe?
13 Àwọn tí kò dá ìwàkiwà lẹ́bi gbàgbé pé Ọlọ́run kò fọ́jú, pé kì í ṣe aláìmọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe aláìlágbára. Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà rí i, ó sì burú ní ojú rẹ̀ pé kò sí ìdájọ́ òdodo. Nígbà tí ó sì rí i pé kò sí ènìyàn kankan, ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà á pé kò sí ẹnì kankan tí ń báni ṣìpẹ̀. Apá rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a gbani là, òdodo rẹ̀ sì ni ohun tí ó tì í lẹ́yìn.” (Aísáyà 59:15b, 16) Nígbà tí àwọn tó wà nípò onídàájọ́ kò ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, Jèhófà yóò dá sí ọ̀ràn ọ̀hún. Nígbà tí Jèhófà bá sì dá sí i, òdodo àti agbára ni yóò fi ṣe é.
14. (a) Ìwà wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ní lóde òní? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe gbára dì láti múṣẹ́ ṣe?
14 Irú ipò kan náà wà lóde òní. Ayé tí a ń gbé yìí jẹ́ ayé kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti “wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò dá sí ọ̀ràn ayé láti mú ìwà ibi kúrò pátápátá. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn pé Jèhófà ń kíyè sí ọ̀ràn ọmọ aráyé fínnífínní. Ó ń ṣèdájọ́ tirẹ̀ lọ, tí àkókò bá sì tó lójú rẹ̀, á ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ìdájọ́ rẹ̀ bá fi hàn. Ṣé ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ló máa ń ṣe? Aísáyà fi hàn pé ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ni. Ní ti ọ̀ràn orílẹ̀-èdè Júdà, Aísáyà kọ̀wé pé: “Nígbà náà ni [Jèhófà] gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe, ó sì fi àṣíborí ìgbàlà sí orí rẹ̀. Síwájú sí i, ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ àgbéwọ̀, ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí ẹni pé aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá ni.” (Aísáyà 59:17) Ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi Jèhófà wé jagunjagun kan tó ń dìhámọ́ra láti lọ jagun. Ó ṣe tán láti ja ìjà ìgbàlà láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ó dá a lójú pé òdodo pọ́ńbélé, tí a kò lè bì wó, ni òdodo òun. Yóò sì lo ìtara láìbẹ̀rù bó ṣe ń bá ìdájọ́ nìṣó. Ó dájú pé òdodo ni yóò sì lékè.
15. (a) Kí ni yóò jẹ́ ìṣesí àwọn Kristẹni tòótọ́ nígbà tí Jèhófà bá ń ṣèdájọ́? (b) Kí ni a lè sọ nípa ìdájọ́ Jèhófà?
15 Ní àwọn ilẹ̀ kan lóde òní, àwọn ọ̀tá òtítọ́ ń gbìyànjú láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nípa títan ìròyìn èké kálẹ̀ láti fi bà wọ́n jẹ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́ tìkọ̀ láti gbèjà òtítọ́ o, àmọ́ wọn kì í wá ọ̀nà láti gbẹ̀san ohun tí ẹnì kan bá fi ṣe wọ́n. (Róòmù 12:19) Kódà nígbà tí Jèhófà bá máa mú kí Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà wá jíhìn, àwọn olùjọsìn Jèhófà kò ní kópa nínú ìparun rẹ̀ rárá. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ti sọ pé fúnra òun lòun máa gbẹ̀san, àti pé ó máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ nígbà tí àkókò bá tó. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí mú un dá wa lójú pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìbálò náà ni òun yóò san ẹ̀san lọ́nà tí ó bá a mu rẹ́gí, ìhónú fún àwọn elénìní rẹ̀, ìlòsí yíyẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Yóò san ìlòsí yíyẹ fún àwọn erékùṣù.” (Aísáyà 59:18) Bí ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe rí nígbà ayé Aísáyà ni yóò ṣe rí lónìí, yàtọ̀ sí pé yóò jẹ́ ìdájọ́ ẹ̀tọ́, yóò tún jẹ́ àṣetán porogodo. Kódà yóò dé “àwọn erékùṣù,” ìyẹn dé àwọn ibi tó jìnnà réré pàápàá. Kò ní sí pé ẹnikẹ́ni wà níbi tó jìnnà réré jù tàbí ibi tó jẹ́ àdádó jù tí ọwọ́ ìdájọ́ Jèhófà ò fi ní tó o.
