Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wòlíì Ọlọ́run Mú Ìmọ́lẹ̀ Wá fún Aráyé

Wòlíì Ọlọ́run Mú Ìmọ́lẹ̀ Wá fún Aráyé

Orí Kìíní

Wòlíì Ọlọ́run Mú Ìmọ́lẹ̀ Wá fún Aráyé

1, 2. Àwọn nǹkan wo ló ń kọ ọ̀pọ̀ èèyàn lóminú lóde ìwòyí?

LÁYÉ ìgbà tiwa yìí, ó jọ pé kò sóhun tọ́mọ aráyé ò lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ ṣe é. Ìrìn àjò ní gbangba òfuurufú, ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, yíyí apilẹ̀ àbùdá padà, àti àwọn ohun mìíràn tí sáyẹ́ǹsì hùmọ̀ ti mú kí aráyé láǹfààní láti ṣe oríṣiríṣi ohun tuntun, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa retí pé àwọn lè gbé ìgbé ayé tó túbọ̀ dára sí i, àní bóyá kí ẹ̀mí wọ́n túbọ̀ gùn sí i pàápàá.

2 Ṣé àwọn ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí ti wá mú kí ààbò wà fún ọ nínú ilé rẹ? Ṣé wọ́n ti mú kó máà sí ewu ogun mọ́? Ṣé wọ́n ti wo àrùn ní àwòtán, tàbí wọ́n ti mú kó máà sí ẹ̀dùn ọkàn ti pé ẹni téèyàn fẹ́ràn ń kú mọ́? Rárá o! Bó ti wù kí ìtẹ̀síwájú ẹ̀dá ènìyàn wúni lórí tó, ó ṣì níwọ̀n ibi tí agbára rẹ̀ mọ. Àjọ Worldwatch Institute sọ pé: “A ti jágbọ́n bí èèyàn ṣe lè rìnrìn àjò lọ sínú òṣùpá, a jágbọ́n bí a ṣe ń fi ègé sílíkọ̀n pẹlẹbẹ ṣe àwọn ẹ̀yà ara ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ tín-tìn-tín tó lágbára àrà ọ̀tọ̀, a sì lè lọ́ apilẹ̀ àbùdá sínú ènìyàn. Ṣùgbọ́n, a ò tíì lè pèsè omi tó mọ́ fún ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta èèyàn, a ò tíì lè dín rírun tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀wọ́ ẹ̀dá alààyè ń run kù, bẹ́ẹ̀ ni a ò tíì lè rí ohun àmúṣagbára tí a nílò láìkó ìdààmú bá àyíká wa.” Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń kọminú nípa ọjọ́ ọ̀la, wọn kò sì mọ ibi tí wọ́n lè yíjú sí fún ìtùnú àti ìrètí.

3. Báwo ni nǹkan ṣe rí ní Júdà ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa?

3 Bí nǹkan ṣe rí fún wa lóde òní jọ bó ṣe rí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà náà lọ́hùn-ún, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí Aísáyà ìránṣẹ́ òun lọ jíṣẹ́ ìtùnú fún àwọn ará Júdà, ìtùnú gan-an sì ni wọ́n ń fẹ́. Oríṣiríṣi àjálù ló ti já lu orílẹ̀-èdè yẹn. Ilẹ̀ Ọba Ásíríà òṣìkà máa tó wá yọ orílẹ̀-èdè yẹn lẹ́nu, wọn yóò sì da jìnnìjìnnì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ibo làwọn èèyàn Ọlọ́run lè yíjú sí fún ìgbàlà? Wọ́n ń dárúkọ Jèhófà lóòótọ́ o, ṣùgbọ́n èèyàn ni wọ́n fẹ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé.—2 Àwọn Ọba 16:7; 18:21.

