Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ga
Orí Kẹrìnlá
Jèhófà Gbé Mèsáyà Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Ga
1, 2. (a) Ṣàpèjúwe irú ìṣòro tí àwọn Júù dojú kọ ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. (b) Kí ni Jèhófà pèsè láti fi ran àwọn Júù olóòótọ́ lọ́wọ́ láti dá Mèsáyà mọ̀?
FOJÚ inú wò ó pé o fẹ́ lọ pàdé èèyàn pàtàkì kan. Ẹ ti ní àkókò àti ibi tí ẹ ó ti jọ pàdé. Ṣùgbọ́n o wá ní ìṣòro kan, ìṣòro náà ni pé: O kò mọ bí ẹni yẹn ṣe rí rárá, bẹ́ẹ̀, wọ́ọ́rọ́wọ́ ni onítọ̀hún máa wá síbẹ̀ láìṣe bí ọlọ́lá. Báwo lo ṣe máa dá a mọ̀? Àfi kóo ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe bí ẹni náà ṣe rí, ìyẹn ni wàá fi lè mọ̀ ọ́n.
2 Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn Júù nìyẹn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Wọ́n ń retí Mèsáyà, tó jẹ́ ẹni pàtàkì jù lọ nínú gbogbo àwọn tó ti ń gbé ayé yìí. (Dáníẹ́lì 9:24-27; Lúùkù 3:15) Àmọ́, báwo làwọn Júù olóòótọ́ yóò ṣe dá a mọ̀? Jèhófà ti lo àwọn wòlíì rẹ̀ tó jẹ́ Hébérù láti kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nípa Mèsáyà, tí àwọn olóye ò fi ní ṣì í mọ̀ rárá.
3. Àpèjúwe wo ni Aísáyà orí kejìléláàádọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàlá sí orí kẹtàléláàádọ́ta, ẹsẹ ìkejìlá ṣe nípa Mèsáyà?
3 Bóyá la rí òmíràn nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí àpèjúwe rẹ̀ kún rẹ́rẹ́ tó ti inú Aísáyà orí kejìléláàádọ́ta, ẹsẹ ìkẹtàlá sí orí kẹtàléláàádọ́ta, ẹsẹ ìkejìlá. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún ṣáájú ni Aísáyà ti ṣe àpèjúwe Mèsáyà, kò ṣàpèjúwe bí ìrísí rẹ̀ ṣe máa rí o, ṣùgbọ́n àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù nípa Mèsáyà ló ṣàpèjúwe, àwọn bíi ète tó fi máa jìyà àti irú ìyà tó máa jẹ, àtàwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ikú, ìsìnkú, àti ìgbéga rẹ̀. Àgbéyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti bí ó ṣe ṣẹ yóò mú inú wa dùn yóò sì fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Ta Ni Jèhófà Pè Ní “Ìránṣẹ́ Mi”?
4. Àwọn èrò wo ni àwọn ọ̀mọ̀wé Júù tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ti sọ nípa ẹni tí “ìránṣẹ́” yìí jẹ́, àmọ́ kí ni ìdí tí ìwọ̀nyí kò fi bá àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mu?
4 Aísáyà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ títú àwọn Júù sílẹ̀ kúrò nígbèkùn Bábílónì tán ni. Nísinsìnyí, ó ń wo ohun tó tún ju ìyẹn lọ dáadáa tí yóò wáyé lọ́jọ́ iwájú, ó wá kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà sílẹ̀, ó ní: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi yóò fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà. Yóò wà ní ipò gíga, a ó sì gbé e lékè dájúdájú, a ó sì gbé e ga gidigidi.” (Aísáyà 52:13) Ta tilẹ̀ ni “ìránṣẹ́” yìí ná? Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni àwọn ọ̀mọ̀wé Júù tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ti ń sọ onírúurú èrò wọn lórí ẹni tó lè jẹ́. Àwọn kan sọ pé ó dúró fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ lásìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn ní Bábílónì. Àmọ́ irú àlàyé yìí kò bá àsọtẹ́lẹ̀ náà mu. Ńṣe ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda láti jìyà. Aláìṣẹ̀ ni, síbẹ̀ ó jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ó dájú pé àpèjúwe yìí kò bá orílẹ̀-èdè àwọn Júù mu rárá, nítorí pé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ló sọ wọ́n dèrò ìgbèkùn. (2 Àwọn Ọba 21:11-15; Jeremáyà 25:8-11) Ni àwọn mìíràn bá tún sọ pé Ìránṣẹ́ tí ibí yìí ń wí dúró fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó jẹ́ onítara ìsìn ní Ísírẹ́lì, àti pé àwọn ọ̀tọ̀kùlú yìí jìyà nítorí àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ láàárín ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ o, lásìkò tí ìpọ́njú bá Ísírẹ́lì, kò sí àwùjọ àwọn kan ní pàtó tó lọ jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn mìíràn.
5. (a) Ta ni àwọn ọ̀mọ̀wé Júù tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí kàn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni ìwé Ìṣe nínú Bíbélì sọ tó fi ẹni tí Ìránṣẹ́ yìí jẹ́ hàn kedere?
5 Kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, àní títí wọ díẹ̀ nínú àwọn Ìṣe 8:26-40; Aísáyà 53:7, 8) Àwọn ìwé mìíràn nínú Bíbélì pẹ̀lú sọ ọ́ pé Jésù Kristi ni Ìránṣẹ́ tó jẹ́ Mèsáyà tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń sọ. * Bí a ó ṣe jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a óò rí àwọn ohun tó bára mu dájúdájú láàárín ẹni tí Jèhófà pè ní “ìránṣẹ́ mi” àti Jésù ti Násárétì.
ọ̀rúndún tó bẹ̀rẹ̀ Sànmánì Tiwa, díẹ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé Júù tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ti sọ ọ́ pé Mèsáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí wà fún. A sì rí i látinú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ yìí. Ìwé Ìṣe sọ pé nígbà tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan sọ pé òun ò mọ ẹni tí Ìránṣẹ́ inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí jẹ́, ṣe ni Fílípì “polongo ìhìn rere nípa Jésù fún un.” (6. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe fi hàn pé Mèsáyà yóò ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ láṣeyege?
