Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́

A mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fún iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì wọn.

NÍTORÍ kíkà tí wọ́n ka iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sí, àwọn kan lè ronú pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ayé. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn, olùkọ́ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́, èyí sì ń béèrè fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́ni yíyẹ. Nítorí náà, ní àfikún sí lílo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ayé dáradára, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jàǹfààní fún ọ̀pọ̀ ọdún láti inú onírúurú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí Watch Tower Society ń darí. Ìwọ̀nyí ti ran àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ara wọn sunwọ̀n sí i ní ti èrò orí, ní ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí.

Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn Ẹlẹ́rìí ti dojú kọ àkànṣe ìpèníjà kan​—bí wọn yóò ṣe kọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àǹfààní láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ fún ìgbà díẹ̀ tàbí tí wọn kò tilẹ̀ lọ rárá, àti nípa báyìí tí wọn kò mọ̀ ọ́n kọ tàbí mọ̀ ọ́n kà. Láti kúnjú àìní yìí, Watch Tower Society ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà.

Fún àpẹẹrẹ, ní Nàìjíríà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń darí kíláàsì mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà láti 1949. Èyí sì ti ran, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀wé kà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìwádìí kan fi hàn pé ohun tó ju mẹ́sàn-án lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló mọ̀wé kọ, tí wọ́n sì mọ̀wé kà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo àwọn tó mọ̀wé kọ tí wọ́n sì mọ̀wé kà lórílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ kò tó ìdá márùn-ún nínú mẹ́wàá. Bákan náà, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, àtọdún 1946 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Láàárín ọdún kan, àwọn èèyàn tó ju 6,500 ni wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè mọ̀wé kọ, kí wọ́n sì mọ̀wé kà. Kódà, ní báyìí ó ti ju 100,000 èèyàn tó ti jàǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ọ̀pọ̀ ọdún la ti ń ṣètò ìlé ẹ̀kọ́ mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà láwọn orílẹ̀-èdè míì bíi Bòlífíà, Kamẹrúùnù, Nepal àti Sáńbíà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ ohun tó ju mílíọ̀nù méje ìwé Apply Yourself to Reading and Writing ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ.

Àwọn aláṣẹ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti gbóríyìn fún irú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà bẹ́ẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí a ti ń darí wọn. Fún àpẹẹrẹ, ní Mexico, òṣìṣẹ́ ìjọba kan kọ̀wé pé: “Mo mọrírì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín, àti lórúkọ ìjọba ìpínlẹ̀, mo ń fi ìkíni àtọkànwá wọn ráńṣẹ́ sí i yín fún iṣẹ́ takuntakun yín tí ń tẹ̀ síwájú fún àǹfààní àwọn ènìyàn ní mímú ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ wá fún àwọn tí kò mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. . . . Mo dàníyàn pé kí ẹ ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín.”

À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú kíkàwé àti sísọ̀rọ̀ ní gbangba

Nítorí pé wọ́n ka iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sí pàtàkì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti mú agbára wọn láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn sunwọ̀n sí i. Láti pèsè irú ìrànwọ́ yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ tí ó ju 119,000 kárí ayé la ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí òye bí a ti ń kàwé àti bí a ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba. Ní gbàrà tí wọ́n bá ti mọ̀wé kà, àwọn tí ó jẹ́ ọmọdé pàápàá lè forúkọ sílẹ̀, kí wọ́n sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, tí ó wúlò fún wọn ní àwọn agbègbè míràn pẹ̀lú, títí kan ní ilé ẹ̀kọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ olùkọ́ ti sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí sábà máa ń ṣàlàyé èrò wọn dáradára.

A fún kíkàwé ní ìṣírí dáradára nínú ìjọ wọn, a sì fún ìdílé kọ̀ọ̀kan níṣìírí bákan náà láti ní ibi àkójọ ìwé kíkà ìdílé pẹ̀lú onírúurú ìtẹ̀jáde

Ní àfikún, a fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níṣìírí láti ní ibi àkójọ ìwé kíkà tí ó ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwé atúmọ̀ èdè, àti àwọn ìwé ìtọ́kasí mìíràn, nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, tàbí ibi ìpàdé wọn. Ibi àkójọ ìwé kíkà yìí wà fún gbogbo àwọn tí ó bá ń wá sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. A fún kíkàwé ní ìṣírí dáradára nínú ìjọ wọn, a sì fún ìdílé kọ̀ọ̀kan níṣìírí bákan náà láti ní ibi àkójọ ìwé kíkà ìdílé pẹ̀lú onírúurú ìtẹ̀jáde láti kúnjú àìní àwọn ọmọ àti àwọn àgbà.

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Mìíràn

Watch Tower Society tún ń darí ilé ẹ̀kọ́ fún dídá àwọn míṣọ́nnárì lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́kọ̀ọ́, títí kan ilé ẹ̀kọ́ fún dídá àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú àwọn ìjọ àdúgbò lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí jẹ́ àfikún ẹ̀rí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sí pàtàkì gidigidi.