A Kó Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè Jọ sí Ilé Àdúrà Ọlọ́run
Orí Kẹtàdínlógún
A Kó Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè Jọ sí Ilé Àdúrà Ọlọ́run
1, 2. Ìkéde amóríyá wo ló wáyé lọ́dún 1935, ara kí ni ìkéde yẹn sì jẹ́?
NÍ FRIDAY, May 31, 1935, Joseph F. Rutherford bá àwùjọ tó wá sí àpéjọpọ̀ ní ìlú Washington, D.C. sọ̀rọ̀ kan. Ó jíròrò nípa ohun tí a lè fi dá àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran mọ̀. Nígbà tí Arákùnrin Rutherford dé òtéńté ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ǹjẹ́ gbogbo àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lè jọ̀wọ́ dìde dúró?” Ọ̀kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà yẹn sọ pé “ó ju ìlàjì àwùjọ tó wà níbẹ̀ tó dìde.” Ni Rutherford wá sọ pé: “Ẹ wò ó! Ogunlọ́gọ̀ ńlá ọ̀hún rèé!” Ohun tí ẹlòmíràn tó wà níbẹ̀ tún rántí ni pé: “Kẹ́kẹ́ kọ́kọ́ pa, lẹ́yìn náà, igbe ìdùnnú wá sọ, ìhó ayọ̀ yẹn sí milẹ̀ tìtì, ó sì ń bá a lọ fúngbà pípẹ́.”—Ìṣípayá 7:9.
2 Àkókò pàtàkì kan nìyẹn jẹ́ nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ń ṣẹ bọ̀ látẹ̀yìnwá, àsọtẹ́lẹ̀ tó ti wà lákọọ́lẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] ọdún ṣáájú, èyí tó wá di Aísáyà orí kẹrìndínlọ́gọ́ta nínú Bíbélì wa. Àwọn ìlérí tó tuni nínú àti ìkìlọ̀ tó lágbára ní ń bẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí bíi ti ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nínú Aísáyà. Nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹ, àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú nígbà ayé Aísáyà ni ọ̀rọ̀ náà bá wí, ṣùgbọ́n ìmúṣẹ rẹ̀ rìn jìnnà dé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún títí kan ìgbà ayé tiwa.
Ohun Tó Wé Mọ́ Rírí Ìgbàlà
3. Bí àwọn Júù bá ń wá ìgbàlà Ọlọ́run, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
3 Àwọn Júù ni ọ̀rọ̀ ìṣítí tó bẹ̀rẹ̀ Aísáyà orí kẹrìndínlọ́gọ́ta ń bá wí. Àmọ́, gbogbo àwọn olùjọsìn tòótọ́ ló yẹ kó kọbi ara sí ohun tí wòlíì yìí kọ sílẹ̀ o. A kà á pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ẹ pa ìdájọ́ òdodo mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí í ṣe òdodo. Nítorí pé ìgbàlà mi kù sí dẹ̀dẹ̀ kí ó wọlé wá, àti òdodo mi kí a ṣí i payá. Aláyọ̀ ni ẹni kíkú tí ń ṣe èyí, àti ọmọ aráyé tí ó rọ̀ mọ́ ọn, tí ń pa sábáàtì mọ́ kí ó má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́, tí ó sì ń pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kí ó má bàa ṣe búburú èyíkéyìí.’” (Aísáyà 56:1, 2) Àwọn ará Júdà tó ń wá ìgbàlà Ọlọ́run ní láti pa Òfin Mósè mọ́, wọ́n ní láti pa ìdájọ́ òdodo mọ́, wọ́n sì ní láti gbé ìgbé ayé òdodo. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé olódodo ni Jèhófà fúnra rẹ̀. Àwọn tó bá ń lépa òdodo a máa ní ayọ̀ tó ń tipa rírí ojú rere Jèhófà wá.—Sáàmù 144:15b.