6 Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi bẹ̀rẹ̀ ni àlàyé nípa àwọn àṣeyọrí tí Mèsáyà yóò ṣe lẹ́nu ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ọ̀rọ̀ náà, “ìránṣẹ́,” fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run bá ti ń fẹ́ ṣáá ni yóò máa ṣe, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ti ń ṣe fún ọ̀gá rẹ̀. Bó bá sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, “yóò fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.” Ìjìnlẹ̀ òye ni pé kéèyàn lè fi làákàyè mọ bí ọ̀ràn kan ṣe rí. Béèyàn bá lo ìjìnlẹ̀ òye, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún hùwà ọlọgbọ́n. Ìwé ìwádìí kan sọ nípa ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Hébérù tí wọ́n lò níhìn-ín pé: “Kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ yìí ni fífòye báni lò àti híhùwà ọlọgbọ́n. Ẹní bá ń hùwà ọlọgbọ́n yóò ṣàṣeyege.” A rí ẹ̀rí pé Mèsáyà yóò ṣàṣeyege dájúdájú látinú ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ, èyíinì ni pé a óò “gbé e lékè dájúdájú, a ó sì gbé e ga gidigidi.”
7. Báwo ni Jésù Kristi ṣe “fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà,” báwo ni a sì ṣe “gbé e lékè,” tí a sì “gbé e ga gidigidi”?
Jòhánù 17:4; 19:30) Kí ni àbáyọrí rẹ̀? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde tó sì gòkè re ọ̀run, “Ọlọ́run . . . gbé e sí ipò gíga, . . . ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.” (Fílípì 2:9; Ìṣe 2:34-36) Nígbà tó sì wá di ọdún 1914, ìgbéga túbọ̀ bá Jésù tí a ṣe lógo. Jèhófà gbé e gorí ìtẹ́ Ìjọba tí yóò wà níkàáwọ́ Mèsáyà. (Ìṣípayá 12:1-5) Bẹ́ẹ̀ ni o, a “gbé e lékè,” a sì “gbé e ga gidigidi.”
7 Jésù sì “fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà” lóòótọ́, ó fi hàn pé òun lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó kan òun, ó sì jẹ́ kí wọ́n ṣamọ̀nà òun láti lè ṣe bí Baba rẹ̀ ṣe fẹ́. (‘Wọ́n Ń Wò Ó Sùn-Ùn Pẹ̀lú Kàyéfì’
8, 9. Nígbà tí Jésù tó ti dẹni àgbéga bá wá láti ṣèdájọ́, kí ni yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn alákòóso ayé, èé sì ti ṣe?
8 Kí ni yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn alákòóso wọn sí Mèsáyà tó ti ní ìgbéga yìí? Bí a bá kọ́kọ́ fo àfikún àlàyé tó wà ní apá tó kẹ́yìn ẹsẹ ìkẹrìnlá ná, àsọtẹ́lẹ̀ náà á wá kà báyìí pé: “Títí dé àyè tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi wò ó sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì . . . bákan náà, òun yóò mú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ta gìrì. Àwọn ọba yóò pa ẹnu wọn dé sí i, nítorí pé ohun tí a kò tíì ròyìn lẹ́sẹẹsẹ fún wọn ni wọn yóò rí ní tòótọ́, ohun tí wọn kò tíì gbọ́ sì ni wọn yóò yí ìrònú wọn sí.” (Aísáyà 52:14a, 15) Aísáyà kò fi ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ṣàpèjúwe ìgbà tí Mèsáyà máa kọ́kọ́ wá sí ayé, ìgbà ìkẹyìn tó máa gbéjà ko àwọn alákòóso ayé ló ń sọ.
9 Nígbà tí Jésù tó ti dẹni àgbéga bá wá dá ètò àwọn nǹkan aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí lẹ́jọ́, ńṣe ni àwọn alákòóso ayé yóò máa “wò ó sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì.” Lóòótọ́, àwọn alákòóso ènìyàn kò ní fi ojúyòójú rí Jésù táa ti ṣe lógo. Ṣùgbọ́n wọn yóò rí àwọn ẹ̀rí tó hàn kedere pé òun ló ń lo Mátíù 24:30) Tipátipá, wọn yóò yí ìrònú wọn sí àwọn ohun tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kò tíì ṣàlàyé fún wọn rí, pé, Jésù mà ni Amúdàájọ́ṣẹ Ọlọ́run o! Ọ̀nà àìròtẹ́lẹ̀ ni Ìránṣẹ́ tó ti dẹni àgbéga, tí yóò kò wọ́n lójú, yóò gbà yọ sí wọn.
agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jagunjagun ọ̀run tó ń jà fún Jèhófà. (10, 11. Ọ̀nà wo ni a lè sọ pé wọ́n gbà ba Jésù lẹ́wà jẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní?
10 Gẹ́gẹ́ bí àfikún àlàyé tó wà ní ẹsẹ ìkẹrìnlá ṣe wí, Aísáyà sọ pé: “Ìbàlẹ́wàjẹ́ náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní ti ìrísí rẹ̀ tí ó fi ju ti ọkùnrin mìíràn àti ní ti ìdúró rẹ̀ onídàńsáákì tí ó fi ju ti àwọn ọmọ aráyé.” (Aísáyà 52:14b) Ǹjẹ́ wọ́n ba ẹwà ìrísí Jésù jẹ́ lọ́nàkọnà? Rárá o. Òótọ́ ni pé Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìrísí Jésù, àmọ́, ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run, tó jẹ́ ẹni pípé, jẹ́ ẹni tó fani mọ́ra tó sì wuni. Èyí wá jẹ́ kó hàn pé ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tẹ́ tí wọn yóò mú bá Jésù ni Aísáyà ń sọ. Jésù fi ìgboyà táṣìírí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ pé alágàbàgebè, òpùrọ́, àti apànìyàn ni wọ́n; làwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn òun náà. (1 Pétérù 2:22, 23) Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé arúfin, asọ̀rọ̀-òdì, ẹlẹ̀tàn àti aṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù ni. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹlẹ́sùn èké yìí ba Jésù jẹ́ pátápátá.
11 Bíbà táwọn èèyàn ń ba Jésù jẹ́ ṣì ń bá a lọ dòní olónìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ka Jésù sí ìkókó kan tó ṣì wà ní ibùjẹ ẹran tàbí kí wọ́n kà á sí ẹni iyì kan táyé ẹ̀ bà jẹ́, tí wọ́n kàn mọ́ àgbélébùú tòun ti adé ẹ̀gún lórí, tí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ ti papó, tójú rẹ̀ sì ti dìdàkudà nítorí ìrora. Àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ló sì túbọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wo Jésù. Wọ́n kùnà láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù jẹ́ Ọba alágbára ní ọ̀run, ẹni tí àwọn orílẹ̀-èdè ayé pátá yóò jíhìn fún. Láìpẹ́ láìjìnnà, tí àwọn olùṣàkóso èèyàn bá wá dojú kọ Jésù tó ti dẹni àgbéga, wọ́n á gbà pé Mèsáyà, ẹni ‘tí a ti fún ní gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé’ làwọn kò yìí!—Mátíù 28:18.
