Jèhófà Ń Kọ́ Wa fún Ire Wa
Orí Kẹsàn-án
Jèhófà Ń Kọ́ Wa fún Ire Wa
1. Ìhà wo ni àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń kọ sí ọ̀rọ̀ Jèhófà?
BÍ JÈHÓFÀ bá sọ̀rọ̀, àwọn ọlọ́gbọ́n a fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, wọn a sì ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí. Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ló sì wà fún àǹfààní wa, nítorí pé ire wa jẹ ẹ́ lógún gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí ó ṣe dùn mọ́ni tó láti gbọ́ bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn tí ó bá dá májẹ̀mú láyé àtijọ́ sọ̀rọ̀ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́!” (Aísáyà 48:18) Wíwúlò tí àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run wúlò, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn, yẹ kó sún wa láti tẹ́tí sí Ọlọ́run kí a sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Àkọsílẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ mú kí a má lè ṣiyè méjì rárá pé Jèhófà ti pinnu láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
2. Torí àwọn wo ni wọ́n ṣe kọ ọ̀rọ̀ inú Aísáyà orí kejìdínláàádọ́ta, ta ló sì tún lè jàǹfààní nínú rẹ̀?
2 Ẹ̀rí fi hàn pé torí àwọn Júù tó máa di ìgbèkùn ní Bábílónì ni wọ́n ṣe kọ ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà orí kejìdínláàádọ́ta. Àmọ́, ìsọfúnni tó wà nínú ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jẹ́ èyí tí àwọn Kristẹni òde òní kò lè gbójú fò dá. Ní Aísáyà orí kẹtàdínláàádọ́ta, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Bábílónì. Nísinsìnyí, Jèhófà wá ń sọ ète ọkàn rẹ̀ nípa àwọn Júù tó jẹ́ ìgbèkùn nínú ìlú yẹn. Àgàbàgebè àwọn èèyàn Jèhófà àti fífi tí wọ́n fi orí kunkun ṣàìgba àwọn ìlérí rẹ̀ gbọ́ dun Jèhófà. Síbẹ̀ náà, ó fẹ́ láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ire wọn. Ó rí i pé àkókò ìyọ́mọ́ kan ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, tí yóò yọrí sí mímú àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn.
3. Kí ló ṣàìtọ́ nínú ìjọsìn Júdà?
3 Àwọn èèyàn Jèhófà mà kúkú ti yà kúrò nínú ìsìn mímọ́ jìnnà o! Gbólóhùn tí Aísáyà fi bẹ̀rẹ̀ múni ronú jinlẹ̀ gan-an ni, ó ní: “Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù, ẹ̀yin tí ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín àti ẹ̀yin tí ẹ jáde wá láti inú omi Júdà gan-an, ẹ̀yin tí ń fi orúkọ Jèhófà búra, tí ẹ sì ń mẹ́nu kan Ọlọ́run Ísírẹ́lì pàápàá, tí kì í ṣe ní òtítọ́, tí kì í sì í ṣe ní òdodo. Nítorí wọ́n ti pe ara wọn ní ará ìlú ńlá mímọ́ náà, wọ́n sì ti gbé ara wọn lé Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.” (Aísáyà 48:1, 2) Àgàbàgebè yìí mà kúkú pọ̀ o! Ó hàn kedere pé bí wọ́n ṣe láwọn “ń fi orúkọ Jèhófà búra,” ṣe ni wọ́n kàn ń dárúkọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n kò dénú ọkàn wọn. (Sefanáyà 1:5) Kó tó di pé àwọn Júù dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n máa ń sin Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù “ìlú ńlá mímọ́.” Ṣùgbọ́n ìjọsìn wọn kò dénú. Ọkàn wọn jìnnà sí Ọlọ́run gan-an ni, ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà jọ́sìn ‘kì í ṣe ní òtítọ́, kì í sì í ṣe ní òdodo.’ Wọn kò ní irú ìgbàgbọ́ tí àwọn baba ńlá wọn ní.—Málákì 3:7.
4. Irú ìjọsìn wo ni inú Jèhófà ń dùn sí?
4 Ọ̀rọ̀ Jèhófà rán wa létí pé ìjọsìn wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ò fọkàn ṣe. Ó ní láti jẹ́ tọkàntọkàn. Iṣẹ́ ìsìn gbà-máà-póò-rọ́wọ́-mi, bóyá tí a ṣe láti kàn fi tẹ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́rùn, tàbí láti fi gba ìyìn wọn, kì í ṣe “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11) Pípè tí èèyàn bá pe ara rẹ̀ ní Kristẹni kò ní kí ìjọsìn rẹ̀ torí ìyẹn wu Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:5) Lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì kéèyàn gbà pé Jèhófà wà, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ṣì ni ìyẹn jẹ́. Ìjọsìn tí ó tọkàn wá, tí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìmọrírì súnni ṣe ni Jèhófà ń fẹ́.—Kólósè 3:23.
