Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Burú Nínú Mímu Ọtí Ní Àmujù?

Kí Ló Burú Nínú Mímu Ọtí Ní Àmujù?

ORÍ 34

Kí Ló Burú Nínú Mímu Ọtí Ní Àmujù?

Kí ló máa jẹ́ ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè tá a tò sí ìsàlẹ̀ yìí? Fi àmì ✔ sínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìdáhùn rẹ.

Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára àwọn ojúgbà rẹ ń mu ọtí nígbà tí wọn kò tíì dàgbà tó láti mutí tàbí kí wọ́n máa mu ọtí àmujù?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ǹjẹ́ àwọn ojúgbà rẹ ti fìgbà kankan rí rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà mu ọtí?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ǹjẹ́ o ti mu ọtí ní àmujù rí?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

KÍ LÓ túmọ̀ sí pé kéèyàn mu ọtí ní àmujù? Àwọn kan sọ pé ó wulẹ̀ túmọ̀ sí pé kéèyàn mutí títí ọtí fi máa pani. Àjọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Kan Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Mímu Ọtí ní Àmupara àti Sísọ Ọtí Mímu Di Bárakú gbìyànjú láti sọ ohun tó jẹ́ gan-an. Ó sọ pé mímu ọtí ní àmujù “sábà máa ń túmọ̀ sí kí ọkùnrin mu ìgò ọtí méjì àti ààbọ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan tàbí kí obìnrin mu ìgò ọtí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.”

Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o mu ọtí ní àmujù tàbí pé kó o mu ọtí nígbà tó jẹ́ pé o ò tíì pé iye ọdún tí òfin gbà ẹ́ láyè láti mutí? Ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ máa ń ṣe. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń mutí ní àmupara. * Àmọ́ bi ara rẹ pé, ‘Kí lohun tí mo lè sọ gan-an pé ó jẹ́ ìdí tí mo fi fẹ́ máa mutí, àti pé kí ni ọtí lè mú kó ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa jẹ́ ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí, ṣé òótọ́ ni àbí irọ́? Fi àmì ✔ sínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìdáhùn rẹ, lẹ́yìn náà kó o wá wo àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀.

a. Torí pé àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ràn bí ọtí ṣe máa ń rí lẹ́nu ni wọ́n ṣe máa ń mu ún.

□ Òótọ́ □ Irọ́

b. Torí pé àwọn ọ̀dọ́ ṣì kéré lọ́jọ́ orí tí ara wọn ṣì ń ta kébékébé, ọtí ò lè ṣàkóbá fún wọn bó ṣe máa ṣàkóbá fáwọn tó ti dàgbà.

□ Òótọ́ □ Irọ́

d. Mímu ọtí ní àmujù kò lè ṣekú pa ẹ́.

□ Òótọ́ □ Irọ́

e. Bíbélì dẹ́bi fún mímu ọtí fún ìdí èyíkéyìí.

□ Òótọ́ □ Irọ́

ẹ. Àìlera ara nìkan ni mímu ọtí ní àmujù máa ń fà.

□ Òótọ́ □ Irọ́

a. Torí pé àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ràn bí ọtí ṣe máa ń rí lẹ́nu ni wọ́n ṣe máa ń mu ún. Ìdáhùn​—Irọ́. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń mutí tó, wọ́n rí i pé iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé torí kí àwọn ojúgbà àwọn lè mọ̀ pé àwọn náà lajú ni àwọn ṣe ń mutí. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìwádìí fi hàn pé iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́ ló sọ pé, torí pé àwọn fẹ́ ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe làwọn ṣe ń mutí. Àmọ́, èyí tó ju ìdajì àwọn ọ̀dọ́ náà ló sọ pé torí kí àwọn lè gbàgbé ìṣòro àwọn ni àwọn ṣe ń mutí.

b. Torí pé àwọn ọ̀dọ́ ṣì kéré lọ́jọ́ orí tí ara wọn ṣì ń ta kébékébé, ọtí ò lè ṣàkóbá fún wọn bó ṣe máa ṣàkóbá fáwọn tó ti dàgbà. Ìdáhùn​—Irọ́. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Discover sọ pé: “Ìwádìí kan tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé wàhálà ni àwọn ọ̀dọ́ tó ń mutí ń fà lẹ́sẹ̀.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? “Ṣe ni àwọn ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tó ń mu ọtí lámujù wulẹ̀ ń ba ọpọlọ wọn jẹ́ díẹ̀díẹ̀.”