Ta Ni Yóò Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Ìhìn Rere Yìí?
12. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 53:1 yìí fà?
12 Lẹ́yìn tí Aísáyà ti ṣàpèjúwe àyípadà àgbàyanu tí yóò bá Mèsáyà, ìyẹn láti ipò ẹni “ìbàlẹ́wàjẹ́” sí ẹni ‘tí a gbé ga gidigidi,’ ó wá béèrè pé: “Ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́? Ní ti apá Jèhófà, ta sì ni a ti ṣí i payá fún?” (Aísáyà 53:1) Àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan dìde pé: Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣẹ? Ǹjẹ́ “apá Jèhófà,” tó dúró fún agbára rẹ̀ tí ó lè lò, yóò fara hàn láti mú kí nǹkan wọ̀nyí ṣẹ?
13. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ sí Jésù lára, ìhà wo ni àwọn èèyàn sì kọ sí àsọtẹ́lẹ̀ yìí?
13 Yóò rí bẹ́ẹ̀ dájúdájú! Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó lo ọ̀rọ̀ Aísáyà láti fi jẹ́rìí pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà gbọ́ tí ó sì kọ sílẹ̀ ṣẹ sí Jésù lára. Ìhìn rere ni ṣíṣe tí Ọlọ́run ṣe Jésù lógo lẹ́yìn tó ti jìyà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́. Pọ́ọ̀lù wá sọ nípa àwọn Júù tó ya aláìgbàgbọ́ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn kọ́ ni wọ́n ṣègbọràn sí ìhìn rere. Nítorí Aísáyà wí pé: ‘Jèhófà, ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa?’ Nítorí náà, ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́. Ẹ̀wẹ̀, ohun tí a gbọ́ jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa Kristi.” (Róòmù 10:16, 17) Síbẹ̀síbẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn díẹ̀ péré ló lo ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí. Kí ni ìdí rẹ̀?
14, 15. Irú ipò wo ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí nígbà tó bá fi wá sáyé?
14 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá ṣàlàyé àwọn ìdí tí àwọn ìbéèrè tí ó wà ní ẹsẹ kìíní fi wáyé fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká rí ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ò fi ní tẹ́wọ́ gba Mèsáyà, ó ní: “Yóò sì jáde wá bí ẹ̀ka igi níwájú [alákìíyèsí kan], àti bí gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ aláìlómi. Kò ní ìdúró onídàńsáákì, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ọlá ńlá kankan; nígbà tí a bá sì rí i, kò ní ìrísí tí a ó fi ní ìfẹ́-ọkàn Aísáyà 53:2) Ibí yìí jẹ́ ká rí irú ipò tí wọ́n máa bí Mèsáyà sí nígbà tó bá máa dé ayé. Ìgbé ayé tálákà ní yóò gbé láti kékeré, tí yóò fi jẹ́ pé lójú àwọn tó ń ṣàkíyèsí rẹ̀, ńṣe ni yóò dà bí ẹni tí kò lè jẹ́ nǹkan kan láyé ńbí. Ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni yóò dà bí ẹ̀ka igi kan lásán, bí èèhù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rú jáde lára ẹ̀ka igi. Yóò sì dà bí ìgbà tí gbòǹgbò tó gbára lé omi wà nínú ilẹ́ gbígbẹ tó ti ṣá. Kò ní wá ní ìwá ọlọ́lá ńlá, àní kò ní wọ ẹ̀wù òye, kó sì ní dé adé iyebíye. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbé ayé mẹ̀kúnnù ni yóò fi bẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀.
sí i.” (15 Àpèjúwe yìí mà bá ìgbésí ayé mẹ̀kúnnù tí Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé láti ìgbà ọmọdé rẹ̀ mu gan-an o! Ńṣe ni Màríà wúńdíá tó jẹ́ Júù kan bí i sí ibùjẹ ẹran kan tó wà ní ìlú kékeré tó ń jẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. * (Lúùkù 2:7; Jòhánù 7:42) Tálákà ni Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀. Nǹkan bí ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí òfin gbà pé tálákà lè mú wá ni wọ́n mú wá, tí í ṣe “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.” (Lúùkù 2:24; Léfítíkù 12:6-8) Nígbà tí ó ṣe, Màríà àti Jósẹ́fù wá lọ ń gbé ní Násárétì, níbi tí Jésù ti dàgbà nínú ìdílé ńlá, ó sì jọ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ.—Mátíù 13:55, 56.
16. Báwo ló ṣe jẹ́ pé Jésù kò ní “ìdúró onídàńsáákì,” bẹ́ẹ̀ ni kò ní “ọlá ńlá kankan” lóòótọ́?
16 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, kò jọ pé inú ilẹ̀ tí ó tọ́ ni Jésù ti ta gbòǹgbò. (Jòhánù 1:46; 7:41, 52) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé tó tún jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba ni, tálákà tó jẹ́ kò jẹ́ kí ó ní “ìdúró onídàńsáákì,” bẹ́ẹ̀ ni kò ní “ọlá ńlá kankan,” pàápàá lójú àwọn tó ń retí pé inú agbo ìdílé àwọn bọ̀rọ̀kìnní ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. Èròkérò tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ń gbìn sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn wá mú kí púpọ̀ wọn ṣàìka Jésù sí, wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwùjọ àwọn Júù kò rí ohunkóhun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí rárá lára ẹni pípé, Ọmọ Ọlọ́run yìí.—Mátíù 27:11-26.
