Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró?

ORÍ 35

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró?

ṢÉ O ò le ṣe kó o má lo oògùn olóró? Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mọ̀ pé bó o ṣe sọ lílò oògùn olóró di bárakú lè ba ìlera àti ọpọlọ rẹ jẹ́. O tiẹ̀ ti lè máa gbìyànjú pé kó o jáwọ́ nínú àṣà yìí, àmọ́ tó o tún ń pa dà sídìí rẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má bọkàn jẹ́. Àwọn kan ti bọ́ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró, ìwọ náà lè bọ́! Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tí àwọn ẹni mẹ́ta tí wọ́n wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ nípa bí wọ́n ṣe bọ́ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró.

ORÚKỌ Marta

IRÚ ÈÈYÀN TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ Mọ́mì mi ò sí nílé ọkọ nígbà tí wọ́n bí mi, torí náà kò sí bàbá tó tọ́ èmi àti àbúrò mi obìnrin dàgbà. Látìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún méjìlá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àǹtí mi kan tó fẹ́ràn ijó lọ sílé ijó. Mo jẹ́ ẹnì kan tó yá mọ́ èèyàn, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọkọ́mọ rìn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi oògùn olóró dánra wò nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu kokéènì. Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mò ń gbádùn ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèrànrán, gbogbo nǹkan sì máa ń bà mí lẹ́rù. Nígbà tí ojú mi bá ti wá dá, èrò pé kí n pa ara mi ló máa ń gbà mí lọ́kàn. Ó wù mí pé kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àmọ́ kò ṣeé ṣe fún mi.

BÍ MO ṢE BỌ́ Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Ọlọ́run, mo tiẹ̀ tún lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà mélòó kan. Àmọ́ ṣe ni ìbànújẹ́ mi tún pọ̀ sí i. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], mo kó lọ sílé ọ̀rẹ́kùnrin mi, a sì bí ọmọkùnrin kan. Ti pé mo ti bímọ mú kó túbọ̀ wù mí pé kí n yí bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi pa dà. Ẹnì kan tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ nígbà kan rí kó wá sílé tó dojú kọ ibi tí mo ń gbé. Ó wá kí mi nílé, ó sì béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Ńṣe ni mo sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún un. Ó sọ pé òun ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sọ pé òun á fẹ́ láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo gbà pé kó wá máa kọ́ mi.

Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé inú Ọlọ́run ò dùn sírú ìgbésí ayé tí mò ń gbé àti pé mo ní láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti sìgá mímu. Àmọ́ ó ṣòro fún mi gan-an láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń bẹ Jèhófà Ọlọ́run lóòjọ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́ nínú àṣà búburú yìí. Mo fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn. (Òwe 27:11) Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Ìgbésí ayé mi ti túbọ̀ nítumọ̀ báyìí. Mo ti kúrò lẹ́ni tó máa ń ní ìdààmú ọkàn nígbà gbogbo. Mo bá Kristẹni ọkùnrin kan tó ń ṣe dáadáa pàdé, a sì fẹ́ra. Mo ti wá fi ìlànà Bíbélì tọ́ ọmọ mi dàgbà. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ó gbọ́ àdúrà mi, ó sì ràn mí lọ́wọ́!

ORÚKỌ Marcio

IRÚ ÈÈYÀN TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ Ìgbèríko ìlú Santo André, ní ìpínlẹ̀ São Paulo ní orílẹ̀-èdè Brazil ni mo dàgbà sí. Láti kékeré ni àwọn ọ̀rẹ́ mi ti fojú mi mọ tábà lílò, lílo oògùn olóró àti iṣẹ́ olè jíjà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ló máa ń jí mọ́tò gbé tí wọ́n sì máa ń gbé oògùn olóró. Ọ̀kan lára wọn máa ń fún àwọn ọ̀dọ́ tó wà ní àgbègbè wa ní oògùn olóró lọ́fẹ̀ẹ́. Tó bá di pé oògùn olóró ti mọ́ wọn lára tán, ṣe ló máa di dandan pé kí wọ́n di oníbàárà rẹ̀.

Ìgbà gbogbo làwọn ọlọ́pàá máa ń pààrà àgbègbè wa, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì ti mú mi lórí àwọn ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, wọ́n sì fura sí mi lẹ́ẹ̀kan pé mo máa ń gbé oògùn olóró. Àìmọye ìgbà ni mo ti bá àwọn ẹgbẹ́ olè kan tọ́jú ẹrù tí wọ́n jí gbé àti ìbọn wọn sínú ilé mi.

Àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù mi gan-an. Ṣe lojú mi máa ń pọ́n koko. Mi kì í rẹ́rìn-ín rárá. Ká sòótọ́, ìgbà gbogbo ni ojú mi máa ń le bí ojú ẹhànnà ẹ̀dá. Àwọn èèyàn máa ń pè mí ní “Tufão” (tó túmọ̀ sí Ìjì) torí pé mo máa ń jà níbikíbi tí mo bá dé. Mo tún máa ń mutí gan-an, mo sì máa ń kó obìnrin. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti kú tàbí tó ti dèrò ẹ̀wọ̀n. Nǹkan tojú sú mi débi pé mo so okùn mọ́ ẹ̀ka igi kan tí mo sì fẹ́ pokùn so.

BÍ MO ṢE BỌ́ LỌ́WỌ́ LÍLO OÒGÙN OLÓRÓ Mo bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Nígbà tó yá, mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ, ìyẹn Jèhófà, àti pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń gbìyànjú gan-an láti máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Sáàmù 83:18; 1 Pétérù 5:6, 7) Ìyípadà tó pọ̀ gan-an ni mo ní láti ṣe. Èyí tó ṣòro jù fún mi ni pé kí n tiẹ̀ lè máa rẹ́rìn-ín.