Sísọ Àsọtẹ́lẹ̀ Àwọn Ohun Tuntun
5. Kí ni díẹ̀ lára “àwọn nǹkan àkọ́kọ́” tí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀?
5 Bóyá ìránnilétí ni àwọn Júù tó wà ní Bábílónì ń fẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà tún rán wọn létí lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun ni Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́, ó ní: “Àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ni mo ti sọ àní láti ìgbà yẹn, ẹnu mi ni wọ́n sì ti jáde lọ, mo sì ń mú kí wọ́n di gbígbọ́. Lójijì, mo gbé ìgbésẹ̀, àwọn nǹkan náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé wá.” (Aísáyà 48:3) Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti gbé ṣe sẹ́yìn, irú bíi dídá tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì àti bó ṣe fún wọn ní Ilẹ̀ Ìlérí láti jogún rẹ̀, ni “àwọn nǹkan àkọ́kọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:14, 15; 15:13, 14) Látẹnu Ọlọ́run ni irú àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ti jáde lọ; àtọ̀dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti wá. Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn gbọ́ àwọn àṣẹ rẹ̀, ohun tí wọ́n sì gbọ́ yẹ kó mú kí wọ́n ṣe bó ṣe sọ. (Diutarónómì 28:15) Ńṣe ló máa ń dìde fùú láti ṣe ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé Jèhófà ni Olódùmarè, ìyẹn mú kó dájú pé ète rẹ̀ á ṣẹ.—Jóṣúà 21:45; 23:14.
6. Báwo ni àwọn Júù ṣe jẹ́ “alágídí àti ọlọ̀tẹ̀” tó?
6 “Alágídí àti ọlọ̀tẹ̀” làwọn èèyàn Jèhófà yà. (Sáàmù 78:8) Ìyẹn ni Jèhófà fi sọ ojú abẹ níkòó fún wọn pé: “Ìwọ jẹ́ ẹni líle . . . ọrùn rẹ jẹ́ fọ́nrán iṣan irin . . . iwájú orí rẹ jẹ́ bàbà.” (Aísáyà 48:4) Bí irin tó ṣòro tẹ̀ làwọn Júù ṣe rí, kì í gbọ́ kì í gbà ẹ̀dá ni wọ́n. Ìdí kan nìyẹn tí Jèhófà fi máa ń ṣí àwọn nǹkan payá kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Láìṣe bẹ́ẹ̀, ohun tí àwọn èèyàn Jèhófà yóò sọ nípa àwọn ohun tí ó ṣe ni pé: “Òrìṣà mi ni ó ṣe wọ́n, àti pé ère gbígbẹ́ mi àti ère dídà mi ni ó pàṣẹ wọn.” (Aísáyà 48:5) Ǹjẹ́ ohun tí Jèhófà ń wí báyìí yóò ní ipa kankan lórí àwọn Júù aláìṣòótọ́? Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ìwọ ti gbọ́. Wo gbogbo rẹ̀. Ní tiyín, ẹ kì yóò ha sọ ọ́ bí? Mo ti jẹ́ kí o gbọ́ àwọn nǹkan tuntun láti àkókò yìí, àní àwọn nǹkan tí a fi pa mọ́, tí o kò mọ̀. Àkókò yìí ni a óò dá wọn, kì í sì í ṣe láti ìgbà yẹn, àní àwọn nǹkan tí o kò gbọ́ ṣáájú òní, kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀.’”—Aísáyà 48:6, 7.
7. Kí ni àwọn Júù tó wà nígbèkùn yóò ní láti gbà, kí ni wọ́n sì lè máa retí rẹ̀?
7 Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ni Aísáyà ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Bábílónì sílẹ̀. Nísinsìnyí tí àwọn Júù ti wá di ìgbèkùn ní Bábílónì, Ọlọ́run wá ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n ronú lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ṣẹ o. Ǹjẹ́ wọ́n lè ṣàìgbà pé Jèhófà ni Aísáyà 48:14-16) Àfi bíi pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ kàyéfì bẹ́ẹ̀ kàn ṣẹ́ yọ lójijì ni. Kò sẹ́ni tí ì bá lè lo òye ohun tó ń lọ nínú ayé láti fi rí i ṣáájú pé wọn yóò ṣẹlẹ̀. Wọ́n ṣẹ́ yọ kúlẹ́ bíi pé kò sí nǹkan kan tó fà á rárá. Ta ló mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn wáyé? Kò sí àní-àní nípa ẹni tó mú kí wọ́n ṣẹlẹ̀, ṣebí Jèhófà ló sáà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn láti nǹkan bí igba ọdún ṣáájú.
Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ? Nígbà tí àwọn ará Júdà sì ti rí i, tí wọ́n sì ti gbọ́ ọ pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́, kò ha yẹ kí àwọn pẹ̀lú kéde òtítọ́ yìí fún àwọn ẹlòmíràn bí? Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ṣí payá sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tuntun tí kò tíì ṣẹlẹ̀, irú bíi Kírúsì yóò ṣe ṣẹ́gun Bábílónì àti ìdáǹdè àwọn Júù. (8. Kí ni àwọn nǹkan tuntun tí àwọn Kristẹni òde òní ń retí, kí sì ni ìdí tí wọ́n fi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà?
8 Ẹ̀wẹ̀, àsìkò tí Jèhófà bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ òun ṣẹ sí náà ló ń ṣẹ. Àwọn Júù ayé àtijọ́ nìkan kọ́ ni ṣíṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ pèsè ẹ̀rí fún pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run, ó tún jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn Kristẹni lónìí pẹ̀lú. Àkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ sẹ́yìn, ìyẹn “àwọn nǹkan àkọ́kọ́,” mú kó dáni lójú pé àwọn nǹkan tuntun tí Jèhófà ṣèlérí, irú bíi pé “ìpọ́njú ńlá” yóò dé, pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yóò la ìpọ́njú ńlá já, pé “ayé tuntun” ń bọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ yóò ṣẹ pátá. (Ìṣípayá 7:9, 14, 15; 21:4, 5; 2 Pétérù 3:13) Ìdánilójú yẹn ń sún àwọn olódodo tó wà lóde òní láti máa fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí ọ̀ràn yìí ṣe rí lára wọn kò yàtọ̀ sí ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo ti sọ ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá. Wò ó! Èmi kò ṣèdíwọ́ fún ètè mi.”—Sáàmù 40:9.
Jèhófà Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu
9. Báwo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ “olùrélànàkọjá láti inú ikùn wá”?
9 Gbígbà tí àwọn Júù kò gba àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà gbọ́ ló fà á tí wọn kò fi kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi Aísáyà 48:8) Ńṣe ni Júdà kọ etí dídi sí ìhìn ayọ̀ Jèhófà. (Aísáyà 29:10) Ọ̀nà tí àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú gbà hùwà yìí fi hàn pé orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ “olùrélànàkọjá láti inú ikùn wá.” Látìgbà tí wọ́n ti dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀, àti ní gbogbo bí ìtàn rẹ̀ ṣe ti ń bá a bọ̀, ìwà ọ̀tẹ̀ ló ń hù ṣáá. Ìrélànàkọjá àti àdàkàdekè kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn náà kàn ń dá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwà tó ti mọ́ wọn lára ni.—Sáàmù 95:10; Málákì 2:11.
ń bá a lọ láti sọ fún wọn pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ kò là láti ìgbà yẹn wá. Nítorí mo mọ̀ dunjú pé ṣe ni o ń ṣe àdàkàdekè ṣáá, àti pé ‘olùrélànàkọjá láti inú ikùn wá’ ni a pè ọ́.” (10. Kí ni ìdí tí Jèhófà yóò fi kó ara rẹ̀ níjàánu?
10 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wọn kò ti wá kọjá àtúnṣe? Ó tì o. Òótọ́ ni pé Júdà ń ṣọ̀tẹ̀ wọ́n sì jẹ́ aládàkàdekè, àmọ́ Jèhófà a máa fìgbà gbogbo jẹ́ olóòótọ́ àti aláìyẹhùn. Ńṣe ni Jèhófà máa jẹ́ kí ìbínú rẹ̀ mọ níwọ̀n láti lè bọlá fún orúkọ ńlá rẹ̀. Ó ní: “Nítorí orúkọ mi, èmi yóò dẹwọ́ ìbínú mi, àti nítorí ìyìn mi, èmi yóò kó ara mi níjàánu sí ọ, kí kíké ọ kúrò má bàa ṣẹlẹ̀.” (Aísáyà 48:9) Ìwà ti Jèhófà mà kúkú yàtọ̀ sí tiwọn o! Ìwà àìṣòótọ́ ni Ísírẹ́lì àti Júdà tí wọ́n jẹ́ èèyàn Jèhófà ń hù sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, yóò gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tí yóò jẹ́ kó ní ìyìn àti ọlá. Ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí ó ké àwọn èèyàn àyànfẹ́ rẹ̀ kúrò.—Jóẹ́lì 2:13, 14.
11. Kí ni ìdí tí Ọlọ́run ò fi ní gbà kí wọ́n pa àwọn èèyàn rẹ̀ run ráúráú?
11 Ìbáwí Ọlọ́run ta àwọn kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ olódodo láàárín àwọn Júù tó wà nígbèkùn jí, wọ́n sì pinnu láti ṣe bí àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣe kọ́ni. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni ìkéde tó tẹ̀ lé e yìí ń fi lọ́kàn balẹ̀ gan-an, ó ní: “Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti fàdákà. Mo ti yàn ọ́ nínú ìléru ìyọ́rin ti ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́. Nítorí tèmi, nítorí tèmi, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀, nítorí pé báwo ni ẹnì kan ṣe lè jẹ́ kí a sọ òun di aláìmọ́? Èmi Aísáyà 48:10, 11) Gbígbà tí Jèhófà gbà kí wọ́n fi ojú àwọn èèyàn òun rí màbo bíi pé wọ́n wọnú ‘ìléru ti ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́,’ ti dán wọn wò, ó ti yọ́ wọn mọ́, ó sì ti fi ohun tó wà lọ́kàn wọn hàn. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà yẹn, èyí tí Mósè fi sọ fún àwọn baba ńlá wọn pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí, kí ó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, láti dán ọ wò, kí ó lè mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà rẹ.” (Diutarónómì 8:2) Ní gbogbo bí orílẹ̀-èdè yẹn ṣe hu ìwà ọ̀tẹ̀ nígbà yẹn, Jèhófà kò pa wọ́n run, kò sì ní pa orílẹ̀-èdè yẹn run ráúráú nísinsìnyí pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, orúkọ àti ọlá rẹ̀ á máa níyì lọ. Tó bá lọ di pé àwọn èèyàn rẹ̀ pa run látọwọ́ àwọn ará Bábílónì, a jẹ́ pé ó da májẹ̀mú tó dá, yóò sì sọ orúkọ rẹ̀ di aláìmọ́. Yóò dà bíi pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì kò lágbára láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ ni.—Ìsíkíẹ́lì 20:9.
kì yóò sì fi ògo tèmi fún ẹlòmíràn.” (12. Báwo ni wọ́n ṣe yọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?
Mátíù 24:14) Wòlíì Málákì sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé irú ìyọ́mọ́ yìí gẹ́lẹ́ yóò wáyé lásìkò tí Jèhófà yóò wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Málákì 3:1-4) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 1918. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ti la sáà ìdánwò gbígbóná janjan kọjá lásìkò ìgbónágbóoru Ogun Agbáyé Kìíní, ìdánwò yẹn ló sì yọrí sí sísọ tí wọ́n sọ Joseph F. Rutherford tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà àti àwọn kan lára àwọn èèyàn tó ń múpò iwájú nínú ẹgbẹ́ náà sẹ́wọ̀n. Àwọn Kristẹni olóòótọ́ inú yẹn jàǹfààní látinú yíyọ́ tí wọ́n yọ́ wọn mọ́ yẹn. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní yóò fi parí, ìpinnu wọn láti sin Ọlọ́run wọn atóbilọ́lá lọ́nàkọnà tó bá sọ pé kí wọn gbà sin òun túbọ̀ wá lágbára sí i ju ti tẹ́lẹ̀ rí.
12 Lóde òní pẹ̀lú, ìyọ́mọ́ tọ́ sí àwọn èèyàn Jèhófà. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, púpọ̀ lára ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéréje ìgbà yẹn ń sin Ọlọ́run nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn fẹ́ láti ṣe ohun tó wù ú, ṣùgbọ́n ète òdì, bíi fífẹ́ láti di olókìkí, làwọn kan ní ní tiwọn. Kí ẹgbẹ́ kékeré yẹn tó lè mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere kárí ayé tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò di ṣíṣe lásìkò òpin, ó ń béèrè pé kí a yọ́ wọn mọ́. (13. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn Jèhófà sí inúnibíni láti àwọn ọdún ẹ̀yìn Ogun Àgbáyé Kìíní wá?
13 Láti ìgbà yẹn wá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fara gba onírúurú inúnibíni tó burú jáì jù lọ léraléra. Ìyẹn kò mú kí wọ́n ṣiyè méjì lórí ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí láyé ìgbà tirẹ̀ ni wọ́n fi sọ́kàn, ìyẹn ni: “A ti fi onírúurú àdánwò kó ẹ̀dùn-ọkàn bá yín, kí ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín tí a ti dán wò . . . lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pétérù 1:6, 7) Inúnibíni lílekoko kì í ba ìwà títọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa fi bí èrò ọkàn wọn ṣe mọ́ tó hàn. Ó máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn di ojúlówó ìgbàgbọ́ tí a ti dán wò, ó sì máa ń fi bí ìfọkànsìn àti ìfẹ́ wọn ṣe jinlẹ̀ tó hàn.—Òwe 17:3.
‘Èmi Ni Ẹni Àkọ́kọ́, Èmi Ni Ẹni Ìkẹyìn’
14. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ “ẹni àkọ́kọ́” àti “ẹni ìkẹyìn”? (b) Iṣẹ́ ńláǹlà wo ni Jèhófà fi “ọwọ́” rẹ̀ ṣe?
14 Jèhófà wá fi ìdùnnú rọ àwọn èèyàn tí ó bá dá májẹ̀mú pé: “Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù, àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè, Ẹnì kan náà ni mí. Èmi ni ẹni àkọ́kọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ni ẹni ìkẹyìn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọwọ́ mi ni ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún mi sì ni ó na ọ̀run. Mo ń pè wọ́n, kí wọ́n lè máa bá a nìṣó ní dídúró pa pọ̀.” (Aísáyà 48:12, 13) Ẹni ayérayé ni Ọlọ́run, kì í yí padà, kò dà bí ọmọ èèyàn rárá. (Málákì 3:6) Nínú Ìṣípayá, Jèhófà kéde pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin.” (Ìṣípayá 22:13) Kò sí Ọlọ́run Olódùmarè kankan ṣáájú Jèhófà, kò sì ní sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀. Òun ni Ẹlẹ́dàá, Atóbijù àti Ẹni Ayérayé. “Ọwọ́” rẹ̀, ìyẹn agbára tí ó lò, ló fi ilẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì na ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀. (Jóòbù 38:4; Sáàmù 102:25) Bí ó bá ti pe àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, kíá wọ́n á ti dé láti ṣe ohun tó bá wí.—Sáàmù 147:4.
15. Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà “nífẹ̀ẹ́” Kírúsì, fún ète wo sì ni?
15 Jèhófà wá pe ìpè pàtàkì kan, èyí tó kan àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù, ó ní: “Ẹ kóra jọpọ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì gbọ́. Ta ni lára wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí? Jèhófà tìkára rẹ̀ ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Òun yóò ṣe ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀ sí Bábílónì, apá rẹ̀ yóò sì wà lára àwọn ará Kálídíà. Èmi—èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo ti pè é. Mo ti mú un wọlé wá, mímú kí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere yóò sì ṣẹlẹ̀.” (Aísáyà 48:14, 15) Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Olódùmarè, tó lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò sì ní yẹ̀ rárá. Èyíkéyìí lára “wọn,” ìyẹn àwọn òrìṣà aláìníláárí, kò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí rárá. Àwọn òrìṣà kọ́ ló nífẹ̀ẹ́ Kírúsì, Jèhófà ló “nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,” ìyẹn ni pé, Jèhófà yàn án nítorí ète pàtó kan. (Aísáyà 41:2; 44:28; 45:1, 13; 46:11) Ó ti rí àrítẹ́lẹ̀ nípa bí Kírúsì yóò ṣe bọ́ sójú ọpọ́n ní ayé, ó sì yàn án láti ṣẹ́gun Bábílónì lọ́jọ́ iwájú.
16, 17. (a) Kí ni ìdí tí a fi lè sọ pé Ọlọ́run kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe kéde àwọn ète rẹ̀ fáyé gbọ́ lóde òní?
16 Jèhófà wá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́tù bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ sún mọ́ mi. Ẹ gbọ́ èyí. Láti ìbẹ̀rẹ̀, èmi kò sọ̀rọ̀ ní ibi ìlùmọ́ rárá. Láti ìgbà tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.” (Aísáyà 48:16a) Jèhófà kò sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn èèyàn kéréje kan tó jọ wà lẹ́gbẹ́ ìmùlẹ̀ ló sọ ọ́ fún. Àwọn wòlíì Jèhófà kì í fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lórúkọ Ọlọ́run bò rárá. (Aísáyà 61:1) Gbangba gbàǹgbà ni wọ́n máa ń kéde ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ mọ́ ti Kírúsì kì í ṣe ọ̀tun lójú Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ohun tí kò rí tẹ́lẹ̀. Nǹkan bí igba ọdún ṣáájú ni Ọlọ́run ti gbẹnu Aísáyà sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ fáyé gbọ́.
17 Bákan náà lóde òní, Jèhófà kò fi àwọn ète rẹ̀ ṣe àpabò. Látilé délé, ní òpópó ọ̀nà àti ibikíbi tí wọ́n bá ṣáà ti lè kéde ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilẹ̀ àti erékùṣù òkun ti ń kéde ìkìlọ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tí ń bọ̀, tí wọ́n sì ń kéde ìhìn rere nípa àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá. Ní tòótọ́, Ọlọ́run tí ń sọ àwọn ète rẹ̀ jáde fáyé gbọ́ ni Jèhófà jẹ́.
“Fetí sí Àwọn Àṣẹ Mi!”
18. Kí ni Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn èèyàn òun ṣe?
18 Bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe wá fún wòlíì yìí lágbára, ó kéde pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti rán mi, àní ẹ̀mí rẹ̀. Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì: ‘Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.’” (Aísáyà 48:16b, 17) Gbólóhùn onífẹ̀ẹ́ yìí tó ń sọ nípa ìtọ́jú Jèhófà yẹ kó fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ Bábílónì. Òun sáà ni Olùtúnnirà wọn. (Aísáyà 54:5) Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ látọkànwá ni pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti àwọn padà dán mọ́rán, kí wọ́n sì máa kíyè sí àwọn àṣẹ òun. Orí pípa àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá mọ́ ni ìsìn tòótọ́ dá lé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sì lè rìn lọ́nà tí ó tọ́ àyàfi tí Jèhófà bá kọ́ wọn ní ‘ọ̀nà tí wọn yóò máa rìn.’
19. Báwo ni Jèhófà ṣe rọ̀ wọ́n látọkànwá?
19 Jèhófà wá fi ọ̀nà tó wúni lórí sọ bí ó ṣe wu òun tó pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ yàgò fún àgbákò kí wọ́n sì gbádùn ayé Aísáyà 48:18) Rírọ̀ tí Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, rọ̀ wọ́n látọkànwá yìí mà ga o! (Diutarónómì 5:29; Sáàmù 81:13) Dípò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi lọ sígbèkùn, àlàáfíà tí yóò pọ̀ yanturu bí omi odò tí ń ṣàn ni ì bá jọba láàárín wọn. (Sáàmù 119:165) Iṣẹ́ òdodo wọn ì bá sì pọ̀ lọ súà bí ìgbì òkun. (Ámósì 5:24) Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi, ìyẹn ló fi ń rọ̀ wọ́n, tí ó sì ń fi tìfẹ́tìfẹ́ fi ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà hàn wọ́n. Áà, ì bá mà dára o bí wọ́n bá gbọ́ràn!
wọn, ó ní: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (20. (a) Kí ni Ọlọ́run ṣì ń fẹ́ kí Ísírẹ́lì ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀? (b) Kí la rí kọ́ lára Jèhófà látinú ìwà tó hù sí àwọn èèyàn rẹ̀? (Wo àpótí ojú ewé 133.)
20 Bí Ísírẹ́lì bá ronú pìwà dà, àwọn ìbùkún wo nìyẹn yóò mú wá? Jèhófà sọ pé: “Àwọn ọmọ rẹ ì bá sì dà bí iyanrìn, àwọn ọmọ ìran láti ìhà inú rẹ ì bá sì dà bí hóró rẹ̀. Orúkọ ẹni ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa á rẹ́ ráúráú kúrò níwájú mi.” (Aísáyà 48:19) Jèhófà rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí nípa ìlérí tí ó ṣe pé irú ọmọ Ábúráhámù yóò pọ̀, “bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17; 32:12) Ṣùgbọ́n, àwọn irú ọmọ Ábúráhámù yìí ya ọlọ̀tẹ̀, wọn kò sì ní ẹ̀tọ́ láti gba ìmúṣẹ ìlérí yẹn. Àní ìwà tí wọ́n ń hù burú débi pé gẹ́gẹ́ bí Òfin Jèhófà gan-an ṣe wí, ṣe ló yẹ kí orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè pa rẹ́ ráúráú. (Diutarónómì 28:45) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà kò fẹ́ kí àwọn èèyàn òun pa rẹ́ ráúráú, kò sì fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá.
21. Àwọn ìbùkún wo la lè rí gbà lóde òní bí a bá ṣàfẹ́rí ìtọ́ni Jèhófà?
21 Àwọn ìlànà tí ń bẹ nínú àyọkà tó gbámúṣé yìí kan àwọn tó ń sin Jèhófà lóde òní. Jèhófà ni Orísun ìyè, ó sì mọ ọ̀nà tó yẹ ká gbà lo ìgbésí ayé wa ju ẹnikẹ́ni lọ. (Sáàmù 36:9) Àwọn ìtọ́sọ́nà tó fún wa jẹ́ fún ire wa, kì í ṣe láti fi dù wá ní adùn ìgbésí ayé. Àwọn Kristẹni tòótọ́ a máa kọbi ara sí ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì máa ṣàfẹ́rí rẹ̀. (Míkà 4:2) Àwọn ìtọ́ni rẹ̀ máa ń dáàbò bo ipò wa nípa tẹ̀mí àti àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ń kó wa yọ lọ́wọ́ àwọn ohun tí Sátánì lè fi sọ wá dìbàjẹ́. Nígbà tí a bá mọ àwọn ìlànà tí àwọn òfin Ọlọ́run wé mọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, a ó rí i pé ńṣe ni Jèhófà ń kọ́ wa fún ire wa. A ó rí i pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” A ò sì ní dẹni ìkékúrò.—1 Jòhánù 2:17; 5:3.
“Ẹ Jáde Lọ Kúrò ní Bábílónì!”
22. Kí ni Jèhófà rọ àwọn Júù olóòótọ́ láti ṣe, ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ló sì fún wọn?
22 Nígbà tí Bábílónì yóò bá fi ṣubú, ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú àwọn Júù yóò ti fọkàn sí ohun tó yẹ ní ṣíṣe? Ǹjẹ́ wọn yóò lo àǹfààní ìdáǹdè Ọlọ́run, kí wọ́n padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kí wọ́n sì mú ìsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò bí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ tẹ̀ lé e fi hàn pé ó dá a lójú pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Ẹ jáde lọ kúrò ní Bábílónì! Ẹ fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà. Àní ẹ fi ìró igbe ìdùnnú sọ ọ́ jáde, ẹ mú kí a gbọ́ èyí. Ẹ jẹ́ kí ó jáde lọ sí ìkángun ilẹ̀ ayé. Ẹ sọ pé: ‘Jèhófà ti tún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jékọ́bù rà. Òùngbẹ kò sì gbẹ wọ́n nígbà tí ó ń mú kí wọ́n rìn la àwọn ibi ìparundahoro kọjá. Ó mú kí omi láti inú àpáta ṣàn jáde fún wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí la àpáta kí omi náà lè ṣàn jáde.’” (Aísáyà 48:20, 21) Jèhófà ń lo àsọtẹ́lẹ̀ láti fi rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n jáde kúrò ní Bábílónì láìjáfara. (Jeremáyà 50:8) Wọ́n ní láti jẹ́ kí ìràpadà wọn di mímọ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. (Jeremáyà 31:10) Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tí àwọn èèyàn rẹ̀ nílò bí wọ́n ṣe ń rìn lọ nínú àwọn ilẹ̀ aṣálẹ̀. Bákan náà ni yóò ṣe pèsè fún àwọn èèyàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń darí lọ sílé láti Bábílónì.—Diutarónómì 8:15, 16.
23. Àwọn wo ni kò ní rí àlàáfíà Ọlọ́run gbà?
Aísáyà 48:22) Ọwọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kò ní tẹ àlàáfíà tí Ọlọ́run ti pa mọ́ de àwọn tó bá fẹ́ràn rẹ̀. Àwọn tó ń fi orí kunkun hu ìwà burúkú tàbí àwọn aláìgbàgbọ́ kọ́ ni iṣẹ́ ìgbàlà wà fún. Àwọn tó nígbàgbọ́ nìkan ni irú ìgbàlà bẹ́ẹ̀ wà fún. (Títù 1:15, 16; Ìṣípayá 22:14, 15) Àwọn èèyàn burúkú kò lè rí àlàáfíà Ọlọ́run gbà láéláé.
23 Ìlànà pàtàkì mìíràn tún wà tí àwọn Júù ní láti fi sọ́kàn nípa àwọn iṣẹ́ ìgbàlà tí Jèhófà ṣe. Àwọn tó lọ́kàn òdodo lè jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn o, ṣùgbọ́n wọn kò ní pa run. Àmọ́ ti àwọn aláìṣòdodo kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. “‘Kò sí àlàáfíà,’ ni Jèhófà wí, ‘fún àwọn ẹni burúkú.’” (24. Kí ló fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìdùnnú lóde òní?
24 Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ pé àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún wọn láti kúrò ní Bábílónì. Lọ́dún 1919, ìdùnnú bá àwọn èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú bí wọ́n ṣe rí ìdáǹdè gbà kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì. (Ìṣípayá 11:11, 12) Wọ́n nírètí pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ń bẹ níwájú fún àwọn, wọ́n sì wá lo àǹfààní yẹn láti fi mú ìgbòkègbodò wọn gbòòrò sí i. Ní tòdodo, ó gba ìgboyà kí ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni kéréje yẹn tó lè lo àǹfààní àwọn ọ̀nà tó ṣí sílẹ̀ fún ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù láàárín ayé tó kórìíra wọn. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ní pẹrẹu. Ẹ̀rí látinú ìtàn sì fi hàn pé Jèhófà bù kún wọn.
25. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fetí sí àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run dáadáa?
25 Apá àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí sọ ọ́ gbọnmọ-gbọnmọ pé Jèhófà ń kọ́ wa fún ire wa ni. Ó ṣe pàtàkì gidigidi láti fetí sí àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run dáadáa. (Ìṣípayá 15:2-4) Bí a bá ń rán ara wa létí ọgbọ́n àti ìfẹ́ Ọlọ́run, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ pé ó tọ́ kí á ṣe. Gbogbo òfin rẹ̀ ló jẹ́ fún àǹfààní wa.—Aísáyà 48:17, 18.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 133]
Ọlọ́run Olódùmarè Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu
Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà pé: “Èmi yóò dẹwọ́ ìbínú mi . . . èmi yóò kó ara mi níjàánu.” (Aísáyà 48:9) Irú gbólóhùn báyìí ń jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run jẹ́ àwòkọ́ṣe pípé ní ti pé kí a má ṣi agbára lò rárá. Lóòótọ́, kò sí ẹni tó lágbára jú Ọlọ́run lọ. Ìdí nìyẹn tí a fi ń pè é ní Olódùmarè, Alágbára Gbogbo. Ó sì tọ́ bí ó ṣe kúkú fúnra rẹ̀ sọ ọ́ pé òun ni “Olódùmarè.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Yàtọ̀ sí pé ibú agbára rẹ̀ kò lópin, òun náà ló ni gbogbo àṣẹ láyé àti lọ́run nítorí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ àgbáálá ayé tó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí kò fi sí ẹni tó jẹ́ dá a láṣà pé òun fẹ́ yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò, tàbí kó sọ fún un pé, “Kí ni o ti ń ṣe?”—Dáníẹ́lì 4:35.
Síbẹ̀, Ọlọ́run máa ń lọ́ra láti bínú, àní nígbà tó bá tilẹ̀ yẹ kó lo agbára rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá. (Náhúmù 1:3) Jèhófà lè ‘dẹwọ́ ìbínú rẹ̀,’ wọ́n sì ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́ pé ó “ń lọ́ra láti bínú,” nítorí pé ìbínú kọ́ ló gba iwájú nínú àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìfẹ́ ni. Kò sí ìgbà tó bá bínú tí kò ní jẹ́ ìbínú òdodo, tí kò ní jẹ́ ìbínú tí ó tọ́, kò sì sígbà tí kì í káwọ́ ìbínú rẹ̀.—Ẹ́kísódù 34:6; 1 Jòhánù 4:8.
Kí ni ìdí tí Jèhófà fi ń hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, ó máa ń fi ànímọ́ mẹ́ta tó kù nínú ànímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìwà rẹ̀ ní, ìyẹn ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́, pẹ̀rọ̀ sí agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè. Kí ó tó lo agbára rẹ̀ rárá, á ti rí i pé ìlò rẹ̀ kò tako èyíkéyìí nínú àwọn ànímọ́ mẹ́ta yòókù yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 122]
Iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò tí Aísáyà jẹ́ mú kí àwọn Júù olóòótọ́ tó wà nígbèkùn ní ìrètí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 124]
Àwọn Júù sábà máa ń fẹ́ gbé ògo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà fún àwọn òrìṣà
1. Íṣítà 2. Ọnà tí wọ́n gbẹ́ sára bíríkì, láti ara Òpópónà Àwọn Aláyẹyẹ ní Bábílónì 3. Dírágónì tí í ṣe àmì Mádọ́kì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
‘Ìléru ti ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’ lè jẹ́ kó hàn bóyá ète tí a fi ń sin Jèhófà jẹ́ ète tó mọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 128]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ti fara gba onírúurú inúnibíni tó burú jáì jù lọ