Àmujù ọtí wà lára àwọn nǹkan tó ń fa rorẹ́, ó ń mú kí ara èèyàn máa hun jọ láìtọ́jọ́, ó ń mú kí èèyàn máa sanra, ó sì tún wà lára àwọn nǹkan tó máa ń jẹ́ kéèyàn sọ ọtí àti oògùn olóró di bárakú. Ó tún máa ń ba àwọn ẹ̀yà inú ara jẹ́, irú bí ẹ̀dọ̀ àti ọkàn, ó sì máa ń da ọpọlọ rú.

d. Mímu ọtí ní àmujù kò lè ṣekú pa ẹ́. Ìdáhùn​—Irọ́. Àmujù ọtí kì í jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn fi bẹ́ẹ̀ ráyè wọnú ọpọlọ; tó bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, ara lè má ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kó ṣiṣẹ́ mọ́ tàbí kó tiẹ̀ ṣíwọ́ iṣẹ́. Ara àwọn nǹkan tí ìyẹn lè fà ni pé kéèyàn máa bì, kó má mọ ohun tó ń ṣe mọ́, kó má lè mí délẹ̀ dáadáa tàbí kó máa mí ní ìdákúrekú. Ó tiẹ̀ lè yọrí sí ikú nígbà míì.

e. Bíbélì dẹ́bi fún mímu ọtí fún ìdí èyíkéyìí. Ìdáhùn​—Irọ́. Bíbélì ò ní kéèyàn má mutí o, kò sì ní káwọn ọ̀dọ́ má ṣe gbádùn ara wọn. (Sáàmù 104:15; Oníwàásù 10:19) Síbẹ̀, ó yẹ kó o dàgbà tó ẹni tí òfin gbà láyé láti mutí kó o tó mú un.​—Róòmù 13:1.

Àmọ́, Bíbélì sọ pé ká má ṣe mu ọtí ní àmupara. Òwe 20:1 sọ pé: “Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.” Mímu ọtí líle lè fa kí wọ́n máa fi ẹ́ ṣẹ̀sín! Òótọ́ ni pé o lè fi gbádùn ara rẹ fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n tó o bá ṣàṣejù nídìí rẹ̀, á ‘bù ẹ́ ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò,’ nígbà tójú ẹ bá dá, wàá wá rí bí ìpalára tó ṣe fún ẹ ti pọ̀ tó.​—Òwe 23:32.

ẹ. Àìlera ara nìkan ni mímu ọtí ní àmujù máa ń fà. Ìdáhùn​—Irọ́. Tó o bá mutí yó, àwọn èèyàn lè fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́, wọ́n lè lù ẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fipá bá ẹ lò pọ̀ pàápàá. Bákan náà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó máa ṣèpalára fáwọn ẹlòmíì, ìyẹn àwọn nǹkan tó ò ní jẹ́ dán wò ká ní kì í ṣe pé o mutí yó. Bíbélì kìlọ̀ pé tó o bá mu ọtí ní àmujù, ‘o kò ní lè ronú dáadáa, ọ̀rọ̀ rẹ kò sì ní já geere.’ (Òwe 23:33, Bíbélì Today’s English Version) Ní kúkúrú, ṣe lo máa wá dà bí òpònú! Lára àwọn nǹkan ìbànújẹ́ míì tó lè yọrí sí ni pé àárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè dà rú, o lè má ṣe dáadáa mọ́ nínú ẹ̀kọ́ àti lẹ́nu iṣẹ́ rẹ, o lè dẹni tí orúkọ rẹ̀ wọ̀wé lọ́dọ̀ ìjọba pé ó jẹ́ ọ̀daràn, o sì lè di akúṣẹ̀ẹ́.​—Òwe 23:21.

Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó yẹ kó o ronú lórí ipa tí ọtí àmujù máa ní lórí àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run. “Gbogbo èrò inú rẹ” ni Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o fi sin òun, kò fẹ́ kó o jẹ́ ẹni tí ọtí àmujù ti gba làákàyè rẹ̀. (Mátíù 22:37) Kì í ṣe “àṣejù nídìí wáìnì” nìkan ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún, ó tún dẹ́bi fún “ìfagagbága ọtí mímu.” (1 Pétérù 4:3) Gbogbo èyí fi hàn pé mímu ọtí ní àmujù ta ko ìfẹ́ inú Ẹlẹ́dàá wa, ó sì lè mú kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run.