‘Àwọn Ènìyàn Tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀, Wọ́n sì Yẹra fún Un’
17. (a) Kí ni Aísáyà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàpèjúwe, kí sì ni ìdí tó fi kọ̀wé rẹ̀ bíi pé ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá? (b) Àwọn wo ló “tẹ́ńbẹ́lú” Jésù tí wọ́n sì “yẹra fún un,” ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Aísáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe nípa irú ojú tí wọ́n máa fi wo Mèsáyà àti ìwà tí wọ́n máa hù sí i, ó ní: “A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwọn ènìyàn sì yẹra fún un, ọkùnrin tí a pète fún ìrora àti fún dídi ojúlùmọ̀ àìsàn. Ó sì dà bí ìfojú-ẹni-pamọ́ sí wa. A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwa sì kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan.” (Aísáyà 53:3) Ìdánilójú tí Aísáyà ní pé ọ̀rọ̀ òun yóò ṣẹ ló jẹ́ kó kọ ọ́ bíi pé ó tilẹ̀ ti ṣẹ kọjá. Ṣé àwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú Jésù Kristi tí wọ́n sì yẹra fún un lóòótọ́? Dájúdájú wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀! Àwọn aṣáájú ìsìn ẹlẹ́mìí mo-mọ́-tán àti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn kà á sí ẹni ìríra jù lọ láyé yìí. Wọ́n pè é ní ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó. (Lúùkù 7:34, 37-39) Wọ́n tutọ́ sí i lójú. Wọ́n lù ú ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì bú u. Wọ́n fi ṣẹ̀sín, wọ́n sì fi ṣẹlẹ́yà. (Mátíù 26:67) Àwọn ọ̀tá òtítọ́ yìí sì kó sí “àwọn ènìyàn” Jésù lọ́kàn, débi pé àwọn pàápàá “kò gbà á wọlé.”—Jòhánù 1:10, 11.
18. Nígbà tí àìsàn kankan kò ṣe Jésù rí, báwo ló ṣe jẹ́ “ọkùnrin tí a pète fún ìrora àti fún dídi ojúlùmọ̀ àìsàn”?
18 Èèyàn pípé ni Jésù, torí náà kò ṣàìsàn rárá. Síbẹ̀, ó jẹ́ “ọkùnrin tí a pète fún ìrora àti fún dídi ojúlùmọ̀ àìsàn.” Ìrora àti àìsàn tí ibí yìí ń wí kì í ṣe tòun alára o. Ńṣe ni Jésù ti ọ̀run wá sínú ayé aláìsàn yìí. Inú ìyà òun ìrora ayé yìí ló gbé, ṣùgbọ́n kò sá fún àwọn aláìsàn rárá, ì báà jẹ́ àìsàn nípa ti ara tàbí nípa tẹ̀mí. Bí oníṣègùn kan tó láájò ló ṣe mọ ìyà tó ń jẹ àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ dunjú. Ẹ̀wẹ̀, ó tún ṣe ohun tí ọmọ aráyé oníṣègùn kankan kò lè ṣe.—Lúùkù 5:27-32.
19. Ojú ta ni wọ́n mú kó wà ní ‘pípamọ́,’ báwo ni àwọn ọ̀tá Jésù sì ṣe fi hàn pé kò tiẹ̀ “já mọ́ nǹkan kan” rárá lójú àwọn?
Aísáyà 53:3 ni, “ohun tí àwọn èèyàn ń gbójú sá fún.” Àwọn ọ̀tá Jésù kà á sí ẹni ìríra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, àfi bíi pé, wọ́n ń tètè yíjú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ kíá bí ẹni tó ríni lára jù láti wò. Kódà wọ́n kà á sí ẹni tí àwọn ò lè rà ju iye owó tí wọ́n á fi ra ẹrú lásán lọ. (Ẹ́kísódù 21:32; Mátíù 26:14-16) Àní Bárábà apànìyàn tilẹ̀ tún níyì lọ́wọ́ wọn jù ú lọ. (Lúùkù 23:18-25) Kí ni wọn ì bá tún ṣe jù èyí lọ láti fi hàn pé Jésù kò já mọ́ nǹkan kan rárá lójú àwọn?
19 Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù alára làwọn ọ̀tá rẹ̀ kà sí aláìsàn, wọn kò sì fojúure wò ó. Wọ́n wá mú kí ojú rẹ̀ wà ní ‘pípamọ́’ fún àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé òun ló gbójú pa mọ́ fún àwọn èèyàn. Gbólóhùn tí The New English Bible fi túmọ̀20. Ìtùnú wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà máa ń fún àwọn èèyàn Jèhófà lónìí?
20 Ìtùnú tó pọ̀ gan-an ni ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí lè fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní. Nígbà mìíràn, àwọn alátakò lè fi àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n ṣe wọ́n bíi pé wọn kò já mọ́ nǹkan kan. Síbẹ̀síbẹ̀, bíi ti Jésù lọ̀ràn wa ṣe rí, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ojú tí Jèhófà Ọlọ́run fi ń wò wá. Bí Jésù kò bá tiẹ̀ “já mọ́ nǹkan kan” lójú àwọn èèyàn, ṣebí kò sáà yí ojú iyebíye tí Ọlọ́run fi ń wò ó padà!
“A Gún Un Nítorí Ìrélànàkọjá Wa”
21, 22. (a) Kí ni Mèsáyà bá àwọn ẹlòmíràn gbé, kí ló sì bá wọn rù? (b) Irú ojú wo ni ọ̀pọ̀ fi wo Mèsáyà, kí sì ni ìjìyà rẹ̀ yọrí sí?
21 Kí wá nìdí tí Mèsáyà fi ní láti jìyà kí ó sì kú? Aísáyà ṣàlàyé pé: “Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé; àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n. Ṣùgbọ́n àwa fúnra wa kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọlù, tí ó sì ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n a gún un nítorí ìrélànàkọjá wa; a ń tẹ̀ ẹ́ rẹ́ Aísáyà 53:4-6.
nítorí àwọn ìṣìnà wa. Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀, àti nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa. Gbogbo wa ti rìn gbéregbère bí àgùntàn; olúkúlùkù wa ni ó ti yíjú sí bíbá ọ̀nà ara rẹ̀ lọ; Jèhófà alára sì ti mú kí ìṣìnà gbogbo wa ṣalábàápàdé ẹni yẹn.”—22 Mèsáyà gbé àìsàn àwọn ẹlòmíràn, ó sì ru ìrora wọn. Ó gbé ẹrù ìnira wọn kúrò lórí wọn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó gbé e lé èjìká tirẹ̀, ó sì bá wọn rù ú. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ tí aráyé jẹ́ ló fa àìsàn àti ìrora fún wọn, bí Mèsáyà ṣe gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ni kò mọ ìdí tó fi ń jìyà, wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run ń jẹ ẹ́ níyà ni, tó ń fi àrùn burúkú yọ ọ́ lẹ́nu. * Kódà àwọn ọ̀rọ̀ líle tó ń fi hàn pé Mèsáyà yóò kú ikú gbígbóná àti ikú oró ni ibí yìí lò, ó ní ó jìyà débi pé wọ́n gún un ní nǹkan, wọ́n tẹ̀ ẹ́ rẹ́, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára. Àmọ́, kíkú tó kú yìí pàápàá, ó fi ṣètùtù ni; ó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún jíjèrè àwọn tó ń rìn gbéregbère nínú ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ padà, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.
23. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ru ìjìyà àwọn ẹlòmíràn?
23 Báwo ni Jésù ṣe wá ru ìjìyà àwọn ẹlòmíràn? Nígbà tí Ìhìn Rere Mátíù ń fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 53:4 yọ, ó ní: “Àwọn ènìyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè wá sọ́dọ̀ rẹ̀; òun sì fi ọ̀rọ̀ lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún sàn; kí a lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: ‘Òun fúnra rẹ̀ gba àwọn àìsàn wa, ó sì ru àwọn òkùnrùn wa.’” (Mátíù 8:16, 17) Bí Jésù ṣe ń wo àwọn tó gbé onírúurú àìsàn tọ̀ ọ́ wá sàn, a lè sọ pé ó ń gba ìyà wọn jẹ nìyẹn. Àwọn ìwòsàn yẹn a sì máa gbà lára okun Jésù lóòótọ́. (Lúùkù 8:43-48) Nígbà tí Jésù sì ti lè wo onírúurú àìsàn sàn, ì báà jẹ́ nípa ti ara tàbí nípa tẹ̀mí, ẹ̀rí nìyẹn pé Ọlọ́run fún un lágbára láti wẹ àwọn èèyàn mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.—Mátíù 9:2-8.
24. (a) Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, kí ló dé tó fi jọ pé Ọlọ́run ló kó “ìyọnu bá” Jésù? (b) Kí ni ìdí tí Jésù fi jìyà tó sì kú?
24 Síbẹ̀ o, lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ṣe ló jọ pé Ọlọ́run ló kó “ìyọnu bá” Jésù. Ṣebí àwọn sàràkí-sàràkí nínú àwọn aṣáájú ìsìn ló sáà lé àwọn èèyàn lóro tí wọ́n fi fìyà jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n, ká rántí pé kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí wọ́n fi ń jẹ ẹ́ níyà o. Pétérù sọ pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀. Òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí òpó igi, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, kí a sì wà láàyè sí òdodo. Àti pé ‘nípa ìnà rẹ̀ ni a mú yín lára dá.’” (1 Pétérù 2:21, 22, 24) Gbogbo wa ló jẹ́ pé àsìkò kan wà tí a ṣèranù lọ nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá, “bí àwọn àgùntàn, tí ń ṣáko lọ.” (1 Pétérù 2:25) Àmọ́ Jèhófà lo Jésù láti fi pèsè ìràpadà fún wa kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀. Jèhófà mú kí ìṣìnà wa “ṣalábàápàdé” Jésù, kí Jésù sì rù ú. Ńṣe ni Jésù aláìṣẹ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti gba ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ. Nígbà tó sì ti jẹ ìyà tí kò tọ́ sí i, ní ti pé ó kú ikú ẹ̀sín lórí igi oró, ó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bá Ọlọ́run rẹ́ padà.
‘Ó Jẹ́ Kí A Ṣẹ́ Òun Níṣẹ̀ẹ́’
25. Báwo la ṣe mọ̀ pé ńṣe ni Mèsáyà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti jìyà àti láti kú?
25 Ǹjẹ́ Mèsáyà fẹ́ láti jìyà kí ó sì kú? Aísáyà sọ pé: “A ni ín lára dé góńgó, ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la Aísáyà 53:7) Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ká ní pé ó fẹ́ ni, ì bá ti pe “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá” lọ pé kí wọ́n wá gba òun sílẹ̀. Àmọ́ ó sọ pé: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?” (Mátíù 26:53, 54) Dípò èyí, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” yìí kò janpata rárá ni. (Jòhánù 1:29) Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà fẹ̀sùn èké kan Jésù níwájú Pílátù, Jésù “kò dáhùn.” (Mátíù 27:11-14) Kò fẹ́ sọ ohunkóhun tó lè ṣèdíwọ́ fún ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fi òun ṣe. Jésù ṣe tán láti kú gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn táa fi rúbọ, nítorí ó mọ̀ dájúdájú pé ikú òun yóò ra àwọn onígbọràn nínú ọmọ aráyé padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú.
ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa; àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.” (26. Lọ́nà wo ni àwọn alátakò Jésù gbà ṣe “ìkálọ́wọ́kò”?
26 Aísáyà wá túbọ̀ ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé wàyí nípa bí ìyà ṣe máa jẹ Mèsáyà, tí ẹ̀tẹ́ yóò sì bá a. Wòlíì yìí kọ̀wé pé: “Nítorí ìkálọ́wọ́kò àti ìdájọ́ ni a fi mú un lọ; ta sì ni yóò dàníyàn nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí pé a yà á nípa sí ilẹ̀ àwọn alààyè. Nítorí ìrélànàkọjá àwọn ènìyàn mi ni ó fi gba ọgbẹ́.” (Aísáyà 53:8) Nígbà tí àwọn ọ̀tá Jésù wá mú un tán, àwọn onísìn tó ń ṣàtakò rẹ̀ lo “ìkálọ́wọ́kò” nínú ohun tí wọ́n ṣe sí i. Kì í ṣe pé wọ́n dín ẹ̀mí ìkórìíra wọn sí i kù o, ìdájọ́ òdodo ni wọ́n ká lọ́wọ́ kò, tí wọ́n dènà rẹ̀. Nígbà tí Bíbélì Septuagint ti Gíríìkì ń túmọ̀ Aísáyà 53:8, “ẹ̀tẹ́” ló pè é dípò “ìkálọ́wọ́kò.” Àwọn ọ̀tá Jésù tẹ́ ẹ débi pé ohun tí wọ́n fojú rẹ̀ rí tilẹ̀ tún burú ju ohun ti wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọ̀daràn pàápàá. Ńṣe ni wọ́n tún fi ìdájọ́ òdodo wọ́lẹ̀ nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésù. Lọ́nà wo?
27. Nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ń ṣe ẹjọ́ Jésù, àwọn òfin wo ni wọ́n tẹ̀ lójú, àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà rú Òfin Ọlọ́run?
Mátíù 26:57-68) Èyí tó tilẹ̀ burú jù ni pé, àwọn aṣáájú ìsìn fi ìwà ọ̀dájú rú Òfin Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹjọ́ yẹn lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fúnni ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti fi wá ẹ̀sùn sí Jésù lọ́rùn. (Diutarónómì 16:19; Lúùkù 22:2-6) Wọ́n gba ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí èké gbọ́. (Ẹ́kísódù 20:16; Máàkù 14:55, 56) Wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀, wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wá sórí ara wọn àti orílẹ̀-èdè wọn. (Númérì 35:31-34; Diutarónómì 19:11-13; Lúùkù 23:16-25) Nípa bẹ́ẹ̀, kò sí “ìdájọ́” rárá, wọn kò fi òdodo ṣe ẹjọ́ débi tí wọ́n fi lè ṣèdájọ́ òtítọ́ láìṣègbè.