4. Kí nìdí tí pípa Sábáàtì mọ́ fi ṣe pàtàkì ní Ísírẹ́lì?
4 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tẹnu mọ́ pípa Sábáàtì mọ́ nítorí pé Sábáàtì jẹ́ apá pàtàkì kan nínú Òfin Mósè. Ní ti gidi, ṣíṣàìpa Sábáàtì mọ́ jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí àwọn ará Júdà fi dèrò ìgbèkùn. (Léfítíkù 26:34, 35; 2 Kíróníkà 36:20, 21) Àmì àkànṣe àjọṣe tí ń bẹ láàárín Jèhófà àti àwọn Júù ni Sábáàtì jẹ́, àwọn tó bá sì ń pa Sábáàtì mọ́ ń fi hàn pé àwọn fi ọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe yẹn. (Ẹ́kísódù 31:13) Síwájú sí i, pípa tí àwọn tó gbé láyé ìgbà Aísáyà yìí bá ń pa Sábáàtì mọ́ yóò mú wọn rántí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wọn. Pípa tí wọ́n bá ń pa á mọ́ yóò mú wọn rántí àánú rẹ̀ sí wọn pẹ̀lú. (Ẹ́kísódù 20:8-11; Diutarónómì 5:12-15) Paríparì rẹ̀, pípa Sábáàtì mọ́ yóò jẹ́ kí wọ́n ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan gbòógì tí yóò máa bá a lọ déédéé, fún jíjọ́sìn Jèhófà. Sísinmi lẹ́nu iṣẹ́ wọn ojoojúmọ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ yóò fún àwọn ará Júdà láǹfààní láti gbàdúrà, láti kẹ́kọ̀ọ́, àti láti ṣàṣàrò.
5. Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn pípa Sábáàtì mọ́ sílò?
5 Àwọn Kristẹni wá ńkọ́ o? Ṣé ìṣírí nípa ti pípa Sábáàtì Kólósè 2:16, 17) Síbẹ̀síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “ìsinmi ti sábáàtì kan” wà fún àwọn Kristẹni olóòótọ́. “Ìsinmi ti sábáàtì” yìí wé mọ́ níní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù láti lè ní ìgbàlà, àti jíjáwọ́ nínú gbígbẹ́kẹ̀ lé kìkì àwọn iṣẹ́ ẹni. (Hébérù 4:6-10) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Sábáàtì ń jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní rántí bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ètò tí Ọlọ́run ṣe fún rírí ìgbàlà. Ó tún jẹ́ ìránnilétí pàtàkì fún wọn pé ó ṣe pàtàkì láti ní àjọse tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ọ̀nà ìjọsìn tó ń lọ déédéé láìyẹ̀.
mọ́ yìí kan àwọn náà? Kò kàn wọ́n ní tààràtà, nítorí àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin, nípa bẹ́ẹ̀ a kò béèrè pé kí wọ́n pa Sábáàtì mọ́. (Ìtùnú fún Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè àti Ìwẹ̀fà
6. Ẹgbẹ́ méjì wo ló gbàfiyèsí báyìí?
6 Jèhófà wá bá ẹgbẹ́ méjì tó ń fẹ́ sìn ín ṣùgbọ́n tí Òfin Mósè kò gbà wọ́n láàyè láti wá sínú ìjọ àwọn Júù, sọ̀rọ̀ wàyí. A kà á pé: “Kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà má sì sọ pé, ‘Láìsí àní-àní, Jèhófà yóò pín mi níyà sí àwọn ènìyàn rẹ̀.’ Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, ‘Wò ó! Igi gbígbẹ ni mí.’” (Aísáyà 56:3) Ìbẹ̀rù ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni pé wọ́n á ké òun kúrò lára Ísírẹ́lì. Ìdààmú ti ìwẹ̀fà ni pé òun kò lè bímọ tí yóò máa jẹ́ orúkọ òun. Kí ẹgbẹ́ méjèèjì lọ mọ́kàn le. Kí a tó rí ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí á ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe wà síra wọn lábẹ́ Òfin.
7. Ààlà wo ni Òfin pa fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní Ísírẹ́lì?