Ìgbà gbogbo ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, mo sì máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Bí àpẹẹrẹ, mo fi àwọn tí mo pè ní ọ̀rẹ́ mi sílẹ̀ mi ò sì lọ sílé ọtí mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, mo pinnu láti máa bá àwọn tó ń fi ìlànà Bíbélì sílò rìn. Kò rọrùn fún mi rárá, àmọ́ mi ò fàjọ̀gbọ̀n mọ́, mi ò sì jalè mọ́. Mo sì ti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá báyìí.

ORÚKỌ Craig

IRÚ ÈÈYÀN TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ Oko kan ní Gúúsù Ọsirélíà ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Ọ̀mùtí ni dádì mi, ìgbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ ni dádì àti mọ́mì mi sì ti fi ara wọn sílẹ̀. Mọ́mì mi fẹ́ ẹlòmíì, ọ̀dọ̀ wọn ni mo sì wà tí mo fi di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Ọdún yẹn ni mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń rẹ́ irun àgùntàn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tó ń rẹ́ irun àgùntàn, iṣẹ́ yẹn sì máa ń gbé wọn kiri. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo onírúurú oògùn olóró, mo sì ń mutí ní ìmukúmu. Mo jẹ́ kí irun orí mi gùn gan-an. Lẹ́yìn náà mo fi ọṣẹ sí i, mo dì í, mo sì wá to ìlẹ̀kẹ̀ sí i. Mo di òjòwú, ẹlẹ́ẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú, mo sì tètè máa ń bínú. Mo ti ṣẹ̀wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà.

Mo kó lọ sí ìlú kékeré kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà, èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi kan tó ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní òtẹ́ẹ̀lì kan tó wà ní àdúgbò náà sì jọ ń gbé. Àwa méjèèjì ni a jọ máa ń mugbó tá a sì ń mutí, a tún ní oko tiwa tá a fi ń gbin igbó.

BÍ MO ṢE BỌ́ LỌ́WỌ́ LÍLO OÒGÙN OLÓRÓ Kò pẹ́ sígbà tá a kórè igbó tá a gbìn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ìlẹ̀kùn ilé àtijọ́ kan tó ti bà jẹ́ tá à ń gbé. Lẹ́yìn tí wọ́n bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún fúnra mi ṣèwádìí, mo sì wá rí i nígbà tó yá pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ. Lẹ́yìn náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í borí àwọn ìṣòro tí mo ní lọ́kọ̀ọ̀kan.

Láìpẹ́, mo wá rí i pé ó yẹ kí n yọwọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ igbó mímu. Kí nìyẹn gbà pé kí n ṣe? Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni mo ṣe láti bójú tó igbó tí mo gbìn, torí ẹ̀ ni mo ṣe kọ́kọ́ rò pé á dáa kí n tà á fún ẹlòmíì. Àmọ́ mo wá pinnu pé ìyẹn kọ́ ló yẹ kí n ṣe, ni mo bá kúkú ro gbogbo ẹ̀ dà nù. Àdúrà ràn mí lọ́wọ́ gan-an kí n tó lè borí bí mo ṣe ń lo oògùn olóró àti bí mo ṣe ń mu ọtí ní àmujù. Mo bẹ Ọlọ́run pé kó fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kí n lè ja ìjà yìí ní àjàṣẹ́gun. Bákan náà, mo dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn tó ń jẹ́ kí n máa lọ́wọ́ nínú àṣàkaṣà yìí. Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo ń kọ́, tí mo sì ń fi ohun tí mo ń kọ́ sílò, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń nígboyà láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ mi. Ọ̀rẹ́bìnrin mi náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà sì yí ìwà rẹ̀ àti bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Lẹ́yìn náà, a ṣègbéyàwó. Láti ọdún mọ́kànlélógún [21] tá a ti ṣègbéyàwó, ṣe ni ara wa túbọ̀ ń le koko, a sì ti ní ọmọ méjì. Mi ò mọ bí ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí báyìí, ká ní mi ò mọ Jèhófà, tí mi ò sì yí ìgbésí ayé mi pa dà.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Jèhófà ni okun mi àti agbára ńlá mi.”​—Aísáyà 12:2.

ÌMỌ̀RÀN

Bó bá ṣeé ṣe, yẹra fún àwọn èèyàn tó o mọ̀ pé ẹ ti jọ máa ń lo oògùn olóró, àwọn ibi tẹ́ ẹ ti máa ń pàdé àti ohun tó máa ń mú ọkàn ẹ fà sí oògùn olóró. Ìwádìí fi hàn pé fífojú kan èyíkéyìí nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kí ọkàn rẹ fà sí oògùn olóró.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Lílo oògùn olóró lè dà ẹ́ lórí rú.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mo bá tún ti lo oògùn olóró, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí ẹnì kan fi ní láti ṣe ìyípadà tó lágbára nígbèésí ayé rẹ̀ tó bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró?

● Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ téèyàn kọ́ nípa Ọlọ́run ṣe lè ranni lọ́wọ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 253]

“Bí mo ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà rere tó wà nínú Bíbélì nígbèésí ayé mi, bẹ́ẹ̀ ni ayé mi ń dùn tó sì ń lóyin.”​—Marta

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 256]

Bí ìgbà téèyàn sá jáde kúrò nínú ilé tó ń jó ni ọ̀rọ̀ kéèyàn borí lílo oògùn olóró, wàá pàdánù àwọn nǹkan, àmọ́ wàá gba ẹ̀mí rẹ là