Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”

Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”

Orí Kẹfà

Jèhófà—“Ọlọ́run Òdodo àti Olùgbàlà”

Aísáyà 45:1-25

1, 2. Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú Aísáyà orí karùnlélógójì, àwọn ìbéèrè wo ni a ó sì gbé yẹ̀ wò?

ÌLÉRÍ tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé làwọn ìlérí Jèhófà. Ọlọ́run tó sì ń ṣí nǹkan payá àti Ọlọ́run aṣẹ̀dá ni. Léraléra ló ti fi hàn pé òun ni Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo. Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà orí karùnlélógójì, èyí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń mọ́kàn ẹni yọ̀.

2 Àpẹẹrẹ tó kàmàmà nípa bí Jèhófà ṣe lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tún wà nínú Aísáyà orí karùnlélógójì yìí pẹ̀lú. Ńṣe ni ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Aísáyà lè bojú wo àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré kí ó sì tún wo àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún síwájú, tí ó sì wá mú kó ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó jẹ́ pé yàtọ̀ sí Jèhófà, Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́, kò sẹ́ni tó tún lè sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí kò sì ní sí ohunkóhun tó máa yẹ̀ nínú rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni? Báwo ló ṣe nípa lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ìgbà Aísáyà? Kí ni ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa lóde òní? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ wòlíì yìí yẹ̀ wò.

Ìkéde Jèhófà Sórí Bábílónì

3. Àwọn gbólóhùn tó yéni kedere wo ni Aísáyà 45:1-3a fi ṣàpèjúwe ìṣẹ́gun Kírúsì?

3 Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Kírúsì, ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀, kí n lè tú àmùrè ìgbáròkó àwọn ọba pàápàá; láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀, tí yóò fi jẹ́ pé, àwọn ẹnubodè pàápàá ni a kì yóò tì: ‘Èmi fúnra mi yóò lọ níwájú rẹ, èmi yóò sì mú àwọn ìyọgọnbu ilẹ̀ tẹ́jú. Àwọn ilẹ̀kùn bàbà ni èmi yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú tí a fi irin ṣe ni èmi yóò sì ké lulẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ìṣúra tí ó wà nínú òkùnkùn àti àwọn ìṣúra fífarasin ní àwọn ibi ìlùmọ́.’”—Aísáyà 45:1-3a.

4. (a) Kí ni ìdí tí Jèhófà fi pe Kírúsì ní “ẹni àmì òróró” òun? (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe rí sí i pé Kírúsì ṣẹ́gun?

4 Jèhófà gbẹnu Aísáyà bá Kírúsì sọ̀rọ̀ bíi pé Kírúsì ti wà láyé, bẹ́ẹ̀ wọn ò sì tíì bí i láyé ìgbà Aísáyà. (Róòmù 4:17) Nítorí yíyàn tí Jèhófà ti yan Kírúsì ṣáájú láti ṣe iṣẹ́ pàtó kan, a lè sọ pé Kírúsì jẹ́ “ẹni àmì òróró” Ọlọ́run. Bó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run ń ṣáájú rẹ̀ lọ, yóò borí àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì sọ àwọn ọba di aláìlágbára tí wọn ò fi ní lè mí fín níwájú rẹ̀. Nígbà tí Kírúsì bá sì wá láti kọ lu Bábílónì, Jèhófà yóò rí sí i pé ilẹ̀kùn ìlú ńlá náà wà ní ṣíṣí sílẹ̀, wọn kò ní wúlò àní bíi ti ẹnubodè tí wọ́n fọ́ sí wẹ́wẹ́. Jèhófà yóò máa ṣáájú Kírúsì lọ, tí yóò sì máa mú kí gbogbo ohun ìdìgbòlù pa rẹ́ mọ́lẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, agbo ọmọ ogun Kírúsì yóò ṣẹ́gun ìlú ńlá náà, wọn yóò sì sọ “àwọn ìṣúra fífarasin,” ìyẹn àwọn ọrọ̀ Bábílónì tí wọ́n kó pa mọ́ sínú àwọn àjà tó ṣókùnkùn biribiri di tiwọn. Ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ?

5, 6. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì ṣẹ, báwo ló sì ṣe ṣẹ?

5 Lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyẹn nǹkan bí igba ọdún lẹ́yìn tí Aísáyà kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Kírúsì wá sí ibi odi Bábílónì lóòótọ́ láti wá kọlu ìlú náà. (Jeremáyà 51:11, 12) Ṣùgbọ́n, àwọn ará Bábílónì ò tilẹ̀ fi í pè. Wọ́n gbà pé mìmì kan ò lè mi ìlú àwọn. Àwòṣífìlà ni odi ìlú wọn kúkú jẹ́ lókè àwọn yàrà jíjìn tí omi Odò Yúfírétì kún dẹ́múdẹ́mú, ara ètò ààbò ìlú sì ni omi yìí jẹ́. Láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ọ̀tá kankan ò sáà tíì bá Bábílónì lábo rí! Àní ọkàn Bẹliṣásárì ọba Bábílónì tó ń gbé ìlú náà tilẹ̀ balẹ̀ débi pé àsè lòun àtàwọn èèyàn ààfin rẹ̀ ń jẹ lọ ràì. (Dáníẹ́lì 5:1) Lóru yẹn, ìyẹn òru October 5 mọ́jú October 6, ni Kírúsì parí bírà kan tó ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ológun dá.