7 Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè aláìdádọ̀dọ́ kò lè bá Ísírẹ́lì ṣe ìjọsìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò lè bá wọn jẹ nínú Ìrékọjá. (Ẹ́kísódù 12:43) Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ máa tẹ àwọn òfin ilẹ̀ Ísírẹ́lì lójú yóò rí ẹ̀tọ́ tirẹ̀ àti aájò àlejò gbà, ṣùgbọ́n kò lè sí àjọṣe tó wà títí gbére láàárín àwọn àti orílẹ̀-èdè yẹn. Lóòótọ́ o, tọkàntara làwọn kan fi gba Òfin, àwọn ọkùnrin sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa dídá adọ̀dọ́. Wọn á wá di aláwọ̀ṣe, ẹni tó láǹfààní láti jọ́sìn nínú àgbàlá ilé Jèhófà, tí wọ́n sì kà sí ara ìjọ ní Ísírẹ́lì. (Léfítíkù 17:10-14; 20:2; 24:22) Àmọ́, àwọn aláwọ̀ṣe pàápàá kò lè kópa ní kíkún nínú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì dá, wọn kò sì ní ogún ilẹ̀ kankan nínú Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yòókù lè yíjú sí tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ẹ̀rí sì fi hàn pé àwọn àlùfáà lè bá wọn rú ẹbọ wọn tí ó bá ṣáà ti bá Òfin mu. (Léfítíkù 22:25; 1 Àwọn Ọba 8:41-43) Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn.
Àwọn Ìwẹ̀fà Gba Orúkọ Tí Yóò Wà fún Àkókò Tó Lọ Kánrin
8. (a) Lábẹ́ Òfin, ojú wo ni wọ́n fi ń wo àwọn ìwẹ̀fà? (b) Kí ni wọ́n ń lo àwọn ìwẹ̀fà fún ní àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí, kí sì ni a lè lo ọ̀rọ̀ náà “ìwẹ̀fà” fún nígbà mìíràn?
8 Òfin kò ka ìwẹ̀fà kankan sí ojúlówó ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kódà bàbá àti ìyá rẹ̀ ì báà jẹ́ Júù. * (Diutarónómì 23:1) Àwọn ìwẹ̀fà ní ipò pàtàkì tiwọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí kan láyé ìgbà tí wọ́n ṣì ń kọ Bíbélì, ó sì jẹ́ àṣà wọn láti tẹ àwọn kan lọ́dàá lára àwọn ọmọ tí wọ́n bá kó nígbèkùn nígbà ogun. Wọ́n máa ń yan àwọn ìwẹ̀fà ṣe òṣìṣẹ́ láàfin. Ìwẹ̀fà lè jẹ́ “olùṣètọ́jú àwọn obìnrin,” “olùṣètọ́jú àwọn wáhàrì,” tàbí kí ó jẹ́ ìránṣẹ́ ayaba. (Ẹ́sítérì 2:3, 12-15; 4:4-6, 9) Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tàbí pé wọ́n dìídì máa ń wá àwọn ìwẹ̀fà tí wọ́n yóò máa ṣiṣẹ́ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì. *
9. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Jèhófà sọ fún àwọn tó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ti ara ìyára?
9 Yàtọ̀ sí pé àwọn tó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ti ara ìyára ní Ísírẹ́lì kò lè fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́, ẹ̀tẹ́ ńlá tún máa ń bá wọn ní ti pé wọn kò lè bímọ tí yóò máa jẹ́ orúkọ ìdílé wọn nìṣó. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí á mà jẹ́ ìtùnú o! A kà á pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún àwọn ìwẹ̀fà tí ń pa àwọn sábáàtì mi mọ́, tí wọ́n sì ti yan ohun tí mo ní inú dídùn sí, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi: ‘Àní èmi yóò fún wọn ní ohun ìránnilétí àti orúkọ ní ilé mi àti nínú àwọn ògiri mi, ohun tí ó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fún wọn, ọ̀kan tí a kì yóò ké kúrò.’”—Aísáyà 56:4, 5.
