Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀

Jèhófà Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀

Orí Kẹrìnlélógún

Jèhófà Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀

Aísáyà 63:1-14

1, 2. (a) Àǹfààní wo ni dídé “ọjọ́ Jèhófà” yóò ṣe fún àwọn Kristẹni? (b) Ohun pàtàkì wo ló wé mọ́ dídé ọjọ́ Jèhófà?

LÁTI nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ni àwọn Kristẹni ti ń ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ (2 Pétérù 3:12; Títù 2:13) Kò yani lẹ́nu pé wọ́n ń fẹ́ kí ọjọ́ yẹn tètè dé. Bí ọjọ́ yẹn bá sáà dé, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lọ́wọ́ ìyà òun ìṣẹ́ tí àìpé ń kó bá wọn. (Róòmù 8:22) Pẹ̀lúpẹ̀lù ìnira tí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ń kó bá wọn yóò dópin.—2 Tímótì 3:1.

2 Àmọ́, bí ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe mú ìtura bá àwọn olódodo, ìparun ni yóò mú wá bá “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8) Ohun téèyàn ń ronú jinlẹ̀ gidigidi lé lórí ni. Ṣé nítorí kí àwọn èèyàn Ọlọ́run sáà ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó ń kó ìpọ́njú bá wọn nìkan ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ pa àwọn ẹni burúkú run? Aísáyà orí kẹtàlélọ́gọ́ta fi hàn pé ohun tó ṣe pàtàkì gidigidi jù bẹ́ẹ̀ lọ ló wé mọ́ ọn, ìyẹn ni, ìsọdimímọ́ orúkọ Ọlọ́run.

Ìrìn Ajagunṣẹ́gun

3, 4. (a) Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí kẹtàlélọ́gọ́ta? (b) Ta ni Aísáyà rí tí ó ń yan bọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, ta sì ni àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ sọ pé ẹni yẹn ní láti jẹ́?

3 Aísáyà orí kejìlélọ́gọ́ta, a kà nípa bí àwọn Júù ṣe gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn Bábílónì àti bí wọ́n ṣe padà bọ̀ sípò ní ìlú ìbílẹ̀ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, ìbéèrè tí yóò wá síni lọ́kàn ni pé: Ṣé àṣẹ́kù àwọn Júù tó padà wálé tún ní láti máa bẹ̀rù pé àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá yòókù ṣì tún ń bọ̀ wá pa àwọn run ni? Ìran tí Aísáyà rí mú kí ìbẹ̀rù yẹn má fi bẹ́ẹ̀ sí. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn lọ báyìí pé: “Ta nìyí tí ń bọ̀ láti Édómù, ẹni tí ó wọ ẹ̀wù aláwọ̀ títàn láti Bósírà, ẹni yìí tí ó ní ọlá nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan lọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu agbára rẹ̀?”—Aísáyà 63:1a.

4 Aísáyà rí jagunjagun alágbára, ajagunṣẹ́gun kan tó ń yan bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Aṣọ ọlọ́lá ńlá tó wọ̀ fi hàn pé ipò rẹ̀ ló ga jù lọ. Ìhà ọ̀nà Bósírà tó jẹ́ ìlú pàtàkì jù lọ ní Édómù ló ti ń bọ̀, tó fi hàn pé ó ti ṣẹ́gun ilẹ̀ ọ̀tá yẹn. Ta wá ni jagunjagun yẹn? Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ sọ pé Jésù Kristi ló ní láti jẹ́. Àwọn mìíràn gbà pé Júdásì Mákábì tó jẹ́ ọ̀gá ológun fún àwọn Júù nígbà kan rí ni. Àmọ́, jagunjagun yìí fúnra rẹ̀ sọ ẹni tí òun jẹ́ nígbà tó dáhùn ìbéèrè yẹn pé: “Èmi ni, Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní òdodo, Ẹni tí ó pọ̀ gidigidi ní agbára láti gbani là.”—Aísáyà 63:1b.

