Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ète Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí

Ète Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí

SPINOZA, ọlọ́gbọ́n èrò orí, ọmọ ilẹ̀ Netherlands, kọ̀wé pé: “Mo ti gbìyànjú láti má ṣe fi ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ́rìn-ín, láti má ṣe sọkún lórí wọn, láti má ṣe kórìíra wọn, ṣùgbọ́n láti lóye wọn.” Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ìwọ́ dojú kọ ìpèníjà gbígbìyànjú láti lóye ojú ìwòye, ìgbésí ayé àtilẹ̀wá, àti ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ tí ó wà lábẹ́ àbójútó rẹ, títí kan àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà míràn, irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lè mú ìdúró tí ó dà bí ẹni pé kò bẹ́gbẹ́ jọ lórí àwọn ọ̀ràn kan. Ṣùgbọ́n, nígbà tí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá jẹ yọ ní kedere láti inú ìgbàgbọ́ ìsìn àti ti ìwà híhù ti akẹ́kọ̀ọ́ kan, wọ́n yẹ fún àfiyèsí rẹ. Watch Tower Bible and Tract Society (ẹgbẹ́ tí ń ṣe ìwé jáde ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà) ni ó ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí jáde, a sì ṣe é láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí dáradára sí i. A retí pé ìwọ yóò wá àyè láti fara balẹ̀ kà á.

Lílóye èrò ìgbàgbọ́ ìsìn ẹlòmíràn kò béèrè pé kí o tẹ́wọ́ gbà á tàbí kí o tẹ̀ lé e, pé kí a sì fi tó ọ létí kì í ṣe láti mú ọ yí ìgbàgbọ́ rẹ padà. Ìwé pẹlẹbẹ yìí kò gbìyànjú láti fi dandan mú ìwọ tàbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye àwọn Ẹlẹ́rìí ní ti ìsìn. Ìfẹ́ ọkàn wa wulẹ̀ jẹ́ láti sọ fún ọ nípa àwọn ìlànà àti èrò ìgbàgbọ́ tí díẹ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn, kí ó baà lè rọrùn fún ọ láti lóye àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí, kí o sì bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀. Àmọ́ ṣáá o, ohun tí a fi kọ́ àwọn ọmọ àti ohun tí wọ́n ń ṣe lè má fi ìgbà gbogbo bára mu, bí ọmọ kọ̀ọ̀kan ti ń kọ́ láti mú ẹ̀rí ọkàn tirẹ̀ dàgbà.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn òbí yóò ti ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n jàǹfààní kíkún nínú lílọ sí ilé ẹ̀kọ́. Fún ìdí èyí, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ wọn. Nítorí èyí, àwọn òbí Ẹlẹ́rìí àti àwọn ọmọ wọ́n máa ń mọrírì rẹ̀ nígbà tí àwọn olùkọ́ bá fi òye àti ọ̀wọ̀ bá wọn lò.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwọn Kristẹni tí a mọ̀ jákèjádò ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, a máa ń ṣì wọ́n lóye nígbà míràn. Nítorí náà, ìrètí wa ni pé, ìwé pẹlẹbẹ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí tí ó wà lábẹ́ àbójútó rẹ dáradára sí i. Ní pàtàkì, a retí pé ìwọ yóò rí ìdí tí ó fi jẹ́ pé, nínú àwọn àyíká ipò pàtó kan, wọ́n lè béèrè fún ẹ̀tọ́ láti yàtọ̀.