10. Ìgbà wo ni ipò àwọn ìwẹ̀fà wá yí padà, àǹfààní wo ló sì ti ṣí sílẹ̀ fún wọn látìgbà yẹn wá?
10 Dájúdájú, ìgbà ń bọ̀ tí jíjẹ́ tí ẹnì kan jẹ́ ìwẹ̀fà ní ti ara ìyára kò ní jẹ́ ìdíwọ́ fún kíkà á sí ìránṣẹ́ Jèhófà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bí àwọn ìwẹ̀fà bá gbọ́ràn, wọn yóò ní “ohun ìránnilétí,” tàbí àyè kan, nínú ilé Jèhófà, wọn yóò sì ní orúkọ tó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin lọ. Ìgbà wo ni èyí wáyé? Ẹ̀yìn ikú Jésù Kristi mà ni o. Ìgbà yẹn ni májẹ̀mú tuntun rọ́pò májẹ̀mú Òfin ògbólógbòó, tí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” sì rọ́pò Ísírẹ́lì nípa ti ara. (Gálátíà 6:16) Láti ìgbà yẹn ni àyè ti ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ láti lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. Nítorí pé ìyàtọ̀ àti ìrísí ẹni nípa ti ara kò jẹ́ nǹkan kan mọ́. Àwọn tó bá ti fi ìṣòtítọ́ forí tì í, bó ṣe wù kí wọ́n rí ní ìrísí, yóò ní “orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin . . . ọ̀kan tí a kì yóò ké kúrò.” Jèhófà kò ní gbàgbé wọn. Ọlọ́run yóò kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí,” tí àsìkò bá sì tó lójú rẹ̀, wọn yóò gba ìyè àìnípẹ̀kun.—Málákì 3:16; Òwe 22:1; 1 Jòhánù 2:17.
Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè Ń Jọ́sìn Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
11. Kí ni Jèhófà fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè níṣìírí láti ṣe bí wọn yóò bá rí ìbùkún gbà?
11 Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wá ńkọ́ o? Àsọtẹ́lẹ̀ yìí padà sórí ọ̀rọ̀ tiwọn wàyí, ọ̀rọ̀ ìtùnú ńláǹlà sì ni Jèhófà fẹ́ sọ fún wọn. Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó sì ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, láti lè di ìránṣẹ́ fún un, gbogbo àwọn tí ń pa sábáàtì mọ́ kí wọ́n má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi, dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́ mi pẹ̀lú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Odindi ọrẹ ẹbọ sísun wọn àti àwọn ẹbọ wọn yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi. Nítorí pé ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà fún gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 56:6, 7.
12. Nígbà kan rí, òye wo ló wà nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ní ti “àwọn àgùntàn mìíràn”?
12 Nígbà tiwa yìí, “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” ti yọjú ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n lóye pé iye àwọn tí yóò rí ìgbàlà yóò pọ̀ gidigidi ju iye àwọn tí yóò bá Jésù jọba ní ọ̀run, ìyẹn àwọn táa mọ̀ sí Ísírẹ́lì Ọlọ́run lóde òní. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 10:16 tó sọ pé: “Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe ara ọ̀wọ́ yìí; àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá, wọn yóò sì fetí sí ohùn mi, wọn yóò sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” Wọ́n lóye pé àwọn “àgùntàn mìíràn” yìí jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn tí yóò wà lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà gbọ́ pé ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù Kristi ni wọ́n tó máa yọjú.
13. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣàlàyé pé ó ní láti jẹ́ ìgbà ìparí ètò àwọn nǹkan ni àwọn àgùntàn inú Mátíù orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n yóò yọjú?