5. Ta ni jagunjagun tí Aísáyà rí, kí sì nìdí tóo fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

5 Kò sí àní-àní pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni jagunjagun yìí. Níbòmíràn nínú Bíbélì, a ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó ní “ọ̀pọ̀ yanturu okun . . . alágbára gíga” àti pé ó “ń sọ ohun tí ó jẹ́ òdodo.” (Aísáyà 40:26; 45:19, 23) Aṣọ ọlọ́lá ńlá tí jagunjagun yẹn wọ̀ mú wa rántí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ, pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi gan-an. Ìwọ ti fi iyì àti ọlá ńlá wọ ara rẹ láṣọ.” (Sáàmù 104:1) Lóòótọ́, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà jẹ́, àmọ́ Bíbélì fi hàn pé, bọ́ràn bá dójú ẹ̀, ó máa ń di jagunjagun.—Aísáyà 34:2; 1 Jòhánù 4:16.

6. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ojú ogun ní Édómù ni Jèhófà ti ń bọ̀?

6 Àmọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ojú ogun ní Édómù ni Jèhófà ti ń bọ̀? Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọmọ Édómù, tí kò jẹ́ kí kèéta tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ísọ̀ baba ńlá wọn ó tán nílẹ̀, ti ń bá àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú ṣọ̀tá. (Jẹ́nẹ́sísì 25:24-34; Númérì 20:14-21) Bí Édómù ṣe kórìíra Júdà tó hàn ní pàtàkì nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì ń pa Jerúsálẹ́mù run, tí àwọn ọmọ Édómù tún ń sà wọ́n. (Sáàmù 137:7) Jèhófà gbà pé òun gan-an ni wọ́n ń ṣe kèéta yẹn sí. Abájọ tó fi yọ idà ẹ̀san rẹ̀ sí Édómù!—Aísáyà 34:5-15; Jeremáyà 49:7-22.

7. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa Édómù ṣe ṣẹ lákọ̀ọ́kọ́? (b) Kí ni Édómù ṣàpẹẹrẹ?

7 Nípa báyìí, ìṣírí gan-an ni ìran tí Aísáyà rí jẹ́ fáwọn Júù tó padà wá sí Jerúsálẹ́mù. Ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé kò séwu fún wọn rárá ní ibùgbé wọn tuntun yìí. Àní nígbà ayé wòlíì Málákì pàápàá, ńṣe ni Ọlọ́run sọ ‘àwọn òkè ńlá Édómù di ahoro, ó sì sọ ogún rẹ̀ di ti àwọn akátá aginjù.’ (Málákì 1:3) Ṣé èyí wá fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ṣẹ pátápátá nígbà ayé Málákì ni? Rárá o, nítorí pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ahoro ni Édómù wà, ó ṣì pinnu láti tún àwọn ibi tó dahoro wọ̀nyẹn kọ́ padà, àti pé Málákì tiẹ̀ ṣì pe Édómù ní “ìpínlẹ̀ ìwà burúkú” àti “àwọn ènìyàn tí Jèhófà ti dá lẹ́bi fún àkókò tí ó lọ kánrin.” * (Málákì 1:4, 5) Àmọ́ ṣá o, ohun tí Édómù ṣàpẹẹrẹ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nasẹ̀ ré kọjá àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀. Ó dúró fún gbogbo orílẹ̀-èdè tó bá fi hàn pé àwọn jẹ́ ọ̀tá àwọn olùjọsìn Jèhófà. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jẹ́ apá pàtàkì nínú orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí Édómù òde òní?

Ibi Ìfúntí Wáìnì

8, 9. (a) Iṣẹ́ wo ni jagunjagun tí Aísáyà rí ti ṣe? (b) Ìgbà wo ni Jèhófà tẹ wáìnì níbi ìfúntí ìṣàpẹẹrẹ yẹn, báwo ló sì ṣe tẹ̀ ẹ́?

8 Aísáyà bi jagunjagun tó ń ti ojú ogun bọ̀ yìí léèrè pé: “Èé ṣe tí aṣọ rẹ fi pupa, tí ẹ̀wù rẹ sì dà bí ti ẹni tí ń tẹ wáìnì ní ibi ìfúntí wáìnì?” Jèhófà fèsì pé: “Ọpọ́n wáìnì ni mo ti tẹ̀ ní èmi nìkan, nígbà tí kò sí ẹnì kankan pẹ̀lú mi láti inú àwọn ènìyàn. Mo sì ń tẹ̀ wọ́n nìṣó nínú ìbínú mi, mo sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ nínú ìhónú mi. Ẹ̀jẹ̀ wọn tí ń tú ṣùrùṣùrù sì ń fún ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára ẹ̀wù mi, gbogbo aṣọ mi sì ni mo ti sọ di eléèérí.”—Aísáyà 63:2, 3.