6 Àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ Kírúsì lọ ya omi Odò Yúfírétì ní apá òkè níbi tí omi ti ń ṣàn wá sí Bábílónì, wọ́n wá darí omi yẹn gba ọ̀nà ibòmíràn lọ, ni omi ò bá ṣàn wá síhà gúúsù níbi tí ìlú wà mọ́. Láìpẹ́ láìjìnnà, omi odò tó wà nínú Bábílónì àti ní àyíká rẹ̀ wá fà débi pé àwọn agbo ọmọ ogun Kírúsì lè wọ́dò kọjá lọ sí àárín gbùngbùn ìlú gan-an. (Aísáyà 44:27; Jeremáyà 50:38) Ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu pé, gẹ́lẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ṣíṣí ni àwọn ibodè ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ odò yẹn wà. Ni agbo ọmọ ogun Kírúsì bá rọ́ wọnú Bábílónì, wọ́n gba ààfin, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì Ọba. (Dáníẹ́lì 5:30) Òru ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀ pátápátá. Bí Bábílónì ṣe ṣubú nìyẹn o, tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ṣẹ láìsí ohunkóhun tó yingin.

7. Báwo ni ṣíṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Kírúsì ṣẹ lọ́nà tó bùáyà ṣe ń fún àwọn Kristẹni lókun?

7 Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ wẹ́kú ń fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni lókun lóde òní. Ó jẹ́ kí wọ́n rí ìdí alágbára láti gbà gbọ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kò tíì ṣẹ ṣeé gbọ́kàn lé pátápátá pẹ̀lú. (2 Pétérù 1:20, 21) Àwọn olùjọsìn Jèhófà lónìí mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìṣubú Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa jẹ́ àpẹẹrẹ fún, ìyẹn ìṣubú “Bábílónì Ńlá,” ti wáyé lọ́dún 1919 lọ́hùn-ún. Ohun tó kù tí wọ́n ṣì ń retí ni ìparun àjọ ẹ̀sìn òde òní yẹn, títí kan ìmúṣẹ ìlérí mímú ètò ìṣèlú tó wà níkàáwọ́ Sátánì kúrò, sísọ Sátánì sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, àti dídé ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. (Ìṣípayá 18:2, 21; 19:19-21; 20:1-3, 12, 13; 21:1-4) Wọ́n mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà kì í ṣe ìlérí òfo, àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó tó dájú pé yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú ni. Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá sì ti rántí pé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ìṣubú Bábílónì ló ṣẹ, ìgbọ́kànlé wọn túbọ̀ máa ń lágbára sí i ni. Wọ́n mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

Ìdí Tí Jèhófà Yóò Fi Ṣojú Rere sí Kírúsì

8. Kí ni ìdí kan tí Jèhófà fi jẹ́ kí Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì?

8 Lẹ́yìn tí Jèhófà ti sọ ẹni tí yóò ṣẹ́gun Bábílónì àti ọ̀nà tó máa gbà ṣe é, ó wá ṣàlàyé ìdí kan tí òun fi máa jẹ́ kí Kírúsì ṣẹ́gun. Jèhófà fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Kírúsì sọ̀rọ̀ pé ìdí tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé “kí o lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ó fi orúkọ rẹ pè ọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (Aísáyà 45:3b) Ó tọ́ gan-an pé kí alákòóso agbára ayé kẹrin nínú ìtàn Bíbélì yìí mọ̀ pé ìtìlẹyìn Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, ẹni tó ga ju òun lọ, ló mú kí ìṣẹ́gun òun tó ga jù lọ yìí ṣeé ṣe. Dandan ni kí Kírúsì gbà pé Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lẹni tó pe òun tàbí tó gbéṣẹ́ lé òun lọ́wọ́. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sì fi hàn pé Kírúsì gbà bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ pé látọwọ́ Jèhófà ni ìṣẹ́gun ńláǹlà òun ti wá.—Ẹ́sírà 1:2, 3.

9. Ìdí kejì wo ni Jèhófà fi mú kí Kírúsì wá ṣẹ́gun Bábílónì?

