Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojúṣe Àwọn Òbí

Ojúṣe Àwọn Òbí

Láìsí àníàní, títọ́ àwọn ọmọ dàgbà láti di àgbà wíwà déédéé nínú àwùjọ tòní kò rọrùn.

ÀJỌ NATIONAL Institute of Mental Health ti United States tẹ àbájáde ìwádìí kan lórí àwọn òbí tí a ronú pé wọ́n ṣàṣeyọrí​—àwọn tí àwọn ọmọ wọn tí ó ti kọjá ọmọ ọdún 21, “jẹ́ àwọn àgbà wíwúlò tí ń mú ara wọn bá àwùjọ mu dáradára.” A bi àwọn òbí wọ̀nyí pé: ‘Láti inú ìrírí rẹ, ìmọ̀ràn dídára jù lọ wo ni ẹ lè fún àwọn òbí yòó kù?’ Ìwọ̀nyí ní èsì tí ó wọ́pọ̀ jù lọ: ‘Fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ dáradára,’ ‘bá wọn wí lọ́nà títọ́,’ ‘ẹ lo àkókò pa pọ̀,’ ‘kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,’ ‘ẹ ní ọ̀wọ̀ fúnra yín,’ ‘fetí sílẹ̀ sí wọn ní ti gidi,’ ‘pèsè ìtọ́sọ́nà dípò ìwàásù,’ sì ‘sọ ojú abẹ níkòó.’

Àwọn olùkọ́ ń kó ipa pàtàkì nínú pípèsè àwọn àgbà bíbójú mu

Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe àwọn òbí nìkan ni ó ní láti ṣiṣẹ́ láti pèsè àwọn àgbà ọ̀dọ́ bíbójú mu. Àwọn olùkọ́ pẹ̀lú ń kó ipa pàtàkì nínú èyí. Onírìírí olùgbaninímọ̀ràn ilé ẹ̀kọ́ kan sọ pé: “Ète pàtàkì tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní láti mú ṣẹ jẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí láti pèsè àwọn àgbà ọ̀dọ́ tí ó ní láárí tí ó dàgbà dáradára ní ti ìmòye, ní ti ara, àti ní ti èrò ìmọ̀lára.”

Nítorí náà, àwọn òbí àti olùkọ́ ń lépa góńgó kan náà​—láti pèsè àwọn èwe tí wọn yóò di àwọn àgbà tí ó dàgbà dénú, tí wọ́n sì wà déédéé, tí wọ́n ń gbádùn ìwàláàyè, tí wọ́n sì wà ní ipò yíyẹ nínú àwùjọ tí wọ́n ń gbé.

Òṣìṣẹ́ Ẹlẹgbẹ́ Ẹni, Kì í Ṣe Abánidíje

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣòro máa ń dìde nígbà tí àwọn òbí bá kùnà láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan kì í kọbi ara sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn rara; àwọn mìíràn ń gbìyànjú láti faga gbága pẹ̀lú àwọn olùkọ́. Ní jíjíròrò ipò yìí, ìwé ìròyìn Faransé kan sọ pé: “Kì í ṣe olùkọ́ nìkan ni ó tún jẹ́ ọ̀gákọ̀ ojú omi mọ́. Bí àṣeyọrí àwọn ọmọ wọn ti gba àwọn òbí lọ́kàn ju bí ó ti yẹ, wọ́n ń yẹ àwọn ìwé ilé ẹ̀kọ́ wò fínnífínní, wọ́n ń ṣèdájọ́ òun lámèyítọ́ àwọn ọ̀nà ìgbàkọ́ni, wọ́n sì máa ń tètè bínú nígbà àkọ́kọ́ tí ọmọ wọ́n bá gba máàkì tí kò dára.” Irú àwọn ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè tẹ ẹ̀tọ́ àwọn olùkọ́ lójú.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nímọ̀lára pé ó túbọ̀ ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní nígbà tí àwọn òbí bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni, ní fífi ọkàn-ìfẹ́ lílágbára, tí ń ṣèrànwọ́ hàn nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ronú pé ó túbọ̀ ń ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní nígbà tí àwọn òbí bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́, ní fífi ọkàn-ìfẹ́ lílágbára, tí ń ṣèrànwọ́ hàn nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ túbọ̀ ń ṣòro sí i.

Àwọn Ìṣòro Ilé Ẹ̀kọ́ Lónìí

Níwọ̀n bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ti ń gbé àwùjọ tí wọ́n jẹ́ apá kan rẹ̀ yọ, wọn kò bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí àwùjọ ní gbogbogbòò ní. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ti pọ̀ sí i lọ́nà yíyára kánkán. Ní ṣíṣàpèjúwe àwọn ipò nǹkan ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní United States, ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń sùn ní kíláàsì, wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ara wọn ní àwọn ọ̀nà àbákọjá tí a lẹ àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú mọ́, wọ́n ń fẹnu tẹ́ḿbẹ́lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rere. . . . Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ń dojú kọ àwọn ìṣòro bíi bíbójú tó ọmọ, bíbá òbí tí ó wà ní àhámọ́ lò àti sísálà lọ́wọ́ ìwà ipá àwọn ìpàǹpá. Ní ọjọ́ èyíkéyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdá márùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ń pa ilé ẹ̀kọ́ jẹ.”

Èyí tí ń dáni níjì ní pàtàkì ni ìṣòro ìwà ipá jákèjádò tí ń lọ sókè ní àwọn ilé ẹ̀kọ́. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, títira ẹni àti lílura ẹni máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n yíyìnbọn àti gígúnbẹ léraléra ni ó rọ́pò rẹ̀ nísinsìnyí. Ohun ìjá ti wá wọ́pọ̀ sí i, ìkọlù wá le koko, tí àwọn ọmọ sì tètè ń yíjú sí ìwà ipá, tí ó sì jẹ́ ní ọjọ́ orí tí ó túbọ̀ kéré.

Láìsí àníàní, kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ni ó dojú kọ àwọn ipò pípòkúdu bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ kárí ayé ń dojú kọ ipò tí a mẹ́nu kàn nínú ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lédè Faransé, Le Point, pé: “A kò tún bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ mọ́; kò ní ọlá àṣẹ kankan.”

Àwọn òbí aláṣeyọrí ń lo àkókò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn

Irú àìlọ́wọ̀ fún ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ewu gidi fún gbogbo àwọn ọmọ. Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti gbin ìgbọ́ràn àti ọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ, àwọn ànímọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí nínú ìgbésí ayé ní ilé ẹ̀kọ́ lónìí, sọ́kàn àwọn ọmọ wọn.