Ìmọ́lẹ̀ Ń Tàn Nínú Òkùnkùn

4. Iṣẹ́ alápá méjì wo ni Jèhófà yàn fún Aísáyà láti polongo?

4 Jerúsálẹ́mù máa tó pa run, àwọn olùgbé Júdà yóò sì dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì nítorí ìṣọ̀tẹ̀ Júdà. Dájúdájú, gbẹgẹdẹ máa gbiná láìpẹ́. Ni Jèhófà bá yan iṣẹ́ fún wòlíì rẹ̀, Aísáyà, pé kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà àjálù yẹn, àmọ́, Ó ní kí ó kéde ìhìn rere pẹ̀lú. Àní lẹ́yìn àádọ́rin ọdún nígbèkùn, àwọn Júù yóò rí ìdáǹdè gbà kúrò ní Bábílónì! Àwọn àṣẹ́kù tó kún fún ìdùnnú yóò padà wá sí Síónì, wọn yóò sì láǹfààní láti tún fìdí ìjọsìn tòótọ́ múlẹ̀ níbẹ̀. Ìhìn ayọ̀ yìí ni Jèhófà gba ẹnu wòlíì rẹ̀ sọ láti fi mú kí ìmọ́lẹ̀ máa tàn nínú òkùnkùn.

5. Kí ni ìdí tí Jèhófà fi tètè sọ ète rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú?

5 Ó ju ọ̀rúndún kan lẹ́yìn tí Aísáyà kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí Júdà tó dahoro. Kí wá ni ìdí tí Jèhófà fi tètè ṣí ète rẹ̀ payá tipẹ́tipẹ́ ṣáájú? Ṣé àwọn tó fetí ara wọn gbọ́ àwọn ìkéde Aísáyà kò ti ní kú tipẹ́tipẹ́ ni kí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tó ṣẹ? Òótọ́ ni, wọ́n á ti kú. Síbẹ̀, nítorí àwọn ohun tí Jèhófà ṣí payá fún Aísáyà, àwọn tó wà láàyè nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa yóò ní àkọsílẹ̀ àwọn ìhìn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí lọ́wọ́. Èyí yóò jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jèhófà ni “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—Aísáyà 46:10; 55:10, 11.

6. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ju àwọn tó ń sọ àsọbádé nínú ọmọ aráyé lọ?

6 Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fọwọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sọ̀yà. Ọmọ ènìyàn lè lo òye tó ní nípa ọ̀ràn ìṣèlú àti bí nǹkan ṣe ń lọ láwùjọ láti fi sọ bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Ṣùgbọ́n Jèhófà nìkan ló lè mọ àmọ̀dájú ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà, àní títí dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà réré. Ó sì lè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.”—Ámósì 3:7.

“Aísáyà” Mélòó Ló Wà?

7. Báwo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣe jiyàn nípa ẹni tó kọ ìwé Aísáyà, kí sì ni ìdí rẹ̀?

7 Àríyànjiyàn lórí bóyá ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tàbí kò jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ló fà á tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fi ń gbé ìbéèrè dìde nípa ẹni tó kọ ìwé Aísáyà. Àwọn aṣelámèyítọ́ rin kinkin mọ́ ọn pé ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, yálà nígbà ìgbèkùn Bábílónì tàbí lẹ́yìn ìgbà náà, ló kọ apá tó kẹ́yìn nínú ìwé Aísáyà. Wọ́n ní ẹ̀yìn tí Júdà dahoro tán ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdahoro rẹ̀, pé nípa bẹ́ẹ̀, wọn kì í ṣe àwítẹ́lẹ̀ rárá ni. Àwọn aṣelámèyítọ́ yìí tún sọ pé lẹ́yìn Aísáyà orí ogójì, ìwé Aísáyà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bíi pé Bábílónì ni ìjọba alágbára tó wà lójú ọpọ́n lásìkò yẹn, àti bíi pé Ísírẹ́lì wà nígbèkùn níbẹ̀. Wọ́n wá sọ pé, ẹni yòówù kó kọ apá tó kẹ́yìn nínú ìwé Aísáyà, ó ní láti jẹ́ pé àárín àsìkò yẹn, ìyẹn láàárín ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, ló kọ ọ́. Ǹjẹ́ ìdí tó ṣe gúnmọ́ wà tí wọ́n fi ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀ bí? Rárá o!

8. Ìgbà wo ni iyè méjì nípa ẹni tó kọ ìwé Aísáyà bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe tàn kálẹ̀?