16. Ta ni yóò la ìdájọ́ tí Jèhófà yóò ṣe já, ẹ̀kọ́ wo ni lílà tí wọ́n bá là á já yóò sì kọ́ wọn?
16 Jèhófà yóò dá àwọn tó bá ń làkàkà láti ṣe ohun tó tọ́ láre. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé láti ìpẹ̀kun kan ayé dé ìpẹ̀kun kejì, ìyẹn kárí ayé, ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ti là á já. Bí wọ́n sì ṣe rí i pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn, ìyẹn á tún mú kí bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rù rẹ̀ àti ọ̀wọ̀ tí wọ́n ń fi fún un túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. (Málákì 1:11) A kà á pé: “Láti wíwọ̀-oòrùn sì ni wọn yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù orúkọ Jèhófà, àti ògo rẹ̀ láti yíyọ oòrùn, nítorí pé yóò wọlé wá bí odò tí ń kó wàhálà báni, èyí tí ẹ̀mí Jèhófà gan-an ń gbá lọ.” (Aísáyà 59:19) Bí ìjì líle tó ń gbá alagbalúgbú omi tó ga bí òkè, tó sì ń fi omi yìí ru gbogbo ohun tó bá pàdé lọ́nà lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí Jèhófà yóò ṣe gbá gbogbo ohun tó bá ń dènà pé kí ìfẹ́ rẹ̀ má ṣe ṣẹ lọ. Ẹ̀mí rẹ̀ lágbára ju agbára yòówù kí èèyàn ní lọ. Nígbà tó bá lò ó láti fi dá àwọn èèyàn àti orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́, ó dájú pé yóò ṣàṣeyọrí.
Ìrètí àti Ìbùkún fún Àwọn Tó Ronú Pìwà Dà
17. Ta ni Olùtúnnirà Síónì, ìgbà wo ló sì tún Síónì rà?
17 Lábẹ́ Òfin Mósè, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú, olùtúnnirà lè rà á padà kúrò lóko ẹrú. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ níṣàájú, ó ti sọ pé Jèhófà ni Olùtúnnirà àwọn kan tó ronú pìwà dà. (Aísáyà 48:17) Ó tún ṣàpèjúwe rẹ̀ nísinsìnyí pẹ̀lú pé ó jẹ́ Olùtúnnirà àwọn tó bá ronú pìwà dà. Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ ìlérí Jèhófà, ó ní: “‘Dájúdájú, Olùtúnnirà yóò sì wá sí Síónì, àti sọ́dọ̀ àwọn tí ń yí padà kúrò nínú ìrélànàkọjá nínú Jékọ́bù,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Aísáyà 59:20) Ìlérí tó fini lọ́kàn balẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n ó tún ní ìmúṣẹ síwájú sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yìí yọ látinú Bíbélì Septuagint, ó sì ní wọ́n ṣẹ sí àwọn Kristẹni lára. Ó kọ̀wé pé: “Lọ́nà yìí ni a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Olùdáǹdè yóò jáde wá láti Síónì, yóò sì yí àwọn ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run padà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù. Èyí sì ni májẹ̀mú náà níhà ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú wọn, nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.’” (Róòmù 11:26, 27) Ní tòótọ́, ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ dé rìn jìnnà gan-an ni, àní ó rìn jìnnà dé ìgbà tiwa ó tún ré kọjá rẹ̀ pàápàá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
18. Ìgbà wo ni Jèhófà mú kí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wáyé, báwo ló sì ṣe mú kó wáyé?