9 Jèhófà ṣàlàyé pé ìdí kejì tí òun fi mú kí Kírúsì wá ṣẹ́gun Bábílónì ni: “Nítorí ìránṣẹ́ mi Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì àyànfẹ́ mi, àní mo bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ rẹ pè ọ́; mo tẹ̀ síwájú láti fún ọ ní orúkọ ọlá, bí ìwọ kò tilẹ̀ mọ̀ mí.” (Aísáyà 45:4) Ohun mánigbàgbé ni ìṣẹ́gun Kírúsì lórí Bábílónì jẹ́. Àmì tó fi hàn pé agbára ayé kan ti ṣubú pé òmíràn sì ti dìde dípò rẹ̀ ni, ó sì tún ní ipa lórí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìtàn àtìrandíran ẹ̀yìn ìgbà náà. Síbẹ̀, ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó ń fi ìháragàgà wo bí ọ̀ràn yẹn ṣe ń lọ láti mọ̀ pé tìtorí àwọn ẹgbẹ̀rún mélòó kan ìgbèkùn “tí kò já mọ́ nǹkan kan” tó wà ní Bábílónì, ìyẹn àwọn Júù, àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù, ni gbogbo ìwọ̀nyí ṣe wáyé. Ṣùgbọ́n lójú Jèhófà o, àwọn tó ṣẹ́ kù lára orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ yìí kì í ṣe àwọn tí kò já mọ́ nǹkan kan. “Ìránṣẹ́” rẹ̀ ni wọ́n. Àwọn nìkan ni “àyànfẹ́” rẹ̀ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kírúsì kò mọ Jèhófà tẹ́lẹ̀ rí, Jèhófà lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Òun fàmì òróró yàn láti lọ ṣẹ́gun ìlú tó kọ̀ láti tú àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀. Ọlọ́run ò sáà pète pé kí àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ máa ráre ní ilẹ̀ òkèèrè títí gbére.

10. Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ni Jèhófà fi lo Kírúsì láti fi fòpin sí Agbára Ayé Bábílónì?

10 Ìdí kẹta, tó tilẹ̀ ṣe pàtàkì jù lọ pàápàá, tún wà tí Jèhófà fi lo Kírúsì láti bi Bábílónì ṣubú. Jèhófà sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn. Yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan. Èmi yóò dì ọ́ lámùrè gírígírí, bí ìwọ kò tilẹ̀ mọ̀ mí, kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ láti yíyọ oòrùn àti láti wíwọ̀ rẹ̀ pé kò sí ẹnì kankan yàtọ̀ sí mi. Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.” (Aísáyà 45:5, 6) Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà lo ìṣubú Agbára Ayé Bábílónì láti fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí òun jẹ́ Ọlọ́run hàn, ẹ̀rí tó ń fi han gbogbo èèyàn pé òun nìkan ló tọ́ kí wọ́n máa jọ́sìn. Ìdáǹdè tí àwọn èèyàn Ọlọ́run sì rí gbà yìí yóò mú kí àwọn èèyàn látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn, gbà pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́.—Málákì 1:11.

11. Àpèjúwe wo ni Jèhófà ṣe láti fi hàn pé òun lágbára láti mú ohun tí òun pète fún Bábílónì ṣẹ?

11 Rántí pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ti wà lákọsílẹ̀ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àwọn kan gbọ́ ọ, wọ́n lè máa rò ó pé, ‘Ṣé agbára Jèhófà sì ká a báyìí láti mú un ṣẹ?’ Ìtàn wá fi hàn pé agbára rẹ̀ ká a dájúdájú. Jèhófà ṣàlàyé ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé ohunkóhun tóun bá ti sọ òun lè ṣe é láṣeparí, ó ní: “Ẹni tí ń ṣẹ̀dá ìmọ́lẹ̀ tí ó sì ń dá òkùnkùn, tí ó ń ṣe àlàáfíà tí ó sì ń dá ìyọnu àjálù, èmi, Jèhófà, ni ó ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Aísáyà 45:7) Gbogbo ìṣẹ̀dá pátá, àní látorí ìmọ́lẹ̀ dórí òkùnkùn, àti gbogbo ohun tó wáyé nínú ìtàn pátá, látorí àlàáfíà dórí àjálù, ìkáwọ́ Jèhófà ni gbogbo rẹ̀ wà. Bó ṣe dá ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán tó sì dá òkùnkùn òru náà ni yóò ṣe mú àlàáfíà wá fún Ísírẹ́lì tí yóò sì mú àjálù bá Bábílónì. Jèhófà ní agbára tó fi lè dá àgbáálá ayé, bẹ́ẹ̀ náà ni agbára ṣe tún ń bẹ fún un láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ìyẹn ń fi àwọn Kristẹni òde òní tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ taápọntaápọn lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni.

12. (a) Kí ni Jèhófà mú kí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ mú jáde? (b) Ìlérí tó tuni nínú wo ló wà fún àwọn Kristẹni òde òní nínú ọ̀rọ̀ Aísáyà 45:8?