13 Nígbà tó yá, òye Ìwé Mímọ́ kan tó tan mọ́ ọn, èyí tó sọ nípa àwọn àgùntàn, túbọ̀ yé wọn sí i. Inú Mátíù orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni àkọsílẹ̀ àkàwé tí Jésù ṣe yìí nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ wà. Gẹ́gẹ́ bí àkàwé yẹn ṣe wí, àwọn àgùntàn rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà nítorí pé wọ́n ṣètìlẹyìn fún àwọn arákùnrin Jésù. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ kan tó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹni àmì òróró, arákùnrin Kristi yìí ni wọ́n. Lọ́dún 1923, nígbà àpéjọpọ̀ kan ní ìlú Los Angeles, California, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n ṣàlàyé pé àárín àwọn ọjọ́ tó parí ètò àwọn nǹkan yìí ni àwọn àgùntàn yìí yóò ní láti yọjú, kì í ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé àkàwé yìí jẹ́ ara ìdáhùn Jésù sí ìbéèrè tí wọ́n béèrè pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.
14, 15. Báwo ni òye ṣe túbọ̀ ń yé wọn sí i ní àkókò òpin nípa ipò àwọn tó jẹ́ àgùntàn mìíràn?
14 Ní àwọn ọdún 1920 sí 1929, àwọn kan tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá ń rí i pé kò ṣe àwọn bíi pé ẹ̀mí Jèhófà ń bá àwọn jẹ́rìí pé àwọn gba ìpè ọ̀run. Síbẹ̀, ìránṣẹ́ tó ń fi ìtara sin Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni wọ́n. Lọ́dún 1931, òye túbọ̀ ń yé wọn sí i nípa ipò tí àwọn wọ̀nyí wà nígbà tí a tẹ ìwé Vindication jáde. Bí ìwé Vindication ṣe ń jíròrò ìwé Ìsíkíẹ́lì inú Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ, ó ṣàlàyé ìran “ọkùnrin” kan tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé. (Ìsíkíẹ́lì 9:1-11) Ńṣe ni “ọkùnrin” yìí ń la Jerúsálẹ́mù lọ tí ó ń sàmì sórí àwọn tó ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. “Ọkùnrin” yìí dúró fún àwọn arákùnrin Jésù, ìyẹn àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé nígbà ìdájọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù tó jẹ́ àpẹẹrẹ Jerúsálẹ́mù àtijọ́. Àwọn tí ó sàmì sí jẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn tó ń gbé ayé lásìkò yẹn. Nínú ìran yẹn, wọ́n dá àwọn wọ̀nyí sí nígbà tí àwọn olùgbẹ̀san fún Jèhófà wá gbẹ̀san lára ìlú apẹ̀yìndà yẹn.
15 Lọ́dún 1932, òye ìjìnlẹ̀ táa ní nípa ìṣẹ̀lẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Jéhù ọba Ísírẹ́lì àti Jèhónádábù tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tó wá ṣètìlẹyìn fún un, jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn àgùntàn mìíràn yìí ṣe láti fi ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi, àní gẹ́lẹ́ bí Jèhónádábù ṣe gbéra láti ṣètìlẹyìn fún Jéhù bó ṣe ń pa ìjọsìn Báálì run. Paríparì rẹ̀, lọ́dún 1935, a dá àwọn àgùntàn mìíràn tó ń gbé ní àkókò òpin ètò àwọn nǹkan yìí mọ̀, pé àwọn ni ogunlọ́gọ̀ ńlá tí àpọ́sítélì Jòhánù rí lójú ìran. Àpéjọpọ̀ tó wáyé ní ìlú Washington, D.C., èyí táa mẹ́nu kàn níṣàájú yẹn, ni àlàyé yìí ti kọ́kọ́ wáyé, nígbà tí Joseph F. Rutherford tọ́ka sí àwọn tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé títí láé pé wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá.”
16. Àwọn àǹfààní àti ojúṣe wo ló jẹ́ ti “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè”?