9 Ohun tí àpèjúwe tó ṣe kedere yìí ń fi hàn ni pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀mí ti ṣègbé. Àní èérí bá ẹ̀wù tó gbayì tí Ọlọ́run wọ̀ pàápàá, àfi bí ẹ̀wù ẹni tí ń tẹ wáìnì níbi ìfúntí! Ibi ìfúntí jẹ́ àpẹẹrẹ tó bá a mu gan-an ni fún ipò àhámọ́ tí àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run bá ara wọn nígbà tí Jèhófà dìde sí wọn láti pa wọ́n run. Ìgbà wo ni Jèhófà yóò tẹ wáìnì ibi ìfúntí ìṣàpẹẹrẹ yìí? Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì àti ti àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa ìfúntí wáìnì ìṣàpẹẹrẹ kan pẹ̀lú. Títẹ wáìnì ibi ìfúntí inú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò wáyé nígbà tí Jèhófà bá ń tẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní àtẹ̀pa nígbà Amágẹ́dọ́nì. (Jóẹ́lì 3:13; Ìṣípayá 14:18-20; 16:16) Àkókò yìí kan náà ni Jèhófà yóò tẹ wáìnì ibi ìfúntí tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń sọ.

10. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé òun nìkan ló tẹ wáìnì níbi ìfúntí?

10 Kí wá nìdí tí Jèhófà fi sọ pé òun nìkan ló tẹ wáìnì níbi ìfúntí, nígbà tí kò sí ẹnì kankan pẹ̀lú òun látinú àwọn èèyàn? Ṣé Jésù Kristi, tó jẹ́ aṣojú Ọlọ́run, kọ́ ni yóò mú ipò iwájú nínú títẹ wáìnì ibi ìfúntí yẹn ni? (Ìṣípayá 19:11-16) Òun ni, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kọ́ ni Jèhófà ń sọ níhìn-ín, àwọn ọmọ aráyé ló ń wí. Ohun tó ń sọ ni pé agbára ọmọ aráyé kankan ò gbé e láti pa àwọn ọmọlẹ́yìn Sátánì rẹ́ láyé yìí. (Aísáyà 59:15, 16) Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ṣoṣo ló kù tí yóò fi ìbínú tẹ̀ wọ́n pa títí tí wọn yóò fi pa rẹ́ ráúráú.

11. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi mú kí “ọjọ́ ẹ̀san” dé? (b) Àwọn wo ni ‘àwọn tí Ọlọ́run tún rà’ láyé àtijọ́, àwọn wo sì ni lóde òní?

11 Jèhófà ṣàlàyé síwájú sí i nípa ìdí tó fi jẹ́ pé òun fúnra òun ló ṣe iṣẹ́ yìí, ó ní: “Ọjọ́ ẹ̀san ń bẹ ní ọkàn-àyà mi, àní ọdún àwọn tí mo tún rà ti dé.” (Aísáyà 63:4) * Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn tó bá ṣèpalára fún àwọn èèyàn rẹ̀. (Diutarónómì 32:35) Láyé àtijọ́, àwọn Júù tó jìyà lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì ni ‘àwọn tí ó tún rà.’ (Aísáyà 35:10; 43:1; 48:20) Láyé òde òní, àwọn ẹni àmì òróró ni. (Ìṣípayá 12:17) Jèhófà tún àwọn ẹni àmì òróró rà kúrò nínú ìgbèkùn ìsìn bí ó ṣe tún àwọn aláfijọ wọn ayé àtijọ́ rà. Àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn sì fojú winá inúnibíni àti àtakò gẹ́lẹ́ bíi tàwọn Júù yẹn. (Jòhánù 10:16) Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá mú un dá àwọn Kristẹni òde òní lójú pé tó bá ti tákòókò lójú Ọlọ́run, yóò gbèjà wọn.