12 Jèhófà kúkú wá lo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ déédéé nínú ìṣẹ̀dá lọ́nà tó ṣe wẹ́kú láti fi ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ń bẹ níwájú fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn, ó ní: “Ẹ̀yin ọ̀run, ẹ mú kí ìkántótó ṣẹlẹ̀ láti òkè; kí òdodo sì máa sẹ̀ láti inú sánmà ṣíṣúdẹ̀dẹ̀ pàápàá. Kí ilẹ̀ ayé ṣí, kí ó sì máa so èso ìgbàlà, kí ó sì mú kí òdodo rú yọ lẹ́ẹ̀kan náà. Èmi tìkára mi, Jèhófà, ni ó dá a.” (Aísáyà 45:8) Bí òjò tó ń mú nǹkan wà láàyè ṣe ń ti ojú ọ̀run rọ̀ wá, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò ṣe mú kí àwọn ohun tó ń múni hùwà òdodo rọ̀ sórí àwọn èèyàn rẹ̀ láti ojú ọ̀run ìṣàpẹẹrẹ. Bí ilẹ̀yílẹ̀ sì ṣe ń ṣí láti méso jáde wọ̀ǹtìwọnti, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò ṣe ké sí ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ pé kí ó mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ète òdodo òun mu ṣẹlẹ̀, àní ní pàtàkì, kí ó mú kí ìgbàlà dé fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Lọ́dún 1919, Jèhófà mú kí “ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” mú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wáyé bákan náà, láti lè dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Inú àwọn Kristẹni òde òní sì dùn bí wọ́n ṣe ń rí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Kí ni ìdí rẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn máa ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun bí wọ́n ṣe ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ọ̀run ìṣàpẹẹrẹ, Ìjọba Ọlọ́run, yóò mú ìbùkún bá ilẹ̀ ayé òdodo. Ní ìgbà yẹn, òdodo àti ìgbàlà tí yóò wá láti ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ yóò wáyé lọ́nà tó bùyààrì ju ti ìgbà tí wọ́n ṣẹ́gun Bábílónì lọ. Áà, ọ̀nà ológo tí ọ̀rọ̀ Aísáyà yóò gbà ní ìmúṣẹ ìkẹyìn tún kọyọyọ!—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1.

Àwọn Ìbùkún Tí Títẹ́wọ́gba Ipò Ọba Aláṣẹ Jèhófà Ń Mú Wá

13. Kí ni ìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kí ọmọ aráyé máa tako àwọn ète Jèhófà?

13 Bí Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìbùkún aláyọ̀ wọ̀nyí tán ló yí ọ̀nà tó gbà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ padà bírí, ló bá kéde ègbé méjì, ó ní: “Ègbé ni fún ẹni tí ń bá Aṣẹ̀dá rẹ̀ fà á, gẹ́gẹ́ bí àpáàdì kan pẹ̀lú àwọn àpáàdì mìíràn lórí ilẹ̀! Ǹjẹ́ ó yẹ kí amọ̀ sọ fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé: ‘Kí ni ìwọ ṣe?’ Kí àṣeyọrí rẹ sì sọ pé: ‘Kò ní ọwọ́’? Ègbé ni fún ẹni tí ó wí fún baba pé: ‘Kí ni o bí?’ àti fún aya pé: ‘Kí ni o ní ìrora ìbímọ fún?’” (Aísáyà 45:9, 10) Ó jọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fara mọ́ ohun tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀. Bóyá wọn ò gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò gbà kí àwọn èèyàn òun lọ sígbèkùn. Tàbí bóyá wọn lòdì sí èrò pé ọba orílẹ̀-èdè abọgibọ̀pẹ̀ kan ló máa wá dá Ísírẹ́lì nídè dípò tí yóò fi jẹ́ ilé Dáfídì. Láti fi bí irú àwọn àtakò yẹn kò ṣe bọ́gbọ́n mu hàn, Aísáyà fi àwọn alátakò yẹn wé àpáàdì àti ìṣùpọ̀ amọ̀ táa ti pa tì tó gbójúgbóyà láti ṣàríwísí ọgbọ́n ẹni tó mọ wọ́n. Kí ohun tí amọ̀kòkò fúnra rẹ̀ ṣe máa wá sọ fún amọ̀kòkò pé kò lọ́wọ́ tàbí pé kò sí ohun tó lè mọ rárá. Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni! Ìṣe àwọn tó ń ṣàtakò yìí kò yàtọ̀ sí ti ọmọ kékeré kan tó ń fi ìwà ọ̀yájú tako àṣẹ àwọn òbí rẹ̀.

14, 15. Kí ni àwọn gbólóhùn yìí “Ẹni Mímọ́” àti “Aṣẹ̀dá” ń fi hàn nípa Jèhófà?

14 Aísáyà sọ ohun tí Jèhófà fi dá àwọn alátakò yìí lóhùn, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì àti Aṣẹ̀dá rẹ̀: ‘Ẹ béèrè lọ́wọ́ mi àní nípa àwọn ohun tí ń bọ̀ ní ti àwọn ọmọ mi; àti nípa ìgbòkègbodò ọwọ́ mi, ẹ pàṣẹ fún mi. Èmi fúnra mi ni mo ṣe ilẹ̀ ayé tí mo sì dá ènìyàn pàápàá sórí rẹ̀. Èmi—ọwọ́ mi ni ó na ọ̀run, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni mo sì ti pàṣẹ fún. Èmi fúnra mi ti gbé ẹnì kan dìde ní òdodo, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì ni èmi yóò mú tẹ́jú. Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ìlú ńlá mi, àwọn tí ó jẹ́ tèmi tí ó wà ní ìgbèkùn ni òun yóò sì jẹ́ kí ó lọ, kì í ṣe fún iye owó tàbí fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.”—Aísáyà 45:11-13.

