Kí Nìdí Tí Dádì àti Mọ́mì Fi Fi Ara Wọn Sílẹ̀?
ORÍ 4
Kí Nìdí Tí Dádì àti Mọ́mì Fi Fi Ara Wọn Sílẹ̀?
“Mo wà nílé pẹ̀lú Mọ́mì lọ́jọ́ tí Dádì fi wá sílẹ̀ lọ. Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni mí nígbà yẹn, torí náà ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kò yé mi. Mo jókòó sílẹ̀ mò ń wo tẹlifíṣọ̀n, mo sì ń gbọ́ tí mọ́mì mi ń sunkún tí wọ́n ń bẹ dádì mi pé kí wọ́n má lọ. Dádì sọ̀ kalẹ̀ wá láti yàrá òkè, wọ́n gbé báàgì ńlá kan dá ní, wọ́n wá kúnlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, wọ́n fi ẹnu kò mí lórí, wọ́n wá sọ pé, ‘Dádì fẹ́ràn ẹ gan-an, Dádì ò ní gbàgbé ẹ.’ Bí wọ́n ṣe jáde lọ nìyẹn. Ó pẹ́ gan-an lẹ́yìn ìgbà yẹn kí n tó tún fojú kan dádì mi. Látìgbà yẹn lẹ̀rù ti máa ń bà mí pé Mọ́mì náà tún lè fi mí sílẹ̀ lọ.”—Elaine, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].
BÍ ÀWỌN òbí rẹ bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó lè dà bíi pé gbogbo nǹkan ti forí ṣánpọ́n, àti pé èyí máa fa ìyà tí kò lópin fún ẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lè mú kí ojú máa tì ẹ́, kínú máa bí ẹ, kí ọkàn rẹ má balẹ̀, kí ẹ̀rù máa bà ẹ́ pé wọ́n á pa ẹ́ tì. O tiẹ̀ lè máa dára ẹ lẹ́bi, ìbànújẹ́ lè sorí rẹ kodò, kó o sì máa mọ̀ ọ́n lára pé o pàdánù ohun tó pọ̀ lápọ̀jù, kódà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o gbẹ̀san.
Tó bá jẹ́ pé ẹnu àìpẹ́ yìí làwọn òbí rẹ fi ara wọn sílẹ̀, irú àwọn ohun tá a sọ yìí lè máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ, èyí kò sì yani lẹ́nu torí pé ṣe ni Ẹlẹ́dàá fẹ́ kí bàbá àti ìyá pa ọwọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. (Éfésù 6:1-3) Ló wá di pé, o kàn dédé wá ọ̀kan nínú wọn tì, bóyá ẹni yẹn lo sì fẹ́ràn gan-an nínú àwọn méjèèjì. Ọmọ kan tó ń jẹ́ Daniel táwọn òbí ẹ fira wọn sílẹ̀ nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méje sọ pé: “Mo fẹ́ràn bàbá mi gan-an, ó sì máa ń wù mí pé kí n máa wà lọ́dọ̀ wọn. Àmọ́ nígbà tí wọ́n lọ sí kóòtù, adájọ́ sọ pé ọ̀dọ̀ mọ́mì mi ni ká máa gbé.”
Ìdí Tí Àwọn Òbí Fi Ń Fi Ara Wọn Sílẹ̀
Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn òbí bá fi ara wọn sílẹ̀, ó máa ń bá àwọn ọmọ lójijì torí pé àwọn òbí kò jẹ́ kí àwọn ọmọ náà mọ̀ pé ìṣòro wà láàárín wọn rárá. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yẹn bá mi lójijì! Ṣe ni mo máa ń rò pé àwọn méjèèjì fẹ́ràn ara wọn gan-an.” Kódà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí yìí kì í sábà gbọ́ ara wọn yé, ó ṣì lè ya àwọn ọmọ lẹ́nu, kó sì dùn wọ́n gan-an pé wọ́n pínyà!
Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn òbí náà ṣe ìṣekúṣe ni wọ́n ṣe fi ara wọn sílẹ̀. Tí èyí bá ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run gba èyí tí kò ṣèṣekúṣe lára wọn láyè láti kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lè fẹ́ ẹlòmíì. (Mátíù 19:9) Àwọn míì sì fi ara wọn sílẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ kí “ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” di ìjà ńlá láàárín wọn, débi pé ọ̀kan lára wọn ń bẹ̀rù pé ẹnì kejì lè ṣe òun àtàwọn ọmọ léṣe. *—Éfésù 4:31.
