Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpèníjà Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ

Ìpèníjà Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ

Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, o dojú kọ ìpèníjà kan tí àwọn olùkọ́ ní àwọn ọ̀rúndún tí ó kọjá kò fi bẹ́ẹ̀ dojú kọ​—ìsìn tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

JÁLẸ̀ Sànmánì Agbedeméjì, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà sábà máa ń ṣe ìsìn kan náà. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ní nǹkan bí òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Europe mọ kìkì àwọn ìsìn pàtàkì díẹ̀: Ìsìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ní ìwọ̀ oòrùn, ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti Ìsìláàmù ní ìlà oòrùn, àti ìsìn Júù. Láìsí iyè méjì, ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ ìsìn tí wọ́pọ̀ gan-an lónìí ní Europe àti jákèjádò ayé. A ti dá àwọn ìsìn tí a kò mọ̀ rí sílẹ̀, yálà kí ó jẹ́ pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ni ó tẹ́wọ́ gbà á tàbí kí ó jẹ́ àwọn àtìpó àti àwọn olùwá ibi ìsádi ni ó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

Nípa báyìí, lónìí, ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Australia, Britain, Faransé, Germany, àti United States, ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí, Búdà, àti Hindu wà níbẹ̀. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ń fi tìtaratìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ilẹ̀ tí ó ju 239 lọ. Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè 14, wọ́n ní àwọn mẹ́ḿbà aláápọn tí ó ju 150,000 lọ.​—Wo àpótí “ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ìsìn Kan Kárí Ayé.”

Ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ àwọn ìsìn àdúgbò lè gbé ìpèníjà kojú àwọn olùkọ́. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè béèrè àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa àwọn ayẹyẹ olókìkí: Ó ha yẹ kí á sọ ọ́ di dandan fún akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe gbogbo ayẹyẹ​—láìka ìsìn rẹ̀ sí bí? Ọ̀pọ̀ lè ṣàìrí ohun tí ó burú nínú irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, kò ha yẹ kí a bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ ara àwùjọ tí kò pọ̀ pẹ̀lú bí? Ìdí mìíràn sì wà tí a ní láti gbé yẹ̀ wò: Ní àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí òfin ti ya ìsìn sọ́tọ̀ kúrò lára ìgbòkègbodò Ìjọba, tí ìtọ́ni ìsìn kò sì sí nínú ètò ẹ̀kọ́, àwọn kan kì yóò ha rí i pé kò wà déédéé láti kan àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ nípá ní ilé ẹ̀kọ́?

Ọjọ́ Ìbí

Kódà èdè àìyedè lè dìde nípa àwọn ayẹyẹ tí ó dà bíi pé wọn kò ní ìsopọ̀ èyíkéyìí pẹ̀lú ìsìn. Èyí jẹ́ òtítọ́ nípa ọjọ́ ìbí, tí a ń ṣe ní ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ọjọ́ ìbí, ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ dáradára pé wọ́n yàn láti má ṣe lọ́wọ́ nínú irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n bóyá, o kò mọ àwọn ìdí tí àwọn àti àwọn ọmọ wọ́n fi pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí.

Le livre des religions (Ìwé Àwọn Ìsìn), ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí ó ní ìpínkiri tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ Faransé, pe àṣà yìí ní ààtò ayẹyẹ, ó sì kà á kún “ààtò ayé.” Bí a tilẹ̀ rò pé ó jẹ́ àṣà ayé tí kì í ṣèpalára lónìí, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ní ìbẹ̀rẹ̀ olórìṣà ní ti gidi.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana (ìtẹ̀jáde ti 1991) sọ pé: “Ayé Íjíbítì, Gíríìsì, Róòmù, àti Páṣíà ìgbàanì ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí àwọn ọlọ́run, àwọn ọba, àti àwọn olókìkí.” Àwọn òǹṣèwé, Ralph àti Adelin Linton, sọ ohun tí ń bẹ nídìí èyí. Nínú ìwé wọn, The Lore of Birthdays, wọ́n kọ̀wé pé: “Mesopotámíà àti Íjíbítì, ibi tí ọ̀làjú ti bẹ̀rẹ̀, tún jẹ́ ilẹ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn ènìyàn ti rántí tí wọ́n sì yẹ́ ọjọ́ ìbí wọn sí. Títọ́jú àkọsílẹ̀ ọjọ́ ìbí ṣe pàtàkì nígbà ìjímìjí nítorí pé mímọ ọjọ́ ìbí ṣe pàtàkì fún fífipò ìràwọ̀ sọ tẹ́lẹ̀.” Ìsopọ̀ tààràtà yìí pẹ̀lú ìwòràwọ̀ jẹ́ ìdí kan fún àníyàn gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó yẹra fún ìwòràwọ̀ nítorí ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.​—Aísáyà 47:13-15.

Kò yani lẹ́nu nígbà náà láti kà nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia pé: “Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ìbí Rẹ̀ [Kristi] nítorí pé wọ́n ka ayẹyẹ ìbí ẹnikẹ́ni sí àṣà ìbọ̀rìṣà.”​—Ìdìpọ̀ 3, ojú ìwé 416.

Ó ń dùn mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí láti jùmọ̀ gbádùn ara wọn

Ní níní àwọn ohun tí a sọ ṣáájú lọ́kàn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàn láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Ó dájú pé, ìbí ọmọ kan jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu, aláyọ̀ kan. Lọ́nà ti ẹ̀dá, gbogbo àwọn òbí máa ń yọ̀ bí àwọn ọmọ wọn ti ń dàgbà, tí wọ́n ń di géńdé, bí ọdún ti ń gorí ọdún. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ń rí ayọ̀ ńlá nínú fífi ìfẹ́ wọn hàn sí ìdílé wọn àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn, nípa fífún wọn ní ẹ̀bùn, àti nípa jíjẹ̀gbádùn pa pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lójú ìwòye ibi tí ọjọ́ ìbí ti pilẹ̀ṣẹ̀ wá, wọ́n yàn láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ní àwọn àkókò míràn jálẹ̀ ọdún.​—Lúùkù 15:22-25; Ìṣe 20:35.

Kérésìmesì

A ń ṣayẹyẹ Kérésìmesì kárí ayé, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kì í ṣe Kristẹni pàápàá. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti tẹ́wọ́ gba họlidé yìí, ó lè yani lẹ́nu pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàn láti má ṣe ṣayẹyẹ yìí. Èé ṣe tí ìyẹn fi rí bẹ́ẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti sọ ní kedere, ọjọ́ ìbí Jésù ni a mọ̀-ọ́nmọ̀ fi sí December 25 láti bá ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà ti àwọn ará Róòmù mu. Kíyè sí àwọn ìpolongo tí ó tẹ̀ lé e yìí tí a mú jáde láti inú àwọn iṣẹ́ ìtọ́kasí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀:

“A kò mọ ọjọ́ ìbí Kristi. Àwọn ìwé Ìhìn Rere kò fi ọjọ́ àti oṣù náà hàn.”​—New Catholic Encyclopedia, Ìdìpọ̀ II, ojú ìwé 656.

“Saturnalia ní Róòmù pèsè àwòṣe fún púpọ̀ jù lọ lára àwọn àṣà àríyá àkókò Kérésìmesì.”​—Encyclopædia of Religion and Ethics

“Púpọ̀ jù lọ lára àwọn àṣà Kérésìmesì tí ó wọ́pọ̀ nísinsìnyí ní Europe, tàbí tí a kọ sílẹ̀ láti àwọn àkókò tó kọjá, kì í ṣe ojúlówó àṣà Kristẹni, bí kò ṣe àṣà abọgibọ̀pẹ̀ tí Ṣọ́ọ̀ṣì ti gbà wọlé tàbí gbà láàyè. . . . Saturnalia ní Róòmù pèsè àwòṣe fún púpọ̀ jù lọ lára àwọn àṣà àríyá àkókò Kérésìmesì.”​—Encyclopædia of Religion and Ethics (Edinburgh, 1910), tí James Hastings ṣàyẹ̀wò ṣàtúnṣe rẹ̀, Ìdìpọ̀ III, ojú ìwé 608, 609.

“A ti ń ṣayẹyẹ Kérésìmesì ní December 25 nínú gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹrin. Ní àkókò yẹn, èyí jẹ́ ọjọ́ àjọyọ̀ ìdúró oòrùn ìgbà òtútù ti olórìṣà, tí a ń pè ní ‘Ìbí (Latin, natale) Oòrùn,’ níwọ̀n bí oòrùn ti ń dà bí èyí tí a tún bí, bí ọjọ́ tí ń gùn sí i lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní Róòmù, Ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́ gba àṣà tí ó gbajúmọ̀ lọ́nà yíyọyẹ́ yìí . . . nípa fífún un ní ìtúmọ̀ tuntun.”​—Encyclopædia Universalis, 1968, (Faransé) Ìdìpọ̀ 19, ojú ìwé 1375.

“Àwọn ayẹyẹ olórìṣà ti Sol Invictus (Mithra) ní agbára ìdarí lórí ìdàgbàsókè àjọyọ̀ Kérésìmesì. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, December 25, tí ó jẹ́ ọjọ́ ìdúró oòrùn ìgbà òtútù ni a kà sí ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sáyé lọ́nà àrà nípasẹ̀ Kristi, ìṣàpẹẹrẹ Sol Invictus ni a sì tipa báyìí sọ di ti Kristi.”​—Brockhaus Enzyklopädie, (German) Ìdìpọ̀ 20, ojú ìwé 125.

Nígbà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ òkodoro òtítọ́ nípa Kérésìmesì, báwo ni àwọn kan ti ṣe hùwà padà? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ní 1644, àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń ta ko ayẹyẹ ìsìn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi òfin Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ka pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ tàbí ààtò ìsìn èyíkéyìí léèwọ̀ lórí ìpìlẹ̀ pé wọ́n [Kérésìmesì] jẹ́ ayẹyẹ abọgibọ̀pẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí a máa pa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí àwẹ̀. Charles Kejì bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò onípọ̀pọ̀ṣìnṣìn náà lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n àwọn ará Scotland rọ̀ mọ́ ojú ìwòye àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń ta ko ayẹyẹ ìsìn.” Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣayẹyẹ Kérésìmesì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sì í ṣe é lónìí tàbí lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Kérésìmesì.

Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì sọ̀rọ̀ dáradára nípa fífúnni ní ẹ̀bùn tàbí kíké sí àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ fún oúnjẹ aládùn ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ míràn. Ó fún àwọn òbí níṣìírí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti jẹ́ ọ̀làwọ́ tọkàntọkàn, dípò wíwulẹ̀ fúnni ni ẹ̀bùn nígbà tí gbogbogbòò máa ń fojú sọ́nà pé kí á ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 6:2, 3) A kọ́ àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ní ìpamọ́ra, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fúnni, èyí sì ní mímọ ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣayẹyẹ Kérésìmesì nínú. Ní òdì kejì, wọ́n ń mọrírì rẹ̀ nígbà tí a bá bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wọn láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ Kérésìmesì.

Àwọn Ayẹyẹ Mìíràn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà di ìdúró kan náà mú lórí àwọn họlidé ìsìn tàbí tí ó fara pẹ́ ti ìsìn tí ó máa ń wáyé ní ọdún ilé ẹ̀kọ́ ní onírúurú ilẹ̀, irú bí àjọyọ̀ June ní Brazil, Epiphany ní Faransé, Ayẹyẹ carnival ní Germany, Setsubun ní Japan, àti Halloween ní United States. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nyí tàbí ayẹyẹ mìíràn ní pàtó tí a kò dárúkọ níhìn-ín, àwọn òbí Ẹlẹ́rìí tàbí àwọn ọmọ wọn dájúdájú yóò láyọ̀ láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí o lè ní.