15 Ńṣe ni ṣíṣàpèjúwe Jèhófà pé ó jẹ́ “Ẹni Mímọ́” ń tẹnu mọ́ ìjẹ́mímọ́ rẹ̀. Pípè é ní “Aṣẹ̀dá” sì ń tẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ tí òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá ní láti pinnu bí àwọn nǹkan ṣe máa wáyé. Jèhófà lágbára láti sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì lè bójú tó iṣẹ́ ọwọ́ tirẹ̀, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí tún fi hàn pé ṣe ni ìlànà ìṣẹ̀dá àti ti ìṣípayá wọnú ara wọn. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé òun ìsálú ọ̀run, ó ní ẹ̀tọ́ láti mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ bó bá ṣe pinnu pé kí wọ́n ṣẹlẹ̀. (1 Kíróníkà 29:11, 12) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí a sì ń bá bọ̀, Ọba Aláṣẹ ọ̀run òun ayé ti pinnu láti yan Kírúsì, abọgibọ̀pẹ̀, ṣe olùdáǹdè Ísírẹ́lì. Lóòótọ́, ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí Kírúsì tó dé, àmọ́ bí ọ̀run òun ayé ṣe wà dájúdájú ló ṣe dájú pé yóò dé. Ọmọ Ísírẹ́lì wo ló wá tó bẹ́ẹ̀ láti tako Baba, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun”?

16. Èé ṣe tó fi yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jọ̀wọ́ ara wọn fún un?

16 Àwọn ìdí mìíràn tó fi yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jọ̀wọ́ ara wọn fún un tún wà nínú àwọn ẹsẹ ìwé Aísáyà kan náà yìí. Àwọn ìpinnu rẹ̀ máa ń jẹ́ fún ire àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo. (Jóòbù 36:3) Nítorí àtiran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n fi lè ṣe ara wọn láǹfààní ló fi ṣe àwọn òfin. (Aísáyà 48:17) Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí àwọn Júù tó tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láyé ìgbà Kírúsì. Kírúsì gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà tó bá òdodo Jèhófà mu, ó dá wọn padà lọ sílé láti Bábílónì kí wọ́n lè lọ tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Ẹ́sírà 6:3-5) Lónìí bákan náà, àwọn tó bá ń fi àwọn òfin Ọlọ́run sílò ní ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n sì jọ̀wọ́ ara wọn fún ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, máa ń gba ìbùkún.—Sáàmù 1:1-3; 19:7; 119:105; Jòhánù 8:31, 32.

Ìbùkún fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yòókù

17. Yàtọ̀ sí Ísírẹ́lì, ta ni yóò tún jàǹfààní nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí Jèhófà yóò ṣe, báwo ni wọn yóò sì ṣe jàǹfààní?

17 Ísírẹ́lì nìkan kọ́ ni orílẹ̀-èdè tí ìṣubú Bábílónì yóò ṣe láǹfààní. Aísáyà ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Àwọn lébìrà Íjíbítì tí a kò sanwó fún àti àwọn olówò Etiópíà àti àwọn Sábéà, àwọn ọkùnrin gíga, àní wọn yóò wá bá ìwọ, tìrẹ ni wọn yóò sì dà. Wọn yóò máa rìn lẹ́yìn rẹ; nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ni wọn yóò wá, ìwọ ni wọn yóò sì máa tẹrí ba fún. Ìwọ ni wọn yóò máa gbàdúrà sí, pé, “Ní tòótọ́, Ọlọ́run wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹlòmíràn; kò sí Ọlọ́run mìíràn.”’” (Aísáyà 45:14) Nígbà ayé Mósè, “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 12:37, 38) Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yóò ṣe bá àwọn Júù tó wà nígbèkùn padà wá sílé láti Bábílónì. Ẹnikẹ́ni ò ní fipá mú àwọn tí kì í ṣe Júù yìí o, fúnra wọn ni “wọn yóò wá.” Nígbà tí Jèhófà sọ pé, “ìwọ ni wọn yóò sì máa tẹrí bá fún,” tó sì tún ní “ìwọ ni wọn yóò máa gbàdúrà sí,” ọ̀rọ̀ bí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè yìí ṣe jọ̀wọ́ ara wọn fún Ísírẹ́lì, tí wọn sì ń wárí fún un ló ń sọ. Bí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bá ń bẹ lọ́rùn wọn, a jẹ́ pé wọ́n fínnú fíndọ̀ tọrùn bọ̀ ọ́ ni, ìyẹn sì dúró fún fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ láti sin àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú, àwọn tí wọn yóò sọ fún pé: “Ọlọ́run wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ.” Wọn yóò di aláwọ̀ṣe tó ń sin Jèhófà níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun tó wà nínú májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì.—Aísáyà 56:6.

18. Lóde òní, àwọn wo ló ti jàǹfààní látinú dídá tí Jèhófà dá “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nídè, ní àwọn ọ̀nà wo sì ni wọ́n gbà jàǹfààní?