Èwo Lo Máa Wá Ṣe Báyìí?

Ṣé ìwọ náà á máa báwọn mutí ní àmujù báwọn ọ̀dọ́ kan ṣe ń ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i?” (Róòmù 6:16) Ṣé ìwọ wá fẹ́ dẹrú àwọn ojúgbà rẹ, tàbí ṣé o fẹ́ dẹrú ọtí?

Kí ló yẹ kó o ṣe bí mímu ọtí ní àmujù bá ti di bárakú fún ẹ? Láìjáfara, sọ fún òbí ẹ tàbí ẹnì kan tó jẹ́ olóye tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀, kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Òun ṣáà ni “ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sáàmù 46:1) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ èèyàn ló sábà máa ń kó ọtí àmujù àti mímu ọtí láti kékeré ranni, ó lè gba pé kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ míì. * Ó lè má rọrùn láti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàṣeyọrí.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

O lè borí sísọ oògùn olóró di bárakú. Wo bó o ṣe lè ṣe é.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 11 Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 249, tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “ Àwọn Wo Ló Máa Ń Mu Ún?

^ ìpínrọ̀ 32 Wo Orí 8 àti 9 nínú ìwé yìí àti Orí 15 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọ̀mùtípara . . . yóò di òtòṣì.”​—Òwe 23:21.

ÌMỌ̀RÀN

Mọ ìdí tí ọtí fi máa ń wù ẹ́ mu. Wá gbìyànjú láti wá àwọn nǹkan míì tí kò ní ṣàkóbá fún ẹ tó o lè ṣe láti fi gbádùn ara rẹ tàbí tí wàá lè fi pàrònú rẹ́ dípò kó o máa mu ọtí.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé, “àwọn tí wọ́n máa ń mu ọtí àmujù sábà máa ń pa kíláàsì jẹ, wọ́n máa ń fìdí rẹmi nílé ìwé, wọ́n máa ń fara pa, wọ́n sì sábà máa ń ya bàsèjẹ́ ní ìlọ́po mẹ́jọ ju àwọn tí kì í mu ọtí àmujù.”

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Tí àwọn ojúgbà mi bá fẹ́ ká jọ máa mu ọtí ní àmujù, màá sọ pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí àwọn ojúgbà rẹ fi fẹ́ kí àwọn míì náà máa mu ọtí ní àmujù bíi tàwọn?

● Ṣé mímu ọtí ní àmujù máa jẹ́ kí àwọn obìnrin (tàbí ọkùnrin) máa gba tìẹ, kí sì nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 250]

“Nígbà táwọn ọmọ ilé ìwé mi fi ọtí lọ̀ mí, mo sọ fún wọn pé kò dìgbà tí mo bá mutí kí n tó gbádùn ara mi.”​—Mark

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 249]

 Àwọn Wo Ló Máa Ń Mu Ún?

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọmọ ilé ìwé girama tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Scotland, àti nílẹ̀ Wales ṣe fi hàn, ìdá mẹ́rin àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́rìnlá “ni wọ́n sọ pé àwọn ‘gbé’ ìgò ọtí méjì àti ààbọ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ‘lura’ rí ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.” Ìdajì àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sí mẹ́rìndínlógún [16] tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí. Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera Ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé “nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [10,400,000] àwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí ogún ọdún ló sọ pé àwọn máa ń mu ọtí. Lára àwọn wọ̀nyí, mílíọ̀nù márùn-ún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún [5,100,000] ló jẹ́ alámujù, tí mílíọ̀nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [2,300,000] lára wọn sì jẹ́ òkú ọ̀mùtí tó ń mu àmujù lẹ́ẹ̀marùn-ún ó kéré tán, lóṣù.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Ọsirélíà fi hàn pé àwọn ọmọbìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń mu ọtí ní àmujù níbẹ̀, àní wọ́n máa ń mu tó ìgò ọtí mẹ́fà sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 251]

Ọtí líle lè buni ṣán bí ejò