8 Ọ̀rúndún kejìlá Sànmánì Tiwa ni ìjiyàn tó bẹ̀rẹ̀ nípa ẹni tó kọ ìwé Aísáyà. Ọmọ Júù alálàyé náà, Abraham Ibn Ezra, ló dá a sílẹ̀. Ìwé Encyclopaedia Judaica sọ pé: “Nínú àlàyé [Abraham Ibn Ezra] nípa Aísáyà, ó sọ pé ìlàjì kejì, tó bẹ̀rẹ̀ láti orí ogójì, jẹ́ iṣẹ́ wòlíì kan tó gbé láyé nígbà Ìgbèkùn Bábílónì sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà Ìpadàbọ̀ Wá sí Síónì.” Nígbà tó di ọ̀rúndún kejìdínlógún sí ìkọkàndínlógún, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mélòó kan gba èrò Ibn Ezra kanrí, títí kan Johann Christoph Doederlein, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, ará Jámánì, tó tẹ atótónu rẹ̀ lórí ìwé Aísáyà jáde lọ́dún 1775, tó sì tẹ ẹ̀dà rẹ̀ kejì jáde lọ́dún 1789. Ìwé New Century Bible Commentary sọ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó wonkoko mọ́ àṣà ìpìlẹ̀, kò sí ẹni tí kò tíì tẹ́wọ́ gba àbá tí Doederlein gbé jáde . . . pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin kì í ṣe ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ bí kò ṣe pé wọ́n kọ ọ́ nígbà pípẹ́ lẹ́yìn náà.”

9. (a) Báwo ni wọ́n ṣe pín ìwé Aísáyà? (b) Báwo ni alálàyé Bíbélì kan ṣe ṣàkópọ̀ àríyànjiyàn tó dìde nípa ẹni tó kọ ìwé Aísáyà?

9 Àmọ́, ìbéèrè lórí ẹni tó kọ ìwé Aísáyà kò mọ síbẹ̀. Àbá èrò orí náà pé ẹni tó kọ ìwé Aísáyà pé méjì, pé Aísáyà Kejì wà, ló ṣokùnfà èrò ti pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tó kọ ọ́ tó mẹ́ta pàápàá. * Ni wọ́n bá tún pín ìwé Aísáyà síwájú sí i, tó fi di pé ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé wòlíì kan tí wọn ò mọ̀ ló kọ orí kẹẹ̀ẹ́dógún àti ìkẹrìndínlógún, tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn wá gbé ìbéèrè dìde nípa ẹni tó kọ orí kẹtàlélógún sí ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n. Síbẹ̀, òmíràn tún sọ pé kò lè jẹ́ Aísáyà ló kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú orí kẹrìnlélọ́gbọ̀n àti ìkarùndínlógójì. Kí ló fà á? Nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ jọ èyí tó wà nínú orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin gan-an ni, bẹ́ẹ̀ wọ́n ti sọ pé ẹlòmíràn yàtọ̀ sí Aísáyà ti ọ̀rúndún kẹjọ ló kọ wọ́n! Alálàyé Bíbélì náà Charles C. Torrey wá ṣàkópọ̀ àbájáde èrò wọn yìí ní ṣókí. Ó ní: “Ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ gbajúgbajà ‘Wòlíì Ìgbà Ìgbèkùn’ ti wá di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, ọ̀nà tí wọ́n gbà pín ìwé rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ òun fúnra rẹ̀ rì.” Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kọ́ ló fara mọ́ pípín tí wọ́n pín ìwé Aísáyà yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí.

Ẹ̀rí Pé Ẹnì Kan Ṣoṣo Ló Kọ Ọ́

10. Sọ àpẹẹrẹ kan nípa bí lílo gbólóhùn tó bára mu látòkè délẹ̀ ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé òǹkọ̀wé kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà.

10 Ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà tí a fi lè tẹnu mọ́ ọn pé ẹnì kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà. Ẹ̀rí kan ni ti bíbára mu tí ìlò gbólóhùn inú rẹ̀ bára mu látòkè délẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àpólà ọ̀rọ̀ náà “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì” fara hàn lẹ́ẹ̀mejìlá nínú Aísáyà orí kìíní sí ìkọkàndínlógójì, ó sì hàn lẹ́ẹ̀mẹtàlá nínú orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin, bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹ̀ẹ̀mẹfà péré ni gbólóhùn tí wọ́n fi ṣàpèjúwe Jèhófà yìí fara hàn nínú ìyókù Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Lílò tó lo gbólóhùn yìí léraléra, tó sì jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ nínú àwọn ìwé yòókù, jẹ́ ẹ̀rí pé òǹkọ̀wé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ́ ló kọ Aísáyà.

11. Kí ni àwọn ohun tó jọra nínú Aísáyà orí kìíní sí ìkọkàndínlọ́gbọ̀n àti orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin?