27 Bí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣáà ti fẹ́ gbẹ̀mí Jésù lọ́nàkọnà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú òfin àwọn fúnra wọn. Ohun tí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wí ni pé, bí ẹjọ́ kan bá ti la ikú lọ, inú gbọ̀ngàn tí wọ́n bá fi òkúta gbígbẹ́ kọ́, tí ó wà láyìíká tẹ́ńpìlì, nìkan ni kí àwọn Sànhẹ́dírìn ti ṣe ẹjọ́ yẹn, kì í ṣe inú ilé àlùfáà àgbà. Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ bá ti ṣu, àyàfi lójú mọmọ nìkan. Tí ẹjọ́ bá sì ti la ikú lọ wàyí, ó gbọ́dọ̀ di ọjọ́ kejì ìgbà tí wọ́n bá parí ìgbẹ́jọ́ kí wọ́n tó kéde ìdájọ́ pé onítọ̀hún jẹ̀bi. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò lè ṣe ẹjọ́ rárá bí Sábáàtì tàbí àjọ̀dún kankan bá ku ọ̀la. Gbogbo òfin wọ̀nyí ni wọ́n tẹ̀ lójú nígbà tí wọ́n ń ṣe ẹjọ́ Jésù. (28. Kí ni àwọn ọ̀tá Jésù kùnà láti gbé yẹ̀ wò?
28 Ǹjẹ́ àwọn ọ̀tá Jésù tilẹ̀ ṣèwádìí láti lè mọ irú ẹni tí àwọn ń ṣe ẹjọ́ rẹ̀ pàápàá? Aísáyà béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ta sì ni yóò dàníyàn nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀?” Ọ̀rọ̀ náà “ìran” lè tọ́ka sí orírun tàbí ìlà ìdílé ẹni. Nígbà tí àwọn Sànhẹ́dírìn ń ṣe ẹjọ́ Jésù, àwọn tó para pọ̀ wà nínú àjọ yẹn kò wo ìlà ìdílé tó ti wá rárá, pé ó kúnjú òṣùwọ̀n ẹni tó lè jẹ́ Mèsáyà táa ṣèlérí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ka ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì sí i lọ́rùn, wọ́n ní ikú tọ́ sí i. (Máàkù 14:64) Lẹ́yìn náà, gómìnà Pọ́ńtíù Pílátù ará Róòmù tẹ̀ sí tiwọn, ó sì dájọ́ pé kí wọ́n lọ kan Jésù mọ́gi. (Lúùkù 23:13-25) Bí wọ́n ṣe ‘ya’ Jésù “nípa” tàbí bí wọ́n ṣe dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò nìyẹn ní agbedeméjì ayé rẹ̀, lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ààbọ̀ péré.
29. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ pé ibi ìsìnkú Jésù wà pẹ̀lú “àwọn ẹni burúkú” àti “pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọlọ́rọ̀”?
29 Lẹ́yìn ìyẹn, Aísáyà kọ̀wé nípa ikú àti ìsìnkú Mèsáyà, pé: “Òun yóò sì ṣe ibi ìsìnkú rẹ̀ àní pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú, àti pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ikú rẹ̀, láìka òtítọ́ náà sí pé kò hu ìwà ipá kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀tàn kankan ní ẹnu rẹ̀.” (Aísáyà 53:9) Báwo ni Jésù ṣe wà pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú àti pẹ̀lú ọlọ́rọ̀ nígbà ikú àti ìsìnkú rẹ̀? Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù kú lórí òpó igi ìṣekúpani lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé àárín arúfin méjì ni wọ́n kàn án mọ́gi sí, lọ́nà yẹn, a lè sọ ọ pé wọ́n ṣe ibi ìsìnkú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú nìyẹn. (Lúùkù 23:33) Àmọ́, nígbà tí Jésù kú tán, Jósẹ́fù ará Arimatíà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀, fi ìgboyà lọ gbàṣẹ lọ́wọ́ Pílátù láti lè sọ òkú Jésù kalẹ̀ kí ó sì sin ín. Jósẹ́fù àti Nikodémù wá pa pọ̀ ṣètò òkú Jésù fún sísin, tí wọ́n sì gbé e sínú ibojì tuntun tí Jósẹ́fù ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́ fún ara rẹ̀. (Mátíù 27:57-60; Jòhánù 19:38-42) Nípa báyìí, ibi ìsìnkú Jésù tún wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọlọ́rọ̀.
‘Jèhófà Ní Inú Dídùn sí Títẹ̀ Ẹ́ Rẹ́’
30. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ní inú dídùn sí títẹ Jésù rẹ́?
30 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà wá sọ ohun kan tó ṣeni ní kàyéfì, ó ní: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́; ó mú kí ó ṣàìsàn. Bí ìwọ yóò bá fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, òun yóò rí àwọn ọmọ rẹ̀, yóò mú ọjọ́ rẹ̀ gùn, ohun tí Jèhófà ní inú dídùn sí yóò sì kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀. Aísáyà 53:10, 11) Báwo ni Jèhófà ṣe wá lè ní inú dídùn nínú rírí i pé wọ́n tẹ ìránṣẹ́ olóòótọ́ yìí rẹ́? Ó dájú pé Jèhófà kò fúnra rẹ̀ fìyà jẹ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Àwọn ọ̀tá Jésù ló fúnra wọn ṣe ohun tí wọ́n ṣe sí i. Ṣùgbọ́n Jèhófà gbà wọ́n láàyè láti hùwà ìkà yẹn. (Jòhánù 19:11) Nítorí kí ni? Ó dájú pé yóò dun Ọlọ́run ẹlẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti oníyọ̀ọ́nú gan-an bó ṣe ń wo Ọmọ rẹ̀ aláìṣẹ̀ tó ń jìyà. (Aísáyà 63:9; Lúùkù 1:77, 78) Dájúdájú, Jèhófà kò bínú sí Jésù rárá. Síbẹ̀, inú Jèhófà dùn sí bí Ọmọ rẹ̀ ṣe múra tán láti jìyà nítorí gbogbo àwọn ìbùkún tí yóò tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.