Àmọ́ ṣá o, àwọn tọkọtaya kan máa ń fi ara wọn sílẹ̀ torí àwọn ìdí tí kò tíì burú tó bẹ́ẹ̀. Tara wọn nìkan ni àwọn kan máa ń rò tí wọ́n fi ń pínyà dípò kí wọ́n jọ yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Wọ́n á sọ pé inú àwọn kì í dùn mọ́ tàbí pé ìfẹ́ ẹnì kejì ti kúrò Málákì 2:16) Yàtọ̀ sí nǹkan wọ̀nyí, ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé àárín àwọn tọkọtaya kan lè dà rú torí pé ọ̀kan lára wọn di Kristẹni tòótọ́.—Mátíù 10:34-36.
lọ́kàn àwọn. Ọlọ́run “kórìíra ìkọ̀sílẹ̀” tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe, kò sì dùn mọ́ ọn nínú. (Èyí tó wù kó jẹ́, bí àwọn òbí rẹ kò bá sọ ìdí tí wọ́n fi fi ara wọn sílẹ̀ fún ẹ tàbí tí wọ́n kàn máa ń dá ẹ lóhùn bákan ṣá nígbà tó o bá bi wọ́n nípa ìkọ̀sílẹ̀ náà, kò túmọ̀ sí pé wọn kò fẹ́ràn rẹ. Ó lè jẹ́ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ náà ṣe ń dùn wọ́n lọ́kàn tó ni kò jẹ́ kí wọ́n fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rárá. (Òwe 24:10) Wọ́n tún lè má mọ bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹ, kí ojú sì máa tì wọ́n láti gbà pé àwọn méjèèjì ṣàṣìṣe.
Ohun Tó O Lè Ṣe
Mọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. Torí pé ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí rẹ lè mú kí nǹkan dojú rú fún ẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ṣáá lórí àwọn nǹkan tó ò tiẹ̀ kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀. Tó bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù rẹ lè dín kù tó o bá kọ́kọ́ mọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. Fi àmì ✔ sí àpótí tó bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù jù nínú àwọn ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí, tàbí kó o kọ ohun tó o mọ̀ pé ó ń bà ẹ́ lẹ́rù síwájú ibi tá a kọ “Nǹkan míì” sí.
□ Òbí mi tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lè fi èmi náà sílẹ̀.
□ Àwa tó kù ò ní rí owó tọ́jú ara wa mọ́.
□ Ó dà bíi pé èmi ni mo jẹ́ kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀.
□ Témi náà bá fẹ́ ẹnì kan, ṣe la máa kọra wa sílẹ̀.
□ Nǹkan míì ․․․․․
Sọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún ẹnì kan. Sólómọ́nì Ọba sọ pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Torí náà, wá ìgbà tó máa dáa jù láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó o sọ pé ó ń bà ẹ́ lẹ́rù yìí. Jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe ń dùn ẹ́ tó tàbí kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò mọ ohun tó o lè ṣe sí i. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàlàyé bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún ẹ, kí ọkàn rẹ sì wá balẹ̀ díẹ̀. Tí àwọn òbí rẹ kò bá fẹ́ dá ẹ lóhùn tàbí tí wọn ò bá lè ṣèrànwọ́ kankan fún ẹ báyìí, o lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún ẹnì kan tó jẹ́ olóye tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀. Ìwọ ni kó o lọ bá onítọ̀hún. Tó o bá kàn tiẹ̀ rí ẹnì kan tó o lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún, ìyẹn lè jẹ́ kí ọkàn rẹ fúyẹ́.—Òwe 17:17.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mọ̀ dájú pé Baba rẹ ọ̀run wà níbẹ̀ fún ẹ láti tẹ́tí gbọ́ ohun tó wà lọ́kàn rẹ torí pé òun ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un ‘nítorí ó bìkítà fún ọ.’—1 Pétérù 5:7.
Ohun Tí Kò Yẹ Kó O Ṣe
Má ṣe mú ẹnikẹ́ni sínú. Daniel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lápá ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí sọ pé: “Tara wọn nìkan ni àwọn òbí mi ń rò, wọn ò tiẹ̀ ro tiwa rárá, wọn ò ro àkóbá tí ohun tí wọ́n ṣe yìí máa ṣe fún wa.” Ohun tí Daniel sọ yìí máa ń dunni lóòótọ́, ó sì lè jẹ́ pé bó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, dáhùn àwọn ìbéèrè yìí wò ná. Kọ ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà tó wà níbẹ̀.
Tí Daniel ò bá jẹ́ kí ìbínú yẹn tán kó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ìpalára wo ló lè ṣe fún un? (Ka Òwe 29:22.) ․․․․․
Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn fún Daniel láti dárí ji àwọn òbí rẹ̀ tó ṣe ohun tó dùn ún yìí, kí nìdí tó fi máa dáa kó rí i pé òun dárí jì wọ́n? (Ka Éfésù 4:31, 32.) ․․․․․
Báwo ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Róòmù 3:23 ṣe máa jẹ́ kí Daniel lè fi ojú tó tọ́ wo àwọn òbí rẹ̀? ․․․․․
Má ṣe ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára. Ọmọ kan tó ń jẹ́ Denny sọ pé: “Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Mi ò wá ṣe dáadáa nílé ìwé mọ́, mo sì fìdí rẹmi lọ́dún kan. Lẹ́yìn ìyẹn . . . mo di aláwàdà nínú kíláàsì wa, ìyẹn sì máa ń fa ìjà gan-an.”