11 Àwọn ohun mìíràn tún wà tó jọra nínú Aísáyà orí kìíní sí ìkọkàndínlógójì àti orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin. Apá méjèèjì ni wọ́n ti lo àkànlò ẹwà èdè kan náà léraléra, irú bí obìnrin tí ìrora ìbímọ mú àti “ọ̀nà” tàbí “òpópó.” * Léraléra ni wọ́n sì tún sọ̀rọ̀ nípa “Síónì,” ìgbà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni ó lo gbólóhùn yìí nínú orí kìíní sí ìkọkàndínlógójì, ó sì lò ó nígbà méjìdínlógún nínú orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin. Kódà, Aísáyà lo ọ̀rọ̀ náà Síónì ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ nínú Bíbélì! Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia wá sọ pé irú ẹ̀rí bí ìwọ̀nyí “jẹ́ àmì tó mú kí ìwé náà dá yàtọ̀ ní tirẹ̀, ìyàtọ̀ tí ì bá ṣòro láti rí” ká ní pé ẹni méjì tàbí mẹ́ta, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ló kọ ọ́.

12, 13. Báwo ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣe fi hàn pé òǹkọ̀wé kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà?

12 Ẹ̀rí tó lágbára jù lọ pé ẹnì kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí Ọlọ́run mí sí. Ìwé yìí fi hàn kedere pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà gbọ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù sọ̀rọ̀ nípa ará Etiópíà kan, òṣìṣẹ́ ọba, tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń rí kà ní Aísáyà orí kẹtàléláàádọ́ta nísinsìnyí, ìyẹn apá tí àwọn aṣelámèyítọ́ òde òní sọ ní pàtó pé Aísáyà Kejì kọ. Ṣùgbọ́n, ohun tí Lúùkù sọ ni pé ará Etiópíà yẹn “ń ka ìwé wòlíì Aísáyà sókè.”—Ìṣe 8:26-28.

13 Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀ràn ti Mátíù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere yẹ̀ wò, èyí tó ṣàlàyé bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jòhánù Olùbatisí ṣe mú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a ń rí kà nísinsìnyí nínú Aísáyà 40:3 ṣẹ. Ta ni Mátíù sọ pé ó kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Ṣé Aísáyà Kejì, ẹni àìmọ̀ kan ló pè é? Rárá, ńṣe ló sọ pé ẹni tó kọ ọ́ ni “Aísáyà wòlíì.” * (Mátíù 3:1-3) Lásìkò mìíràn, Jésù ka ọ̀rọ̀ tí a ń rí kà nínú Aísáyà 61:1, 2 nísinsìnyí jáde látinú ìwé kíká kan. Nígbà tí Lúùkù ń sọ ìtàn yẹn, ó ní: “A fi àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà lé e lọ́wọ́.” (Lúùkù 4:17) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó tọ́ka sí àwọn apá ìṣáájú àti ti ìkẹyìn ìwé Aísáyà, síbẹ̀ kò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ gba ìhà pé òǹkọ̀wé mìíràn tún wà yàtọ̀ sí Aísáyà kan náà tó kọ ọ́. (Róòmù 10:16, 20; 15:12) Ó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò gbà gbọ́ pé òǹkọ̀wé méjì àbí mẹ́ta, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló kọ ìwé Aísáyà.

14. Báwo ni àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ṣe mú kí ọ̀ràn nípa òǹkọ̀wé Aísáyà túbọ̀ ṣe kedere sí i?

14 Tún ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí látinú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, ìyẹn àwọn ìwé àtayébáyé, tí púpọ̀ wọn ti wà ṣáájú ìgbà ayé Jésù. Ọ̀kan nínú ìwé Aísáyà tó jẹ́ àfọwọ́kọ, tí a mọ̀ sí Àkájọ Ìwé Aísáyà, ti wà láti ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì já àwọn aṣelámèyítọ́ tó sọ pé orí ogójì ni Aísáyà Kejì ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ ìyókù ìwé náà lọ nírọ́. Báwo ló ṣe já wọn nírọ́? Nínú ìwé àtayébáyé yìí, orí tí a mọ̀ sí orí ogójì nísinsìnyí bẹ̀rẹ̀ ní ìlà tí ó gbẹ̀yìn nínú òpó ìlà kan, inú òpó ìlà tó tẹ̀ lé e sì ni gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ orí náà parí sí. Ó dájú pé adàwékọ yẹn kò rí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìyàtọ̀ tí wọ́n wí, láti fi hàn pé ẹni tó ń kọ̀wé ti yí padà tàbí pé apá mìíràn nínú ìwé yẹn bẹ̀rẹ̀ láti ibẹ̀ síwájú.