18 Láti ọdún 1919 tí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí ni ọ̀rọ̀ Aísáyà ti ṣẹ lọ́nà tó ga gidigidi ju ti ìgbà ayé Kírúsì lọ. Ẹgbàágbèje èèyàn yí ká ayé ló ń fi hàn pé àwọn fínnúfíndọ̀ fẹ́ láti sin Jèhófà. (Gálátíà 6:16; Sekaráyà 8:23) Bíi ti “àwọn lébìrà” àti “àwọn olówò” tí Aísáyà mẹ́nu kàn làwọn náà ṣe ń fi tayọ̀tayọ̀ lo agbára àti ohun àmúṣọrọ̀ wọn fún ìtìlẹyìn ìjọsìn tòótọ́. (Mátíù 25:34-40; Máàkù 12:30) Wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fun Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìdùnnú di ẹrú rẹ̀. (Lúùkù 9:23) Jèhófà nìkan ni wọ́n ń sìn, wọ́n sì ń jàǹfààní ìbákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti Jèhófà, èyí tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú lọ́nà àkànṣe. (Mátíù 24:45-47; 26:28; Hébérù 8:8-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn lébìrà” àti “àwọn olówò” yẹn kò kópa nínú májẹ̀mú yìí, wọ́n ń jàǹfààní látinú rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn òfin tó wé mọ́ ọn mọ́, wọ́n ń fi ìgboyà kéde pé: “Kò sí Ọlọ́run mìíràn.” Ó mà wúni lórí pé bí iye àwọn tó ń fínnúfíndọ̀ kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́ yìí ṣe ń pọ̀ sí i lọ́nà tó bùáyà yìí ṣojú ẹni lóde òní o!—Aísáyà 60:22.

19. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó wonkoko mọ́ ìbọ̀rìṣà?

19 Lẹ́yìn tí wòlíì yìí ti sọ ọ́ pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò dara pọ̀ nínú jíjọ́sìn Jèhófà, ó wá sọ̀rọ̀ tìyanutìyanu, ó ní: “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ń pa ara rẹ mọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Olùgbàlà”! (Aísáyà 45:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò tíì fẹ́ fi agbára rẹ̀ hàn nísinsìnyí, lọ́jọ́ iwájú kò ní fara pa mọ́ mọ́. Yóò fi ara rẹ̀ hàn pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni òun, Olùgbàlà àwọn èèyàn rẹ̀. Àmọ́ ṣá, Jèhófà ò ní jẹ́ Olùgbàlà fún àwọn tó lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà. Aísáyà sọ nípa irú àwọn wọ̀nyẹn pé: “Ṣe ni ojú yóò tì wọ́n, a ó sì tẹ́ wọn lógo pàápàá, gbogbo wọn. Lápapọ̀ nínú ìtẹ́lógo ni àwọn tí ń ṣe àwọn ohun tí ó ní ìrísí òrìṣà yóò ti máa rìn.” (Aísáyà 45:16) Ìtẹ́lógo tí yóò bá wọn yóò ju ẹ̀tẹ́ àti ìtìjú tí yóò wulẹ̀ dùn wọ́n fúngbà díẹ̀. Ikú ni yóò jẹ́, ìyẹn òdì kejì ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún Ísírẹ́lì tẹ̀ lé e.

20. Ọ̀nà wo ni Ísírẹ́lì yóò gbà rí “ìgbàlà tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin”?

20 Ó ní: “Ní ti Ísírẹ́lì, ṣe ni a ó fi ìgbàlà tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin gbà á là ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ojú kì yóò tì yín, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tẹ́ yín lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin ti ayérayé.” (Aísáyà 45:17) Ìgbàlà ayérayé ni Jèhófà ṣèlérí fún Ísírẹ́lì, àmọ́, ìyẹn sinmi lórí ipò kan. Ísírẹ́lì ní láti máa bá a lọ láti wà “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà.” Tí Ísírẹ́lì bá ba ìrẹ́pọ̀ yẹn jẹ́ nípa kíkọ̀ láti gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, orílẹ̀-èdè yẹn á pàdánù ìrètí rẹ̀ fún “ìgbàlà tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Àmọ́, àwọn kan ní Ísírẹ́lì yóò gba Jésù gbọ́, àwọn yẹn yóò sì wá di ìpìlẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí yóò rọ́pò Ísírẹ́lì nípa ti ara. (Mátíù 21:43; Gálátíà 3:28, 29; 1 Pétérù 2:9) Ẹ̀tẹ́ kò ní bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí láé. “Májẹ̀mú àìnípẹ̀kun” ni Ọlọ́run yóò bá òun dá ní tirẹ̀.—Hébérù 13:20.

Nínú Ìṣẹ̀dá àti Nínú Ìṣípayá, Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

21. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá nínú ìṣẹ̀dá àti nínú ìṣípayá?