16 Ìyẹn la fi wá rí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” ní ipa tó pọ̀ tí wọn yóò kó nínú ète Jèhófà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ńṣe ni wọ́n tọ Ísírẹ́lì Ọlọ́run wá láti lè sin Jèhófà. (Sekaráyà 8:23) Àwọn àti orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí wá jùmọ̀ ń rú ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run, wọ́n sì wọnú ìsinmi ti sábáàtì. (Hébérù 13:15, 16) Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ń sin Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, èyí tó jẹ́ “ilé àdúrà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (Máàkù 11:17) Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, ‘wọ́n sì fọ aṣọ wọn, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ Wọ́n ń sin Jèhófà déédéé, wọ́n sì “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru.”—Ìṣípayá 7:14, 15.
17. Báwo ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè òde òní ṣe rọ̀ mọ́ májẹ̀mú tuntun?
17 Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè òde òní yìí rọ̀ mọ́ májẹ̀mú tuntun ní ti pé wọ́n dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run, wọ́n wá ń rí àwọn àǹfààní àti ìbùkún tó ń tipa májẹ̀mú tuntun yẹn wá gbà. Lóòótọ́ wọn kò kópa nínú májẹ̀mú yẹn, àmọ́ tọkàntọkàn ni wọ́n ń jẹ́ kí àwọn òfin tó rọ̀ mọ́ ọn darí àwọn. Nípa bẹ́ẹ̀, òfin Jèhófà wà nínú ọkàn àyà wọn, Jeremáyà 31:33, 34; Mátíù 6:9; Jòhánù 17:3.
wọ́n sì wá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Baba wọn ọ̀run àti Ọba Aláṣẹ gíga jù lọ.—18. Iṣẹ́ ìkójọpọ̀ wo ló ń lọ lọ́wọ́ ní àkókò òpin yìí?
18 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń bá a lọ pé: “Àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tí ń kó àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọpọ̀, ni pé: ‘Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tirẹ̀ tí a ti kó jọpọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.’” (Aísáyà 56:8) Ní àkókò òpin yìí, Jèhófà ti kó “àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró jọpọ̀. Láfikún sí i, ó tún ń kó àwọn mìíràn jọpọ̀ pẹ̀lú, ìyẹn àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá. Wọ́n wá ń jọ́sìn pa pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lábẹ́ àbójútó Jèhófà àti Ọba tí ó gbé karí ìtẹ́, Kristi Jésù. Nítorí ìdúróṣinṣin wọn sí ìjọba Jèhófà tí Kristi ń ṣàkóso, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ti wá kó wọn jọ sínú agbo oníṣọ̀kan tó jẹ́ aláyọ̀.
Àwọn Afọ́jú Olùṣọ́, Ajá Tí Kò Lè Fọhùn
19. Kí ni wọ́n ké sí àwọn ẹranko pápá àti tinú igbó láti wá ṣe?
19 Ọ̀rọ̀ líle tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àgbọ́fọwọ́dití ló tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ atura tó gbéni ró tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí. Jèhófà ṣe tán láti fi àánú hàn sí àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ìwẹ̀fà. Ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú àwọn tó ní àwọn jẹ́ ara ìjọ Ọlọ́run ló ti dẹni àbùkù tí wọ́n máa tó dá lẹ́jọ́. Àní sẹ́, wọn kò tilẹ̀ yẹ lẹ́ni tí ìsìnkú ẹ̀yẹ tọ́ sí, àfi kí àwọn ẹranko ẹhànnà jẹ wọ́n ráúráú. Ìyẹn la fi rí i kà pé: “Gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá gbalasa, ẹ wá jẹun, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú igbó.” (Aísáyà 56:9) Kí ni àwọn ẹranko wọ̀nyí fẹ́ jẹ? Àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣàlàyé. Bí àlàyé yìí ṣe ń lọ, ó lè mú wa rántí ohun tó máa bá àwọn alátakò Ọlọ́run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tí ń bọ̀, tó jẹ́ pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ni wọ́n ó fi òkú wọn fún jẹ.—Ìṣípayá 19:17, 18.
20, 21. Àwọn ìkùnà wo ló mú kí àwọn aṣáájú ìsìn jẹ́ ẹni tí kò lè jẹ́ atọ́nà nípa tẹ̀mí?