Nítorí ìdààmú ọkàn rẹ̀, òun yóò wò, òun yóò ní ìtẹ́lọ́rùn. Nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi, olódodo, yóò fi mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn; àwọn ìṣìnà wọn ni òun fúnra rẹ̀ yóò sì rù.” (31. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ọkàn Jésù lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi”? (b) Lẹ́yìn gbogbo ìdààmú tó bá Jésù nígbà tó ṣì jẹ́ ẹ̀dá èèyàn, kí ni ohun tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn ní pàtàkì?
31 Ọ̀kan lára ìbùkún yẹn ni pé Jèhófà fi ọkàn Jésù lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi.” Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Jésù gòkè padà sí ọ̀run, ó gbé ìtóye ẹbọ tó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rú wọlé wá síwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, Jèhófà sì fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gbà á fún gbogbo ìran ènìyàn. (Hébérù 9:24; 10:5-14) Nípa ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi tí Jésù rú yìí, ó di ẹni tó ní “àwọn ọmọ.” Òun gẹ́gẹ́ bíi “Baba Ayérayé,” lè wá fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ ní ìyè, àní ìyè ayérayé. (Aísáyà 9:6) Lẹ́yìn gbogbo ìdààmú tó bá Jésù nígbà tó ṣì jẹ́ èèyàn tí í ṣe ọkàn kan, ìtẹ́lọ́rùn gbáà ni yóò jẹ́ fún un pé òun lè wá dá aráyé nídè kúrò lọ́wọ́ àìsàn àti ikú wàyí! Ó sì dájú pé èyí tí yóò tilẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn jù lọ ni mímọ̀ tó mọ̀ pé ìwà títọ́ tí òun pa mọ́ yóò jẹ́ kí Baba òun lókè ọ̀run lè fún Sátánì Èṣù Elénìní tó ń ṣáátá Jèhófà lésì.—Òwe 27:11.
32. “Ìmọ̀” wo ni Jésù ní tó fi lè mú “ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀,” àwọn wo ló sì ní ìdúró òdodo yìí?
Hébérù 4:15) Bí Jésù sì ṣe jìyà débi pé ó kú sí i yìí, ó mú kó lè pèsè ẹbọ táa nílò láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìdúró òdodo. Àwọn wo ló wá ní ìdúró òdodo yìí? Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró ló kọ́kọ́ ní in. Lílò tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ni Jèhófà fi sọ pé wọ́n jẹ́ olódodo, ìyẹn yóò sì mú kó gbà wọ́n ṣọmọ tí yóò sì sọ wọ́n di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù. (Róòmù 5:19; 8:16, 17) Lẹ́yìn náà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀, wọ́n wá ní ìdúró òdodo, ìyẹn sì sọ wọ́n di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọn yóò sì la Amágẹ́dọ́nì já.—Ìṣípayá 7:9; 16:14, 16; Jòhánù 10:16; Jákọ́bù 2:23, 25.
32 Ìbùkún mìíràn tí ikú Jésù tún mú wá ni pé ó “mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” kódà ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí. Aísáyà sì sọ pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀ “nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀.” Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù gba ìmọ̀ yìí ní ti pé ó di ènìyàn, tó sì wá jìyà tí kò tọ́ sí i nítorí ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. (33, 34. (a) Kí ni ohun tí a kọ́ nípa Jèhófà tó mú inú wa dùn? (b) Àwọn wo ni “ọ̀pọ̀lọpọ̀” tí Mèsáyà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò rí “ìpín” gbà láàárín wọn?
33 Paríparì rẹ̀, Aísáyà wá ṣàpèjúwe àjàṣẹ́gun tí Mèsáyà jà, ó ní: “Fún ìdí yẹn, èmi yóò fún un ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀, tòun ti àwọn alágbára ńlá ni yóò sì jùmọ̀ pín ohun ìfiṣèjẹ, nítorí òtítọ́ náà pé ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú, àwọn olùrélànàkọjá ni a sì kà á mọ́; òun fúnra rẹ̀ sì ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pàápàá, ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣìpẹ̀ nítorí àwọn olùrélànàkọjá.”—34 Àwọn ọ̀rọ̀ tó parí apá àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí kọ́ni ní ohun ìdùnnú kan nípa Jèhófà, ìyẹn ni pé: Ó ka àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i sí iyebíye. A rí èyí látinú ìlérí tó ṣe pé òun yóò “fún” Mèsáyà Ìránṣẹ́ òun “ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀.” Ó jọ pé inú àṣà àwọn tó ń pín ohun àkótogunbọ̀ ni gbólóhùn yìí ti wá. Jèhófà mọyì ìdúróṣinṣin “ọ̀pọ̀lọpọ̀” àwọn olóòótọ́ ìgbàanì, títí kan àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù, àti Jóòbù, ó sì ti fi “ìpín” kan pa mọ́ fún wọn nínú ayé tuntun rẹ̀ tó ń bọ̀. (Hébérù 11:13-16) Bákan náà, yóò fún Mèsáyà Ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìpín pẹ̀lú. Dájúdájú, Jèhófà yóò san Jésù lérè fún pípa ìwà títọ́ mọ́. Kí ó dá àwa náà lójú pé Jèhófà kò ní ‘gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀.’—Hébérù 6:10.
35. Àwọn wo ni “àwọn alágbára ńlá” tí Jésù bá pín àwọn ohun ìfiṣèjẹ, kí sì ni àwọn ohun ìfiṣèjẹ yìí?
35 Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò sì tún rí ohun ìfiṣèjẹ látinú àjàṣẹ́gun rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá. Òun àti “àwọn alágbára ńlá” ni yóò sì jùmọ̀ pín àwọn ohun ìfiṣèjẹ yìí. Àwọn wo ni “àwọn alágbára ńlá” yìí nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó kọ́kọ́ ṣẹ́gun ayé bíi tirẹ̀ ni, ìyẹn ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Jòhánù 16:33; Ìṣípayá 3:21; 14:1) Kí wá ni àwọn ohun ìfiṣèjẹ yìí? Ó dájú pé “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wà lára rẹ̀, ìyẹn àwọn tí a lè sọ pé Jésù já gbà kúrò níkàáwọ́ Sátánì, tó sì fi fún ìjọ Kristẹni. (Éfésù 4:8-12) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “alágbára ńlá” tún gba ìpín nínú ohun ìfiṣèjẹ mìíràn. Nípa ṣíṣẹ́gun tí wọ́n ṣẹ́gun ayé, ńṣe ni wọ́n já ohunkóhun tí Sátánì lè gùn lé láti ṣáátá Ọlọ́run gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. Ìfọkànsìn wọn sí Jèhófà, tí kì í yẹ̀, ń gbé e ga, ó sì ń mú inú rẹ̀ dùn.