12, 13. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà kò gbà rí olùrànlọ́wọ́? (b) Báwo ni apá Jèhófà ṣe mú ìgbàlà wá fún un, báwo sì ni ìbínú rẹ̀ ṣe tì í lẹ́yìn?

12 Jèhófà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo sì ń wò ṣáá, ṣùgbọ́n kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan; ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà mí, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó pèsè ìtìlẹyìn. Nítorí náà, apá mi mú ìgbàlà wá fún mi, ìhónú mi sì ni ohun tí ó tì mí lẹ́yìn. Mo sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n mu ìhónú mi ní àmupara, mo sì mú kí ẹ̀jẹ̀ wọn tí ń tú ṣùrùṣùrù dà wá sí ilẹ̀.”—Aísáyà 63:5, 6.

13 Kò sí ọmọ aráyé tó lè sọ pé òun lòun ran Jèhófà lọ́wọ́ lọ́jọ́ ẹ̀san ńlá rẹ̀. Àti pé Jèhófà ò tiẹ̀ nílò ìtìlẹyìn ọmọ èèyàn kó tó mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. * Apá rẹ̀ alágbára tó bùáyà ti tó láti ṣe iṣẹ́ yẹn. (Sáàmù 44:3; 98:1; Jeremáyà 27:5) Ẹ̀wẹ̀, ìhónú rẹ̀ tún tì í lẹ́yìn pẹ̀lú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní ti pé Ọlọ́run kì í bínú sódì, ìbínú òdodo ni ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ìlànà òdodo ni Jèhófà máa fi ń ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe, ńṣe ni ìhónú rẹ̀ tì í lẹ́yìn, tó sì sún un láti mú kí “ẹ̀jẹ̀” àwọn ọ̀tá rẹ̀ “tí ń tú ṣùrùṣùrù” di èyí tó “dà wá sí ilẹ̀” láti dójú tì wọ́n àti láti ṣẹ́gun wọn.—Sáàmù 75:8; Aísáyà 25:10; 26:5.

Inú Rere Onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run

14. Ọ̀rọ̀ tó bá a mu gẹ́ẹ́ wo ni Aísáyà wá sọ láti fi rán wọn létí?

14 Láwọn ìgbà tó ti kọjá, kò pẹ́ rárá kí àwọn Júù tó tẹ́ńbẹ́lú àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí tiwọn. Ìyẹn ló fi bá a mu bí Aísáyà ṣe rán wọn létí ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Aísáyà sọ pé: “Àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni èmi yóò mẹ́nu kàn, àwọn ìyìn Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, àní oore púpọ̀ yanturu fún ilé Ísírẹ́lì, èyí tí òun ti ṣe fún wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àánú rẹ̀ àti ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu àwọn inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Dájúdájú, ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò já sí èké.’ Nítorí náà, àwọn ni òun wá jẹ́ Olùgbàlà fún. Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un. Ońṣẹ́ òun tìkára rẹ̀ sì ni ó gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti nínú ìyọ́nú rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ tún wọn rà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn sókè, ó sì rù wọ́n ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.”—Aísáyà 63:7-9.

15. Báwo ni Jèhófà ṣe fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí irú ọmọ Ábúráhámù ní Íjíbítì, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Àpẹẹrẹ ńláǹlà mà ni Jèhófà fi lélẹ̀ yìí o ní ti bí a ṣe ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin hàn! (Sáàmù 36:7; 62:12) Jèhófà kò jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní sí Ábúráhámù yẹ̀ rárá. (Míkà 7:20) Ó ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ipasẹ̀ irú ọmọ rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Jèhófà kò jẹ́ kí ìlérí yìí yẹ̀, ó ṣe oore ńláǹlà fún ilé Ísírẹ́lì. Gbígbà tó gba irú ọmọ Ábúráhámù kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì jẹ́ ohun títayọ lára ìṣe adúróṣinṣin tí ó ṣe.—Ẹ́kísódù 14:30.

16. (a) Kí ni Jèhófà rò nípa Ísírẹ́lì nígbà tó bá wọn dá májẹ̀mú? (b) Irú ọwọ́ wo ni Ọlọ́run fi mú àwọn èèyàn rẹ̀?