15. Kí ni Flavius Josephus òpìtàn, ọmọ Júù ti ọ̀rúndún kìíní náà, rí sọ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Kírúsì?

15 Níkẹyìn, gbé ẹ̀rí Flavius Josephus òpìtàn, ọmọ Júù ti ọ̀rúndún kìíní náà, yẹ̀ wò. Yàtọ̀ sí pé ó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Kírúsì tó wà nínú Aísáyà ti wà lákọsílẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, ó tún sọ pé Kírúsì mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú. Josephus kọ ọ́ pé: “Kírúsì mọ nǹkan wọ̀nyí nítorí pé ó ka ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà ti kọ sílẹ̀ láti igba ọdún ó lé mẹ́wàá sẹ́yìn.” Bí Josephus ṣe wí, ó ṣeé ṣe kí mímọ̀ tí Kírúsì mọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí tilẹ̀ fi kún ìdí tó fi fínnú-fíndọ̀ fẹ́ láti dá àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, nítorí Josephus kọ ọ́ pé “ìfẹ́ àti ìtaraṣàṣà láti ṣe ohun tó wà lákọsílẹ̀ jẹ” Kírúsì “lógún gidigidi.”—Jewish Antiquities, Ìwé Kọkànlá, orí kìíní, ìpínrọ̀ kejì.

16. Kí ni a lè sọ nípa ohun tí àwọn aṣelámèyítọ́ sọ pé, lápá ìgbẹ̀yìn Aísáyà, wọ́n ṣàpèjúwe Bábílónì bíi pé òun gan-an ni ìjọba alágbára tó wà lójú ọpọ́n lásìkò yẹn?

16 Bí a ti sọ ṣáájú, ọ̀pọ̀ àwọn aṣelámèyítọ́ sọ pé bẹ̀rẹ̀ láti Aísáyà orí ogójì síwájú, ńṣe ni Aísáyà ṣàpèjúwe Bábílónì bíi pé òun gan-an ni ìjọba alágbára tó wà lójú ọpọ́n lásìkò yẹn, àti pé ó sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi pé wọ́n ti wà nígbèkùn. Ǹjẹ́ èyí kò ní fi hàn pé ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa ni òǹkọ̀wé yẹn gbé láyé? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ní tòdodo, ṣáájú kí ìwé Aísáyà tó dé orí ogójì pàápàá ló ti máa ń ṣàpèjúwe Bábílónì gẹ́gẹ́ bí agbára ayé tó wà lójú ọpọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nínú Aísáyà 13:19, ó pe Bábílónì ní “ìṣelóge àwọn ìjọba” tàbí, gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Today’s English Version ṣe túmọ̀ rẹ̀, ó ní “ìjọba tó lẹ́wà jù lọ.” Ó hàn kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́, nítorí pé ó ju ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà kí Bábílónì tó di agbára ayé. Aṣelámèyítọ́ kan wá “yanjú” ohun tí wọ́n kà sí ìṣòro yìí nípa wíwulẹ̀ sọ pé òǹkọ̀wé mìíràn ló kọ Aísáyà orí kẹtàlá jàre! Àmọ́ ṣá o, ká sọ̀rọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú bíi pé wọ́n ti ṣẹlẹ̀ kọjá jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ gan-an nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ńṣe ni ọ̀nà ìgbàkọ̀wé yìí máa ń jẹ́ kó túbọ̀ hàn dájúdájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ṣẹ dandan ni. (Ìṣípayá 21:5, 6) Ní tòótọ́, Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ nìkan ló tó láti sọ gbólóhùn yìí pé: “Àwọn nǹkan tuntun ni mo ń sọ jáde. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rú yọ, mo mú kí ẹ gbọ́ wọn.”—Aísáyà 42:9.

Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé

17. Àlàyé wo la lè ṣe nípa ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ Aísáyà tó yí padà láti orí ogójì síwájú?