36. Ǹjẹ́ Jésù mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣẹ sí òun lára? Ṣàlàyé.
36 Jésù mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣẹ sí òun lára. Lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa mú un, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lákọsílẹ̀ nínú Aísáyà 53:12, ó wá sọ pé wọn yóò ṣẹ lára òun, ó ní: “Mo sọ fún yín pé èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ ṣe parí nínú mi, èyíinì ni, ‘A sì kà á mọ́ àwọn aláìlófin.’ Nítorí èyíinì tí ó kàn mí ń ní àṣeparí.” (Lúùkù 22:36, 37) Ó báni lọ́kàn jẹ́ pé, ìṣe pé Jésù jẹ́ aláìlófin náà ni wọ́n ṣe sí i lóòótọ́. Bí wọ́n ṣe ń pa arúfin ni wọ́n ṣe pa á, wọ́n kàn án mọ́gi láàárín àwọn olè méjì. (Máàkù 15:27) Síbẹ̀, ó fínnú-fíndọ̀ fara gba ẹ̀gàn yìí, nítorí ó mọ̀ dáadáa pé ńṣe lòun ń bá wa bẹ̀bẹ̀. Àfi bíi pé ó dúró sáàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ọrẹ́ ikú tó ń bọ̀ wá sórí wọn, tó sì fúnra rẹ̀ bá wọn fara gba ọrẹ́ yẹn.
37. (a) Kí ni àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbésí Jésù àti ikú rẹ̀ jẹ́ kí a lè dá mọ́? (b) Kí ni ìdí tó fi yẹ kí á dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti dẹni àgbéga?
37 Àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti ikú rẹ̀ ń jẹ́ kí a mọ kiní kan dájú, òun ni pé: Jésù Kristi ni Ìránṣẹ́ tí í ṣe Mèsáyà tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà yọ̀ǹda pé kí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá mú ojúṣe tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé Ìránṣẹ́ yìí yóò ṣe ṣẹ, kí ó jìyà kí ó sì kú, kí a lè rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú! Ìfẹ́ ńláǹlà ni Jèhófà sì fẹ́ wa yìí. Róòmù 5:8 sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” Ó mà yẹ kí á sì tún dúpẹ́ gidigidi, lọ́wọ́ Jésù Kristi, Ìránṣẹ́ tó ti dẹni àgbéga yìí o, pé ó fínnú-fíndọ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 5 Bí ìwé Targum ti Jonathan ben Uzziel (ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa), èyí tí J. F. Stenning túmọ̀ ṣe sọ ọ̀rọ̀ Aísáyà 52:13 ni pé: “Wò ó, ìránṣẹ́ mi, Ẹni Àmì Òróró (tàbí, Mèsáyà), yóò ṣàṣeyege.” Bákan náà, ìwé Babylonian Talmud, (ti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa) sọ pé: “Mèsáyà tí à ń wí, kí lorúkọ rẹ̀ ná? . . . [; àwọn] ará ilé Rábì [pè é ní, Aláìsàn], nítorí wọ́n ti sọ ọ́ pé, ‘Dájúdájú, ó ti ru àìsàn wa.’”—Sànhẹ́dírìn 98b; Aísáyà 53:4.
^ ìpínrọ̀ 15 Wòlíì Míkà pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ibi “tí ó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà.” (Míkà 5:2) Síbẹ̀, ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kékeré yìí ni a dá lọ́lá pé kí ó jẹ́ ibi tí wọ́n ti máa bí Mèsáyà.
^ ìpínrọ̀ 22 Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ìyọnu” fún ọ̀ràn àrùn ẹ̀tẹ̀. (2 Àwọn Ọba 15:5) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan wí, Aísáyà 53:4 yìí ló mú kí àwọn Júù kan ní èrò pé adẹ́tẹ̀ ni Mèsáyà yóò jẹ́. Ìwé Babylonian Talmud sọ pé ọ̀rọ̀ Mèsáyà ni ẹsẹ yìí ń sọ, ló bá pe Mèsáyà ní “ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó jẹ́ adẹ́tẹ̀.” Bíbélì Douay Version ti ìjọ Àgùdà túmọ̀ ẹsẹ kan náà yìí lọ́nà tí ẹ̀dà Vulgate lédè Látìn gbà túmọ̀ rẹ̀, ó ní: “A kà á sí ẹni tó dẹ́tẹ̀.”
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 212]
ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ
Bí Jésù Ṣe Mú Ojúṣe Yẹn Ṣẹ
ÀSỌTẸ́LẸ̀
ÌṢẸ̀LẸ̀
ÌMÚṢẸ
A gbé e lékè, a sì gbé e ga
Ìṣe 2:34-36; Fílí. 2:8-11; 1 Pét. 3:22
Wọ́n bà á jẹ́ wọ́n sì bẹ̀tẹ́ lù ú
Mát. 11:19; 27:39-44, 63, 64; Jòh. 8:48; 10:20
Ó mú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ta gìrì
Mát. 24:30; 2 Tẹs. 1:6-10; Ìṣí. 1:7
Wọn ò gbà á gbọ́
Jòh. 12:37, 38; Róòmù 10:11, 16, 17
Ìgbé ayé mẹ̀kúnnù ló fi bẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
Wọ́n tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ wọ́n sì kọ̀ ọ́
Mát. 26:67; Lúùkù 23: 18-25; Jòh. 1:10, 11
Ó gbé àwọn àìsàn wa
Wọ́n gún un
Ó jìyà nítorí ìṣìnà àwọn ẹlòmíràn
Ó dákẹ́ jẹ́ẹ́ kò wíjọ́ níwájú àwọn tó fẹ̀sùn kàn án
Mát. 27:11-14; Máàkù 14:60, 61; Ìṣe 8:32, 35
Wọ́n ṣe ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà àbòsí wọ́n sì dá a lẹ́bi láìtọ́
Mát. 26:57-68; 27:1, 2, 11-26; Jòh. 18:12-14, Jòh 18:19-24, 28-40
Wọ́n sìnkú rẹ̀ pẹ̀lú ọlọ́rọ̀
A fi ọkàn rẹ̀ rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi
Ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ní ìdúró òdodo
Róòmù 5:18, 19; 1 Pét. 2:24; Ìṣí. 7:14
Wọ́n kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Mát. 26:55, 56; 27:38; Lúùkù 22:36, 37
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 203]
‘Àwọn ènìyàn tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 206]
“Kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀”
[Credit Line]
Ara àwòrán inú “Ecce Homo” látọwọ́ Antonio Ciseri
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 211]
“Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú”