Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìparí

Ìparí

A KÒ ṢE ìwé pẹlẹbẹ yìí láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kíkún. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ti sapá láti ṣàlàyé díẹ̀ nínú àwọn ìlànà tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́, àti láti fi irú àwọn agbára ìdarí ìdílé tí ń nípa lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, bí ọ̀kan tàbí àwọn òbí méjèèjì bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí, hàn kedere.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ìdàgbàsókè tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn sí gan-an. Wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé pé èyí ń ṣèrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn ọmọ wọn ní àwọn agbègbè míràn. Èrò Ìgbàgbọ́ tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà, àti àwọn ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé mú kí ìgbésí ayé wọ́n nítumọ̀, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wọn ojoojúmọ́. Ní àfikún sí i, àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti ìlànà yẹn yẹ kí ó sún wọn láti gbìyànjú láti jẹ́ ògbóṣáṣá akẹ́kọ̀ọ́ àti ọmọ orílẹ̀-èdè rere jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń sapá láti wo ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí gan-an, nítorí náà, wọ́n ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sí pàtàkì gan-an. Nítorí èyí, ó jẹ́ àníyàn wọn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ débi tí agbára wọ́n mọ. Ní ti wọn, ní ilé wọn àti ní àwọn ibi ìjọsìn wọn kárí ayé, wọn yóò máa bá a lọ láti fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti ṣe ipa tiwọn nínú iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe tí ń méso jáde yìí.