21 Ṣé àwọn Júù lè wá gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí ìgbàlà ayérayé tí Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì? Aísáyà dáhùn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn. Èmi kò sọ̀rọ̀ ní ibi ìlùmọ́, ní ibi tí ó ṣókùnkùn ní ilẹ̀ ayé; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sọ fún irú-ọmọ Jékọ́bù pé, “Ẹ kàn máa wá mi lásán.” Èmi ni Jèhófà, tí ń sọ ohun tí ó jẹ́ òdodo, tí ń sọ ohun dídúróṣánṣán.’” (Aísáyà 45:18, 19) Èyí ni ìgbà kẹrin, ó sì jẹ́ ìgbà ìkẹyìn nínú orí yìí, tí Aísáyà yóò fi gbólóhùn yìí: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí” bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó rinlẹ̀. (Aísáyà 45:1, 11, 14) Kí ni Jèhófà wá wí? Ó sọ pé ní ti ìṣẹ̀dá àti ìṣípayá, òun ṣeé gbára lé. Kò “wulẹ̀” dá ilẹ̀ ayé “lásán.” Bákan náà, kò sọ pé kí àwọn èèyàn òun, Ísírẹ́lì, “kàn máa” wá òun “lásán.” Ọlọ́run yóò mú ohun tó pète nípa àwọn àyànfẹ́ èèyàn rẹ̀ ṣẹ àní gẹ́lẹ́ bí yóò ṣe mú ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò dà bí ọ̀rọ̀ àwọn abọ̀rìṣà tó máa ń fara sin, gbangba gbàǹgbà ni Jèhófà máa ń sọ ọ̀rọ̀ tirẹ̀. Òdodo lọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn yóò sì ṣẹ. Àwọn tí ń sìn ín kò ní sìn ín lásán.

22. (a) Ìdánilójú wo ni àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì lè ní? (b) Ìfọ̀kànbalẹ̀ wo làwọn Kristẹni òde òní ní?

22 Ńṣe ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà nígbèkùn Bábílónì lọ́kàn balẹ̀ pé Ilẹ̀ Ìlérí kò ní wà láhoro títí gbére. Yóò padà di ibi tí àwọn èèyàn ń gbé. Àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wọn sì ṣẹ. Bákan náà, ńṣe ni ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí ń fi àwọn èèyàn Ọlọ́run tòde òní lọ́kàn balẹ̀ pé ilẹ̀ ayé kò ní di ahoro tí kò ní olùgbé, tó ti jóná gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe gbà gbọ́, tàbí èyí tí bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé pa run, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn ṣe ń bẹ̀rù pé ó máa rí. Ète Ọlọ́run ni pé kí ilẹ̀ ayé wà títí láé, kí ó lẹ́wà, kí àwọn olódodo sì máa gbé inú rẹ̀. (Sáàmù 37:11, 29; 115:16; Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, àní gẹ́lẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Ísírẹ́lì.

Jèhófà Nawọ́ Àánú Rẹ̀ Síwájú Sí I

23. Kí ni ọ̀ràn àwọn abọ̀rìṣà já sí, báwo ni nǹkan sì ṣe rí fún àwọn tó ń sin Jèhófà?

23 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ tẹ̀ lé e túbọ̀ tẹnu mọ́ ìgbàlà Ísírẹ́lì. Ó ní: “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá. Ẹ kó ara yín jọpọ̀, ẹ̀yin olùsálà láti inú àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí ń gbé igi ère gbígbẹ́ wọn kò ní ìmọ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbani là kò ní in. Ẹ gbé ìròyìn àti ọ̀rọ̀ yín kalẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n fikùn lukùn ní ìṣọ̀kan. Ta ni ó ti mú kí a gbọ́ èyí láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn? Ta ni ó ti ròyìn rẹ̀ láti ìgbà yẹn gan-an? Kì í ha ṣe èmi, Jèhófà ni, tí kò sí Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí mi; Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà, tí kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe èmi?” (Aísáyà 45:20, 21) Jèhófà fàṣẹ pe àwọn “olùsálà” pé kí wọ́n fi ìgbàlà tiwọn àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn abọ̀rìṣà wéra. (Diutarónómì 30:3; Jeremáyà 29:14; 50:28) Àwọn òrìṣà aláìlágbára tí kò lè gbà wọ́n ni àwọn abọ̀rìṣà máa ń ké pè, ìyẹn ló fi jẹ́ pé wọn “kò ní ìmọ̀ kankan.” Asán ni ìjọsìn wọn, òfo sì ni gbogbo rẹ̀ ń já sí. Ṣùgbọ́n, àwọn tó ń sin Jèhófà ń rí i pé gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti sọ tẹ́lẹ̀ “láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn” ló lágbára láti mú ṣẹ, títí kan ìgbàlà àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Agbára àti òye ọjọ́ iwájú tí Jèhófà ní láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ mú kó yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà gbogbo. Ní tòótọ́, “Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà” ni.

“Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wa . . . Ni Ìgbàlà Wa Ti Wá”

24, 25. (a) Ìpè wo ni Jèhófà pè, kí sì ni ìdí tó fi dájú pé ìlérí rẹ̀ yóò ṣẹ? (b) Kí ni Jèhófà fi ẹ̀tọ́ sọ pé òun ń fẹ́?