18 Ní ọ̀rúndún kìíní, àṣẹ́kù kéréje nínú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tẹ́wọ́ gba Jésù pé òun ni Mèsáyà. (Róòmù 9:27; 11:5) Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí ọgọ́fà lára àwọn onígbàgbọ́ yẹn, ó sì mú wọn wọ májẹ̀mú tuntun rẹ̀ tí Jésù Kristi jẹ́ alárinà rẹ̀. (Jeremáyà 31:31-33; Hébérù 9:15) Ọjọ́ yẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wáyé, orílẹ̀-èdè tuntun kan tí èèyàn kì í tipa jíjẹ́ ọmọ Ábúráhámù nípa ti ara di ará ibẹ̀ bí kò ṣe nípa pé kí onítọ̀hún jẹ́ ẹni táa fi ẹ̀mí Ọlọ́run bí. (Gálátíà 6:16) Orílẹ̀-èdè tuntun yìí ní àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ nínú, ìyẹn sì bẹ̀rẹ̀ látorí Kọ̀nílíù. (Ìṣe 10:24-48; Ìṣípayá 5:9, 10) Nípa báyìí, wọ́n di ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run gbà ṣọmọ, wọ́n sì di ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, àti ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù.—Róòmù 8:16, 17.
19. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run dá?
19 Nísinsìnyí, Jèhófà wá bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run dá májẹ̀mú. A kà á pé: “‘Ní tèmi, èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn,’ ni Jèhófà wí. ‘Ẹ̀mí mi tí ó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ—a kì yóò mú wọn kúrò ní ẹnu rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ-ọmọ rẹ,’ ni Jèhófà wí, ‘láti ìsinsìnyí lọ àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.’” (Aísáyà 59:21) Yálà ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ sára Aísáyà fúnra rẹ̀ tàbí kò ṣẹ o, ó dájú pé wọ́n ṣẹ lára Jésù, ẹni tí a mú kó dá lójú pé “yóò rí àwọn ọmọ rẹ̀.” (Aísáyà 53:10) Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹ̀mí Jèhófà sì tún bà lé e. (Jòhánù 1:18; 7:16) Ó sì tún bá a mu gẹ́ẹ́ pé àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jọ jẹ́ ajùmọ̀jogún, àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run, gba ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bákan náà, wọ́n sì ń wàásù ohun tí wọ́n kọ́ látọ̀dọ̀ Bàbá wọn ọ̀run. Gbogbo wọn jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 54:13; Lúùkù 12:12; Ìṣe 2:38) Jèhófà wá dá májẹ̀mú wàyí, yálà nípasẹ̀ Aísáyà tàbí nípasẹ̀ Jésù tí Aísáyà ṣàpẹẹrẹ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, pé òun kò ní fi ẹnikẹ́ni rọ́pò wọn, pé ńṣe lòun yóò máa lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òun àní títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. (Aísáyà 43:10) Ṣùgbọ́n, àwọn wo wá ni “àwọn ọmọ-ọmọ” wọn tó tún jàǹfààní látinú májẹ̀mú yìí?
20. Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ṣe ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
20 Láyé àtijọ́, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn àṣẹ́kù kéréje tí wọ́n tẹ́wọ́ gba Mèsáyà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ti ara jáde lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ láti lọ máa wàásù ìhìn rere nípa Kristi. Ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ ló sì ti tipasẹ̀ Jésù, Irú Ọmọ Ábúráhámù náà, “bù kún ara wọn,” bẹ̀rẹ̀ látorí Kọ̀nílíù. Wọ́n di ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run, àti irú ọmọ onípò kejì nínú irú ọmọ Ábúráhámù. Wọ́n jẹ́ ara “orílẹ̀-èdè mímọ́” ti Jèhófà, iṣẹ́ wọ́n sì jẹ́ láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 Pétérù 2:9; Gálátíà 3:7-9, 14, 26-29.