Kí lo rò pé Denny fẹ́ ṣe fún àwọn òbí rẹ̀ tó fi sọ ara rẹ̀ di aláwàdà nínú kíláàsì? ․․․․․
Kí lo rò pé ó fà á tó fi dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í jà? ․․․․․
Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa hùwàkiwà kí ìwọ náà lè ṣe Gálátíà 6:7 ṣe máa jẹ́ kó o lè ronú, kó o sì hùwà tó tọ́? ․․․․․
ohun tó máa dun àwọn òbí rẹ, báwo ni ohun tó wà nínúOhun Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn
Béèyàn bá fara pa, irú bíi kí egungun rẹ̀ kán, ó lè gba ọ̀sẹ̀ púpọ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù kó tó jinná pátápátá. Bákan náà, ọgbẹ́ ọkàn tó ń fa ìbànújẹ́ máa ń pẹ́ kó tó kúrò. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan gbà pé ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ ló sábà máa ń le jù lẹ́yìn tí àwọn òbí bá kọ ara wọn sílẹ̀. Ó lè dà bíi pé ọdún mẹ́ta yìí ti pẹ́ jù lójú tìrẹ, àmọ́ má gbàgbé pé ọ̀pọ̀ àtúnṣe ló ní láti wáyé kí nǹkan tó tún lè máa lọ déédéé fún ẹ.
Bí àpẹẹrẹ, ẹ máa ní láti tún ètò ṣe nípa àwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ilé, èyí tí ìkọ̀sílẹ̀ yẹn ti jẹ́ kó dà rú. Ó tún máa gba àkókò díẹ̀ kí ọkàn àwọn òbí rẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀ dáadáa. Ìgbà yẹn ni wọ́n á tó lè máa ṣèrànwọ́ fún ẹ bó ṣe yẹ. Àmọ́ tí ipò yẹn bá ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ ẹ lára, ọkàn rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀ gan-an.
KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 25, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ
Bí ọkàn rẹ kò bá balẹ̀ torí pé bàbá tàbí ìyá rẹ fẹ́ ẹlòmíì, kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 8 Wo Orí 24 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Akoko wà fun . . . imularada.”—Oníwàásù 3:1, 3, Bibeli Mimọ.
ÌMỌ̀RÀN
Bí àwọn òbí rẹ bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ọ̀kan lára wọn tàbí àwọn méjèèjì pàápàá ti ṣe àwọn àṣìṣe kan. Gbìyànjú láti mọ àwọn àṣìṣe náà, kó o má bàa ṣe irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá lọ́kọ tàbí tó o bá láya.—Òwe 27:12.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ìdílé tìẹ lè jẹ́ aláyọ̀ bí àárín bàbá àti ìyá rẹ ò bá tiẹ̀ tòrò.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Mo lè ṣàlàyé àwọn nǹkan tó ń bà mí lẹ́rù fún (kọ orúkọ ẹnì kan tó jẹ́ olóye tó o máa fẹ́ sọ fún) ․․․․․
Tó bá ń ṣe mí bíi pé kí n máa hùwàkiwà kí èmi náà lè ṣe ohun tó máa dun àwọn òbí mi, ohun tí màá ṣe kí èrò yẹn lè kúrò lọ́kàn mi ni: ․․․․․
Ohun tí màá béèrÈ LỌ́WỌ́ DÁDÌ TÀBÍ MỌ́MÌ NÍPA Ọ̀RỌ̀ YÌÍ NI ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí ló lè fà á táwọn òbí rẹ fi lè ṣàì fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ wọn fún ẹ?
● Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa rántí pé àwọn òbí rẹ ló ń bára wọn jà tí wọ́n fi kọ ara wọn sílẹ̀, pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n ń bá jà?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 32]
“Nígbà tí mọ́mì mi fi wá sílẹ̀, ó dùn mí gan-an, ojoojúmọ́ ni mo máa ń sunkún. Ṣùgbọ́n mo máa ń gbàdúrà gan-an, mo máa ń lọ ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ dáadáa, ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn olóye tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ni mo sì máa ń wà jù. Mo rò pé àwọn nǹkan yìí ni Jèhófà Ọlọ́run fi ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà yẹn.”—Natalie
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 33]
Ṣe ni bíborí ìbànújẹ́ tí ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí rẹ fà dà bí ìgbà téèyàn kán lápá tó sì ń jinná. Ó lè dùn ẹ́ gan-an o, àmọ́ ìbànújẹ́ yẹn ṣì máa lọ