20 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá a lọ pé: “Afọ́jú ni àwọn olùṣọ́ rẹ̀. Kò sí ìkankan nínú wọn tí ó ṣàkíyèsí. Ajá tí kò lè fọhùn ni gbogbo wọn; wọn kò lè gbó, wọ́n ń mí hẹlẹ, wọ́n ń dùbúlẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti máa tòògbé. Àní àwọn ajá tí ó le nínú ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn ni wọ́n; wọn kò ní ìtẹ́lọ́rùn rí. Wọ́n tún jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò mọ bí a ti ń lóye. Gbogbo wọn ti yí padà sí ọ̀nà ara wọn, olúkúlùkù fún èrè rẹ̀ aláìbá ìdájọ́ òdodo mu láti ojú ààlà tirẹ̀ pé: ‘Ẹ wá! Kí n mu wáìnì díẹ̀; kí a sì mu ọtí tí ń pani ní àmuyó kẹ́ri. Ó dájú pé ọ̀la yóò rí gẹ́gẹ́ bí òní, yóò tóbi lọ́nà tí ó pọ̀ sí i gidigidi.’”—21 Àwọn aṣáájú ìsìn ní Júdà sọ pé Jèhófà làwọn ń sìn. Wọ́n ní àwọn jẹ́ “olùṣọ́ rẹ̀.” Àmọ́, afọ́jú, aláìlè sọ̀rọ̀ àti ẹni tó ń tòògbé nípa tẹ̀mí ni wọ́n. Bí wọn kò bá lè máa ṣọ́nà kí wọ́n sì kéde ìkìlọ̀ nípa ewu tí ń bọ̀, kí wá ni ìwúlò wọn? Irú àwọn olùṣọ́ inú ìsìn bẹ́ẹ̀ kò lóye kankan, wọn kò tóótun láti tọ́ àwọn ẹni bí àgùntàn sọ́nà nípa tẹ̀mí rárá. Àti pé wọ́n tún jẹ́ oníwà ìbàjẹ́. Jẹgúdújẹrá onímọtara ẹni nìkan ni wọ́n. Dípò ti wọn ì bá fi tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà, ọ̀nà tara wọn ni wọ́n ń wá, tí wọ́n ń lépa èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, wọ́n ń mu ọtí líle lámuyó, wọ́n sì ń rọ àwọn ẹlòmíràn láti dà bí àwọn ṣe dà. Wọ́n ṣàìmọ ohunkóhun nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó kù sí dẹ̀dẹ̀ yẹn débi pé wọ́n ń sọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ fọkàn balẹ̀, pé nǹkan máa tó rọ̀ pẹ̀sẹ̀.
22. Báwo ló ṣe jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé Jésù dà bí tàwọn ti Júdà ìgbà àtijọ́?
22 Aísáyà ti lo irú àkàwé kan náà yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ìṣáájú láti fi ṣàpèjúwe àwọn aṣáájú ìsìn Júdà aláìṣòótọ́, pé wọ́n ti mutí yó, pé wọ́n ń tòògbé, àti pé wọn kò ní òye nípa tẹ̀mí. Wọ́n fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn di ẹrù pa àwọn èèyàn yẹn, wọ́n ń pa irọ́ fún wọn nínú ìsìn wọn, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ 2 Àwọn Ọba 16:5-9; Aísáyà 29:1, 9-14) Ó hàn kedere pé wọn kò fi ìyẹn kọ́gbọ́n. Ó bani nínú jẹ́ pé irú àwọn aṣáájú ìsìn kan náà ló wà ní ọ̀rúndún kìíní. Kàkà tí wọn ì bá fi tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tí Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ mú tọ̀ wọ́n wá, ṣe ni wọ́n kọ Jésù, wọ́n sì dìtẹ̀ láti ṣekú pá a. Jésù sọ ojú abẹ níkòó pé wọ́n jẹ́ “afọ́jú afinimọ̀nà,” ó sì fi kún un pé “bí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò.”—Mátíù 15:14.
lé Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́ dípò tí wọn ì bá fi yíjú sí Ọlọ́run. (Àwọn Olùṣọ́ Lóde Òní
23. Àsọtẹ́lẹ̀ Pétérù wo nípa àwọn aṣáájú ìsìn ló ti ṣẹ?