17 Nígbà náà, ibo ni ẹ̀rí wọ̀nyí wá forí ọ̀rọ̀ tì sí? Òun ni pé, òǹkọ̀wé onímìísí kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá tí ìwé yẹn lódindi ti ń ti ọwọ́ ìran kan bọ́ sí ìkejì, iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kan ṣoṣo ni wọ́n kà á sí, kì í ṣe tẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lóòótọ́, àwọn kan lè sọ pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ìwé Aísáyà yàtọ̀ lọ́nà kan ṣá láti orí ogójì síwájú. Ṣùgbọ́n, rántí pé ó ju ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta tí Aísáyà fi ṣe iṣẹ́ wòlíì Ọlọ́run. A ó retí pé kí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ tó ń jẹ́, àti ọ̀nà tó ń gbà jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ yí padà láàárín àsìkò yẹn. Ohun kan ni pé, iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún Aísáyà kò mọ sí kíkéde ìkìlọ̀ líle nípa ìdájọ́ nìkan. Ó tún ní láti kéde ọ̀rọ̀ tó tẹnu Jèhófà wá pé: “Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú.” (Aísáyà 40:1) Ìlérí Ọlọ́run pé wọn yóò dá àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn lẹ́yìn àádọ́rin ọdún ní ìgbèkùn yóò jẹ́ ìtùnú gan-an fún àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú.

18. Kí ni ọ̀kan lára ẹṣin ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà tí a fẹ́ jíròrò nínú ìtẹ̀jáde yìí?

18 Ìdáǹdè àwọn Júù kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì ló jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ púpọ̀ nínú orí ìwé Aísáyà tí a jíròrò nínú ìwé yìí. * Bí a ó ṣe rí i, àwọn kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ tòde òní. Ẹ̀wẹ̀, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wúni lórí nípa ìgbésí ayé Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, àti ikú rẹ̀ pàápàá, ń bẹ nínú ìwé Aísáyà. Dájúdájú, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì inú ìwé Aísáyà yóò ṣe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti àwọn mìíràn kárí ayé láǹfààní. Ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo aráyé ni àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ní tòótọ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 9 Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ pe ẹnì kẹta tí wọ́n dá lábàá pé ó wà lára àwọn tó kọ Aísáyà ní Aísáyà Kẹta, wọ́n lóun ló kọ orí kẹrìndínlọ́gọ́ta sí ìkẹrìndínláàádọ́rin.

^ ìpínrọ̀ 13 Nínú àkọsílẹ̀ ìtàn kan náà yìí tó wà nínú Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù, àpólà ọ̀rọ̀ kan náà ni wọ́n lò.—Máàkù 1:2; Lúùkù 3:4; Jòhánù 1:23.

^ ìpínrọ̀ 18 Ìjíròrò Aísáyà orí kìíní sí ogójì wáyé nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Ẹ̀rí Látinú Àyẹ̀wò Àyípadà Tó Ń Bá Èdè Bí Ọjọ́ Ṣe Ń Gorí Ọjọ́

Ìwádìí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àyípadà tó ń bá èdè díẹ̀díẹ̀ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ pèsè ẹ̀rí síwájú sí i pé ẹnì kan ṣoṣo ló kọ ìwé Aísáyà. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n kọ apá kan ìwé Aísáyà ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì kọ apá mìíràn ní igba ọdún lẹ́yìn náà, ó yẹ kí ìyàtọ̀ wà nínú irú èdè Hébérù tí wọ́n lò ní ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n bí ìwádìí kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Westminster Theological Journal, ṣe wí, “ẹ̀rí látinú àyẹ̀wò nípa àyípadà tó ń bá èdè bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ti ìṣirò ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi hàn pé wọ́n ti kọ Aísáyà orí ogójì sí ìkẹrìndínláàádọ́rin ṣáájú ìgbà ìgbèkùn” lẹ́yìn. Òǹṣèwé ìwádìí náà wá parí èrò tirẹ̀ báyìí pé: “Bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó ń ṣe lámèyítọ́ bá ṣì rin kinkin mọ́ ọn pé dandan ni kí a gbà pé ìgbà ìgbèkùn tàbí ẹ̀yìn ìgbà ìgbèkùn ni wọ́n kọ Aísáyà, a jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n dijú sí ẹ̀rí tó wá látinú àyẹ̀wò nípa àyípadà tó ń bá èdè bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tó ta ko ìyẹn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Apá kan lára Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Aísáyà. Ibi tí Aísáyà orí kọkàndínlógójì parí sí ni a fi àmì tọ́ka sí yẹn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Igba ọdún ṣáájú ni Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè àwọn Júù