16 Lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà mú wọn wá sí Òkè Sínáì, ó sì ṣe ìlérí yìí fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi . . . Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Ṣé Jèhófà ń tàn wọ́n ni nígbà tó ṣèlérí yìí? Rárá o, nítorí Aísáyà sọ pé Jèhófà sọ fún ara rẹ̀ pé: “Dájúdájú, ènìyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kì yóò já sí èké.” Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ṣàlàyé pé: “‘Dájúdájú’ tí ó lò níbí yìí kì í ṣe bí ìgbà tí ó ń fi òté lé e gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ tàbí nítorí pé ó ti wo ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì rí i pé ohunkóhun ò ní lè yẹ ọ̀rọ̀ yẹn: ìfẹ́ tó ní sí wọn ló jẹ́ kó ní ìrètí kí ó sì fọkàn tán wọn débi tó fi lè sọ bẹ́ẹ̀.” Ní tòdodo, inú kan ni Jèhófà fi bá àwọn èèyàn rẹ̀ dá májẹ̀mú yìí, ó sì fi tinútinú fẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Pẹ̀lú gbogbo àléébù wọn, ó ṣì fọkàn tán wọn. Ó mà dùn mọ́ni o láti sin irú Ọlọ́run tó ń fọkàn tán àwọn olùjọsìn rẹ̀ yìí! Okun gidi làwọn alàgbà máa ń fún àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn nígbà tí àwọn alàgbà náà bá fọkàn tán àwọn èèyàn Ọlọ́run pé olúkúlùkù wọn ló sáà jẹ́ ẹni rere.—2 Tẹsalóníkà 3:4; Hébérù 6:9, 10.

17. (a) Ẹ̀rí wo ni Jèhófà fi hàn nípa bí ó ṣe fẹ́ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó? (b) Ìdánilójú wo ni a lè ní lóde òní?

17 Síbẹ̀síbẹ̀ onísáàmù sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà wọn, Olùṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì.” (Sáàmù 106:21) Ìwà àìgbọràn wọn àti yíyà tí wọ́n ya ọlọ́rùn líle ń mú kí wọ́n kàgbákò lọ́pọ̀ ìgbà. (Diutarónómì 9:6) Ǹjẹ́ Jèhófà ṣíwọ́ inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí wọn? Rárá o, Aísáyà sọ pé “nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” Áà, Jèhófà mà lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò o! Bó ṣe máa ń dun bàbá tó bá fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ ló ṣe ń dún Ọlọ́run tó bá rí i pé àwọn ọmọ òun ń jìyà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ ìwà òmùgọ̀ wọn ló kó bá wọn. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe wí, àti nítorí bí ó ṣe fẹ́ràn wọn tó, ó rán “ońṣẹ́ òun tìkára rẹ̀” láti ṣáájú wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, ó sì jọ pé Jésù ni ońṣẹ́ yẹn kó tó di pé ó wá sí ayé. (Ẹ́kísódù 23:20) Nípa báyìí, ńṣe ni Jèhófà gbé orílẹ̀-èdè yẹn sókè tí ó sì gbé e “gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan ti í gbé ọmọ rẹ̀.” (Diutarónómì 1:31; Sáàmù 106:10) Lóde òní, kí ó dá wa lójú pé bákan náà ni Jèhófà ṣe mọ ìyà tó ń jẹ wá, àti pé ó máa ń dùn ún bí ìpọ́njú bá bá wa. A lè fi ìdánilójú ‘kó gbogbo àníyàn wa lé e, nítorí ó bìkítà fún wa.’—1 Pétérù 5:7.

Ọlọ́run Di Ọ̀tá Wọn

18. Kí nìdí tí Jèhófà fi di ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀?

18 Ṣùgbọ́n kí á má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú inú rere onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run láé o. Aísáyà tẹ̀ síwájú pé: “Àwọn tìkára wọn ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì ba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́. Wàyí o, ó yí padà di ọ̀tá wọn; òun fúnra rẹ̀ bá wọn jagun.” (Aísáyà 63:10) Jèhófà ti ṣèkìlọ̀ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́ lòun, “lọ́nàkọnà, [òun] kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe sọ ìwà àìgbọràn dàṣà, ńṣe ni wọ́n sọ ara wọn dẹni tí ìyà tọ́ sí. Mósè rán wọn létí pé: “Má gbàgbé bí o ti tán Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní sùúrù ní aginjù. Láti ọjọ́ tí o ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di ìgbà tí ẹ dé ibí yìí ni ẹ ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ nínú ìwà híhù yín sí Jèhófà.” (Diutarónómì 9:7) Bí wọ́n ṣe ń tako àwọn ọ̀nà rere tí ẹ̀mí Ọlọ́run fẹ́ máa darí wọn sí, wọ́n ń bà á nínú jẹ́, tàbí pé wọ́n ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a nìyẹn. (Éfésù 4:30) Ìyẹn ni wọ́n fi sọ Jèhófà di ọ̀tá wọn tipátipá.—Léfítíkù 26:17; Diutarónómì 28:63.

19, 20. Kí ni àwọn Júù rántí, kí sì nìdí tí wọ́n fi rántí?

19 Inú ìpọ́njú tí àwọn Júù wà ni àwọn kan nínú wọn ti rántí ìgbà tó ti kọjá. Aísáyà sọ pé: “Ẹnì kan sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, pé: ‘Ẹni tí ó mú wọn gòkè wá láti inú òkun pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀ dà? Ẹni tí ó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀ dà? Ẹni tí ó mú kí apá Rẹ̀ ẹlẹ́wà lọ ní ọwọ́ ọ̀tún Mósè; Ẹni tí ó pín omi níyà níwájú wọn, kí ó bàa lè ṣe orúkọ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ara rẹ̀; Ẹni tí ó mú wọn rin àárín omi ríru kọjá tí ó fi jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ní aginjù, wọn kò kọsẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ẹranko ti ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, àní ẹ̀mí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n sinmi.’”—Aísáyà 63:11-14a. *

20 Bẹ́ẹ̀ ni o, ìyà àìgbọràn ń jẹ àwọn Júù, wọ́n wá rántí àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, nígbà tí Jèhófà jẹ́ Olùdáǹdè wọn dípò jíjẹ́ ọ̀tá wọn. Wọ́n rántí bí “olùṣọ́ àgùntàn” wọn, Mósè àti Áárónì, ṣe kó wọn la Òkun Pupa já láìsí ìpalára. (Sáàmù 77:20; Aísáyà 51:10) Wọ́n rántí àkókò kan tó jẹ́ pé, dípò èyí tí àwọn fi wá ń ba ẹ̀mí Ọlọ́run nínú jẹ́ nísinsìnyí, ńṣe ni ẹ̀mí yẹn ń ṣamọ̀nà àwọn nípasẹ̀ ìtọ́sọ́nà tí Mósè àti àwọn àgbààgbà yòókù tí ẹ̀mí mímọ́ yàn ń fún wọn. (Númérì 11:16, 17) Wọ́n sì tún rántí pé àwọn rí bí Jèhófà ṣe tipasẹ̀ Mósè lo “apá Rẹ̀ ẹlẹ́wà” fún ire wọn pẹ̀lú! Nígbà tó yá, Ọlọ́run kó wọn jáde kúrò nínú aginjù ńlá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, ó sì ṣamọ̀nà wọn lọ sí ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, ìyẹn ibi ìsinmi. (Diutarónómì 1:19; Jóṣúà 5:6; 22:4) Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ìyà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ nítorí pé wọ́n ti ba àjọṣe dáadáa tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run jẹ́!

‘Ó Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀’

21. (a) Àǹfààní ńláǹlà wo ni Ísírẹ́lì ì bá ní nípa orúkọ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi dá irú ọmọ Ábúráhámù nídè kúrò ní Íjíbítì?

21 Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàdánù nípa ti ara kò já mọ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àdánù tó bá wọn nítorí àǹfààní tí wọ́n sọnù, ìyẹn, àǹfààní kíkópa nínú ṣíṣe orúkọ Ọlọ́run lógo. Mósè ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà yóò fìdí rẹ múlẹ̀ bí àwọn ènìyàn mímọ́ fún ara rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, nítorí pé ìwọ ń bá a lọ láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, o sì ti rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni a fi ń pè ọ́, àyà rẹ yóò sì máa fò wọ́n ní tòótọ́.” (Diutarónómì 28:9, 10) Kì í ṣe nítorí kí Jèhófà kàn lè mú kí ayé túbọ̀ rọ̀ ṣọ̀mù fún irú ọmọ Ábúráhámù ló ṣe gbèjà wọn tó sì dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú Íjíbítì. Ohun tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, ńṣe ló ń rí sí i pé a ‘polongo orúkọ òun ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’ (Ẹ́kísódù 9:15, 16) Nígbà tí Ọlọ́run sì ṣàánú Ísírẹ́lì lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ wọn ní aginjù, kì í ṣe ẹ̀mí àánú ló kàn jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ ni pé: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi kí a má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.”—Ìsíkíẹ́lì 20:8-10.

