Ojú Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń wo Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo òbí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, wọn kò kóyán ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kéré. “Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yẹ kí ó ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti di ẹni tí ó wúlò láwùjọ. Ó tún yẹ kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì dàgbà fún àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n jogún bá, kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn.”
Tímótì Kìíní 5:8) Ọdún tí àwọn ọmọ ń lò ní ilé ẹ̀kọ́ ń múra wọn sílẹ̀ fún ẹrù iṣẹ́ tí wọn yóò tẹ́wọ́ gbà nínú ìgbésí ayé. Nítorí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí nímọ̀lára pé, a ní láti fi ọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
GẸ́GẸ́ bí àyọkà yìí láti inú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣe dábàá, ọ̀kan lára ète pàtàkì ẹ̀kọ́ ìwé jẹ́ láti kọ́ àwọn ọmọ fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́, tí ó wé mọ́ mímú kí wọ́n lè bójú tó àìní ìdílé ní ọjọ́ iwájú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé èyí jẹ́ ẹrù iṣẹ́ mímọ́ ọlọ́wọ̀. Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Dájúdájú bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (“Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yẹ kí ó ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti di ẹni tí ó wúlò láwùjọ. Ó tún yẹ kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì dàgbà fún àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n jogún bá, kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn.”—The World Book Encyclopedia
Àwọn Ẹlẹ́rìí ń sapá láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Bíbélì náà: “Ohun yòó wù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi gbogbo ọkàn yín ṣiṣẹ́ lẹ́nu rẹ̀, bí ẹni pé ẹ ń ṣiṣẹ́ fún Olúwa, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kólósè 3:23, Today’s English Version) Ìlànà yìí kan gbogbo apá ìgbésí ayé ojoojúmọ́, títí kan ilé ẹ̀kọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń tipa báyìí fún àwọn èwe wọn níṣìírí láti ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n sì fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí a bá yàn fún wọn ní ilé ẹ̀kọ́.
“Ohun yòó wù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi gbogbo ọkàn yín ṣiṣẹ́ lẹ́nu rẹ̀, bí ẹni pé ẹ ń ṣiṣẹ́ fún Olúwa.”—Kólósè 3:23, Today’s English Version
Bíbélì kọ́ni láti ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè tí ẹnì kan ń gbé pẹ̀lú. Nítorí náà, nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ bá pọn dandan dé ọjọ́ orí kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àṣẹ yìí.—Róòmù 13:1-7.
Bí kò tilẹ̀ tẹ́ḿbẹ́lú ìjẹ́pàtàkì ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́, Bíbélì fi hàn pé èyí kì í ṣe góńgó kan ṣoṣo, tàbí góńgó pàtàkì jù lọ tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó kẹ́sẹ járí yẹ kí ó gbé ayọ̀ wíwà láàyè ró nínú àwọn ọmọ, kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di mẹ́ḿbà tí ó wà déédéé láwùjọ. Nípa báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò pé yíyan àwọn ìgbòkègbodò lẹ́yìn òde kíláàsì ṣe pàtàkì gidigidi. Wọ́n gbà gbọ́ pé ìsinmi gbígbámúṣé, orin, eré ọwọ́dilẹ̀, eré ìmárale, ìbẹ̀wò sí àwọn ibi àkójọ ìwé kíkà àti sí àwọn ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀m̀báyé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ń ṣe bẹbẹ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé. Ní àfikún sí i, wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà, kí wọ́n sì máa wá àyè láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àfikún Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Ńkọ́?
Nítorí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun, àǹfààní láti rí iṣẹ́ ṣe ń yí padà látìgbàdégbà. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ yóò ní láti ṣiṣẹ́ tàbí ṣòwò tí wọn kò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣe pàtó lé lórí. Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ ti rí báyìí, ìwà wọn sí iṣẹ́ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́
ara ẹni, ní pàtàkì agbára wọn láti mára bá ìyípadà mu, yóò wúlò fún wọn gan-an. Nítorí náà, ó sàn jù pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dàgbà di ẹni tí ó ní ‘orí tí a ṣe dáradára dípò orí tí ó kún dáradára,’ gẹ́gẹ́ bí Montaigne, aláròkọ ti Ìgbà Ìsọjí Ọ̀làjú, ti sọ.Àìríṣẹ́ṣe, tí ń bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ àti èyí tí ó tòṣì jà, sábà máa ń fẹjú mọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí kò ní páálí tí ó kúnjú ìwọ̀n. Nítorí náà, bí àǹfààní àtiríṣẹ́ ṣe bá béèrè fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní àfikún sí èyí tí ó kéré jù lọ tí òfin béèrè fún, ó kù sọ́wọ́ àwọn òbí láti tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà nínú ṣíṣe ìpinnu nípa àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn àǹfààní ọjọ́ iwájú àti àwọn ìrúbọ tí irú àfikún ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yóò gbà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ yóò gbà pé àṣeyọrí nínú ìgbésí ayé ní nínú ju àṣeyọrí ní ti ara. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ri gbogbo ìgbésí ayé wọn bọ inú iṣẹ́ wọn pàdánù ohun gbogbo nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn. Àwọn òbí kan ti fi ìgbésí ayé ìdílé wọn àti àkókò tí ó yẹ kí wọ́n lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn rúbọ, ní kíkùnà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà di géńdé, nítorí pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kò jẹ́ kí wọ́n ráyè.
Ní kedere, ó yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé fi hàn pé a nílò ju aásìkí ti ara lọ, láti láyọ̀ ní tòótọ́. Jésù Kristi sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì í wà láàyè nípa àkàrà nìkan ṣoṣo, bí Mátíù 4:4, New International Version) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọrírì ìjẹ́pàtàkì mímú àwọn ànímọ́ dídára ní ti ọ̀nà ìwà híhù àti ní ti ẹ̀mí dàgbà títí kan mímúra ara wọn sílẹ̀ fún bíbójú tó àwọn àìní wọn ní ti ara.
kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ń jáde wá láti ẹnu Ọlọ́run.’” (