23 Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé àwọn olùkọ́ èké yóò dìde láti ṣi àwọn Kristẹni lọ́nà pẹ̀lú. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn wòlíì èké wà pẹ̀lú láàárín àwọn ènìyàn [Ísírẹ́lì], gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ èké yóò ti wà pẹ̀lú láàárín yín. Àwọn wọ̀nyí ni yóò yọ́ mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé wá, wọn yóò sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú olúwa tí ó rà wọ́n pàápàá, wọn yóò mú ìparun yíyára kánkán wá sórí ara wọn.” (2 Pétérù 2:1) Kí ni àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ẹ̀ya ìsìn tí irú àwọn olùkọ́ èké bẹ́ẹ̀ mú wá yọrí sí? Kirisẹ́ńdọ̀mù ni, èyí tí àwọn aṣáájú ìsìn rẹ̀ òde òní ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run bù kún àwọn olóṣèlú ọ̀rẹ́ wọn, tí wọ́n sì ń ṣèlérí pé ayé ṣì ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀. Àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ afọ́jú, aláìlèsọ̀rọ̀, wọ́n sì sùn fọnfọn ní ti àwọn ohun tẹ̀mí.
24. Ìṣọ̀kan wo ló wà láàárín Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí àti àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?
24 Àmọ́, Jèhófà ń kó ẹgbàágbèje àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wọlé wá sínú ilé àdúrà ńlá rẹ̀ nípa tẹ̀mí láti wá jọ́sìn pẹ̀lú àwọn tó kẹ́yìn nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti èdè púpọ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yìí ti wá, wọ́n wà níṣọ̀kan láàárín ara wọn àti pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Ó dá wọn lójú pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi nìkan ni ìgbàlà ti lè wá. Ìfẹ́ tí wọ́n fẹ́ Jèhófà sì sún wọn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì tí Ọlọ́run mí sí sì sọ jẹ́ ìtùnú fún wọn gan-an ni, ó ní: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ́ là.”—Róòmù 10:9.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 8 Ọ̀rọ̀ náà “ìwẹ̀fà” tún di èyí tí a ń lò fún ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin láìjẹ́ pé wọ́n tẹ̀ ẹ́ lọ́dàá. Nígbà tó sì ti jọ pé aláwọ̀ṣe ni ará Etiópíà tí Fílípì rì bọmi, tí wọ́n sì tún rì í bọmi ṣáájú kí ọ̀nà tó ṣí sílẹ̀ fún àwọn tí kì í ṣe Júù, a jẹ́ pé irú ìwẹ̀fà bí èyí ni tirẹ̀.—Ìṣe 8:27-39.
^ ìpínrọ̀ 8 Ìwẹ̀fà ni wọ́n pe Ebedi-mélékì tó ṣèrànwọ́ fún Jeremáyà, tó tún jẹ́ ẹni tó lè tọ Sedekáyà Ọba lọ fàlàlà. Ó jọ pé jíjẹ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin nìyẹn tọ́ka sí dípò ti pé ó jẹ́ ẹni tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá.—Jeremáyà 38:7-13.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 250]
Sábáàtì yóò fún wọn láǹfààní láti gbàdúrà, láti kẹ́kọ̀ọ́, àti láti ṣàṣàrò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 256]
A ṣe àlàyé yékéyéké nípa bí àwọn àgùntàn mìíràn ṣe jẹ́ nígbà àpéjọpọ̀ kan ní ìlú Washington, D.C., lọ́dún 1935 (fọ́tò batisí ló wà nísàlẹ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ló wà lápá ọ̀tún)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 259]
A ké sí àwọn ẹranko láti wá jẹ àsè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 261]
Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè àti Ísírẹ́lì Ọlọ́run jọ wà níṣọ̀kan