22. (a) Lọ́jọ́ iwájú, kí nìdí tí Ọlọ́run yóò tún fi jà nítorí àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni fífẹ́ tí a fẹ́ràn orúkọ Ọlọ́run fi kan àwọn ìṣe wa?

22 Àgbà ọ̀rọ̀ mà ni Aísáyà wá fi parí àsọtẹ́lẹ̀ yìí o! Ó ní: “Bí o ṣe ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ nìyẹn, kí o bàa lè ṣe orúkọ ẹlẹ́wà fún ara rẹ.” (Aísáyà 63:14b) Wàyí o, a lè wá rí ìdí tí Jèhófà fi ń jà gidigidi fún ire àwọn èèyàn rẹ̀. Ó jẹ́ nítorí kí ó lè ṣe orúkọ ẹlẹ́wà fún ara rẹ̀. Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà jẹ́ ohun tí ń ránni létí gbọnmọ gbọnmọ pé àgbàyanu àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà ló jẹ́ fúnni bí a bá ń pe orúkọ Jèhófà mọ́ni. Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ fẹ́ràn orúkọ Jèhófà ju ìwàláàyè tiwọn pàápàá lọ. (Aísáyà 56:6; Hébérù 6:10) Ó ń kó wọn nírìíra láti ṣe ohunkóhun tó bá lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ ọlọ́wọ̀ yẹn. Wọ́n ń fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ dídúró ṣinṣin tí Ọlọ́run fi hàn sí wọn nípa jíjẹ́ adúróṣinṣin sí i. Nítorí pé wọ́n fẹ́ràn orúkọ ẹlẹ́wà tí Jèhófà ní, wọ́n ń wọ̀nà fún ọjọ́ tí Jèhófà yóò tẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ fọ́ nínú ibi ìfúntí ìbínú rẹ̀, kì í ṣe nítorí àǹfààní tí ìyẹn kàn máa ṣe wọ́n, bí kò ṣe nítorí pé ó máa yọrí sí ṣíṣe orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fẹ́ràn lógo.—Mátíù 6:9.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Ọmọ Édómù làwọn Hẹ́rọ́dù ti ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa.

^ ìpínrọ̀ 11 Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn náà “ọdún àwọn tí mo tún rà” tọ́ka sí àkókò kan náà tó jẹ́ “ọjọ́ ẹ̀san.” Ṣàkíyèsí bí a ṣe lo àwọn gbólóhùn kan náà yìí ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ nínú Aísáyà 34:8.

^ ìpínrọ̀ 13 Ó ya Jèhófà lẹ́nu pé ẹnikẹ́ni kò ṣètìlẹyìn. Ó lè jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu lóòótọ́ pé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn alágbára nínú ọmọ aráyé ṣì ń tako ìfẹ́ Ọlọ́run síbẹ̀síbẹ̀.—Sáàmù 2:2-12; Aísáyà 59:16.

^ ìpínrọ̀ 19 A tún lè bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ yìí báyìí pé: “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí.” (Aísáyà 63:11, àlàyé etí ìwé, NW) Ṣùgbọ́n, èyí kò fi dandan túmọ̀ sí pé Jèhófà ni ẹni tó ń rántí nǹkan wọ̀nyẹn. Bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn Ọlọ́run fúnra wọn ni ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e ń sọ, kì í ṣe bí ó ṣe rí lára Jèhófà fúnra rẹ̀. Ìyẹn ni ìwé Soncino Books of the Bible fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn báyìí pé: “Ìyẹn làwọn èèyàn Rẹ̀ fi wá rántí àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.”

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 359]

Jèhófà nírètí pé àwọn èèyàn òun yóò hùwà rere