24 Àánú tí Jèhófà ní mú kó pe ìpè yìí pé: “Ẹ yíjú sọ́dọ̀ mi kí a sì gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin tí ń bẹ ní òpin ilẹ̀ ayé; nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn. Mo ti fi ara mi búra—ẹnu ara mi ni ọ̀rọ̀ náà ti jáde lọ nínú òdodo, tí kì yóò fi padà—pé gbogbo eékún yóò tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n yóò búra, pé, ‘Dájúdájú, inú Jèhófà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo àti okun wà. Gbogbo àwọn tí ń gbaná jẹ mọ́ ọn yóò wá tààrà sọ́dọ̀ rẹ̀, ojú yóò sì tì wọ́n. Nínú Jèhófà, gbogbo irú-ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò tọ̀nà, wọn yóò sì máa ṣògo nípa ara wọn.’”—Aísáyà 45:22-25.

25 Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì ni pé ẹni tó bá yí padà sí òun lára àwọn tó wà ní Bábílónì, òun yóò gbà á là. Àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò sì lè kùnà láé, torí pé Jèhófà ń fẹ́ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lágbára láti gbà wọ́n. (Aísáyà 55:11) Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá tilẹ̀ ti sọ ṣeé gbara lé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé ó tún fi ìbúra tì í lẹ́yìn. (Hébérù 6:13) Ó tọ́ gan-an bó ṣe sọ pé kí àwọn tó bá ń fẹ́ rí ojú rere òun tẹrí ba fún òun (ìyẹn ni pé “gbogbo eékún yóò tẹ̀ ba”) kí wọ́n sì bá òun jẹ́ ẹ̀jẹ́ (ìyẹn “gbogbo ahọ́n yóò búra”). Àwọn tó bá tẹra mọ́ jíjọ́sìn Jèhófà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò rí ìgbàlà. Wọn yóò lè fi ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn yangàn.—2 Kọ́ríńtì 10:17.

26. Báwo ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń jẹ́ ìpè Jèhófà pé kí wọ́n yíjú sí òun?

26 Àmọ́ o, àwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì ayé àtijọ́ nìkan kọ́ ni Ọlọ́run pè pé kí wọ́n yíjú sí òun. (Ìṣe 14:14, 15; 15:19; 1 Tímótì 2:3, 4) Ìpè yìí ṣì ń lọ lọ́wọ́, “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” sì ń jẹ́ ìpè yìí, tí wọ́n sì ń polongo pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa . . . àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] ni ìgbàlà wa ti wá.” (Ìṣípayá 7:9, 10; 15:4) Lọ́dọọdún, ẹgbàágbèje ẹni tuntun tó ń yíjú sí Ọlọ́run, tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kéde fáyé gbọ́ pé òun ló ni ìfọkànsìn àwọn, ló ń kún iye ogunlọ́gọ̀ yìí. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tún ń fi àìyẹhùn gbárùkù ti Ísírẹ́lì tẹ̀mí, “irú-ọmọ Ábúráhámù.” (Gálátíà 3:29) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ìṣàkóso òdodo Jèhófà nípa kíkéde kárí ayé pé: “Dájúdájú, inú Jèhófà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo àti okun wà.” * Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ọ̀rọ̀ Aísáyà 45:23 yìí ló fà yọ látinú ìtumọ̀ Septuagint nígbà tó ń fi hàn pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn gbogbo ẹní bá ń bẹ láàyè ni yóò tẹ́wọ́ gba ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run, tí yóò sì máa yin orúkọ rẹ̀ títí gbére.—Róòmù 14:11; Fílípì 2:9-11; Ìṣípayá 21:22-27.

27. Ìdí wo ni àwọn Kristẹni òde òní fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Jèhófà pátápátá?

27 Kí ni ìdí tí àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé bí àwọn bá yíjú sí Ọlọ́run àwọn yóò rí ìgbàlà? Ìdí rẹ̀ ni pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà orí karùnlélógójì ṣe fi hàn kedere. Gan-an bí Jèhófà ṣe ní agbára àti ọgbọ́n láti dá ọ̀run òun ayé, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ní agbára àti ọgbọ́n láti mú kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ. Gẹ́lẹ́ bó sì ṣe rí sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa Kírúsì ṣẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yòókù pátá tí kò tíì ní ìmúṣẹ ṣẹ. Nítorí náà, kí ó dá àwọn olùjọsìn Jèhófà lójú pé láìpẹ́, Jèhófà yóò tún fi ara rẹ̀ hàn ní “Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 26 Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo gbólóhùn náà, “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òdodo,” nítorí pé ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun púpọ̀ ló wà ní ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ní èdè Hébérù. Ńṣe ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ atọ́ka ohun púpọ̀ níhìn-ín láti fi gbé bí òdodo Jèhófà ṣe pọ̀ gidigidi tó yọ.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 80, 81]

Jèhófà, tí ń ṣẹ̀dá ìmọ́lẹ̀ tí ó sì ń dá òkùnkùn, lè mú kí àlàáfíà wà, ó sì lè dá àjálù sílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 83]

Jèhófà yóò mú kí “ọ̀run” rọ ìbùkún sílẹ̀ bí òjò, kí “ilẹ̀ ayé” sì mú ìgbàlà jáde wá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 84]

Ńjẹ́ ó yẹ kí àpáàdì ṣàríwísí ọgbọ́n ẹni tó mọ ọ́n?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 89]

Jèhófà kò dá ayé lásán