21. (a) Irú “àwọn ọmọ-ọmọ” wo ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti bí lákòókò òde òní? (b) Báwo ni májẹ̀mú tí Jèhófà dá, tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣe ń fi “àwọn ọmọ-ọmọ” yìí lọ́kàn balẹ̀?
21 Láyé òde òní, ó jọ pé a ti kó ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run jọ tán. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń gba ìbùkún Sáàmù 37:11, 29) “Àwọn ọmọ-ọmọ” yìí pẹ̀lú gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì gba ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Aísáyà 2:2-4) Lóòótọ́, a kò fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n sí ẹni tó ń kópa nínú májẹ̀mú tuntun, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń fún wọn lókun láti lè borí gbogbo ìdènà tí Sátánì ń gbé dínà iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Aísáyà 40:28-31) Iye wọn ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, ó sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i bí àwọn náà ṣe ń bí ọmọ-ọmọ pẹ̀lú. Májẹ̀mú tí Jèhófà dá, tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, fún àwọn ẹni àmì òróró ń fi “àwọn ọmọ-ọmọ” wọ̀nyí lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò máa bá a lọ láti lo àwọn náà gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀ títí ayérayé.—Ìṣípayá 21:3, 4, 7.
lọ́nà tó tiẹ̀ tún gadabú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní ti pé Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti ní “àwọn ọmọ-ọmọ,” ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń retí láti wà láàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (22. Ìdánilójú wo ni a lè ní nínú Jèhófà, ipa wo ló sì yẹ kí èyí ní lórí wa?
22 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà náà. Ó fẹ́ láti gbà wá là, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀! Ọwọ́ rẹ̀ kò lè kúrú láé; yóò máa bá a lọ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ là. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní kúrò lẹ́nu gbogbo ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, “láti ìsinsìnyí lọ àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.”
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 294]
Kirisẹ́ńdọ̀mù Bá Jerúsálẹ́mù Apẹ̀yìndà Dọ́gba
Jerúsálẹ́mù, olú ìlú orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn, ṣàpẹẹrẹ ètò àjọ Ọlọ́run ti ọ̀run tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí àti bákan náà, àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró táa jí dìde lọ sí ọ̀run láti di aya Kristi. (Gálátíà 4:25, 26; Ìṣípayá 21:2) Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ará Jerúsálẹ́mù máa ń hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, a sì ṣàpèjúwe ìlú yẹn gẹ́gẹ́ bíi kárùwà àti panṣágà. (Ìsíkíẹ́lì 16:3, 15, 30-42) Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, Jerúsálẹ́mù jẹ́ àpẹẹrẹ tó bá Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà mu gan-an ni.
Jésù pe Jerúsálẹ́mù ní “olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán jáde sí i lókùúta.” (Lúùkù 13:34; Mátíù 16:21) Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe bíi ti Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́, wọ́n láwọn ń sin Ọlọ́run tòótọ́, ṣùgbọ́n wọ́n yapa jìnnà kúró nínú àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀. Kí ó dá wa lójú pé ìwọ̀n òdodo kan náà tí Jèhófà fi ṣèdájọ́ Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà ni yóò lò láti fi ṣèdájọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 296]
Òdodo ló yẹ kí adájọ́ fi ṣèdájọ́, kí ó máa wá ọ̀nà láti ṣèdájọ́ òdodo, kí ó má sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 298]
Bí omi tó kún àkúnya ni ìdájọ́ Jèhófà yóò ṣe gbá gbogbo ohun tó bá ń dènà pé kí ìfẹ́ rẹ̀ má ṣe ṣẹ lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 302]
Jèhófà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àǹfààní jíjẹ́ ẹlẹ́rìí òun kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn òun láé